18 Torí kì í ṣe ohun tó ṣeé fọwọ́ bà,+ tí a sì dáná sí,+ lẹ sún mọ́, kì í ṣe ìkùukùu tó ṣú dùdù àti òkùnkùn biribiri àti ìjì,+ 19 àti ìró kàkàkí+ àti ohùn tó ń sọ̀rọ̀,+ èyí tó jẹ́ pé nígbà tí àwọn èèyàn náà gbọ́ ọ, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé ká má ṣe bá àwọn sọ̀rọ̀ mọ́.+