-
Diutarónómì 16:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 “Kí o ka ọ̀sẹ̀ méje. Ìgbà tí o bá kọ́kọ́ ki dòjé bọ ọkà tó wà ní ìdúró ni kí o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọ̀sẹ̀ méje náà.+ 10 Kí o wá fi ọrẹ àtinúwá tí o mú wá ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o mú un wá bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ṣe bù kún ọ tó.+ 11 Kí o sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* rẹ, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó, tí wọ́n wà láàárín rẹ, ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+
-