Àfikún
Ọ̀rọ̀ Ìyànjú fún Àwọn Òbí:
Ẹ̀yin òbí, ó dájú pé ó wù yín láti ran àwọn ọmọ yín ọ̀wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún un. Báwo lẹ ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tóótun láti ṣèrìbọmi? Ìgbà wo gan-an ni wọ́n á tóótun láti ṣe ìpinnu pàtàkì yìí?
Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.” (Mát. 28:19) Bí àṣẹ yìí ṣe sọ, a rí i pé kí ẹnì kan tó lè ṣèrìbọmi, ó yẹ kó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ìyẹn ni pé kó lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, kó gbà á gbọ́, kó sì máa fi í sílò. Ó dájú pé ọmọdé pàápàá lè ṣe àwọn nǹkan yìí.
Ẹ̀yin òbí, ẹ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì sapá láti jẹ́ kí ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọnú ọkàn wọn. (Diu. 6:6-9) Lára ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà ṣe èyí ni pé kẹ́ ẹ fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì, kẹ́ ẹ kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè máa ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì àti bí wọ́n ṣe lè máa fi sílò nígbèésí ayé wọn. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bí àwọn fúnra wọn á ṣe máa ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (1 Pét. 3:15) Bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ ẹ̀yin òbí, táwọn fúnra wọn náà ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tẹ́ ẹ jọ ń ṣe ìjọsìn ìdílé, tí wọ́n ń wá sípàdé déédéé, tí wọ́n sì ń bá àwọn tó ń ṣe dáadáa nínú ìjọ ṣọ̀rẹ́, wọ́n á túbọ̀ lóye òtítọ́, wọ́n á sì rí ìṣírí gbà. Èyí á mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi, kódà wọ́n á tún tẹ̀ síwájú gan-an lẹ́yìn náà. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Òwe 20:11 sọ pé: “Èèyàn lè fi ìṣe ọmọdé pàápàá dá a mọ̀, bóyá ìwà rẹ̀ mọ́, tí ó sì tọ́.” Àwọn nǹkan wo ló máa fi hàn pé ọmọ kan ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi lóòótọ́ àti pé ó ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi?
Ọmọ tó ń tẹ̀ síwájú tó sì ń fẹ́ láti ṣe ìrìbọmi gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí òbí rẹ̀ lẹ́nu. (Ìṣe 5:29; Kól. 3:20) Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé: ‘Ó ń gbọ́ràn sí àwọn òbí rẹ̀ lẹ́nu.’ (Lúùkù 2:51) Lóòótọ́, a ò retí pé kọ́mọ wa jẹ́ ẹni pípé bíi ti Jésù. Àmọ́ ọmọ tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi á máa sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, àwọn èèyàn á sì mọ̀ ọ́n sí ọmọ tó máa ń gbọ́ràn sáwọn òbí rẹ̀ lẹ́nu.
Ọmọ náà tún gbọ́dọ̀ máa hùwà tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì. (Lúùkù 2:46) Ṣé inú ọmọ rẹ máa ń dùn tó o bá sọ pé ìpàdé yá, ṣó máa ń dáhùn nípàdé? (Sm. 122:1) Ṣó fẹ́ràn láti máa ka Bíbélì déédéé kó sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́?—Mát. 4:4.
Ọmọ tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ láti fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò kìíní nígbèésí ayé rẹ̀. (Mát. 6:33) Ó mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ó máa ń lọ́wọ́ nínú oríṣiríṣi apá tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pín sí, kì í sì í tijú láti jẹ́ káwọn olùkọ́ rẹ̀ àtàwọn ọmọ iléèwé rẹ̀ mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. Ó máa ń múra iṣẹ́ tí wọ́n bá fún un ní Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ sílẹ̀ dáadáa.
Ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè máa hùwà tó yẹ Kristẹni, torí náà, kì í bá àwọn tí kì í fi ìlànà Ọlọ́run sílò kẹ́gbẹ́. (Òwe 13:20; 1 Kọ́r. 15:33) Èyí sì máa ń hàn nínú irú orin tó ń gbọ́, fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó ń wò, títí kan àwọn géèmù tó ń gbá àti bó ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì.
Ọ̀pọ̀ ọmọ ló ti gbé iṣẹ́ àtàtà àwọn òbí wọn yọ, wọ́n ti sọ òtítọ́ di tiwọn, wọ́n sì ti ṣèrìbọmi nígbà tí wọ́n ṣì jẹ́ ọ̀dọ́. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bù kún yín bẹ́ ẹ ṣe ń ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe ìpinnu pàtàkì yìí, tó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Ọ̀rọ̀ Ìyànjú fún Akéde Tí Kò Tíì Ṣèrìbọmi:
Àǹfààní ńlá ni kéèyàn jẹ́ akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. A gbóríyìn fún ẹ gan-an torí bó o ṣe tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Jèhófà. Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ò ń kọ́ ti mú kó o mọ Jèhófà, o sì ti wá ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí rẹ̀.—Jòh. 17:3; Héb. 11:6.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o ní ẹ̀sìn tó ò ń ṣe kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o ò ṣe ẹ̀sìn kankan. O sì lè ti máa ṣe àwọn nǹkan kan tí kò bá ìlànà Bíbélì mu tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, ìgbàgbọ́ tó o ní ti mú kó o ronú pìwà dà, ìyẹn ni pé o kábàámọ̀ àwọn nǹkan tí kò dáa tó o ti ṣe sẹ́yìn. O sì ti yí pa dà, ìyẹn ni pé o ti fi ọ̀nà ìgbésí ayé tí kò dára sílẹ̀, o sì pinnu pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni wàá máa ṣe.—Ìṣe 3:19.
Ó sì lè jẹ́ pé “láti kékeré jòjòló” lo ti mọ Ìwé Mímọ́, èyí sì ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ta kété sí àwọn ìwà àìtọ́ tí kò yẹ Kristẹni. (2 Tím. 3:15) O ti mọ ohun tó o lè ṣe káwọn ojúgbà rẹ má bàa sọ ẹ́ dà bí wọ́n ṣe dà àti bó o ṣe lè yẹra fún ohun tí Jèhófà kórìíra. Bó o ṣe ń gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ tó o sì ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì, ò ń fi hàn pé o nígbàgbọ́. Kódà, o ti mọ bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Kó o lè túbọ̀ máa sin Jèhófà, ìwọ fúnra rẹ ti wá pinnu báyìí láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.
Bóyá látìgbà ọmọdé jòjòló ni wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ ẹ ni o tàbí o ti dàgbà kó o tó mọ Jèhófà, ó ṣeé ṣe kó o ti máa ronú nípa nǹkan méjì tó ṣì kù tó o máa ṣe kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn ni ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Láti ṣe ìyàsímímọ́, wàá gbàdúrà sí Jèhófà, wàá sọ fún un pé o ti pinnu lọ́kàn rẹ pé òun nìkan ṣoṣo ni wàá máa sìn títí láé. (Mát. 16:24) Lẹ́yìn náà, wàá ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́. (Mát. 28:19, 20) Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tó o ṣe ló mú kó o di òjíṣẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run yàn. O ò rí i pé àǹfààní àgbàyanu nìyẹn jẹ́!
Bí ìwọ náà ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú Bíbélì, àwọn tó bá ṣe irú ìpinnu tó o ṣe yìí máa dojú kọ àwọn ìṣòro kan. Rántí pé kété tí Jésù ṣèrìbọmi ni ẹ̀mí “darí Jésù lọ sínú aginjù kí Èṣù lè dán an wò.” (Mát. 4:1) Lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi tó o sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, fi sọ́kàn pé àdánwò máa dé o. (Jòh. 15:20) Onírúurú ọ̀nà ni àdánwò náà máa gbà wá. Àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ lè ta kò ẹ́. (Mát. 10:36) Àwọn ọmọ iléèwé rẹ, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣọ̀rẹ́ tẹ́lẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́ máa rántí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Máàkù 10:29, 30 tó sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kò sí ẹni tó fi ilé tàbí àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, ìyá, bàbá, àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá sílẹ̀ nítorí mi àti nítorí ìhìn rere, tí kò ní gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) àwọn ilé, àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, àwọn ìyá, àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni ní báyìí àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀.” Torí náà, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà kó o sì máa fi àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ ṣèwà hù.
Tó o bá fẹ́ ṣèrìbọmi, sọ fún olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ rẹ. Wọ́n máa jíròrò àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí pẹ̀lú rẹ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá o kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìbéèrè náà dánra wò tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́.
Tó o bá ń múra àwọn ìbéèrè náà sílẹ̀, rí i pé o ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a ṣe àyọkà rẹ̀ síbẹ̀. O lè kọ àwọn ohun tó o bá fẹ́ rántí sínú ìwé yìí tàbí sínú ìwé míì. Tí àwọn alàgbà bá ń jíròrò àwọn ìbéèrè náà pẹ̀lú rẹ, o lè lo àwọn àkọsílẹ̀ náà, kó o sì ṣí ìwé yìí sílẹ̀. Bí èyíkéyìí nínú àwọn ìbéèrè náà kò bá yé ọ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ pé kí ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí alàgbà kan ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Nígbà táwọn alàgbà bá ń jíròrò pẹ̀lú rẹ, má ṣe rò pé dandan ni kí ìdáhùn rẹ gùn tàbí kí àlàyé rẹ pọ̀. Ohun tó dáa jù ni pé kó o dáhùn ṣókí lọ́rọ̀ ara rẹ, kó sì ṣe tààràtà. Tó o bá ń dáhùn ọ̀pọ̀ lára àwọn ìbéèrè náà, ó tún máa dáa kó o fi ẹsẹ Bíbélì kan tàbí méjì ti ìdáhùn rẹ lẹ́yìn.
Tí o ò bá tíì fi bẹ́ẹ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ lóye, àwọn alàgbà á bá ẹ wá ẹni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, kí ìwọ náà lè máa fúnra rẹ ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó fi hàn pé o lóye rẹ̀ dáadáa, kó o sì lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi nígbà tó bá yá.
[Àkíyèsí fún àwọn alàgbà ìjọ: Ìtọ́ni lórí bẹ́ ẹ ṣe máa bójú tó ìjíròrò pẹ̀lú ẹni tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi wà ní ojú ìwé 208 sí 212.]