Àpótí Ìbéèrè
◼ Kí àwọn alàgbà tó fọwọ́ sí i pé kí akéde kan ṣèrìbọmi, báwo ló ṣe yẹ kó máa wá sípàdé, kó sì máa lọ sóde ẹ̀rí tó?
Ìpinnu láti ṣèrìbọmi ló ṣe pàtàkì jù lára ìpinnu téèyàn máa ń ṣe nígbèésí ayé. Torí náà, ká tó fọwọ́ sí i pé kí ẹnì kan ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ ti lóye ohun tí Ọlọ́run ń béèrè dé ìwọ̀n tó bọ́gbọ́n mu. Ó tún gbọ́dọ̀ ti máa fi hàn nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀ pé òun ti múra tán láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.
Ọlọ́run pàṣẹ fún àwa Kristẹni pé a kò gbọ́dọ̀ máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, torí náà akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ ti máa wá sí ìpàdé déédéé. (Héb. 10:24, 25) Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún gbọ́dọ̀ máa dáhùn nípàdé. Ó ṣeé ṣe kó tiẹ̀ ti forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ èyí kì í ṣe dandan.
Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run fún wa láṣẹ láti kéde ìhìn rere fáyé gbọ́ ká sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, torí náà, akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ ti máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé kó tó ṣèrìbọmi. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Oṣù mélòó ló gbọ́dọ̀ fi wàásù kó tó ṣèrìbọmi? Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká fún un láyè tó pọ̀ tó láti fi hàn pé lóòótọ́ ló fẹ́ máa fi ìtara wàásù lóṣooṣù láìdáwọ́dúró. (Sm. 78:37) Àmọ́ ṣá, kò pọn dandan kó pẹ́ gan-an lẹ́yìn tó di akéde ká tó fọwọ́ sí i pé kó ṣèrìbọmi, ó lè jẹ́ lẹ́yìn oṣù díẹ̀. Wákàtí mélòó ló gbọ́dọ̀ máa ròyìn? Kò sí iye wákàtí kan pàtó. Ipò akéde kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, ìdí nìyí táwọn alàgbà fi máa lo ìfòyemọ̀, tí wọn ò sì ní retí pé kí ẹnì kan ṣe ohun tó ju agbára rẹ̀ lọ.—Lúùkù 21:1-4.
Nígbà táwọn alàgbà (tàbí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láwọn ìjọ tí alàgbà kò pọ̀) bá ń ṣe àtúnyẹ̀wò fún akéde tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi, kí wọ́n rántí pé akéde kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, kí wọ́n sì lo òye láti fi pinnu bóyá akéde náà kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi. Lára ohun tá a retí ni pé kí akéde náà ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kó sì mọyì àǹfààní tó ní láti dara pọ̀ mọ́ ètò Ọlọ́run, kó sì tún máa wàásù. Àwọn alàgbà tún máa fi sọ́kàn pé akéde náà kò tíì dàgbà nípa tẹ̀mí bíi tàwọn tó ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run, kò sì tíì ní ìrírí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bíi tàwọn akéde ògbóṣáṣá tó ti ṣèrìbọmi. Tí àwọn alàgbà bá wá rí i pé ẹni náà kò tíì kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi, kí wọ́n fi Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ṣe ìpinnu náà fún un, kí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ kó lè kúnjú ìwọ̀n.