25 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé ní Ṣítímù,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọbìnrin Móábù+ ṣe ìṣekúṣe. 2 Àwọn obìnrin náà pè wọ́n síbi àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sí àwọn ọlọ́run+ wọn, àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run+ wọn.