ORÍ 12
Bá A Ṣe Ń Ti Iṣẹ́ Ìwàásù Lẹ́yìn ní Ìjọ Kọ̀ọ̀kan àti Kárí Ayé
IṢẸ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ṣẹ, a sì ti wàásù ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run “dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8; Mát. 24:14) Ohun tó mú ká lè ṣe èyí ni pé à ń lo àkókò àti okun wa láti máa wàásù fún àwọn èèyàn. A sì ń bá a nìṣó láti máa fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní nígbèésí ayé wa torí pé a gbọ́kàn lé Jèhófà pé ó máa pèsè fún àwọn tó ń bá a ṣiṣẹ́. (Mát. 6:25-34; 1 Kọ́r. 3:5-9) Bí iṣẹ́ yìí ṣe ń tẹ̀ síwájú fi hàn pé inú Jèhófà ń dùn sí wa, ó sì ń bù kún wa.
BÍ A ṢE Ń BÓJÚ TÓ ÀWỌN OHUN TÓ JẸ MỌ́ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN KÁRÍ AYÉ
2 Bí àwọn èèyàn ṣe ń kíyè sí oríṣiríṣi ọ̀nà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń wàásù àti bá a ṣe ń fún àwọn èèyàn láwọn ìtẹ̀jáde láì díye lé e, wọ́n máa ń béèrè pé: “Báwo lẹ ṣe ń ṣe é?” Ká sòótọ́, owó kékeré kọ́ là ń ná láti tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. A tún ń náwó sórí kíkọ́ àwọn Bẹ́tẹ́lì, a sì ń ṣe àbójútó rẹ̀, kí àwọn òjíṣẹ́ tó wà níbẹ̀ lè máa lo àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, kí àwọn míì sì lè máa darí iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn iṣẹ́ míì tó ń mú kí ìhìn rere tẹ̀ síwájú. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ń ṣètìlẹyìn fáwọn alábòójútó àyíká, àwọn míṣọ́nnárì tó ń sìn ní pápá, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àtàwọn míì tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn nìṣó. Ó ṣe kedere pé lóde òní, owó bàǹtàbanta là ń ná sórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yálà lágbègbè wa tàbí kárí ayé. Ibo wá la ti ń rí gbogbo owó tá à ń ná?
3 Ọ̀pọ̀ èèyàn tó mọyì iṣẹ́ ìwàásù tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé máa ń láyọ̀ láti fowó ti iṣẹ́ ìwàásù wa lẹ́yìn. Àmọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la máa ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú ìtìlẹ́yìn náà, àwọn kan lára wa sì máa ń fi irú ọrẹ àtinúwá bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bá a ṣe ń fi tinútinú ṣe èyí mú ká fìwà jọ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́, tí wọ́n fi tinútinú ṣètìlẹ́yìn lọ́pọ̀ yanturu láti kọ́ ilé ìjọsìn Jèhófà. (Ẹ́kís. 35:20-29; 1 Kíró. 29:9) Àwọn kan máa ń pín ogún wọn fún ètò Ọlọ́run, àwọn míì máa ń fi ohun tí wọ́n lágbára ránṣẹ́, a sì tún máa ń rí ọrẹ gbà níwọ̀nba látinú àwọn ìjọ àtàwọn àyíká. Tá a bá pa àwọn ẹ̀bùn yìí pọ̀, a máa ń rí iye tó pọ̀ tó láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ.
Àǹfààní làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kà á sí pé à ń lo owó àtàwọn nǹkan míì tá a ní láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù máa tẹ̀ síwájú
4 Àǹfààní làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kà á sí pé à ń lo owó àtàwọn nǹkan míì tá a ní láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù máa tẹ̀ síwájú. Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àpótí kan tí wọ́n ń tọ́jú owó sí, èyí tí wọ́n máa ń lò fún àwọn ìnáwó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. (Jòh. 13:29) Bíbélì sọ nípa àwọn obìnrin tí wọ́n ṣètìlẹ́yìn fún Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Máàkù 15:40, 41; Lúùkù 8:3) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìlọsíwájú ìhìn rere tí wọ́n sì fẹ́ láti ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ohun ìní tara, òun náà sì fìfẹ́ gbà á. (Fílí. 4:14-16; 1 Tẹs. 2:9) Àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó fi ìtara sin Ọlọ́run láyé àtijọ́ tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀làwọ́ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé lónìí. Ìyẹn sì ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn ọlọ́kàn rere níbi gbogbo láti “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìfi. 22:17.
BÍ A ṢE Ń BÓJÚ TÓ ÌNÁWÓ ÌJỌ
5 Ọrẹ àtinúwá la fi ń bójú tó àwọn ìnáwó ìjọ. A kì í gbégbá owó, a kì í bu owó léni, a kì í sì í tọrọ owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn àpótí ọrẹ máa ń wà láwọn ìpàdé wa kí kálukú lè ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn “gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀.”—2 Kọ́r. 9:7.
6 A sábà máa ń fi ọrẹ yìí bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè pinnu pé àwọn á fi lára owó náà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kí iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé lè máa tẹ̀ síwájú. Bí wọ́n bá pinnu bẹ́ẹ̀, wọ́n á gbé ìpinnu náà síwájú ìjọ kí àwọn ará lè fọwọ́ sí i. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ ìjọ láti máa fi ọrẹ ránṣẹ́ déédéé fún iṣẹ́ kárí ayé. Bí gbogbo wa bá mọ àwọn nǹkan tá à ń náwó lé lórí nínú ìjọ tá a sì ń ṣètìlẹ́yìn bó ṣe yẹ, kò ní sí ìdí láti máa ṣèfilọ̀ lemọ́lemọ́ nípa ọrẹ.
BÍ A ṢE Ń BÓJÚ TÓ ÀWỌN ỌRẸ
7 Lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí, arákùnrin méjì á kó owó tó bá wà nínú àwọn àpótí ọrẹ, wọ́n á sì ṣe àkọsílẹ̀ iye tí wọ́n kó níbẹ̀. (2 Ọba 12:9, 10; 2 Kọ́r. 8:20) Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa ṣètò tó yẹ láti tọ́jú owó náà dáadáa títí dìgbà tí ìjọ á fi nílò rẹ̀ tàbí tí wọ́n á fi owó náà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Arákùnrin tó ń bójú tó àkáǹtì ìjọ máa ń ṣe àkọsílẹ̀ owó tó ń wọlé fún ìjọ àti owó tí ìjọ ń ná, wọ́n á sì ka ìròyìn náà fún ìjọ. Ní oṣù mẹ́ta mẹ́ta, olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa ń ṣètò fún àyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ.
BÍ A ṢE Ń BÓJÚ TÓ ÌNÁWÓ ÀYÍKÁ
8 Ọrẹ tí àwọn ará tó wà ní àyíká bá fi ṣètìlẹyìn la máa fi ń bójú tó ìnáwó tó bá jẹ yọ láwọn àpéjọ àyíká àtàwọn ìnáwó míì tí àyíká bá ṣe. Àwọn àpótí ọrẹ máa ń wà nínú gbọ̀ngàn àpéjọ kí àwọn tó bá fẹ́ ṣe ọrẹ àtinúwá fún àyíká lè ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè gba pé kí àwọn ìjọ mú ọrẹ wá láwọn ìgbà míì kí wọ́n lè bójú tó àwọn ìnáwó tó ń jẹ́ yọ.
9 Ó yẹ kí àyíká kọ̀ọ̀kan lè bójú tó ìnáwó wọn, kí wọ́n sì fi owó tó bá ṣẹ́ kù ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé. Àmọ́ tí kò bá sí owó tó pọ̀ tó nínú àkáǹtì àyíká láti san owó tí wọ́n ná ní àpéjọ tí wọ́n ṣe tán tàbí tí kò bá sí owó tí wọ́n lè fi bójú tó àwọn nǹkan tí wọ́n nílò fún àpéjọ tó kàn, irú bí owó gbọ̀ngàn tí wọ́n fẹ́ lò fún àpéjọ tó kàn, alábòójútó àyíká lè ní kí wọ́n rán àwọn ìjọ tó wà ní àyíká náà létí pé wọ́n láǹfààní láti fowó ṣètìlẹyìn. Kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kọ̀ọ̀kan tó wà ní àyíká yẹn jíròrò ọ̀rọ̀ náà, kí wọ́n sì pinnu iye tí ìjọ wọn máa fi ṣètìlẹ́yìn fún ìnáwó àyíká wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n á gbé ìpinnu yẹn síwájú ìjọ.
10 Tí ọ̀rọ̀ ìnáwó bá jẹ yọ, tó sì gba pé káwọn alàgbà tó wà ní àyíká gbọ́ sí i, kí gbogbo alàgbà àyíká náà ṣèpàdé lọ́jọ́ àpéjọ àyíká wọn. Ó máa gba pé káwọn alàgbà fọwọ́ sí ìnáwó èyíkéyìí míì tó bá yọjú tó yàtọ̀ sí àwọn ìnáwó tá a máa ń ṣe déédéé. Nígbàkigbà tá a bá fẹ́ ná owó táwọn alàgbà fọwọ́ sí yìí, a gbọ́dọ̀ ṣàkọ́sílẹ̀ iye owó náà, ká sì gba àṣẹ.
11 A máa ń ṣètò pé kí wọ́n yẹ àkáǹtì àyíká wò lóòrèkóòrè.
BÍ A ṢE Ń BÓJÚ TÓ ÀWỌN ALÁÌNÍ
12 Lára ohun tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń fi owó tó wà nínú àpótí owó wọn ṣe ni láti máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́. (Máàkù 14:3-5; Jòh. 13:29) Ojúṣe àwa Kristẹni nìyẹn, kò sì tíì yí pa dà, torí Jésù sọ pé: “Ìgbà gbogbo ni àwọn aláìní wà láàárín yín.” (Máàkù 14:7) Kí làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lóde òní láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́?
13 Nígbà míì, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lè nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tara nítorí ọjọ́ ogbó, àìlera tàbí àjálù kan tó kọjá agbára wọn. Nírú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ìdílé wọn, mọ̀lẹ́bí wọn àtàwọn míì tó bá gbọ́ sí i máa ń fẹ́ láti ṣèrànwọ́. Ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ní ohun ìní ayé yìí, tó sì rí i pé arákùnrin rẹ̀ ṣaláìní síbẹ̀ tí kò ṣàánú rẹ̀, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe wà nínú rẹ̀? Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, kò yẹ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí ti ahọ́n, àmọ́ ó yẹ kó jẹ́ ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòh. 3:17, 18; 2 Tẹs. 3:6-12) Apá kan ìjọsìn tòótọ́ ni kéèyàn máa bójú tó àwọn olóòótọ́ tó nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tara.—Jém. 1:27; 2:14-17.
14 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó ṣàlàyé bá a ṣe lè ṣèrànwọ́ nípa tara fún àwọn tó bá yẹ. Wàá rí ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí nínú 1 Tímótì 5:3-21. Ojúṣe Kristẹni kan ni láti máa pèsè fún ìdílé rẹ̀. Ní tàwọn òbí tó ti dàgbà tàbí tí wọ́n ní àìlera, àwọn ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí mọ̀lẹ́bí wọn tó sún mọ́ wọn ló gbọ́dọ̀ máa bójú tó wọn. Nígbà míì, ìjọba tàbí ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re máa ń pèsè ìrànwọ́ nípa tara, tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ẹlòmíì bá àgbàlagbà tàbí aláìlera náà béèrè fún ẹ̀tọ́ tirẹ̀. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin tó ti pẹ́ nínú òtítọ́ tó sì jẹ́ olóòótọ́ wà nínú ipò àìní, ó lè pọn dandan pé kí ìjọ pawọ́ pọ̀ ràn án lọ́wọ́. Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé kò sí ọmọ, àyà tàbí ọkọ, tàbí mọ̀lẹ́bí kankan tó lè ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, tí ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ ìjọba ò sì tó, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè ṣe ètò tó yẹ láti ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Inú àwa Kristẹni máa ń dùn láti fi ohun ìní wa ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìní.
15 Lára ohun tó máa ń sọ àwọn ará wa di aláìní ni inúnibíni, ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, omíyalé, ìyàn tàbí àwọn àjálù míì tó wọ́pọ̀ ní àwọn àkókò líle koko yìí. (Mát. 24:7-9) Nírú àsìkò báyìí, àwọn ìjọ tó wà ní àdúgbò náà lè má fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan tí wọ́n lè fi ran ara wọn lọ́wọ́, torí náà Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń ṣètò báwọn ará níbòmíì ṣe máa dìde ìrànlọ́wọ́. Irú ètò yìí náà làwọn Kristẹni tó wà ní Éṣíà Kékeré ṣe láti fún àwọn ará tó wà ní Jùdíà lóúnjẹ nígbà tí ìyàn mú. (1 Kọ́r. 16:1-4; 2 Kọ́r. 9:1-5) Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, à ń fi hàn pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa àti pé ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ni wá.—Jòh. 13:35.
BÍ A ṢE Ń PÍN ÀWỌN ÌWÉ WA
16 Iṣẹ́ ńlá ni Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì ń ṣe nínú bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà sábà máa ń yan ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan láti máa bójú tó bí ìjọ ṣe ń gba ìwé. Àwọn arákùnrin tá a yan iṣẹ́ yìí fún máa ń fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ wọn. Wọ́n máa ń ní àkọsílẹ̀ tó péye kí ìjọ lè ní ìtẹ̀jáde tó máa tó wọn lò.
17 Torí pé Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ ni wá, a mọ̀ pé ohun yòówù ká ní, Jèhófà ló fún wa ó sì yẹ ká lò ó fún un, ì báà jẹ́ àkókò wa, làákàyè àti ẹ̀bùn wa, dúkìá àti ohun ìní wa, títí kan ẹ̀mí wa pàápàá. (Lúùkù 17:10; 1 Kọ́r. 4:7) Tá a bá ń lo gbogbo ohun tá a ní lọ́nà rere, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Inú wa máa ń dùn láti máa fi ohun ìní wa tó ṣeyebíye bọlá fún Jèhófà torí pé ó mọyì bá a ṣe ń fi tọkàntọkàn lo ẹ̀bùn èyíkéyìí tá a ní fún un. (Òwe 3:9; Máàkù 14:3-9; Lúùkù 21:1-4; Kól. 3:23, 24) Jésù sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mát. 10:8) Bá a ṣe ń lo ara wa àtàwọn nǹkan tá a ní nínú ìjọsìn Jèhófà, àwa náà máa ní ayọ̀ púpọ̀.—Ìṣe 20:35.