-
Nọ́ńbà 11:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Jèhófà wá dá Mósè lóhùn pé: “Kó àádọ́rin (70) ọkùnrin jọ fún mi nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì, àwọn tí o mọ̀ pé wọ́n jẹ́* àgbààgbà àti olórí láàárín àwọn èèyàn náà,+ kí o mú wọn lọ sí àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ. 17 Èmi yóò sọ̀ kalẹ̀+ wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀,+ mo máa mú lára ẹ̀mí+ tó wà lára rẹ, màá sì fi sára wọn, wọ́n á sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru ẹrù àwọn èèyàn náà, kí o má bàa dá ru ẹrù náà.+
-