Ẹ̀KỌ́ 16
Ta Ni Jóòbù?
Ọkùnrin kan wà tó ń gbé nílẹ̀ Úsì tó sì ń jọ́sìn Jèhófà. Jóòbù lorúkọ ẹ̀. Ọkùnrin yẹn lówó gan-an, ó sì ní àwọn ọmọ àtàwọn ìránṣẹ́ tó pọ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó máa ń ṣoore fáwọn tálákà, ó sì tún máa ń ṣoore fáwọn tí ọkọ wọn ti kú àtàwọn ọmọ tí kò lóbìí. Àmọ́, ṣé bí Jóòbù ṣe ń ṣoore yẹn wá sọ pé kò ní níṣòro kankan?
Èṣù ń ṣọ́ Jóòbù, àmọ́ Jóòbù ò mọ̀ pé ó ń ṣọ́ òun. Jèhófà sọ fún Sátánì pé: ‘Ǹjẹ́ o kíyè sí Jóòbù ìránṣẹ́ mi? Kò sẹ́ni tó dà bíi rẹ̀ láyé. Ó máa ń tẹ́tí sí mi, ó sì máa ń hùwà rere.’ Sátánì dáhùn pé: ‘Mo gbà pé Jóòbù máa ń ṣe ohun tó o fẹ́. Ò ń dáàbò bò ó, o sì ń bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ó nílé, ó ní ilẹ̀, ó sì láwọn ẹran tó pọ̀. Tó o bá gba gbogbo ẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀, wàá rí i pé kò ní sìn ẹ́ mọ́.’ Jèhófà wá sọ pé: ‘O lè lọ dán Jóòbù wò. Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ pa á.’ Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà kí Sátánì dán Jóòbù wò? Ó dá Jèhófà lójú pé Jóòbù máa jẹ́ olóòótọ́.
Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí í kó ìdààmú bá Jóòbù. Lákọ̀ọ́kọ́, ó rán àwọn Sábéà pé kí wọ́n jí àwọn màlúù àtàwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Jóòbù. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi iná jó gbogbo àgùntàn Jóòbù. Nígbà tó yá, àwọn ará Kálídíà wá jí àwọn ràkúnmí ẹ̀. Wọ́n tún pa àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ń tọ́jú àwọn ẹranko yẹn. Ǹjẹ́ o mọ nǹkan tó burú jù tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù? Lọ́jọ́ kan táwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ń ṣe àríyá, ilé wó pa gbogbo wọn. Inú Jóòbù bà jẹ́ gan-an, àmọ́ kò fi Jèhófà sílẹ̀.
Síbẹ̀, Sátánì ò fi Jóòbù sílẹ̀. Ó tún mú kí àìsàn ṣe Jóòbù, tó fi jẹ́ pé ééwo wà ní gbogbo ara ẹ̀, ara sì máa ń ro ó. Jóòbù ò mọ ìdí tí gbogbo nǹkan yẹn fi ń ṣẹlẹ̀ sóun. Síbẹ̀, Jóòbù ò fi Jèhófà sílẹ̀, ó ṣì ń jọ́sìn ẹ̀. Inú Ọlọ́run dùn sí Jóòbù gan-an.
Nígbà tó yá, Sátánì rán àwọn ọkùnrin mẹ́ta láti lọ dán Jóòbù wò. Wọ́n sọ fún un pé: ‘Ó dájú pé o ti dẹ́ṣẹ̀, tó ò sì jẹ́wọ́. Torí ẹ̀ ni Ọlọ́run ṣe ń fìyà jẹ ọ́.’ Jóòbù sọ pé: ‘Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, mi ò dẹ́ṣẹ̀ kankan.’ Àmọ́, Jóòbù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Jèhófà ló fa ìṣòro tóun ní, ó tún sọ pé Ọlọ́run ò ṣe dáadáa sóun.
Ọ̀dọ́kùnrin kan wà níbẹ̀ tó ń jẹ́ Élíhù. Ó ń tẹ́tí sílẹ̀ nígbà táwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn ń bá Jóòbù sọ̀rọ̀. Ó wá dá sí ọ̀rọ̀ náà, ó ní: ‘Ọ̀rọ̀ tí gbogbo yín sọ ò dáa. Jèhófà tóbi ju gbogbo wa lọ, kì í ṣe búburú rárá. Ó ń rí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì máa ń ran àwa èèyàn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.’
Lẹ́yìn ìyẹn ni Jèhófà wá bá Jóòbù sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: ‘Ibo lo wà nígbà tí mo dá ọ̀run àtayé? Kí ló dé tó o fi sọ pé mi ò ṣe dáadáa sí ẹ? Ò ń sọ̀rọ̀, àmọ́ o ò mọ ìdí táwọn nǹkan yìí fi ń ṣẹlẹ̀.’ Jóòbù gbà pé òun ṣàṣìṣe, ó sì sọ pé: ‘Jọ̀ọ́, má bínú. Tẹ́lẹ̀, ṣe ni mo gbọ́ nípa rẹ, àmọ́ mo ti wá mọ̀ ẹ́ báyìí. Kò sóhun tí ìwọ Ọlọ́run ò lè ṣe. Jọ̀ọ́, dárí jì mí fún gbogbo ohun tí mo ti sọ.’
Nígbà tó yá, Jóòbù bọ́ nínú ìṣoro yẹn, Jèhófà mú kí ara ẹ̀ yá, ó sì mú kó ní nǹkan tó pọ̀ ju ohun tó ní tẹ́lẹ̀ lọ. Jóòbù pẹ́ láyé gan-an, ó sì gbádùn ayé ẹ̀. Jèhófà bù kún Jóòbù torí pé ó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kódà lásìkò tí nǹkan le. Ṣé wàá ṣe bíi Jóòbù, kó o sì ṣe ìfẹ́ Jèhófà kódà nígbà ìṣòro?
“Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ibi tí Jèhófà jẹ́ kó yọrí sí.”—Jémíìsì 5:11