ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 34:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú,+ tó ń gba tẹni rò,*+ tí kì í tètè bínú,+ tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ àti òtítọ́*+ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,

  • Nọ́ńbà 14:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 ‘Jèhófà, Ọlọ́run tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ sì pọ̀ gan-an, tó ń dárí ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini, àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀, tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti dórí ìran kẹrin.’+

  • Nehemáyà 9:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Wọn ò fetí sílẹ̀,+ wọn ò sì rántí àwọn ohun àgbàyanu tí o ṣe láàárín wọn, àmọ́ wọ́n ya alágídí,* wọ́n sì yan olórí láti kó wọn pa dà sí ipò ẹrú wọn ní Íjíbítì.+ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tó ṣe tán láti dárí jini* ni ọ́, o jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò* àti aláàánú, o kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀* sì pọ̀ gidigidi,+ o ò pa wọ́n tì.+

  • Sáàmù 106:44, 45
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 44 Àmọ́ á tún rí ìdààmú tó bá wọn,+

      Á sì gbọ́ igbe ìrànlọ́wọ́ wọn.+

      45 Nítorí wọn, á rántí májẹ̀mú rẹ̀,

      Àánú á sì ṣe é* nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tó ga tí kì í sì í yẹ̀.*+

  • Míkà 7:18, 19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ta ló dà bí rẹ, Ọlọ́run,

      Tó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, tó sì ń gbójú fo ìṣìnà+ àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ogún rẹ̀?+

      Kò ní máa bínú lọ títí láé,

      Torí inú rẹ̀ máa ń dùn sí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.+

      19 Ó tún máa ṣàánú wa;+ ó sì máa pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́.*

      O máa ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sí ìsàlẹ̀ òkun.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́