ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/8 ojú ìwé 4-7
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Ọgbà Lílókìkí Mélòó Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Ọgbà Lílókìkí Mélòó Kan
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọgbà Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀
  • Láti Àwọn Ọgbà Arébíà sí Àwọn Ọgbà Ilẹ̀ England
  • Ìrísí Ojú Ilẹ̀ Ìlà Oòrùn
  • Ìfẹ́ Kárí Ayé Kan
  • Ìfẹ́ Tí A Ní Fún Ọgbà
    Jí!—1997
  • Pípèsè Oúnjẹ Látinú Oko Rẹ
    Jí!—2003
  • Ṣé Ayé Máa Di Párádísè Lóòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ibo Ni Párádísè Tí Bíbélì Sọ Máa Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Jí!—1997
g97 4/8 ojú ìwé 4-7

Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Ọgbà Lílókìkí Mélòó Kan

ÌRÍRÍ ẹ̀dá ènìyàn nípa Párádísè bẹ̀rẹ̀ nínú ọgbà kan tí ó wà ní àgbègbè kan tí a ń pè ní Édẹ́nì, tí ó ṣeé ṣe kí ó ti wà nítòsí Adágún Van, ti Turkey òde òní. Odò kan tí ó pẹ̀ka sí ọ̀nà mẹ́rin ń fomi rin ọgbà náà fún Ádámù àti Éfà, tí ó yẹ “láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o.” Ẹ wo bí yóò ti múni láyọ̀ tó láti máa bójú tó ọgbà kan, nínú èyí tí “olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ” wà lọ́pọ̀ yanturu!—Jẹ́nẹ́sísì 2:8-15, NW.

Édẹ́nì jẹ́ ibùgbé àdánidá pípé. A pète pé kí Ádámù òun Éfà àti àwọn àtọmọdọ́mọ wọn mú kí ààlà rẹ̀ gbòòrò sí i, láìsíyèméjì, kí wọ́n lo ìrísí ọgbà amúniláyọ̀ tí Ọlọ́run ṣe ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ bí àwòkọ́ṣe wọn. Bí àkókò ti ń lọ, gbogbo ilẹ̀ ayé ì bá di párádísè kan tí àwọn ènìyàn kún inú rẹ̀ nídẹ̀ra. Ṣùgbọ́n àìgbọràn àmọ̀ọ́mọ̀ṣe àwọn òbí wa àkọ́kọ́ yọrí sí lílé wọn jáde kúrò ní ibi aláàbò yí. Ó bani nínú jẹ́ pé, lẹ́yìn òde ibùgbé àdánidá ti Édẹ́nì yí ni a ti bí gbogbo àwọn yòó kù nínú ìdílé ẹ̀dá ènìyàn.

Síbẹ̀síbẹ̀, inú Párádísè ni Ẹlẹ́dàá dá aráyé láti máa gbé. Ó tipa bẹ́ẹ̀ bá ìwà ẹ̀dá mu pé, àwọn ìran ọjọ́ iwájú yóò gbìyànjú láti fi àwọn ohun tí ó fara jọ ọ́ sí àyíká wọn.

Àwọn Ọgbà Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀

A ti gbóṣùbà fún Ọgbà Alágbèékọ́ ti Bábílónì gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ohun àgbàyanu nínú ayé ìgbà láéláé. Ní ohun tí ó lé ní 2,500 ọdún sẹ́yìn ni Ọba Nebukadinésárì ṣe ọgbà náà fún aya rẹ̀, ará Mídíánì, tí ń yán hànhàn fún àwọn igbó àti òkè tí ń bẹ ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Ìgbékalẹ̀ títẹ̀ bí òrùlé tí a gbin igi kún inú rẹ̀ yí, tí ó ga ní mítà 22, tí ó sì ní àtẹ̀gùn, ní ilẹ̀ púpọ̀ tó láti mú kí àwọn igi ńláńlá dàgbà. Ó ṣeé ṣe kí ayaba tí àárò ilé ń sọ yìí ti ní ìtùnú bí ó ti ń rìn la àgbègbè orí ilé tí ó dà bí Édẹ́nì yí já.

Sísọ ìrísí ojú ilẹ̀ di ọgbà ọ̀gbìn lókìkí ní Àfonífojì Náílì lílọ́ràá ní Íjíbítì. Ìwé náà, The Oxford Companion to Gardens, sọ pé: “Íjíbítì ni orísun àwọn àwòrán ọgbà ọlọ́jọ́ pípẹ́ jù lọ lágbàáyé, òun sì ni ibi tí àṣà ṣíṣe iṣẹ́ nínú ọgbà . . . ti lọ́jọ́ lórí jù lọ.” Ìwéwèé ìrísí ojú ilẹ̀ ọgbà kan, tí ó lọ́jọ́ lórí tó nǹkan bí ọdún 1400 ṣáájú Sànmánì Tiwa, tí ó jẹ́ ti aláṣẹ ará Íjíbítì kan ní Tíbésì, ṣàfihàn àwọn ọ̀gọ̀dọ̀, àwọn ọ̀nà tí a figi tọ́, àti àwọn àgọ́. Bí a bá yọwọ́ àwọn ọgbà ti aláyélúwà, àwọn ọgbà ti tẹ́ńpìlì ni ó tún jojú ní gbèsè jù lọ, tí a ń bomi rin àwọn igbó wọn, òdòdó wọn, àti igi wọn láti inú àwọn odò tí a là láti inú àwọn ọ̀gọ̀dọ̀ àti adágún, tí àwọn ẹyẹ omi, ẹja, àti òṣíbàtà kún inú wọn.—Fi wé Ẹ́kísódù 7:19.

Àwọn ará Páṣíà pẹ̀lú yọrí ọlá nínú ọ̀ràn gbígbin ọgbà. Àwọn ọgbà Páṣíà àti Íjíbítì wọni lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ológun tí ń ṣẹ́gun fún Alexander Ńlá fi kó hóró èso, àwọn irúgbìn, àti onírúurú èròǹgbà bọ̀, nígbà tí wọ́n pa dà sí Gíríìsì ní ọ̀rúndún kẹrin ṣáájú Sànmánì Tiwa. Ní Áténì, Aristotle àti akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, Theophrastus, ṣàkójọ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ohun ọ̀gbìn tí ń pọ̀ sí i, wọ́n sì gbin ọgbà ìtọ́jú àkànṣe ohun ọ̀gbìn kan, fún ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun ọ̀gbìn àti pípín wọn sí ìsọ̀rí. Ọ̀pọ̀ àwọn Gíríìkì ọlọ́rọ̀ ló ní ọgbà jíjojúnígbèsè bíi ti àwọn ará Íjíbítì àti Páṣíà tó wà ṣáájú wọn.

Àwọn olùgbé ìlú ńlá ní Róòmù ń ṣàgbékalẹ̀ ilé òun ọgbà nínú ìwọ̀n àyè híhá tí wọ́n ní ní ìlú ńlá. Ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ ṣàgbékalẹ̀ àwọn ọgbà ìtura àrímálèlọ ní àwọn ilé tí wọ́n kọ́ sí àrọko. Kódà, òṣìkà aninilára náà, Nero, ń fẹ́ Édẹ́nì tirẹ̀, nítorí náà, ó lé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìdílé dà nù láìláàánú, ó wó àwọn ilé wọn, ó sì ṣàgbékalẹ̀ ọgbà àdáni kan tí ó jẹ́ 50 hẹ́kítà yí ààfin rẹ̀ po. Lẹ́yìn náà, ní nǹkan bí ọdún 138 Sànmánì Tiwa, ní ilé Olú Ọba Hadrian ní Tivoli, iṣẹ́ ìrísí ojú ilẹ̀ ti Róòmù dé òtéńté rẹ̀. Ilé náà ní 243 hẹ́kítà ilẹ̀ àwọn ọgbà, àwọn ibùwẹ̀, àwọn adágún, àti àwọn ìsun omi.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì pẹ̀lú ní àwọn ọgbà àti àwọn ọgbà ìtura. Òpìtàn Júù náà, Josephus, kọ̀wé nípa àwọn ọgbà ìtura tí wọ́n ní àwọn odò kéékèèké nínú ní ibì kan tí a ń pè ní Etam, ní nǹkan bíi kìlómítà 13 sí 16 láti Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọgbà ìtura Etam ti lè wà lára ‘àwọn ọgbà, ọgbà ìtura, adágún omi, àti igbó’ tí Bíbélì sọ pé Sólómọ́nì ‘ṣe fún ara rẹ̀.’ (Oníwàásù 2:5, 6) Kété lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù, lórí Òkè Ńlá Ólífì ni Ọgbà Gẹtisémánì wà, èyí tí Jésù Kristi sọ di olókìkí. Ibí ni Jésù ti rí ibi aláàbò tí ó ti lè kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ ní ìparọ́rọ́.—Mátíù 26:36; Jòhánù 18:1, 2.

Láti Àwọn Ọgbà Arébíà sí Àwọn Ọgbà Ilẹ̀ England

Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Arébíà fọ́n ká lọ sí ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn nì ọ̀rúndún keje Sànmánì Tiwa, bíi ti Alexander, àwọn pẹ̀lú rí àwọn ọgbà Páṣíà. (Fi wé Ẹ́sítérì 1:5.) Howard Loxton kọ̀wé pé: “Àwọn ará Arébíà rí i pé àwọn ọgbà Páṣíà jọ párádísè tí a ṣèlérí fún àwọn ẹlẹ̀sìn nínú Kùránì.” Bí àwọn ọgbà Páṣíà tí wọ́n fi ṣe àwòṣe, àmúṣàpẹẹrẹ ọgbà Arébíà, láti Ilẹ̀ Aláìlọ́ràá Sípéènì dé Kashmir, ni a fi odò mẹ́rin tí ibùwẹ̀ kan tàbí ìsun omi kan so pọ̀ ní àárín pín sí ọ̀nà mẹ́rin, tí ń ránni létí àwọn odò mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti Édẹ́nì.

Ní ìhà àríwá Íńdíà, nítòsí Adágún Dal ní Àfonífojì Kashmir rírẹwà, àwọn alákòóso Mogul ti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún gbin àwọn ọgbà párádísè tí ó lé ní 700. Ìwọ̀nyí dà bí àpótí onírúurú àwọ̀ mèremère tí a fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìsun omi, ilẹ̀ títẹ́jú, àti àwọn ọ̀ṣọ̀rọ̀ omi há láàárín. Ìsọ̀ onímábìlì dúdú tí Shah Jahan (tí ó kọ́ Taj Mahal) kọ́ sí etí Adágún Dal ṣì ní àkọlé náà pé: “Bí párádísè kankan bá wà ní ojú ilẹ̀ ayé, ibí ló wà, ibí ló wà, ibí ló wà.”

Ní ọ̀rúndún mélòó kan ṣáájú, ilẹ̀ Europe ti la Sànmánì Agbedeméjì já sínú Ìmúsọjí Ọ̀làjú ti ọ̀rúndún kẹrìnlá. Àṣà ṣíṣe iṣẹ́ inú ọgbà ti ilẹ̀ Róòmù, tí wọ́n tẹ̀ rì nígbà tí Sànmánì Agbedeméjì bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Tiwa, tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i—lọ́tẹ̀ yí, ó jẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso ṣọ́ọ̀ṣì. Kirisẹ́ńdọ̀mù ń wo ọgbà náà bíi ‘párádísè onígbà díẹ̀.’ Àwòrán ìkọ́lé ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kan ní ọ̀rúndún kẹsàn-án fi àwọn ọgbà méjì tí a pè ní “Párádísè” hàn. Àwọn ọgbà Kirisẹ́ńdọ̀mù bẹ̀rẹ̀ sí í tóbi sí i, wọ́n sì ń kọyọyọ sí i, ṣùgbọ́n dípò kí wọ́n fi àwọn ohun yíyẹ tẹ̀mí hàn, ọ̀pọ̀ wọn ló di àmì agbára àti ọrọ̀.

Nígbà tí Charles Kẹjọ ti Faransé ṣẹ́gun Naples, Ítálì, ní 1495, ó kọ̀wé sílé pé: “Yóò ṣòro fún yín láti gbà gbọ́ nípa àwọn ọgbà rírẹwà tí mo ní nílùú ńlá yìí . . . Ó jọ pé Ádámù àti Éfà nìkan ló kù kí wọ́n wà níbẹ̀ láti sọ ọ́ di párádísè ilẹ̀ ayé kan.” Àmọ́, ká ní Charles ti wà láàyè wọnú ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ni, ì bá ti rí àwọn ọgbà ńláńlá ti Ọba Louis Kẹrìnlá lórí ilẹ̀ Faransé gan-an. Ìwé náà, The Garden, sọ pé, àwọn ọgbà tí ó wà ní Ààfin ti Versailles “ṣì ṣeé kà sí èyí tí ó tóbi jù lọ, tí ó sì lọ́lá jù lọ, lágbàáyé.”

Bí ó ti wù kí ó rí, Sáà Ìmúsọjí Ọ̀làjú náà ní ìtumọ̀ tuntun fún párádísè: ìṣẹ̀dá gbọ́dọ̀ wà lábẹ́ ìsìnrú ẹ̀dá ènìyàn tí ó lajú, ẹni tí yóò máa pàṣẹ lórí ọgbà náà nípa mímú gbogbo ìrísí àdánidá rẹ̀ kúrò. Wọ́n ṣètò ìrísí àwọn igi àti òdòdó lọ́nà oníṣirò pàtó. Nípa bẹ́ẹ̀, ìgẹ̀lórí ti ilẹ̀ Róòmù láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀—ọnà ìṣètò ìrísí igi àti koríko nípa gígé wọn àti dídarí wọn—ni a tún mú sọjí lọ́nà tó bùáyà.

Lẹ́yìn náà, ní ọ̀rúndún kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún, ìṣàwárí inú omi àti ìṣòwò ojú òkun fi àwọn irúgbìn tuntun àti ọ̀nà ìtọ́jú ọgbà tuntun han àwọn orílẹ̀-èdè ìhà ìwọ̀ oòrùn. Ilẹ̀ England bọ́ sójú ọ̀gbagadè wíwéwèé ìrísí ọgbà tirẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The New Encyclopædia Britannica, sọ pé: “Ní ilẹ̀ England ti ọ̀rúndún kejìdínlógún, ènìyàn túbọ̀ wá ń mọ̀ sí i nípa ìṣẹ̀dá, tí òun náà jẹ́ apá kan rẹ̀. Kàkà kí ó máa gbé àwọn ìṣètò oníṣirò tí ẹ̀dá ènìyàn ṣe lé orí ìṣẹ̀dá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàgbéyẹ̀wò mímú ọ̀nà ìgbésí ayé tirẹ̀ bá a mu.” Àwọn ènìyàn bíi William Kent àti Lancelot Brown ta yọ ní ti iṣẹ́ ìtẹ́jú ilẹ̀. Brown ṣàgbékalẹ̀ àwọn dúkìá onílé ńlá tí ó ju igba lọ ní England. Àwọn ènìyàn méjì, tí wọ́n wá di ààrẹ United States, Thomas Jefferson àti John Adams, rìnrìn àjò yí ká England ní 1786 láti ṣàyẹ̀wò àwọn ọgbà ilẹ̀ England.

Ìrísí Ojú Ilẹ̀ Ìlà Oòrùn

Ọ̀nà tí a gbà ń ṣe iṣẹ́ ọgbà ní China ní ipa gidigidi lórí ọ̀làjú Ìlà Oòrùn bí àwọn ọ̀nà ti Íjíbítì, Gíríìsì, àti Róòmù ti ṣe ní ipa lórí ọ̀làjú Ìwọ̀ Oòrùn. Ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, àwọn ará China ń ṣe ìsìn onímọlẹ̀, nínú èyí tí wọ́n máa ń wo àwọn odò, àpáta, àti òkè ńláńlá, bí àwọn ẹ̀mí tí ó para dà, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹ fún ọ̀wọ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ̀sìn Tao, ẹ̀sìn Confucius, àti ẹ̀sìn Búdà gba gbogbo ilẹ̀ náà kan, wọ́n sì mú irú ọgbà tiwọn náà jáde.

Níhà kejì Òkun Japan, àwọn ọgbà àwọn ará Japan rú yọ ní ọ̀nà tiwọn, níbi tí ìrísí ti ṣe pàtàkì ju àwọ̀ lọ, tí ohun kọ̀ọ̀kan sì ní àyè tirẹ̀. Nínú ìgbìyànjú láti gba ẹwà àti ìjónírúurú ìṣẹ̀dá mọ́ra, ní àgbègbè kékeré kan, ọlọ́gbà náà ń fìṣọ́ra ṣàgbékalẹ̀ àwọn àpáta rẹ̀, ó sì ń fara balẹ̀ gbin ọgbà rẹ̀, tí ó sì ń tọ́ àwọn ọ̀gbìn inú rẹ̀. A rí ẹ̀rí èyí nínú bonsai (tí ó túmọ̀ sí “ọ̀gbìn inú ìkòkò”), ọgbọ́n ọnà fífún igi tàbí igbó onígi kan ní ìrísí àti ìwọ̀n pàtó.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀nà àgbékalẹ̀ rẹ̀ lè yàtọ̀ sí ti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn, ọgbà ìhà Ìlà Oòrùn pẹ̀lú ń ṣàfihàn ìyánhànhàn kan fún Párádísè. Bí àpẹẹrẹ, Wybe Kuitert, òpìtàn kan nípa àwọn ọgbà ilẹ̀ Japan, kọ̀wé pé, ní sáà Heian ní Japan (794 sí 1185), àwọn ọlọ́gbà gbìdánwò láti mú kí a nímọ̀lára “párádísè orí ilẹ̀ ayé” kan.

Ìfẹ́ Kárí Ayé Kan

Títí kan àwọn ẹ̀yà tí ń ṣọdẹ, tí ó tún ń ṣa èso jẹ pàápàá, tí wọ́n gbé nínú àwọn ọgbà “àdánidá”—ẹgàn, igbó, àti pápá—kárí ayé ni a nífẹ̀ẹ́ fún ọgbà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Britannica sọ pé: “Àwọn tí wọ́n ṣẹ́gun àwọn Aztec ti Mexico àti àwọn Inca ti Peru ròyìn pé wọ́n rí àwọn ọgbà kíkàmàmà tí ó ní àwọn òkè títẹ́jú, àwọn ẹgàn, ìsun omi, àti ọ̀gọ̀dọ̀ tí a fi ṣe ọ̀ṣọ́ . . . tí wọ́n fara jọ àwọn ọgbà ìgbà kan náà ní Ìwọ̀ Oòrùn.”

Dájúdájú, àwọn ẹgàn ìgbàanì lọ́tùn-ún lósì Náílì, àwọn ilẹ̀ títẹ́jú ti Ìlà Oòrùn, àwọn ọgbà ìtura láàárín ìlú, àwọn ọgbà ìtọ́jú ohun ọ̀gbìn—kí ni ìwọ̀nyí ń fi hàn? Ìyánhànhàn aráyé fún Párádísè. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa “ìfẹ́ àtọkànwá fún Párádísè” tí aráyé ń ní láìdẹ́kun yìí, òǹkọ̀wé Terry Comito wí pé: “Inú ọgbà ni ibi tí àwọn ènìyàn ti máa ń ní ìmọ̀lára pé àwọn darí dé ilé.” Ẹ̀dá ènìyàn wo sì ni kì í dunnú láti sọ pé, ‘Ilé mi dà bí Ọgbà Édẹ́nì’? Àmọ́, ǹjẹ́ àlá lásán kan ni Édẹ́nì kárí ayé kan—láìsìṣe fún àwọn ọlọ́rọ̀ nìkan—jẹ́ bí? Tàbí ohun tí ó dáni lójú nípa ọjọ́ ọ̀la kan ni bí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwòrán àfinúrò ayàwòrán nípa Ọgbà Alágbèékọ́ ti Bábílónì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọgbà bíbódemu kan ní Japan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Versailles, Faransé

Jálẹ̀jálẹ̀ ìtàn, ẹ̀dá ènìyàn ti yán hànhàn fún Párádísè

[Credit Line]

French Government Tourist Office/Rosine Mazin

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́