ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 32:35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  35 Tèmi ni ẹ̀san àti ìyà ẹ̀ṣẹ̀,+

      Ní àkókò náà tí ẹsẹ̀ wọn máa yọ̀ tẹ̀rẹ́,+

      Torí ọjọ́ àjálù wọn sún mọ́lé,

      Ohun tó sì ń dúró dè wọ́n máa tètè dé.’

  • Jóṣúà 24:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Jóṣúà wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ ò lè sin Jèhófà, torí pé Ọlọ́run mímọ́ ni;+ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo ni.+ Kò ní dárí àwọn ìṣìnà* àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.+

  • Róòmù 2:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Àmọ́ nítorí agídí rẹ àti ọkàn rẹ tí kò ronú pìwà dà, ò ń kó ìrunú jọ sórí ara rẹ, ìrunú yìí máa hàn ní ọjọ́ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run.+

  • 2 Pétérù 2:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ó dájú pé Ọlọ́run kò fawọ́ sẹ́yìn láti fìyà jẹ àwọn áńgẹ́lì tó ṣẹ̀,+ àmọ́ ó jù wọ́n sínú Tátárọ́sì,*+ ó fi wọ́n sí ìdè* òkùnkùn biribiri de ìdájọ́.+

  • Júùdù 14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Kódà, Énọ́kù+ tó jẹ́ ẹnì keje nínú ìran Ádámù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn pé: “Wò ó! Jèhófà* dé pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye* àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,+ 15 láti ṣe ìdájọ́ gbogbo èèyàn+ àti láti dá gbogbo àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi torí gbogbo ìwà búburú wọn àti gbogbo ọ̀rọ̀ tó burú jáì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ti sọ sí i.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́