Ẹ̀KỌ́ 92
Jésù Fara Han Àwọn Apẹja
Lẹ́yìn ọjọ́ tí Jésù fara han àwọn àpọ́sítélì ẹ̀, Pétérù lọ sí òkun Gálílì láti lọ pẹja. Tọ́másì, Jémíìsì, Jòhánù àtàwọn ọmọlẹ́yìn míì sì tẹ̀ lé e lọ. Wọ́n wá ẹja láti alẹ́ mọ́jú, àmọ́ wọn ò rí ẹja kankan pa.
Láàárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, wọ́n rí ọkùnrin kan tó dúró létí òkun. Ọkùnrin náà wá béèrè lọ́wọ́ wọn pé: ‘Ṣé ẹ rí ẹja pa?’ Wọ́n dáhùn pé: “Rárá!” Ọkùnrin náà wá sọ pé: ‘Ẹ ju nẹ́ẹ̀tì yín sápá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi náà.’ Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, nẹ́ẹ̀tì wọn kó ẹja tó pọ̀ gan-an débi pé wọn ò lè fà á sínú ọkọ̀ ojú omi wọn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jòhánù ti rí i pé Jésù ni ọkùnrin tó ń bá wọn sọ̀rọ̀, ló bá pariwo pé: “Olúwa ni!” Pétérù wá bẹ́ sínú omi, ó sì wẹ̀ lọ sétí òkun láti pàdé Jésù. Àwọn tó kù sì wa ọkọ̀ lọ bá a.
Nígbà tí wọ́n dé etí òkun, wọ́n rí i pé ẹja àti búrẹ́dì wà lórí iná. Jésù ní kí wọ́n mú díẹ̀ wá nínú ẹja tí wọ́n pa, kí wọ́n sì fi kún èyí tó wà lórí iná. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ wá jẹ oúnjẹ àárọ̀ yín.’
Lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán, Jésù béèrè lọ́wọ́ Pétérù pé: ‘Ṣó o fẹ́ràn mi ju iṣẹ́ ẹja pípa lọ?’ Pétérù dáhùn pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn ẹ.’ Jésù sọ pé: ‘Torí náà máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.’ Jésù tún béèrè lẹ́ẹ̀kejì pé: ‘Pétérù, ṣó o fẹ́ràn mi?’ Pétérù dáhùn pé: ‘Olúwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn ẹ.’ Jésù sọ pé: ‘Máa ṣe olùṣọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.’ Jésù tún béèrè nígbà kẹta. Ẹ̀dùn ọkàn wá bá Pétérù, ó sì sọ pé: ‘Olúwa, o mọ ohun gbogbo. O mọ̀ pé mo fẹ́ràn ẹ.’ Jésù sọ fún un pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” Jésù tún sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.”
“[Jésù] sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa tẹ̀ lé mi, màá sì sọ yín di apẹja èèyàn.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa àwọ̀n wọn tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.”—Mátíù 4:19, 20