ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 22:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Ohun kan ṣoṣo tó bò ó lára nìyẹn, aṣọ tó fi bo ara* rẹ̀; kí wá ni kó fi bora sùn?+ Tó bá ké pè mí, ó dájú pé màá gbọ́, torí mo jẹ́ aláàánú.*+

  • 2 Kíróníkà 30:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Torí ìgbà tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà ni àwọn arákùnrin yín àti àwọn ọmọ yín máa rí àánú gbà látọ̀dọ̀ àwọn tó mú wọn lẹ́rú,+ wọ́n á sì jẹ́ kí wọ́n pa dà sí ilẹ̀ yìí,+ nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò* àti aláàánú,+ kò sì ní yí ojú rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ yín tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀.”+

  • Nehemáyà 9:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Wọn ò fetí sílẹ̀,+ wọn ò sì rántí àwọn ohun àgbàyanu tí o ṣe láàárín wọn, àmọ́ wọ́n ya alágídí,* wọ́n sì yan olórí láti kó wọn pa dà sí ipò ẹrú wọn ní Íjíbítì.+ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tó ṣe tán láti dárí jini* ni ọ́, o jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò* àti aláàánú, o kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀* sì pọ̀ gidigidi,+ o ò pa wọ́n tì.+

  • Sáàmù 86:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Àmọ́ ní tìrẹ, Jèhófà, o jẹ́ Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò,*

      Tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òdodo* rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.+

  • Jóẹ́lì 2:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ọkàn yín ni kí ẹ fà ya,+ kì í ṣe ẹ̀wù yín,+

      Kí ẹ sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín,

      Torí ó ń gba tẹni rò,* ó jẹ́ aláàánú, kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,+

      Òun yóò sì pèrò dà* nípa àjálù náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́