Ẹ̀KỌ́ 4
Kéènì Bínú Pa Àbúrò Rẹ̀
Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. Kéènì lorúkọ ọmọ tí wọ́n kọ́kọ́ bí, iṣẹ́ àgbẹ̀ ló ń ṣe. Ébẹ́lì lọmọ wọn kejì, àgùntàn lòun máa ń bójú tó ní tiẹ̀.
Lọ́jọ́ kan, àwọn méjèèjì rú ẹbọ sí Jèhófà. Ṣé o mọ ohun tíyẹn túmọ̀ sí? Ńṣe ni wọ́n fún Jèhófà ní ẹ̀bùn pàtàkì. Inú Jèhófà dùn sí ẹbọ Ébẹ́lì, àmọ́ inú rẹ̀ kò dùn sí ẹbọ Kéènì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bí Kéènì nínú gan-an. Jèhófà wá kìlọ̀ fún Kéènì pé inú tó ń bí i lè mú kó ṣe nǹkan tó burú. Àmọ́, Kéènì kò gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu.
Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Kéènì ṣe? Ó sọ fún Ébẹ́lì àbúrò ẹ̀ pé: ‘Jẹ́ ká jọ lọ sí oko.’ Nígbà tí wọ́n dénú oko, Kéènì fi nǹkan lu àbúrò ẹ̀, ó sì pa á. Kí lo rò pé Jèhófà máa ṣe? Jèhófà fìyà jẹ Kéènì, ó lé e jìnnà sílé. Kéènì ò lè pa dà sọ́dọ̀ àwọn ẹbí ẹ̀ mọ́.
Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ ẹ? O lè máa bínú tí nǹkan ò bá rí bó o ṣe fẹ́. Bóyá o máa ń bínú gan-an débi pé àwọn èèyàn ti ń kìlọ̀ fún ẹ. Á dáa kó o tètè wá nǹkan ṣe, kó o sì yíwà pa dà. Ìdí ni pé tó ò bá tètè wá nǹkan ṣe, ìbínú lè mú kó o hùwà burúkú.
Ébẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì níwà tó dáa, ìdí nìyẹn tí Jèhófà ò fi ní gbàgbé ẹ̀ láé. Jèhófà máa jí Ébẹ́lì dìde nígbà tí ayé bá di Párádísè.
“Kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ, lẹ́yìn náà, kí o pa dà wá fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”—Mátíù 5:24