ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/8 ojú ìwé 3
  • Ìfẹ́ Tí A Ní Fún Ọgbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfẹ́ Tí A Ní Fún Ọgbà
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọgbà Lè Ṣàlékún Ìlera
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Ọgbà Lílókìkí Mélòó Kan
    Jí!—1997
  • Pípèsè Oúnjẹ Látinú Oko Rẹ
    Jí!—2003
  • Ọgbà Ẹlẹ́wà Kan
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ṣé Òótọ́ Ni Pé Ọgbà Édẹ́nì Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 4/8 ojú ìwé 3

Ìfẹ́ Tí A Ní Fún Ọgbà

ÌWỌ ha ń gbádùn ìparọ́rọ́ ọgbà ẹlẹ́wà kan bí ibi ààbò lọ́wọ́ ariwo àti kòókòó-jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé bí? Àwọn ọgbà píparọ́rọ́ tí ó ní àwọn koríko, òdòdó, igi oníbòòji, àti ọ̀gọ̀dọ̀ ha jẹ́ ibi tí o ń yàn láàyò fún ìgbafẹ́ pẹ̀lú ìdílé rẹ tàbí fún ìnasẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ bí? Dájúdájú, ẹ wo bí ọgbà ti jẹ́ ibi amárarọni, atunilára, alálàáfíà, kódà, afúnninílera pàápàá tó!

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn kan lè ṣàìnífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe iṣẹ́ nínú ọgbà, bóyá nítorí pé wọn kò ní àkókò fún un, gbogbo wa ni àwọn àwọ̀, ìtasánsán, ìró, àti èso ọgbà máa ń gbádùn mọ́. Thomas Jefferson—ayàwòrán ilé, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, amòfin, olùṣàwárí, àti ààrẹ United States—fẹ́ràn iṣẹ́ ọgbà. Ó kọ̀wé pé: “Kò sí iṣẹ́ tí ń mú mi láyọ̀ bí iṣẹ́ ilẹ̀ ríro. . . . Ṣíṣe iṣẹ́ nínú ọgbà ṣì ń jẹ mí lọ́kàn. Bí mo tilẹ̀ jẹ́ arúgbó, síbẹ̀ ọ̀dọ́ òṣìṣẹ́ inú ọgbà ni mí.”

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ojú ìwòye tí ó ní. Lọ́dọọdún, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ olùṣèbẹ̀wò ń ya lọ sí àwọn ọgbà lílókìkí lágbàáyé—Ọgbà Kew (Ọgbà Ìtọ́jú Ohun Ọ̀gbìn ti Aláyélúwà), ní England; àwọn ọgbà ní Kyoto, Japan; àwọn ọgbà Ààfin ti Versailles, ní ilẹ̀ Faransé; Ọgbà Longwood, ní Pennsylvania, U.S.A., pé kí a kàn dárúkọ àwọn díẹ̀. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ní àwọn àgbègbè ìlú níbi tí àwọn ilé tí a kọ́ sí àwọn ìpín ìlú tí a fi igi tọ́, ti ní àwọn koríko, igi, àti àwọn àwọ̀ òdòdó wíwuni tí ó yí wọn ká—bíi párádísè kékeré kan.

Àwọn Ọgbà Lè Ṣàlékún Ìlera

A ti ṣàkíyèsí pé nígbà tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn bá ń rí àwọn ohun àdánidá, ìlera wọn lè túbọ̀ dára sí i, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé rírí náà kò kọjá kìkì títi ojú fèrèsé wo àwọn òdòdó, igi, koríko, àti ẹyẹ. Èyí ló mú kí ilé ìwòsàn kan ní Ìlú Ńlá New York gbin ọgbà kan sí orí òrùlé rẹ̀. Àgbà òṣìṣẹ́ kan nílé ìwòsàn náà sọ pé, àwọn ènìyàn “tẹ́wọ́ gbà á tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Ó ti jẹ́ ohun amúǹkansunwọ̀n fún àwọn olùgbàtọ́jú àti àwọn òṣìṣẹ́. . . . A wòye pé ó ní ipa ìwonisàn ṣíṣeéṣe púpọ̀.” Ní gidi, àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn ènìyàn lè jàǹfààní ní ti ara ìyára, ní ti èrò orí, àti ní ti ìmọ̀lára nípa títẹ́ àwọn agbára ìmòye wọn lọ́rùn.

Síwájú sí i, ẹnì kan tí ó ní ìtẹ̀sí tẹ̀mí lè nímọ̀lára sísún mọ́ Ọlọ́run sí i nígbà tí ó bá wà láàárín iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀. A lè tọpa apá yìí nípa ọgbà pa dà sí ọgbà àkọ́kọ́ gan-an lórí ilẹ̀ ayé, Ọgbà Édẹ́nì, níbi tí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bá ènìyàn sọ̀rọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17; 3:8.

Níní ìfẹ́ fún ọgbà jẹ́ ọ̀ràn kárí ayé. Bí a óò sì ṣe rí i, èyí ṣe kókó. Kí a tó jíròrò apá yìí ṣáá, a rọ̀ ọ́ láti “rìn” la àwọn ọgbà mélòó kan tí wọ́n wà nínú ìtàn kọjá, kí o lè rí bí ìyánhànhàn fún Párádísè ti jinlẹ̀ gidigidi tó lọ́kàn gbogbo ènìyàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́