Ẹ̀KỌ́ 11
Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò
Torí pé Ábúráhámù kọ́ Ísákì ọmọ ẹ̀ dáadáa, ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì gba gbogbo ìlérí Jèhófà gbọ́. Àmọ́ nígbà tí Ísákì wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), Jèhófà ní kí Ábúráhámù ṣe ohun kan tó ṣòro ṣe. Ǹjẹ́ o mọ ohun náà?
Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Jọ̀ọ́, mú ọmọ kan ṣoṣo tó o ní, kẹ́ ẹ jọ lọ sórí òkè kan nílẹ̀ Moráyà kó o sì fi ọmọ náà rúbọ.’ Ábúráhámù ò mọ ìdí tí Jèhófà fi ní kó ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣe ohun tí Jèhófà sọ.
Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, Ábúráhámù àti Ísákì pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ méjì rin ìrìn àjò lọ sí Moráyà. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n dé ìtòsí ibi tí wọ́n ń lọ, wọ́n sì ń wo òkè náà níwájú. Ábúráhámù sọ fáwọn ìránṣẹ́ náà pé kí wọ́n dúró de àwọn, òun àti Ísákì sì lọ láti rúbọ. Ábúráhámù ní kí Ísákì ru igi tí wọ́n máa lò, Ábúráhámù sì mú ọ̀bẹ lọ́wọ́. Ísákì béèrè lọ́wọ́ bàbá ẹ̀ pé: ‘Ẹran tá a máa fi rúbọ dà?’ Bàbá ẹ̀ sì dáhùn pé: ‘Ọmọ mi, Jèhófà máa fún wa ni ẹran tá a máa lò.’
Nígbà tí wọ́n dé orí òkè náà, wọ́n ṣe pẹpẹ kan. Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù fi okùn di ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Ísákì, ó sì gbé e sórí pẹpẹ náà.
Ábúráhámù wá mú ọ̀bẹ láti pa ọmọ rẹ̀. Ṣàdédé ló gbọ́ ohùn áńgẹ́lì Jèhófà láti ọ̀run, tó sọ pé: ‘Ábúráhámù! Má fọwọ́ kan ọmọ yẹn! Mo ti wá mọ̀ báyìí pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tó o fi ṣe tán láti fi ọmọ ẹ rúbọ.’ Ìgbà yẹn ni Ábúráhámù rí àgbò kan tí ìwo ẹ̀ há sínú igbó. Kíá ló tú Ísákì sílẹ̀, tó sì fi àgbò náà rúbọ dípò ẹ̀.
Láti ọjọ́ yẹn lọ ni Jèhófà ti ń pe Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ òun. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jèhófà fi ń pè é bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ní kí Ábúráhámù ṣe ló máa ń ṣe, nígbà míì ó tiẹ̀ lè má mọ ìdí tí Jèhófà fi ní kóun ṣe nǹkan náà.
Jèhófà tún wá ṣèlérí fún Ábúráhámù bó ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Màá bù kún ẹ, màá mú káwọn ọmọ ẹ pọ̀ gan-an.’ Èyí túmọ̀ sí pé ipasẹ̀ ìdílé Ábúráhámù ni Jèhófà máa gbà bù kún gbogbo èèyàn rere.
“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16