ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ypq ìbéèrè 10 ojú ìwé 30-31
  • Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?
  • Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Ọ̀rọ̀ Tó Kan Gbogbo Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
  • Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì?
    Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì?
  • Ohun Míì Tó Máa Ran Ìdílé Lọ́wọ́
    Jí!—2018
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Òbí
    Jí!—2019
Àwọn Míì
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
ypq ìbéèrè 10 ojú ìwé 30-31
Ọ̀dọ́kùnrin kan jókòó síta, ó sì ń ka Bíbélì

ÌBÉÈRÈ 10

Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Bíbélì sọ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lọ́rọ̀ yìí, a jẹ́ pé Bíbélì lè tọ́ ẹ sọ́nà nìyẹn.

KÍ LO MÁA ṢE?

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: David ń wa mọ́tò lọ ní ibì kan tí kò dé rí. Àwọn àkọlé àtàwọn ilé tó ń rí jẹ́ kó mọ̀ pé ibi tóun ń lọ kọ́ lòun wà yìí. À ṣé David ti ṣìnà. Ó ní láti jẹ́ pé ó ti yà níbi tí kò yẹ kó ti yà.

Tó bá jẹ́ ìwọ ni David, kí lo máa ṣe?

RÒ Ó WÒ NÁ!

Ohun mélòó kan wà tó o lè ṣe:

  1. O lè ní káwọn èèyàn júwe ọ̀nà fún ẹ.

  2. O lè lo máàpù tàbí ẹ̀rọ tó máa ń jẹ́ kéèyàn mọ̀nà, ìyẹn GPS.

  3. O lè máa wa mọ́tò ẹ̀ lọ, lérò pé tó bá pẹ́ tó o ti ń wa mọ́tò kiri, wàá débi tó ò ń lọ.

Ó ṣe kedere pé àbá kẹta yìí ò lè ṣiṣẹ́.

Èyí èkejì ṣì dáa jú àkọ́kọ́ lọ, ó ṣe tán, máàpù tàbí ẹ̀rọ̀ ajúwe-ọ̀nà á wà lọ́wọ́ ẹ títí tó o fi máa débi tó ò ń lọ, á sì máa sọ bó o ṣe máa rìn ín fún ẹ.

Bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì ṣe lè tọ́ ẹ sọ́nà.

Ìwé tó tà jù lọ láyé ni Bíbélì, ó sì máa

  • tọ́ ẹ sọ́nà kó o lè yanjú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé

  • jẹ́ kó o mọ irú ẹni tíwọ fúnra ẹ jẹ́, á sì tún ayé ẹ ṣe

  • jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dáa jù lọ

BÓ O ṢE LÈ RÍ ÌDÁHÙN SÁWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ NÍPA ÌGBÉSÍ AYÉ

Àtìgbà tá a ti mọ ọ̀rọ̀ sọ la ti ń béèrè ìbéèrè.

  • Kí ló dé tójú ọ̀run fi funfun?

  • Kí ni wọ́n fi dá àwọn ìràwọ̀?

Tó bá sì yá, àá bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ìbéèrè nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé.

  • Kí ló dé tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀?

  • Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń kú?

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọjọ́ pẹ́ táwọn ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí ti wà nínú Bíbélì?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé ìtàn àròsọ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu ló kún inú Bíbélì, pé kò wúlò lóde òní tàbí pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kì í tètè yéèyàn. Àmọ́, ṣé Bíbélì fúnra rẹ̀ ló níṣòro àbí ohun táwọn èèyàn ti gbọ́ nípa Bíbélì gangan ni ìṣòro? Ṣé kì í ṣe pé ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀?

Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn rò pé Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló ń darí ayé. Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ayé yìí ti dà rú! Ó kún fún ìrora àti ìyà, àìsàn àti ikú, ipò òṣì àti àjálù. Ǹjẹ́ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa lè fa gbogbo nǹkan yìí?

Ṣé wàá fẹ́ mọ ìdáhùn? Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá mọ ẹni tí Bíbélì sọ pé ó ń darí ayé!

Wàá ti kíyè sí i pé orí Bíbélì ni gbogbo àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé yìí dá lé. Ó dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú pé inú Bíbélì la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dára jù lọ. Ìdí sì ni pé “Ọlọ́run [ló] mí sí [Bíbélì], ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.” (2 Tímótì 3:​16, 17) O ò rí i pé ó yẹ kó o ṣàyẹ̀wò ìwé àtayébáyé tọ́rọ̀ inú ẹ̀ ṣì bágbà mu yìí!

MỌ PÚPỌ̀ SÍ I!

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Wo fídíò náà, Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? lórí ìkànnì www.jw.org/⁠yo.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́