Ẹ̀KỌ́ 25
Wọ́n Kọ́ Àgọ́ Ìjọsìn
Nígbà tí Mósè wà lórí Òkè Sínáì, Jèhófà ní kó kọ́ àgọ́ kan táwọn ọmọ Ísírẹ́lì á ti máa jọ́sìn òun. Wọ́n á máa gbé àgọ́ náà lọ sí gbogbo ibi tí wọ́n bá fẹ́ lọ.
Jèhófà sọ pé: ‘Sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n mú ohunkóhun tí agbára wọn bá gbé wá kí wọ́n lè fi kọ́ àgọ́ náà.’ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wúrà, fàdákà, bàbà, àwọn òkúta iyebíye àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ wá. Wọ́n tún mú òwú, aṣọ ọ̀gbọ̀, awọ ẹran àtàwọn nǹkan míì wá. Ohun tí wọ́n mú wá pọ̀ débi tí Mósè fi sọ fún wọn pé: ‘Ohun tẹ́ ẹ mú wá ti tó! Ẹ má ṣe mú ohunkóhun wá mọ́.’
Àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tí wọ́n mọṣẹ́ dáadáa ló kọ́ àgọ́ yìí. Jèhófà tún fún wọn lọ́gbọ́n láti ṣe iṣẹ́ náà. Àwọn kan ń ṣètò òwú tí wọ́n máa lò, àwọn míì sì ń fi òwú náà hun aṣọ. Àwọn kan ń to òkúta, wọ́n ń fi wúrà ṣe oríṣiríṣi nǹkan, wọ́n sì ń gbẹ́ igi.
Àwọn èèyàn náà kọ́ àgọ́ náà gẹ́lẹ́ bí Jèhófà ṣe ní kí wọ́n kọ́ ọ. Wọ́n ṣe aṣọ ìdábùú tó rẹwà gan-an láti fi pín àgọ́ náà sí méjì, kó lè pààlà sí Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ni wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú sí. Igi àti wúrà ni wọ́n fi ṣe é. Ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi wúrà ṣe, tábìlì kan àti pẹpẹ tí wọ́n ti ń sun tùràrí wà nínú Ibi Mímọ́. Báàfù bàbà kan àti pẹpẹ ńlá kan sì wà nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì náà. Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá tí ń rí àpótí májẹ̀mú yìí, wọ́n máa ń rántí ìlérí tí wọ́n ṣe fún Jèhófà láti máa ṣègbọràn sí i. Ṣé o mọ ohun tí májẹ̀mú túmọ̀ sí? Májẹ̀mú jẹ́ ìlérí àrà ọ̀tọ̀ kan téèyàn gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú.
Jèhófà yan Áárónì àtàwọn ọmọkùnrin ẹ̀ láti máa ṣe isẹ́ àlùfáà nínú àgọ́ yìí. Wọ́n ní láti máa bójú tó ibẹ̀, kí wọ́n sì máa rúbọ sí Jèhófà níbẹ̀. Áárónì tó jẹ́ àlùfáà àgbà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ló máa ń wọ ibẹ̀, ohun tó sì máa ń gbé lọ síbẹ̀ ni ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tiẹ̀, tàwọn ẹbí ẹ̀ àti ti gbogbo Ísírẹ́lì lápapọ̀.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ àgọ́ náà parí lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. Ní báyìí, wọ́n ti wá ní ibi tí wọ́n á ti máa jọ́sìn Jèhófà.
Jèhófà jẹ́ kí ògo ẹ̀ bo àgọ́ náà, ó sì tún mú kí ìkùukùu yọ lórí àgọ́ ìjọsìn yìí. Tí wọ́n bá ń rí ìkùukùu yẹn lórí àgọ́ náà, wọn ò ní kúrò níbi tí wọ́n wà, àmọ́ tí ìkùukùu náà bá sún sókè, wọ́n mọ̀ pé àkókò ti tó láti gbéra kúrò níbi tí wọ́n wà nìyẹn. Wọ́n á tú àgọ́ ìjọ́sìn náà palẹ̀, wọ́n á sì máa tẹ̀ lé ìkùukùu náà.
“Ni mo bá gbọ́ ohùn kan tó dún ketekete látorí ìtẹ́ náà, ó sọ pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, á máa bá wọn gbé, wọ́n á sì jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa wà pẹ̀lú wọn.’”—Ìfihàn 21:3