9 “Kí o ka ọ̀sẹ̀ méje. Ìgbà tí o bá kọ́kọ́ ki dòjé bọ ọkà tó wà ní ìdúró ni kí o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọ̀sẹ̀ méje náà.+ 10 Kí o wá fi ọrẹ àtinúwá tí o mú wá ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o mú un wá bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ṣe bù kún ọ tó.+