-
Ẹ́kísódù 31:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ pa àwọn sábáàtì mi mọ́,+ torí ó jẹ́ àmì láàárín èmi àti ẹ̀yin ní ìrandíran yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń sọ yín di mímọ́. 14 Kí ẹ pa Sábáàtì mọ́, torí ohun mímọ́ ló jẹ́ fún yín.+ Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá sọ ọ́ di aláìmọ́. Tí ẹnikẹ́ni bá ṣiṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà, kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò nínú àwọn èèyàn rẹ̀.+
-
-
Diutarónómì 5:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “‘Máa pa ọjọ́ Sábáàtì mọ́, kí o lè yà á sí mímọ́, bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́.+ 13 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi ṣiṣẹ́, kí o sì fi ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,+ 14 àmọ́ ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti akọ màlúù rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ àti èyíkéyìí nínú ẹran ọ̀sìn rẹ àti àjèjì tó ń gbé nínú àwọn ìlú* rẹ,+ kí ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ lè sinmi bíi tìẹ.+
-