ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 2/1 ojú ìwé 20-23
  • Rírú Ẹbọ Tí Jèhófà Yóò Tẹ́wọ́ Gbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Rírú Ẹbọ Tí Jèhófà Yóò Tẹ́wọ́ Gbà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyan Ọ̀nà Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
  • Ìmọ̀ràn Jèhófà àti Ìhùwàpadà Kéènì
  • Ẹ̀kọ́ Táa Rí Kọ́
  • Àwọn Ọmọ Ìyá Kan Náà Tí Ìwà Wọ́n Yàtọ̀ Síra
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Kéènì Bínú Pa Àbúrò Rẹ̀
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ọmọ Rere Àti Ọmọ Búburú
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 2/1 ojú ìwé 20-23

Rírú Ẹbọ Tí Jèhófà Yóò Tẹ́wọ́ Gbà

NÍGBÀ kan rí, a lè rí ohun àràmàǹdà kan ní ẹnu ọ̀nà tó wà ní ìlà-oòrùn ọgbà Édẹ́nì.a Àwọn kérúbù méjì, alágbára ńlá, dúró wáwááwá sí ẹnu ọ̀nà táà ń wí yìí, ìrí ojú wọn pàápàá dẹ́rù bani, ó sì mú kó ṣe kedere pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti gbabẹ̀ kọjá. Ohun mìíràn tí kò tún lè jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ta félefèle níbẹ̀ ni abẹ idà tí ń jó lala, tó sì ń yí bíríbírí, tó ṣeé ṣe kó mú kí àwọn igi tó wà lágbègbè náà mọ́lẹ̀ rokoṣo tó bá dọwọ́ alẹ́, èyí pẹ̀lú lè kó jìnnìjìnnì báni. (Jẹ́nẹ́sísì 3:24) Bó ti wù kí èyí jẹ́ ohun àrímáleèlọ tó, àfi kí èèyàn yáa máa ti òkèèrè wò ó.

Ó ṣeé ṣe kí Kéènì àti Ébẹ́lì ti ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ẹ̀yìn òde ọgbà Édẹ́nì ni Ádámù àti Éfà bí wọn sí, ṣe ni wọn á wulẹ̀ máa méfò nípa bí ìgbésí ayé tí àwọn òbí wọn gbé nínú Párádísè ti rí, ibi tí ewéko rẹ̀ ń rí omi tí ó tó, tí gbogbo rẹ̀ tutù yọ̀yọ̀, tí èso pọ̀ lọ rẹpẹtẹ, tí ewébẹ̀ sí lọ yanturu. Wàyí o, kò sí àní-àní pé ìwọ̀nba ibi tó ṣẹ́kù tí wọ́n lè pè ní Édẹ́nì yóò ti di ìgbòrò, yóò sì ti di ẹgàn.

Ó dájú pé Ádámù àti Éfà ti ṣàlàyé fún àwọn ọmọ wọn nípa ìdí tí ọgbà náà kò fi rí àbójútó àti ìdí tí a fi lé wọn kúrò níbẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:6, 23) Inú Kéènì àti Ébẹ́lì á mà bà jẹ́ gan-an o! Wọ́n lè rí ọgbà náà, àmọ́ wọn ò tẹ́ni tí í wọbẹ̀. Àwọn rèé lẹ́bàá Párádísè, àmọ́ Párádísè ti jìnnà sí wọn. Àìpé ti sọ wọ́n dìdàkudà, Kéènì tàbí Ébẹ́lì kò sì rọ́gbọ́n dá sí i.

Ó dájú pé bí àárín àwọn òbí wọn ṣe rí kò lè yanjú ọ̀ràn yìí. Nígbà tí Ọlọ́run ń ṣèdájọ́ Éfà, ó wí pé: “Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ sì ni ìfàsí-ọkàn rẹ yóò máa wà, òun yóò sì jọba lé ọ lórí.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Kí àsọtẹ́lẹ̀ yìí lè ṣẹ, Ádámù á ti bẹ̀rẹ̀ sí lo agbára rẹ̀ lórí aya rẹ̀, ó tilẹ̀ lè má ṣe é bí èkejì rẹ̀ àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ mọ́. Ó sì dà bí pé bí Éfà pàápàá kò bá fojú kan ọkọ rẹ̀, ara rẹ̀ kò ní lélẹ̀. Alálàyé kan tilẹ̀ sọ ọ́ débi ṣíṣàpèjúwe “ìfàsí-ọkàn” rẹ̀ bí “ìfẹ́ tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di àrùn.”

Bíbélì kò sọ bí ipò lọ́kọláya wọ́n ṣe nípa lórí ọ̀wọ̀ tí àwọn ọmọ wọn ń fún wọn gẹ́gẹ́ bí òbí. Ṣùgbọ́n, ó ṣe kedere pé, Ádámù àti Éfà fi àpẹẹrẹ tí ń dani láàmú lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn.

Yíyan Ọ̀nà Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Ébẹ́lì di olùṣọ́ àgùntàn, Kéènì sì ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 4:2) Bí Ébẹ́lì bá ti ń daran rẹ̀ kiri, kò sí àní-àní pé ó ní àkókò púpọ̀ láti ṣàṣàrò lórí àsọtẹ́lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ tí a sọ ṣáájú kí a tó lé àwọn òbí rẹ̀ jáde kúrò nínú Édẹ́nì pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ébẹ́lì ti gbọ́dọ̀ máa ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni ìlérí Ọlọ́run nípa irú-ọmọ tí yóò fọ́ orí ejò náà yóò ṣe nímùúṣẹ, báwo sì ni a óò ṣe pa irú-ọmọ yìí ní gìgísẹ̀?’

Nígbà tó yá, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nígbà tí wọ́n ti di géńdé, Kéènì àti Ébẹ́lì rúbọ sí Jèhófà. Nígbà tó jẹ́ pé olùṣọ́ àgùntàn ni Ébẹ́lì, kò yani lẹ́nu pé “àwọn àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ̀ . . . , àní àwọn apá tí ó lọ́ràá nínú wọn” ló mú wá. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, “àwọn èso kan tí ilẹ̀ mú jáde” ni Kéènì fi rúbọ. Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì, ṣùgbọ́n “òun kò fi ojú rere kankan wo Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-5) Èé ṣe?

Àwọn kan sọ pé ohun tó fà á ni pé ẹbọ Ébẹ́lì wá láti inú “àwọn àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ̀,” àmọ́ ti Kéènì jẹ́ “àwọn èso kan tí ilẹ̀ mú jáde.” Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn náà kì í ṣe bóyá ohun tí Kéènì fi rúbọ dára tàbí kò dára, nítorí àkọsílẹ̀ náà sọ pé Jèhófà fi ojú rere “wo Ébẹ́lì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀,” kò sì fi ojú rere kankan “wo Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” Nítorí náà, bí ọkàn-àyà olùjọsìn náà ti rí ni Jèhófà wò. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kí ló rí? Hébérù 11:4 sọ pé “nípa ìgbàgbọ́” ni Ébẹ́lì rú ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà, ó hàn gbangba pé, Kéènì kò ní ìgbàgbọ́ tó mú kí a tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì.

Ní ti èyí, ó yẹ fún àfiyèsí pé ọrẹ ẹbọ Ébẹ́lì ní títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nínú. Ó ti lè parí èrò sí pé, ìlérí Ọlọ́run nípa irú-ọmọ tí a óò pa ní gìgísẹ̀ yóò ní fífi nǹkan ẹlẹ́mìí rúbọ nínú. Ọrẹ ẹbọ Ébẹ́lì nígbà náà ti lè jẹ́ ẹ̀bẹ̀ fún ètùtù, ó sì fi ìgbàgbọ́ hàn pé Ọlọ́run yóò pèsè ẹbọ ìpẹ̀tù fún ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tó bá tó àkókò.

Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Kéènì má ronú jinlẹ̀ rárá nípa ẹbọ tó rú. Alálàyé Bíbélì kan ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún sọ pé: “Ẹbọ rẹ̀ jẹ́ wíwulẹ̀ gbà pé Ọlọ́run jẹ́ oníbú ọrẹ. Ó hàn kedere pé kò gbà pé ìṣòro kankan wà láàárín òun àti Ẹlẹ́dàá òun, tàbí pé ó yẹ kí òun jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí kí òun gbára lé ètùtù kan.”

Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí, ìwà ọ̀yájú ti lè mú Kéènì ronú pé òun ni irú-ọmọ náà tí a ṣèlérí, ẹni tí yóò pa Ejò náà, Sátánì, run. Ó ṣeé ṣe kí Éfà pàápàá ti ní irú ipò ọlá bẹ́ẹ̀ lọ́kàn fún àkọ́bí rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 4:1) Àmọ́ ṣá o, bó bá jẹ́ ohun tí Kéènì àti Éfà ń rò nìyí, wọ́n mà kúkú ṣàṣìṣe o.

Bíbélì kò sọ bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì. Àwọn kan sọ pé iná bọ́ sí i láti ọ̀run, ó sì jó o. Ọ̀nà yòówù kó jẹ́, gbàrà tí Kéènì ti mọ̀ pé a kò tẹ́wọ́ gba ẹbọ òun, “ìbínú Kéènì . . . gbóná gidigidi, ojú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀wẹ̀sì.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:5) Ìjàngbọ̀n mà ni Kéènì ń fà lẹ́sẹ̀ yìí.

Ìmọ̀ràn Jèhófà àti Ìhùwàpadà Kéènì

Jèhófà bá Kéènì fèròwérò. Ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Èé ṣe tí ìbínú rẹ fi gbóná, èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì?” Èyí fún Kéènì ní àǹfààní tí ó tó láti yẹ ìmọ̀lára àti èrò-ọkàn rẹ̀ wò fínnífínní. Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ; ní tìrẹ, ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?”—Jẹ́nẹ́sísì 4:6, 7. (Wo àpótí ní ojú ìwé 23.)

Kéènì ò mà gbọ́ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó tan Ébẹ́lì lọ sí pápá, ó sì pa á. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jèhófà béèrè Ébẹ́lì lọ́wọ́ Kéènì, ó tún parọ́ kún ọ̀ràn tó ti dá. Ó fèsì gán-ún pé: “Èmi kò mọ̀. Èmi ha ni olùtọ́jú arákùnrin mi bí?”—Jẹ́nẹ́sísì 4:8, 9.

Kí Kéènì tó pa Ébẹ́lì, ó kọ̀ láti “yíjú sí ṣíṣe rere,” ìgbà tó sì pa á tán kò yí padà. Ó yàn láti jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kápá òun, nítorí èyí, a lé Kéènì kúrò ní àgbègbè ibi tí ìdílé ènìyàn ń gbé. A ṣe “àmì” kan, tí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àṣẹ kan pé kò sí ẹni tó gbọ́dọ̀ gbẹ̀san ikú Ébẹ́lì nípa pípa Kéènì.—Jẹ́nẹ́sísì 4:15.

Lẹ́yìn náà, Kéènì lọ tẹ ìlú ńlá kan dó, ó sì sọ ọ́ ní orúkọ ọmọ rẹ̀. Abájọ tí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ fi di ẹni tí a mọ̀ mọ ìwà ipá. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìlà ìdílé Kéènì dópin nígbà tí Àkúnya ọjọ́ Nóà gbá gbogbo àwọn aláìṣòdodo dànù.—Jẹ́nẹ́sísì 4:17-24; 7:21-24.

Àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Kéènì àti Ébẹ́lì kì í kàn án ṣe ìtàn àkàgbádùn lásán. Kàkà bẹ́ẹ̀, ‘a kọ ọ́ fún ìtọ́ni wa,’ ó sì “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún bíbániwí.” (Róòmù 15:4; 2 Tímótì 3:16) Kí la lè rí kọ́ nínú àkọsílẹ̀ yìí?

Ẹ̀kọ́ Táa Rí Kọ́

Bí i Kéènì àti Ébẹ́lì, a ké sí àwọn Kristẹni lónìí láti rú ẹbọ sí Ọlọ́run—kì í ṣe ọrẹ ẹbọ tí a ń fi iná sun, ṣùgbọ́n “ẹbọ ìyìn . . . èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) A ń ṣe èyí lọ́wọ́lọ́wọ́ ní gbogbo àgbáyé, bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n. (Mátíù 24:14) Ṣé ò ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ yẹn? Nígbà náà, mọ̀ dájú pé “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ [rẹ] àti ìfẹ́ tí [o] fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Hébérù 6:10.

Bí i ti ọrẹ ẹbọ Kéènì àti Ébẹ́lì, kì í ṣe bí ẹbọ rẹ ti rí lójú ló ṣe pàtàkì jù—fún àpẹẹrẹ, bóyá nípa iye wákàtí tí o lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Jèhófà ń wò ju ìyẹn lọ. Jeremáyà 17:10 sọ pé, ó ń “wá inú ọkàn-àyà,” àní ó tún ń “ṣàyẹ̀wò kíndìnrín” pàápàá—èrò, ìmọ̀lára, àti ìsúnniṣe tó fara sin jù lọ nínú àkópọ̀ ìwà ẹnì kan. Nítorí náà kókó ọ̀ràn náà ni, ète ìsúnniṣe, kì í ṣe iye táa ṣe. Lóòótọ́, yálà ó kéré tàbí ó pọ̀, Ọlọ́run mọrírì ẹbọ wa, bó bá wá láti inú ọkàn-àyà tí ìfẹ́ sún ṣiṣẹ́.—Fi Máàkù 12:41-44 wé 14:3-9.

Bákan náà, ó yẹ ká mọ̀ pé Jèhófà kò ní gba ẹbọ gbà-má-pòóò-rọ́wọ́-mi, gan-an bí kò ṣe gba ẹbọ tí kò ti ọkàn-àyà Kéènì wá. (Málákì 1:8, 13) Ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ ni ohun tó dára jù lọ, ìyẹn ni pé, kí o fi gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn, èrò-inú, àti okun sìn ín. (Máàkù 12:30) Ṣé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀? Nígbà náà, ó yẹ kí ẹbọ rẹ fún ọ ní ìtẹ́lọ́rùn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”—Gálátíà 6:4.

Bákan náà la kúkú ṣe tọ́ Kéènì àti Ébẹ́lì dàgbà. Ṣùgbọ́n àkókò àti àyíká ipò fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn láǹfààní láti mú ànímọ́ tó yàtọ̀ síra dàgbà. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni owú, asọ̀, àti inúfùfù ba ìwà Kéènì jẹ́.

Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run rántí Ébẹ́lì gẹ́gẹ́ bí olódodo ènìyàn. (Mátíù 23:35) Ìpinnu rẹ̀ láti rí i pé òun ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí ní gbogbo ọ̀nà mú kí Ébẹ́lì yàtọ̀ pátápátá sí àwọn abarámóorejẹ ẹ̀dá tó wà nínú ìdílé rẹ̀—Ádámù, Éfà, àti Kéènì. Bíbélì sọ fún wa pé, bí Ébẹ́lì tilẹ̀ kú, ó “ń sọ̀rọ̀ síbẹ̀.” Iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ tó fi tọkàntọkàn ṣe sí Ọlọ́run wà lára ìtàn tí kò lè parẹ́ tó wà nínú Bíbélì. Ǹjẹ́ kí a tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ébẹ́lì nípa rírú ọrẹ ẹbọ tó ṣètẹ́wọ́gbà sí Ọlọ́run.—Hébérù 11:4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èrò àwọn kan ni pé àgbègbè olókè ní ìlà-oòrùn ilẹ̀ Turkey òde òní ni ọgbà Édẹ́nì ọjọ́sí wà.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwòṣe fún Àwọn Kristẹni Agbaninímọ̀ràn

“ÈÉ ṢE tí ìbínú rẹ fi gbóná, èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì?” Ìbéèrè yìí ni Jèhófà lò láti fi inú rere bá Kéènì fèròwérò. Kò fipá mú Kéènì láti yí padà, nítorí Kéènì jẹ́ ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù. (Fi wé Diutarónómì 30:19.) Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà kò lọ́ra láti sọ àbájáde ìwàkíwà Kéènì fún un. Ó kìlọ̀ fún Kéènì pé: “Bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ.”—Jẹ́nẹ́sísì 4:6, 7.

Ó yẹ fún àfiyèsí pé pẹ̀lú ìbáwí lílágbára yìí pàápàá, Jèhófà kò bá Kéènì lò gẹ́gẹ́ bí ‘ẹni tí kò lè wúlò mọ́.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí Kéènì mọ àwọn ìbùkún tí yóò rí gbà, bó bá yí ọ̀nà rẹ̀ padà, ó sì fi ìgbọ́kànlé sọ pé Kéènì lè borí ìṣòro rẹ̀ bó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Jèhófà wí pé: “Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí?” Ó tún béèrè lọ́wọ́ Kéènì nípa inú fùfù rẹ̀ tó lè yọrí sí ìpànìyàn pé: “Ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?”

Lónìí, ó yẹ kí àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà. Bí a ti sọ ọ́ nínú 2 Tímótì 4:2, nígbà mìíràn, wọ́n gbọ́dọ̀ “fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà,” kí wọ́n “báni wí kíkankíkan,” kò sì yẹ kí wọ́n máa fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tí wọ́n bá ń sọ àbájáde ìwàkíwà tí oníwà àìtọ́ kan ń gùn lé. Bákan náà, àwọn alàgbà ní láti “gbani níyànjú.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, pa·ra·ka·leʹo, túmọ̀ sí “láti fúnni níṣìírí.” Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Theological Dictionary of the New Testament, sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ìṣílétí náà kò le koko, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìbínú, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò fi ṣe lámèyítọ́. Òtítọ́ náà pé a tún lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà sí ìtùnú tún fi èrò kan náà hàn.”

Ó tún yẹ fún àfiyèsí pé, ọ̀rọ̀ Gíríìkì mìíràn tó tan mọ́ ọn ni, pa·raʹkle·tos, èyí lè túmọ̀ sí olùrànlọ́wọ́ tàbí agbẹjọ́rò nínú ọ̀ràn òfin. Nítorí náà, àní nígbà tí àwọn alàgbà bá ń báni wí tààràtà pàápàá, ó yẹ kí wọ́n rántí pé olùrànlọ́wọ́ làwọ́n jẹ́—wọn kì í ṣe ọ̀tá—fún ẹni tó nílò ìmọ̀ràn. Bí i Jèhófà, àwọn alàgbà ní láti ní ẹ̀mí pé nǹkan yóò dára, kí wọ́n ní ìgbọ́kànlé pé ẹni tí wọ́n ń gbà nímọ̀ràn lè kápa ìṣòro rẹ̀.—Fi wé Gálátíà 6:1.

Àmọ́ ṣá o, ní àbárèbábọ̀, ó kù sọ́wọ́ onítọ̀hún láti fi ìṣílétí náà sílò. (Gálátíà 6:5; Fílípì 2:12) Gẹ́gẹ́ bí Kéènì ti yàn láti ṣá ìbáwí tí Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀ fún un tì, àwọn agbaninímọ̀ràn lè rí i pé àwọn kan kì í kọbi ara sí ìkìlọ̀ wọn. Síbẹ̀, nígbà tí àwọn alàgbà bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, Àwòṣe pípé fún àwọn Kristẹni agbaninímọ̀ràn, wọ́n lè ní ìdálójú pé wọ́n ti ṣe ojúṣe wọn láti ran Kristẹni kan lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́