Ẹ́KÍSÓDÙ
1 Orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n bá Jékọ́bù wá sí Íjíbítì nìyí, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan tó mú agbo ilé rẹ̀ wá:+ 2 Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà;+ 3 Ísákà, Sébúlúnì àti Bẹ́ńjámínì; 4 Dánì àti Náfútálì; Gádì àti Áṣérì.+ 5 Gbogbo ọmọ* tí wọ́n bí fún Jékọ́bù* jẹ́ àádọ́rin (70),* àmọ́ Jósẹ́fù ti wà ní Íjíbítì.+ 6 Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù kú,+ gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran yẹn sì kú. 7 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* ń bímọ, wọ́n sì ń pọ̀ sí i, wọ́n ń bí sí i, wọ́n sì túbọ̀ ń lágbára gidigidi, débi pé wọ́n kún ilẹ̀ náà.+
8 Nígbà tó yá, ọba tuntun tí kò mọ Jósẹ́fù jẹ ní Íjíbítì. 9 Ó sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ wò ó! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pọ̀ jù wá lọ, wọ́n sì tún lágbára jù wá lọ.+ 10 Ẹ jẹ́ ká dọ́gbọ́n kan. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n á máa pọ̀ sí i. Tí ogun bá sì dé, wọ́n á dara pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa láti gbógun jà wá, wọ́n á sì kúrò nílùú.”
11 Wọ́n wá yan àwọn ọ̀gá* lé wọn lórí láti máa fipá kó wọn ṣiṣẹ́ àṣekára.+ Wọ́n sì kọ́ àwọn ìlú tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí fún Fáráò. Orúkọ àwọn ìlú náà ni Pítómù àti Rámísésì.+ 12 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ni wọ́n ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń tàn kálẹ̀. Ẹ̀rù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ń ba àwọn ará Íjíbítì gidigidi.+ 13 Torí náà, àwọn ará Íjíbítì sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú, wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n gan-an.+ 14 Wọ́n ni wọ́n lára gidigidi bí wọ́n ṣe ń mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekára, wọ́n ń fi àpòrọ́ alámọ̀ àti bíríkì ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń mú wọn ṣe onírúurú iṣẹ́ nínú oko bí ẹrú. Kódà, wọ́n lò wọ́n nílòkulò bí ẹrú láti ṣe onírúurú iṣẹ́ àṣekára.+
15 Lẹ́yìn náà, ọba Íjíbítì bá àwọn tó ń gbẹ̀bí àwọn Hébérù sọ̀rọ̀, orúkọ wọn ni Ṣífúrà àti Púà, 16 ó sì sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá ń gbẹ̀bí+ àwọn obìnrin Hébérù, tí wọ́n sì wà lórí àpótí ìbímọ, kí ẹ pa ọmọ náà tó bá jẹ́ ọkùnrin; àmọ́ kí ẹ dá ẹ̀mí rẹ̀ sí tó bá jẹ́ obìnrin.” 17 Àmọ́ àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, wọn ò sì ṣe ohun tí ọba Íjíbítì ní kí wọ́n ṣe. Ṣe ni wọ́n ń dá ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin sí.+ 18 Nígbà tó yá, ọba Íjíbítì pe àwọn agbẹ̀bí náà, ó sì bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń dá ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin sí?” 19 Àwọn agbẹ̀bí náà sọ fún Fáráò pé: “Àwọn obìnrin Hébérù ò dà bí àwọn obìnrin Íjíbítì. Wọ́n lágbára, wọ́n sì ti máa ń bímọ kí agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”
20 Ọlọ́run wá ṣojúure sí àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn èèyàn náà ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń lágbára sí i. 21 Torí pé àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, ó fún wọn ní ìdílé tiwọn nígbà tó yá. 22 Fáráò wá pàṣẹ fún gbogbo èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ ju gbogbo ọmọkùnrin Hébérù tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sínú odò Náílì, àmọ́ kí ẹ dá ẹ̀mí gbogbo ọmọbìnrin sí.”+
2 Ní àkókò yẹn, ọkùnrin kan láti ìdílé Léfì fẹ́ ọmọbìnrin Léfì kan.+ 2 Obìnrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tó rí bí ọmọ náà ṣe rẹwà tó, ó gbé e pa mọ́ fún oṣù mẹ́ta.+ 3 Nígbà tí kò lè gbé e pa mọ́ mọ́,+ ó mú apẹ̀rẹ̀* kan tí wọ́n fi òrépèté ṣe, ó fi ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì àti ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ kùn ún, ó sì gbé ọmọ náà sínú rẹ̀. Ó wá gbé e sáàárín àwọn esùsú* etí odò Náílì. 4 Àmọ́ ẹ̀gbọ́n ọmọ náà obìnrin+ dúró ní ọ̀ọ́kán kó lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i.
5 Nígbà tí ọmọbìnrin Fáráò wá wẹ̀ ní odò Náílì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ń rìn létí odò Náílì. Obìnrin náà tajú kán rí apẹ̀rẹ̀ náà láàárín àwọn esùsú. Ló bá rán ẹrúbìnrin rẹ̀ kó lọ gbé e wá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+ 6 Nígbà tó ṣí apẹ̀rẹ̀ náà, ó rí ọmọ náà, ọmọ náà sì ń sunkún. Àánú rẹ̀ ṣe é, àmọ́ ó sọ pé: “Ọ̀kan lára ọmọ àwọn Hébérù ni.” 7 Ẹ̀gbọ́n ọmọ náà wá sọ fún ọmọbìnrin Fáráò pé: “Ṣé kí n lọ bá ọ pe obìnrin Hébérù kan tó jẹ́ olùtọ́jú wá kó lè máa bá ọ tọ́jú rẹ̀?” 8 Ọmọbìnrin Fáráò fèsì pé: “Lọ pè é wá!” Ni ọmọbìnrin náà bá lọ pe ìyá ọmọ náà wá.+ 9 Ọmọbìnrin Fáráò wá sọ fún obìnrin náà pé: “Gbé ọmọ yìí lọ kí o máa bá mi tọ́jú rẹ̀, màá sì sanwó fún ọ.” Obìnrin náà wá gbé ọmọ náà, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. 10 Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, obìnrin náà mú un wá fún ọmọbìnrin Fáráò, ó sì fi ṣe ọmọ rẹ̀.+ Ó sọ ọ́ ní Mósè,* ó sì sọ pé: “Ìdí ni pé inú omi ni mo ti gbé e jáde.”+
11 Nígbà yẹn, lẹ́yìn tí Mósè dàgbà,* ó jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, kó lè lọ wo ìnira tí wọ́n ń fara dà,+ ó sì tajú kán rí ọmọ Íjíbítì kan tó ń lu Hébérù kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn rẹ̀. 12 Ó wọ̀tún wòsì, nígbà tí kò sì rí ẹnì kankan, ó pa ọmọ Íjíbítì náà, ó sì fi iyẹ̀pẹ̀ bo òkú rẹ̀.+
13 Àmọ́ lọ́jọ́ kejì, ó jáde, ó sì rí àwọn ọkùnrin Hébérù méjì tó ń bára wọn jà. Ó wá sọ fún ẹni tó jẹ̀bi pé: “Kí ló dé tí o lu ọ̀rẹ́ rẹ?”+ 14 Nìyẹn bá fèsì pé: “Ta ló fi ọ́ ṣe olórí àti onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ọmọ Íjíbítì yẹn ni?”+ Ẹ̀rù wá ba Mósè, ó sì sọ pé: “Ó dájú pé àwọn èèyàn ti mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí!”
15 Lẹ́yìn náà, Fáráò gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì fẹ́ pa Mósè; àmọ́ Mósè sá lọ torí Fáráò, ó sì lọ ń gbé ní ilẹ̀ Mídíánì.+ Nígbà tó dé ibẹ̀, ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ kànga kan. 16 Àlùfáà Mídíánì+ ní ọmọbìnrin méje, àwọn ọmọ yìí wá fa omi, wọ́n sì pọnmi kún àwọn ọpọ́n ìmumi kí wọ́n lè fún agbo ẹran bàbá wọn lómi. 17 Àmọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn wá lé wọn kúrò, bí wọ́n ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ni Mósè bá dìde, ó ran àwọn obìnrin náà lọ́wọ́,* ó sì fún agbo ẹran wọn lómi. 18 Nígbà tí wọ́n dé ilé lọ́dọ̀ Réúẹ́lì*+ bàbá wọn, ó yà á lẹ́nu, ó sì bi wọ́n pé: “Kí ló mú kí ẹ tètè pa dà sílé lónìí?” 19 Wọ́n fèsì pé: “Ará Íjíbítì+ kan ló gbà wá lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn, ó tún bá wa fa omi, ó sì fún agbo ẹran lómi.” 20 Ó bi àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pé: “Ẹni náà wá dà? Kí ló dé tí ẹ fi ọkùnrin ọ̀hún sílẹ̀? Ẹ lọ pè é wá, kó lè bá wa jẹun.” 21 Lẹ́yìn náà, Mósè gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ó sì fún Mósè ní Sípórà+ ọmọ rẹ̀ kó fi ṣe aya. 22 Nígbà tó yá, obìnrin náà bí ọmọkùnrin kan, Mósè sì sọ ọ́ ní Gẹ́ṣómù,*+ torí ó sọ pé, “Mo ti di àjèjì nílẹ̀ àjèjì.”+
23 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún,* ọba Íjíbítì kú,+ àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kérora torí wọ́n wà lóko ẹrú, wọ́n sì ń ráhùn, igbe tí wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ torí pé wọ́n ń fi wọ́n ṣe ẹrú sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.+ 24 Nígbà tó yá, Ọlọ́run gbọ́ bí wọ́n ṣe ń kérora,+ Ọlọ́run sì rántí májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù dá.+ 25 Torí náà, Ọlọ́run yíjú sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; Ọlọ́run sì kíyè sí wọn.
3 Mósè ń bójú tó agbo ẹran Jẹ́tírò+ bàbá ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ àlùfáà Mídíánì. Nígbà tó ń da agbo ẹran náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn aginjù, ó dé Hórébù, òkè Ọlọ́run tòótọ́.+ 2 Áńgẹ́lì Jèhófà fara hàn án nínú ọwọ́ iná tó ń jó láàárín igi ẹlẹ́gùn-ún kan.+ Bó ṣe ń wò ó, ó rí i pé iná ń jó lára igi ẹlẹ́gùn-ún náà, síbẹ̀ igi náà ò jóná. 3 Mósè wá sọ pé: “Jẹ́ kí n lọ wo nǹkan àrà yìí, kí n lè mọ ohun tí kò jẹ́ kí igi ẹlẹ́gùn-ún náà jóná.” 4 Nígbà tí Jèhófà rí i pé ó lọ wò ó, Ọlọ́run pè é látinú igi ẹlẹ́gùn-ún náà pé: “Mósè! Mósè!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí.” 5 Ó wá sọ pé: “Má ṣe sún mọ́ ibí yìí. Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, torí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí.”
6 Ó sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run bàbá rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù.”+ Ni Mósè bá fojú pa mọ́, torí ẹ̀rù ń bà á láti wo Ọlọ́run tòótọ́. 7 Jèhófà sì sọ pé: “Mo ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn mi ní Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ igbe wọn torí àwọn tó ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́; mo mọ̀ dáadáa pé wọ́n ń jẹ̀rora.+ 8 Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ màá sì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ yẹn lọ sí ilẹ̀ kan tó dára, tó sì fẹ̀, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ní agbègbè àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+ 9 Wò ó! Mo ti gbọ́ igbe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo sì ti rí bí àwọn ará Íjíbítì ṣe ń fìyà jẹ wọ́n gidigidi.+ 10 Ní báyìí, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí Fáráò, wàá sì mú àwọn èèyàn mi, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì.”+
11 Àmọ́ Mósè sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ta ni mo jẹ́, tí màá fi lọ bá Fáráò, tí màá sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì?” 12 Ó fèsì pé: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ,+ ohun tí yóò sì jẹ́ àmì fún ọ pé èmi ni mo rán ọ nìyí: Lẹ́yìn tí o bá ti mú àwọn èèyàn náà kúrò ní Íjíbítì, ẹ máa jọ́sìn* Ọlọ́run tòótọ́ lórí òkè yìí.”+
13 Àmọ́ Mósè sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ká ní mo lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí mo sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì bi mí pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’+ Kí ni kí n sọ fún wọn?” 14 Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Fẹ́.”*+ Ó sì sọ pé: “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Èmi Yóò Di ti rán mi sí yín.’”+ 15 Ọlọ́run wá sọ fún Mósè lẹ́ẹ̀kan sí i pé:
“Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù+ ló rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi títí láé,+ bí wọ́n á sì ṣe máa rántí mi láti ìran dé ìran nìyí. 16 Wá lọ, kí o kó àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ti fara hàn mí, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù, ó sì sọ pé: “Mo ti kíyè sí yín,+ mo sì ti rí ohun tí wọ́n ń ṣe sí yín ní Íjíbítì. 17 Torí náà, mo ṣèlérí pé màá gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tó ń fìyà jẹ yín,+ màá sì mú yín lọ sí ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì,+ àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ sí ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.”’+
18 “Ó dájú pé wọ́n á fetí sí ohùn rẹ,+ ìwọ àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì yóò lọ bá ọba Íjíbítì, ẹ ó sì sọ fún un pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù+ ti bá wa sọ̀rọ̀. Torí náà, jọ̀ọ́, jẹ́ ká rin ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sí aginjù, ká lè rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa.’+ 19 Àmọ́ èmi fúnra mi mọ̀ dáadáa pé ọba Íjíbítì kò ní jẹ́ kí ẹ lọ àfi tí mo bá fi ọwọ́ agbára mú un.+ 20 Ṣe ni màá na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ Íjíbítì nípasẹ̀ gbogbo nǹkan àgbàyanu tí màá ṣe níbẹ̀, lẹ́yìn náà, á jẹ́ kí ẹ lọ.+ 21 Màá mú kí àwọn èèyàn yìí rí ojú rere àwọn ará Íjíbítì, tí ẹ bá sì ń lọ, ó dájú pé ẹ ò ní lọ lọ́wọ́ òfo.+ 22 Kí obìnrin kọ̀ọ̀kan béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti wúrà pẹ̀lú aṣọ lọ́wọ́ ọmọnìkejì rẹ̀ àti obìnrin tó ń gbé nílé rẹ̀, kí ẹ sì fi wọ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin yín; ẹ ó sì gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.”+
4 Àmọ́ Mósè fèsì pé: “Tí wọn ò bá gbà mí gbọ́ ńkọ́, tí wọn ò sì fetí sí mi?+ Torí wọ́n á sọ pé, ‘Jèhófà ò fara hàn ọ́.’” 2 Jèhófà bi í pé: “Kí ló wà lọ́wọ́ rẹ yẹn?” Ó fèsì pé: “Ọ̀pá ni.” 3 Ọlọ́run sọ pé: “Jù ú sílẹ̀.” Ó jù ú sílẹ̀, ló bá di ejò;+ Mósè sì sá fún un. 4 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ mú un níbi ìrù.” Ó nawọ́ mú un, ó sì di ọ̀pá lọ́wọ́ rẹ̀. 5 Ọlọ́run wá sọ pé, “Èyí á jẹ́ kí wọ́n gbà gbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù+ ti fara hàn ọ́.”+
6 Jèhófà tún sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, ki ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ rẹ lápá òkè.” Ó wá ki ọwọ́ bọ inú aṣọ rẹ̀. Nígbà tó yọ ọ́ jáde, ẹ̀tẹ̀ ti bò ó lọ́wọ́, ó sì funfun bíi yìnyín!+ 7 Ọlọ́run wá sọ pé: “Dá ọwọ́ rẹ pa dà sínú aṣọ rẹ lápá òkè.” Ó sì dá ọwọ́ rẹ̀ pa dà sínú aṣọ rẹ̀. Nígbà tó yọ ọ́ jáde nínú aṣọ, ó ti pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀! 8 Ó sọ pé: “Tí wọn ò bá gbà ọ́ gbọ́, tí wọn ò sì fiyè sí àmì àkọ́kọ́, ó dájú pé wọ́n á gba àmì kejì gbọ́.+ 9 Síbẹ̀, tí wọn ò bá gba àmì méjèèjì yìí gbọ́, tí wọn ò sì fetí sí ọ, kí o bu omi díẹ̀ látinú odò Náílì, kí o sì dà á sórí ilẹ̀, omi tí o bù nínú odò Náílì yóò sì di ẹ̀jẹ̀ lórí ilẹ̀.”+
10 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: “Má bínú, Jèhófà, mi ò lè sọ̀rọ̀ dáadáa ṣáájú àkókò yìí àti lẹ́yìn tí o bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, torí ọ̀rọ̀ mi ò já geere,* ahọ́n mi sì wúwo.”+ 11 Jèhófà sọ fún un pé: “Ta ló fún èèyàn ní ẹnu, ta ló sì ń mú kó má lè sọ̀rọ̀, kó ya adití, kó ríran kedere tàbí kó fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe èmi Jèhófà ni? 12 Torí náà, lọ, màá wà pẹ̀lú rẹ bí o ṣe ń sọ̀rọ̀,* màá sì kọ́ ọ ní ohun tí o máa sọ.”+ 13 Àmọ́ Mósè sọ pé: “Má bínú, Jèhófà, jọ̀ọ́ rán ẹnikẹ́ni tí o bá fẹ́.” 14 Jèhófà wá bínú sí Mósè, ó sì sọ pé: “Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ+ tó jẹ́ ọmọ Léfì ńkọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ dáadáa. Ó sì ti ń bọ̀ wá bá ọ níbí báyìí. Tó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóò dùn.+ 15 Kí o bá a sọ̀rọ̀, kí o sì fi àwọn ọ̀rọ̀ náà sí ẹnu rẹ̀,+ màá wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì bí o ṣe ń sọ̀rọ̀,+ màá sì kọ́ yín ní ohun tí ẹ máa ṣe. 16 Yóò bá ọ bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀, òun ló máa jẹ́ agbẹnusọ fún ọ, ìwọ yóò sì dà bí Ọlọ́run fún un.*+ 17 Kí o mú ọ̀pá yìí dání, kí o sì fi ṣe àwọn iṣẹ́ àmì náà.”+
18 Mósè wá pa dà sọ́dọ̀ Jẹ́tírò bàbá ìyàwó rẹ̀,+ ó sì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, mo fẹ́ pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi tó wà ní Íjíbítì kí n lè rí i bóyá wọ́n ṣì wà láàyè.” Jẹ́tírò sọ fún Mósè pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.” 19 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè ní Mídíánì pé: “Pa dà lọ sí Íjíbítì, torí gbogbo àwọn tó fẹ́ pa ọ́* ti kú.”+
20 Mósè wá gbé ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó forí lé ilẹ̀ Íjíbítì. Mósè sì mú ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ dání. 21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Tí o bá dé Íjíbítì, rí i pé gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí mo fún ọ lágbára láti ṣe lo ṣe níwájú Fáráò.+ Àmọ́, màá jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ le,+ kò sì ní jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ.+ 22 Kí o sọ fún Fáráò pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ọmọ mi ni Ísírẹ́lì, àkọ́bí mi ni.+ 23 Mò ń sọ fún ọ pé, Jẹ́ kí ọmọ mi máa lọ kó lè sìn mí. Àmọ́ tí o ò bá jẹ́ kó lọ, màá pa ọmọkùnrin rẹ, àkọ́bí rẹ.”’”+
24 Lójú ọ̀nà ibi tí wọ́n dé sí, Jèhófà + pàdé rẹ̀, ó sì fẹ́ pa á.+ 25 Ni Sípórà+ bá mú akọ òkúta,* ó dádọ̀dọ́* ọmọ rẹ̀, ó sì mú kí adọ̀dọ́ rẹ̀ kan ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ní: “Torí ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ lo jẹ́ fún mi.” 26 Torí náà, Ó jẹ́ kó lọ. Ìdádọ̀dọ́ náà ló mú kí obìnrin náà pè é ní “ọkọ ẹlẹ́jẹ̀” nígbà yẹn.
27 Jèhófà wá sọ fún Áárónì pé: “Lọ bá Mósè nínú aginjù.”+ Torí náà, ó lọ pàdé rẹ̀ ní òkè Ọlọ́run tòótọ́,+ ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu láti kí i. 28 Mósè sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹni tó rán an, fún Áárónì,+ ó sì sọ fún un nípa gbogbo iṣẹ́ àmì tó pa láṣẹ pé kó ṣe.+ 29 Lẹ́yìn náà, Mósè àti Áárónì lọ, wọ́n sì kó gbogbo àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ.+ 30 Áárónì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Mósè fún wọn, ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ àmì náà+ níṣojú àwọn èèyàn náà. 31 Èyí mú kí àwọn èèyàn náà gbà á gbọ́.+ Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jèhófà ti yíjú sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ àti pé ó ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn,+ wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀.
5 Lẹ́yìn náà, Mósè àti Áárónì wọlé lọ bá Fáráò, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ, kí wọ́n lè ṣe àjọyọ̀ fún mi nínú aginjù.’” 2 Àmọ́ Fáráò sọ pé: “Ta ni Jèhófà,+ tí màá fi gbọ́ràn sí i lẹ́nu pé kí n jẹ́ kí Ísírẹ́lì lọ?+ Mi ò mọ Jèhófà rárá, mi ò sì ní jẹ́ kí Ísírẹ́lì lọ.”+ 3 Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Ọlọ́run àwa Hébérù ti bá wa sọ̀rọ̀. Jọ̀ọ́, a fẹ́ rin ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sí aginjù, ká sì rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, yóò fi àìsàn kọ lù wá tàbí kó fi idà pa wá.” 4 Ọba Íjíbítì fèsì pé: “Mósè àti Áárónì, kí ló dé tí ẹ fẹ́ mú àwọn èèyàn yìí kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ pa dà sẹ́nu iṣẹ́* yín!”+ 5 Fáráò tún sọ pé: “Ẹ wo bí àwọn èèyàn yìí ṣe pọ̀ tó nílẹ̀ yìí, ẹ wá fẹ́ dá iṣẹ́ wọn dúró!”
6 Ọjọ́ yẹn gan-an ni Fáráò pàṣẹ fún àwọn tó ń kó wọn ṣiṣẹ́ àti àwọn olórí wọn pé: 7 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fún àwọn èèyàn náà ní pòròpórò mọ́ láti fi ṣe bíríkì.+ Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ máa wá a fúnra wọn. 8 Àmọ́ ẹ gbọ́dọ̀ rí i pé iye bíríkì tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni wọ́n ṣì ń ṣe. Ẹ ò gbọ́dọ̀ dín in kù, torí wọ́n ti ń dẹwọ́.* Ìyẹn ni wọ́n ṣe ń pariwo pé, ‘A fẹ́ máa lọ, a fẹ́ lọ rúbọ sí Ọlọ́run wa!’ 9 Ẹ jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ṣiṣẹ́ kára, ẹ sì jẹ́ kí ọwọ́ wọn dí kí wọ́n má bàa fetí sí irọ́.”
10 Torí náà, àwọn tó ń kó wọn ṣiṣẹ́+ àti àwọn olórí wọn lọ bá àwọn èèyàn náà pé: “Ohun tí Fáráò sọ nìyí, ‘Mi ò ní fún yín ní pòròpórò kankan mọ́. 11 Ẹ lọ máa wá pòròpórò tí ẹ máa lò fúnra yín níbikíbi tí ẹ bá ti lè rí i, àmọ́ iṣẹ́ yín ò ní dín kù rárá.’” 12 Àwọn èèyàn náà wá fọ́n káàkiri gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì láti wá pòròpórò tí wọ́n máa lò dípò èyí tí wọ́n ń fún wọn tẹ́lẹ̀. 13 Àwọn tó ń kó wọn ṣiṣẹ́ sì ń sọ fún wọn pé: “Kálukú yín gbọ́dọ̀ máa parí iṣẹ́ rẹ̀ lójoojúmọ́, bí ìgbà tí à ń fún yín ní pòròpórò tẹ́lẹ̀.” 14 Bákan náà, wọ́n lu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Fáráò fi ṣe olórí.+ Wọ́n bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí iye bíríkì tí ẹ ṣe kò tó iye tí ẹ máa ń ṣe tẹ́lẹ̀? Ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lánàá, ó tún ṣẹlẹ̀ lónìí.”
15 Àwọn olórí láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá lọ bá Fáráò, wọ́n sì ń ṣàròyé pé: “Kí ló dé tí ò ń ṣe àwa ìránṣẹ́ rẹ báyìí? 16 Wọn ò fún àwa ìránṣẹ́ rẹ ní pòròpórò, síbẹ̀ wọ́n ń sọ fún wa pé, ‘Ẹ máa ṣe bíríkì!’ Wọ́n lu àwa ìránṣẹ́ rẹ, àmọ́ àwọn èèyàn rẹ ló lẹ̀bi.” 17 Àmọ́ ó fèsì pé: “Ẹ ti ń dẹwọ́,* ẹ ti ń dẹwọ́!*+ Torí ẹ̀ lẹ ṣe ń sọ pé, ‘A fẹ́ máa lọ, a fẹ́ lọ rúbọ sí Jèhófà.’+ 18 Ó yá, ẹ pa dà sẹ́nu iṣẹ́! Ẹ ò ní rí pòròpórò kankan gbà mọ́, àmọ́ ẹ ṣì gbọ́dọ̀ máa ṣe iye bíríkì tó yẹ kí ẹ ṣe.”
19 Àwọn olórí láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá rí i pé àwọn ti wọ wàhálà, torí àṣẹ tí Fáráò pa pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dín iye bíríkì tí ẹ̀ ń ṣe lójúmọ́ kù rárá.” 20 Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ bá Mósè àti Áárónì, tí wọ́n ń dúró dè wọ́n kí wọ́n lè pàdé wọn bí wọ́n ṣe ń jáde lọ́dọ̀ Fáráò. 21 Ni wọ́n bá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: “Kí Jèhófà bojú wò yín kó sì ṣèdájọ́, torí ẹ ti mú kí Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kórìíra wa,* ẹ sì ti fi idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa wá.”+ 22 Mósè bá yíjú sí Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jèhófà, kí ló dé tí o fìyà jẹ àwọn èèyàn yìí? Kí nìdí tí o fi rán mi? 23 Látìgbà tí mo ti lọ bá Fáráò, tí mo sì sọ̀rọ̀ lórúkọ rẹ+ ló ti túbọ̀ ń fìyà jẹ àwọn èèyàn yìí,+ o ò sì gba àwọn èèyàn rẹ sílẹ̀ rárá.”+
6 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ní báyìí, wàá rí ohun tí màá ṣe sí Fáráò.+ Ọwọ́ agbára ló máa mú kó fi wọ́n sílẹ̀, ọwọ́ agbára ló sì máa mú kó lé wọn kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.”+
2 Ọlọ́run wá sọ fún Mósè pé: “Èmi ni Jèhófà. 3 Mo ti máa ń fara han Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè,+ àmọ́ ní ti orúkọ mi Jèhófà,+ mi ò jẹ́ kí wọ́n fi mọ̀ mí.+ 4 Mo tún bá wọn dá májẹ̀mú pé màá fún wọn ní ilẹ̀ Kénáánì, ilẹ̀ tí wọ́n gbé bí àjèjì.+ 5 Èmi fúnra mi ti gbọ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń kérora, àwọn tí àwọn ará Íjíbítì fi ń ṣẹrú, mo sì rántí májẹ̀mú mi.+
6 “Torí náà, sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Èmi ni Jèhófà, màá mú yín kúrò lábẹ́ àjàgà àwọn ará Íjíbítì, màá sì gbà yín sílẹ̀ lóko ẹrú.+ Màá fi apá mi tí mo nà jáde* àti àwọn ìdájọ́ tó rinlẹ̀ gbà yín pa dà.+ 7 Màá mú yín bí èèyàn mi, màá sì di Ọlọ́run yín.+ Ó dájú pé ẹ ó mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín tó mú yín kúrò lábẹ́ àjàgà àwọn ará Íjíbítì. 8 Màá mú yín wá sí ilẹ̀ tí mo búra* pé màá fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù; màá sì mú kó di ohun ìní yín.+ Èmi ni Jèhófà.’”+
9 Nígbà tó yá, Mósè jíṣẹ́ yìí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ wọn ò fetí sí Mósè torí wọ́n ti rẹ̀wẹ̀sì àti pé ìyà ń jẹ wọ́n gan-an lóko ẹrú.+
10 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 11 “Wọlé lọ bá Fáráò ọba Íjíbítì, kí o sì sọ fún un pé kó jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.” 12 Àmọ́ Mósè sọ fún Jèhófà pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò fetí sí mi;+ ṣé Fáráò ló máa wá fetí sí mi, èmi tí mi ò lè sọ̀rọ̀ dáadáa?”*+ 13 Àmọ́ Jèhófà tún sọ fún Mósè àti Áárónì nípa àṣẹ tí wọ́n máa pa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Fáráò ọba Íjíbítì, kí wọ́n lè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní ilẹ̀ Íjíbítì.
14 Àwọn olórí agbo ilé àwọn bàbá wọn nìyí: Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àkọ́bí Ísírẹ́lì+ ni Hánókù, Pálù, Hésírónì àti Kámì.+ Àwọn ni ìdílé Rúbẹ́nì.
15 Àwọn ọmọ Síméónì ni Jémúélì, Jámínì, Óhádì, Jákínì, Sóhárì àti Ṣéọ́lù ọmọ obìnrin ará Kénáánì.+ Àwọn ni ìdílé Síméónì.
16 Orúkọ àwọn ọmọ Léfì+ nìyí, gẹ́gẹ́ bí ìlà ìdílé wọn: Gẹ́ṣónì, Kóhátì àti Mérárì.+ Ọjọ́ ayé Léfì jẹ́ ọdún mẹ́tàdínlógóje (137).
17 Àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì ni Líbínì àti Ṣíméì, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.+
18 Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámúrámù, Ísárì, Hébúrónì àti Úsíélì.+ Ọjọ́ ayé Kóhátì jẹ́ ọdún mẹ́tàléláàádóje (133).
19 Àwọn ọmọ Mérárì ni Máhílì àti Múṣì.
Ìdílé àwọn ọmọ Léfì nìyí, gẹ́gẹ́ bí ìlà ìdílé wọn.+
20 Ámúrámù wá fi Jókébédì àbúrò bàbá rẹ̀ ṣe aya.+ Jókébédì sì bí Áárónì àti Mósè fún un.+ Ọjọ́ ayé Ámúrámù jẹ́ ọdún mẹ́tàdínlógóje (137).
21 Àwọn ọmọ Ísárì ni Kórà,+ Néfégì àti Síkírì.
22 Àwọn ọmọ Úsíélì ni Míṣáẹ́lì, Élísáfánì+ àti Sítírì.
23 Áárónì wá fi Élíṣébà, ọmọ Ámínádábù, arábìnrin Náṣónì+ ṣe aya. Ó bí Nádábù, Ábíhù, Élíásárì àti Ítámárì+ fún un.
24 Àwọn ọmọ Kórà ni Ásírì, Ẹlikénà àti Ábíásáfù.+ Ìdílé àwọn ọmọ Kórà+ nìyí.
25 Élíásárì+ ọmọ Áárónì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Pútíélì ṣe aya. Ó bí Fíníhásì fún un.+
Àwọn ni olórí agbo ilé bàbá àwọn ọmọ Léfì, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.+
26 Áárónì àti Mósè yìí ni Jèhófà sọ fún pé: “Ẹ mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní àwùjọ-àwùjọ.”*+ 27 Àwọn ló bá Fáráò ọba Íjíbítì sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì. Mósè àti Áárónì+ yìí kan náà ni.
28 Ní ọjọ́ tí Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ nílẹ̀ Íjíbítì, 29 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Èmi ni Jèhófà. Sọ gbogbo ohun tí mò ń sọ fún ọ fún Fáráò ọba Íjíbítì.” 30 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: “Wò ó! Mi ò lè sọ̀rọ̀ dáadáa,* ṣé Fáráò á wá fetí sí mi?”+
7 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Wò ó, mo ti mú kí o dà bí Ọlọ́run* fún Fáráò, Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ yóò sì di wòlíì rẹ.+ 2 Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ, Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ ló máa bá Fáráò sọ̀rọ̀, á sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. 3 Ní tèmi, màá jẹ́ kí ọkàn Fáráò le,+ màá sì ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tó pọ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 4 Àmọ́ Fáráò ò ní fetí sí yín. Ọwọ́ mi yóò tẹ Íjíbítì, màá sì fi ìdájọ́ tó rinlẹ̀ mú ogunlọ́gọ̀ mi,* ìyẹn àwọn èèyàn mi, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní ilẹ̀ náà.+ 5 Ó sì dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà+ nígbà tí mo bá na ọwọ́ mi láti bá Íjíbítì jà, tí mo sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò láàárín wọn.” 6 Mósè àti Áárónì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. 7 Ẹni ọgọ́rin (80) ọdún ni Mósè, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83) sì ni Áárónì nígbà tí wọ́n bá Fáráò sọ̀rọ̀.+
8 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 9 “Tí Fáráò bá sọ fún yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu,’ kí o sọ fún Áárónì pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ, kí o sì jù ú sílẹ̀ níwájú Fáráò.’ Ọ̀pá náà yóò di ejò ńlá.”+ 10 Mósè àti Áárónì wọlé lọ bá Fáráò, wọ́n sì ṣe ohun tí Jèhófà pàṣẹ fún wọn gẹ́lẹ́. Áárónì ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò ńlá. 11 Ni Fáráò bá ránṣẹ́ pe àwọn amòye àti àwọn oníṣẹ́ oṣó. Àwọn àlùfáà onídán ní Íjíbítì+ pẹ̀lú sì fi agbára* wọn ṣe ohun kan náà.+ 12 Kálukú wọn ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, àwọn ọ̀pá náà sì di ejò ńlá; àmọ́ ọ̀pá Áárónì gbé àwọn ọ̀pá wọn mì. 13 Síbẹ̀, ọkàn Fáráò le,+ kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.
14 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Fáráò ò yí ọkàn rẹ̀ pa dà.+ Kò gbà kí àwọn èèyàn náà lọ. 15 Lọ bá Fáráò ní àárọ̀. Wò ó! Ó ń lọ sí odò! Kí o lọ dúró sétí odò Náílì láti pàdé rẹ̀, kí o sì mú ọ̀pá tó di ejò náà dání.+ 16 Kí o sọ fún un pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù rán mi sí ọ,+ ó ní: “Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ kí wọ́n lè lọ sìn mí ní aginjù,” àmọ́ o ò gbọ́ tèmi títí di báyìí. 17 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ohun tí wàá fi mọ̀ pé èmi ni Jèhófà+ nìyí. Màá fi ọ̀pá ọwọ́ mi lu omi odò Náílì, á sì di ẹ̀jẹ̀. 18 Àwọn ẹja inú odò Náílì yóò kú, odò Náílì yóò máa rùn, àwọn ará Íjíbítì ò sì ní lè mu omi odò Náílì rárá.”’”
19 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ, kí o sì na ọwọ́ rẹ sórí omi Íjíbítì,+ sórí àwọn odò rẹ̀, àwọn omi tó ń ṣàn láti ibẹ̀,* àwọn irà rẹ̀+ àti gbogbo adágún omi rẹ̀, kí wọ́n lè di ẹ̀jẹ̀.’ Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, títí kan inú àwọn ọpọ́n onígi àtèyí tí wọ́n fi òkúta ṣe.” 20 Lójú ẹsẹ̀, Mósè àti Áárónì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ gẹ́lẹ́. Ó na ọ̀pá náà sókè, ó sì fi lu omi odò Náílì níṣojú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, gbogbo omi odò náà sì di ẹ̀jẹ̀.+ 21 Àwọn ẹja inú odò náà kú,+ odò náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rùn, àwọn ará Íjíbítì kò wá lè mu omi odò Náílì,+ ẹ̀jẹ̀ sì wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.
22 Síbẹ̀, àwọn àlùfáà onídán ní Íjíbítì fi agbára òkùnkùn wọn ṣe ohun kan náà,+ ìyẹn sì mú kí ọkàn Fáráò túbọ̀ le, kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.+ 23 Fáráò wá pa dà sí ilé rẹ̀, kò sì ka ọ̀rọ̀ yìí sí pẹ̀lú. 24 Gbogbo àwọn ará Íjíbítì wá ń gbẹ́lẹ̀ kiri yí odò Náílì ká kí wọ́n lè rí omi mu, torí wọn ò lè mu omi odò Náílì rárá. 25 Ọjọ́ méje gbáko sì kọjá lẹ́yìn tí Jèhófà lu odò Náílì.
8 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Wọlé lọ bá Fáráò, kí o sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ kí wọ́n lè lọ sìn mí.+ 2 Tí o bá kọ̀ jálẹ̀, tí o ò jẹ́ kí wọ́n lọ, màá mú kí àkèré bo gbogbo ilẹ̀ rẹ.+ 3 Àkèré yóò kún inú odò Náílì, wọ́n á jáde wá látinú odò, wọ́n á sì wọnú ilé rẹ àti yàrá rẹ, wọ́n á gun ibùsùn rẹ, wọ́n á wọ ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ, wọ́n á bo àwọn èèyàn rẹ, wọ́n á wọnú àwọn ààrò rẹ àti àwọn ọpọ́n* tí o fi ń po nǹkan.+ 4 Àkèré yóò bo ìwọ, àwọn èèyàn rẹ àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ.”’”
5 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì pé, ‘Na ọ̀pá ọwọ́ rẹ sórí àwọn odò, àwọn ipa odò Náílì àti àwọn irà, kí o sì mú kí àkèré bo ilẹ̀ Íjíbítì.’” 6 Áárónì wá na ọwọ́ rẹ̀ sórí àwọn omi Íjíbítì, àwọn àkèré sì bẹ̀rẹ̀ sí í jáde, wọ́n sì bo ilẹ̀ Íjíbítì. 7 Àmọ́ àwọn àlùfáà onídán fi agbára òkùnkùn wọn ṣe ohun kan náà, àwọn náà mú kí àkèré jáde sórí ilẹ̀ Íjíbítì.+ 8 Fáráò wá pe Mósè àti Áárónì, ó sì sọ pé: “Ẹ bẹ Jèhófà pé kó mú àwọn àkèré náà kúrò lọ́dọ̀ èmi àti àwọn èèyàn mi,+ torí mo fẹ́ yọ̀ǹda àwọn èèyàn náà kí wọ́n máa lọ kí wọ́n lè rúbọ sí Jèhófà.” 9 Mósè sọ fún Fáráò pé: “Mo fún ọ láǹfààní láti sọ ìgbà tí o fẹ́ kí n bẹ̀bẹ̀ pé kí àwọn àkèré náà kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn èèyàn rẹ àti nínú àwọn ilé rẹ. Inú odò Náílì nìkan ni wọ́n á ṣẹ́ kù sí.” 10 Ó fèsì pé: “Ní ọ̀la.” Ó wá sọ pé: “Bí o ṣe sọ ló máa rí, kí o lè mọ̀ pé kò sẹ́ni tó dà bíi Jèhófà Ọlọ́run wa.+ 11 Àwọn àkèré náà máa kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nínú àwọn ilé rẹ, lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn èèyàn rẹ. Inú odò Náílì nìkan ni wọ́n á ṣẹ́ kù sí.”+
12 Mósè àti Áárónì wá kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, Mósè sì bẹ Jèhófà nítorí àwọn àkèré tó mú kó bo Fáráò.+ 13 Jèhófà sì ṣe ohun tí Mósè béèrè. Àwọn àkèré tó wà nínú ilé, nínú àwọn àgbàlá àti nínú oko sì bẹ̀rẹ̀ sí í kú. 14 Wọ́n wá ń kó wọn jọ pelemọ, òkìtì wọn ò sì lóǹkà, ilẹ̀ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rùn. 15 Nígbà tí Fáráò rí i pé ìtura dé, ó tún mú ọkàn rẹ̀ le,+ kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.
16 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì pé, ‘Na ọ̀pá rẹ, kí o lu erùpẹ̀, yóò sì di kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.’” 17 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Áárónì na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì fi lu erùpẹ̀, àwọn kòkòrò náà wá bo èèyàn àti ẹranko. Gbogbo erùpẹ̀ di kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+ 18 Àwọn àlùfáà onídán náà gbìyànjú láti ṣe ohun kan náà, wọ́n fẹ́ fi agbára òkùnkùn wọn mú kòkòrò jáde,+ àmọ́ wọn ò rí i ṣe. Àwọn kòkòrò náà bo èèyàn àti ẹranko. 19 Torí náà, àwọn àlùfáà onídán sọ fún Fáráò pé: “Ìka Ọlọ́run nìyí!”+ Àmọ́ ọkàn Fáráò ṣì le, kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.
20 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Dìde ní àárọ̀ kùtù, kí o lọ dúró de Fáráò. Wò ó! Ó ń jáde bọ̀ wá sí odò! Kí o sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ kí wọ́n lè lọ sìn mí. 21 Àmọ́ tí o ò bá jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ, màá mú kí eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ bo ìwọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn èèyàn rẹ, wọ́n á sì wọnú àwọn ilé rẹ; eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ yóò kún àwọn ilé Íjíbítì, wọ́n á sì bo ilẹ̀ tí wọ́n* dúró sí. 22 Ní ọjọ́ yẹn, ó dájú pé màá ya ilẹ̀ Góṣénì sọ́tọ̀, níbi tí àwọn èèyàn mi ń gbé. Eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ kankan ò ní sí níbẹ̀;+ èyí á sì jẹ́ kí o mọ̀ pé èmi Jèhófà wà ní ilẹ̀ yìí.+ 23 Màá fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn èèyàn mi àti àwọn èèyàn rẹ. Iṣẹ́ àmì yìí máa ṣẹlẹ̀ lọ́la.”’”
24 Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya bo ilé Fáráò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+ Àwọn eṣinṣin náà run ilẹ̀ náà.+ 25 Níkẹyìn, Fáráò pe Mósè àti Áárónì, ó sì sọ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ rúbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.” 26 Àmọ́ Mósè sọ pé: “Kò tọ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀, torí àwọn ará Íjíbítì máa kórìíra ohun tí a fẹ́ fi rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa.+ Tí a bá fi ohun tí àwọn ará Íjíbítì kórìíra rúbọ níṣojú wọn, ṣé wọn ò ní sọ wá lókùúta? 27 A máa rin ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sí aginjù, ibẹ̀ la sì ti máa rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa bó ṣe ní ká ṣe gẹ́lẹ́.”+
28 Ni Fáráò bá sọ pé: “Màá jẹ́ kí ẹ lọ rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run yín nínú aginjù. Àmọ́, ẹ má lọ jìnnà o. Ẹ bá mi bẹ̀ ẹ́.”+ 29 Mósè wá sọ pé: “Màá kúrò lọ́dọ̀ rẹ báyìí, màá bá ọ bẹ Jèhófà, àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ náà yóò sì kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́la. Àmọ́ kí Fáráò má ṣe tún tàn wá* mọ́, kó má sọ pé òun ò ní gbà kí àwọn èèyàn náà lọ rúbọ sí Jèhófà.”+ 30 Mósè wá kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, ó sì bẹ Jèhófà.+ 31 Jèhófà ṣe ohun tí Mósè sọ, àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ náà sì kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀ láìku ẹyọ kan. 32 Àmọ́ Fáráò tún mú kí ọkàn rẹ̀ le, kò sì jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ.
9 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Wọlé lọ bá Fáráò, kí o sì sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ nìyí: “Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ kí wọ́n lè sìn mí.+ 2 Àmọ́ tí o ò bá jẹ́ kí wọ́n lọ, tí o sì ń dá wọn dúró, 3 wò ó! ọwọ́ Jèhófà+ máa kọ lu àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ nínú oko. Àjàkálẹ̀ àrùn tó le gan-an+ yóò run àwọn ẹṣin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ràkúnmí, ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran. 4 Ó dájú pé Jèhófà yóò fi ìyàtọ̀ sáàárín ẹran ọ̀sìn Ísírẹ́lì àti ẹran ọ̀sìn Íjíbítì, ìkankan ò sì ní kú nínú ẹran tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”’”+ 5 Jèhófà sì dá ìgbà tó máa ṣe é, ó ní: “Ọ̀la ni Jèhófà yóò ṣe é ní ilẹ̀ yìí.”
6 Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ kejì, gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ará Íjíbítì lóríṣiríṣi sì bẹ̀rẹ̀ sí í kú,+ àmọ́ ìkankan nínú ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò kú. 7 Nígbà tí Fáráò ṣe ìwádìí, wò ó! ìkankan ò kú nínú ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, Fáráò ò yí ọkàn rẹ̀ pa dà, kò sì jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ.+
8 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: “Ẹ fi ọwọ́ méjèèjì bu ẹ̀kúnwọ́ eérú* níbi ààrò, kí Mósè sì fọ́n ọn sínú afẹ́fẹ́ níṣojú Fáráò. 9 Ó máa di eruku lórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, á sì di eéwo tó ń ṣọyún lára èèyàn àti ẹranko ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.”
10 Torí náà, wọ́n bu eérú níbi ààrò, wọ́n sì dúró níwájú Fáráò, Mósè wá fọ́n ọn sínú afẹ́fẹ́, ó sì di eéwo tó ń ṣọyún lára èèyàn àti ẹranko. 11 Àwọn àlùfáà onídán kò lè dúró níwájú Mósè torí eéwo náà, torí eéwo ti bo àwọn àlùfáà náà àti gbogbo ará Íjíbítì.+ 12 Àmọ́ Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le, kò sì fetí sí wọn, bí Jèhófà ṣe sọ fún Mósè.+
13 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Dìde ní àárọ̀ kùtù, kí o lọ dúró níwájú Fáráò, kí o sì sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ nìyí: “Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ, kí wọ́n lè sìn mí. 14 Torí èmi yóò fi gbogbo ìyọnu látọ̀dọ̀ mi kọ lu ọkàn rẹ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn èèyàn rẹ, kí o lè mọ̀ pé kò sí ẹlòmíì bí èmi ní gbogbo ayé.+ 15 Mi ò bá ti na ọwọ́ mi kí n lè fi àjàkálẹ̀ àrùn tó le gan-an kọ lu ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ, kí n sì pa ọ́ rẹ́* kúrò ní ayé. 16 Àmọ́ ìdí tí mo fi dá ẹ̀mí rẹ sí ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a sì lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.+ 17 O ò ka àwọn èèyàn mi sí, o ò jẹ́ kí wọ́n lọ, àbí? 18 Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rọ òjò yìnyín tó pọ̀, irú èyí tí kò tíì wáyé rí ní Íjíbítì láti ọjọ́ tó ti wà títí di báyìí. 19 Torí náà, ní kí wọ́n kó gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti gbogbo ohun tó jẹ́ tìrẹ nínú oko wọlé. Gbogbo èèyàn àti ẹranko tó bá wà nínú oko, tí wọn ò kó wọlé ló máa kú tí yìnyín bá bọ́ lù wọ́n.”’”
20 Àwọn tó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Jèhófà nínú àwọn ìránṣẹ́ Fáráò yára mú àwọn ìránṣẹ́ wọn àtàwọn ẹran ọ̀sìn wọn wọnú ilé, 21 àmọ́ àwọn tí kò ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí fi àwọn ìránṣẹ́ wọn àtàwọn ẹran ọ̀sìn wọn sílẹ̀ nínú oko.
22 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sí ọ̀run, kí yìnyín lè rọ̀ sórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì,+ sórí èèyàn àti ẹranko àti gbogbo ewéko ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 23 Mósè wá na ọ̀pá rẹ̀ sí ọ̀run, Jèhófà sì mú kí ààrá sán, yìnyín bọ́, iná* sọ̀ kalẹ̀, Jèhófà sì ń mú kí òjò yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀ Íjíbítì. 24 Yìnyín bọ́, iná sì ń kọ mànà láàárín yìnyín náà. Yìnyín náà pọ̀ gan-an; kò sí irú rẹ̀ rí nílẹ̀ náà látìgbà tí Íjíbítì ti di orílẹ̀-èdè.+ 25 Yìnyín náà bọ́ lu gbogbo ohun tó wà nínú oko ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, látorí èèyàn dórí ẹranko, ó run gbogbo ewéko, ó sì run gbogbo igi oko.+ 26 Ilẹ̀ Góṣénì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nìkan ni yìnyín náà ò dé.+
27 Fáráò wá ránṣẹ́ pe Mósè àti Áárónì, ó sì sọ fún wọn pé: “Mo ti ṣẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí. Olódodo ni Jèhófà, èmi àti àwọn èèyàn mi la jẹ̀bi. 28 Ẹ bẹ Jèhófà pé kí ààrá àti yìnyín látọ̀dọ̀ Ọlọ́run dáwọ́ dúró. Lẹ́yìn náà, màá jẹ́ kí ẹ lọ, mi ò sì ní dá yín dúró mọ́.” 29 Mósè wá sọ fún un pé: “Gbàrà tí mo bá ti kúrò nílùú, màá tẹ́wọ́ síwájú Jèhófà. Ààrá náà yóò dáwọ́ dúró, yìnyín náà ò sì ní rọ̀ mọ́, kí o lè mọ̀ pé Jèhófà ló ni ayé.+ 30 Àmọ́ mo mọ̀ pé, síbẹ̀, ìwọ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ò ní bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run.”
31 Ọ̀gbọ̀ àti ọkà bálì ti run, torí pé ọkà bálì wà nínú ṣírí, ọ̀gbọ̀ sì ti yọ òdòdó. 32 Àmọ́ kò sóhun tó ṣe àlìkámà* àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì torí wọ́n máa ń pẹ́ so.* 33 Mósè wá kúrò nínú ìlú lọ́dọ̀ Fáráò, ó sì tẹ́wọ́ síwájú Jèhófà, ààrá àti yìnyín náà wá dáwọ́ dúró, òjò tó ń rọ̀ náà sì dáwọ́ dúró.+ 34 Nígbà tí Fáráò rí i pé òjò, yìnyín àti ààrá ti dáwọ́ dúró, ló bá tún ṣẹ̀, ó sì mú kí ọkàn rẹ̀ le,+ òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 35 Fáráò ò yí ọkàn rẹ̀ pa dà, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ, bí Jèhófà ṣe gbẹnu Mósè sọ.+
10 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Wọlé lọ bá Fáráò, torí mo ti jẹ́ kí ọkàn òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ le,+ kí n lè ṣe àwọn iṣẹ́ àmì mi níwájú rẹ̀,+ 2 kí o sì lè sọ fún àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ bí mo ṣe fìyà jẹ Íjíbítì tó àti àwọn ohun tí mo ṣe sí wọn;+ ó sì dájú pé ẹ ó mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”
3 Mósè àti Áárónì wá wọlé lọ bá Fáráò, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ nìyí, ‘O ò rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi, ìgbà wo lo fẹ́ ṣèyí dà?+ Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ, kí wọ́n lè sìn mí. 4 Torí tí o ò bá jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ, màá mú kí eéṣú wọ ilẹ̀ rẹ ní ọ̀la. 5 Wọ́n á bo ilẹ̀ débi pé ilẹ̀ ò ní ṣeé rí. Wọ́n á jẹ ohun tó ṣẹ́ kù fún yín ní àjẹrun, èyí tí òjò yìnyín ṣẹ́ kù, wọ́n á sì jẹ gbogbo igi tó ń hù nínú oko run.+ 6 Wọ́n á kún inú ilé rẹ, ilé gbogbo ìránṣẹ́ rẹ àti gbogbo ilé tó wà ní Íjíbítì dé ìwọ̀n tí àwọn bàbá rẹ àti àwọn baba ńlá rẹ kò tíì rí láti ọjọ́ tí wọ́n ti wà nílẹ̀ yìí títí dòní.’”+ Ni Mósè bá yíjú pa dà, ó sì kúrò lọ́dọ̀ Fáráò.
7 Àwọn ìránṣẹ́ Fáráò wá sọ fún un pé: “Ìgbà wo ni ọkùnrin yìí fẹ́ ṣèyí dà, tí yóò máa kó wa sínú ewu?* Jẹ́ kí àwọn èèyàn náà máa lọ kí wọ́n lè sin Jèhófà Ọlọ́run wọn. Ṣé o ò rí i pé Íjíbítì ti run tán ni?” 8 Wọ́n wá mú Mósè àti Áárónì pa dà wá sọ́dọ̀ Fáráò, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ, kí ẹ lọ sin Jèhófà Ọlọ́run yín. Àmọ́ àwọn wo gan-an ló ń lọ?” 9 Ni Mósè bá sọ pé: “Tọmọdé tàgbà wa ló máa lọ, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àwọn àgùntàn wa àti àwọn màlúù wa,+ torí a máa ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà.”+ 10 Ó sọ fún wọn pé: “Tí mo bá jẹ́ kí ẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín lọ, á jẹ́ pé Jèhófà wà pẹ̀lú yín lóòótọ́!+ Ó ṣe kedere pé nǹkan burúkú kan wà lọ́kàn yín tí ẹ fẹ́ ṣe. 11 Mi ò gbà! Àwọn ọkúnrin yín nìkan ni kó lọ sin Jèhófà, torí ohun tí ẹ béèrè nìyẹn.” Ni wọ́n bá lé wọn kúrò níwájú Fáráò.
12 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sórí ilẹ̀ Íjíbítì kí àwọn eéṣú lè jáde, kí wọ́n bo ilẹ̀ Íjíbítì, kí wọ́n sì run gbogbo ewéko ilẹ̀ náà tán, gbogbo ohun tí òjò yìnyín ṣẹ́ kù.” 13 Ni Mósè bá na ọ̀pá rẹ̀ sórí ilẹ̀ Íjíbítì, Jèhófà sì mú kí atẹ́gùn fẹ́ wá láti ìlà oòrùn sí ilẹ̀ náà lọ́jọ́ yẹn tọ̀sántòru. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, atẹ́gùn tó fẹ́ wá láti ìlà oòrùn gbé àwọn eéṣú wá. 14 Àwọn eéṣú náà kún gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n sì bo gbogbo agbègbè Íjíbítì.+ Wọ́n ṣọṣẹ́ gan-an;+ eéṣú ò tíì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí, wọn ò sì ní pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ mọ́ láé. 15 Wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ náà, wọ́n sì mú kí ilẹ̀ náà ṣókùnkùn. Wọ́n jẹ gbogbo ewéko ilẹ̀ náà run àti gbogbo èso igi tí òjò yìnyín ṣẹ́ kù; kò sí ewé kankan lórí àwọn igi tàbí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.
16 Ni Fáráò bá yára pe Mósè àti Áárónì, ó sì sọ pé: “Mo ti ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín, mo sì ti ṣẹ̀ yín. 17 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ dárí jì mí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo yìí, kí ẹ sì bẹ Jèhófà Ọlọ́run yín pé kó mú ìyọnu ńlá yìí kúrò lórí mi.” 18 Ó* wá kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, ó sì bẹ Jèhófà.+ 19 Jèhófà sì mú kí atẹ́gùn náà ṣẹ́rí pa dà, ó wá ń fẹ́ lọ sí ìwọ̀ oòrùn, atẹ́gùn náà sì le gan-an. Ó gbé àwọn eéṣú náà lọ, ó sì gbá wọn sínú Òkun Pupa. Eéṣú kankan ò ṣẹ́ kù ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 20 Síbẹ̀, Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le,+ kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.
21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sí ọ̀run, kí òkùnkùn lè bo ilẹ̀ Íjíbítì, òkùnkùn tó máa ṣú biribiri débi pé á fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣeé fọwọ́ bà.” 22 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè na ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì fún ọjọ́ mẹ́ta.+ 23 Wọn ò rí ara wọn, ìkankan nínú wọn ò sì kúrò níbi tó wà fún ọjọ́ mẹ́ta; àmọ́ ìmọ́lẹ̀ wà níbi tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé.+ 24 Fáráò wá pe Mósè, ó sì sọ pé: “Ẹ lọ sin Jèhófà.+ Àwọn àgùntàn àti màlúù yín nìkan ni ẹ ò ní kó lọ. Àwọn ọmọ yín pàápàá lè bá yín lọ.” 25 Àmọ́ Mósè sọ pé: “Ìwọ náà máa fún wa ní* ohun tí a máa fi rúbọ àti èyí tí a máa fi rú ẹbọ sísun, a ó sì fi rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa.+ 26 Àwọn ẹran ọ̀sìn wa náà máa bá wa lọ. A ò ní jẹ́ kí ẹran* kankan ṣẹ́ kù, torí a máa lò lára wọn láti jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run wa, a ò sì mọ ohun tí a máa fi rúbọ sí Jèhófà àfi tí a bá débẹ̀.” 27 Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le, kò sì gbà kí wọ́n lọ.+ 28 Fáráò sọ fún Mósè pé: “Kúrò níwájú mi! O ò gbọ́dọ̀ tún fi ojú kàn mí mọ́, torí ọjọ́ tí o bá fi ojú kàn mí ni wàá kú.” 29 Mósè wá fèsì pé: “Bí o ṣe sọ, mi ò ní fojú kàn ọ́ mọ́.”
11 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ó ku ìyọnu kan tí màá mú wá sórí Fáráò àti Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, ó máa jẹ́ kí ẹ kúrò níbí.+ Ṣe ló máa lé yín kúrò níbí nígbà tó bá gbà pé kí ẹ máa lọ.+ 2 Torí náà, sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí gbogbo ọkùnrin àti obìnrin béèrè àwọn nǹkan tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe lọ́wọ́ ọmọnìkejì wọn.”+ 3 Jèhófà sì jẹ́ kí àwọn èèyàn náà rí ojúure àwọn ará Íjíbítì. Mósè fúnra rẹ̀ ti wá di ẹni ńlá nílẹ̀ Íjíbítì lójú àwọn ìránṣẹ́ Fáráò àti àwọn èèyàn náà.
4 Mósè wá sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Tó bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ọ̀gànjọ́ òru, màá lọ sí àárín Íjíbítì,+ 5 gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì yóò sì kú,+ látorí àkọ́bí Fáráò tó wà lórí ìtẹ́ dórí àkọ́bí ẹrúbìnrin tó ń lọ nǹkan lórí ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn.+ 6 Igbe ẹkún máa pọ̀ gan-an ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí, irú ẹ̀ ò sì ní ṣẹlẹ̀ mọ́.+ 7 Àmọ́, ajá ò tiẹ̀ ní gbó* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àti ẹran ọ̀sìn wọn, kí ẹ lè mọ̀ pé Jèhófà lè fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’+ 8 Ó dájú pé gbogbo ìránṣẹ́ rẹ yóò wá bá mi, wọ́n á wólẹ̀ fún mi, wọ́n á sì sọ pé, ‘Máa lọ, ìwọ àti gbogbo èèyàn tó ń tẹ̀ lé ọ.’+ Lẹ́yìn náà, èmi yóò lọ.” Ló bá fi ìbínú kúrò níwájú Fáráò.
9 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Fáráò ò ní fetí sí yín,+ kí iṣẹ́ ìyanu mi lè pọ̀ sí i nílẹ̀ Íjíbítì.”+ 10 Mósè àti Áárónì ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu yìí níwájú Fáráò,+ àmọ́ Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.+
12 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì ní ilẹ̀ Íjíbítì pé: 2 “Oṣù yìí ni yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn oṣù fún yín. Òun ni yóò jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ fún yín nínú ọdún.+ 3 Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Lọ́jọ́ kẹwàá oṣù yìí, kí kálukú wọn mú àgùntàn kan+ fún ilé bàbá wọn, àgùntàn kan fún ilé kan. 4 Àmọ́ tí àgùntàn kan bá ti pọ̀ jù fún agbo ilé náà, kí àwọn àti aládùúgbò wọn* tó múlé tì wọ́n jọ pín in nínú ilé wọn, kí wọ́n pín in sí iye èèyàn* tí wọ́n jẹ́. Kí ẹ ṣírò iye ẹran àgùntàn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa jẹ. 5 Kí ara àgùntàn yín dá ṣáṣá,+ kó jẹ́ akọ, ọlọ́dún kan. Ẹ lè mú lára àwọn ọmọ àgbò tàbí àwọn ewúrẹ́. 6 Kí ẹ máa tọ́jú rẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí,+ kí gbogbo àpéjọ* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pa á ní ìrọ̀lẹ́.*+ 7 Kí wọ́n mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì wọ́n ọn sára òpó méjèèjì ilẹ̀kùn àti apá òkè ẹnu ọ̀nà àwọn ilé tí wọ́n ti jẹ ẹ́.+
8 “‘Kí wọ́n jẹ ẹran náà lálẹ́ yìí.+ Kí wọ́n yan án lórí iná, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú+ àti ewébẹ̀ kíkorò.+ 9 Ẹ má jẹ ẹ́ ní tútù tàbí ní bíbọ̀, ẹ má fi omi sè é, àmọ́ ẹ yan án lórí iná, ẹ yan orí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ àti àwọn nǹkan inú rẹ̀. 10 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ìkankan lára rẹ̀ kù di àárọ̀, àmọ́ tí ìkankan lára rẹ̀ bá ṣẹ́ kù di àárọ̀, kí ẹ fi iná sun ún.+ 11 Bí ẹ ó ṣe jẹ ẹ́ nìyí, ẹ di àmùrè,* ẹ wọ bàtà, kí ẹ mú ọ̀pá yín dání; kí ẹ sì yára jẹ ẹ́. Ìrékọjá Jèhófà ni. 12 Torí màá lọ káàkiri ilẹ̀ Íjíbítì lálẹ́ yìí, màá sì pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì, látorí èèyàn dórí ẹranko;+ màá sì dá gbogbo ọlọ́run Íjíbítì lẹ́jọ́.+ Èmi ni Jèhófà. 13 Ẹ̀jẹ̀ náà yóò jẹ́ àmì yín lára àwọn ilé tí ẹ wà; èmi yóò rí ẹ̀jẹ̀ náà, èmi yóò sì ré yín kọjá, ìyọnu náà ò sì ní pa yín run nígbà tí mo bá kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì.+
14 “‘Kí ẹ máa rántí ọjọ́ yìí, kí ẹ sì máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀, kó jẹ́ àjọyọ̀ sí Jèhófà jálẹ̀ àwọn ìran yín. Ẹ máa pa àjọyọ̀ náà mọ́, ó ti di òfin fún yín títí láé. 15 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú.+ Lọ́jọ́ kìíní, kí ẹ mú àpòrọ́ kíkan kúrò ní ilé yín, kí ẹ pa ẹni* tó bá jẹ ohun tó ní ìwúkàrà* láti ọjọ́ kìíní títí dé ìkeje ní Ísírẹ́lì. 16 Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣe àpéjọ mímọ́ míì ní ọjọ́ keje. Ẹ má ṣe iṣẹ́ kankan ní àwọn ọjọ́ yìí.+ Ohun tí ẹnì* kọ̀ọ̀kan máa jẹ nìkan ni kí wọ́n sè.
17 “‘Kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ torí ní ọjọ́ yìí gangan, èmi yóò mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ* yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Kí ẹ máa pa ọjọ́ yìí mọ́ jálẹ̀ àwọn ìran yín, ó ti di òfin fún yín títí láé. 18 Kí ẹ jẹ búrẹ́dì aláìwú láti alẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní títí di alẹ́ ọjọ́ kọkànlélógún oṣù náà.+ 19 Kò gbọ́dọ̀ sí àpòrọ́ kíkan nínú ilé yín rárá fún ọjọ́ méje, torí tí ẹnikẹ́ni bá jẹ ohun tó ní ìwúkàrà, yálà àjèjì tàbí ọmọ ìbílẹ̀,+ kí ẹ pa* ẹni* yẹn kúrò nínú àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 20 Ẹ má jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà. Búrẹ́dì aláìwú ni kí ẹ jẹ ní gbogbo ilé yín.’”
21 Mósè yára pe gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ mú àwọn ọmọ ẹran* fún ìdílé yín níkọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pa ẹran tí ẹ máa fi rúbọ nígbà Ìrékọjá. 22 Kí ẹ wá ki ìdìpọ̀ ewéko hísópù bọnú ẹ̀jẹ̀ tó wà nínú bàsíà, kí ẹ sì wọ́n ọn sí apá òkè ẹnu ọ̀nà àti sára òpó méjèèjì ilẹ̀kùn náà; kí ẹnì kankan nínú yín má sì jáde ní ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀ títí di àárọ̀. 23 Tí Jèhófà bá wá kọjá kó lè fi ìyọnu kọ lu àwọn ará Íjíbítì, tó sì rí ẹ̀jẹ̀ náà ní apá òkè ẹnu ọ̀nà àti lára òpó rẹ̀ méjèèjì, ó dájú pé Jèhófà yóò ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí ìyọnu ikú* wọnú ilé yín.+
24 “Kí ẹ máa pa àjọ̀dún yìí mọ́, ó ti di àṣẹ fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín títí láé.+ 25 Tí ẹ bá sì dé ilẹ̀ tí Jèhófà yóò fún yín bó ṣe sọ, kí ẹ máa ṣe àjọyọ̀ yìí.+ 26 Tí àwọn ọmọ yín bá sì bi yín pé, ‘Kí nìdí tí ẹ fi ń ṣe àjọyọ̀ yìí?’+ 27 kí ẹ sọ pé, ‘Ẹbọ Ìrékọjá sí Jèhófà ni, ẹni tó ré ilé àwa ọmọ Ísírẹ́lì kọjá ní Íjíbítì nígbà tó fi ìyọnu kọ lu àwọn ará Íjíbítì, tó sì dá ilé wa sí.’”
Àwọn èèyàn náà tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀. 28 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè àti Áárónì.+ Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
29 Nígbà tó di ọ̀gànjọ́ òru, Jèhófà pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì,+ látorí àkọ́bí Fáráò tó wà lórí ìtẹ́ dórí àkọ́bí ẹni tó wà lẹ́wọ̀n* àti gbogbo àkọ́bí ẹranko.+ 30 Fáráò dìde ní òru yẹn, òun àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará Íjíbítì yòókù, igbe ẹkún ńlá sì sọ láàárín àwọn ará Íjíbítì, torí kò sí ilé kankan tí èèyàn ò ti kú.+ 31 Ló bá pe Mósè àti Áárónì+ ní òru, ó sì sọ pé: “Ẹ gbéra, ẹ kúrò láàárín àwọn èèyàn mi, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. Ẹ lọ sin Jèhófà bí ẹ ṣe sọ.+ 32 Kí ẹ kó àwọn agbo ẹran yín àti ọ̀wọ́ ẹran yín, kí ẹ sì lọ bí ẹ ṣe sọ.+ Àmọ́ kí ẹ súre fún mi.”
33 Àwọn ará Íjíbítì wá ń rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n tètè kúrò ní ilẹ̀ náà.+ Wọ́n sọ pé, “Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, gbogbo wa la máa kú!”+ 34 Torí náà, àwọn èèyàn náà gbé àpòrọ́ ìyẹ̀fun wọn tí kò ní ìwúkàrà, wọ́n fi aṣọ wé ọpọ́n* tí wọ́n fi ń po nǹkan, wọ́n sì gbé e lé èjìká. 35 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí Mósè sọ fún wọn, wọ́n béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti wúrà pẹ̀lú aṣọ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì.+ 36 Jèhófà mú kí àwọn èèyàn náà rí ojú rere àwọn ará Íjíbítì, wọ́n fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè, wọ́n sì gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.+
37 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá kúrò ní Rámésésì,+ wọ́n sì forí lé Súkótù,+ wọ́n tó nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkùnrin tó ń fẹsẹ̀ rìn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọdé.+ 38 Oríṣiríṣi èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ*+ ló tún bá wọn lọ, pẹ̀lú àwọn agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹran ọ̀sìn. 39 Wọ́n wá ń fi àpòrọ́ tí wọ́n mú kúrò ní Íjíbítì ṣe búrẹ́dì aláìwú tó rí ribiti. Kò ní ìwúkàrà, torí ṣe ni wọ́n lé wọn kúrò ní Íjíbítì lójijì débi pé wọn ò ráyè ṣètò oúnjẹ kankan fún ara wọn.+
40 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tó gbé ní Íjíbítì,+ ti lo ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún.+ 41 Ní ọjọ́ yìí tí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún pé ni gbogbo èèyàn Jèhófà tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. 42 Òru yẹn ni wọ́n á ṣe àjọyọ̀ torí pé Jèhófà mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Kí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì máa pa òru ọjọ́ yìí mọ́ jálẹ̀ àwọn ìran wọn láti bọlá fún Jèhófà.+
43 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé, “Àṣẹ tí ẹ ó máa tẹ̀ lé nígbà Ìrékọjá nìyí: Àjèjì kankan ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.+ 44 Àmọ́ tí ẹnì kan bá ní ẹrú tó jẹ́ ọkùnrin, tó fi owó rà, kí o dádọ̀dọ́ rẹ̀.*+ Ìgbà yẹn ló tó lè jẹ nínú rẹ̀. 45 Ẹni tó wá gbé láàárín yín àti alágbàṣe kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀. 46 Inú ilé kan ni kí ẹ ti jẹ ẹ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú ìkankan nínú ẹran náà kúrò nínú ilé lọ síta, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fọ́ ìkankan nínú egungun rẹ̀.+ 47 Kí gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ayẹyẹ yìí. 48 Tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín, tó sì fẹ́ ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá láti bọlá fún Jèhófà, kí gbogbo ọkùnrin ilé rẹ̀ dádọ̀dọ́.* Ìgbà yẹn ló lè ṣe ayẹyẹ náà, yóò sì dà bí ọmọ ìbílẹ̀. Àmọ́ aláìdádọ̀dọ́* ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.+ 49 Òfin kan náà ni kí ọmọ ìbílẹ̀ àti àjèjì tó ń gbé láàárín yín máa tẹ̀ lé.”+
50 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè àti Áárónì. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. 51 Ọjọ́ yìí gan-an ni Jèhófà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.
13 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 2 “Ya gbogbo àkọ́bí ọkùnrin* nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí mímọ́* fún mi. Tèmi ni àkọ́bí yín lọ́kùnrin àti àkọ́bí ẹran yín tó jẹ́ akọ.”+
3 Mósè wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ máa rántí ọjọ́ yìí tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ ní ilé ẹrú, torí ọwọ́ agbára ni Jèhófà fi mú yín kúrò níbí.+ Torí náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà. 4 Òní yìí, nínú oṣù Ábíbù* lẹ máa kúrò.+ 5 Tí Jèhófà bá ti mú yín dé ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá yín pé òun máa fún yín,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ kí ẹ máa ṣe ayẹyẹ yìí ní oṣù yìí. 6 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú,+ ẹ ó sì ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà ní ọjọ́ keje. 7 Búrẹ́dì aláìwú ni kí ẹ jẹ fún ọjọ́ méje náà;+ ohunkóhun tó bá ní ìwúkàrà ò gbọ́dọ̀ sí lọ́wọ́ yín,+ kò sì gbọ́dọ̀ sí àpòrọ́ kíkan lọ́wọ́ yín ní gbogbo ilẹ̀* yín. 8 Kí ẹ sì sọ fún ọmọ yín ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Torí ohun tí Jèhófà ṣe fún mi nígbà tí mo kúrò ní Íjíbítì ni.’+ 9 Yóò jẹ́ àmì fún yín lára ọwọ́ yín àti ìrántí ní iwájú orí* yín,+ kí òfin Jèhófà bàa lè wà ní ẹnu yín, torí ọwọ́ agbára ni Jèhófà fi mú yín kúrò ní Íjíbítì. 10 Kí ẹ máa pa òfin yìí mọ́ ní àkókò rẹ̀ lọ́dọọdún.+
11 “Tí Jèhófà bá ti mú yín dé ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, ilẹ̀ tó búra nípa rẹ̀ fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín pé òun máa fún yín,+ 12 kí ẹ ya gbogbo àkọ́bí ọkùnrin* sọ́tọ̀ fún Jèhófà, pẹ̀lú gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn yín tó jẹ́ akọ. Jèhófà ló ni àwọn akọ.+ 13 Kí ẹ fi àgùntàn ra gbogbo àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pa dà, tí ẹ ò bá sì rà á pa dà, kí ẹ ṣẹ́ ọrùn rẹ̀. Kí ẹ sì ra gbogbo àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin yín pa dà.+
14 “Ní ọjọ́ iwájú, tí ọmọ yín bá bi yín pé, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ kí ẹ sọ fún un pé, ‘Ọwọ́ agbára ni Jèhófà fi mú wa kúrò ní Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.+ 15 Nígbà tí Fáráò ń ṣe orí kunkun, tí kò jẹ́ ká lọ,+ Jèhófà pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì, látorí àkọ́bí èèyàn dórí àkọ́bí ẹranko.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń fi gbogbo akọ tó jẹ́ àkọ́bí nínú ẹran ọ̀sìn* rúbọ sí Jèhófà, tí mo sì ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin mi pa dà.’ 16 Kí èyí jẹ́ àmì lára ọwọ́ yín àti aṣọ ìwérí ní iwájú orí*+ yín, torí ọwọ́ agbára ni Jèhófà fi mú wa kúrò ní Íjíbítì.”
17 Nígbà tí Fáráò ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, Ọlọ́run ò darí wọn gba ọ̀nà ilẹ̀ àwọn Filísínì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wà nítòsí, torí Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn èèyàn náà lè yí èrò pa dà tí wọ́n bá gbógun jà wọ́n, wọ́n á sì pa dà sí Íjíbítì.” 18 Torí náà, Ọlọ́run mú kí àwọn èèyàn náà lọ yí gba ọ̀nà aginjù tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun Pupa.+ Ṣe ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ nígbà tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. 19 Mósè kó àwọn egungun Jósẹ́fù dání, torí Jósẹ́fù ti mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi òótọ́ inú búra pé: “Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé yín. Kí ẹ kó egungun mi dání kúrò níbí.”+ 20 Wọ́n kúrò ní Súkótù, wọ́n sì pàgọ́ sí Étámù létí aginjù.
21 Ní ọ̀sán, Jèhófà máa ń lọ níwájú wọn nínú ọwọ̀n ìkùukùu* kó lè máa darí wọn lójú ọ̀nà,+ àmọ́ ní òru, ó máa ń lọ níwájú wọn nínú ọwọ̀n iná* kó lè fún wọn ní ìmọ́lẹ̀, kí wọ́n lè máa bá ìrìn àjò wọn lọ tọ̀sántòru.+ 22 Ọwọ̀n ìkùukùu* náà kì í kúrò níwájú àwọn èèyàn náà lọ́sàn-án, ọwọ̀n iná kì í sì í kúrò lóru.+
14 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣẹ́rí pa dà, kí wọ́n sì pàgọ́ síwájú Píháhírótì, láàárín Mígídólì àti òkun, níbi tí wọ́n á ti máa rí Baali-séfónì lọ́ọ̀ọ́kán.+ Kí ẹ pàgọ́ síbi tó dojú kọ ọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun. 3 Fáráò yóò wá sọ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ṣe ni wọ́n ń rìn gbéregbère káàkiri ilẹ̀. Wọ́n ti há sí aginjù.’ 4 Màá jẹ́ kí ọkàn Fáráò le,+ ó máa lépa wọn, màá sì ṣe ara mi lógo nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀.+ Ó dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”+ Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn.
5 Nígbà tó yá, wọ́n ròyìn fún ọba Íjíbítì pé àwọn èèyàn náà ti sá lọ. Lójú ẹsẹ̀, Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yí ọkàn pa dà nípa àwọn èèyàn náà,+ wọ́n sì sọ pé: “Kí la ṣe yìí, kí ló dé tí a yọ̀ǹda àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe ẹrú wa mọ́?” 6 Ló bá múra àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì kó àwọn èèyàn rẹ̀ dání.+ 7 Ó yan ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó dáa, ó sì kó wọn dání pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin yòókù ní Íjíbítì, jagunjagun sì wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. 8 Bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí ọkàn Fáráò ọba Íjíbítì le nìyẹn, ó sì ń lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì balẹ̀* bí wọ́n ṣe ń lọ.+ 9 Àwọn ará Íjíbítì wá ń lépa wọn,+ gbogbo ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ Fáráò àti àwọn agẹṣin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ lé wọn bá nígbà tí wọ́n pàgọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun, nítòsí Píháhírótì, tí wọ́n ti dojú kọ Baali-séfónì.
10 Nígbà tí Fáráò ń sún mọ́ tòsí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wòkè, wọ́n sì rí i pé àwọn ará Íjíbítì ń lépa wọn. Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà.+ 11 Wọ́n sọ fún Mósè pé: “Ṣé torí kò sí ibi ìsìnkú ní Íjíbítì lo ṣe mú wa wá sínú aginjù ká lè kú síbí?+ Kí ló dé tí o mú wa kúrò ní Íjíbítì? 12 Ṣebí ohun tí a sọ fún ọ ní Íjíbítì ni pé, ‘Fi wá sílẹ̀, ká lè máa sin àwọn ará Íjíbítì’? Torí ó sàn ká máa sin àwọn ará Íjíbítì ju ká wá kú sí aginjù.”+ 13 Mósè wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ má bẹ̀rù.+ Ẹ dúró gbọn-in, kí ẹ sì rí bí Jèhófà ṣe máa gbà yín là lónìí.+ Torí àwọn ará Íjíbítì tí ẹ rí lónìí yìí, ẹ ò ní rí wọn mọ́ láé.+ 14 Jèhófà fúnra rẹ̀ máa jà fún yín,+ ẹ ó sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.”
15 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ké pè mí? Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n tú àgọ́ wọn ká. 16 Ní tìrẹ, mú ọ̀pá rẹ, kí o na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí o sì pín in níyà, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gba orí ilẹ̀ kọjá láàárín òkun. 17 Ní tèmi, màá jẹ́ kí ọkàn àwọn ará Íjíbítì le, kí wọ́n lè lépa wọn wọnú òkun, kí n sì ṣe ara mi lógo nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣin rẹ̀.+ 18 Ó dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá tipasẹ̀ Fáráò, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣin rẹ̀ ṣe ara mi lógo.”+
19 Áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́+ tó ń lọ níwájú àwùjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò níwájú, ó sì bọ́ sí ẹ̀yìn wọn, ọwọ̀n ìkùukùu* tó wà níwájú wọn wá bọ́ sí ẹ̀yìn wọn, ó sì dúró síbẹ̀.+ 20 Ó wà láàárín àwùjọ àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Ó mú kí òkùnkùn ṣú lápá kan. Àmọ́ lápá kejì, ó mú kí ìmọ́lẹ̀ wà ní òru yẹn.+ Torí náà, àwùjọ kìíní ò dé ọ̀dọ̀ àwùjọ kejì ní gbogbo òru yẹn.
21 Ni Mósè bá na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun;+ Jèhófà sì mú kí atẹ́gùn líle fẹ́ wá láti ìlà oòrùn ní gbogbo òru yẹn, ó sì bi òkun náà sẹ́yìn. Ó mú kí ìsàlẹ̀ òkun di ilẹ̀ gbígbẹ,+ omi náà sì pínyà.+ 22 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá gba orí ilẹ̀ kọjá láàárín òkun,+ omi náà sì dà bí ògiri ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì wọn.+ 23 Àwọn ará Íjíbítì ń lé wọn, gbogbo ẹṣin Fáráò, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣin rẹ̀ sì tẹ̀ lé wọn wọ àárín òkun.+ 24 Nígbà ìṣọ́ òwúrọ̀,* Jèhófà wo àwùjọ àwọn ará Íjíbítì látinú ọwọ̀n iná* àti ìkùukùu,+ ó sì mú kí àwùjọ àwọn ará Íjíbítì dà rú. 25 Ó ń mú kí àgbá kẹ̀kẹ́ yọ kúrò lára àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn, ìyẹn sì ń mú kó nira fún wọn láti wa àwọn kẹ̀kẹ́ náà, àwọn ará Íjíbítì sì ń sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ ká fọwọ́ kan Ísírẹ́lì rárá o, torí Jèhófà ń gbèjà wọn, ó sì ń bá àwa ọmọ Íjíbítì jà.”+
26 Ni Jèhófà bá sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí omi náà lè pa dà, kó sì bo àwọn ará Íjíbítì, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti àwọn agẹṣin wọn.” 27 Ni Mósè bá na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun, bí ilẹ̀ sì ṣe ń mọ́ bọ̀, òkun náà pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Bí àwọn ará Íjíbítì ṣe ń sá pa dà, Jèhófà bi àwọn ará Íjíbítì ṣubú sáàárín òkun.+ 28 Omi náà rọ́ pa dà, ó sì bo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn agẹṣin àti gbogbo ọmọ ogun Fáráò tó lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọnú òkun.+ Kò sí ìkankan nínú wọn tó yè é.+
29 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba orí ilẹ̀ kọjá láàárín òkun,+ omi náà sì dà bí ògiri ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì wọn.+ 30 Bí Jèhófà ṣe gba Ísírẹ́lì là lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì lọ́jọ́ yẹn nìyẹn,+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rí òkú àwọn ará Íjíbítì ní etíkun. 31 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún rí agbára* ńlá tí Jèhófà fi bá àwọn ará Íjíbítì jà, àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù Jèhófà, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀.+
15 Nígbà yẹn, Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ orin yìí sí Jèhófà:+
“Jẹ́ kí n kọrin sí Jèhófà, torí ó ti di ẹni àgbéga.+
Ó taari ẹṣin àti ẹni tó gùn ún sínú òkun.+
2 Jáà* ni okun àti agbára mi, torí ó ti wá gbà mí là.+
Ọlọ́run mi nìyí, màá yìn ín;+ Ọlọ́run bàbá mi,+ màá gbé e ga.+
3 Jagunjagun tó lágbára ni Jèhófà.+ Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.+
4 Ó ti ju àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sínú òkun,+
Àwọn tó dára jù nínú àwọn jagunjagun rẹ̀ sì ti rì sínú Òkun Pupa.+
5 Alagbalúgbú omi bò wọ́n; wọ́n rì sí ìsàlẹ̀ ibú omi bí òkúta.+
6 Ọwọ́ ọ̀tún rẹ mà lágbára o, Jèhófà;+
Jèhófà, ọwọ́ ọ̀tún rẹ lè fọ́ ọ̀tá túútúú.
7 Nínú ọlá ńlá rẹ, o lè bi àwọn tó bá dìde sí ọ ṣubú;+
O mú kí ìbínú rẹ tó ń jó fòfò jẹ wọ́n run bí àgékù pòròpórò.
8 Èémí tó ti ihò imú rẹ jáde mú kí omi wọ́ jọ;
Omi náà dúró, kò pa dà;
Alagbalúgbú omi dì láàárín òkun.
9 Ọ̀tá sọ pé: ‘Màá lépa wọn! Màá lé wọn bá!
Màá pín ẹrù ogun wọn títí yóò fi tẹ́ mi* lọ́rùn!
Màá fa idà mi yọ! Ọwọ́ mi yóò ṣẹ́gun wọn!’+
10 O fẹ́ èémí rẹ jáde, òkun sì bò wọ́n;+
Wọ́n rì sínú alagbalúgbú omi bí òjé.
11 Jèhófà, ta ló dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run?+
Ta ló dà bí rẹ, ìwọ tí o fi hàn pé ẹni mímọ́ jù lọ ni ọ́?+
Ẹni tó yẹ ká máa bẹ̀rù, ká máa fi orin yìn, Ẹni tó ń ṣe ohun ìyanu.+
12 O na ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ilẹ̀ sì gbé wọn mì.+
13 O fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ṣamọ̀nà àwọn èèyàn tí o rà pa dà;+
Ìwọ yóò fi agbára rẹ darí wọn lọ sí ibùgbé rẹ mímọ́.
14 Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ gbọ́,+ jìnnìjìnnì á bò wọ́n;
Àwọn tó ń gbé Filísíà máa jẹ̀rora.*
15 Ní àkókò yẹn, ẹ̀rù yóò ba àwọn séríkí* Édómù,
Àwọn alágbára tó ń ṣàkóso Móábù* yóò gbọ̀n rìrì.+
Ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé ní Kénáánì yóò domi.+
16 Ìbẹ̀rù àti jìnnìjìnnì yóò bò wọ́n.+
Ọwọ́ ńlá rẹ yóò mú kí wọ́n dúró sójú kan bí òkúta
Títí àwọn èèyàn rẹ yóò fi kọjá, Jèhófà,
Títí àwọn èèyàn tí o mú jáde+ yóò fi kọjá.+
17 Ìwọ yóò mú wọn wá, ìwọ yóò sì gbìn wọ́n sí òkè ogún rẹ,+
Ibi tó fìdí múlẹ̀ tí o ti pèsè kí ìwọ fúnra rẹ lè máa gbé, Jèhófà,
Ibi mímọ́ tí o fi ọwọ́ rẹ ṣe, Jèhófà.
18 Jèhófà yóò máa jọba títí láé àti láéláé.+
19 Nígbà tí àwọn ẹṣin Fáráò àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣin rẹ̀ wọnú òkun,+
Jèhófà mú kí omi òkun pa dà, ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀,+
Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba orí ilẹ̀ kọjá láàárín òkun.”+
20 Míríámù wòlíì obìnrin, ẹ̀gbọ́n Áárónì wá mú ìlù tanboríìnì, gbogbo obìnrin sì ń jó tẹ̀ lé e pẹ̀lú ìlù tanboríìnì. 21 Míríámù fi orin dá àwọn ọkùnrin lóhùn pé:
“Ẹ kọrin sí Jèhófà, torí ó ti di ẹni àgbéga.+
Ó taari ẹṣin àti ẹni tó gùn ún sínú òkun.”+
22 Lẹ́yìn náà, Mósè darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Òkun Pupa, wọ́n sì lọ sí aginjù Ṣúrì. Wọ́n rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní aginjù, àmọ́ wọn ò rí omi. 23 Wọ́n dé Márà,*+ àmọ́ wọn ò lè mu omi tó wà ní Márà torí ó korò. Ìdí nìyẹn tó fi pè é ní Márà. 24 Àwọn èèyàn náà wá ń kùn sí Mósè+ pé: “Kí la máa mu báyìí?” 25 Ó bá ké pe Jèhófà,+ Jèhófà sì darí rẹ̀ síbi igi kan. Nígbà tó jù ú sínú omi, omi náà wá dùn.
Ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé òfin àti ìlànà ìdájọ́ kalẹ̀ fún wọn, Ó sì dán wọn wò níbẹ̀.+ 26 Ó sọ pé: “Tí ẹ bá ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín délẹ̀délẹ̀, tí ẹ ṣe ohun tó tọ́ ní ojú rẹ̀, tí ẹ pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ń tẹ̀ lé gbogbo ìlànà rẹ̀,+ mi ò ní mú kí ìkankan ṣe yín nínú àwọn àrùn tí mo mú kó ṣe àwọn ará Íjíbítì,+ torí èmi Jèhófà ló ń mú yín lára dá.”+
27 Lẹ́yìn náà, wọ́n dé Élímù, níbi tí ìsun omi méjìlá (12) àti àádọ́rin (70) igi ọ̀pẹ wà. Wọ́n sì pàgọ́ síbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi náà.
16 Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Élímù, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé aginjù Sínì,+ tó wà láàárín Élímù àti Sínáì. Wọ́n dé ibẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kejì tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.
2 Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì ní aginjù.+ 3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sọ fún wọn pé: “Jèhófà ì bá ti kúkú pa wá nílẹ̀ Íjíbítì nígbà tí a jókòó ti ìkòkò ẹran,+ tí à ń jẹun ní àjẹtẹ́rùn. Ẹ wá mú wa wá sínú aginjù yìí kí ebi lè pa gbogbo ìjọ yìí kú.”+
4 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Màá rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run,+ kí kálukú máa jáde lọ kó iye tó máa tó o lójoojúmọ́,+ kí n lè dán wọn wò, kí n sì rí i bóyá wọ́n á pa òfin mi mọ́ tàbí wọn ò ní pa á mọ́.+ 5 Àmọ́ ní ọjọ́ kẹfà,+ nígbà tí wọ́n bá ń ṣètò ohun tí wọ́n kó, kó jẹ́ ìlọ́po méjì ohun tí wọ́n ń kó ní àwọn ọjọ́ tó kù.”+
6 Mósè àti Áárónì wá sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ní alẹ́, ó dájú pé ẹ ó mọ̀ pé Jèhófà ló mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 7 Ní àárọ̀, ẹ máa rí ògo Jèhófà, torí Jèhófà ti gbọ́ bí ẹ ṣe ń kùn sí òun. Ta ni àwa jẹ́ tí ẹ ó fi máa kùn sí wa?” 8 Mósè ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà tí Jèhófà bá fún yín ní ẹran jẹ ní alẹ́, tó sì fún yín ní oúnjẹ ní àárọ̀, tí ẹ jẹ àjẹyó, ẹ máa rí i pé Jèhófà ti gbọ́ bí ẹ ṣe ń kùn sí òun. Ta ni àwa jẹ́? Àwa kọ́ lẹ̀ ń kùn sí, Jèhófà ni.”+
9 Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ wá síwájú Jèhófà, torí ó ti gbọ́ bí ẹ ṣe ń kùn.’”+ 10 Gbàrà tí Áárónì bá gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ tán, wọ́n yíjú pa dà, wọ́n sì dojú kọ aginjù. Wò ó! ògo Jèhófà fara hàn nínú ìkùukùu.*+
11 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 12 “Mo ti gbọ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń kùn.+ Sọ fún wọn pé, ‘Ní ìrọ̀lẹ́,* ẹ ó jẹ ẹran, tó bá sì di àárọ̀, ẹ ó jẹ oúnjẹ ní àjẹyó,+ ó sì dájú pé ẹ ó mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’”+
13 Torí náà, ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, àwọn àparò fò wá, wọ́n sì bo ibi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ sí,+ nígbà tó sì di àárọ̀, ìrì ti sẹ̀ yí ká ibi tí wọ́n pàgọ́ sí. 14 Nígbà tí ìrì náà gbẹ, ohun kan wà lórí ilẹ̀ ní aginjù náà tó rí wínníwínní.+ Ó rí bíi yìnyín tó rọ̀ sórí ilẹ̀. 15 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí nìyí?” torí wọn ò mọ ohun tó jẹ́. Mósè sọ fún wọn pé: “Oúnjẹ tí Jèhófà fún yín pé kí ẹ jẹ ni.+ 16 Àṣẹ Jèhófà ni pé, ‘Kí kálukú kó ìwọ̀n tó lè jẹ. Kí ẹ kó oúnjẹ tó kún òṣùwọ̀n ómérì kan*+ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan bí iye èèyàn* tó wà nínú àgọ́ kálukú yín bá ṣe pọ̀ tó.’” 17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ń ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n ń kó o, àwọn kan kó púpọ̀, àwọn kan sì kó díẹ̀. 18 Nígbà tí wọ́n fi òṣùwọ̀n ómérì wọ̀n ọ́n, kò ṣẹ́ kù lọ́wọ́ ẹni tó kó púpọ̀, kò sì ṣaláìtó fún ẹni tó kó díẹ̀.+ Ohun tí kálukú wọn máa lè jẹ ni wọ́n kó.
19 Mósè wá sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ oúnjẹ náà kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì.”+ 20 Àmọ́ wọn ò fetí sí Mósè. Nígbà tí àwọn kan ṣẹ́ ẹ kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì, oúnjẹ náà ti ń yọ ìdin, ó sì ń rùn. Mósè wá bínú sí wọn. 21 Àràárọ̀ ni wọ́n máa ń kó oúnjẹ náà, ohun tí kálukú bá sì lè jẹ ló máa kó. Tí oòrùn bá ti mú, oúnjẹ náà á yọ́.
22 Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì oúnjẹ náà,+ oúnjẹ tó kún òṣùwọ̀n ómérì méjì fún ẹnì kan. Gbogbo ìjòyè àpéjọ náà wá sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fún Mósè. 23 Mósè sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyẹn. Gbogbo ọ̀la yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi,* yóò jẹ́ sábáàtì mímọ́ fún Jèhófà.+ Ẹ yan ohun tí ẹ bá fẹ́ yan, ẹ se ohun tí ẹ bá fẹ́ sè;+ kí ẹ wá tọ́jú oúnjẹ tó bá ṣẹ́ kù di àárọ̀ ọ̀la.” 24 Wọ́n wá ṣẹ́ ẹ kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì, bí Mósè ṣe pa á láṣẹ. Kò rùn, kò sì yọ ìdin. 25 Mósè wá sọ pé: “Ẹ jẹ ẹ́ lónìí, torí òní jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà. Lónìí, ẹ ò ní rí oúnjẹ kó nílẹ̀. 26 Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ máa fi kó o, àmọ́ ní ọjọ́ keje, ọjọ́ Sábáàtì,+ kò ní sí rárá.” 27 Síbẹ̀, àwọn èèyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje yẹn láti kó oúnjẹ, àmọ́ wọn ò rí ìkankan.
28 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ọjọ́ wo ni ẹ fẹ́ ṣèyí dà, ẹ ò pa àwọn àṣẹ mi àti òfin mi mọ́?+ 29 Ẹ kíyè sí i pé Jèhófà ti fún yín ní Sábáàtì.+ Ìdí nìyẹn tó fi fún yín ní oúnjẹ ọjọ́ méjì ní ọjọ́ kẹfà. Kí kálukú dúró sí ibi tó bá wà; ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ kúrò ní agbègbè rẹ̀ ní ọjọ́ keje.” 30 Àwọn èèyàn náà wá pa Sábáàtì mọ́* ní ọjọ́ keje.+
31 Ilé Ísírẹ́lì pe oúnjẹ náà ní “mánà.”*+ Ó funfun bí irúgbìn kọriáńdà, ó sì dùn bí àkàrà olóyin pẹlẹbẹ. 32 Mósè sì sọ pé: “Àṣẹ tí Jèhófà pa nìyí, ‘Ẹ kó oúnjẹ náà, kó kún òṣùwọ̀n ómérì kan, kí ẹ tọ́jú rẹ̀ jálẹ̀ àwọn ìran yín,+ kí wọ́n lè rí oúnjẹ tí mo fún yín ní aginjù nígbà tí mo mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.’” 33 Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Gbé ìkòkò kan, kí o da mánà tó kún òṣùwọ̀n ómérì kan sínú rẹ̀, kí o sì gbé e síwájú Jèhófà, kí ẹ tọ́jú rẹ̀ jálẹ̀ àwọn ìran yín.”+ 34 Torí náà, Áárónì gbé e síwájú Ẹ̀rí+ kí wọ́n lè tọ́jú rẹ̀ bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún Mósè. 35 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ mánà fún ogójì (40) ọdún,+ títí wọ́n fi dé ilẹ̀ kan tí àwọn èèyàn ń gbé.+ Wọ́n jẹ mánà títí wọ́n fi dé ààlà ilẹ̀ Kénáánì.+ 36 Òṣùwọ̀n ómérì kan jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà.*
17 Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní aginjù Sínì+ láti ibì kan sí ibòmíì bí Jèhófà ṣe pàṣẹ,+ wọ́n sì pàgọ́ sí Réfídímù.+ Àmọ́ àwọn èèyàn náà ò rí omi mu.
2 Àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá Mósè jà,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Fún wa lómi mu.” Àmọ́ Mósè bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń bá mi jà? Kí ló dé tí ẹ̀ ń dán Jèhófà wò?”+ 3 Síbẹ̀ òùngbẹ ń gbẹ àwọn èèyàn náà gan-an níbẹ̀, wọ́n sì ń kùn sí Mósè ṣáá,+ wọ́n ń sọ pé: “Kí ló dé tí o mú wa kúrò ní Íjíbítì kí o lè fi òùngbẹ pa àwa àti àwọn ọmọ wa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa?” 4 Níkẹyìn, Mósè ké pe Jèhófà, ó ní: “Kí ni màá ti ṣe àwọn èèyàn yìí sí? Wọn ò ní pẹ́ sọ mí lókùúta!”
5 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Máa lọ níwájú àwọn èèyàn náà, kí o sì mú lára àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì dání pẹ̀lú ọ̀pá rẹ tí o fi lu odò Náílì.+ Mú un dání kí o sì máa lọ. 6 Wò ó! Èmi yóò dúró níwájú rẹ lórí àpáta tó wà ní Hórébù. Kí o lu àpáta náà, omi yóò jáde látinú rẹ̀, àwọn èèyàn náà á sì mu ún.”+ Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ níṣojú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì. 7 Ó wá pe ibẹ̀ ní Másà*+ àti Mẹ́ríbà,*+ torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá a jà àti pé wọ́n dán Jèhófà wò,+ wọ́n ní: “Ṣé Jèhófà wà láàárín wa àbí kò sí?”
8 Àwọn ọmọ Ámálékì+ wá bá Ísírẹ́lì jà ní Réfídímù.+ 9 Ni Mósè bá sọ fún Jóṣúà+ pé: “Bá wa yan àwọn ọkùnrin, kí o sì lọ bá àwọn ọmọ Ámálékì jà. Ní ọ̀la, màá dúró sórí òkè, màá sì mú ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ dání.” 10 Jóṣúà ṣe ohun tí Mósè sọ fún un,+ ó sì bá àwọn ọmọ Ámálékì jà. Mósè, Áárónì àti Húrì + wá gun òkè náà lọ.
11 Tí ọwọ́ Mósè bá wà lókè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń borí, àmọ́ tó bá ti lè gbé ọwọ́ rẹ̀ wálẹ̀, àwọn ọmọ Ámálékì á máa borí. 12 Nígbà tí ọwọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ro Mósè, wọ́n gbé òkúta kan sábẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé e. Áárónì àti Húrì wá dúró sí ẹ̀gbẹ́ Mósè lọ́tùn-ún àti lósì, wọ́n bá a gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ọwọ́ rẹ̀ sì dúró gbọn-in títí oòrùn fi wọ̀. 13 Bí Jóṣúà ṣe fi idà ṣẹ́gun Ámálékì àti àwọn èèyàn rẹ̀ nìyẹn.+
14 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú ìwé fún ìrántí, kí o sì tún un sọ fún Jóṣúà pé, ‘Màá mú kí wọ́n gbàgbé Ámálékì pátápátá lábẹ́ ọ̀run.’”+ 15 Mósè mọ pẹpẹ kan, ó sì sọ ọ́ ní Jèhófà-nisì,* 16 ó ní: “Torí ó gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Jáà,+ Jèhófà yóò máa gbógun ja Ámálékì láti ìran dé ìran.”+
18 Jẹ́tírò àlùfáà Mídíánì, bàbá ìyàwó Mósè+ gbọ́ nípa gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mósè àti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ èèyàn rẹ̀, bí Jèhófà ṣe mú Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì.+ 2 Jẹ́tírò bàbá ìyàwó Mósè ti mú Sípórà ìyàwó Mósè sọ́dọ̀ nígbà tó ní kó pa dà sọ́dọ̀ Jẹ́tírò, 3 pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì.+ Ọ̀kan ń jẹ́ Gẹ́ṣómù,*+ torí Mósè sọ pé, “mo ti di àjèjì nílẹ̀ òkèèrè.” 4 Èkejì ń jẹ́ Élíésérì,* torí ó sọ pé, “Ọlọ́run bàbá mi ni olùrànlọ́wọ́ mi, ẹni tó gbà mí lọ́wọ́ idà Fáráò.”+
5 Jẹ́tírò, bàbá ìyàwó Mósè, pẹ̀lú àwọn ọmọ Mósè àti ìyàwó rẹ̀ wá bá Mósè ní aginjù níbi tó pàgọ́ sí, ní òkè Ọlọ́run tòótọ́.+ 6 Ó ránṣẹ́ sí Mósè pé: “Èmi, Jẹ́tírò bàbá ìyàwó rẹ+ ń bọ̀ wá bá ọ, pẹ̀lú ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì.” 7 Lójú ẹsẹ̀, Mósè lọ pàdé bàbá ìyàwó rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Wọ́n béèrè àlàáfíà ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́.
8 Mósè sọ fún bàbá ìyàwó rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe sí Fáráò àti Íjíbítì torí Ísírẹ́lì,+ gbogbo ìyà tó jẹ wọ́n lọ́nà+ àti bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n sílẹ̀. 9 Inú Jẹ́tírò dùn torí gbogbo ohun rere tí Jèhófà ṣe fún Ísírẹ́lì, bó ṣe gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní* Íjíbítì. 10 Jẹ́tírò wá sọ pé: “Ẹ yin Jèhófà, ẹni tó gbà yín sílẹ̀ kúrò ní Íjíbítì àti lọ́wọ́ Fáráò, tó sì gba àwọn èèyàn náà kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì. 11 Mo ti wá mọ̀ báyìí pé Jèhófà tóbi ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ+ torí ohun tó ṣe sí àwọn tí kò ka àwọn èèyàn rẹ̀ sí.” 12 Jẹ́tírò bàbá ìyàwó Mósè wá mú ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ míì wá fún Ọlọ́run, Áárónì àti gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì sì bá bàbá ìyàwó Mósè jẹun níwájú Ọlọ́run tòótọ́.
13 Ní ọjọ́ kejì, Mósè jókòó bí ìṣe rẹ̀ láti dá ẹjọ́ fún àwọn èèyàn náà, àwọn èèyàn náà sì dúró níwájú Mósè láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. 14 Nígbà tí bàbá ìyàwó Mósè rí gbogbo ohun tí Mósè ń ṣe fún àwọn èèyàn náà, ó ní: “Kí lò ń ṣe fún àwọn èèyàn yìí? Kí ló dé tí ìwọ nìkan jókòó síbí, tí gbogbo èèyàn dúró síwájú rẹ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀?” 15 Mósè sọ fún bàbá ìyàwó rẹ̀ pé: “Torí pé àwọn èèyàn ń wá sọ́dọ̀ mi kí n lè bá wọn wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run ni. 16 Tí ẹjọ́ kan bá délẹ̀, wọ́n á gbé e wá sọ́dọ̀ mi, màá sì ṣèdájọ́ ẹnì kìíní àti ẹnì kejì, màá jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìpinnu Ọlọ́run tòótọ́ àti àwọn òfin rẹ̀.”+
17 Bàbá ìyàwó Mósè sọ fún un pé: “Ohun tí ò ń ṣe yìí kò dáa. 18 Ó máa tán ìwọ àtàwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ lókun, torí ẹrù yìí ti pọ̀ jù fún ọ, o ò lè dá rù ú. 19 Gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ fún ọ. Jẹ́ kí n gbà ọ́ nímọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.+ Ìwọ máa ṣe aṣojú àwọn èèyàn náà lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́,+ kí o sì máa kó ẹjọ́ náà tọ Ọlọ́run tòótọ́ lọ.+ 20 Kí o kìlọ̀ fún wọn nípa ohun tí àwọn ìlànà àtàwọn òfin sọ,+ kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tí wọ́n á máa rìn àti ohun tí wọ́n á máa ṣe. 21 Àmọ́ kí o yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n nínú àwọn èèyàn náà,+ àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọ́n ṣeé fọkàn tán, tí wọ́n sì kórìíra èrè tí kò tọ́,+ kí o wá fi àwọn yìí ṣe olórí wọn, kí wọ́n jẹ́ olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí mẹ́wàá-mẹ́wàá.+ 22 Kí wọ́n máa dá ẹjọ́ tí àwọn èèyàn náà bá gbé wá.* Kí wọ́n máa gbé gbogbo ẹjọ́ tó bá ṣòroó dá wá sọ́dọ̀ rẹ,+ àmọ́ kí wọ́n máa dá àwọn ẹjọ́ tí kò tó nǹkan. Jẹ́ kí wọ́n bá ọ gbé lára ẹrù yìí kí nǹkan lè rọrùn fún ọ.+ 23 Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, tí Ọlọ́run sì pa á láṣẹ fún ọ, wàá lè gbé ẹrù yìí, gbogbo èèyàn á sì fi ìtẹ́lọ́rùn pa dà sílé wọn.”
24 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè fetí sí ohun tí bàbá ìyàwó rẹ̀ sọ, ó sì ṣe gbogbo ohun tó sọ. 25 Mósè yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n nínú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn èèyàn náà, ó fi wọ́n ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí àwọn mẹ́wàá-mẹ́wàá. 26 Wọ́n ń bá àwọn èèyàn náà dá ẹjọ́ tí wọ́n bá gbé wá. Wọ́n máa ń gbé ẹjọ́ tó bá ṣòroó dá lọ sọ́dọ̀ Mósè,+ àmọ́ wọ́n máa ń dá àwọn ẹjọ́ tí kò tó nǹkan. 27 Lẹ́yìn náà, Mósè sin bàbá ìyàwó rẹ̀ sọ́nà,+ ó sì pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀.
19 Ní ọjọ́ tó pé oṣù mẹ́ta tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n dé aginjù Sínáì. 2 Wọ́n ṣí kúrò ní Réfídímù,+ wọ́n dé aginjù Sínáì, wọ́n sì pàgọ́ sí aginjù náà. Ísírẹ́lì pàgọ́ síbẹ̀ níwájú òkè náà.+
3 Mósè wá gòkè lọ bá Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà sì pè é láti òkè náà+ pé: “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún ilé Jékọ́bù àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, 4 ‘Ẹ ti fojú ara yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Íjíbítì,+ kí n lè fi àwọn ìyẹ́ idì gbé yín wá sọ́dọ̀ ara mi.+ 5 Tí ẹ bá ṣègbọràn sí ohùn mi délẹ̀délẹ̀, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, ó dájú pé ẹ ó di ohun ìní mi pàtàkì* nínú gbogbo èèyàn,+ torí gbogbo ayé jẹ́ tèmi.+ 6 Ẹ ó di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.’+ Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyẹn.”
7 Mósè wá pe àwọn àgbààgbà láàárín àwọn èèyàn náà, ó sì sọ fún wọn nípa gbogbo ọ̀rọ̀ yìí tí Jèhófà pa láṣẹ fún un.+ 8 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn náà fohùn ṣọ̀kan, wọ́n fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ la múra tán láti ṣe.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè mú èsì àwọn èèyàn náà tọ Jèhófà lọ. 9 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! Màá wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìkùukùu* tó ṣú dùdù, kí àwọn èèyàn náà lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì lè tipa bẹ́ẹ̀ máa gba ìwọ náà gbọ́.” Lẹ́yìn náà, Mósè mú èsì àwọn èèyàn náà tọ Jèhófà lọ.
10 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Lọ bá àwọn èèyàn náà, kí o sọ wọ́n di mímọ́ lónìí àti lọ́la, kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn. 11 Kí wọ́n múra sílẹ̀ de ọjọ́ kẹta, torí pé ní ọjọ́ kẹta, Jèhófà yóò sọ̀ kalẹ̀ sórí Òkè Sínáì níṣojú gbogbo àwọn èèyàn náà. 12 Kí o pa ààlà yí òkè náà ká fún àwọn èèyàn náà, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má gun òkè náà, ẹ má sì fara kan ààlà rẹ̀. Ó dájú pé ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkè náà yóò kú. 13 Ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan ẹni náà, ṣe ni kí ẹ sọ ọ́ lókùúta tàbí kí ẹ gún un ní àgúnyọ.* Ẹ ò ní dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, yálà ẹranko ni tàbí èèyàn.’+ Àmọ́ tí ìró ìwo àgbò bá ti dún,+ kí àwọn èèyàn náà wá sí òkè náà.”
14 Lẹ́yìn náà, Mósè sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè, ó sì lọ bá àwọn èèyàn náà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn èèyàn náà di mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn.+ 15 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ múra sílẹ̀ de ọjọ́ kẹta. Ẹ má ṣe ní ìbálòpọ̀.”*
16 Ní àárọ̀ ọjọ́ kẹta, ààrá sán, mànàmáná kọ. Àwọsánmà ṣú+ bo orí òkè, ìró ìwo sì dún sókè gan-an, ẹ̀rù wá ń ba gbogbo àwọn tó wà nínú àgọ́.+ 17 Mósè sì mú àwọn èèyàn náà kúrò nínú àgọ́ láti pàdé Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n dúró ní ìsàlẹ̀ òkè náà. 18 Èéfín ń rú ní gbogbo Òkè Sínáì, torí Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ sórí rẹ̀ nínú iná;+ èéfín rẹ̀ sì ń lọ sókè bíi ti iná ìléru, gbogbo òkè náà sì ń mì tìtì.+ 19 Bí ìró ìwo náà ṣe túbọ̀ ń dún kíkankíkan, Mósè sọ̀rọ̀, Ọlọ́run tòótọ́ sì dá a lóhùn.*
20 Jèhófà wá sọ̀ kalẹ̀ sórí Òkè Sínáì. Lẹ́yìn náà, Jèhófà pe Mósè wá sí orí òkè náà, Mósè sì gòkè lọ.+ 21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ̀ kalẹ̀, kí o lọ kìlọ̀ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n má fi dandan wá ọ̀nà láti wo Jèhófà, kí ọ̀pọ̀ nínú wọn má bàa pa run. 22 Jẹ́ kí àwọn àlùfáà tó ń wá síwájú Jèhófà déédéé sọ ara wọn di mímọ́, kí Jèhófà má bàa pa* wọ́n.”+ 23 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: “Àwọn èèyàn náà ò lè wá sórí Òkè Sínáì, torí o ti kìlọ̀ fún wa tẹ́lẹ̀ pé, ‘Pa ààlà yí òkè náà ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’”+ 24 Àmọ́ Jèhófà sọ fún un pé: “Lọ, sọ̀ kalẹ̀, kí o sì pa dà wá sókè, ìwọ àti Áárónì, àmọ́ má ṣe jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn èèyàn náà fipá gòkè wá sọ́dọ̀ Jèhófà, kó má bàa pa wọ́n.”+ 25 Mósè wá sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn èèyàn náà, ó sì sọ fún wọn.
20 Ọlọ́run wá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, ó ní:+
2 “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.+ 3 O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.*+
4 “O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ tàbí kí o ṣe ohun* kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé tàbí nínú omi nísàlẹ̀.+ 5 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n tàn ọ́ láti sìn wọ́n,+ torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti ìran kẹrin àwọn tó kórìíra mi, 6 àmọ́ tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi títí dé ẹgbẹ̀rún ìran wọn, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.+
7 “O ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò tọ́,+ torí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tó bá lo orúkọ Rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́.+
8 “Máa rántí ọjọ́ Sábáàtì, kí o lè yà á sí mímọ́.+ 9 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi ṣiṣẹ́, kí o sì fi ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,+ 10 àmọ́ ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti ẹran ọ̀sìn rẹ àti àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.*+ 11 Torí ọjọ́ mẹ́fà ni Jèhófà fi dá ọ̀run àti ayé, òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sinmi ní ọjọ́ keje.+ Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bù kún ọjọ́ Sábáàtì, tó sì yà á sí mímọ́.
12 “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,+ kí ẹ̀mí rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.+
13 “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.+
15 “O ò gbọ́dọ̀ jalè.+
16 “O ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì rẹ.+
17 “O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ilé ọmọnìkejì rẹ wọ̀ ọ́ lójú. Ojú rẹ ò sì gbọ́dọ̀ wọ ìyàwó ọmọnìkejì rẹ+ tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.”+
18 Gbogbo àwọn èèyàn náà ń rí ààrá tó ń sán àti mànàmáná tó ń kọ yẹ̀rì, wọ́n ń gbọ́ ìró ìwo, wọ́n sì ń rí òkè tó ń yọ èéfín; àwọn ohun tí wọ́n rí yìí bà wọ́n lẹ́rù, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n wá dúró ní òkèèrè.+ 19 Torí náà, wọ́n sọ fún Mósè pé: “Ìwọ ni kí o máa bá wa sọ̀rọ̀, a ó sì fetí sílẹ̀. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run bá wa sọ̀rọ̀ ká má bàa kú.”+ 20 Mósè wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ má bẹ̀rù, torí ṣe ni Ọlọ́run tòótọ́ wá dán yín wò,+ kí ẹ lè máa bẹ̀rù rẹ̀ kí ẹ má bàa ṣẹ̀.”+ 21 Àwọn èèyàn náà ò kúrò ní ọ̀ọ́kán níbi tí wọ́n dúró sí, àmọ́ Mósè sún mọ́ ìkùukùu* tó ṣú dùdù náà níbi tí Ọlọ́run tòótọ́ wà.+
22 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Ẹ̀yin fúnra yín rí i pé láti ọ̀run ni mo ti bá yín sọ̀rọ̀.+ 23 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run fàdákà láti máa sìn wọ́n pẹ̀lú mi, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run wúrà fún ara yín.+ 24 Fi erùpẹ̀ mọ pẹpẹ fún mi, kí o sì rú àwọn ẹbọ sísun rẹ lórí rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀* rẹ, agbo ẹran rẹ àti ọ̀wọ́ ẹran rẹ. Gbogbo ibi tí mo bá ti mú kí wọ́n rántí orúkọ mi+ ni màá ti wá bá ọ, tí màá sì bù kún ọ. 25 Tí o bá fi òkúta ṣe pẹpẹ fún mi, o ò gbọ́dọ̀ lo òkúta tí o fi irinṣẹ́ gbẹ́.*+ Torí tí o bá lo irinṣẹ́* rẹ lára rẹ̀, wàá sọ ọ́ di aláìmọ́. 26 O ò sì gbọ́dọ̀ fi àtẹ̀gùn gun pẹpẹ mi, kí abẹ́* rẹ má bàa hàn lórí rẹ̀.’
21 “Àwọn ìdájọ́ tí wàá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa rẹ̀ nìyí:+
2 “Tí o bá ra Hébérù kan ní ẹrú,+ kí ó sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà, àmọ́ ní ọdún keje, kí o dá a sílẹ̀ láìgba ohunkóhun.+ 3 Tó bá jẹ́ pé òun nìkan ló wá, òun nìkan ni yóò pa dà. Tó bá ní ìyàwó, kí ìyàwó rẹ̀ bá a lọ. 4 Tó bá jẹ́ pé ọ̀gá rẹ̀ ló fún un ní ìyàwó, tí obìnrin náà sì bí àwọn ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin fún un, obìnrin náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò di ti ọ̀gá rẹ̀, ọkùnrin náà nìkan ni yóò lọ.+ 5 Àmọ́ tí ẹrú náà ò bá gbà láti lọ, tó sì sọ pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá mi, ìyàwó mi àti àwọn ọmọ mi; mi ò fẹ́ kí ọ̀gá mi dá mi sílẹ̀,’+ 6 kí ọ̀gá rẹ̀ mú un wá síwájú Ọlọ́run tòótọ́. Kó wá mú ọkùnrin náà wá síbi ilẹ̀kùn tàbí férémù ilẹ̀kùn, kí ọ̀gá rẹ̀ sì fi òòlu* lu etí rẹ̀, yóò sì di ẹrú rẹ̀ títí láé.
7 “Tí ọkùnrin kan bá ta ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹrú, ọ̀gá rẹ̀ ò ní dá a sílẹ̀ bí wọ́n ti ń ṣe fún ọkùnrin tó jẹ́ ẹrú. 8 Tí inú ọ̀gá obìnrin náà ò bá dùn sí i, tí kò sì fi ṣe wáhàrì,* àmọ́ tó mú kí ẹlòmíì rà á,* kò ní lẹ́tọ̀ọ́ láti tà á fún àwọn àjèjì, torí ó ti da obìnrin náà. 9 Tó bá fún ọmọkùnrin rẹ̀ ní obìnrin náà pé kó fi ṣe aya, kó fún obìnrin náà ní ẹ̀tọ́ tó yẹ ọmọbìnrin. 10 Tó bá fẹ́ ìyàwó míì, oúnjẹ, aṣọ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó+ àkọ́kọ́ ò gbọ́dọ̀ dín kù. 11 Tí kò bá fún un ní nǹkan mẹ́ta yìí, kí obìnrin náà lọ lọ́fẹ̀ẹ́, láìsan owó.
12 “Tí ẹnì kan bá lu èèyàn pa, kí ẹ pa onítọ̀hún.+ 13 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé kò mọ̀ọ́mọ̀ pa á, tí Ọlọ́run tòótọ́ sì fàyè gbà á, màá yan ibì kan fún ọ tó lè sá lọ.+ 14 Tí ẹnì kan bá bínú gidigidi sí ọmọnìkejì rẹ̀, tó sì mọ̀ọ́mọ̀ pa á,+ kí ẹ pa onítọ̀hún, ì báà jẹ́ ibi pẹpẹ mi lo ti máa wá mú un.+ 15 Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá lu bàbá tàbí ìyá rẹ̀.+
16 “Kí ẹ pa+ ẹnikẹ́ni tó bá jí èèyàn gbé+ tó sì tà á tàbí tí wọ́n ká a mọ́ ọn lọ́wọ́.+
17 “Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣépè fún* bàbá tàbí ìyá rẹ̀.+
18 “Tí àwọn èèyàn bá ń jà, tí ẹnì kan wá ju òkúta lu ẹnì kejì rẹ̀ tàbí tó gbá a ní ẹ̀ṣẹ́,* tí kò sì kú, àmọ́ tí kò lè kúrò lórí ibùsùn rẹ̀, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nìyí: 19 Tó bá lè dìde, tó sì fi ọ̀pá rìn káàkiri níta, ẹ má fìyà jẹ ẹni tó ṣe é léṣe. Àmọ́ kó san nǹkan kan láti fi dí àkókò tí ẹni tó fara pa yẹn ò fi lè ṣiṣẹ́ títí ara rẹ̀ á fi yá.
20 “Tí ọkùnrin kan bá fi igi lu ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, tó sì kú mọ́ ọn lọ́wọ́, kí ẹ gbẹ̀san ẹrú náà.+ 21 Àmọ́, tí kò bá kú láàárín ọjọ́ kan sí méjì, ẹ má gbẹ̀san lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀, torí owó ara rẹ̀ ló fi rà á.
22 “Tí àwọn èèyàn bá ń jà, tí wọ́n sì ṣe obìnrin tó lóyún léṣe, tó wá bímọ nígbà tí àsìkò rẹ̀ kò tíì tó,*+ àmọ́ tí kò la ẹ̀mí lọ,* ẹni tó ṣe obìnrin náà léṣe gbọ́dọ̀ san owó ìtanràn tí ọkọ rẹ̀ bá bù lé e; kí ó san án nípasẹ̀ àwọn adájọ́.+ 23 Àmọ́ tó bá la ẹ̀mí lọ, kí o fi ẹ̀mí dípò ẹ̀mí,*+ 24 ojú dípò ojú, eyín dípò eyín, ọwọ́ dípò ọwọ́, ẹsẹ̀ dípò ẹsẹ̀,+ 25 kí o fi nǹkan jó ẹni tó bá fi nǹkan jó ẹnì kejì, ọgbẹ́ dípò ọgbẹ́, ẹ̀ṣẹ́ dípò ẹ̀ṣẹ́.
26 “Tí ọkùnrin kan bá lu ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ní ojú, tí ojú rẹ̀ sì fọ́, kó dá ẹrú náà sílẹ̀ lómìnira láti fi dípò ojú rẹ̀ tó fọ́.+ 27 Tó bá sì gbá eyín ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ yọ, kó dá ẹrú náà sílẹ̀ lómìnira láti fi dípò eyín rẹ̀ tó yọ.
28 “Tí akọ màlúù kan bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin kan, tí ẹni yẹn sì kú, kí ẹ sọ akọ màlúù náà lókùúta pa,+ kí ẹnikẹ́ni má sì jẹ ẹran rẹ̀. Ẹ má fìyà jẹ ẹni tó ni akọ màlúù náà. 29 Àmọ́ tó bá ti di ìṣe akọ màlúù kan láti máa kàn, tí wọ́n sì ti kìlọ̀ fún ẹni tó ni ín àmọ́ tí kò bójú tó o, tí akọ màlúù náà wá pa ọkùnrin tàbí obìnrin kan, kí ẹ sọ ọ́ lókùúta pa, kí ẹ sì pa ẹni tó ni ín. 30 Tí wọ́n bá ní kó san ìràpadà,* ó gbọ́dọ̀ san gbogbo owó tí wọ́n bá ní kó san láti fi ra ẹ̀mí* rẹ̀ pa dà. 31 Ì báà jẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin ni màlúù náà kàn, ìdájọ́ yìí ni kí wọ́n ṣe fún ẹni tó ni akọ màlúù náà. 32 Tí akọ màlúù náà bá kan ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin kan, ẹni tó ni ín yóò san ọgbọ̀n (30) ṣékélì* fún ọ̀gá ẹrú yẹn, wọ́n á sì sọ akọ màlúù náà lókùúta pa.
33 “Tí ọkùnrin kan bá ṣí kòtò kan sílẹ̀ tàbí tó gbẹ́ kòtò kan, tí kò sì bò ó, tí akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan wá já sínú rẹ̀, 34 kí ẹni tó ni kòtò náà san iye kan dípò ẹran náà.+ Kí ó san owó náà fún ẹni tó ni ín, òkú ẹran náà yóò sì di tirẹ̀. 35 Tí akọ màlúù ẹnì kan bá ṣe akọ màlúù ẹlòmíì léṣe, tó sì kú, kí wọ́n ta akọ màlúù tí kò kú yẹn, kí wọ́n sì pín owó rẹ̀; kí wọ́n tún pín òkú ẹran náà. 36 Tàbí tó bá jẹ́ pé ó ti di ìṣe akọ màlúù kan láti máa kàn, àmọ́ tí ẹni tó ni ín ò bójú tó o, kó fi akọ màlúù dípò akọ màlúù, èyí tó kú yóò sì di tirẹ̀.
22 “Tí ẹnì kan bá jí akọ màlúù tàbí àgùntàn, tó sì pa á tàbí tó tà á, kó fi akọ màlúù márùn-ún dípò akọ màlúù náà, kó sì fi àgùntàn mẹ́rin dípò àgùntàn náà.+
2 (“Tí ẹ bá rí olè kan+ níbi tó ti ń fọ́lé, tí ẹ lù ú, tó sì kú, ẹnikẹ́ni ò ní jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 3 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ojúmọmọ ló ṣẹlẹ̀, ẹ ó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.)
“Ó gbọ́dọ̀ fi nǹkan dípò. Tí kò bá ní nǹkan kan, kí ẹ ta òun fúnra rẹ̀ láti fi dí ohun tó jí. 4 Tí ohun tó jí bá ṣì wà láàyè, tó sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, bóyá akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àgùntàn, kó san án pa dà ní ìlọ́po méjì.
5 “Tí ẹnikẹ́ni bá da àwọn ẹran rẹ̀ lọ jẹko nínú pápá tàbí ọgbà àjàrà kan, tó sì jẹ́ kí wọ́n jẹko nínú pápá ẹlòmíì, kí ẹni náà fi ohun tó dáa jù nínú pápá rẹ̀ tàbí ohun tó dáa jù nínú ọgbà àjàrà rẹ̀ dí i.
6 “Tí ẹnì kan bá dá iná, tó wá ràn mọ́ àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún, tó sì jó àwọn ìtí ọkà, tó jó ọkà tó wà ní ìdúró tàbí oko run, ẹni tó dá iná náà gbọ́dọ̀ san nǹkan kan láti fi dípò ohun tó jóná.
7 “Tí ẹnì kan bá fi owó tàbí àwọn ohun kan pa mọ́ sọ́wọ́ ọmọnìkejì rẹ̀, tí olè wá jí àwọn nǹkan náà kó nílé onítọ̀hún, tí ẹ bá mú olè náà, kó fi nǹkan dípò ní ìlọ́po méjì.+ 8 Tí ẹ ò bá rí olè náà, kí ẹ mú ẹni tó ni ilé náà wá síwájú Ọlọ́run tòótọ́+ láti mọ̀ bóyá òun ló mú nǹkan ẹnì kejì rẹ̀. 9 Ní ti gbogbo ẹjọ́ tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ẹrù tí wọ́n jí, bóyá akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, aṣọ tàbí ohunkóhun tó sọ nù, tí ẹnì kan wá sọ pé, ‘Èmi ni mo ni ín!’ kí àwọn méjèèjì tí ọ̀rọ̀ náà kàn gbé ẹjọ́ wọn wá síwájú Ọlọ́run tòótọ́.+ Ẹni tí Ọlọ́run bá sọ pé ó jẹ̀bi ni yóò fi nǹkan dípò ní ìlọ́po méjì fún ọmọnìkejì rẹ̀.+
10 “Tí ẹnì kan bá fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí akọ màlúù tàbí àgùntàn tàbí ẹran ọ̀sìn èyíkéyìí pa mọ́ sọ́dọ̀ ọmọnìkejì rẹ̀, tí ẹran náà wá kú tàbí tó di aláàbọ̀ ara tàbí tí ẹnì kan mú un lọ nígbà tí ẹnikẹ́ni ò rí i, 11 kí àwọn méjèèjì wá síwájú Jèhófà, kó lè búra pé òun ò fọwọ́ kan ẹrù ọmọnìkejì òun; kí ẹni tó ni ẹrù náà sì fara mọ́ ọn. Kí ẹnì kejì má san nǹkan kan dípò.+ 12 Àmọ́ tí wọ́n bá jí ẹran náà lọ́dọ̀ rẹ̀, kó fi nǹkan kan dípò fún ẹni tó ni ín. 13 Tó bá jẹ́ pé ẹranko búburú ló pa á, kó mú un wá bí ẹ̀rí. Kó má fi ohunkóhun dípò ẹran tí ẹranko búburú pa.
14 “Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá yá ẹran lọ́wọ́ ọmọnìkejì rẹ̀, tí ẹran náà wá di aláàbọ̀ ara tàbí tó kú nígbà tí ẹni tó ni ín kò sí níbẹ̀, ẹni tó yá a yóò san nǹkan kan dípò rẹ̀. 15 Tí ẹni tó ni ín bá wà níbẹ̀, ẹni tó yá a kò ní san nǹkan kan dípò. Tó bá jẹ́ pé ṣe ló fi owó yá a, owó tó san yẹn ni yóò fi dí i.
16 “Tí ọkùnrin kan bá fa ojú wúńdíá kan tí kò ní àfẹ́sọ́nà mọ́ra, tó sì bá a sùn, ó gbọ́dọ̀ san owó orí rẹ̀ kó lè di ìyàwó rẹ̀.+ 17 Tí bàbá obìnrin náà bá kọ̀ jálẹ̀ láti fún un ní ọmọbìnrin náà, kí ọkùnrin náà san iye tí wọ́n máa ń gbà fún owó orí.
18 “O ò gbọ́dọ̀ dá àjẹ́ sí.+
19 “Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá bá ẹranko sùn.+
20 “Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá rúbọ sí ọlọ́run èyíkéyìí yàtọ̀ sí Jèhófà.+
21 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ àjèjì tàbí kí ẹ ni ín lára,+ torí àjèjì lẹ jẹ́ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
22 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ opó tàbí ọmọ aláìníbaba* kankan.+ 23 Tí ẹ bá fìyà jẹ ẹ́ pẹ́nrẹ́n, tó sì ké pè mí, ó dájú pé màá gbọ́ igbe rẹ̀;+ 24 màá bínú gidigidi, màá sì fi idà pa yín, àwọn ìyàwó yín yóò di opó, àwọn ọmọ yín yóò sì di aláìníbaba.
25 “Tí ẹ bá yá ìkankan nínú àwọn èèyàn mi tó jẹ́ aláìní* lówó, ẹni tó ń bá yín gbé, ẹ ò gbọ́dọ̀ hùwà sí i bí àwọn tó ń yáni lówó èlé.* Ẹ ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ rẹ̀.+
26 “Tí o bá gba aṣọ ọmọnìkejì rẹ láti fi ṣe ìdúró,*+ kí o dá a pa dà fún un nígbà tí oòrùn bá wọ̀. 27 Ohun kan ṣoṣo tó bò ó lára nìyẹn, aṣọ tó fi bo ara* rẹ̀; kí wá ni kó fi bora sùn?+ Tó bá ké pè mí, ó dájú pé màá gbọ́, torí mo jẹ́ aláàánú.*+
28 “O ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ òdì sí* Ọlọ́run+ tàbí kí o sọ̀rọ̀ òdì sí ìjòyè* nínú àwọn èèyàn rẹ.+
29 “O ò gbọ́dọ̀ lọ́ra láti mú nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irè oko rẹ àti ohun tó kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú àwọn ibi ìfúntí* rẹ láti fi ṣe ọrẹ.+ Kí o fún mi ní àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ.+ 30 Ohun tí wàá ṣe sí akọ màlúù àti àgùntàn rẹ nìyí:+ Kí ó wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Tó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí o mú un wá fún mi.+
31 “Kí ẹ fi hàn pé èèyàn mi tó jẹ́ mímọ́ ni yín,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹranko èyíkéyìí tí ẹranko búburú ti pa.+ Kí ẹ jù ú sí àwọn ajá.
23 “O ò gbọ́dọ̀ tan ìròyìn èké kálẹ̀.*+ Má ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ẹni burúkú láti jẹ́rìí èké.+ 2 O ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ èèyàn láti hùwà ibi, o ò sì gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ èèyàn láti jẹ́rìí èké* kí o lè yí ìdájọ́ po. 3 O ò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú nínú ẹjọ́ aláìní.+
4 “Tí o bá rí i tí akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀tá rẹ ń ṣìnà, kí o dá a pa dà fún un.+ 5 Tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tó kórìíra rẹ, tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ṣubú tí kò sì lè dìde torí ẹrù tó gbé, o ò gbọ́dọ̀ fi sílẹ̀ lọ. Kí o bá a gbé ẹrù náà kúrò.+
6 “Tí aláìní kan láàárín yín bá ní ẹjọ́, má ṣe yí ìdájọ́ rẹ̀ po.+
7 “Má ṣe lọ́wọ́ sí ẹ̀sùn èké,* má sì pa aláìṣẹ̀ àti olódodo, torí mi ò ní pe ẹni burúkú ní olódodo.*+
8 “Má ṣe gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, torí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí àwọn tó ríran kedere lójú, ó sì lè mú kí àwọn olódodo yí ọ̀rọ̀ po.+
9 “O ò gbọ́dọ̀ ni àjèjì lára. Ẹ mọ bó ṣe máa ń rí kéèyàn jẹ́ àjèjì,* torí àjèjì lẹ jẹ́ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
10 “Ọdún mẹ́fà ni kí o fi fún irúgbìn sí ilẹ̀ rẹ, kí o sì fi kórè èso rẹ̀.+ 11 Àmọ́ ní ọdún keje, kí o fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ láìro, má fi dá oko. Àwọn tó jẹ́ aláìní nínú àwọn èèyàn rẹ yóò jẹ nínú rẹ̀, àwọn ẹran inú igbó yóò sì jẹ ohun tí wọ́n bá ṣẹ́ kù. Ohun tí o máa ṣe sí ọgbà àjàrà rẹ àti àwọn igi ólífì rẹ nìyẹn.
12 “Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o máa fi ṣe iṣẹ́ rẹ; àmọ́ ní ọjọ́ keje, kí o ṣíwọ́ iṣẹ́, kí akọ màlúù rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lè sinmi, kí ara sì lè tu ọmọ ẹrúbìnrin rẹ àti àjèjì.+
13 “Kí ẹ rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí mo sọ fún yín,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ dárúkọ àwọn ọlọ́run míì; kò gbọ́dọ̀ ti ẹnu* yín jáde.+
14 “Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún ni kí ẹ máa ṣe àjọyọ̀ fún mi.+ 15 Kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.+ Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú ní àkókò rẹ̀ nínú oṣù Ábíbù,*+ bí mo ṣe pa á láṣẹ fún yín, torí ìgbà yẹn lẹ kúrò ní Íjíbítì. Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wá síwájú mi lọ́wọ́ òfo.+ 16 Bákan náà, kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Ìkórè* àwọn èso oko yín tó kọ́kọ́ pọ́n, èyí tí ẹ ṣiṣẹ́ kára láti gbìn;+ àti Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé* níparí ọdún, nígbà tí ẹ bá kórè gbogbo ohun tí ẹ gbìn sí oko.+ 17 Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún ni kí gbogbo ọkùnrin* yín wá síwájú Jèhófà, Olúwa tòótọ́.+
18 “O ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀jẹ̀ rúbọ sí mi pa pọ̀ pẹ̀lú ohun tó ní ìwúkàrà. Ọ̀rá tí o bá fi rúbọ níbi àwọn àjọyọ̀ mi ò sì gbọ́dọ̀ ṣẹ́ kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì.
19 “Kí o mú èyí tó dáa jù nínú àwọn èso tó kọ́kọ́ pọ́n ní ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+
“O ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.+
20 “Màá rán áńgẹ́lì kan ṣáájú yín+ kó lè dáàbò bò yín lójú ọ̀nà, kó sì mú yín wá síbi tí mo ti ṣètò sílẹ̀.+ 21 Kí ẹ fetí sí i, kí ẹ sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀. Ẹ má ṣọ̀tẹ̀ sí i, torí kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì,+ torí pé orúkọ mi wà lára rẹ̀. 22 Àmọ́, tí ẹ bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn rẹ̀, tí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí mo sọ, màá bá àwọn ọ̀tá yín jà, màá sì gbógun ti àwọn tó ń gbógun tì yín. 23 Torí áńgẹ́lì mi yóò ṣáájú yín, yóò sì mú yín wá sọ́dọ̀ àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì, màá sì pa wọ́n run.+ 24 Ẹ ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run wọn, ẹ má sì jẹ́ kí wọ́n mú kí ẹ sìn wọ́n, ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí ẹ wó wọn palẹ̀, kí ẹ sì run àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn.+ 25 Jèhófà Ọlọ́run yín ni ẹ gbọ́dọ̀ máa sìn,+ yóò sì bù kún oúnjẹ àti omi yín.+ Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàárín yín.+ 26 Oyún kò ní bà jẹ́ lára àwọn obìnrin ilẹ̀ yín, wọn ò sì ní yàgàn.+ Màá jẹ́ kí ẹ̀mí yín gùn dáadáa.*
27 “Màá mú kí àwọn èèyàn máa bẹ̀rù mi kí ẹ tó dé ọ̀dọ̀ wọn,+ màá sì da àárín gbogbo àwọn tí ẹ bá pàdé rú. Màá mú kí ẹ ṣẹ́gun gbogbo ọ̀tá yín, wọ́n á sì sá lọ.*+ 28 Màá mú kí àwọn èèyàn rẹ̀wẹ̀sì* kí ẹ tó dé ọ̀dọ̀ wọn,+ ìrẹ̀wẹ̀sì náà yóò sì lé àwọn Hífì, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ọmọ Hétì kúrò níwájú yín.+ 29 Mi ò ní lé wọn kúrò níwájú yín láàárín ọdún kan, kí ilẹ̀ náà má bàa di ahoro, kí àwọn ẹranko búburú má bàa pọ̀ níbẹ̀ kí wọ́n sì ṣe yín lọ́ṣẹ́.+ 30 Díẹ̀díẹ̀ ni màá lé wọn kúrò níwájú yín, títí ẹ ó fi bí àwọn ọmọ, tí ẹ ó sì gba ilẹ̀ náà.+
31 “Màá pààlà fún yín láti Òkun Pupa dé òkun àwọn Filísínì àti láti aginjù dé Odò;*+ torí màá mú kí ọwọ́ yín tẹ àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà, ẹ ó sì lé wọn kúrò níwájú yín.+ 32 Ẹ ò gbọ́dọ̀ bá àwọn èèyàn náà tàbí àwọn ọlọ́run wọn dá májẹ̀mú.+ 33 Kí wọ́n má ṣe gbé ní ilẹ̀ yín, kí wọ́n má bàa mú kí ẹ ṣẹ̀ mí. Tí ẹ bá lọ sin àwọn ọlọ́run wọn, ó dájú pé yóò di ìdẹkùn fún yín.”+
24 Ó wá sọ fún Mósè pé: “Kí ìwọ àti Áárónì gòkè lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, pẹ̀lú Nádábù àti Ábíhù+ àti àádọ́rin (70) nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì, kí ẹ sì tẹrí ba láti òkèèrè. 2 Mósè nìkan ni kó sún mọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà; kí àwọn tó kù má ṣe sún mọ́ ibẹ̀, kí àwọn èèyàn náà má sì bá a gòkè.”+
3 Lẹ́yìn náà, Mósè wá, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà àti gbogbo ìdájọ́ náà+ fún àwọn èèyàn, gbogbo àwọn èèyàn náà sì fohùn ṣọ̀kan, wọ́n fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ la múra tán láti ṣe.”+ 4 Mósè wá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà sílẹ̀.+ Ó dìde ní àárọ̀ kùtù, ó sì mọ pẹpẹ kan sísàlẹ̀ òkè náà àti òpó méjìlá (12) tó dúró fún ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì. 5 Lẹ́yìn náà, ó rán àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n rú ẹbọ sísun, wọ́n sì fi àwọn akọ màlúù rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ sí Jèhófà. 6 Mósè wá mú ìdajì lára ẹ̀jẹ̀ náà, ó dà á sínú àwọn abọ́, ó sì wọ́n ìdajì sórí pẹpẹ. 7 Lẹ́yìn náà, ó mú ìwé májẹ̀mú, ó kà á sókè fún àwọn èèyàn náà.+ Wọ́n sì sọ pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ la múra tán láti ṣe, a ó sì máa ṣègbọràn.”+ 8 Mósè wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sára àwọn èèyàn náà,+ ó sì sọ pé: “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Jèhófà bá yín dá pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ yìí.”+
9 Mósè àti Áárónì, Nádábù àti Ábíhù àti àádọ́rin (70) nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá gòkè lọ, 10 wọ́n sì rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ Ohun tó dà bíi pèpéle òkúta sàfáyà wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì mọ́ nigínnigín bí ọ̀run.+ 11 Kò pa àwọn èèyàn pàtàkì yìí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára,+ wọ́n sì rí ìran Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.
12 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wá bá mi lórí òkè, kí o sì dúró síbẹ̀. Màá fún ọ ní àwọn wàláà òkúta tí èmi yóò kọ òfin àti àṣẹ sí láti fún àwọn èèyàn náà ní ìtọ́ni.”+ 13 Mósè gbéra pẹ̀lú Jóṣúà ìránṣẹ́ rẹ̀,+ Mósè sì lọ sórí òkè Ọlọ́run tòótọ́.+ 14 Àmọ́ ó ti sọ fún àwọn àgbààgbà náà pé: “Ẹ dúró dè wá níbí títí a ó fi pa dà wá bá yín.+ Áárónì àti Húrì+ wà pẹ̀lú yín. Tí ẹnikẹ́ni bá ní ẹjọ́, kó lọ bá wọn.”+ 15 Mósè wá lọ sórí òkè náà nígbà tí ìkùukùu* ṣì bo òkè náà.+
16 Ògo Jèhófà+ ò kúrò lórí Òkè Sínáì,+ ìkùukùu náà sì bò ó fún ọjọ́ mẹ́fà. Ní ọjọ́ keje, ó pe Mósè látinú ìkùukùu náà. 17 Lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ògo Jèhófà rí bí iná tó ń jẹ nǹkan run lórí òkè náà. 18 Mósè wá wọ inú ìkùukùu náà, ó sì lọ sórí òkè náà.+ Mósè sì dúró lórí òkè náà fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru.+
25 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n mú ọrẹ wá fún mi. Kí ẹ gba ọrẹ fún mi lọ́wọ́ gbogbo ẹni tí ọkàn rẹ̀ bá sún láti mú un wá.+ 3 Ọrẹ tí ẹ máa gbà lọ́wọ́ wọn nìyí: wúrà,+ fàdákà,+ bàbà,+ 4 fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù,* òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò,* aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, irun ewúrẹ́, 5 awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa, awọ séálì, igi bọn-ọ̀n-ní,+ 6 òróró fìtílà,+ òróró básámù tí wọ́n á fi ṣe òróró àfiyanni+ àti tùràrí onílọ́fínńdà,+ 7 àwọn òkúta ónísì àti àwọn òkúta míì tí wọ́n máa tò sára éfódì+ àti aṣọ ìgbàyà.+ 8 Kí wọ́n ṣe ibi mímọ́ fún mi, èmi yóò sì máa gbé láàárín* wọn.+ 9 Kí ẹ ṣe àgọ́ ìjọsìn àti gbogbo ohun tó máa wà níbẹ̀, kó rí bí ohun* tí màá fi hàn ọ́ gẹ́lẹ́.+
10 “Kí wọ́n fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àpótí, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjì ààbọ̀, kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+ 11 Kí o wá fi ògidì wúrà bò ó.+ Kí o fi bò ó nínú àti níta, kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká.+ 12 Kí o fi wúrà rọ òrùka mẹ́rin fún un, kí o sì fi wọ́n síbi òkè ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, òrùka méjì ní ẹ̀gbẹ́ kan àti òrùka méjì ní ẹ̀gbẹ́ kejì. 13 Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì fi wúrà bò wọ́n.+ 14 O máa ki àwọn ọ̀pá náà bọ inú àwọn òrùka tó wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì Àpótí náà, kí ẹ lè máa fi gbé Àpótí náà. 15 Inú àwọn òrùka Àpótí náà ni kí àwọn ọ̀pá náà máa wà; ẹ má ṣe yọ wọ́n kúrò níbẹ̀.+ 16 Kí o gbé Ẹ̀rí tí èmi yóò fún ọ sínú Àpótí náà.+
17 “Kí o fi ògidì wúrà ṣe ìbòrí, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+ 18 Kí o fi wúrà ṣe kérúbù méjì; kó jẹ́ iṣẹ́ ọnà tí o fi òòlù ṣe sí ìkángun méjèèjì ìbòrí náà.+ 19 Kí o ṣe àwọn kérúbù náà sí ìkángun méjèèjì, kérúbù kan ní ìkángun kọ̀ọ̀kan ìbòrí náà. 20 Kí àwọn kérúbù náà na ìyẹ́ wọn méjèèjì sókè, kí wọ́n fi bo ìbòrí náà,+ kí wọ́n sì dojú kọra. Kí àwọn kérúbù náà sì máa wo ìbòrí náà. 21 Kí o gbé ìbòrí náà+ sórí Àpótí náà, kí o sì fi Ẹ̀rí tí màá fún ọ sínú Àpótí náà. 22 Màá pàdé rẹ níbẹ̀, màá sì bá ọ sọ̀rọ̀ látorí ìbòrí náà.+ Láti àárín àwọn kérúbù méjì tó wà lórí àpótí Ẹ̀rí náà ni màá ti jẹ́ kí o mọ gbogbo ohun tí màá pa láṣẹ fún ọ pé kí o sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
23 “Kí o tún fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe tábìlì,+ kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+ 24 Kí o fi ògidì wúrà bò ó, kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká. 25 Kí o ṣe etí tó fẹ̀ tó ìbú ọwọ́* kan sí i yí ká, kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí etí náà yí ká.* 26 Kí o ṣe òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, kí o sì fi àwọn òrùka náà sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, níbi tí ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà. 27 Kí àwọn òrùka náà sún mọ́ etí Àpótí náà, torí òun ló máa gba àwọn ọ̀pá tí wọ́n á máa fi gbé tábìlì náà dúró. 28 Igi bọn-ọ̀n-ní ni kí o fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, kí o sì fi wúrà bò wọ́n, kí wọ́n máa fi wọ́n gbé tábìlì náà.
29 “Kí o tún ṣe àwọn abọ́ ìjẹun rẹ̀, àwọn ife rẹ̀, àwọn ṣágo àti àwọn abọ́ rẹ̀ tí wọ́n á máa da ọrẹ ohun mímu látinú rẹ̀. Kí o fi ògidì wúrà ṣe wọ́n.+ 30 Kí o sì máa gbé búrẹ́dì àfihàn sórí tábìlì níwájú mi ní gbogbo ìgbà.+
31 “Kí o fi ògidì wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà.+ Kí ọ̀pá fìtílà náà jẹ́ iṣẹ́ ọnà tí o fi òòlù ṣe. Kí ìsàlẹ̀ rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, àwọn ẹ̀ka rẹ̀, àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ̀, àwọn kókó rubutu rẹ̀ àti àwọn ìtànná rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo.+ 32 Ẹ̀ka mẹ́fà ló máa yọ jáde ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ọ̀pá fìtílà náà, ẹ̀ka mẹ́ta láti ẹ̀gbẹ́ kan àti ẹ̀ka mẹ́ta láti ẹ̀gbẹ́ kejì. 33 Iṣẹ́ ọnà mẹ́ta tó rí bí òdòdó álímọ́ńdì ni kó wà lára àwọn ẹ̀ka tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, kí kókó rubutu àti ìtànná kọ̀ọ̀kan tẹ̀ léra, kí iṣẹ́ ọnà mẹ́ta tó rí bí òdòdó álímọ́ńdì sì wà lára àwọn ẹ̀ka tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì, kí kókó rubutu àti ìtànná kọ̀ọ̀kan sì tẹ̀ léra. Bí ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ṣe máa yọ jáde lára ọ̀pá fìtílà náà nìyí. 34 Kí iṣẹ́ ọnà mẹ́rin tó rí bí òdòdó álímọ́ńdì wà lára ọ̀pá náà, kí kókó rubutu rẹ̀ àti ìtànná rẹ̀ sì tẹ̀ léra. 35 Kí kókó rubutu kan wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì àkọ́kọ́ tó yọ jáde lára ọ̀pá náà, kí kókó rubutu kan tún wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì tó tẹ̀ lé e, kí kókó rubutu míì sì wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì tó tẹ̀ lé ìyẹn, bó ṣe máa wà lábẹ́ ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó yọ jáde lára ọ̀pá fìtílà náà nìyẹn. 36 Kí àwọn kókó rubutu, àwọn ẹ̀ka àti ọ̀pá fìtílà náà lódindi jẹ́ iṣẹ́ ọnà tí o fi òòlù ṣe, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan, kó sì jẹ́ ògidì wúrà.+ 37 Fìtílà méje ni kí o ṣe sórí ọ̀pá náà, tí wọ́n bá sì tan àwọn fìtílà náà, iná wọn á mọ́lẹ̀ síwájú ọ̀pá náà.+ 38 Kí o fi ògidì wúrà ṣe àwọn ìpaná* rẹ̀ àti àwọn ìkóná rẹ̀.+ 39 Ògidì wúrà tálẹ́ńtì* kan ni kí o fi ṣe é, pẹ̀lú àwọn ohun èlò yìí. 40 Rí i pé o ṣe wọ́n bí ohun* tí mo fi hàn ọ́ lórí òkè.+
26 “Kí o mú aṣọ mẹ́wàá tí wọ́n fi ń pa àgọ́, kí o sì fi ṣe àgọ́ ìjọsìn.+ Kí aṣọ náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa, pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò. Kí o kó iṣẹ́ sí wọn lára, kí iṣẹ́ náà+ jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù.+ 2 Kí gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlọ́gbọ̀n (28), kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Kí ìwọ̀n gbogbo aṣọ àgọ́ náà dọ́gba.+ 3 Kí o so aṣọ àgọ́ márùn-ún pọ̀ mọ́ra, kó jẹ́ ọ̀wọ́ kan, kí o sì so aṣọ àgọ́ márùn-ún yòókù pọ̀, kó jẹ́ ọ̀wọ́ kan. 4 Kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe àwọn ihò sí etí aṣọ àgọ́ tó kẹ́yìn lára ọ̀wọ́ náà, kí o sì ṣe ohun kan náà sí etí aṣọ àgọ́ tó wà ní ìkángun ọ̀wọ́ kejì níbi tí yóò ti so pọ̀ mọ́ ti àkọ́kọ́. 5 Kí o lu àádọ́ta (50) ihò sí aṣọ àgọ́ kan, kí o sì lu àádọ́ta (50) ihò sí etí aṣọ àgọ́ kejì kí wọ́n lè kọjú síra níbi tí wọ́n á ti so pọ̀ mọ́ra. 6 Kí o fi wúrà ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́, kí o sì fi àwọn ìkọ́ náà so àwọn aṣọ àgọ́ náà pọ̀, kí àgọ́ ìjọsìn náà lè di odindi.+
7 “Kí o tún fi irun ewúrẹ́+ ṣe àwọn aṣọ àgọ́ láti fi bo àgọ́ ìjọsìn náà. Kí o ṣe aṣọ àgọ́ mọ́kànlá (11).+ 8 Kí gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Kí ìwọ̀n gbogbo aṣọ àgọ́ mọ́kànlá (11) náà dọ́gba. 9 Kí o so márùn-ún nínú àwọn aṣọ àgọ́ náà pọ̀ mọ́ra, kí o so aṣọ àgọ́ mẹ́fà yòókù pọ̀ mọ́ra, kí o sì ṣẹ́ aṣọ àgọ́ kẹfà po níwájú àgọ́ náà. 10 Kí o lu àádọ́ta (50) ihò sí etí aṣọ àgọ́ tó wà ní ìkángun nínú ọ̀wọ́ náà, kí o tún lu àádọ́ta (50) ihò sí etí aṣọ àgọ́ tó wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì, níbi tí wọ́n ti so pọ̀ mọ́ra. 11 Kí o fi bàbà ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́, kí o sì fi àwọn ìkọ́ náà sínú àwọn ihò náà, kí o wá so àwọn aṣọ àgọ́ náà pọ̀ mọ́ra, yóò sì di odindi. 12 Èyí tó ṣẹ́ kù lára àwọn aṣọ àgọ́ náà yóò so rọ̀. Kí ìdajì aṣọ àgọ́ náà ṣẹ́ kù sí ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà. 13 Èyí tó ṣẹ́ kù lára àwọn aṣọ àgọ́ náà yóò ṣẹ́ kù sí ẹ̀gbẹ́ àgọ́ ìjọsìn náà kó lè bò ó, ìgbọ̀nwọ́ kan ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan.
14 “Kí o tún fi awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa ṣe ìbòrí àgọ́ náà, kí o wá fi awọ séálì bo awọ àgbò náà.+
15 “Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn náà, kí wọ́n wà ní òró.+ 16 Kí gígùn férémù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀. 17 Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan férémù náà ní ìtẹ̀bọ̀ méjì* lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe gbogbo férémù àgọ́ ìjọsìn náà. 18 Kí o ṣe ogún (20) férémù sí apá gúúsù àgọ́ ìjọsìn náà, kó dojú kọ gúúsù.
19 “Kí o fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò+ sábẹ́ ogún (20) férémù náà: ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sábẹ́ férémù kan, kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀, kí ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sì wà lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù, kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀.+ 20 Kí o ṣe ogún (20) férémù sí ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà, ní apá àríwá, 21 kí o sì fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò fún wọn. Kí ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò wà lábẹ́ férémù kan, kí ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò wà lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù. 22 Kí o ṣe férémù mẹ́fà sí ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà, lápá ìwọ̀ oòrùn.+ 23 Kí o fi férémù méjì ṣe òpó sí igun méjèèjì ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà. 24 Kí férémù náà ní igi méjì láti ìsàlẹ̀ dé òkè, níbi òrùka àkọ́kọ́. Ohun tí o máa ṣe sí méjèèjì nìyẹn, wọ́n á sì jẹ́ òpó ní igun méjèèjì. 25 Ó máa jẹ́ férémù mẹ́jọ àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn mẹ́rìndínlógún (16) tí wọ́n fi fàdákà ṣe, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò máa wà lábẹ́ férémù kan, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sì máa wà lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù.
26 “Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá gbọọrọ, ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan àgọ́ ìjọsìn náà,+ 27 ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà àti ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́ ìjọsìn náà lápá ìwọ̀ oòrùn, ní ẹ̀yìn. 28 Kí ọ̀pá gbọọrọ tó wà láàárín gba àárín àwọn férémù náà kọjá láti ìkángun dé ìkángun.
29 “Kí o fi wúrà bo àwọn férémù náà,+ kí o sì tún fi wúrà ṣe àwọn òrùka tó máa di àwọn ọ̀pá náà mú, kí o sì fi wúrà bo àwọn ọ̀pá náà. 30 Kí o ṣe àgọ́ ìjọsìn náà bí àwòrán tí mo fi hàn ọ́ lórí òkè.+
31 “Kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ṣe aṣọ ìdábùú.+ Kí o kó iṣẹ́ sí i lára, kí iṣẹ́ náà jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù. 32 Kí o gbé e kọ́ sára òpó igi bọn-ọ̀n-ní mẹ́rin tí wọ́n fi wúrà bò. Kí o fi wúrà ṣe àwọn ìkọ́ wọn. Kí àwọn òpó náà wà lórí ìtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó ní ihò tí wọ́n fi fàdákà ṣe. 33 Kí o fi aṣọ ìdábùú náà kọ́ sábẹ́ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí Ẹ̀rí náà+ wọnú ibi tí aṣọ ìdábùú náà bò. Aṣọ ìdábùú náà ni kí ẹ fi pín Ibi Mímọ́+ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ.+ 34 Kí o fi ìbòrí náà bo àpótí Ẹ̀rí náà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ.
35 “Kí o gbé tábìlì sí ìta aṣọ ìdábùú náà, kí ọ̀pá fìtílà+ náà dojú kọ tábìlì náà ní apá gúúsù àgọ́ ìjọsìn; kí o sì gbé tábìlì náà sí apá àríwá. 36 Kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ṣe aṣọ* tí ẹ máa ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.+ 37 Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe òpó márùn-ún fún aṣọ* náà, kí o sì fi wúrà bo àwọn òpó náà. Kí o fi wúrà ṣe àwọn ìkọ́ wọn, kí o sì fi bàbà ṣe ìtẹ́lẹ̀ márùn-ún tó ní ihò fún wọn.
27 “Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe pẹpẹ;+ kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* márùn-ún, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Kí ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin pẹpẹ náà dọ́gba, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta.+ 2 Kí o ṣe ìwo+ sí igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin; àwọn ìwo náà yóò wà lára pẹpẹ náà, kí o sì fi bàbà bo pẹpẹ náà.+ 3 Kí o ṣe àwọn garawa láti máa fi kó eérú* rẹ̀ dà nù, kí o tún ṣe àwọn ṣọ́bìrì, àwọn abọ́, àwọn àmúga àti àwọn ìkóná, bàbà sì ni kí o fi ṣe gbogbo ohun èlò rẹ̀.+ 4 Kí o fi bàbà ṣe àgbàyan* tó rí bí àwọ̀n fún pẹpẹ náà, kí o sì fi bàbà ṣe òrùka mẹ́rin sí igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 5 Kí o gbé e sí ọwọ́ ìsàlẹ̀ etí pẹpẹ náà, kí àgbàyan náà sì wọnú pẹpẹ náà níbi àárín. 6 Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá fún pẹpẹ náà, kí o sì fi bàbà bò wọ́n. 7 Kí o ki àwọn ọ̀pá náà bọnú àwọn òrùka náà, kí àwọn ọ̀pá náà lè wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì pẹpẹ náà nígbà tí wọ́n bá gbé e.+ 8 Kí o ṣe pẹpẹ náà bí àpótí onípákó tí inú rẹ̀ jìn. Kí o ṣe é bí Ó ṣe fi hàn ọ́ lórí òkè gẹ́lẹ́.+
9 “Kí o ṣe àgbàlá+ àgọ́ ìjọsìn náà. Ní apá gúúsù tó dojú kọ gúúsù, kí àgbàlá náà ní àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa ṣe, èyí tí wọ́n máa ta, kí gígùn ẹ̀gbẹ́ kan jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́.+ 10 Kí ó ní ogún (20) òpó pẹ̀lú ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe. Kí o fi fàdákà ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 11 Kí gígùn àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta sí apá àríwá náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́, kí àwọn òpó rẹ̀ jẹ́ ogún (20) àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe, pẹ̀lú ìkọ́ àwọn òpó náà àti ohun tó so wọ́n pọ̀* tí wọ́n fi fàdákà ṣe. 12 Kí àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta sí ẹ̀gbẹ́ àgbàlá náà lápá ìwọ̀ oòrùn jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wàá tó ní ihò. 13 Kí fífẹ̀ àgbàlá náà ní apá ìlà oòrùn tí oòrùn ti ń yọ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́. 14 Kí àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) wà ní ẹ̀gbẹ́ kan, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò.+ 15 Kí àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò.
16 “Kí o ta aṣọ* tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ṣe é,+ pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn mẹ́rin.+ 17 Fàdákà ni kí o fi ṣe gbogbo òpó tó yí àgbàlá náà ká àti àwọn ohun tí wọ́n fi ń de nǹkan pọ̀ àti àwọn ìkọ́, àmọ́ bàbà ni kí o fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn.+ 18 Kí gígùn àgbàlá náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́,+ kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ni kí o fi ṣe é, kó sì ní àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe. 19 Bàbà ni kí o fi ṣe gbogbo ohun èlò àti àwọn nǹkan tí ẹ ó máa fi ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn náà, pẹ̀lú àwọn èèkàn àgọ́ náà àti gbogbo èèkàn àgbàlá náà.+
20 “Kí o pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gbé ògidì òróró ólífì tí wọ́n fún wá sọ́dọ̀ rẹ láti máa fi tan iná, kí àwọn fìtílà náà lè máa wà ní títàn nígbà gbogbo.+ 21 Nínú àgọ́ ìpàdé, lẹ́yìn òde aṣọ ìdábùú tó wà nítòsí Ẹ̀rí náà,+ kí Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ ṣètò bí àwọn fìtílà náà á ṣe máa wà ní títàn láti alẹ́ títí di àárọ̀ níwájú Jèhófà.+ Àṣẹ yìí ni kí gbogbo ìran wọn máa tẹ̀ lé títí lọ, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe é.+
28 “Kí o mú Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ látinú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè di àlùfáà mi,+ Áárónì,+ pẹ̀lú Nádábù àti Ábíhù,+ Élíásárì àti Ítámárì,+ àwọn ọmọ Áárónì.+ 2 Kí o ṣe aṣọ mímọ́ fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ, kó lè ní ògo àti ẹwà.+ 3 Kí o bá gbogbo àwọn tó mọṣẹ́* sọ̀rọ̀, àwọn tí mo ti fi ẹ̀mí ọgbọ́n kún inú wọn,+ kí wọ́n lè ṣe aṣọ Áárónì láti sọ ọ́ di mímọ́, kó lè di àlùfáà mi.
4 “Àwọn aṣọ tí wọ́n á ṣe nìyí: aṣọ ìgbàyà,+ éfódì,+ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá,+ aṣọ tó ní bátànì igun mẹ́rin, láwàní+ àti ọ̀já;+ kí wọ́n ṣe àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kó lè di àlùfáà mi. 5 Àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ náà yóò lo wúrà náà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa.
6 “Kí wọ́n lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa láti fi ṣe éfódì, kí wọ́n sì kóṣẹ́ sí i.+ 7 Kí ó ní apá méjì tí wọ́n máa rán pa pọ̀ ní èjìká aṣọ náà. 8 Ní ti àmùrè* tí wọ́n hun,+ èyí tó wà lára éfódì náà láti dì í mú kó lè dúró dáadáa, ohun kan náà ni kí wọ́n fi ṣe é, kí wọ́n lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa.
9 “Kí o mú òkúta ónísì méjì,+ kí o sì fín orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sára wọn,+ 10 orúkọ mẹ́fà lára òkúta kan, orúkọ mẹ́fà tó ṣẹ́ kù lára òkúta kejì, bí wọ́n ṣe bí wọn tẹ̀ léra. 11 Kí oníṣẹ́ ọnà òkúta fín orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sára òkúta méjèèjì bí ìgbà tó ń fín èdìdì.+ Kí o wá fi wúrà tẹ́lẹ̀ wọn. 12 Kí o fi òkúta méjèèjì sórí àwọn aṣọ èjìká éfódì náà, kó lè jẹ́ òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí orúkọ wọn sì máa wà ní èjìká Áárónì méjèèjì, kó lè jẹ́ ohun ìrántí tó bá wá síwájú Jèhófà. 13 Kí o fi wúrà ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀, 14 kí o sì fi ògidì wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n méjì, kí o lọ́ ọ pọ̀ bí okùn,+ kí o sì so àwọn ẹ̀wọ̀n tó dà bí okùn náà mọ́ àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà.+
15 “Kí o mú kí ẹni tó ń kó iṣẹ́ sí aṣọ ṣe aṣọ ìgbàyà ìdájọ́.+ Kó ṣe é bí éfódì, kí ó lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa láti fi ṣe é.+ 16 Kí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba tí wọ́n bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, kó jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan* ní gígùn àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan ní fífẹ̀. 17 Kí o to àwọn òkúta sórí rẹ̀, kí o to òkúta náà ní ìpele mẹ́rin. Kí ìpele àkọ́kọ́ jẹ́ rúbì, tópásì àti émírádì. 18 Kí ìpele kejì jẹ́ tọ́kọ́wásì, sàfáyà àti jásípérì. 19 Kí ìpele kẹta jẹ́ òkúta léṣémù,* ágétì àti ámétísì. 20 Kí ìpele kẹrin jẹ́ kírísóláítì, ónísì àti jéèdì. Kí o lẹ̀ wọ́n mọ́ ìtẹ́lẹ̀ tí o fi wúrà ṣe. 21 Àwọn òkúta náà yóò dúró fún orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì méjìlá (12). Kí o fín orúkọ sára òkúta kọ̀ọ̀kan bí èdìdì, kí orúkọ kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjìlá (12) náà.
22 “Kí o ṣe ẹ̀wọ̀n tó lọ́ pọ̀ sára aṣọ ìgbàyà náà, bí okùn tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe.+ 23 Kí o ṣe òrùka wúrà méjì sára aṣọ ìgbàyà náà, kí o sì fi òrùka méjèèjì sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà. 24 Kí o ki okùn oníwúrà méjèèjì bọnú àwọn òrùka méjì tó wà ní igun aṣọ ìgbàyà náà. 25 Kí o wá ki etí okùn méjèèjì bọnú ìtẹ́lẹ̀ méjèèjì náà, kí o sì so wọ́n mọ́ àwọn aṣọ èjìká éfódì náà níwájú. 26 Kí o ṣe òrùka wúrà méjì, kí o sì fi wọ́n sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà ní inú, kó dojú kọ éfódì náà.+ 27 Kí o tún ṣe òrùka wúrà méjì síwájú éfódì náà, nísàlẹ̀ aṣọ èjìká méjèèjì lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tó ti so pọ̀, lókè àmùrè* éfódì náà tí wọ́n hun.+ 28 Kí o fi okùn aláwọ̀ búlúù di aṣọ ìgbàyà náà mú, kí o fi okùn náà so àwọn òrùka aṣọ ìgbàyà náà mọ́ àwọn òrùka éfódì. Èyí máa mú kí aṣọ ìgbàyà náà dúró lórí éfódì náà, lókè àmùrè* éfódì tí wọ́n hun.
29 “Kí orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì máa wà lára aṣọ ìgbàyà ìdájọ́ tó wà ní àyà Áárónì nígbà tó bá wá sínú Ibi Mímọ́, kó lè jẹ́ ohun ìrántí níwájú Jèhófà nígbà gbogbo. 30 Kí o fi Úrímù àti Túmímù*+ sínú aṣọ ìgbàyà ìdájọ́ náà, kí wọ́n sì máa wà ní àyà Áárónì nígbà tó bá wá síwájú Jèhófà, kí Áárónì máa gbé ohun tí wọ́n fi ń ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí àyà rẹ̀ níwájú Jèhófà nígbà gbogbo.
31 “Fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ni kí o lò látòkè délẹ̀ láti fi ṣe aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá sí éfódì náà.+ 32 Kí o yọ ọrùn* sí aṣọ náà, ní àárín. Kí ẹni tó ń hun aṣọ ṣe ìgbátí sí ọrùn rẹ̀ yí ká. Kí o ṣe ọrùn aṣọ náà bíi ti ẹ̀wù irin, kó má bàa ya. 33 Kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ṣe pómégíránétì sí etí aṣọ náà yí ká, kí o sì fi àwọn agogo wúrà sáàárín wọn. 34 Kí o to agogo wúrà kan tẹ̀ lé pómégíránétì kan, agogo wúrà kan tẹ̀ lé pómégíránétì kan yí ká etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà. 35 Kí Áárónì wọ̀ ọ́ kó lè máa fi ṣiṣẹ́, kí àwọn ohun tó wà lára aṣọ náà sì máa dún nígbà tó bá ń wọ inú ibi mímọ́ níwájú Jèhófà àti nígbà tó bá ń jáde, kó má bàa kú.+
36 “Kí o fi ògidì wúrà ṣe irin pẹlẹbẹ tó ń dán, kí o sì fín ọ̀rọ̀ yìí sára rẹ̀ bí ẹni fín èdìdì, pé: ‘Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.’+ 37 Kí o fi okùn aláwọ̀ búlúù dè é mọ́ ara láwàní;+ kó máa wà níwájú láwàní náà. 38 Yóò wà ní iwájú orí Áárónì, kí Áárónì sì máa ru ẹ̀bi ẹni tó bá ṣe ohun tí kò tọ́ sí àwọn ohun mímọ́,+ èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà sí mímọ́ nígbà tí wọ́n fi ṣe ẹ̀bùn mímọ́. Kò gbọ́dọ̀ kúrò níwájú orí rẹ̀, kí wọ́n lè rí ojú rere Jèhófà.
39 “Kí o fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa hun aṣọ tó ní bátànì igun mẹ́rin, kí o sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa ṣe láwàní, kí o sì hun ọ̀já.+
40 “Kí o tún ṣe aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti ọ̀já fún àwọn ọmọ Áárónì+ pẹ̀lú aṣọ tí wọ́n máa wé sórí, kí wọ́n lè ní ògo àti ẹwà.+ 41 Kí o wọ aṣọ fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí o fòróró yàn wọ́n,+ kí o fiṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́,*+ kí o sì sọ wọ́n di mímọ́, wọ́n á sì di àlùfáà mi. 42 Kí o tún fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe ṣòkòtò péńpé* fún wọn kó lè bo ìhòòhò wọn.+ Kó gùn láti ìbàdí dé itan. 43 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí wọ́n bá wá sínú àgọ́ ìpàdé tàbí nígbà tí wọ́n wá síbi pẹpẹ láti ṣiṣẹ́ nínú ibi mímọ́, kí wọ́n má bàa jẹ̀bi, kí wọ́n sì kú. Òun àti àwọn ọmọ* rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa pa àṣẹ yìí mọ́ títí láé.
29 “Ohun tí o máa ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́ kí wọ́n lè di àlùfáà mi nìyí: Mú ọmọ akọ màlúù kan, àgbò méjì tí kò ní àbùkù,+ 2 búrẹ́dì aláìwú, búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n pò mọ́ òróró, tó rí bí òrùka àti búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n fi òróró pa.+ Ìyẹ̀fun àlìkámà* tó kúnná ni kí o fi ṣe wọ́n. 3 kí o wá kó wọn sínú apẹ̀rẹ̀, kí o sì fi apẹ̀rẹ̀ náà gbé e wá,+ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà.
4 “Kí o mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,+ kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.+ 5 Kí o wá kó àwọn aṣọ náà,+ kí o sì wọ aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ fún Áárónì, pẹ̀lú aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tó máa wà lábẹ́ éfódì, kí o wọ éfódì náà fún un àti aṣọ ìgbàyà, kí o sì so àmùrè éfódì tí wọ́n hun* náà mọ́ ìbàdí rẹ̀ pinpin.+ 6 Kí o wé láwàní náà sí i lórí, kí o sì fi àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́* sára láwàní náà;+ 7 kí o mú òróró àfiyanni,+ kí o sì dà á sí i lórí láti fòróró yàn án.+
8 “Kí o wá mú àwọn ọmọ rẹ̀ wá síwájú, kí o sì wọ aṣọ fún wọn,+ 9 kí o fi àwọn ọ̀já náà di Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lámùrè, kí o sì wé aṣọ sí wọn lórí; àwọn ni yóò máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà, kí èyí jẹ́ ìlànà tó máa wà títí láé.+ Bí o ṣe máa sọ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ di àlùfáà* nìyí.+
10 “Kí o mú akọ màlúù náà wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ màlúù náà.+ 11 Kí o pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà, lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 12 Fi ìka rẹ mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, kí o fi sórí àwọn ìwo pẹpẹ,+ kí o sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ 13 Kí o wá mú gbogbo ọ̀rá+ tó bo ìfun, àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn, kí o fi iná sun wọ́n kí wọ́n lè rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 14 Àmọ́ kí o fi iná sun ẹran akọ màlúù náà pẹ̀lú awọ rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn òde àgọ́. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
15 “Kí o wá mú ọ̀kan lára àwọn àgbò náà, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí àgbò náà.+ 16 Kí o pa àgbò náà, kí o mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì wọ́n ọn sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà.+ 17 Gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, kí o fọ ìfun rẹ̀+ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì to àwọn ègé ẹran náà pẹ̀lú orí rẹ̀. 18 Kí o sun àgbò náà lódindi, jẹ́ kó rú èéfín lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ló jẹ́ sí Jèhófà, olóòórùn dídùn.*+ Ó jẹ́ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
19 “Lẹ́yìn náà, kí o mú àgbò kejì, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí àgbò náà.+ 20 Kí o pa àgbò náà, kí o mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì fi sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún Áárónì àti sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún àwọn ọmọ rẹ̀, kí o tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn, kí o sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà. 21 Kí o wá mú lára ẹ̀jẹ̀ tó wà lórí pẹpẹ àti lára òróró àfiyanni náà,+ kí o sì wọ́n ọn sára Áárónì àti aṣọ rẹ̀ àti sára àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn, kí òun àti aṣọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn lè jẹ́ mímọ́.+
22 “Kí o yọ ọ̀rá lára àgbò náà, kí o gé ìrù rẹ̀ tó lọ́ràá, ọ̀rá tó bo ìfun, àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tó wà lára wọn,+ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún, torí ó jẹ́ àgbò àfiyanni.+ 23 Kí o tún mú búrẹ́dì ribiti kan àti búrẹ́dì tí wọ́n fi òróró sí tó rí bí òrùka àti búrẹ́dì pẹlẹbẹ kan látinú apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú tó wà níwájú Jèhófà. 24 Kí o kó gbogbo wọn sí ọwọ́ Áárónì àti sí ọwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà. 25 Kí o wá gbà á lọ́wọ́ wọn, kí o sì sun ún lórí pẹpẹ, lórí ẹbọ sísun, kó lè mú òórùn dídùn* jáde níwájú Jèhófà. Ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ló jẹ́.
26 “Kí o gé igẹ̀ àgbò àfiyanni náà,+ tí o fi rúbọ torí Áárónì, kí o sì fì í síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà, yóò sì di ìpín tìrẹ. 27 Kí o ya igẹ̀ ọrẹ fífì náà sí mímọ́, pẹ̀lú ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ tí o fì, èyí tí o gé lára àgbò àfiyanni náà,+ látinú ohun tí o fi rúbọ torí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. 28 Yóò di ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó jẹ́ àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa pa mọ́ títí láé, torí ìpín mímọ́ ló jẹ́, yóò sì di ìpín mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa fún wọn.+ Ìpín mímọ́ wọn fún Jèhófà ni, látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wọn.+
29 “Àwọn aṣọ mímọ́+ tó jẹ́ ti Áárónì ni àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa lò+ tí wọ́n bá ti fòróró yàn wọ́n, tí wọ́n sì di àlùfáà. 30 Kí àlùfáà tó bá rọ́pò rẹ̀ lára àwọn ọmọ rẹ̀ tó sì wá sínú àgọ́ ìpàdé láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ wọ àwọn aṣọ náà fún ọjọ́ méje.+
31 “Kí o mú àgbò àfiyanni, kí o sì bọ ẹran rẹ̀ ní ibi mímọ́.+ 32 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ+ ẹran àgbò náà àti búrẹ́dì tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 33 Kí wọ́n jẹ àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣe ètùtù láti sọ wọ́n di àlùfáà,* kí wọ́n sì di mímọ́. Àmọ́ ẹni tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i* ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, torí ohun mímọ́ ni.+ 34 Bí èyíkéyìí nínú ẹran tí o fi rú ẹbọ ìyannisípò àti búrẹ́dì náà bá ṣẹ́ kù di àárọ̀, kí o fi iná sun ohun tó ṣẹ́ kù.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, torí ohun mímọ́ ni.
35 “Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ yìí ni kí o ṣe fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. Ọjọ́ méje ni kí o lò láti sọ wọ́n di àlùfáà.*+ 36 Kí o máa fi akọ màlúù tó wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rúbọ lójoojúmọ́ láti fi ṣe ètùtù, kí o sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lára rẹ̀, kí o sì fòróró yàn án láti sọ ọ́ di mímọ́.+ 37 Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà, kí o sì sọ ọ́ di mímọ́ kó lè di pẹpẹ mímọ́ jù lọ.+ Ẹnikẹ́ni tó bá fara kan pẹpẹ náà ti gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.
38 “Ohun tí ìwọ yóò fi rúbọ lórí pẹpẹ náà nìyí: ọmọ àgbò méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan lójoojúmọ́ títí lọ.+ 39 Kí o fi ọmọ àgbò kan rúbọ ní àárọ̀, kí o sì fi ọmọ àgbò kejì rúbọ ní ìrọ̀lẹ́.*+ 40 Kí o fi ọmọ àgbò àkọ́kọ́ rúbọ pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí: ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí o pò mọ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* òróró tí wọ́n fún àti ọrẹ ohun mímu tó jẹ́ wáìnì tó kún ìlàrin òṣùwọ̀n hínì. 41 Kí o fi ọmọ àgbò kejì rúbọ ní ìrọ̀lẹ́,* pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti ọrẹ ohun mímu kan náà bíi ti àárọ̀. Kí o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn,* ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 42 Kí ẹ máa rú ẹbọ sísun yìí nígbà gbogbo jálẹ̀ àwọn ìran yín ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Jèhófà, níbi tí màá ti pàdé yín láti bá yín sọ̀rọ̀.+
43 “Màá pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níbẹ̀, ògo mi yóò sì sọ ọ́ di mímọ́.+ 44 Màá sọ àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ di mímọ́, màá sì sọ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀+ di mímọ́, kí wọ́n lè di àlùfáà mi. 45 Èmi yóò máa gbé láàárín* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.+ 46 Ó sì dájú pé wọ́n á mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn, tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì kí n lè máa gbé láàárín wọn.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn.
30 “Kí o ṣe pẹpẹ kan láti máa fi sun tùràrí;+ igi bọn-ọ̀n-ní ni kí o fi ṣe é.+ 2 Kó ní igun mẹ́rin tó dọ́gba, ìgbọ̀nwọ́* kan ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Kí pẹpẹ náà àti àwọn ìwo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan.+ 3 Kí o fi ògidì wúrà bò ó lókè pẹ̀lú ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yí ká àti àwọn ìwo rẹ̀; kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká. 4 Kí o fi wúrà ṣe òrùka méjì sí ìsàlẹ̀ ìgbátí rẹ̀* ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì tó wà lódìkejì ara wọn, ìyẹn ló máa gba àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e dúró. 5 Igi bọn-ọ̀n-ní ni kí o fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, kí o sì fi wúrà bò wọ́n. 6 Kí o gbé e síwájú aṣọ ìdábùú tó wà nítòsí àpótí Ẹ̀rí,+ níwájú ìbòrí tó wà lórí Ẹ̀rí, níbi tí màá ti pàdé rẹ.+
7 “Kí Áárónì+ sun tùràrí onílọ́fínńdà+ lórí rẹ̀,+ kí ó mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ nígbà tó bá ń bójú tó àwọn fìtílà náà+ láràárọ̀. 8 Bákan náà, tí Áárónì bá tan àwọn fìtílà náà ní ìrọ̀lẹ́,* kó sun tùràrí náà. Bí wọ́n á ṣe máa sun tùràrí ní gbogbo ìgbà níwájú Jèhófà jálẹ̀ àwọn ìran yín nìyẹn. 9 Ẹ ò gbọ́dọ̀ sun tùràrí tí kò yẹ + tàbí rú ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ọkà lórí rẹ̀, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ da ọrẹ ohun mímu sórí rẹ̀. 10 Kí Áárónì máa ṣe ètùtù lórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.+ Kí ó mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ti ètùtù+ láti ṣe ètùtù fún un lẹ́ẹ̀kan lọ́dún jálẹ̀ gbogbo ìran yín. Ohun mímọ́ jù lọ ló jẹ́ sí Jèhófà.”
11 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 12 “Nígbàkigbà tí o bá ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí kálukú mú ohun tí yóò fi ra ẹ̀mí* rẹ̀ pa dà wá fún Jèhófà nígbà ìkànìyàn náà. Èyí ò ní jẹ́ kí ìyọnu kankan ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá forúkọ wọn sílẹ̀. 13 Ohun tí gbogbo àwọn tó bá forúkọ sílẹ̀ máa mú wá nìyí: ààbọ̀ ṣékélì,* kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.*+ Ogún (20) òṣùwọ̀n gérà* ni ṣékélì kan. Ààbọ̀ ṣékélì ni ọrẹ fún Jèhófà.+ 14 Kí gbogbo ẹni tó bá forúkọ sílẹ̀, tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè mú ọrẹ wá fún Jèhófà.+ 15 Kí ọlọ́rọ̀ má ṣe mú ohun tó ju ààbọ̀ ṣékélì* wá, kí aláìní má sì mú ohun tó kéré síyẹn wá láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà kí ẹ lè fi ṣe ètùtù fún ẹ̀mí* yín. 16 Kí o gba owó fàdákà fún ètùtù lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì mú un wá fún iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé, kó lè jẹ́ ohun ìrántí níwájú Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti ṣe ètùtù fún ẹ̀mí* yín.”
17 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 18 “Kí o fi bàbà ṣe bàsíà kan pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀ fún wíwẹ̀;+ kí o gbé e sáàárín àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ, kí o sì bu omi sínú rẹ̀.+ 19 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn níbẹ̀.+ 20 Tí wọ́n bá ń lọ sínú àgọ́ ìpàdé tàbí tí wọ́n bá sún mọ́ pẹpẹ láti ṣiṣẹ́, láti fi iná sun ọrẹ kó sì rú èéfín sí Jèhófà, kí wọ́n lo omi náà kí wọ́n má bàa kú. 21 Kí wọ́n fi wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n má bàa kú. Kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà yìí títí lọ, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ jálẹ̀ àwọn ìran wọn.”+
22 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 23 “Lẹ́yìn náà, kí o mú àwọn lọ́fínńdà tó dáa jù: ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìwọ̀n òjíá dídì àti sínámónì dídùn tó jẹ́ ìdajì rẹ̀, ìyẹn igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n àti igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n ewéko kálámọ́sì dídùn 24 àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìwọ̀n kaṣíà, kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,*+ pẹ̀lú òróró ólífì tó kún òṣùwọ̀n hínì* kan. 25 Kí o wá fi ṣe òróró àfiyanni mímọ́; kí o ro àwọn èròjà náà pọ̀ dáadáa.*+ Òróró àfiyanni mímọ́ ni yóò jẹ́.
26 “Kí o ta òróró náà sí àgọ́ ìpàdé+ àti àpótí Ẹ̀rí, 27 pẹ̀lú tábìlì àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà àti àwọn ohun èlò rẹ̀, pẹpẹ tùràrí, 28 pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, pẹ̀lú bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀. 29 Kí o sọ wọ́n di mímọ́ kí wọ́n lè di mímọ́ jù lọ.+ Ẹnikẹ́ni tó bá fara kàn wọ́n ti gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.+ 30 Kí o fi òróró yan Áárónì+ àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ kí o sì sọ wọ́n di mímọ́ kí wọ́n lè di àlùfáà mi.+
31 “Kí o sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Òróró yìí ni yóò máa jẹ́ òróró àfiyanni mímọ́ fún mi ní ìrandíran yín.+ 32 Èèyàn kankan ò gbọ́dọ̀ fi pa ara, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tó ní irú èròjà rẹ̀. Ohun mímọ́ ni. Yóò máa jẹ́ ohun mímọ́ fún yín. 33 Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe òróró ìpara tó dà bíi rẹ̀ tàbí tó fi pa ẹni tí kò tọ́ sí* lára, kí ẹ pa ẹni náà, kí ẹ lè mú un kúrò nínú àwọn èèyàn rẹ̀.’”+
34 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Mú àwọn lọ́fínńdà yìí ní ìwọ̀n kan náà:+ àwọn ẹ̀kán sítákítè, ọ́níkà, gábánọ́mù onílọ́fínńdà àti ògidì oje igi tùràrí. 35 Kí o fi ṣe tùràrí;+ kí o ro àwọn èròjà náà pọ̀ dáadáa,* fi iyọ̀ sí i,+ kó jẹ́ ògidì, kó sì jẹ́ mímọ́. 36 Kí o gún lára rẹ̀, kó sì kúnná, kí o wá bù lára rẹ̀ síwájú Ẹ̀rí nínú àgọ́ ìpàdé, níbi tí màá ti pàdé rẹ. Kó jẹ́ mímọ́ jù lọ fún yín. 37 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe tùràrí tó ní irú èròjà yìí fún ìlò ara yín.+ Kí ẹ kà á sí ohun mímọ́ fún Jèhófà. 38 Tí ẹnikẹ́ni bá ṣe ohun tó jọ ọ́ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, ṣe ni kí ẹ pa ẹni náà, kí ẹ lè mú un kúrò nínú àwọn èèyàn rẹ̀.
31 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Wò ó, mo ti yan* Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì látinú ẹ̀yà Júdà.+ 3 Màá fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún inú rẹ̀, màá fún un ní ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ ọnà, 4 kó lè ṣe iṣẹ́ ọnà ayàwòrán, kó lè fi wúrà, fàdákà àti bàbà ṣiṣẹ́, 5 kó lè gé òkúta, kó sì tò ó,+ kó sì lè fi igi ṣe onírúurú nǹkan.+ 6 Bákan náà, mo ti yan Òhólíábù + ọmọ Áhísámákì látinú ẹ̀yà Dánì kó lè ràn án lọ́wọ́, màá sì fi ọgbọ́n sínú ọkàn gbogbo àwọn tó mọṣẹ́,* kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ:+ 7 àgọ́ ìpàdé,+ àpótí Ẹ̀rí+ àti ìbòrí rẹ̀,+ gbogbo ohun èlò àgọ́ náà, 8 tábìlì+ àti àwọn ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,+ pẹpẹ tùràrí,+ 9 pẹpẹ ẹbọ sísun+ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀,+ 10 àwọn aṣọ tí wọ́n hun dáadáa, aṣọ mímọ́ ti àlùfáà Áárónì, aṣọ tí àwọn ọmọ rẹ̀ máa fi ṣiṣẹ́ àlùfáà,+ 11 òróró àfiyanni àti tùràrí onílọ́fínńdà fún ibi mímọ́.+ Kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ.”
12 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 13 “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ pa àwọn sábáàtì mi mọ́,+ torí ó jẹ́ àmì láàárín èmi àti ẹ̀yin ní ìrandíran yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń sọ yín di mímọ́. 14 Kí ẹ pa Sábáàtì mọ́, torí ohun mímọ́ ló jẹ́ fún yín.+ Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá sọ ọ́ di aláìmọ́. Tí ẹnikẹ́ni bá ṣiṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà, kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò nínú àwọn èèyàn rẹ̀.+ 15 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, àmọ́ kí ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá.+ Ohun mímọ́ ló jẹ́ fún Jèhófà. Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ Sábáàtì. 16 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ pa Sábáàtì mọ́; wọ́n gbọ́dọ̀ máa pa Sábáàtì mọ́ jálẹ̀ gbogbo ìran wọn. Májẹ̀mú tó máa wà títí lọ ni. 17 Ó jẹ́ àmì tó máa wà pẹ́ títí láàárín èmi àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ torí ọjọ́ mẹ́fà ni Jèhófà fi dá ọ̀run àti ayé, ó wá sinmi ní ọjọ́ keje, ara sì tù ú.’”+
18 Gbàrà tó bá a sọ̀rọ̀ tán lórí Òkè Sínáì, ó fún Mósè ní wàláà Ẹ̀rí méjì,+ àwọn wàláà òkúta tí ìka Ọlọ́run+ kọ̀wé sí.
32 Ní gbogbo àkókò yẹn, àwọn èèyàn náà rí i pé Mósè ń pẹ́ lórí òkè náà.+ Àwọn èèyàn náà wá yí Áárónì ká, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ó yá, ṣe ọlọ́run kan fún wa tó máa ṣáájú wa,+ torí a ò mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Mósè yìí, ẹni tó kó wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.” 2 Ni Áárónì bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gba yẹtí wúrà+ tó wà ní etí àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kí ẹ sì kó o wá fún mi.” 3 Gbogbo àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ yẹtí wúrà tó wà ní etí wọn, wọ́n sì ń kó o wá fún Áárónì. 4 Ó gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, ó lo irinṣẹ́ àwọn tó ń fín nǹkan láti fi mọ ọ́n, ó sì fi ṣe ère* ọmọ màlúù.+ Wọ́n wá ń sọ pé: “Ìwọ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run rẹ nìyí, òun ló mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+
5 Nígbà tí Áárónì rí èyí, ó mọ pẹpẹ kan síwájú rẹ̀. Áárónì wá kéde pé: “Àjọyọ̀ wà fún Jèhófà lọ́la.” 6 Ni wọ́n bá tètè dìde ní ọjọ́ kejì, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ń mú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá. Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu. Wọ́n sì dìde láti gbádùn ara wọn.+
7 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Máa lọ, sọ̀ kalẹ̀, torí pé àwọn èèyàn rẹ tí o mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ti ba ara wọn jẹ́.+ 8 Wọ́n ti yára kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa rìn.+ Wọ́n ti ṣe ère* ọmọ màlúù fún ara wọn, wọ́n ń tẹrí ba fún un, wọ́n sì ń rúbọ sí i, wọ́n ń sọ pé, ‘Ìwọ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run rẹ nìyí, òun ló mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.’” 9 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: “Mo ti rí i pé alágídí* ni àwọn èèyàn yìí.+ 10 Ní báyìí, fi mí sílẹ̀, màá fi ìbínú mi tó ń jó bí iná pa wọ́n run, kí o sì jẹ́ kí n sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá dípò wọn.”+
11 Mósè wá bẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,*+ ó sọ pé: “Jèhófà, kí ló dé tí wàá fi bínú gidigidi sí àwọn èèyàn rẹ, lẹ́yìn tí o fi agbára ńlá àti ọwọ́ agbára mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì?+ 12 Ṣé kí àwọn ará Íjíbítì wá máa sọ pé, ‘Èrò ibi ló wà lọ́kàn rẹ̀ nígbà tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ wa. Ṣe ló fẹ́ pa wọ́n síbi àwọn òkè, kó sì run wọ́n kúrò lórí ilẹ̀’?+ Má ṣe jẹ́ kínú bí ọ sí wọn, jọ̀ọ́ pèrò dà nípa ìpinnu tí o ṣe* láti mú àjálù yìí bá àwọn èèyàn rẹ. 13 Rántí Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí o fi ara rẹ búra fún pé, ‘Màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,+ màá sì fún ọmọ* rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo yàn yìí, kó lè di ohun ìní wọn títí láé.’”+
14 Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí í pèrò dà* lórí àjálù tó sọ pé òun máa mú bá àwọn èèyàn òun.+
15 Lẹ́yìn náà, Mósè yíjú pa dà, ó sì sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè náà, ó gbé wàláà Ẹ̀rí méjì+ náà dání.+ Ọ̀rọ̀ tí a kọ wà lára wàláà náà ní ojú méjèèjì, ní iwájú àti ní ẹ̀yìn. 16 Iṣẹ́ ọnà Ọlọ́run ni àwọn wàláà náà, Ọlọ́run ló sì kọ ọ̀rọ̀ sára rẹ̀.+ 17 Nígbà tí Jóṣúà bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń pariwo, ó sọ fún Mósè pé: “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.” 18 Àmọ́ Mósè sọ pé:
“Kì í ṣe orin ìṣẹ́gun,*
Kì í sì í ṣe ìró àwọn tó ń pohùn réré ẹkún torí pé wọ́n ṣẹ́gun wọn;
Ìró orin míì ni mò ń gbọ́.”
19 Gbàrà tí Mósè sún mọ́ àgọ́ náà, tó sì rí ère ọmọ màlúù+ àtàwọn tó ń jó, inú bí Mósè gan-an, ó ju àwọn wàláà náà sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn túútúú sí ẹsẹ̀ òkè náà.+ 20 Ó mú ère ọmọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó fi iná sun ún, ó sì fọ́ ọ túútúú tó fi di lẹ́búlẹ́bú;+ ó wá fọ́n ọn sójú omi, ó sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mu ún.+ 21 Mósè bi Áárónì pé: “Kí ni àwọn èèyàn yìí ṣe sí ọ tí o fi mú kí wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá?” 22 Áárónì fèsì pé: “Má bínú, olúwa mi. O mọ̀ dáadáa pé èrò ibi ló wà lọ́kàn àwọn èèyàn náà.+ 23 Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe ọlọ́run kan fún wa tó máa ṣáájú wa, torí a ò mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Mósè yìí, ẹni tó kó wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.’+ 24 Mo wá sọ fún wọn pé, ‘Kí ẹnikẹ́ni tó bá ní wúrà yọ ọ́ wá, kó sì fún mi.’ Mo jù ú sínú iná, òun sì ni mo fi ṣe ọmọ màlúù yìí.”
25 Mósè rí i pé apá ò ká àwọn èèyàn náà mọ́, torí Áárónì ti fàyè gbà wọ́n, wọ́n sì ti di ẹni ìtìjú lójú àwọn alátakò wọn. 26 Lẹ́yìn náà, Mósè dúró ní ẹnubodè àgọ́ náà, ó sì sọ pé: “Ta ló fara mọ́ Jèhófà? Kó máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi!”+ Gbogbo àwọn ọmọ Léfì sì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. 27 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Kí kálukú yín sán idà rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́, kí ẹ sì lọ káàkiri àgọ́ náà láti ẹnubodè sí ẹnubodè, kí kálukú pa arákùnrin rẹ̀, aládùúgbò rẹ̀ àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.’”+ 28 Àwọn ọmọ Léfì ṣe ohun tí Mósè sọ. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn ni wọ́n pa lọ́jọ́ yẹn. 29 Mósè wá sọ pé: “Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀* fún Jèhófà lónìí, torí kálukú yín ti kẹ̀yìn sí ọmọ rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀;+ òun yóò bù kún yín lónìí.”+
30 Ní ọjọ́ kejì, Mósè sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá lẹ dá, màá sì gòkè tọ Jèhófà lọ báyìí, kí n wò ó bóyá mo lè bá yín wá nǹkan ṣe sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ dá.”+ 31 Mósè wá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn yìí dá mà burú o! Wọ́n fi wúrà ṣe ọlọ́run fún ara wọn!+ 32 Àmọ́, tí o bá fẹ́, dárí jì wọ́n;+ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jọ̀ọ́, pa mí rẹ́ kúrò nínú ìwé rẹ tí o kọ.”+ 33 Àmọ́ Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Màá pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ mí rẹ́ kúrò nínú ìwé mi. 34 Máa lọ báyìí, darí àwọn èèyàn náà lọ síbi tí mo bá ọ sọ. Wò ó! Áńgẹ́lì mi yóò ṣáájú rẹ.+ Lọ́jọ́ tí mo bá sì fẹ́ ṣèdájọ́, èmi yóò fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.” 35 Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìyọnu bá àwọn èèyàn náà torí wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù, èyí tí Áárónì ṣe.
33 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: “Kúrò níbí pẹ̀lú àwọn èèyàn tí o mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Kí ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé, ‘Ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ ni màá fún.’+ 2 Màá rán áńgẹ́lì kan ṣáájú yín,+ màá sì lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò, pẹ̀lú àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+ 3 Ẹ máa lọ sí ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ Àmọ́ mi ò ní bá yín lọ, torí alágídí* ni yín,+ mo sì lè pa yín run lójú ọ̀nà.”+
4 Nígbà tí àwọn èèyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ líle yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀, ìkankan nínú wọn ò sì lo ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀. 5 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Alágídí* ni yín.+ Ní ìṣẹ́jú kan, mo lè la àárín yín kọjá, kí n sì pa yín run.+ Torí náà, ẹ yọ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ yín kúrò títí màá fi mọ ohun tí màá ṣe sí yín.’” 6 Láti Òkè Hórébù lọ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ti lo* ohun ọ̀ṣọ́ wọn.
7 Mósè wá ká àgọ́ rẹ̀, ó sì lọ pa àgọ́ náà sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tó jìnnà sí àwọn yòókù, ó sì pè é ní àgọ́ ìpàdé. Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà+ yóò jáde lọ sí àgọ́ ìpàdé náà, tó wà ní ẹ̀yìn ibùdó. 8 Gbàrà tí Mósè bá ti ń lọ síbi àgọ́ náà, gbogbo àwọn èèyàn náà á dìde, wọ́n á sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn, wọ́n á sì máa wo Mósè títí yóò fi wọnú àgọ́. 9 Gbàrà tí Mósè bá ti wọnú àgọ́, ọwọ̀n ìkùukùu*+ máa sọ̀ kalẹ̀, á sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ nígbà tí Ọlọ́run bá ń bá Mósè sọ̀rọ̀.+ 10 Nígbà tí gbogbo èèyàn rí ọwọ̀n ìkùukùu tó dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, kálukú wọn dìde, wọ́n sì tẹrí ba ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn. 11 Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,+ bí ìgbà téèyàn méjì ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. Nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn náà, Jóṣúà+ ọmọ Núnì, òjíṣẹ́ rẹ̀ àti ìránṣẹ́ rẹ̀+ ò kúrò níbi àgọ́ náà.
12 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: “Wò ó, ò ń sọ fún mi pé, ‘Darí àwọn èèyàn yìí lọ,’ àmọ́ o ò jẹ́ kí n mọ ẹni tí o máa rán pẹ̀lú mi. O tún sọ pé, ‘Mo fi orúkọ mọ̀ ọ́,* o sì tún rí ojúure mi.’ 13 Jọ̀ọ́, tí mo bá rí ojúure rẹ, jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ,+ kí n lè mọ̀ ọ́, kí n sì túbọ̀ máa rí ojú rere rẹ. Tún ro ti orílẹ̀-èdè yìí, tí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ.”+ 14 Ó sọ pé: “Èmi fúnra mi* yóò bá ọ lọ,+ màá sì fún ọ ní ìsinmi.”+ 15 Mósè wá sọ fún un pé: “Tí ìwọ fúnra rẹ* ò bá ní bá wa lọ, má ṣe mú wa kúrò níbí. 16 Báwo ni àwọn èèyàn yóò ṣe mọ̀ pé èmi àti àwọn èèyàn rẹ ti rí ojúure rẹ? Ṣebí tí o bá bá wa lọ ni,+ kí èmi àti àwọn èèyàn rẹ lè yàtọ̀ sí gbogbo èèyàn yòókù tó wà ní ayé?”+
17 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Màá tún ṣe ohun tí o ní kí n ṣe yìí, torí o ti rí ojúure mi, mo sì fi orúkọ mọ̀ ọ́.” 18 Mósè bá sọ pé: “Jọ̀ọ́, fi ògo rẹ hàn mí.” 19 Àmọ́ Ọlọ́run dáhùn pé: “Màá mú kí gbogbo oore mi kọjá níwájú rẹ, màá sì kéde orúkọ Jèhófà níwájú rẹ;+ èmi yóò ṣojúure sí ẹni tí èmi yóò ṣojúure sí, èmi yóò sì ṣàánú ẹni tí èmi yóò ṣàánú.”+ 20 Àmọ́ ó tún sọ pé: “O ò lè rí ojú mi, torí kò sí èèyàn tó lè rí mi, kó sì wà láàyè.”
21 Jèhófà wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ibì kan nìyí nítòsí mi. Dúró sórí àpáta. 22 Tí ògo mi bá ń kọjá, màá fi ọ́ pa mọ́ sínú ihò àpáta, màá sì fi ọwọ́ mi bò ọ́ títí màá fi kọjá. 23 Lẹ́yìn náà, màá gbé ọwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi. Àmọ́ o ò ní rí ojú mi.”+
34 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Kí ìwọ fúnra rẹ gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́,+ màá sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lórí àwọn wàláà àkọ́kọ́+ tí o fọ́ túútúú+ sára rẹ̀. 2 Múra sílẹ̀ de àárọ̀, torí ìwọ yóò gun Òkè Sínáì lọ ní àárọ̀, kí o sì dúró síbẹ̀ lórí òkè náà níwájú mi.+ 3 Àmọ́ ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ bá ọ lọ, ẹnikẹ́ni ò sì gbọ́dọ̀ sí níbikíbi lórí òkè náà. Àwọn agbo ẹran tàbí ọ̀wọ́ ẹran pàápàá ò gbọ́dọ̀ jẹko níwájú òkè yẹn.”+
4 Mósè wá gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́, ó gbéra ní àárọ̀ kùtù lọ sí Òkè Sínáì, bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un, ó sì gbé wàláà òkúta méjì náà dání. 5 Jèhófà sọ̀ kalẹ̀+ nínú ìkùukùu,* ó dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ níbẹ̀, ó sì kéde orúkọ Jèhófà.+ 6 Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú,+ tó ń gba tẹni rò,*+ tí kì í tètè bínú,+ tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ àti òtítọ́*+ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, 7 tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini,+ àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ, dórí ìran kẹta àti dórí ìran kẹrin.”+
8 Mósè sáré tẹrí ba, ó sì wólẹ̀. 9 Ó sọ pé: “Jèhófà, tí mo bá ti rí ojúure rẹ, jọ̀ọ́ Jèhófà, máa bá wa lọ kí o sì wà láàárín wa,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé alágídí* ni wá,+ kí o dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì,+ kí o sì mú wa bí ohun ìní rẹ.” 10 Ó fèsì pé: “Èmi yóò dá májẹ̀mú kan: Níṣojú gbogbo èèyàn rẹ, èmi yóò ṣe àwọn ohun àgbàyanu tí wọn ò ṣe* rí ní gbogbo ayé tàbí láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè,+ gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń gbé láàárín wọn yóò rí iṣẹ́ Jèhófà, torí ohun àgbàyanu ni màá ṣe fún yín.+
11 “Ẹ fiyè sí ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín lónìí.+ Èmi yóò lé àwọn Ámórì kúrò níwájú yín àti àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+ 12 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá májẹ̀mú,+ kó má bàa di ìdẹkùn fún yín.+ 13 Ṣùgbọ́n kí ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, kí ẹ sì fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn túútúú, kí ẹ sì wó àwọn òpó òrìṣà* wọn lulẹ̀.+ 14 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún ọlọ́run míì,+ torí Jèhófà máa ń fẹ́* kí a jọ́sìn òun nìkan.* Àní, ó jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa sin òun nìkan.+ 15 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú, torí tí wọ́n bá ń bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn,+ ẹnì kan yóò pè ọ́ wá, wàá sì jẹ nínú ẹbọ rẹ̀.+ 16 Ó sì dájú pé ẹ máa mú lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín,+ àwọn ọmọbìnrin wọn máa bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, wọ́n á sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe.+
17 “O ò gbọ́dọ̀ fi irin rọ àwọn ọlọ́run.+
18 “Kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.+ Ẹ jẹ búrẹ́dì aláìwú bí mo ṣe pa á láṣẹ fún yín; ọjọ́ méje ni kí ẹ fi ṣe é ní àkókò rẹ̀ nínú oṣù Ábíbù,*+ torí oṣù Ábíbù lẹ kúrò ní Íjíbítì.
19 “Tèmi ni gbogbo ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí,*+ pẹ̀lú gbogbo ẹran ọ̀sìn yín, yálà ó jẹ́ àkọ́bí akọ màlúù tàbí ti àgùntàn.+ 20 Kí ẹ fi àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pa dà. Àmọ́ tí ẹ ò bá rà á pa dà, kí ẹ ṣẹ́ ọrùn rẹ̀. Kí ẹ ra gbogbo àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin yín pa dà.+ Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wá síwájú mi lọ́wọ́ òfo.
21 “Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, àmọ́ kí ẹ sinmi* ní ọjọ́ keje.+ Kódà, nígbà ìtúlẹ̀ àti ìkórè, kí ẹ sinmi.
22 “Kí ẹ fi àwọn èso yín tó kọ́kọ́ pọ́n nígbà ìkórè àlìkámà* ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ àti Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé* nígbà tí ọdún bá yí po.+
23 “Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún ni kí gbogbo ọkùnrin* yín wá síwájú Jèhófà, Olúwa tòótọ́, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 24 Torí màá lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú yín,+ màá sì mú kí ilẹ̀ yín fẹ̀, ilẹ̀ yín ò sì ní wọ ẹnikẹ́ni lójú nígbà tí ẹ bá ń gòkè lọ rí ojú Jèhófà Ọlọ́run yín lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún.
25 “O ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀jẹ̀ rúbọ sí mi pa pọ̀ pẹ̀lú ohun tó ní ìwúkàrà.+ Ẹbọ àjọyọ̀ Ìrékọjá ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ kù di àárọ̀.+
26 “Kí o mú èyí tó dáa jù nínú àwọn èso tó kọ́kọ́ pọ́n ní ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+
“O ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.”+
27 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,+ torí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi yóò fi bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.”+ 28 Ó sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. Kò jẹun rárá, kò sì mu omi.+ Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà sára àwọn wàláà náà, Òfin Mẹ́wàá.*+
29 Mósè wá sọ̀ kalẹ̀ látorí Òkè Sínáì, àwọn wàláà Ẹ̀rí méjì náà sì wà lọ́wọ́ rẹ̀.+ Nígbà tó sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, Mósè ò mọ̀ pé ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú òun torí ó ti ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. 30 Nígbà tí Áárónì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí Mósè, wọ́n rí i pé ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú rẹ̀, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti sún mọ́ ọn.+
31 Àmọ́ Mósè pè wọ́n, Áárónì àti gbogbo ìjòyè àpéjọ náà sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, Mósè sì bá wọn sọ̀rọ̀. 32 Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ ọn, ó sì sọ gbogbo àṣẹ tí Jèhófà pa fún un lórí Òkè Sínáì fún wọn.+ 33 Tí Mósè bá ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, á fi nǹkan bojú.+ 34 Àmọ́ tí Mósè bá fẹ́ wọlé lọ bá Jèhófà sọ̀rọ̀, á ṣí ìbòjú náà kúrò títí á fi jáde.+ Ó wá jáde, ó sì sọ àwọn àṣẹ tó gbà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 35 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rí i pé ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú Mósè; torí náà, Mósè lo ìbòjú náà títí ó fi wọlé lọ bá Ọlọ́run* sọ̀rọ̀.+
35 Lẹ́yìn náà, Mósè pe gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa pọ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Àwọn ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé ká ṣe nìyí:+ 2 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, àmọ́ kí ọjọ́ keje jẹ́ mímọ́ fún yín. Kí ọjọ́ náà jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá.+ Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ náà.+ 3 Ní ọjọ́ Sábáàtì, ẹ ò gbọ́dọ̀ dá iná ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé.”
4 Mósè tún sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nìyí, 5 ‘Kí ẹ gba ọrẹ fún Jèhófà láàárín ara yín.+ Kí gbogbo ẹni tó bá wù látọkàn wá+ mú ọrẹ wá fún Jèhófà: wúrà, fàdákà, bàbà, 6 fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, irun ewúrẹ́,+ 7 awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa, awọ séálì, igi bọn-ọ̀n-ní, 8 òróró fìtílà, òróró básámù tí wọ́n á fi ṣe òróró àfiyanni àti tùràrí onílọ́fínńdà,+ 9 àwọn òkúta ónísì àti àwọn òkúta míì tí wọ́n máa tò sára éfódì+ àti aṣọ ìgbàyà.+
10 “‘Kí gbogbo àwọn tó mọṣẹ́*+ láàárín yín wá ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ, 11 ìyẹn, àgọ́ ìjọsìn pẹ̀lú àgọ́ rẹ̀ àti ìbòrí rẹ̀, àwọn ìkọ́ àti àwọn férémù rẹ̀, àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀; 12 Àpótí náà+ àti àwọn ọ̀pá rẹ̀,+ ìbòrí+ àti aṣọ+ tí wọ́n á ta síbẹ̀; 13 tábìlì+ àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti búrẹ́dì àfihàn;+ 14 ọ̀pá fìtílà+ tí wọ́n á máa fi tan iná àti àwọn ohun èlò rẹ̀ àti àwọn fìtílà rẹ̀ àti òróró láti máa fi tan iná;+ 15 pẹpẹ tùràrí+ àti àwọn ọ̀pá rẹ̀; òróró àfiyanni àti tùràrí onílọ́fínńdà;+ aṣọ* tó máa wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn; 16 pẹpẹ ẹbọ sísun+ àti àgbàyan* tí ẹ ó fi bàbà ṣe, àwọn ọ̀pá rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀;+ 17 àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta sí àgbàlá,+ àwọn òpó rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀; aṣọ* tó máa wà ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá; 18 àwọn èèkàn àgọ́ ìjọsìn àtàwọn èèkàn àgbàlá pẹ̀lú àwọn okùn wọn;+ 19 àwọn aṣọ tí wọ́n hun dáadáa+ láti máa fi ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ ti àlùfáà Áárónì+ àti aṣọ tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa fi ṣiṣẹ́ àlùfáà.’”
20 Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá kúrò níwájú Mósè. 21 Gbogbo ẹni tí ọkàn rẹ̀ sún un+ tó sì tinú rẹ̀ wá láti ṣe ọrẹ mú ọrẹ wá fún Jèhófà, ọrẹ tí wọ́n á fi ṣe àgọ́ ìpàdé, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn aṣọ mímọ́ náà. 22 Wọ́n ń wá ṣáá, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kálukú ń wá láti ṣe ọrẹ látọkàn wá, wọ́n mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n ń so mọ́ aṣọ wá, pẹ̀lú yẹtí, òrùka àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ míì, pẹ̀lú onírúurú ohun èlò wúrà. Gbogbo wọn mú ọrẹ* wúrà wá fún Jèhófà.+ 23 Gbogbo àwọn tó ní fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò sì mú wọn wá, pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa, irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa àti awọ séálì. 24 Gbogbo àwọn tó ń fi fàdákà àti bàbà ṣe ọrẹ mú un wá fún Jèhófà, gbogbo àwọn tó sì ní igi bọn-ọ̀n-ní tó ṣeé lò fún èyíkéyìí nínú iṣẹ́ náà mú un wá.
25 Gbogbo àwọn obìnrin tó mọṣẹ́+ fi ọwọ́ wọn rànwú, wọ́n sì mú àwọn ohun tí wọ́n ṣe wá: fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa. 26 Gbogbo obìnrin tó mọṣẹ́, tí ọkàn wọn sún wọn sì ran irun ewúrẹ́.
27 Àwọn ìjòyè náà mú àwọn òkúta ónísì wá àti àwọn òkúta míì tí wọ́n máa tò sára éfódì àti aṣọ ìgbàyà,+ 28 pẹ̀lú òróró básámù àti òróró tí wọ́n á máa fi tan iná, òróró tí wọ́n á fi ṣe òróró àfiyanni+ àti tùràrí onílọ́fínńdà.+ 29 Gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí ọkàn wọn sún wọn mú ohun kan wá fún iṣẹ́ tí Jèhófà pa láṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọ́n ṣe; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọrẹ àtinúwá wá fún Jèhófà.+
30 Mósè wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ wò ó, Jèhófà ti yan Bẹ́sálẹ́lì ọmọ Úráì ọmọ Húrì látinú ẹ̀yà Júdà.+ 31 Ó ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún inú rẹ̀, ó fún un ní ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ ọnà, 32 kó lè ṣe iṣẹ́ ọnà ayàwòrán, kó lè fi wúrà, fàdákà àti bàbà ṣiṣẹ́, 33 kó lè gé òkúta, kó sì tò ó, kó sì lè fi igi ṣe onírúurú iṣẹ́ ọnà. 34 Ó sì ti fi sínú ọkàn rẹ̀ láti máa kọ́ni, òun àti Òhólíábù+ ọmọ Áhísámákì látinú ẹ̀yà Dánì. 35 Ó ti mú kí wọ́n ní ìmọ̀*+ láti ṣe gbogbo iṣẹ́ ọnà, láti kó iṣẹ́ sára aṣọ, láti fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa ṣe iṣẹ́ ọnà sí aṣọ, kí wọ́n sì máa hun aṣọ. Àwọn ọkùnrin yìí máa ṣe onírúurú iṣẹ́, wọ́n á sì ṣètò onírúurú iṣẹ́ ọnà.
36 “Kí Bẹ́sálẹ́lì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Òhólíábù àti gbogbo ọkùnrin tó mọṣẹ́* tí Jèhófà ti fún ní ọgbọ́n àti òye kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn mímọ́ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ.”+
2 Lẹ́yìn náà, Mósè pe Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù àti gbogbo ọkùnrin tó mọṣẹ́ tí Jèhófà fi ọgbọ́n sínú ọkàn wọn,+ gbogbo ẹni tí ọkàn rẹ̀ sún láti yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ náà.+ 3 Wọ́n wá gba gbogbo ọrẹ+ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ náà lọ́wọ́ Mósè. Síbẹ̀, wọ́n ṣì ń mú ọrẹ àtinúwá wá fún Mósè láràárọ̀.
4 Lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mímọ́ náà, gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ ń wá, ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn, 5 wọ́n sì ń sọ fún Mósè pé: “Ohun tí àwọn èèyàn ń mú wá pọ̀ gan-an ju ohun tí a nílò fún iṣẹ́ tí Jèhófà pa láṣẹ pé ká ṣe.” 6 Mósè wá pàṣẹ pé kí wọ́n kéde káàkiri àgọ́ náà pé: “Ẹ̀yin èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ẹ má ṣe mú nǹkan kan wá mọ́ láti fi ṣe ọrẹ mímọ́.” Bí wọn ò ṣe jẹ́ káwọn èèyàn náà mú ohunkóhun wá mọ́ nìyẹn. 7 Ohun tí wọ́n mú wá tó fún gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe, ó sì tún ṣẹ́ kù.
8 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́+ mú aṣọ mẹ́wàá tó jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa, tí wọ́n fi ń pa àgọ́, pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, wọ́n sì fi ṣe àgọ́ ìjọsìn;+ ó* kó iṣẹ́ sí wọn lára, iṣẹ́ náà jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù.+ 9 Gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlọ́gbọ̀n (28), fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Ìwọ̀n gbogbo aṣọ àgọ́ náà dọ́gba. 10 Ó wá so márùn-ún nínú aṣọ àgọ́ náà mọ́ra, ó sì so aṣọ àgọ́ márùn-ún yòókù pọ̀. 11 Lẹ́yìn náà, ó fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe àwọn ihò sí etí aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan níbi tó ti so mọ́ ìkejì. Ó ṣe ohun kan náà sí etí aṣọ àgọ́ tó wà ní ìkángun níbi tó yẹ kó ti so pọ̀ mọ́ ti àkọ́kọ́. 12 Ó lu àádọ́ta (50) ihò sí aṣọ àgọ́ kan, ó sì lu àádọ́ta (50) ihò sí aṣọ àgọ́ náà ní ẹ̀gbẹ́ kejì níbi tí yóò ti so pọ̀ kí àwọn ihò náà lè wà ní òdìkejì ara wọn. 13 Níkẹyìn, ó fi wúrà ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́, ó sì fi àwọn ìkọ́ náà so àwọn aṣọ àgọ́ náà pọ̀, kí àgọ́ ìjọsìn náà lè di odindi.
14 Ó wá fi irun ewúrẹ́ ṣe àwọn aṣọ àgọ́ láti fi bo àgọ́ ìjọsìn náà. Ó ṣe aṣọ àgọ́ mọkànlá (11).+ 15 Gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Ìwọn aṣọ àgọ́ mọ́kànlá (11) náà dọ́gba. 16 Ó so márùn-ún nínú àwọn aṣọ àgọ́ náà mọ́ra, ó sì so aṣọ àgọ́ mẹ́fà yòókù pọ̀ mọ́ra. 17 Lẹ́yìn náà, ó lu àádọ́ta (50) ihò sí etí aṣọ àgọ́ tó wà ní ìkángun níbi tó ti so pọ̀, ó sì lu àádọ́ta (50) ihò sí etí aṣọ àgọ́ kejì tó so pọ̀ mọ́ ọn. 18 Ó fi bàbà ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́ láti so àgọ́ náà pọ̀ kó lè di odindi.
19 Ó fi awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa ṣe ìbòrí àgọ́ náà, ó sì fi awọ séálì bo awọ àgbò náà.+
20 Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní+ ṣe àwọn férémù àgọ́ ìjọsìn náà, wọ́n sì wà ní òró.+ 21 Gígùn férémù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀. 22 Férémù kọ̀ọ̀kan ní ìtẹ̀bọ̀ méjì* lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe ṣe gbogbo férémù àgọ́ ìjọsìn náà. 23 Ó ṣe àwọn férémù sí apá gúúsù àgọ́ ìjọsìn náà, ogún (20) férémù tó dojú kọ gúúsù. 24 Ó wá fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò sábẹ́ ogún (20) férémù náà, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sábẹ́ férémù kan kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀, ó sì ṣe ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù, kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀.+ 25 Ó ṣe ogún (20) férémù sí ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà, ní apá àríwá, 26 ó sì fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò fún wọn, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò lábẹ́ férémù kan àti ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù.
27 Ó ṣe férémù mẹ́fà sí ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà lápá ìwọ̀ oòrùn.+ 28 Ó fi férémù méjì ṣe òpó sí igun méjèèjì àgọ́ ìjọsìn náà lápá ẹ̀yìn. 29 Àwọn òpó náà ní igi méjì láti ìsàlẹ̀ dé òkè, níbi òrùka àkọ́kọ́. Ohun tó ṣe sí òpó tó wà ní igun méjèèjì nìyẹn. 30 Gbogbo rẹ̀ wá jẹ́ férémù mẹ́jọ, pẹ̀lú ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn mẹ́rìndínlógún (16) tí wọ́n fi fàdákà ṣe, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sì wà lábẹ́ férémù kọ̀ọ̀kan.
31 Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá gbọọrọ, ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan àgọ́ ìjọsìn náà+ 32 àti ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà àti ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún férémù ọwọ́ ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà lápá ìwọ̀ oòrùn. 33 Ó ṣe ọ̀pá gbọọrọ sí àárín, èyí tó gba àárín àwọn férémù náà kọjá láti ìkángun kan sí èkejì. 34 Ó fi wúrà bo àwọn férémù náà, ó fi wúrà ṣe òrùka tó máa di àwọn ọ̀pá náà mú, ó sì fi wúrà bo àwọn ọ̀pá náà.+
35 Ó sì fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ṣe aṣọ ìdábùú.+ Ó kó iṣẹ́ sí i lára,+ iṣẹ́ náà jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù.+ 36 Lẹ́yìn náà, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe òpó mẹ́rin fún un, ó sì fi wúrà bò wọ́n, pẹ̀lú àwọn ìkọ́ tó fi wúrà ṣe, ó sì fi fàdákà rọ ìtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó ní ihò fún wọn. 37 Ó fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ṣe aṣọ* tí wọ́n máa ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà,+ 38 pẹ̀lú òpó rẹ̀ márùn-ún àti àwọn ìkọ́ wọn. Ó fi wúrà bo orí wọn àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀,* àmọ́ bàbà ló fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn márààrún.
37 Bẹ́sálẹ́lì+ wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe Àpótí.+ Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjì ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+ 2 Ó fi ògidì wúrà bò ó nínú àti níta, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká.+ 3 Lẹ́yìn náà, ó fi wúrà rọ òrùka mẹ́rin fún un, ó fi síbi òkè ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, òrùka méjì ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan àti òrùka méjì ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kejì. 4 Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n.+ 5 Ó ki àwọn ọ̀pá náà bọnú àwọn òrùka tó wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì Àpótí náà, láti máa fi gbé Àpótí náà.+
6 Ó fi ògidì wúrà ṣe ìbòrí.+ Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+ 7 Ó wá fi wúra ṣe kérúbù+ méjì sí ìkángun méjèèjì ìbòrí náà, ó jẹ́ iṣẹ́ ọnà tó fi òòlù ṣe.+ 8 Kérúbù kan wà ní ìkángun kan, kérúbù kejì sì wà ní ìkángun kejì. Ó ṣe àwọn kérúbù náà sí ìkángun méjèèjì ìbòrí náà. 9 Àwọn kérúbù méjèèjì na ìyẹ́ wọn sókè, ìyẹ́ wọn sì bo ìbòrí náà.+ Wọ́n dojú kọra, wọ́n sì ń wo ìbòrí náà.+
10 Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe tábìlì.+ Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+ 11 Ó fi ògidì wúrà bò ó, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká. 12 Lẹ́yìn náà, ó ṣe etí tó fẹ̀ tó ìbú ọwọ́ kan* sí i yí ká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí etí náà yí ká.* 13 Ó tún fi wúrà rọ òrùka mẹ́rin fún un, ó sì fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin níbi tí ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà. 14 Àwọn òrùka náà sún mọ́ etí náà láti máa gba àwọn ọ̀pá tí wọ́n máa fi gbé tábìlì náà dúró. 15 Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá láti máa fi gbé tábìlì náà, ó sì fi wúrà bo àwọn ọ̀pá náà. 16 Lẹ́yìn náà, ó fi ògidì wúrà ṣe àwọn ohun èlò tó wà lórí tábìlì—àwọn abọ́ ìjẹun rẹ̀, àwọn ife rẹ̀, àwọn abọ́ rẹ̀ àti àwọn ṣágo tí wọ́n á máa da ọrẹ ohun mímu látinú rẹ̀.+
17 Ó wá fi ògidì wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà.+ Iṣẹ́ ọnà tó fi òòlù ṣe ni ọ̀pá fìtílà náà. Ìsàlẹ̀ rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ̀, àwọn kókó rubutu rẹ̀ àti àwọn ìtànná rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo.+ 18 Ẹ̀ka mẹ́fà yọ jáde lára ọ̀pá rẹ̀, ẹ̀ka mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kan àti ẹ̀ka mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kejì. 19 Iṣẹ́ ọnà mẹ́ta tó rí bí òdòdó álímọ́ńdì wà lára àwọn ẹ̀ka tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, kókó rubutu àti ìtànná sì tẹ̀ léra, iṣẹ́ ọnà mẹ́ta tó rí bí òdòdó álímọ́ńdì wà lára àwọn ẹ̀ka tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì, kókó rubutu àti ìtànná sì tẹ̀ léra. Bó ṣe ṣe ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó yọ jáde lára ọ̀pá fìtílà náà nìyí. 20 Iṣẹ́ ọnà mẹ́rin tó rí bí òdòdó álímọ́ńdì wà lára ọ̀pá náà, kókó rubutu àti ìtànná sì tẹ̀ léra. 21 Kókó rubutu kan wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì àkọ́kọ́ tó yọ jáde lára ọ̀pá náà, kókó rubutu kan tún wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì tó tẹ̀ lé e, kókó rubutu míì sì wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì tó tẹ̀ lé ìyẹn, bó ṣe wà lábẹ́ ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó yọ jáde lára ọ̀pá fìtílà náà nìyẹn. 22 Ó ṣe àwọn kókó rubutu, àwọn ẹ̀ka àti ọ̀pá fìtílà náà lódindi, ó jẹ́ iṣẹ́ ọnà tó fi òòlù ṣe, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan, ó sì jẹ́ ògidì wúrà. 23 Lẹ́yìn náà, ó fi ògidì wúrà ṣe fìtílà rẹ̀ méje+ àti àwọn ìpaná* rẹ̀ àti àwọn ìkóná rẹ̀. 24 Ògidì wúrà tálẹ́ńtì* kan ló fi ṣe é pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀.
25 Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe pẹpẹ tùràrí.+ Ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Pẹpẹ náà àti àwọn ìwo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan.+ 26 Ó fi ògidì wúrà bò ó lókè pẹ̀lú ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yí ká àti àwọn ìwo rẹ̀, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká. 27 Ó fi wúrà ṣe òrùka méjì sí ìsàlẹ̀ ìgbátí rẹ̀,* ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì tó wà lódìkejì ara wọn láti gba àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi máa gbé e dúró. 28 Lẹ́yìn náà, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n. 29 Ó tún ṣe òróró àfiyanni mímọ́+ àti ògidì tùràrí onílọ́fínńdà,+ ó ro àwọn èròjà rẹ̀ pọ̀ dáadáa.*
38 Ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe pẹpẹ ẹbọ sísun. Ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* márùn-ún, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta.+ 2 Ó wá ṣe àwọn ìwo sí igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Pẹpẹ náà àti àwọn ìwo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, ó fi bàbà bò ó.+ 3 Lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ náà, àwọn korobá, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn abọ́, àwọn àmúga àti àwọn ìkóná. Bàbà ló fi ṣe gbogbo ohun èlò rẹ̀. 4 Ó tún fi bàbà ṣe àgbàyan* tó rí bí àwọ̀n fún pẹpẹ náà, sí ọwọ́ ìsàlẹ̀ etí rẹ̀, ó wọnú pẹpẹ náà níbi àárín. 5 Ó rọ òrùka mẹ́rin sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nítòsí àgbàyan bàbà náà, kí wọ́n lè gba àwọn ọ̀pá dúró. 6 Lẹ́yìn náà, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi bàbà bò wọ́n. 7 Ó ki àwọn ọ̀pá náà bọnú àwọn òrùka tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ náà láti máa fi gbé e. Ó ṣe pẹpẹ náà bí àpótí onípákó tí inú rẹ̀ jìn.
8 Lẹ́yìn náà, ó fi bàbà ṣe bàsíà+ àti ẹsẹ̀ bàsíà náà; ó lo dígí* àwọn obìnrin tí wọ́n ṣètò pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ ìsìn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
9 Ó wá ṣe àgbàlá.+ Ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa ṣe àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ tó máa wà ní apá gúúsù àgbàlá náà, níbi tó dojú kọ gúúsù.+ 10 Ó ní ogún (20) òpó àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe, fàdákà ni wọ́n sì fi ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 11 Bákan náà, ó ṣe àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ tí wọ́n máa ta sí apá àríwá. Bàbà ni wọ́n fi ṣe ogún (20) òpó wọn àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn. Fàdákà ni wọ́n fi ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 12 Àmọ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́ ni àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí apá ìwọ̀ oòrùn. Òpó mẹ́wàá àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wàá tó ní ihò wà níbẹ̀, fàdákà ni wọ́n sì fi ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 13 Fífẹ̀ apá ìlà oòrùn tí oòrùn ti ń yọ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́. 14 Àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) wà ní ẹ̀gbẹ́ kan, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò. 15 Àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì, lápá kejì ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò. 16 Aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ni wọ́n fi ṣe gbogbo aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta yí àgbàlá náà ká. 17 Bàbà ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ oníhò àwọn òpó náà, fàdákà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀,* wọ́n fi fàdákà bo orí àwọn òpó náà, fàdákà sì ni wọ́n fi ṣe àwọn ohun tí wọ́n fi ń de nǹkan pọ̀ mọ́ gbogbo òpó inú àgbàlá náà.+
18 Fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ni wọ́n fi ṣe aṣọ* tí wọ́n máa ta sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí àgbàlá náà.+ 19 Bàbà ni wọ́n fi ṣe òpó wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Fàdákà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀,* wọ́n sì fi fàdákà bo orí àwọn òpó náà. 20 Bàbà ni wọ́n fi ṣe gbogbo èèkàn àgọ́ ìjọsìn náà àti àwọn tó wà yí ká àgbàlá náà.+
21 Àwọn nǹkan yìí ni wọ́n kà pé ó wà nínú àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ Ẹ̀rí.+ Mósè ló pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Léfì+ kà á, kí Ítámárì ọmọ àlùfáà Áárónì sì darí wọn.+ 22 Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì látinú ẹ̀yà Júdà ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè. 23 Òhólíábù+ ọmọ Áhísámákì látinú ẹ̀yà Dánì sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó jẹ́ oníṣẹ́ ọnà, ó máa ń kóṣẹ́ sí aṣọ, ó sì máa ń hun aṣọ pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa.
24 Gbogbo wúrà tí wọ́n lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà dọ́gba pẹ̀lú iye wúrà ọrẹ fífì,+ ó jẹ́ tálẹ́ńtì* mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) àti ọgọ́rùn-ún méje ó lé ọgbọ̀n (730) ṣékélì,* ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.* 25 Fàdákà àwọn tó forúkọ sílẹ̀ lára àpéjọ náà sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì àti ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti márùndínlọ́gọ́rin (1,775) ṣékélì, ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.* 26 Ìlàjì ṣékélì tó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́* ni ìlàjì ṣékélì ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìyẹn gbogbo ẹni tó wà lára àwọn tó forúkọ sílẹ̀ láti ẹni ogún (20) ọdún sókè,+ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550).+
27 Ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì ni wọ́n fi rọ àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ibi mímọ́ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ti aṣọ ìdábùú; ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì ni wọ́n fi ṣe ọgọ́rùn-ún (100) ìtẹ́lẹ̀ oníhò, tálẹ́ńtì kan fún ìtẹ́lẹ̀ oníhò kọ̀ọ̀kan.+ 28 Nínú ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti márùndínlọ́gọ́rin (1,775) ṣékélì ló ti ṣe ìkọ́ àwọn òpó, tó bo orí wọn, tó sì so wọ́n pọ̀.
29 Bàbà tí wọ́n fi ṣe ọrẹ* jẹ́ àádọ́rin (70) tálẹ́ńtì àti ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (2,400) ṣékélì. 30 Èyí ló fi ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, pẹpẹ bàbà àti àgbàyan rẹ̀ tó fi bàbà ṣe, gbogbo ohun èlò pẹpẹ, 31 àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò tó wà yí ká àgbàlá náà, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ẹnu ọ̀nà àgbàlá àti gbogbo èèkàn àgọ́ ìjọsìn náà àti gbogbo èèkàn+ tó wà yí ká àgbàlá náà.
39 Wọ́n fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò+ hun àwọn aṣọ lọ́nà tó dáa láti máa fi ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́. Wọ́n ṣe àwọn aṣọ mímọ́ ti Áárónì,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
2 Ó fi wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa ṣe éfódì.+ 3 Wọ́n fi òòlù lu àwọn wúrà pẹlẹbẹ títí tó fi fẹ́lẹ́, ó wá gé e tẹ́ẹ́rẹ́-tẹ́ẹ́rẹ́ kó lè lò ó pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa, ó sì kóṣẹ́ sí i. 4 Wọ́n ṣe apá méjì tí wọ́n rán pa pọ̀ ní èjìká aṣọ náà. 5 Àwọn ohun kan náà ni wọ́n fi ṣe àmùrè tí wọ́n hun,* èyí tó wà lára éfódì náà láti dì í mú kó lè dúró dáadáa,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè, wọ́n lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa.
6 Lẹ́yìn náà, wọ́n lẹ òkúta ónísì mọ́ orí ìtẹ́lẹ̀ wúrà, wọ́n sì fín orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sára rẹ̀, bí ìgbà tí wọ́n fín nǹkan sára èdìdì.+ 7 Ó fi wọ́n sórí àwọn aṣọ èjìká éfódì náà kó lè jẹ́ òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè. 8 Ó wá mú kí ẹni tó ń kó iṣẹ́ sí aṣọ ṣe aṣọ ìgbàyà,+ bí wọ́n ṣe ṣe éfódì, ó lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa.+ 9 Tí wọ́n bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba. Wọ́n ṣe aṣọ ìgbàyà náà, tó jẹ́ pé tí wọ́n bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, gígùn rẹ̀ àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.* 10 Wọ́n to òkúta sára rẹ̀ ní ìpele mẹ́rin. Ìpele àkọ́kọ́ jẹ́ rúbì, tópásì àti émírádì. 11 Ìpele kejì jẹ́ tọ́kọ́wásì, sàfáyà àti jásípérì. 12 Ìpele kẹta jẹ́ òkúta léṣémù,* ágétì àti ámétísì. 13 Ìpele kẹrin jẹ́ kírísóláítì, ónísì àti jéèdì. Wọ́n lẹ̀ wọ́n mọ́ ìtẹ́lẹ̀ tí wọ́n fi wúrà ṣe. 14 Àwọn òkúta náà dúró fún orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì méjìlá (12), wọ́n sì fín àwọn orúkọ náà sára òkúta bí èdìdì, orúkọ kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjìlá (12) náà.
15 Wọ́n wá ṣe ẹ̀wọ̀n tó lọ́ pọ̀ sára aṣọ ìgbàyà náà, bí okùn tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe.+ 16 Wọ́n fi wúrà ṣe ìtẹ́lẹ̀ méjì àti òrùka méjì, wọ́n sì fi òrùka méjèèjì sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà. 17 Lẹ́yìn náà, wọ́n ki okùn oníwúrà méjèèjì bọnú àwọn òrùka méjì tó wà ní igun aṣọ ìgbàyà náà. 18 Wọ́n wá ki etí okùn méjèèjì bọnú ìtẹ́lẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ àwọn aṣọ èjìká éfódì náà níwájú. 19 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì fi wọ́n sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà ní inú, ó dojú kọ éfódì náà.+ 20 Wọ́n tún ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì fi wọ́n síwájú éfódì náà, nísàlẹ̀ àwọn aṣọ èjìká méjèèjì éfódì náà, nítòsí ibi tí wọ́n ti so pọ̀, ní òkè ibi tí àmùrè* tí wọ́n hun ti so mọ́ éfódì náà. 21 Níkẹyìn, wọ́n fi okùn aláwọ̀ búlúù so àwọn òrùka aṣọ ìgbàyà náà mọ́ àwọn òrùka éfódì náà, kí aṣọ ìgbàyà náà lè dúró lórí éfódì náà, lókè àmùrè* tí wọ́n hun, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
22 Lẹ́yìn náà, ó ṣe aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá sí éfódì náà, ẹni tó ń hun aṣọ fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe é látòkè délẹ̀.+ 23 Ó yọ ọrùn sí aṣọ àwọ̀lékè náà ní àárín, bí ọrùn ẹ̀wù irin. Ó ṣe ìgbátí sí ọrùn rẹ̀ yí ká, kó má bàa ya. 24 Lẹ́yìn náà, wọ́n fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí wọ́n lọ́ pọ̀ ṣe pómégíránétì sí etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà. 25 Wọ́n fi ògidì wúrà ṣe àwọn agogo, wọ́n sì fi àwọn agogo náà sáàárín àwọn pómégíránétì yí ká etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà, láàárín àwọn pómégíránétì; 26 wọ́n to agogo kan tẹ̀ lé pómégíránétì kan, agogo kan tẹ̀ lé pómégíránétì kan yí ká etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
27 Wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa ṣe aṣọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ẹni tó ń hun aṣọ ló ṣe é,+ 28 wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa ṣe láwàní+ àti aṣọ tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ tí wọ́n máa wé sórí,+ wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ṣe àwọn ṣòkòtò péńpé,*+ 29 wọ́n tún fi aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa, pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí wọ́n hun pọ̀ ṣe ọ̀já, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
30 Níkẹyìn, wọ́n fi ògidì wúrà ṣe irin pẹlẹbẹ tó ń dán, tó jẹ́ àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́,* wọ́n sì fín ọ̀rọ̀ sára rẹ̀ bí ẹni fín èdìdì, pé: “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.”+ 31 Wọ́n so okùn tí wọ́n fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe mọ́ ọn, kí wọ́n lè dè é mọ́ láwàní náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
32 Wọ́n wá parí gbogbo iṣẹ́ àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè.+ Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
33 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé àgọ́ ìjọsìn+ náà wá sọ́dọ̀ Mósè, àgọ́ náà+ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀: àwọn ìkọ́ rẹ̀,+ àwọn férémù rẹ̀,+ àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀+ àti àwọn òpó rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀;+ 34 ìbòrí rẹ̀ tí wọ́n fi awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa ṣe,+ ìbòrí rẹ̀ tí wọ́n fi awọ séálì ṣe, aṣọ tí wọ́n máa ta sí ẹnu ọ̀nà;+ 35 àpótí Ẹ̀rí àti àwọn ọ̀pá rẹ̀+ àti ìbòrí náà;+ 36 tábìlì, gbogbo ohun èlò rẹ̀+ àti búrẹ́dì àfihàn; 37 ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe, àwọn fìtílà rẹ̀,+ ọ̀wọ́ àwọn fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀+ àti òróró tí wọ́n á máa fi tan iná;+ 38 pẹpẹ+ wúrà, òróró àfiyanni,+ tùràrí onílọ́fínńdà,+ aṣọ* tí wọ́n máa ta+ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́; 39 pẹpẹ bàbà+ àti àgbàyan* rẹ̀ tí wọ́n fi bàbà ṣe, àwọn ọ̀pá rẹ̀,+ gbogbo ohun èlò rẹ̀,+ bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀;+ 40 àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta sí àgbàlá náà, àwọn òpó rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀,+ aṣọ* tí wọ́n máa ta+ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá, àwọn okùn àgọ́ rẹ̀ àti àwọn èèkàn àgọ́ rẹ̀+ àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n máa fi ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn náà, ní àgọ́ ìpàdé; 41 àwọn aṣọ tí wọ́n hun dáadáa láti máa fi ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ ti àlùfáà Áárónì+ àti àwọn aṣọ tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa fi ṣiṣẹ́ àlùfáà.
42 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo iṣẹ́ náà bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.+ 43 Nígbà tí Mósè yẹ gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ṣe wò, ó rí i pé wọ́n ṣe é gẹ́lẹ́ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ; Mósè sì súre fún wọn.
40 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní, kí o to àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé náà.+ 3 Gbé àpótí Ẹ̀rí sínú rẹ̀,+ kí o sì ta aṣọ ìdábùú bo ibi tí Àpótí náà wà.+ 4 Kí o gbé tábìlì+ náà wọlé, kí o sì to àwọn nǹkan tó yẹ kó wà lórí rẹ̀ síbẹ̀, kí o wá gbé ọ̀pá fìtílà+ wọlé, kí o sì tan àwọn fìtílà rẹ̀.+ 5 Kí o gbé pẹpẹ tùràrí+ tí wọ́n fi wúrà ṣe síwájú àpótí Ẹ̀rí, kí o sì ta aṣọ* sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn.+
6 “Kí o gbé pẹpẹ ẹbọ sísun+ síwájú ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé náà, 7 kí o gbé bàsíà sáàárín àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ, kí o sì bu omi sínú rẹ̀.+ 8 Kí o wá ṣe àgbàlá+ yí i ká, kí o sì ta aṣọ*+ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. 9 Lẹ́yìn náà, kí o gbé òróró àfiyanni,+ kí o fòróró yan àgọ́ ìjọsìn náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀,+ kí o sì ya àgọ́ náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ sí mímọ́, kó lè di ohun mímọ́. 10 Kí o fòróró yan pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, kí o sì ya pẹpẹ náà sí mímọ́, kó lè di pẹpẹ mímọ́ jù lọ.+ 11 Kí o fòróró yan bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì yà á sí mímọ́.
12 “Lẹ́yìn náà, kí o mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sún mọ́ ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.+ 13 Kí o wọ àwọn aṣọ mímọ́ náà fún Áárónì,+ kí o fòróró yàn án,+ kí o sì sọ ọ́ di mímọ́, yóò sì di àlùfáà mi. 14 Kí o wá mú àwọn ọmọ rẹ̀ sún mọ́ tòsí, kí o sì wọ aṣọ fún wọn.+ 15 Kí o fòróró yàn wọ́n bí o ṣe fòróró yan bàbá wọn,+ kí wọ́n lè di àlùfáà mi, ìran wọn á sì máa ṣiṣẹ́ àlùfáà títí lọ torí o ti fòróró yàn wọ́n.”+
16 Mósè ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un.+ Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
17 Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní, ọdún kejì, wọ́n to àgọ́ ìjọsìn náà.+ 18 Nígbà tí Mósè to àgọ́ ìjọsìn náà, ó fi àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀+ sísàlẹ̀, ó to àwọn férémù,+ ó fi àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀+ sí i, ó sì to àwọn òpó rẹ̀. 19 Ó fi aṣọ àgọ́+ bo àgọ́ ìjọsìn náà, ó sì fi ìbòrí+ àgọ́ náà bò ó, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
20 Lẹ́yìn náà, ó mú Ẹ̀rí,+ ó sì fi sínú Àpótí náà.+ Ó ki àwọn ọ̀pá+ sí ẹ̀gbẹ́ Àpótí náà, ó sì fi ìbòrí+ bo Àpótí náà.+ 21 Ó gbé Àpótí náà wá sínú àgọ́ ìjọsìn, ó sì ta aṣọ ìdábùú+ bo ibẹ̀. Ó fi bo ibi tí àpótí Ẹ̀rí náà+ wà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
22 Lẹ́yìn náà, ó gbé tábìlì+ sínú àgọ́ ìpàdé ní apá àríwá àgọ́ ìjọsìn náà ní ìta aṣọ ìdábùú, 23 ó sì to búrẹ́dì+ náà sórí ara wọn lórí rẹ̀ níwájú Jèhófà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
24 Ó gbé ọ̀pá fìtílà+ sínú àgọ́ ìpàdé níwájú tábìlì náà, ní apá gúúsù àgọ́ ìjọsìn náà. 25 Ó tan àwọn fìtílà+ náà níwájú Jèhófà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
26 Lẹ́yìn náà, ó gbé pẹpẹ wúrà+ sínú àgọ́ ìpàdé níwájú aṣọ ìdábùú, 27 kó lè mú kí tùràrí onílọ́fínńdà+ rú èéfín lórí rẹ̀,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
28 Ó wá ta aṣọ*+ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn náà.
29 Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun+ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé náà, kó lè fi ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ọkà rúbọ lórí rẹ̀, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
30 Lẹ́yìn náà, ó gbé bàsíà sí àárín àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ, ó sì bu omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀.+ 31 Mósè àti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn níbẹ̀. 32 Nígbàkigbà tí wọ́n bá wọnú àgọ́ ìpàdé tàbí tí wọ́n bá sún mọ́ pẹpẹ, wọ́n á wẹ̀,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
33 Níkẹyìn, ó ṣe àgbàlá+ yí àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ náà ká, ó sì ta aṣọ* sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà.+
Bí Mósè ṣe parí iṣẹ́ náà nìyẹn. 34 Ìkùukùu* sì bẹ̀rẹ̀ sí í bo àgọ́ ìpàdé, ògo Jèhófà sì kún inú àgọ́ ìjọsìn náà.+ 35 Mósè ò lè wọnú àgọ́ ìpàdé torí pé ìkùukùu ò kúrò lórí àgọ́ náà, ògo Jèhófà sì kún inú àgọ́ ìjọsìn náà.+
36 Tí ìkùukùu bá ti kúrò lórí àgọ́ ìjọsìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tú àgọ́ wọn ká bí wọ́n ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibòmíì lẹ́nu gbogbo ìrìn àjò wọn.+ 37 Àmọ́, tí ìkùukùu náà ò bá kúrò, wọn ò ní tú àgọ́ wọn ká títí di ọjọ́ tí ìkùukùu náà bá kúrò.+ 38 Torí ìkùukùu Jèhófà máa ń wà lórí àgọ́ ìjọsìn náà ní ọ̀sán, iná sì máa ń wà lórí rẹ̀ ní òru, gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì máa ń rí i, bí wọ́n ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibòmíì lẹ́nu gbogbo ìrìn àjò wọn.+
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “tó ti itan Jékọ́bù jáde.”
Tàbí “àádọ́rin ọkàn.”
Ní Héb., “Àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Tàbí “akóniṣiṣẹ́.”
Tàbí “áàkì; àpótí.”
Ìyẹn, koríko etí omi.
Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí Wọ́n Gbé Jáde,” ìyẹn, ẹní tí wọ́n gba ẹ̀mí rẹ̀ là látinú omi.
Tàbí “bí Mósè ṣe ń lágbára.”
Tàbí “ó gbèjà àwọn obìnrin náà.”
Ìyẹn, Jẹ́tírò.
Ó túmọ̀ sí “Ó Di Àjèjì Níbẹ̀.”
Ní Héb., “ọjọ́.”
Tàbí “sin.”
Tàbí “Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Yàn; Èmi Yóò Jẹ́ Ohun Tí Èmi Yóò Jẹ́.” Wo Àfikún A4.
Ní Héb., “ẹnu mi wúwo.”
Ní Héb., “màá wà pẹ̀lú ẹnu rẹ.”
Tàbí “ìwọ yóò jẹ́ àṣojú Ọlọ́run fún un.”
Tàbí “àwọn tó ń wá ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọ̀bẹ tí wọ́n fi òkúta ṣe.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “sábẹ́ àjàgà.”
Tàbí “ṣọ̀lẹ.”
Tàbí “ṣọ̀lẹ.”
Tàbí “ẹ ti ń ṣọ̀lẹ.”
Tàbí “mú kí á dà bí òórùn burúkú sí Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”
Tàbí “ọwọ́ agbára mi.”
Ní Héb., “mo gbé ọwọ́ mi sókè nípa rẹ̀.”
Ní Héb., “mi ò dá ètè mi bí ẹni dá adọ̀dọ́.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “Mi ò dá ètè mi bí ẹni dá adọ̀dọ́.”
Ní Héb., “fi ọ́ ṣe Ọlọ́run.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun mi.”
Tàbí “agbára idán.”
Ìyẹn, omi tó ń ṣàn láti odò Náílì.
Tàbí “abọ́.”
Ìyẹn, àwọn ará Íjíbítì.
Tàbí “mú wa ṣeré.”
Tàbí “màjàlà.”
Tàbí “run.”
Ó lè jẹ́ mànàmáná tó ń bù yẹ̀rì sórí ayé.
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “wọn ò tètè gbìn wọ́n.”
Ní Héb., “tí yóò máa jẹ́ ìdẹkùn fún wa?”
Ó jọ pé Mósè ni.
Tàbí “jẹ́ ká ní.”
Ní Héb., “pátákò.”
Ní Héb., “yọ ahọ́n sí.”
Ní Héb., “òun àti aládùúgbò rẹ̀.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “gbogbo ìjọ àpéjọ.”
Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Ní Héb., “ẹ di ìbàdí yín lámùrè.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “kí ẹ ké ẹni tó bá jẹ ohun tó ní ìwúkàrà kúrò.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun.”
Tàbí “kí ẹ ké.”
Tàbí “ọkàn.”
Ìyẹn, ọmọ àgùntàn tàbí ewúrẹ́.
Ní Héb., “ìparun.”
Ní Héb., “ní ilé kòtò omi.”
Tàbí “abọ́.”
Ìyẹn, oríṣiríṣi èèyàn tí wọn kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, títí kan àwọn ará Íjíbítì.
Ní Héb., “gbogbo ọmọ ogun Jèhófà.”
Tàbí “kọ ọ́ nílà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun.”
Ní Héb., “gbogbo àkọ́bí tó ṣí ilé ọmọ kọ̀ọ̀kan.”
Tàbí “sọ́tọ̀.”
Wo Àfikún B15.
Ní Héb., “ààlà.”
Ní Héb., “ní àárín ojú.”
Ní Héb., “gbogbo àkọ́bí tó ṣí ilé ọmọ kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “gbogbo àkọ́bí tó ṣí ilé ọmọ kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ní àárín ojú.”
Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
Tàbí “iná tó rí bí òpó.”
Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
Ní Héb., “ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lókè.”
Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
Ìyẹn, nǹkan bí aago méjì òru sí aago mẹ́fà ìdájí.
Tàbí “iná tó rí bí òpó.”
Ní Héb., “ọwọ́.”
“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “ọkàn mi.”
Ní Héb., “jẹ̀rora ìbímọ.”
Séríkí jẹ́ olóyè láàárín ẹ̀yà kan.
Tàbí “Àwọn olórí tó ń ṣi agbára lò ní Móábù.”
Ó túmọ̀ sí “Ìkorò.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “Láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Nǹkan bí òṣùwọ̀n tó jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Gbogbo ọ̀la lẹ máa fi pa sábáàtì mọ́.”
Tàbí “sinmi.”
Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Kí nìyí?”
Òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 22. Wo Àfikún B14.
Ó túmọ̀ sí “Àdánwò.”
Ó túmọ̀ sí “Ìjà.”
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Òpó Àmì Mi.”
Ó túmọ̀ sí “Ó Di Àjèjì Níbẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí “Olùrànlọ́wọ́ Ni Ọlọ́run Mi.”
Ní Héb., “lọ́wọ́.”
Ní Héb., “dá ẹjọ́ àwọn èèyàn náà ní gbogbo ìgbà.”
Tàbí “tó ṣeyebíye.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pẹ̀lú ọfà.
Ní Héb., “Ẹ má ṣe sún mọ́ obìnrin.”
Ní Héb., “ohùn Ọlọ́run tòótọ́ sì dá a lóhùn.”
Ní Héb., “kọ lù.”
Tàbí “láti fojú di mí.” Ní Héb., “níṣojú mi.”
Tàbí “àwòrán.”
Ní Héb., “tó wà ní ẹnubodè rẹ.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “ẹbọ àlàáfíà.”
Tàbí “òkúta gbígbẹ́.”
Tàbí “ohun èlò tí a fi ń gbẹ́ igi tàbí òkúta.”
Ní Héb., “ìhòòhò.”
Ìyẹn, ohun tí wọ́n fi ń dá nǹkan lu.
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “tún un rà.”
Tàbí “pe ibi wá sórí.”
Tàbí kó jẹ́, “fi ohun kan lù ú.”
Ní Héb., “tí àwọn ọmọ rẹ̀ sì jáde.”
Tàbí “tí jàǹbá tó burú jáì kò ṣẹlẹ̀.”
Tàbí “ọkàn fún ọkàn.”
Tàbí “owó ìtanràn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “aláìlóbìí.”
Tàbí “tí ìyà ń jẹ.”
Tàbí “ayánilówó èlé gọbọi.”
Tàbí “ìdógò.”
Ní Héb., “awọ ara.”
Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
Tàbí “kẹ́gàn.”
Tàbí “olórí.”
Ìyẹn, àwọn ibi tí wọ́n ti ń fún òróró àti wáìnì.
Ní Héb., “gbé ìròyìn èké kiri.”
Tàbí “bá wọn jẹ́rìí èké tí ọ̀pọ̀ èèyàn fara mọ́.”
Ní Héb., “ọ̀rọ̀ èké.”
Tàbí “dá ẹni burúkú láre.”
àbí “Ẹ mọ bí ẹ̀mí (ọkàn) àjèjì ṣe máa ń rí.”
Tàbí “ètè.”
Wo Àfikún B15.
Wọ́n tún máa ń pè é ní Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ tàbí Pẹ́ńtíkọ́sì.
Wọ́n tún máa ń pè é ní Àjọyọ̀ Àtíbàbà (Àgọ́ Ìjọsìn).
Tàbí “akọ.”
Tàbí “Màá mú kí ọjọ́ ayé yín kún.”
Tàbí “Màá mú kí gbogbo ọ̀tá yín yísẹ̀ pa dà lọ́dọ̀ yín.”
Tàbí kó jẹ́, “bẹ̀rù; wárìrì.”
Ìyẹn, odò Yúfírétì.
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “òwú tí wọ́n fi àwọ̀ pọ́pù tó dà pọ̀ mọ́ pupa pa láró.”
Tàbí “òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “pàgọ́ sáàárín.”
Tàbí “àwòrán.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “mọ wúrà sí etí rẹ̀.”
Tàbí “mọ wúrà sí etí rẹ̀.”
Nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 7.4 (ínǹṣì 2.9). Wo Àfikún B14.
Tàbí “mọ wúrà sí etí rẹ̀ yí ká.”
Tàbí “ẹ̀mú.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “àwòrán.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “òpó méjì tó wà ní òró.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.
Tàbí “ayanran.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Ní Héb., “jẹ́ ọlọgbọ́n ní ọkàn.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 22.2 (ínǹṣì 8.75). Wo Àfikún B14.
Òkúta iyebíye kan tí a ò mọ bó ṣe rí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òkúta áńbérì, háyásíǹtì, ópálì tàbí tọ́málínì.
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ibi tó máa ki orí sí.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ wọn.”
Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Tàbí “adé mímọ́.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ Áárónì àti ọwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ wọn.”
Ní Héb., “àjèjì,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ara ìdílé Áárónì.
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ wọn.”
Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 22. Wo Àfikún B14.
Òṣùwọ̀n hínì kan jẹ́ Lítà 3.67. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “pàgọ́ sí àárín.”
Nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “mọ wúrà sí etí rẹ̀.”
Tàbí “wúrà tí o mọ sí etí rẹ̀.”
Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Tàbí “ọkàn.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Gérà kan jẹ́ gíráàmù 0.57. Wo Àfikún B14.
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Òṣùwọ̀n hínì kan jẹ́ Lítà 3.67. Wo Àfikún B14.
Tàbí “bíi ti ẹni tó máa ń ṣe òróró ìpara.”
Ní Héb., “àjèjì,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ara ìdílé Áárónì.
Tàbí “bíi ti ẹni tó máa ń ṣe òróró ìpara.”
Ní Héb., “fi orúkọ pe.”
Ní Héb., “jẹ́ ọlọgbọ́n ní ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “ère dídà.”
Ní Héb., “ọlọ́rùn líle.”
Tàbí “tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú.”
Tàbí “yí ìpinnu rẹ pa dà.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”
Tàbí “iṣẹ́ àgbàyanu.”
Ní Héb., “Ẹ fi kún ọwọ́ yín.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “ọlọ́rùn líle.”
Ní Héb., “Ọlọ́rùn líle.”
Ní Héb., “ti wá bọ́.”
Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
Ní Héb., “Mo mọ̀ ọ́ lójúkojú.”
Ní Héb., “Ojú mi.”
Ní Héb., “Tí ojú rẹ.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
Tàbí “inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”
Tàbí “ìṣòtítọ́.”
Ní Héb., “ọlọ́rùn líle.”
Tàbí “dá.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “torí orúkọ Jèhófà ní nínú.”
Tàbí “kò fẹ́ kí o ní ọlọ́run míì.”
Wo Àfikún B15.
Ní Héb., “gbogbo àkọ́bí tó ṣí ilé ọmọ kọ̀ọ̀kan.”
Tàbí “kí ẹ pa sábáàtì mọ́.”
Tàbí “wíìtì.”
Wọ́n tún máa ń pè é ní Àjọyọ̀ Àtíbàbà (Àgọ́ Ìjọsìn).
Tàbí “akọ.”
Ní Héb., “Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá.”
Ní Héb., “bá a.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Ní Héb., “jẹ́ ọlọgbọ́n ní ọkàn.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “ayanran.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “ọrẹ fífì.”
Ní Héb., “gbọ́n ní ọkàn.”
Ní Héb., “jẹ́ ọlọgbọ́n ní ọkàn.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Ó ṣe kedere pé Bẹ́sálẹ́lì ló ń tọ́ka sí.
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “òpó méjì tó wà ní òró.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “mọ wúrà sí etí rẹ̀.”
Tàbí “mọ wúrà sí etí rẹ̀.”
Nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 7.4 (ínǹṣì 2.9). Wo Àfikún B14.
Tàbí “mọ wúrà sí etí rẹ̀ yí ká.”
Tàbí “ẹ̀mú.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “mọ wúrà sí etí rẹ̀.”
Tàbí “wúrà tó mọ sí etí rẹ̀.”
Tàbí “bíi ti ẹni tó máa ń ṣe òróró ìpara.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “ayanran.”
Ìyẹn, àwọn dígí tí wọ́n fi irin tó ń dán gbinrin ṣe.
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Tàbí “ọrẹ fífì.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 22.2 (ínǹṣì 8.75). Wo Àfikún B14.
Òkúta iyebíye kan tí a ò mọ bó ṣe rí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òkúta áńbérì, háyásíǹtì, ópálì tàbí tọ́málínì.
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “adé mímọ́.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “ayanran.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “àwọsánmà.”