-
Nọ́ńbà 35:22-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ńṣe ló ṣèèṣì tì í, tí kì í ṣe pé ó kórìíra rẹ̀ tàbí tó ju nǹkan lù ú láì gbèrò ibi+ sí i,* 23 tàbí tó ṣèèṣì sọ òkúta lù ú láìmọ̀ pé ó wà níbẹ̀, tí kì í sì í ṣe pé ọ̀tá rẹ̀ ni tàbí pé ó fẹ́ ṣe é léṣe, tí ẹni náà sì kú, 24 kí àpéjọ náà tẹ̀ lé ìdájọ́+ wọ̀nyí láti dá ẹjọ́ ẹni tó pààyàn àti ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀. 25 Kí àpéjọ náà wá gba apààyàn náà sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀, kí wọ́n sì dá a pa dà sí ìlú ààbò rẹ̀ tó sá lọ, kó sì máa gbé níbẹ̀ títí ọjọ́ tí àlùfáà àgbà tí wọ́n fi òróró mímọ́+ yàn fi máa kú.
-
-
Diutarónómì 19:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Kí o pín àwọn ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ pé kó di tìrẹ sí ọ̀nà mẹ́ta, kí o sì ṣe àwọn ọ̀nà, kí ẹnikẹ́ni tó bá pààyàn lè sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà.
4 “Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí apààyàn tó bá sá lọ síbẹ̀ kó má bàa kú nìyí: Tó bá ṣèèṣì pa ẹnì kejì rẹ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀;+ 5 bóyá òun àti ẹnì kejì rẹ̀ jọ lọ ṣa igi nínú igbó, tó wá gbé àáké sókè láti gé igi, àmọ́ tí irin àáké náà fò yọ, tó ba ẹnì kejì rẹ̀, tó sì kú, kí apààyàn náà sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú yìí, kó má bàa kú.+
-
-
Jóṣúà 20:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Torí náà, wọ́n ya Kédéṣì+ ní Gálílì sọ́tọ̀* ní agbègbè olókè Náfútálì, Ṣékémù+ ní agbègbè olókè Éfúrémù àti Kiriati-ábà,+ ìyẹn Hébúrónì, ní agbègbè olókè Júdà. 8 Ní agbègbè Jọ́dánì, lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, wọ́n yan Bésérì+ ní aginjù tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú* látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Mánásè.+
9 Àwọn ìlú yìí ni wọ́n yàn fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn àjèjì tó ń gbé láàárín wọn, kí ẹnikẹ́ni tó bá ṣèèṣì pa èèyàn* lè sá lọ síbẹ̀,+ kí ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má bàa pa á kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú àpéjọ náà.+
-