-
Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Lẹ́yìn náà, ojú ìyàwó ọ̀gá Jósẹ́fù kò kúrò lára rẹ̀, ó sì ń sọ fún un pé: “Wá bá mi sùn.” 8 Àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà, ó sì sọ fún ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ọ̀gá mi kì í yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò nínú ilé, ó sì ti fa gbogbo ohun tó ní lé mi lọ́wọ́. 9 Kò sẹ́ni tó tóbi jù mí lọ nínú ilé yìí, kò sì fawọ́ ohunkóhun sẹ́yìn fún mi àyàfi ìwọ, torí pé ìwọ ni ìyàwó rẹ̀. Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?”+
-
-
Diutarónómì 5:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 “‘O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.+
-