8 Àmọ́, ó gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí orúkọ rẹ̀,+
Kí wọ́n lè mọ bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.+
9 Ó bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ;
Ó mú wọn gba ìsàlẹ̀ rẹ̀ bí ẹni gba aṣálẹ̀ kọjá;+
10 Ó gbà wọ́n lọ́wọ́ elénìní,+
Ó sì gbà wọ́n pa dà lọ́wọ́ ọ̀tá.+
11 Omi bo àwọn elénìní wọn;
Kò sí ìkankan lára wọn tó yè bọ́.+