Jóòbù
35 Élíhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé:
2 “Ṣé ó dá ọ lójú pé o jàre tí wàá fi sọ pé,
‘Òdodo mi ju ti Ọlọ́run lọ’?+
3 Torí o sọ pé, ‘Àǹfààní wo nìyẹn ṣe ọ́?*
Ṣé mo sàn ju ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ ni?’+
4 Màá fún ọ lésì,
Màá sì fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ+ tó wà lọ́dọ̀ rẹ lésì.
6 Tí o bá ṣẹ̀, kí lo ṣe tó dùn ún?+
Tí àṣìṣe rẹ bá ń pọ̀ sí i, kí lo ṣe fún un?+
8 Èèyàn bíi tìẹ ni ìwà burúkú rẹ lè ṣàkóbá fún,
Ọmọ aráyé nìkan sì ni òdodo rẹ wà fún.
9 Àwọn èèyàn máa ń ké jáde tí ìnira bá mu wọ́n lómi;
Wọ́n á kígbe kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ alágbára tó ń jẹ gàba lé wọn lórí.+
14 Ká má tiẹ̀ wá sọ ti àròyé tí ò ń ṣe pé o kò rí i!+
Ẹjọ́ rẹ wà níwájú rẹ̀, torí náà dúró dè é, kí o sì máa retí rẹ̀.+
15 Torí kò fi ìbínú pè ọ́ láti wá jíhìn;
Bẹ́ẹ̀ ni kò ka ìwàǹwára rẹ tó le gan-an sí.+
16 Jóòbù kàn ń la ẹnu lásán ni;
Ó sọ̀rọ̀ púpọ̀ láìní ìmọ̀.”+