Ẹ̀KỌ́ 6
Èèyàn Mẹ́jọ La Ìparun Já
Nóà àti ìdílé ẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹranko wọnú áàkì. Lẹ́yìn tí wọ́n wọlé, Jèhófà ti ilẹ̀kùn áàkì náà, òjò sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Òjò yẹn rọ̀ gan-an débi pé omi bẹ̀rẹ̀ sí í gbé áàkì náà. Omi yẹn pọ̀ gan-an, kódà ó bo gbogbo ayé. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò sí nínú áàkì náà? Gbogbo wọn pátá ló kú, àmọ́ Nóà àti ìdílé ẹ̀ wà láàyè torí pé inú áàkì ni wọ́n wà. Ǹjẹ́ o rò pé inú wọn máa dùn pé àwọn ṣègbọràn sí Jèhófà?
Òjò yẹn rọ̀ fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. Lẹ́yìn náà, omi tó bo ayé bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Nígbà tó yá, áàkì náà dúró sórí òkè kan. Àmọ́, omi rẹpẹtẹ ṣì wà lórí ilẹ̀, torí náà, Nóà àti ìdílé ẹ̀ dúró sínú áàkì náà.
Díẹ̀díẹ̀, omi náà gbẹ tán. Ó ju ọdún kan lọ tí Nóà àti ìdílé ẹ̀ fi wà nínú áàkì yẹn. Jèhófà wá sọ fún wọn pé kí wọ́n jáde nínú áàkì náà, kí wọ́n sì bọ́ sínú ayé tá a lè pè ní ayé tuntun. Inú wọn dùn pé Jèhófà dá ẹ̀mí wọn sí, torí náà, wọ́n rú ẹbọ sí Jèhófà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀.
Inú Jèhófà dùn sí ẹbọ tí wọ́n rú yẹn. Jèhófà wá ṣèlérí fún wọn pé òun ò tún ní fi omi pa ayé run mọ́. Káwa èèyàn lè mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn, Ọlọ́run mú kí òṣùmàrè yọ sí ojú ọ̀run. Ṣé o ti rí òṣùmàrè rí?
Lẹ́yìn ìyẹn ni Jèhófà wá sọ fún Nóà àti ìdílé ẹ̀ pé kí wọ́n bímọ, káwọn ọmọ wọn sì kún ayé.
“Nóà wọ ọkọ̀ áàkì, [àwọn èèyàn náà] ò fiyè sí i títí Ìkún Omi fi dé, tó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—Mátíù 24:38, 39