25 Jèhófà bá sọ̀ kalẹ̀ nínú ìkùukùu,*+ ó bá a+ sọ̀rọ̀, ó sì mú díẹ̀ lára ẹ̀mí+ tó wà lára rẹ̀, ó fi sára àwọn àádọ́rin (70) àgbààgbà náà lọ́kọ̀ọ̀kan. Gbàrà tí ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi wòlíì,*+ àmọ́ wọn ò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
8 Ojúkojú* ni mò ń bá a sọ̀rọ̀,+ láì fọ̀rọ̀ pa mọ́, kì í ṣe lówelówe; ìrísí Jèhófà ló sì ń rí. Kí wá nìdí tí ẹ̀rù ò fi bà yín láti sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Mósè ìránṣẹ́ mi?”