-
Léfítíkù 18:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe nílẹ̀ Íjíbítì tí ẹ gbé rí, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe nílẹ̀ Kénáánì tí mò ń mú yín lọ.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àṣẹ wọn.
-
-
Diutarónómì 12:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 rí i pé o ò kó sí ìdẹkùn lẹ́yìn tí wọ́n bá pa run kúrò níwájú rẹ. Má ṣe béèrè nípa àwọn ọlọ́run wọn pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe máa ń sin àwọn ọlọ́run wọn? Ohun tí wọ́n ṣe lèmi náà máa ṣe.’+
-
-
2 Kíróníkà 33:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ó ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, torí pé ó ń ṣe àwọn ohun ìríra bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
-