ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rj apá 5 ojú ìwé 12-15
  • Pa dà Sọ́dọ̀ ‘Olùṣọ́ Àgùntàn àti Alábòójútó Rẹ’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pa dà Sọ́dọ̀ ‘Olùṣọ́ Àgùntàn àti Alábòójútó Rẹ’
  • Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Pa Dà Sọ́dọ̀ Mi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára
    Kọrin sí Jèhófà
  • O Ṣeyebíye Gan-an Lójú Jèhófà!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà
rj apá 5 ojú ìwé 12-15

APÁ 5

Pa dà Sọ́dọ̀ ‘Olùṣọ́ Àgùntàn àti Alábòójútó Rẹ’

Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà jọ àwọn ohun tá a jíròrò nínú ìwé yìí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kó o mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lára àwọn míì náà. Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ àti lóde òní ló ní irú àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu bà, àmọ́ Jèhófà mú kí wọ́n borí àwọn ìṣòro yẹn. Mọ̀ dájú pé á mú kíwọ náà borí tìẹ.

Jèhófà á wà pẹ̀lú rẹ bó o ṣe ń  pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀

JẸ́ KÓ dá ẹ lójú pé Jèhófà á wà pẹ̀lú rẹ bó o ṣe ń  pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Á mú kó o borí àníyàn, á bá ẹ yanjú ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ, á sì jẹ́ kó o ní àlááfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá mọ́. Èyí á mú kó wù ẹ́ láti tún pa dà máa sin Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn bíi tìẹ. Ọ̀rọ̀ rẹ á wà dà bíi tàwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tí àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa wọn pé: “Ẹ dà bí àwọn àgùntàn, tí ń ṣáko lọ; ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ ti padà sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn àti alábòójútó ọkàn yín.”—1 Pétérù 2:25.

Ohun tó dáa jù ni pé kó o pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá múnú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Ìwọ náà sì mọ̀ pé ohun tá a bá ṣe lè múnú Jèhófà dùn tàbí kó o bà á lọ́kàn jẹ́. Ohun kan ni pé, Jèhófà kì í fipá mú wa pé ká sin òun tàbí pé ká nífẹ̀ẹ́ òun. (Diutarónómì 30:19, 20) Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé ńṣe ni ọkàn èèyàn dà bí ilẹ̀kùn kan tó jẹ́ pé inú nìkan ni wọ́n ti lè ṣí i. Béèyàn ò bá fúnra rẹ̀ ṣí i, kò sẹ́lòmíì tó lè ṣí i. Tá a bá ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, tá a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣe lò dà bíi pé a ṣí ìlẹ̀kùn ọkàn wa sílẹ̀ fún un. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa dà bíi pé a fún Jèhófà ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ẹ̀bùn yẹn la lè fi wé ìṣòtítọ́ wa, èyí á sì múnú rẹ̀ dùn gan-an. Wàá wá rí i pé kò sóhun tá a lè fi wé ayọ̀ téèyàn máa ń ní téèyàn bá fún Jèhófà ní ìjọsìn tó tọ́ sí i.—Ìṣe 20:35; Ìṣípayá 4:11.

Arábìnrin kan tí kò wá sí ìpàdé mọ́ tẹ́lẹ̀ ni wọ́n fi ọ̀yàyà kí káàbọ̀ yìí

Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà pa dà, wàá rí i pé ṣe lo túbọ̀ ń láyọ̀ bó o ṣe ń jọ́sìn rẹ̀. (Mátíù 5:3) Lọ́nà wo? Nǹkan tojú sú àwọn èèyàn níbi gbogbo láyé, wọ́n fẹ́ mọ ìdí tá a fi wà láyé. Wọ́n ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè nípa ìgbésí ayé. Aráyé ń fẹ́ mọ àwọn nǹkan yìí torí Jèhófà dá wa lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ó ti dá a mọ́ wa pé kó máa wù wá láti jọ́sìn òun. Kò sì sóhun tó lè tẹ́ wa lọ́rùn bíi ká jọ́sìn Jèhófà torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Sáàmù 63:1-5.

Ọ̀rẹ́ wa, Jèhófà fẹ́ kó o pa dà wá sọ́dọ̀ òun. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Wò ó báyìí ná: Tàdúràtàdúrà la fi fara balẹ̀ ṣe ìwé yìí. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ alàgbà kan tàbí ẹni tó o ti mọ̀ rí nínú ìjọ ló mú un wá bá ẹ. Ohun tó o kà níbẹ̀ wú ẹ lórí, ó sì ta ọ́ jí tó bẹ́ẹ̀ tó o fi pinnu pé wàá ṣiṣẹ́ lé e lórí. Gbogbo èyí fi hàn pé Jèhófà ò gbàgbé rẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè pa dà sọ́dọ̀ òun Ọlọ́run rẹ.—Jòhánù 6:44.

Ó tù wá nínú pé Jèhófà kì í gbàgbé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó kúrò nínú ètò rẹ̀. Bó ṣe rí lára arábìnrin kan tó ń jẹ́ Donna nìyẹn, ó ní: “Díẹ̀díẹ̀ ni mo kúrò nínú òtítọ́ láìfura, ṣùgbọ́n ní gbogbo ìgbà yẹn, ńṣe ni mo máa ń ronú lórí Sáàmù 139:23, 24, tó ní: ‘Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi. Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè. Kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi, Kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin.’ Ní gbogbo ìgbà yẹn, mo rí i pé ìwà àwọn èèyàn ayé ò bá mi lára mú rárá. Ṣe ni mo máa ń sọ lọ́kàn mi pé, lọ́jọ́ kan màá pa dà sínú ètò Jèhófà torí pé ibẹ̀ ló yẹ kí n wà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé Jèhófà ò pa mí tì. Èmi ló yẹ kí n wá ọ̀nà láti pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Inú mi sì dùn gan-an pé mo ti pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ báyìí.”

“Mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé Jèhófà ò pa mí tì; èmi ló yẹ kí n wá ọ̀nà láti pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀”

Àdúrà wa ni pé kí ìwọ náà pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, kí ó sì máa rí ìdùnnú rẹ̀. (Nehemáyà 8:10) O ò ní kábàámọ̀ láé pé o pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.

Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè Nípa Bó O Ṣe Lè Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà

IBO NI KÍ N TI BẸ̀RẸ̀?

Arábìnrin kan tí kò wá sí ìpàdé mọ́ tẹ́lẹ̀ ń ka Bíbélì

Ó máa ń gba àkókò díẹ̀ kí ẹnì kan tó ń ṣàìsàn tẹ́lẹ̀ tó lè máa lọ sókè sódò bó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Bákan náà, ó lè gba àkókò díẹ̀ kí ìwọ náà tó lè máa ṣe bó o ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìjọ. Torí náà, díẹ̀díẹ̀ ni kó o bẹ̀rẹ̀, máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. O lè lo àkókò díẹ̀ láti fi ka Bíbélì tàbí kó o tẹ́tí sí Bíbélì tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀, o sì lè ka ọ̀kan lára àwọn ìwé wa tàbí kó o lọ sórí ìkànnì wa tàbí kó o máa wo àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n wa, lórí jw.org. Pinnu pé wàá lọ sí ìpàdé Kristẹni tó kàn lọ́sẹ̀ yìí. Jú gbogbo rẹ̀ lọ, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíbélì rọ̀ wá pé: ‘Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.’—1 Pétérù 5:7.

“Lẹ́yìn tí mo ti dẹwọ́ nínú ìjọsìn mi sí Jèhófà, ojú bẹ̀rẹ̀ sí í tì mí débi pé ẹnu mi wúwo láti gbàdúrà. Àmọ́ nígbà tó yá, mo ṣọkàn gírí mo sì gbàdúrà, lẹ́yìn náà ni alàgbà kan wá bẹ̀ mí wò. Ọ̀rọ̀ ìwúrí tó bá mi sọ mú kí n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ mi ò sú Jèhófà. Alàgbà náà rọ̀ mí pé kí n máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ohun tí mo ṣe nìyẹn tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé. Nígbà tó yá, mò bẹ̀rẹ̀ sí í jáde òde ẹ̀rí. Mo dúpẹ́ gan-an pé Jèhófà kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi sú òun.”—Eeva.

OJÚ WO LÀWỌN ARÁ FI MÁA WÒ MÍ?

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú àwọn ará á dùn gan-an láti rí ẹ. Wọn ò ní fojú burúkú wò ẹ́ tàbí kàn ẹ́ lábùkù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n á gbà ẹ́ tọwọ́tẹsẹ̀ láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ, wọ́n á sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fún ẹ níṣìírí.—Hébérù 10:24, 25.

“Ojú tì mí láti tún lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, torí mi ò mọ irú ojú táwọn ará máa fi wò mí. Àmọ́ nígbà tí mo lọ, ara tù mi gan-an. Lára ohun tó mára tù mí ni ọ̀rọ̀ tí ìyá kan tó ti wà nínú ìjọ yẹn láti ọgbọ̀n [30] ọdún sẹ́yìn sọ fún mi, ó ní, ‘Káàbọ̀ ọmọ mi, mo bá ẹ yọ̀.’ Ọ̀rọ̀ yẹn wú mi lórí gan-an, ọkàn mi sì balẹ̀ lóòótọ́ pé ilé ni mo pa dà sí.”—Javier.

“Lọ́jọ́ ti mo pa dà lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ọwọ́ ẹ̀yìn pátápátá ni mo jókòó sí kí ẹnì kankan má bàa dá mi mọ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn tó mọ̀ mí láti kékeré ló ṣì dá ojú mi mọ̀. Wọ́n dì mọ́ mi, ara sì tù mí pẹ̀sẹ̀. Ṣe ló dà bíi pé mo pa dà wá sílé.”—Marco.

BÁWO LÀWỌN ALÀGBÀ ṢE MÁA RÀN MÍ LỌ́WỌ́?

Àwọn alàgbà á ràn ẹ́ lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́. Wọ́n á gbóríyìn fún ẹ pé o ò gbàgbé Jèhófà. (Ìṣípayá 2:4) Wọ́n á fìfẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ, wọn ò sì ní le koko mọ́ ẹ. (Gálátíà 6:1; Òwe 28:13) Wọ́n tún lè ní kẹ́nì kan máa fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! tàbí ‘Sún Mọ́ Jèhófà’ kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, fọkàn balẹ̀, àwọn alàgbà á tù ẹ́ nínú, wọ́n á sì tì ẹ́ lẹ́yìn ní gbogbo ọ̀nà.—Aísáyà 32:1, 2.

“Ní gbogbo ọdún mẹ́jọ tí mi ò fi lọ sípàdé mọ́, àwọn alàgbà ò fi mí sílẹ̀. Lọ́jọ́ kan, alàgbà kan fi àwọn fọ́tò kan tá a jọ yà hàn mí. Àwọn fọ́tò yẹn mú mi rántí àwọn ọjọ́ débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí pé kí n tún pa dà máa fayọ̀ sin Jèhófà. Mo mà dúpẹ́ o, pé àwọn alàgbà ràn mí lọ́wọ́ láti pa dà máa sin Jèhófà.”—Victor.

“Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára”

Àwọn arábìnrin méjì ń pín ìwé orin kan lò bí wọ́n ṣe ń kọrin

Nínú ìwé orin wa, “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà, àwọn orin mélòó kan wà níbẹ̀ tá á tú ẹ̀ nínú tá á sì fún ẹ níṣìírí bó o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà pa dà. Àpẹẹrẹ kan ni ti àwọn ọ̀rọ̀ inú orin 38 tá a mú nínú 1 Pétérù 5:10, èyí tó ní àkọlé náà: “Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára.”

  1. Ó nídìí t’Ọ́lọ́run fi jẹ́ kó o rí òótọ́,

    Tó sì mú ọ wá sínú ìmọ́lẹ̀.

    Ó rọ́kàn rẹ, ó rí gbogbo bó o ṣe ńsapá

    Kóo lè sún mọ́ ọn, kó o lè ṣohun tó tọ́.

    O ṣèlérí fún un pé wàá ṣèfẹ́ rẹ̀.

    Ó dájú pé yóò máa ràn ọ́ lọ́wọ́.

  2. Ọlọ́run fọmọ rẹ̀ rúbọ nítorí rẹ,

    Torí Ó fẹ́ kó o ṣe àṣeyọrí.

    B’Ọ́lọ́run kò ṣe fọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n dù ọ́,

    Kò ní ṣàì fún ọ lókun tóo nílò.

    Yóò rántí ìgbàgbọ́ àtìfẹ́ rẹ;

    Ó máa ń ṣìkẹ́ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ó fẹ̀jẹ̀ Jésù rà ọ́; ti Jèhófà ni ọ́.

    Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀, yóò fún ọ lágbára.

    Yóò máa tọ́ ẹ sọ́nà, yóò sì máa dáàbò bò ọ́.

    Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀, yóò fún ọ lágbára.

Àwo orin tá a fi ẹnu kọ lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Sing to Jehovah​—Vocal Renditions

Bó o bá fẹ́ gbọ́ orin yìí àtàwọn orin Ìjọba Ọlọ́run yòókù tá a fẹnu kọ, wo abẹ́ OHUN TÁ A NÍ > ORIN.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́