-
Ẹ́kísódù 35:4-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Mósè tún sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nìyí, 5 ‘Kí ẹ gba ọrẹ fún Jèhófà láàárín ara yín.+ Kí gbogbo ẹni tó bá wù látọkàn wá+ mú ọrẹ wá fún Jèhófà: wúrà, fàdákà, bàbà, 6 fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, irun ewúrẹ́,+ 7 awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa, awọ séálì, igi bọn-ọ̀n-ní, 8 òróró fìtílà, òróró básámù tí wọ́n á fi ṣe òróró àfiyanni àti tùràrí onílọ́fínńdà,+ 9 àwọn òkúta ónísì àti àwọn òkúta míì tí wọ́n máa tò sára éfódì+ àti aṣọ ìgbàyà.+
-
-
1 Kíróníkà 29:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Inú àwọn èèyàn náà dùn pé wọ́n mú ọrẹ wá tinútinú, nítorí pé gbogbo ọkàn+ ni wọ́n fi mú ọrẹ náà wá fún Jèhófà, inú Ọba Dáfídì pẹ̀lú sì dùn gan-an.
-