Ẹ̀KỌ́ 24
Wọn Ò Mú Ìlérí Wọn Ṣẹ
Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Wá bá mi lórí òkè. Kí n lè kọ àwọn òfin mi sórí òkúta pẹlẹbẹ fún ẹ.’ Mósè gun orí òkè náà lọ, ó sì wà níbẹ̀ fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. Ní gbogbo àsìkò yẹn, Jèhófà kọ Òfin Mẹ́wàá náà sórí òkúta pẹlẹbẹ méjì, ó sì gbé e fún Mósè.
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò tètè rí Mósè, wọ́n gbà pé ó ti pa àwọn tì. Wọ́n wá sọ fún Áárónì pé: ‘A fẹ́ kí ẹnì kan máa darí wa. Ṣe ọlọ́run kan fún wa!’ Áárónì wá sọ pé: ‘Ẹ kó àwọn wúrà yín wá.’ Ó fi iná yọ́ wúrà náà, ó sì fi ṣe ère màlúù. Àwọn èèyàn náà sọ pé: ‘Ère yìí ni Ọlọ́run wa tó kó wa jáde nílẹ̀ Íjíbítì!’ Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn ère màlúù oníwúrà náà, wọ́n sì ń ṣe àríyá. Ṣé ohun tí wọ́n ṣe yìí burú àbí kò burú? Ó burú torí pé àwọn èèyàn náà ti ṣèlérí pé Jèhófà nìkan làwọn á máa jọ́sìn. Àmọ́, wọn ò mú ìlérí wọn ṣẹ.
Jèhófà rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì sọ fún Mósè pé: ‘Sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn èèyàn náà. Wọ́n ti ṣàìgbọràn sí mi, wọ́n sì ti ń bọ òrìṣà.’ Mósè wá sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà pẹ̀lú àwọn òkúta pẹlẹbẹ méjì tó wà lọ́wọ́ ẹ̀.
Bó ṣe ń sún mọ́ ibi táwọn èèyàn náà wà, ó gbọ́ tí wọ́n ń kọrin. Ó tún rí i tí wọ́n ń jó tí wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún ère màlúù náà. Inú bí Mósè gan-an. Ló bá la òkúta pẹlẹbẹ méjèèjì tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ mọ́lẹ̀, wọ́n sì fọ́ yángá. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ba ère màlúù náà jẹ́. Ó wá bi Áárónì pé: ‘Kí ló dé tó o jẹ́ káwọn èèyàn yìí mú kó o hùwà burúkú yìí?’ Áárónì sọ pé: ‘Má bínú. Ìwọ náà mọ ìwà àwọn èèyàn yìí. Wọ́n ní àwọn ń wá ọlọ́run, ni mo bá gba àwọn wúrà wọn, mo dà á sínú iná, òun sì ni mo fi ṣe ọmọ màlúù yìí.’ Kò yẹ kí Áárónì ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Mósè wá pa dà sórí òkè náà, ó sì bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wọ́n.
Jèhófà dárí ji àwọn tó ṣègbọràn nínú wọn. Ṣé ìwọ náà rí i pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tẹ̀ lé Mósè tó jẹ́ aṣáájú wọn?
“Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, má fi falẹ̀, san án, nítorí inú rẹ̀ kì í dùn sí àwọn òmùgọ̀. Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án.”—Oníwàásù 5:4