-
Ẹ́kísódù 20:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Máa rántí ọjọ́ Sábáàtì, kí o lè yà á sí mímọ́.+ 9 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi ṣiṣẹ́, kí o sì fi ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,+ 10 àmọ́ ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti ẹran ọ̀sìn rẹ àti àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.*+
-
-
Ẹ́kísódù 31:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ pa àwọn sábáàtì mi mọ́,+ torí ó jẹ́ àmì láàárín èmi àti ẹ̀yin ní ìrandíran yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń sọ yín di mímọ́.
-