ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 1 ojú ìwé 8
  • Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí í Ṣẹ̀dá Àwọn Nǹkan
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àwọn Ẹranko
    Jí!—2015
  • Ọgbà Ẹlẹ́wà Kan
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ẹni Tí Ó Dá Ohun Gbogbo
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 1 ojú ìwé 8
Ọgbà Édẹ́nì

Ẹ̀KỌ́ 1

Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé

Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa. Òun ló dá àwọn nǹkan tá a lè fojú rí àtàwọn ohun tá ò lè rí. Kí Ọlọ́run tó dá àwọn nǹkan tá a lè rí, ó kọ́kọ́ dá àwọn áńgẹ́lì. Ọlọ́run dá àwọn áńgẹ́lì tó pọ̀ gan-an. Ṣé o mọ báwọn áńgẹ́lì ṣe rí? Bí Ọlọ́run ṣe rí náà làwọn áńgẹ́lì ṣe rí. A ò lè rí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà la ò lè rí àwọn áńgẹ́lì. Áńgẹ́lì tí Jèhófà kọ́kọ́ dá máa ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́. Áńgẹ́lì yìí ran Jèhófà lọ́wọ́ nígbà tí Jèhófà dá àwọn ìràwọ̀, oòrùn àti gbogbo nǹkan míì. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá ni ayé yìí.

Jèhófà wá ṣe ayé yìí lọ́nà táwa èèyàn àtàwọn ẹranko á fi lè máa gbénú ẹ̀. Ó jẹ́ kí oòrùn máa ràn dé ayé. Ó dá àwọn òkè ńláńlá, odò àti omi òkun tó pọ̀ gan-an.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jèhófà ṣe lẹ́yìn náà? Jèhófà sọ pé: ‘Mo máa dá àwọn koríko, ewéko àtàwọn igi.’ Bó ṣe di pé àwọn igi bẹ̀rẹ̀ sí í so èso lóríṣiríṣi nìyẹn, tí oríṣiríṣi ẹ̀fọ́ àtàwọn òdòdó sì bẹ̀rẹ̀ sí í hù. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà dá gbogbo àwọn ẹranko, ó dá àwọn ẹyẹ tó ń fò, àwọn ẹranko tó ń fàyà fà, èyí tó ń rìn nílẹ̀ àtàwọn tó ń gbé inú omi. Àwọn ẹranko kan tóbi gan-an, àpẹẹrẹ kan ni erin. Àwọn ẹranko míì sì kéré, eku wà lára irú àwọn ẹranko bẹ́ẹ̀. Ẹranko wo lo fẹ́ràn jù?

Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún áńgẹ́lì àkọ́kọ́ yẹn pé: ‘Jẹ́ ká dá èèyàn.’ Ọlọ́run ò dá àwa èèyàn àtàwọn ẹranko bákan náà, a yàtọ̀ síra. Ọlọ́run dá wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé a lè ronú, ká sì ṣe oríṣiríṣi nǹkan míì. A lè sọ̀rọ̀, a lè rẹ́rìn-ín, a sì lè gbàdúrà. Àwa la tún máa bójú tó ayé yìí àtàwọn ẹranko. Ṣé o mọ orúkọ ọkùnrin tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá? Wàá rí i nínú ẹ̀kọ́ tó kàn.

“Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.”​—Jẹ́nẹ́sísì 1:1

Ìbéèrè: Ta ni Jèhófà Ọlọ́run? Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà dá?

Jẹ́nẹ́sísì 1:1-26; Òwe 8:30, 31; Jeremáyà 10:12; Kólósè 1:15-17

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́