ÌBÉÈRÈ TÁ A MÁA Ń BI ÀWỌN TÓ FẸ́ ṢÈRÌBỌMI
Ìjíròrò Tó Kẹ́yìn Pẹ̀lú Àwọn Tó Fẹ́ Ṣèrìbọmi
Ibi àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìrìbọmi ti máa ń wáyé. Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ bá fẹ́ parí àsọyé ìrìbọmi, á ní kí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi dìde dúró, kí wọ́n sì dáhùn àwọn ìbéèrè méjì yìí sókè ketekete:
1. Ṣé o ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ṣé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ṣé o sì gbà pé Jésù Kristi ni Jèhófà lò láti gbà wá là?
2. Ṣé o mọ̀ pé ìrìbọmi rẹ fi hàn pé o jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú ètò Ọlọ́run?
Táwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi bá dáhùn ketekete pé bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, ẹ̀rí nìyẹn pé wọ́n “kéde ní gbangba” pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà Jésù àti pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ pátápátá fún Jèhófà. (Róòmù 10:9, 10) Torí náà, á dáa kí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi gbàdúrà, kí wọ́n sì ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìbéèrè yìí ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n máa ṣèrìbọmi kí wọ́n lè dáhùn àwọn ìbéèrè náà látọkàn wá.
Ṣé o ti gbàdúrà sí Jèhófà láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún un, tó o sì ti ṣèlérí fún un pé òun nìkan lo máa sìn àti pé ìfẹ́ rẹ̀ lo máa kà sí pàtàkì jù ní ìgbésí ayé rẹ?
Ṣé ó dá ẹ lójú dáadáa pé wàá fẹ́ ṣèrìbọmi ní àpéjọ tó kàn yìí?
Irú aṣọ wo ló bójú mu fún ìrìbọmi? (1 Tím. 2:9, 10; Jòh. 15:19; Fílí. 1:10)
Ó yẹ kí “ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti àròjinlẹ̀” máa hàn nínú bá a ṣe ń múra, ká lè fi hàn pé à “ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn.” Torí náà, kò yẹ kẹ́ni tó fẹ́ ṣèrìbọmi wọ aṣọ ìwẹ̀ tó ń ṣí ara sílẹ̀ tàbí aṣọ tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí lára. Kí wọ́n wọ aṣọ tó bójú mu, tí kò dọ̀tí, táwọn èèyàn ò ní kọminú sí, tó sì máa ṣeé ṣèrìbọmi.
Báwo ló ṣe yẹ kí ẹnì kan ṣe lákòókò ìrìbọmi? (Lúùkù 3:21, 22)
Ìrìbọmi Jésù ni àwòkọ́ṣe táwa Kristẹni ń tẹ̀ lé lónìí. Ó mọ̀ pé ìgbésẹ̀ pàtàkì ni ìrìbọmi, ó sì hàn nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀. Torí náà, odò ìrìbọmi kì í ṣe ibi tó o ti lè máa ṣẹ̀fẹ̀, tó o ti lè máa ṣeré tàbí lúwẹ̀ẹ́, kò sì yẹ kó o hu àwọn ìwà míì tó lè mú kó dà bíi pé nǹkan yẹpẹrẹ kan là ń ṣe. Bákan náà, kò yẹ kó o máa ṣe bí ẹni pé o gboyè jáde. Òótọ́ ni pé nǹkan ayọ̀ ni ìrìbọmi jẹ́, àmọ́ kò yẹ ká ṣàṣejù.
Tó o bá ń lọ sípàdé déédéé, tó o sì ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ará ìjọ, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ ṣẹ?
Lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o ṣe ètò tó dáa fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o sì máa jáde òde ẹ̀rí déédéé?
ÌTỌ́NI TÍ ÀWỌN ALÀGBÀ GBỌ́DỌ̀ FI SỌ́KÀN
Tí akéde ti kò tíì ṣèrìbọmi bá sọ fún yín pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi, ẹ sọ fún un pé kó lọ fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò “Ìbéèrè Tá A Máa Ń Bi Àwọn Tó Fẹ́ Ṣèrìbọmi,” tó wà lójú ìwé 185 sí 207 nínú ìwé yìí. Ẹ ní kó lọ ka apá tá a pè ní “Ọ̀rọ̀ Ìyànjú fún Akéde Tí Kò Tíì Ṣèrìbọmi,” tó wà lójú ìwé 182, èyí tó ṣàlàyé nípa bó ṣe lè múra sílẹ̀ fún ohun tẹ́yin alàgbà máa bá a jíròrò. Nínú àlàyé náà, a sọ pé ó lè ṣàkọsílẹ̀ sórí ìwé kan, kó sì máa wò ó nígbà ìjíròrò náà. Àmọ́, kò sídìí tó fi yẹ kí ẹnì kan jíròrò àwọn ìbéèrè náà pẹ̀lú rẹ̀ kẹ́yin alàgbà tó bá a jíròrò.
Kí ẹni tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi sọ fún olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn tí ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi náà bá ti múra apá ibi tá a pè ní “Ìbéèrè Tá A Máa Ń Bi Àwọn Tó Fẹ́ Ṣèrìbọmi,” olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa bi ẹni náà bóyá ó ti gbàdúrà sí Jèhófà láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, tó sì ti ṣèlérí fún Jèhófà pé ìfẹ́ Rẹ̀ lòun á máa ṣe. Tí ẹni náà bá ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, kí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ṣètò alàgbà méjì tó máa bá a jíròrò “Ìbéèrè Tá A Máa Ń Bi Àwọn Tó Fẹ́ Ṣèrìbọmi.” Alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kó bójú tó apá kọ̀ọ̀kan nínú apá méjì náà. Kò pọn dandan kẹ́ ẹ dúró dìgbà tí àpéjọ bá sún mọ́lé kẹ́ ẹ tó jíròrò pẹ̀lú ẹni náà.
Ẹ lè kárí apá méjèèjì yìí ní ìjókòó méjì, kò sì yẹ kí ìjókòó kọ̀ọ̀kan gbà ju nǹkan bíi wákàtí kan lọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé, kò burú láti lò jù bẹ́ẹ̀ lọ, tó bá pọn dandan. Àdúrà ni kẹ́ ẹ fi bẹ̀rẹ̀, kẹ́ ẹ sì fi parí ìjíròrò apá kọ̀ọ̀kan. Alàgbà tó ń ṣe àtúnyẹ̀wò àti ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi kò gbọ́dọ̀ kán ara wọn lójú nígbà ìjíròrò náà. Kí àwọn alàgbà tí wọ́n bá yàn láti ṣe àtúnyẹ̀wò yìí tètè ṣe é láìjáfara.
Tí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi bá ju ẹyọ kan lọ, ohun tó dáa ni pé kí ẹ ṣe àtúnyẹ̀wò náà fún wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, kì í ṣe lápapọ̀. Ìdáhùn ẹnì kọ̀ọ̀kàn wọn sáwọn ìbéèrè náà máa jẹ́ kí ẹ̀yin alàgbà mọ bí òye ẹni náà ṣe jinlẹ̀ tó, á sì jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ dájú bóyá ó tóótun tàbí kò tóótun láti ṣèrìbọmi. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé òun àti alàgbà náà nìkan ni wọ́n jọ ń jíròrò ìbéèrè yìí, á lè sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún alàgbà náà. Tí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi náà bá jẹ́ tọkọtaya, ẹ lè ṣe àtúnyẹ̀wò náà fún wọn pa pọ̀.
Tó bá jẹ́ obìnrin lẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi, kẹ́ ẹ bójú tó ìjíròrò náà níbi táwọn èèyàn á ti máa rí yín, àmọ́ kí wọ́n má ṣe gbọ́ ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ. Tó bá pọn dandan pé kí ẹlòmíì wà pẹ̀lú yín, kí ẹni náà jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ òjíṣẹ́. Àmọ́ o, ìyẹn sinmi lórí apá tẹ́ ẹ fẹ́ jíròrò bá a ṣe ṣàlàyé nínú ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí.
Tí alàgbà ò bá fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní ìjọ yín, ẹ lè lo àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ní ìfòyemọ̀ tó sì máa ń fi làákàyè ṣe nǹkan láti jíròrò “Apá Kìíní: Ohun Táwọn Kristẹni Gbà Gbọ́” pẹ̀lú ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi. Alàgbà nìkan ni kó bójú tó “Apá Kejì: Ìgbé Ayé Kristẹni.” Àmọ́ bí kò bá sí alàgbà tó lè bójú tó apá yìí, kí ẹ kàn sí alábòójútó àyíká yín kó lè ṣètò pé kí ìjọ kan tó wà nítòsí ràn yín lọ́wọ́.
Tí ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi náà bá jẹ́ ọmọdé, kí (àwọn) òbí rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni wà níbẹ̀ tẹ́ ẹ bá ń jíròrò apá méjèèjì. Àmọ́ tí kò bá ṣeé ṣe fún wọn láti wà níbẹ̀, kí alàgbà méjì (tàbí alàgbà kan àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan, èyí sinmi lórí apá tẹ́ ẹ bá ń jíròrò) wà níbẹ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú apá méjèèjì náà.
Kí àwọn alàgbà rí i dájú pé ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi yìí ní òye tó pọ̀ tó nípa àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì. Kí wọ́n sì rí i dájú pé ẹni náà mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ dáadáa, ó sì mọrírì ètò Jèhófà. Tí ẹni náà kò bá tíì lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì dáadáa, kí ẹ̀yin alàgbà ṣètò láti ràn án lọ́wọ́ kó lè tóótun láti ṣèrìbọmi nígbà míì. Àwọn míì sì wà tó máa gba pé ká fún wọn ní àkókò díẹ̀ sí i, kí wọ́n lè túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù, tàbí kí wọ́n lè túbọ̀ fi ara wọn sábẹ́ ìṣètò Ọlọ́run. Alàgbà kọ̀ọ̀kan tó ń ṣe àtúnyẹ̀wò pẹ̀lú ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi ló máa pinnu bó ṣe máa bójú tó apá tá a yàn fún un láàárín wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́nà tá á fi mọ̀ bóyá lóòótọ́ lẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi yẹn ti ṣe tán. Lóòótọ́, a lè pẹ́ díẹ̀ lórí àwọn ìbéèrè kan, a sì lè má pẹ́ rárá lórí àwọn míì, síbẹ̀ gbogbo ìbéèrè yẹn ni kẹ́ ẹ gbé yẹ̀ wò.
Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti bójú tó apá kejì, kí àwọn alàgbà tó ṣe àtúnyẹ̀wò náà pàdé láti pinnu bóyá kí ẹni náà ṣèrìbọmi tàbí kò má ṣe. Àwọn alàgbà máa fi sọ́kàn pé ìgbésí ayé tẹ́nì kan gbé látẹ̀yìnwá yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì, agbára wọn ò rí bákan náà, ipò wọn ò sì jọra. Àwọn tí wọ́n ṣe tán láti sin Jèhófà tọkàntọkàn tí wọ́n sì lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì là ń wá. Ó dájú pé tẹ́ ẹ bá ràn wọ́n lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́, àwọn náà á lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wọn lọ́nà tí wọ́n á fi lè ṣe é láṣeyọrí.
Lẹ́yìn náà, kí ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó bójú tó àtúnyẹ̀wò náà tàbí àwọn méjèèjì bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀, kí wọ́n jẹ́ kó mọ̀ bóyá á lè ṣèrìbọmi. Tí ẹni yẹn bá máa lè ṣèrìbọmi, kí àwọn alàgbà náà jíròrò apá tá a pè ní “Ìjíròrò Tó Kẹ́yìn Pẹ̀lú Àwọn Tó Fẹ́ Ṣèrìbọmi” pẹ̀lú rẹ̀, èyí tó wà lójú ìwé 206 sí 207. Tí ẹni náà kò bá tíì parí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ rọ̀ ọ́ pé kó parí ìwé náà lẹ́yìn ìrìbọmi. Ẹ sọ fún ẹni náà pé ẹ máa kọ ọjọ́ tó ṣèrìbọmi sínú Àkọsílẹ̀ Akéde Ìjọ tiẹ̀. Kí ẹ rán an létí pé, àwọn alàgbà máa gba àwọn ìsọfúnni nípa rẹ̀ kí ètò Ọlọ́run lè fi bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, kí akéde náà lè kópa nínú ìjọsìn, ká sì lè ràn án lọ́wọ́ nínú ìjọsìn rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà tún lè rán akéde tuntun náà létí pé a máa ń lo àwọn ìsọfúnni náà ní ìbámu pẹ̀lú Àdéhùn Ààbò Lórí Ìsọfúnni Ara Ẹni Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Tẹ̀ Lé Kárí Ayé bó ṣe wà lórí ìkànnì jw.org. Kò yẹ kí ìjíròrò yìí kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá, tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀.
Lẹ́yìn ọdún kan tí akéde náà ti ṣèrìbọmi, kí alàgbà méjì ṣèpàdé pẹ̀lú rẹ̀ láti fún un níṣìírí kí wọ́n sì jẹ́ kó mọ bó ṣe tún lè tẹ̀ síwájú. Kí ọ̀kan lára àwọn alàgbà méjì náà jẹ́ alábòójútó àwùjọ tí akéde náà wà. Tí ẹni tuntun náà bá sì jẹ́ ọmọdé, á dáa kí àwọn òbí rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà níbi ìpàdé náà. Kí ẹ jẹ́ kí ìpàdé náà tani jí, kó sì tuni lára. Kí ẹ sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe tẹ̀ síwájú sí nínú ìjọsìn Jèhófà. Kí ẹ dábàá àwọn ohun tó lè ṣe kó lè máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé, kó máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, tí ìjọsìn ìdílé rẹ̀ á sì máa ṣe déédéé. Kí ẹ gbà á níyànjú láti túbọ̀ máa wá sípàdé déédéé kó sì máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Éfé. 5:15, 16) Tí kò bá tíì parí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ ṣètò pé kí ẹnì kan kọ́ ọ ní apá tó kù. Kí ẹ̀yin alàgbà rí i pé ẹ gbóríyìn fún un dáadáa. Tó bá pọn dandan pé kẹ́ ẹ fún un nímọ̀ràn lórí àwọn apá tó ń fẹ́ àtúnṣe, á dáa kó má ju kókó kan tàbí méjì lọ.