-
Ẹ́kísódù 25:2-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n mú ọrẹ wá fún mi. Kí ẹ gba ọrẹ fún mi lọ́wọ́ gbogbo ẹni tí ọkàn rẹ̀ bá sún láti mú un wá.+ 3 Ọrẹ tí ẹ máa gbà lọ́wọ́ wọn nìyí: wúrà,+ fàdákà,+ bàbà,+ 4 fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù,* òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò,* aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, irun ewúrẹ́, 5 awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa, awọ séálì, igi bọn-ọ̀n-ní,+ 6 òróró fìtílà,+ òróró básámù tí wọ́n á fi ṣe òróró àfiyanni+ àti tùràrí onílọ́fínńdà,+ 7 àwọn òkúta ónísì àti àwọn òkúta míì tí wọ́n máa tò sára éfódì+ àti aṣọ ìgbàyà.+
-
-
Ẹ́kísódù 35:29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí ọkàn wọn sún wọn mú ohun kan wá fún iṣẹ́ tí Jèhófà pa láṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọ́n ṣe; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọrẹ àtinúwá wá fún Jèhófà.+
-