ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 34:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú,+ tó ń gba tẹni rò,*+ tí kì í tètè bínú,+ tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ àti òtítọ́*+ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,

  • Diutarónómì 32:36
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  36 Torí Jèhófà máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn+ rẹ̀,

      Ó sì máa káàánú* àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀,

      Tó bá rí i pé okun wọn ti ń tán,

      Tó sì rí i pé àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ àtàwọn tó ti rẹ̀ ló ṣẹ́ kù.

  • Àìsáyà 63:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Màá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ṣe torí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,

      Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ ká yìn,

      Torí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa,+

      Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere tó ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì,

      Nínú àánú rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tó lágbára.

  • Ìdárò 3:32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Bí ó tilẹ̀ fa ẹ̀dùn ọkàn, á tún fi àánú hàn nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.+

  • Jóẹ́lì 2:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ọkàn yín ni kí ẹ fà ya,+ kì í ṣe ẹ̀wù yín,+

      Kí ẹ sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín,

      Torí ó ń gba tẹni rò,* ó jẹ́ aláàánú, kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,+

      Òun yóò sì pèrò dà* nípa àjálù náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́