ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt ojú ìwé 109-111
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́kísódù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Mósè Àti Áárónì Lọ Rí Fáráò
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Bí Ohun Tí Mósè Gbélé Ayé Ṣe Ṣe Kàn Ọ́
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

Ẹ́KÍSÓDÙ

OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ

  • 1

    • Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i ní Íjíbítì (1-7)

    • Fáráò ń fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (8-14)

    • Àwọn agbẹ̀bí tó bẹ̀rù Ọlọ́run dá ẹ̀mí sí (15-22)

  • 2

    • Wọ́n bí Mósè (1-4)

    • Ọmọbìnrin Fáráò fi Mósè ṣe ọmọ rẹ̀ (5-10)

    • Mósè sá lọ sí Mídíánì, ó sì fẹ́ Sípórà (11-22)

    • Ọlọ́run gbọ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń kérora (23-25)

  • 3

    • Mósè àti igi ẹlẹ́gùn-ún tó ń jó (1-12)

    • Jèhófà sọ ìtúmọ̀ orúkọ Rẹ̀ (13-15)

    • Jèhófà fún Mósè ní ìtọ́ni (16-22)

  • 4

    • Iṣẹ́ àmì mẹ́ta tí Mósè máa ṣe (1-9)

    • Mósè ní òun ò kúnjú ìwọ̀n (10-17)

    • Mósè pa dà sí Íjíbítì (18-26)

    • Mósè àti Áárónì tún jọ pàdé (27-31)

  • 5

    • Mósè àti Áárónì lọ bá Fáráò (1-5)

    • Wọ́n túbọ̀ fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (6-18)

    • Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá Mósè àti Áárónì lẹ́bi (19-23)

  • 6

    • Ọlọ́run tún ṣèlérí òmìnira ((1-13)

      • Wọn ò mọ orúkọ Jèhófà délẹ̀délẹ̀ (2, 3)

    • Ìlà ìdílé Mósè àti Áárónì (14-27)

    • Mósè tún máa lọ sọ́dọ̀ Fáráò (28-30)

  • 7

    • Jèhófà fún Mósè lókun (1-7)

    • Ọ̀pá Áárónì di ejò ńlá (8-13)

    • Ìyọnu 1: omi di ẹ̀jẹ̀ (14-25)

  • 8

    • Ìyọnu 2: àkèré (1-15)

    • Ìyọnu 3: kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ (16-19)

    • Ìyọnu 4: eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ (20-32)

      • Ìyọnu ò dé ilẹ̀ Góṣénì 22, 23)

  • 9

    • Ìyọnu 5: àwọn ẹran ọ̀sìn kú (1-7)

    • Ìyọnu 6: eéwo yọ sára èèyàn àti ẹranko (8-12)

    • Ìyọnu 7: òjò yìnyín (13-35)

      • Fáráò yóò rí agbára Ọlọ́run (16)

      • Wọ́n á mọ orúkọ Jèhófà (16)

  • 10

    • Ìyọnu 8: eéṣú (1-20)

    • Ìyọnu 9: òkùnkùn (21-29)

  • 11

    • Ó kéde ìyọnu kẹwàá (1-10)

      • Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì béèrè ẹ̀bùn (2)

  • 12

    • Ó fi Ìrékọjá lọ́lẹ̀ (1-28)

      • Wọ́n máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn (7)

    • Ìyọnu 10: Ó pa àkọ́bí (29-32)

    • Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò ní ilẹ̀ náà (33-42)

      • 430 ọdún parí (40, 41)

    • Ìtọ́ni fún àwọn tó fẹ́ ṣe Ìrékọjá (43-51)

  • 13

    • Ti Jèhófà ni gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ akọ (1, 2)

    • Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú (3-10)

    • Kí wọ́n ya gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ akọ sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run (11-16)

    • Ọlọ́run darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ọ̀nà Òkun Pupa (17-20)

    • Ọwọ̀n ìkùukùu àti ọwọ̀n iná (21, 22)

  • 14

    • Ísírẹ́lì dé òkun (1-4)

    • Fáráò ń lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (5-14)

    • Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá Òkun Pupa (15-25)

    • Àwọn ará Íjíbítì rì sínú òkun (26-28)

    • Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà (29-31)

  • 15

    • Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọrin ìṣẹ́gun (1-19)

    • Míríámù fi orin dáhùn pa dà (20, 21)

    • Omi tó korò wá dùn (22-27)

  • 16

    • Àwọn èèyàn ń ráhùn torí oúnjẹ (1-3)

    • Jèhófà gbọ́ ìráhùn wọn (4-12)

    • Ó fún wọn ní ẹyẹ àparò àti mánà (13-21)

    • Kò sí mánà lọ́jọ́ Sábáàtì (22-30)

    • Wọ́n tọ́jú mánà fún ìrántí (31-36)

  • 17

    • Wọ́n ráhùn pé wọn ò rí omi mu ní Hórébù (1-4)

    • Omi jáde látinú àpáta (5-7)

    • Àwọn ọmọ Ámálékì gbógun ja Ísírẹ́lì, àmọ́ wọn ò borí (8-16)

  • 18

    • Jẹ́tírò àti Sípórà dé (1-12)

    • Jẹ́tírò ní kó yan àwọn adájọ́ (13-27)

  • 19

    • Ní Òkè Sínáì (1-25)

      • Ísírẹ́lì yóò di ìjọba àwọn àlùfáà (5, 6)

      • Ó sọ àwọn èèyàn di mímọ́ láti pàdé Ọlọ́run (14, 15)

  • 20

    • Òfin Mẹ́wàá (1-17)

    • Ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí dẹ́rù bà wọ́n (18-21)

    • Ìtọ́ni nípa ìjọsìn (22-26)

  • 21

    • Ìdájọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tẹ̀ lé (1-36)

      • Tí wọ́n bá ra Hébérù ní ẹrú (2-11)

      • Tí ẹnì kan bá hùwà ipá sí ẹnì kejì (12-27)

      • Nípa àwọn ẹranko (28-36)

  • 22

    • Ìdájọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tẹ̀ lé (1-31)

      • Tí ẹnì kan bá jalè (1-4)

      • Tí ẹnì kan bá ba irè oko ẹlòmíì jẹ́ (5, 6)

      • Nípa àsanfidípò àti ohun ìní (7-15)

      • Nípa fífa ojú wúńdíá mọ́ra (16, 17)

      • Nípa ìjọsìn àti ohun tó tọ́ láwùjọ (18-31)

  • 23

    • Ìdájọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tẹ̀ lé (1-19)

      • Nípa ìṣòtítọ́ àti ìwà tó tọ́ (1-9)

      • Nípa sábáàtì àti àwọn àjọyọ̀ (10-19)

    • Áńgẹ́lì yóò máa darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (20-26)

    • Gbígba ilẹ̀ àti ààlà (27-33)

  • 24

    • Àwọn èèyàn gbà láti pa májẹ̀mú mọ́ (1-11)

    • Mósè lọ sórí Òkè Sínáì (12-18)

  • 25

    • Ọrẹ àgọ́ ìjọsìn (1-9)

    • Àpótí (10-22)

    • Tábìlì (23-30)

    • Ọ̀pá fìtílà (31-40)

  • 26

    • Àgọ́ ìjọsìn (1-37)

      • Àwọn aṣọ àgọ́ (1-14)

      • Àwọn férémù àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò (15-30)

      • Aṣọ ìdábùú àti aṣọ tí wọ́n máa ta sí ẹnu ọ̀nà (31-37)

  • 27

    • Pẹpẹ ẹbọ sísun (1-8)

    • Àgbàlá (9-19)

    • Òróró ọ̀pá fìtílà (20, 21)

  • 28

    • Àwọn aṣọ àlùfáà (1-5)

    • Éfódì (6-14)

    • Aṣọ ìgbàyà (15-30)

      • Úrímù àti Túmímù (30)

    • Aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá (31-35)

    • Láwàní àti àwo dídán (36-39)

    • Àwọn aṣọ míì tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà (40-43)

  • 29

    • Fífi iṣẹ́ lé àwọn àlùfáà lọ́wọ́ (1-37)

    • Ọrẹ ojoojúmọ́ (38-46)

  • 30

    • Pẹpẹ tùràrí (1-10)

    • Ìkànìyàn àti owó ètùtù (11-16)

    • Bàsíà bàbà láti máa fi wẹ̀ (17-21)

    • Àkànṣe òróró àfiyanni (22-33)

    • Àwọn èròjà tùràrí mímọ́ (34-38)

  • 31

    • Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ kún inú àwọn oníṣẹ́ ọnà (1-11)

    • Sábáàtì jẹ́ àmì láàárín Ọlọ́run àti Ísírẹ́lì (12-17)

    • Wàláà òkúta méjì (18)

  • 32

    • Wọ́n jọ́sìn ère ọmọ màlúù (1-35)

      • Mósè gbọ́ orin tó ṣàjèjì (17, 18)

      • Mósè fọ́ àwọn wàláà òfin túútúú (19)

      • Àwọn ọmọ Léfì ò fi Jèhófà sílẹ̀ (26-29)

  • 33

    • Ọlọ́run bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí (1-6)

    • Àgọ́ ìpàdé ní ẹ̀yìn ibùdó (7-11)

    • Mósè fẹ́ rí ògo Jèhófà (12-23)

  • 34

    • Ó gbẹ́ àwọn wàláà òkúta míì (1-4)

    • Mósè rí ògo Jèhófà (5-9)

    • Ọlọ́run tún àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà sọ (10-28)

    • Ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú Mósè (29-35)

  • 35

    • Àwọn ìtọ́ni Sábáàtì (1-3)

    • Ọrẹ àgọ́ ìjọsìn (4-29)

    • Ọlọ́run fi ẹ̀mí kún inú Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù (30-35)

  • 36

    • Ọrẹ náà tó, ó ṣẹ́ kù (1-7)

    • Wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn (8-38)

  • 37

    • Ó ṣe Àpótí (1-9)

    • Tábìlì (10-16)

    • Ọ̀pá fìtílà (17-24)

    • Pẹpẹ tùràrí (25-29)

  • 38

    • Pẹpẹ ẹbọ sísun (1-7)

    • Ó fi bàbà ṣe bàsíà (8)

    • Àgbàlá (9-20)

    • Wọ́n ka àwọn ohun èlò àgọ́ ìjọsìn (21-31)

  • 39

    • Wọ́n ṣe àwọn aṣọ àlùfáà (1)

    • Éfódì (2-7)

    • Aṣọ ìgbàyà (8-21)

    • Aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá (22-26)

    • Àwọn aṣọ míì tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà (27-29)

    • Àwo wúrà (30, 31)

    • Mósè yẹ iṣẹ́ tí wọ́n ṣe sí àgọ́ ìjọsìn wò (32-43)

  • 40

    • Wọ́n to àgọ́ ìjọsìn (1-33)

    • Ògo Jèhófà kún inú àgọ́ ìjọsìn (34-38)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́