ORÍ 136
Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Létíkun Gálílì
WỌ́N RÍ JÉSÙ NÍ ETÍ ÒKUN GÁLÍLÌ
JÉSÙ NÍ KÍ PÉTÉRÙ ÀTÀWỌN TÓ KÙ MÁA BỌ́ ÀWỌN ÀGÙNTÀN ÒUN
Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “Lẹ́yìn tí mo bá jíǹde, màá lọ sí Gálílì ṣáájú yín.” (Mátíù 26:32; 28:7, 10) Torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ sí Gálílì, àmọ́ kí ni wọ́n fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀?
Lẹ́yìn tí wọ́n débẹ̀, Pétérù sọ fún mẹ́fà nínú àwọn àpọ́sítélì pé: “Mò ń lọ pẹja.” Àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà dáhùn pé: “A máa tẹ̀ lé ọ.” (Jòhánù 21:3) Àmọ́ wọn ò rí ẹja kankan mú ní gbogbo òru ọjọ́ yẹn. Bí ojúmọ́ ṣe ń mọ́ bọ̀, wọ́n rí Jésù ní etíkun, àmọ́ wọn ò dá a mọ̀. Jésù wá nahùn pè wọ́n, ó ní: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ ò ní nǹkan tí ẹ máa jẹ, àbí ẹ ní?” Wọ́n dáhùn pé: “Rárá o!” Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ ju àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ sì máa rí díẹ̀.” (Jòhánù 21:5, 6) Ẹja tí wọ́n rí kó pọ̀ débi pé wọn ò lè fa àwọ̀n wọn jáde látinú omi.
Ni Jòhánù bá sọ fún Pétérù pé: “Olúwa ni!” (Jòhánù 21:7) Bí Pétérù ṣe yára sán aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́dìí nìyẹn, torí kò wọ̀ ọ́ tẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń pẹja. Ló bá bẹ́ sínú òkun, ó sì wẹ̀ lọ sí etíkun. Nǹkan bí àádọ́rùn-ún (90) mítà ni láti ibi tó wà sí etíkun. Àwọn tó kù sì rọra ń wa ọkọ̀ ojú omi tẹ̀ lé e, wọ́n ń wọ́ àwọ̀n tí ẹja ti kúnnú ẹ̀ lọ sí etíkun.
Nígbà tí wọ́n dé etíkun, wọ́n rí “ẹja lórí iná èédú níbẹ̀, wọ́n sì rí búrẹ́dì.” Jésù wá sọ pé: “Ẹ mú díẹ̀ wá lára ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa.” Ni Pétérù bá fa àwọ̀n náà sí etíkun, wọ́n sì bá ẹja ńlá ọgọ́rùn-ún kan ó lé mẹ́tàléláàádọ́ta (153) nínú ẹ̀! Lẹ́yìn náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ wá jẹ oúnjẹ àárọ̀.” Àmọ́ kò sẹ́ni tó jẹ́ bi í pé: “Ta ni ọ́?” torí wọ́n mọ̀ pé Jésù ni. (Jòhánù 21:10-12) Ìgbà kẹta rèé tí Jésù máa yọ sáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lápapọ̀.
Jésù fún wọn ní búrẹ́dì àti ẹja. Ó ṣeé ṣe kó yíjú sí ẹja tí wọ́n pa nígbà tó bi Pétérù pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ?” Ṣé iṣẹ́ ẹja pípa ló gba Pétérù lọ́kàn ju iṣẹ́ tí Jésù fẹ́ kó máa ṣe lọ? Pétérù fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Jésù wá sọ fún un pé: “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn mi.”—Jòhánù 21:15.
Jésù tún bi í pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o nífẹ̀ẹ́ mi?” Ìbéèrè yẹn lè fẹ́ ya Pétérù lẹ́nu, ó wá dáhùn látọkàn wá pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Ohun tí Jésù fi dá a lóhùn jọra pẹ̀lú ohun tó sọ tẹ́lẹ̀, ó ní: “Máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.”—Jòhánù 21:16.
Jésù bi í lẹ́ẹ̀kẹta pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi?” Ó ṣeé ṣe kí Pétérù máa wò ó pé bóyá Jésù ò gba òun gbọ́. Ni Pétérù bá fi ìdánilójú sọ pé: “Olúwa, o mọ ohun gbogbo; o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Jésù tún wá tẹnu mọ́ ohun tó yẹ kí Pétérù ṣe, ó ní: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” (Jòhánù 21:17) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí i pé ó yẹ káwọn tó ń múpò iwájú máa bójú tó àwọn tí Ọlọ́run fà wá sínú agbo rẹ̀.
Torí pé Jésù ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an ni wọ́n ṣe mú un, tí wọ́n sì pa á. Ó wá sọ fún Pétérù pé ohun tó jọ ìyẹn ló máa ṣẹlẹ̀ sí i, ó ní: “Nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́, o máa ń wọ aṣọ fúnra rẹ, o sì máa ń rìn káàkiri lọ síbi tí o fẹ́. Àmọ́ tí o bá darúgbó, o máa na ọwọ́ rẹ, ẹlòmíì máa wọ aṣọ fún ọ, ó sì máa gbé ọ lọ síbi tó ò fẹ́.” Síbẹ̀, Jésù rọ Pétérù pé: “Máa tẹ̀ lé mi.”—Jòhánù 21:18, 19.
Nígbà tí Pétérù rí àpọ́sítélì Jòhánù, ó béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Olúwa, ẹni yìí ńkọ́?” Láàárín àwọn àpọ́sítélì, Jòhánù ni Jésù nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ sí. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí i? Jésù sọ fún Pétérù pé: “Kí ló kàn ọ́ tí mo bá fẹ́ kó wà títí màá fi dé?” (Jòhánù 21:21-23) Jésù fẹ́ kí Pétérù mọ̀ pé kò yẹ kó máa da ara ẹ̀ láàmú lórí nǹkan táwọn míì ń ṣe. Àmọ́ ohun tí Jésù sọ fi hàn pé ẹ̀mí Jòhánù máa gùn ju tàwọn àpọ́sítélì yòókù lọ, ó sì máa rí ìran nípa ìgbà tí Jésù bá dé nínú agbára, lẹ́yìn tó di ọba.
Ká sòótọ́, àwọn nǹkan míì wà tí Jésù ṣe, ó pọ̀ débi pé ọ̀pọ̀ àkájọ ìwé ò lè gbà á.