ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • od orí 14 ojú ìwé 141-156
  • Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìjọ Wà ní Mímọ́ Kí Àlàáfíà sì Jọba

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìjọ Wà ní Mímọ́ Kí Àlàáfíà sì Jọba
  • A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÍ A ṢE LÈ YANJÚ ÀÌGBỌ́RA-ẸNI-YÉ
  • BÍ ÀWỌN ALÀGBÀ ṢE Ń FI ÌWÉ MÍMỌ́ TỌ́NI SỌ́NÀ
  • ÀWỌN TÓ Ń RÌN SÉGESÈGE
  • BÍ A ṢE LÈ YANJÚ ÀWỌN ÌWÀ ÀÌTỌ́ KAN
  • BÁ A ṢE Ń BÓJÚ TÓ ÌWÀ ÀÌTỌ́ TÓ BURÚ JÁÌ
  • ÌFILỌ̀ ÌBÁWÍ
  • TÍ WỌ́N BÁ PINNU LÁTI YỌ ONÍWÀ ÀÌTỌ́ LẸ́GBẸ́
  • ÌFILỌ̀ ÌYỌLẸ́GBẸ́
  • ÌMÚRA-ẸNI-KÚRÒ-LẸ́GBẸ́
  • BÁ A ṢE Ń GBA ẸNI TÁ A YỌ LẸ́GBẸ́ PA DÀ
  • ÌFILỌ̀ ÌGBÀPADÀ
  • TÍ ỌMỌDÉ TÓ TI ṢÈRÌBỌMI BÁ HÙWÀ ÀÌTỌ́
  • TÍ AKÉDE TÍ KÒ TÍÌ ṢÈRÌBỌMI BÁ HÙWÀ ÀÌTỌ́
  • JÈHÓFÀ Ń BÙ KÚN ÀWỌN ÈÈYÀN RẸ̀ TÓ JẸ́ MÍMỌ́ TÍ WỌ́N SÌ WÀ NÍ ÀLÀÁFÍÀ
  • Máa Gba Ìbáwí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Bá A Ṣe Lè Ṣàánú Ẹni Tó Dẹ́ṣẹ̀, Ká sì Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Báwọn Alàgbà Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tí Wọ́n Mú Kúrò Nínú Ìjọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ẹyin Alagba, Ẹ Fi Ododo Ṣe Idajọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
od orí 14 ojú ìwé 141-156

ORÍ 14

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìjọ Wà ní Mímọ́ Kí Àlàáfíà sì Jọba

BÍ Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọdọọdún ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ń rọ́ wá sínú ìjọsìn mímọ́ Jèhófà. (Míkà 4:1, 2) Inú wa sì máa ń dùn láti kí wọn káàbọ̀ sínú “ìjọ Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:28) Wọ́n mọyì bá a ṣe jọ ń sin Jèhófà, bá a ṣe jẹ́ mímọ́, tá a sì jọ wà lálàáfíà nínú Párádísè tẹ̀mí. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà àti ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ló ń mú kí ìjọ wa wà ní mímọ́ kí àlàáfíà sì wà láàárín wa.​—Sm. 119:105; Sek. 4:6.

2 Bá a ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, à ń fi “ìwà tuntun” wọ ara wa láṣọ. (Kól. 3:10) A kì í jẹ́ kí aáwọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àti àìgbọ́ra-ẹni yé dá wàhálà sílẹ̀ láàárín wa. Torí pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan làwa náà fi ń wò ó, à ń borí àwọn ohun tó lè fa ìpínyà, èyí sì ń jẹ́ kí gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé máa ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan.​—Ìṣe 10:34, 35.

3 Síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ìṣòro tó lè paná àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ máa ń wáyé. Kí ló ń fà á? Ohun tó fà á lọ́pọ̀ ìgbà ni pé a ò fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. Bákan náà, aláìpé ni wá. Ó ṣe tán, ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa. (1 Jòh. 1:10) Ẹnì kan lè hùwà tó lè kó àbàwọ́n bá ìjọ tàbí kó dọ́gbọ́n mú àwọn ẹ̀kọ́ tàbí àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu wọnú ìjọ. Láìmọ̀, a lè sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tó máa bí ẹnì kan nínú, ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ tàbí ìwà tó hù sì lè múnú bí àwa náà. (Róòmù 3:23) Bí irú àwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀, báwo la ṣe lè yanjú ẹ̀?

4 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó mọ̀ pé irú àwọn nǹkan yìí lè ṣẹlẹ̀ láàárín wa. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wa ní ìmọ̀ràn tá a lè tẹ̀ lé táwọn ìṣòro bá wáyé. Àwọn alàgbà tí wọ́n ń fìfẹ́ bójú tó wa wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Tá a bá fi ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa látinú Ìwé Mímọ́ sílò, àárín àwa àtàwọn míì máa dán mọ́rán, àá sì rí ojú rere Jèhófà. Tí wọ́n bá bá wa wí torí ìwà àìtọ́ kan tá a hù, kí a mọ̀ pé Jèhófà ló ń fìfẹ́ bá wa wí.​—Òwe 3:11, 12; Héb. 12:6.

BÍ A ṢE LÈ YANJÚ ÀÌGBỌ́RA-ẸNI-YÉ

5 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, aáwọ̀ tàbí àwọn ìṣòro pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lè wáyé láàárín àwọn ará nínú ìjọ. Ó yẹ ká tètè máa fi ìfẹ́ yanjú irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀. (Éfé. 4:26; Fílí. 2:2-4; Kól. 3:12-14) Wàá rí i pé ẹ lè yanjú àwọn aáwọ̀ tó máa ń wáyé láàárín ìwọ àti ẹlòmíì nínú ìjọ tẹ́ ẹ bá fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín, torí ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pét. 4:8) Bíbélì sọ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jém. 3:2) Tá a bá ń fi Òfin Oníwúrà yẹn sílò, èyí tó sọ pé, gbogbo ohun tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí wa ni ká máa ṣe sí wọn, àá lè máa dárí àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ji ara wa, àá sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tán síbẹ̀.​—Mát. 6:14, 15; 7:12.

6 Tó o bá kíyè sí pé ọ̀rọ̀ kan tó o sọ tàbí ohun tó o ṣe múnú bí ẹnì kan, á dáa kó o pe onítọ̀hún, kẹ́ ẹ sì wá bẹ́ ẹ ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà. Máa fi sọ́kàn pé ọ̀rọ̀ yìí kan àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà. Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Tí o bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ. Kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ, lẹ́yìn náà, kí o pa dà wá fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” (Mát. 5:23, 24) Ó lè jẹ́ pé ṣe lẹ ṣi ara yín lóye. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ wá bẹ́ẹ̀ ṣe jọ máa sọ ọ̀rọ̀ náà. Tí gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ bá ń bá ara wa sọ̀rọ̀ fàlàlà, ó máa ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti dènà èdèkòyédè, àá sì lè yanjú ìṣòro tó bá wáyé torí àìpé ẹ̀dá.

BÍ ÀWỌN ALÀGBÀ ṢE Ń FI ÌWÉ MÍMỌ́ TỌ́NI SỌ́NÀ

7 Nígbà míì, àwọn alábòójútó máa ń rí i pé ó yẹ káwọn fún ẹnì kan nímọ̀ràn láti tún ìrònú rẹ̀ ṣe. Èyí kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni ní Gálátíà pé: “Ẹ̀yin ará, tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kó tó mọ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ kúnjú ìwọ̀n nípa tẹ̀mí sapá láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tọ́ ẹni náà sọ́nà.”​—Gál. 6:1.

8 Bí àwọn alàgbà ṣe ń bójú tó agbo, wọ́n ń dáàbò bo àwọn ará ìjọ kí ohunkóhun má bàa ba àárín wọn àti Jèhófà jẹ́, kí wàhálà má sì ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ. Àwọn alàgbà máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bójú tó ìjọ bá ìlérí tí Jèhófà ṣe nípasẹ̀ Àìsáyà mu, pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa dà bí ibi tó ṣeé fara pa mọ́ sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù, ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí omi tó ń ṣàn ní ilẹ̀ tí kò lómi, bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ tó gbẹ táútáú.”​—Àìsá. 32:2.

ÀWỌN TÓ Ń RÌN SÉGESÈGE

9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa àwọn kan tó lè kó ìwà tàbí àṣà búburú ran àwọn ará nínu ìjọ. Ó sọ pé: “À ń fún yín ní ìtọ́ni . . . pé kí ẹ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ gbogbo arákùnrin tó ń rìn ségesège, tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣà tí ẹ gbà lọ́dọ̀ wa.” Ó ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí síwájú sí i pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí a sọ nínú lẹ́tà yìí, ẹ sàmì sí ẹni náà, ẹ má sì bá a kẹ́gbẹ́ mọ́, kí ojú lè tì í. Síbẹ̀, ẹ má kà á sí ọ̀tá, àmọ́ ẹ máa gbà á níyànjú bí arákùnrin.”​—2 Tẹs. 3:6, 14, 15.

10 Ẹnì kan lè wà nínú ìjọ tí kò dá ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára táá lè torí ẹ̀ yọ ọ́ lẹ́gbẹ́, àmọ́ tó jẹ́ pé ó ń hùwà tó fi hàn pé kò ka àwọn ìlànà Ọlọ́run sí rárá. Lára irú ìwà bẹ́ẹ̀ ni kéèyàn ya ọ̀lẹ paraku, kéèyàn ya ọ̀bùn tàbí kó máa ṣe àríwísí. Ó lè máa ‘tojú bọ ohun tí kò kàn án.’ (2 Tẹs. 3:11) Ó sì lè jẹ́ ẹni tó máa ń dọ́gbọ́n gba tọwọ́ àwọn èèyàn tàbí tó máa ń lọ́wọ́ nínú àwọn eré ìnàjú tó hàn kedere pé kò bá ìlànà Bíbélì mu. Irú àwọn ìwà àìnítìjú yìí burú débi pé wọ́n lè ba ìjọ lórúkọ jẹ́, wọ́n sì lè kó èèràn ran àwọn ará míì.

11 Àwọn alàgbà á kọ́kọ́ gbìyànjú láti ran ẹni tó ń hu ìwà àìtọ́ yìí lọ́wọ́, wọ́n á lo Bíbélì láti tọ́ ọ sọ́nà. Àmọ́, tí ẹni náà bá ṣì ń bá ìwà àìtọ́ yìí nìṣó lẹ́yìn tí wọ́n ti tọ́ ọ sọ́nà lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn alàgbà lè pinnu pé á dáa káwọn sọ àsọyé kan láti kìlọ̀ fún ìjọ. Àwọn alàgbà máa lo òye láti mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ náà burú tó bẹ́ẹ̀, tó sì lè dá wàhálà sílẹ̀ débi táá fi yẹ kí wọ́n sọ àsọyé láti kìlọ̀ fún ìjọ nípa rẹ̀. Ẹni tó máa sọ àsọyé náà á sọ àwọn ìlànà tó kan ìwà náà, àmọ́ kò ní dárúkọ ẹni tó ń hùwà àìtọ́ náà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tó bá mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ tí àsọyé náà dá lé lórí á kíyè sára, wọn ò sì ní máa ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ń bá wí, àmọ́ wọ́n á ṣì jọ máa lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, wọ́n á sì “máa gbà á níyànjú bí arákùnrin.”

12 A retí pé bí àwọn ará ṣe yẹra fún oníwà àìtọ́ náà máa jẹ́ kó rí i pé ìwà àìtọ́ tí òun hù ló mú kí wọ́n yẹra fún òun, èyí á sì mú kó ṣàtúnṣe tó yẹ. Tó bá ṣe kedere pé ẹni náà ti jáwọ́ nínú ìwà àìtọ́ tó ń hù, kò sídìí tí àwọn ará á fi máa fojú ẹni tá a sàmì sí wò ó mọ́.

BÍ A ṢE LÈ YANJÚ ÀWỌN ÌWÀ ÀÌTỌ́ KAN

13 Tá a bá tiẹ̀ gbójú fo ohun tẹ́nì kan ṣe sí wa tá a sì dárí jì í, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé inú wa dùn sí ìwà àìtọ́ náà tàbí pé a fọwọ́ sí i. Àìpé tá a jogún kọ́ ló ń fa gbogbo ìwà àìtọ́ o; kò sì ní bọ́gbọ́n mú ká máa gbójú fo àwọn ìwà àìtọ́ tó kọjá ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. (Léf. 19:17; Sm. 141:5) Òfin Mósè gbà pé ẹ̀ṣẹ̀ burú jura wọn lọ, bó sì ṣe rí nínú ètò ìjọ Kristẹni náà nìyẹn.​—1 Jòh. 5:16, 17.

14 Jésù sọ ohun pàtó tó yẹ ká ṣe láti yanjú ìṣòro tó bá wáyé láàárín àwa àtàwọn ará wa. Kíyè sí ohun tó ní ká ṣe, ó ní: “Tí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, [1] lọ sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un láàárín ìwọ àti òun nìkan. Tó bá fetí sí ọ, o ti jèrè arákùnrin rẹ. Àmọ́ tí kò bá fetí sí ọ, [2] mú ẹnì kan tàbí méjì dání, kó lè jẹ́ pé nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta, a ó fìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀. Tí kò bá fetí sí wọn, [3] sọ fún ìjọ. Tí kò bá fetí sí ìjọ pàápàá, bí èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti agbowó orí ni kó rí sí ọ gẹ́lẹ́.”​—Mát. 18:15-17.

15 Tá a bá wo àkàwé tí Jésù sọ lẹ́yìn ìtọ́ni yìí, ìyẹn àkàwé tó wà nínú Mátíù 18:23-35, ó jọ pé ara ohun tó lè mú káwọn Kristẹni ṣẹ ara wọn bó ṣe wà nínú Mátíù 18:15-17 ni ọ̀rọ̀ owó tàbí ti ohun ìní míì, bóyá ẹnì kan kọ̀ láti san owó tó yá pa dà tàbí pé kí ẹnì kan lu ẹlòmíì ní jìbìtì. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe lẹnì kan sọ ọ̀rọ̀ ẹlòmíì láìdáa tó sì tipa bẹ́ẹ̀ bà á lórúkọ jẹ́.

16 Tí ẹ̀rí bá wà pé ẹnì kan nínú ìjọ ti hu irú ìwà àìtọ́ bẹ́ẹ̀ sí ọ, má ṣe yára sọ fún àwọn alàgbà pé kí wọ́n bá yín dá sí i. Bí Jésù ṣe sọ, kọ́kọ́ lọ bá ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ sọ̀rọ̀. Ẹ gbìyànjú láti yanjú ọ̀rọ̀ náà láàárín ara yín láìpe ẹlòmíì sí i. Rántí pé Jésù kò sọ pé ‘ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré ni kó o lọ sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un.’ Torí náà, tí ẹni yẹn kò bá gbà pé òun jẹ̀bi, tí kò sì tọrọ àforíjì, ohun tó máa bọ́gbọ́n mu ni pé kó o pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà míì. Tẹ́ ẹ bá lè yanjú ọ̀rọ̀ náà lọ́nà yìí, inú ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ máa dùn pé o ò jẹ́ kí ẹlòmíì gbọ́ nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti pé orúkọ òun ò bà jẹ́ nínú ìjọ. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o “ti jèrè arákùnrin rẹ” nìyẹn.

17 Tí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà bá gbà pé òun ṣe ohun tí kò dáa, tó tọrọ àforíjì, tó sì ṣe ohun tó mú kí ọ̀rọ̀ yanjú, kò sídìí láti fẹ ọ̀rọ̀ náà lójú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣe burú, kò ju ohun tí èèyàn méjì lè yanjú láàárín ara wọn lọ.

18 Tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti jèrè arákùnrin rẹ pa dà lẹ́yìn tó o ti sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un “láàárín ìwọ àti òun nìkan,” o wá lè ṣe ohun tí Jésù tún sọ, pé kó o “mú ẹnì kan tàbí méjì dání,” kó o sì bá arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Àwọn tó máa fẹ́ kó o jèrè arákùnrin rẹ pa dà ni kó o mú dání o. Á dáa kí wọ́n jẹ́ ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú ẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò bá sí ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú ẹ̀, o lè ní kí arákùnrin kan tàbí méjì tẹ̀ lé ẹ, kí wọ́n lè mọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n lè ti ní ìrírí nínú irú ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ fẹ́ yanjú náà, tí wọ́n á sì lè mọ̀ bóyá ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn burú lóòótọ́. Tó bá jẹ́ pé àwọn alàgbà ló bá ẹ lọ, kì í ṣe ìjọ ni wọ́n ṣojú fún o, torí pé kì í ṣe ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló dìídì yàn wọ́n láti dá sí ọ̀rọ̀ náà.

19 Tẹ́ ò bá rí ọ̀rọ̀ náà yanjú lẹ́yìn tẹ́ ẹ ti wá ọ̀nà láti yanjú rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, ìyẹn ni pé tó o ti bá a sọ̀rọ̀ níwọ nìkan, lẹ́yìn náà, tó o tún mú ẹnì kan tàbí méjì dání lọ, tó sì wá ṣòro fún ẹ láti gbójú fo ọ̀rọ̀ náà, á dáa kó o fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn alàgbà nínú ìjọ létí. Má gbàgbé pé ohun táwọn alàgbà ń wá ni pé kí ìjọ wà ní mímọ́ kí àlàáfíà sì jọba. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ fún àwọn alàgbà, fi ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ fún wọn, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Má ṣe jẹ́ kí ìwà ẹlòmíì mú ẹ kọsẹ̀ láé tàbí kó ba ayọ̀ tó o ní nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà jẹ́.​—Sm. 119:165.

20 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run máa wádìí ọ̀rọ̀ náà, tó bá sì ṣe kedere pé lóòótọ́ ni arákùnrin náà ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú sí ọ, síbẹ̀ tí kò ronú pìwà dà, tí kò sì ṣe tán láti ṣe àtúnṣe tó yẹ, ìgbìmọ̀ tí àwọn alàgbà yàn láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà lè rí i pé ó pọn dandan kí wọ́n yọ oníwà àìtọ́ náà kúrò nínú ìjọ. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á dáàbò bo agbo, wọ́n á sì jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́.​—Mát. 18:17.

BÁ A ṢE Ń BÓJÚ TÓ ÌWÀ ÀÌTỌ́ TÓ BURÚ JÁÌ

21 Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó burú jáì, tó kọjá èyí tí ẹni téèyàn ṣẹ̀ lè forí rẹ̀ jini, kí ọ̀rọ̀ sì tán síbẹ̀. Lára irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ìṣekúṣe, àgbèrè, kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lò pọ̀, ọ̀rọ̀ òdì, ìpẹ̀yìndà, ìbọ̀rìṣà àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì tó lágbára. (1 Kọ́r. 6:9, 10; Gál. 5:19-21) Torí pé irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí lè ba ìjẹ́mímọ́ ìjọ jẹ́, wọ́n sì lè kó bá àwọn ará ìjọ, ṣe ló yẹ ká sọ fáwọn alàgbà nípa rẹ̀, kí wọ́n lè bójú tó o. (1 Kọ́r. 5:6; Jém. 5:14, 15) Ẹnì kan lè lọ bá àwọn alàgbà láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tàbí kó lọ sọ ohun tó mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn míì. (Léf. 5:1; Jém. 5:16) Ọ̀nà yòówù káwọn alàgbà fi kọ́kọ́ mọ̀ nípa ìwà àìtọ́ tó burú jáì tí akéde kan tó ti ṣèrìbọmi hù, wọ́n ní láti yan àwọn alàgbà méjì láti kọ́kọ́ wádìí ọ̀rọ̀ náà. Bí wọ́n bá sì ti wádìí ọ̀rọ̀ náà, tó sì ṣe kedere sí wọn pé lóòótọ́ lẹnì kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà á yan alàgbà mẹ́ta, ó kéré tán, láti jẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ tó máa bójú tó ọ̀rọ̀ náà.

22 Àwọn alàgbà máa ń wà lójúfò bí wọ́n ṣe ń bójú tó agbo Ọlọ́run kí ohunkóhun má bàa bá àjọṣe táwọn ará ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Wọ́n tún máa ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá ẹni tó ṣẹ̀ wí lọ́nà tí ọ̀rọ̀ náà á fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn, kó lè tún àjọṣe òun àti Jèhófà ṣe. (Júùdù 21-23) Èyí bà ìtọ́ni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì mu pé: “Mo pàṣẹ tó rinlẹ̀ yìí fún ọ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù, ẹni tó máa ṣèdájọ́ àwọn alààyè àti òkú, . . . Fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, máa gbani níyànjú, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ sùúrù àti ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó dáa.” (2 Tím. 4:1, 2) Èyí lè gba ọ̀pọ̀ àkókò, àmọ́ ara iṣẹ́ ńlá táwọn alàgbà ní láti ṣe ni. Àwọn ará ìjọ mọyì iṣẹ́ wọn, wọ́n sì máa ń fún wọn ní “ọlá ìlọ́po méjì.”​—1 Tím. 5:17.

23 Ní gbogbo ìgbà tí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ bá ti fẹ̀rí ẹ̀ múlẹ̀ pé oníwà àìtọ́ kan jẹ̀bi, ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣe ni pé kí wọ́n ran oníwà àìtọ́ náà lọ́wọ́ láti tún àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣe. Tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́, kí wọ́n fún un ní ìbáwí ìdákọ́ńkọ́ tàbí níṣojú àwọn tó wá jẹ́rìí sọ́rọ̀ náà nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ náà. Ìbáwí tí wọ́n fún un yìí á mú kó ṣàtúnṣe, á sì jẹ́ káwọn tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà kọ́gbọ́n. (2 Sám. 12:13; 1 Tím. 5:20) Ní gbogbo ìgbà tí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ bá fún oníwà àìtọ́ kan ní ìbáwí, wọ́n á fún un láwọn ìkálọ́wọ́kò kan, ìyẹn ni pé àwọn àǹfààní kan wà tó ní tẹ́lẹ̀ tí wọ́n máa gbà lọ́wọ́ rẹ̀. Èyí á mú kí oníwà àìtọ́ náà lè ṣe ‘ọ̀nà tó tọ́ fún ẹsẹ̀ rẹ̀.’ (Héb. 12:13) Bí àkókò ṣe ń lọ, wọ́n á máa mú àwọn ìkálọ́wọ́kò náà kúrò tó bá hàn kedere pé ẹni náà ti ṣàtúnṣe tó yẹ, kí àárín òun àti Jèhófà lè sunwọ̀n sí i.

ÌFILỌ̀ ÌBÁWÍ

24 Tí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ bá rí i pé oníwà àìtọ́ kan ti ronú pìwà dà, síbẹ̀ tó ṣeé ṣe káwọn ará ìjọ tàbí àwọn ará àdúgbò mọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, tàbí tí wọ́n bá rí i pé ó pọn dandan kí wọ́n kìlọ̀ fún ìjọ láti ṣọ́ra fún oníwà àìtọ́ náà, wọ́n á ṣèfilọ̀ ṣókí ní Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Bí ìfilọ̀ náà ṣe máa kà rèé: “A ti fún Arákùnrin/Arábìnrin [Orúkọ ẹni náà] ní ìbáwí.”

TÍ WỌ́N BÁ PINNU LÁTI YỌ ONÍWÀ ÀÌTỌ́ LẸ́GBẸ́

25 Láwọn ìgbà míì, ọkàn oníwà àìtọ́ náà lè ti yigbì débi pé gbogbo bí wọ́n ṣe ràn án lọ́wọ́ tó, pàbó ló já sí. Nígbà ìgbẹ́jọ́ náà, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ sí ẹ̀rí tó pọ̀ tó láti fi hàn pé ó ṣe “àwọn iṣẹ́ tó fi ìrònúpìwàdà hàn.” (Ìṣe 26:20) Kí wá ni ṣíṣe? Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó kàn ni pé kí wọ́n yọ oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà náà lẹ́gbẹ́, kò sì ní láǹfààní láti bá àwọn èèyàn Jèhófà kẹ́gbẹ́. Èyí ò ní jẹ́ kí ìwà àìtọ́ rẹ̀ ran ìjọ, á sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìjọ wà ní mímọ́, á dáàbò bo àwọn ará ìjọ, orúkọ ìjọ ò sì ní bà jẹ́. (Diu. 21:20, 21; 22:23, 24) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbọ́ nípa ìwà ìtìjú tí ẹnì kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì hù, ó gba àwọn alàgbà ìjọ náà nímọ̀ràn pé kí wọ́n “fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé Sátánì lọ́wọ́ . . . kí ipò tẹ̀mí ìjọ lè wà láìyingin.” (1 Kọ́r. 5:5, 11-13) Pọ́ọ̀lù tún mẹ́nu kan àwọn míì tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní torí pé wọ́n ta ko òtítọ́.​—1 Tím. 1:20.

26 Tí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ bá pinnu pé ká yọ oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́, wọ́n gbọ́dọ̀ sọ ìpinnu náà fún un, kí wọ́n sì fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ìdí tí a fi yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Nígbà tí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ bá ń sọ ìpinnu wọn fún oníwà àìtọ́ náà, kí wọ́n sọ fún un pé, tó bá rò pé àṣìṣe wà nínú ìdájọ́ tí ìgbìmọ̀ náà ṣe, tó sì fẹ́ láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, kó kọ lẹ́tà, kó sì kọ ìdí tí ìdájọ́ náà kò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn lọ́nà tó ṣe kedere sínú lẹ́tà náà. Wọ́n á sọ fún un pé ó lè kọ lẹ́tà náà láàárín ọjọ́ méje tó tẹ̀ lé ìgbà tí wọ́n sọ ìpinnu wọn fún un. Tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá gba irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n fi tó alábòójútó àyíká létí kó lè yan àwọn alàgbà míì tó kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ ìgbìmọ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó máa tún ẹjọ́ náà gbọ́. Ìgbìmọ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yìí máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti gbọ́ ẹjọ́ náà láàárín ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tí wọ́n gba lẹ́tà náà. Tí ẹni náà bá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, a ò ní tíì ṣe ìfilọ̀ ìyọlẹ́gbẹ́ náà. Àmọ́ títí dìgbà tí wọ́n fi máa yanjú ẹjọ́ náà, ẹni tá a fẹ̀sùn kàn náà kò ní dáhùn nípàdé, kò ní máa gbàdúrà nípàdé, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ní àwọn àkànṣe àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì, bíi gbígbé makirofóònù, bíbójú tó ìwé, aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

27 Bá a ṣe gba ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn láyè láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, ṣe la fi àánú hàn sí i ká lè tún ẹjọ́ rẹ̀ gbọ́. Nítorí náà, tí oníwà àìtọ́ náà bá mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti wá síbi ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà, tí ìgbìmọ̀ náà sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti kàn sí i, àmọ́ tí kò yọjú, kí wọ́n ṣe ìfilọ̀ ìyọlẹ́gbẹ́ náà.

28 Tí oníwà àìtọ́ náà kò bá fẹ́ pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, kí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó ronú pìwàdà, kí wọ́n sì tún sọ àwọn ohun tó máa ṣe tó bá ti fẹ́ kí wọ́n gba òun pa dà. Àlàyé yìí máa ràn án lọ́wọ́, á sì jẹ́ kó mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun àti pé wọ́n fẹ́ kí òun ṣe àtúnṣe tó yẹ kí òun lè pa dà sínú ètò Jèhófà.​—2 Kọ́r. 2:6, 7.

ÌFILỌ̀ ÌYỌLẸ́GBẸ́

29 Bí a bá ní láti yọ oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́, a máa ṣe ìfilọ̀ ṣókí pé: “[Orúkọ ẹni náà] kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́.” Ìfilọ̀ yìí á jẹ́ káwọn ará ìjọ tó jẹ́ olóòótọ́ mọ̀ pé kò yẹ káwọn máa bá onítọ̀hún ṣe wọléwọ̀de mọ́.​—1 Kọ́r. 5:11.

ÌMÚRA-ẸNI-KÚRÒ-LẸ́GBẸ́

30 Ẹni tó múra rẹ̀ kúrò lẹ́gbẹ́ ni ẹni tó jẹ́ akéde tó ti ṣèrìbọmi àmọ́ tó mọ̀ọ́mọ̀ ṣíwọ́ láti máa jẹ́ Kristẹni, tó sọ pé òun kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ àti pé òun ò fẹ́ kí wọ́n ka òun sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn ìgbésẹ̀ tó gbé ló fi hàn pé kì í ṣe ara ìjọ mọ́, bóyá ó dara pọ̀ mọ́ ètò tó ń gbé ohun tó ta ko ẹ̀kọ́ Bíbélì lárugẹ, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run máa dá lẹ́jọ́.​—Àìsá. 2:4; Ìfi. 19:17-21.

31 Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó sọ pé àwọn kì í ṣe Kristẹni mọ́ nígbà ayé rẹ̀, ó ní: “Wọ́n kúrò lọ́dọ̀ wa, àmọ́ wọn kì í ṣe ara wa; torí ká ní wọ́n jẹ́ ara wa ni, wọn ò ní fi wá sílẹ̀.”​—1 Jòh. 2:19.

32 Tí ẹnì kan bá mú ara rẹ̀ kúrò lẹ́gbẹ́, ojú tí Jèhófà fi ń wò ó yàtọ̀ pátápátá sí ti Kristẹni tó di aláìṣiṣẹ́mọ́, ìyẹn ẹni tí kì í wàásù mọ́. Kristẹni kan lè di aláìṣiṣẹ́mọ́ bóyá torí pé kì í kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ déédéé. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn ìṣòro kan tàbí inúnibíni ló jẹ́ kí ìtara tó ní fún ìjọsìn Jèhófà dín kù. Àwọn alàgbà àtàwọn ará nínú ìjọ á ṣì máa fún Kristẹni tó di aláìṣiṣẹ́mọ́ níṣìírí látinú Ìwé Mímọ́.​—Róòmù 15:1; 1 Tẹs. 5:14; Héb. 12:12.

33 Àmọ́ tí Kristẹni kan bá mọ̀ọ́mọ̀ mú ara rẹ̀ kúrò lẹ́gbẹ́, a máa ṣe ìfilọ̀ ṣókí fún ìjọ pé: “[Orúkọ ẹni náà] kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́.” Ọwọ́ tá a fi ń mú ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà la fi ń mú ẹni tó mú ara rẹ̀ kúrò lẹ́gbẹ́.

BÁ A ṢE Ń GBA ẸNI TÁ A YỌ LẸ́GBẸ́ PA DÀ

34 A lè gba ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tó mú ara rẹ̀ kúrò lẹ́gbẹ́ pa dà tó bá fi ẹ̀rí hàn kedere pé òun ti rònú pìwàdà, tó sì fi hàn láàárín àkókò tó pọ̀ tó pé òun kò tún hùwà àìtọ́ mọ́. Ó tún fi hàn pé ó wu òun gan-an láti pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Àwọn alàgbà máa ń fara balẹ̀ kí àkókò tó pọ̀ tó kọjá. Torí ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, wọ́n lè ní láti dúró fún ọ̀pọ̀ oṣù, ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Nígbà táwọn alàgbà bá gba lẹ́tà tí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ fi ń bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n gba òun pa dà, ìgbìmọ̀ ìgbanipadà máa bá ẹni náà sọ̀rọ̀. Ìgbìmọ̀ náà máa ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ẹni náà ti ṣe “àwọn iṣẹ́ tó fi ìrònúpìwàdà hàn,” wọ́n á wá pinnu bóyá kí wọ́n gbà á pa dà lásìkò yẹn tàbí kí wọ́n túbọ̀ ní sùúrù.​—Ìṣe 26:20.

35 Tó bá jẹ́ pé ìjọ míì ni wọ́n ti yọ ẹni tó kọ lẹ́tà pé kí wọ́n gba òun pa dà yìí lẹ́gbẹ́, ìjọ tó wà báyìí máa yan ìgbìmọ̀ ìgbanipadà tó máa rí onítọ̀hún láti gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹ̀ wò. Tí ìgbìmọ̀ ìgbanipadà náà bá ronú pé a lè gbà á pa dà, wọ́n á sọ àbá wọn fún ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ tí wọ́n ti yọ ẹni náà lẹ́gbẹ́. Ìgbìmọ̀ méjèèjì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti rí i pé wọ́n gbé gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa, kí ìpinnu wọn lè bá ìdájọ́ òdodo mu. Àmọ́ ṣá o, ìgbìmọ̀ ìgbanipadà ní ìjọ tí wọ́n ti yọ ẹni náà lẹ́gbẹ́ ló máa pinnu láti gbà á pa dà.

ÌFILỌ̀ ÌGBÀPADÀ

36 Tó bá dá ìgbìmọ̀ ìgbanipadà lójú pé ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tó mú ara rẹ̀ kúrò lẹ́gbẹ́ náà ti ronú pìwà dà lóòótọ́, tó sì yẹ lẹ́ni tá a lè gbà pa dà, wọ́n á ṣèfilọ̀ nínú ìjọ tí wọ́n ti bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Tí ẹni náà bá sì ti wà ní ìjọ míì, kí wọ́n ṣe ìfilọ̀ náà níbẹ̀ pẹ̀lú. Bí ìfilọ̀ náà ṣe máa lọ rèé: “A ti gba [orúkọ ẹni náà] pa dà bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

TÍ ỌMỌDÉ TÓ TI ṢÈRÌBỌMI BÁ HÙWÀ ÀÌTỌ́

37 Tí ọmọdé tó ti ṣèrìbọmi bá hùwà àìtọ́ tó burú jáì, ó yẹ kí wọ́n sọ fún àwọn alàgbà. Tí àwọn alàgbà bá ń bójú tó ẹjọ́ ìwà àìtọ́ ọmọ náà, ohun tó máa dáa jù ni pé káwọn òbí ọmọ náà tí wọ́n ti ṣèrìbọmi wà níbẹ̀. Á dáa kí àwọn òbí náà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, kí wọ́n má ṣe gbè sẹ́yìn ọmọ náà, kó lè gba ìbáwí tó yẹ. Bíi ti àgbàlagbà tó hùwà àìtọ́, kí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ fún ọmọ náà ní ìbáwí tó yẹ, táá mú kó tún àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣe. Ṣùgbọ́n bí ọmọdé náà kò bá ronú pìwà dà, kí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.

TÍ AKÉDE TÍ KÒ TÍÌ ṢÈRÌBỌMI BÁ HÙWÀ ÀÌTỌ́

38 Tí akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi bá hùwà àìtọ́ tó burú jáì ńkọ́? Torí pé kò tíì ṣèrìbọmi, a ò lè yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ṣe ni kò fi bẹ́ẹ̀ lóye ìlànà Bíbélì. Torí náà, kí àwọn alàgbà fìfẹ́ gbà á nímọ̀ràn kó lè “ṣe ọ̀nà tó tọ́ fún ẹsẹ̀” rẹ̀.​—Héb. 12:13.

39 Tí akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi náà kò bá ronú pìwà dà lẹ́yìn táwọn alàgbà méjì ti bá a sọ̀rọ̀ kó lè ṣàtúnṣe ìwà rẹ̀, nígbà náà, á dáa kí wọ́n ṣèfilọ̀ fún ìjọ. Bí ìfilọ̀ ṣókí náà ṣe máa lọ rèé: “[Orúkọ ẹni náà] kì í ṣe akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi mọ́.” Lẹ́yìn ìfilọ̀ yìí, ojú èèyàn ayé ni ìjọ á fi máa wò ó. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò yọ oníwà àìtọ́ náà lẹ́gbẹ́, síbẹ̀ ó yẹ káwọn ará ṣọ́ra kí wọ́n má ṣe máa bá a ṣe wọléwọ̀de. (1 Kọ́r. 15:33) A ò ní gba ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́.

40 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ẹni tí kì í ṣe akéde mọ́ náà lè sọ pé òun fẹ́ pa dà di akéde. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà méjì máa rí i, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ ló ti ṣàtúnṣe. Tí wọ́n bá rí i pé ó lè pa dà di akéde, a máa ṣèfilọ̀ ṣókí pé: “[Orúkọ ẹni náà] ti pa dà di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.”

JÈHÓFÀ Ń BÙ KÚN ÀWỌN ÈÈYÀN RẸ̀ TÓ JẸ́ MÍMỌ́ TÍ WỌ́N SÌ WÀ NÍ ÀLÀÁFÍÀ

41 Ó dájú pé inú gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ Ọlọ́run lónìí ló ń dùn nítorí ogún tẹ̀mí tó ṣeyebíye tí Jèhófà fún àwa èèyàn rẹ̀. Pápá tẹ̀mí wa ń méso jáde lọ́pọ̀ yanturu, bẹ́ẹ̀ sì ni Jèhófà ń fún wa ní omi òtítọ́ tó ń tù wá lára. Bí Jèhófà ṣe ṣètò àwa èèyàn rẹ̀ lábẹ́ ìdarí Kristi ń dáàbò bò wá. (Sm. 23; Àìsá. 32:1, 2) Ọkàn wa balẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó kún fún wàhálà yìí torí pé a wà nínu Párádísè tẹ̀mí.

Bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kí ìjọ máa wà ní mímọ́, kí àlàáfíà sì jọba, àá máa tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Ìjọba náà níbi gbogbo

42 Bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kí ìjọ máa wà ní mímọ́, kí àlàáfíà sì jọba, àá máa jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Ìjọba náà máa tàn. (Mát. 5:16; Jém. 3:18) Lọ́lá ìbùkún Jèhófà, ayọ̀ wa á máa pọ̀ sí i bá a ṣe ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà, kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ wa láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́