ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 2
  • Ọgbà Ẹlẹ́wà Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọgbà Ẹlẹ́wà Kan
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ẹni Tí Ó Dá Ohun Gbogbo
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Ìdí Tí Wọ́n Fi Pàdánù Ibùgbé Wọn
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ìfẹ́ Tí A Ní Fún Ọgbà
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 2
Àwọn ẹranko, òdòdó, igi àti omi tó ń ṣàn wà nínú ọgbà Édẹ́nì tó rẹwà

ÌTÀN 2

Ọgbà Ẹlẹ́wà Kan

WO BÍ ilẹ̀ ayé ṣe rí nínú àwòrán yìí! Ó dára tàbí kò dára? Wo koríko àti igi, òdòdó àti gbogbo àwọn ẹranko. Ǹjẹ́ o lè tọ́ka sí èyí tó jẹ́ erin àti èyí tó jẹ́ kìnnìún nínú àwọn ẹranko yìí?

Báwo ni ọgbà ẹlẹ́wà yìí ṣe di èyí tó wà? Jẹ́ ká wo àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe sílẹ̀ de àwa èèyàn ká lè gbádùn ilẹ̀ ayé.

Lákọ̀ọ́kọ́, Ọlọ́run mú kí koríko hù bo ojú ilẹ̀. Ó sì dá oríṣiríṣi àwọn igi kéékèèké àti àwọn igi ńlá-ńlá pẹ̀lú igbó ńlá-ńlá àti igbó kéékèèké. Àwọn nǹkan wọ̀nyí tó ń hù ló mú kí ilẹ̀ ayé lẹ́wà. Àmọ́ kì í ṣe pé wọ́n máa ń mú kí ilẹ̀ ayé lẹ́wà nìkan, a tún ń rí oúnjẹ aládùn lára ọ̀pọ̀ nínú wọn.

Lẹ́yìn èyí, Ọlọ́run wá dá àwọn ẹja pé kí wọ́n máa wẹ̀ nínú omi àti àwọn ẹyẹ pé kí wọ́n máa fò lójú ọ̀run. Ó dá ajá àti ológbò àti ẹṣin; àwọn ẹranko ńlá-ńlá àti ẹranko kéékèèké. Irú ẹranko wo ló wà nítòsí ilé yín? Ǹjẹ́ kò yẹ kí inú wa máa dùn pé Ọlọ́run dá àwọn nǹkan wọ̀nyí fún wa?

Níkẹyìn, Ọlọ́run ṣe apá ibì kan lórí ilẹ̀ ayé ní àrà ọ̀tọ̀. Ó pe ibẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì. Ibẹ̀ dára gan-an ni. Ohun gbogbo tó wà níbẹ̀ ló lẹ́wà. Ọlọ́run sì fẹ́ kí gbogbo orí ilẹ̀ ayé rí gẹ́gẹ́ bí ọgbà ẹlẹ́wà tó dá yìí.

Ṣùgbọ́n tún wo àwòrán ọgbà yìí dáadáa. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Ọlọ́run rí i pé kò sí níbẹ̀? Jẹ́ ká wò ó ná.

Jẹ́nẹ́sísì 1:11-25; 2:8, 9.

Àwọn Ìbéèré fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́