ÌBÉÈRÈ TÁ A MÁA Ń BI ÀWỌN TÓ FẸ́ ṢÈRÌBỌMI
Apá Kìíní: Ohun Táwọn Kristẹni Gbà Gbọ́
Ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o kọ́ lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jẹ́ kó o mọ òtítọ́. Ó sì dájú pé àwọn ẹ̀kọ́ yẹn ti jẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ó tún ti jẹ́ kó o nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa àti pé wàá gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún nínú Párádísè lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ tó o ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti lágbára sí i, o sì ti rí ọ̀pọ̀ ìbùkún látìgbà tó o ti ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni. O ti wá lóye bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ lónìí.—Sek. 8:23.
Bó o ṣe ń gbára dì fún ìrìbọmi, wàá rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú àtúnyẹ̀wò táwọn alàgbà máa ṣe pẹ̀lú rẹ nípa àwọn ohun táwọn Kristẹni gbà gbọ́. (Héb. 6:1-3) Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa bù kún gbogbo ìsapá rẹ láti túbọ̀ mọ̀ ọ́n, kí ìyè àìnípẹ̀kun tó ṣèlérí sì jẹ́ tìrẹ.—Jòh. 17:3.
1. Kí nìdí tó o fi fẹ́ ṣèrìbọmi?
2. Ta ni Jèhófà?
• “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹlòmíì.”—Diu. 4:39.
• “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.”—Sm. 83:18.
3. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa lo orúkọ Ọlọ́run?
• “Ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.’ ”—Mát. 6:9.
• “Gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà yóò rí ìgbàlà.”—Róòmù 10:13.
4. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Bíbélì lò láti ṣàpèjúwe Jèhófà?
• “Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ayé, jẹ́ Ọlọ́run títí ayé.”—Àìsá. 40:28.
• “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mát. 6:9.
• “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòh. 4:8.
5. Kí lo lè fún Jèhófà Ọlọ́run?
• “Fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”—Máàkù 12:30.
• “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.”—Lúùkù 4:8.
6. Kí nìdí tó o fi fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?
• “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tó ń pẹ̀gàn mi lésì.”—Òwe 27:11.
7. Ta lo máa ń gbàdúrà sí, orúkọ ta lo sì máa fi ń gbàdúrà?
• “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo [Jésù] sọ fún yín, tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba, ó máa fún yín ní orúkọ mi.”—Jòh. 16:23.
8. Àwọn nǹkan wo lo lè gbàdúrà fún?
• “Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí; kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, bí àwa náà ṣe dárí ji àwọn tó jẹ wá ní gbèsè. Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’ ”—Mát. 6:9-13.
• “Ohun tó dá wa lójú nípa rẹ̀ ni pé, tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.”—1 Jòh. 5:14.
9. Kí ló lè mú kí Jèhófà má gbọ́ àdúrà ẹnì kan?
• “Wọ́n á ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, àmọ́ kò ní dá wọn lóhùn . . . torí ìwà burúkú wọn.”—Míkà 3:4.
• “Ojú Jèhófà wà lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; àmọ́ Jèhófà kọjú ìjà sí àwọn tó ń ṣe ohun búburú.”—1 Pét. 3:12.
10. Ta ni Jésù Kristi?
• “Símónì Pétérù dáhùn pé: ‘Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”—Mát. 16:16.
11. Kí nìdí tí Jésù fi wá sáyé?
• “Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ èèyàn ò ṣe wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́, kó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”—Mát. 20:28.
• “Mo [Jésù] tún gbọ́dọ̀ kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú míì, torí pé nítorí èyí la ṣe rán mi.”—Lúùkù 4:43.
12. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì bí Jésù ṣe kú fún wa?
• “Ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.”—2 Kọ́r. 5:15.
13. Àṣẹ wo ni Jésù ní?
• “Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.”—Mát. 28:18.
• ‘Ọlọ́run gbé e sí ipò gíga, ó sì fún un ní orúkọ tó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.’—Fílí. 2:9.
14. Ṣé o gbà pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Jésù yàn?
• “Ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn pé kó máa bójú tó àwọn ará ilé rẹ̀, kó máa fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ?”—Mát. 24:45.
15. Ṣé ẹnì kan ni ẹ̀mí mímọ́?
• “Áńgẹ́lì náà dá a lóhùn pé: ‘Ẹ̀mí mímọ́ máa bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ sì máa ṣíji bò ọ́. Ìdí nìyẹn tí a fi máa pe ẹni tí o bí ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.’ ”—Lúùkù 1:35.
• “Torí náà, tí ẹ̀yin bá mọ bí ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín ní ẹ̀bùn tó dáa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín, mélòómélòó wá ni Baba yín tó wà ní ọ̀run, ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—Lúùkù 11:13.
16. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀?
• “Ọ̀rọ̀ ni Jèhófà fi dá àwọn ọ̀run, nípa èémí ẹnu rẹ̀ sì ni gbogbo ohun tó wà nínú wọn fi wà.”—Sm. 33:6.
• “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”—Ìṣe 1:8.
• “Kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó wá látinú èrò ara ẹni èyíkéyìí. Torí a ò fìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípasẹ̀ ìfẹ́ èèyàn, àmọ́ àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.”—2 Pét. 1:20, 21.
17. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?
• “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé. A ò ní gbé ìjọba yìí fún èèyàn èyíkéyìí míì. Ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú, ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.”—Dán. 2:44.
18. Àǹfààní wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún ẹ?
• “Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìfi. 21:4.
19. Báwo lo ṣe mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ò ní pẹ́ dé?
• “Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá a ní òun nìkan, wọ́n sọ pé: ‘Sọ fún wa, ìgbà wo ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì pé o ti wà níhìn-ín àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?’ Jésù dá wọn lóhùn pé: ‘. . . Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀ sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì. A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.’ ”—Mát. 24:3, 4, 7, 14.
• “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira. Torí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìmoore, aláìṣòótọ́, ẹni tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni, kìígbọ́-kìígbà, abanijẹ́, ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere, ọ̀dàlẹ̀, alágídí, ajọra-ẹni-lójú, wọ́n á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run, wọ́n á jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, àmọ́ ìṣe wọn ò ní fi agbára rẹ̀ hàn.”—2 Tím. 3:1-5.
20. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ṣe pàtàkì sí ẹ?
• “Ẹ máa wá Ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.”—Mát. 6:33.
• “Jésù wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀, kó gbé òpó igi oró rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi.’ ”—Mát. 16:24.
21. Ta ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí-èṣù?
• “Ọ̀dọ̀ Èṣù bàbá yín lẹ ti wá . . . Apààyàn ni ẹni yẹn nígbà tó bẹ̀rẹ̀.”—Jòh. 8:44.
• “A wá ju dírágónì ńlá náà sísàlẹ̀, ejò àtijọ́ náà, ẹni tí à ń pè ní Èṣù àti Sátánì, tó ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà; a jù ú sí ayé, a sì ju àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìfi. 12:9.
22. Ẹ̀sùn wo ni Sátánì fi kan Jèhófà àtàwọn tó ń jọ́sìn Rẹ̀?
• “Ni obìnrin náà bá sọ fún ejò yẹn pé: ‘A lè jẹ lára àwọn èso igi inú ọgbà. Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún wa nípa èso igi tó wà láàárín ọgbà pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kódà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án; kí ẹ má bàa kú.” ’ Ejò yẹn wá sọ fún obìnrin náà pé: ‘Ó dájú pé ẹ ò ní kú. Torí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ tí ẹ bá jẹ ẹ́ ni ojú yín máa là, ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ẹ sì máa mọ rere àti búburú.’ ”—Jẹ́n. 3:2-5.
• “Sátánì dá Jèhófà lóhùn pé: ‘Awọ dípò awọ. Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀.’ ”—Jóòbù 2:4.
23. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé irọ́ làwọn ọ̀rọ̀ Sátánì?
• ‘Fi gbogbo ọkàn sin [Ọlọ́run].’—1 Kíró. 28:9.
• “Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!”—Jóòbù 27:5.
24. Kí ló fa ikú?
• ‘Ẹ̀ṣẹ̀ tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé, ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn torí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.’—Róòmù 5:12.
25. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?
• “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn máa kú, àmọ́ àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníw. 9:5.
26. Ìrètí wo ló wà fún àwọn tó ti kú?
• “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
27. Àwọn mélòó ló máa lọ sọ́run láti jọba pẹ̀lú Jésù?
• “Wò ó! mo rí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà tó dúró lórí Òkè Síónì, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) wà pẹ̀lú rẹ̀, a kọ orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Baba rẹ̀ sí iwájú orí wọn.”—Ìfi. 14:1.