ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Jẹ́nẹ́sísì 1:1-50:26
  • Jẹ́nẹ́sísì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́nẹ́sísì
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì

JẸ́NẸ́SÍSÌ

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.+

2 Nígbà yẹn, ayé wà ní bọrọgidi, ó sì ṣófo. Òkùnkùn bo ibú omi,*+ ẹ̀mí Ọlọ́run*+ sì ń lọ káàkiri lójú omi.+

3 Ọlọ́run wá sọ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ wà.” Ìmọ́lẹ̀ sì wà.+ 4 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí í pààlà sáàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn. 5 Ọlọ́run pe ìmọ́lẹ̀ ní Ọ̀sán, ó sì pe òkùnkùn ní Òru.+ Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ kìíní.

6 Ọlọ́run sì sọ pé: “Kí òfúrufú+ wà láàárín omi, kí omi sì pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.”+ 7 Ọlọ́run wá ṣe òfúrufú, ó pààlà sáàárín omi tó wà lókè òfúrufú náà àti omi tó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.+ Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 8 Ọlọ́run pe òfúrufú ní Ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ kejì.

9 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ pé: “Kí àwọn omi tó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́ jọ síbì kan, kí ilẹ̀ sì fara hàn.”+ Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 10 Ọlọ́run pe ilẹ̀ náà ní Ayé,+ àmọ́ ó pe omi tó wọ́ jọ ní Òkun.+ Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.+ 11 Ọlọ́run sì sọ pé: “Kí koríko hù ní ayé, pẹ̀lú àwọn ewéko tó ní irúgbìn àti àwọn igi eléso tó ní irúgbìn ní irú tiwọn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 12 Koríko bẹ̀rẹ̀ sí í hù ní ayé pẹ̀lú àwọn ewéko tó ní irúgbìn+ àti àwọn igi eléso tó ní irúgbìn ní irú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 13 Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ kẹta.

14 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ pé: “Kí orísun ìmọ́lẹ̀*+ wà ní ojú ọ̀run, kí ìyàtọ̀ lè wà láàárín ọ̀sán àti òru,+ wọ́n á sì jẹ́ àmì láti fi mọ àwọn àsìkò, ọjọ́ àti ọdún.+ 15 Wọ́n á jẹ́ orísun ìmọ́lẹ̀ tí á máa tàn sórí ayé láti ojú ọ̀run.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 16 Ọlọ́run ṣe orísun ìmọ́lẹ̀ ńlá méjì, èyí tó tóbi á máa yọ ní ọ̀sán,+ èyí tó kéré á sì máa yọ ní òru, ó sì dá àwọn ìràwọ̀.+ 17 Ọlọ́run wá fi wọ́n sí ojú ọ̀run kí wọ́n lè máa tàn sórí ayé, 18 kí wọ́n lè máa yọ ní ọ̀sán àti ní òru, kí wọ́n sì mú kí ìyàtọ̀ wà láàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.+ Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 19 Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ kẹrin.

20 Ọlọ́run sì sọ pé: “Kí àwọn ohun alààyè* máa gbá yìn-ìn nínú omi, kí àwọn ẹ̀dá tó ń fò sì máa fò lójú ọ̀run.”*+ 21 Ọlọ́run sì dá àwọn ẹran ńlá inú òkun àti gbogbo ohun alààyè* tó ń gbá yìn-ìn nínú omi ní irú tiwọn àti àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ní irú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 22 Torí náà, Ọlọ́run súre fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún inú omi òkun,+ kí àwọn ẹ̀dá tó ń fò sì pọ̀ ní ayé.” 23 Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ karùn-ún.

24 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run wá sọ pé: “Kí ilẹ̀ mú àwọn ohun alààyè* jáde ní irú tiwọn, àwọn ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹran tó ń rákò* àti àwọn ẹran inú igbó ní irú tiwọn.”+ Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 25 Ọlọ́run dá àwọn ẹran inú igbó ní irú tiwọn àti àwọn ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn àti àwọn ẹran tó ń rákò ní irú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.

26 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ pé: “Jẹ́ ká+ dá èèyàn ní àwòrán wa,+ kí wọ́n jọ wá,+ kí wọ́n sì máa jọba lórí àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, àwọn ẹran ọ̀sìn, lórí gbogbo ayé àti lórí gbogbo ẹran tó ń rákò tó sì ń rìn lórí ilẹ̀.”+ 27 Ọlọ́run sì dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run; akọ àti abo ló dá wọn.+ 28 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé,+ kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀,+ kí ẹ máa jọba lórí+ àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run àti lórí gbogbo ohun alààyè tó ń rìn lórí ilẹ̀.”

29 Ọlọ́run sì sọ pé: “Mo fún yín ní gbogbo ewéko ní gbogbo ayé, àwọn tó ní irúgbìn àti gbogbo igi eléso tó ní irúgbìn. Kí wọ́n jẹ́ oúnjẹ fún yín.+ 30 Mo sì fi gbogbo ewéko tútù ṣe oúnjẹ fún gbogbo ẹran inú igbó àti gbogbo ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run àti gbogbo ohun abẹ̀mí* tó ń rìn lórí ilẹ̀.”+ Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

31 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run rí gbogbo ohun tó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an.+ Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ kẹfà.

2 Bí Ọlọ́run ṣe parí dídá ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn* nìyẹn.+ 2 Nígbà tó fi máa di ọjọ́ keje, Ọlọ́run ti parí iṣẹ́ tó ti ń ṣe,* ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sinmi ní ọjọ́ keje lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ tó ti ń ṣe.*+ 3 Ọlọ́run wá bù kún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, torí ọjọ́ yẹn ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í sinmi lẹ́yìn gbogbo ohun tó ti dá, ìyẹn gbogbo ohun tó ní lọ́kàn.

4 Ìtàn ọ̀run àti ayé nìyí, ní àkókò tí Ọlọ́run dá wọn, ní ọjọ́ tí Jèhófà* Ọlọ́run dá ayé àti ọ̀run.+

5 Kò sí igbó kankan ní ayé nígbà yẹn, ewéko kankan ò sì tíì hù, torí Jèhófà Ọlọ́run ò tíì rọ òjò sórí ilẹ̀, kò sì sí ẹnì kankan tó máa ro ilẹ̀. 6 Àmọ́ omi máa ń sun látinú ilẹ̀, á sì rin gbogbo ilẹ̀.

7 Jèhófà Ọlọ́run fi erùpẹ̀+ ilẹ̀ mọ ọkùnrin, ó mí èémí ìyè+ sí ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì di alààyè.*+ 8 Jèhófà Ọlọ́run wá gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì,+ ní apá ìlà oòrùn; ó sì fi ọkùnrin tó dá+ síbẹ̀. 9 Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run mú kí gbogbo igi tó dùn-ún wò, tó sì dára fún oúnjẹ hù látinú ilẹ̀, ó sì mú kí igi ìyè+ hù ní àárín ọgbà náà pẹ̀lú igi ìmọ̀ rere àti búburú.+

10 Odò kan ń ṣàn jáde láti Édẹ́nì, tí omi rẹ̀ ń rin ọgbà náà, ó sì pín sí odò mẹ́rin* níbẹ̀. 11 Orúkọ odò àkọ́kọ́ ni Píṣónì; òun ló yí gbogbo ilẹ̀ Háfílà ká, níbi tí wúrà wà. 12 Wúrà ilẹ̀ náà dára. Gọ́ọ̀mù bídẹ́líọ́mù àti òkúta ónísì tún wà níbẹ̀. 13 Orúkọ odò kejì ni Gíhónì; òun ló yí gbogbo ilẹ̀ Kúṣì ká. 14 Orúkọ odò kẹta ni Hídẹ́kẹ́lì;*+ òun ló ṣàn lọ sí ìlà oòrùn Ásíríà.+ Odò kẹrin sì ni Yúfírétì.+

15 Jèhófà Ọlọ́run mú ọkùnrin náà, ó sì fi sínú ọgbà Édẹ́nì kó lè máa ro ó, kó sì máa tọ́jú rẹ̀.+ 16 Jèhófà Ọlọ́run tún pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé: “O lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà yìí ní àjẹtẹ́rùn.+ 17 Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, torí ó dájú pé ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ lo máa kú.”+

18 Jèhófà Ọlọ́run wá sọ pé: “Kò dáa kí ọkùnrin náà máa dá wà. Màá ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tó máa jẹ́ ẹnì kejì rẹ̀.”+ 19 Jèhófà Ọlọ́run dá gbogbo ẹranko látinú ilẹ̀ àti gbogbo ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sọ́dọ̀ ọkùnrin náà láti wo orúkọ tó máa sọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; orúkọ tí ọkùnrin náà bá sì sọ ohun alààyè* kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ń jẹ́.+ 20 Ọkùnrin náà wá sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn lórúkọ àti gbogbo ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run pẹ̀lú gbogbo ẹranko, àmọ́ kò sí olùrànlọ́wọ́ kankan fún ọkùnrin náà tó máa jẹ́ ẹnì kejì rẹ̀. 21 Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sun oorun àsùnwọra. Nígbà tó ń sùn, ó yọ ọ̀kan lára egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran bo ibẹ̀. 22 Jèhófà Ọlọ́run wá fi egungun ìhà tó yọ lára ọkùnrin náà mọ obìnrin, ó sì mú un wá fún ọkùnrin náà.+

23 Ni ọkùnrin náà bá sọ pé:

“Èyí gan-an ni egungun látinú egungun mi

Àti ẹran ara látinú ẹran ara mi.

Obìnrin ni yóò máa jẹ́,

Torí ara ọkùnrin ló ti wá.”+

24 Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin á ṣe fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́* ìyàwó rẹ̀, wọ́n á sì di ara kan.+ 25 Ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ̀ sì wà ní ìhòòhò;+ síbẹ̀ ojú ò tì wọ́n.

3 Nínú gbogbo ẹranko tí Jèhófà Ọlọ́run dá, ejò+ ló máa ń ṣọ́ra jù.* Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso gbogbo igi inú ọgbà?”+ 2 Ni obìnrin náà bá sọ fún ejò yẹn pé: “A lè jẹ lára àwọn èso igi inú ọgbà.+ 3 Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún wa nípa èso igi tó wà láàárín ọgbà+ pé: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kódà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án; kí ẹ má bàa kú.’” 4 Ejò yẹn wá sọ fún obìnrin náà pé: “Ó dájú pé ẹ ò ní kú.+ 5 Torí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ tí ẹ bá jẹ ẹ́ ni ojú yín máa là, ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ẹ sì máa mọ rere àti búburú.”+

6 Obìnrin náà wá rí i pé èso igi náà dára fún jíjẹ, ó dùn-ún wò, àní, igi náà wuni. Ló bá mú lára èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́.+ Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ lára èso náà nígbà tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.+ 7 Ni ojú àwọn méjèèjì bá là, wọ́n sì wá rí i pé ìhòòhò ni àwọn wà. Torí náà, wọ́n so ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì ṣe bàǹtẹ́ fún ara wọn.+

8 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run nígbà tó ń rìn nínú ọgbà ní àkókò tí atẹ́gùn máa ń fẹ́ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́,* ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ̀ sì lọ fara pa mọ́ sáàárín àwọn igi inú ọgbà, kí Jèhófà Ọlọ́run má bàa rí wọn. 9 Jèhófà Ọlọ́run sì ń pe ọkùnrin náà, ó ń sọ pé: “Ibo lo wà?” 10 Níkẹyìn, ọkùnrin náà fèsì pé: “Mo gbọ́ ohùn rẹ nínú ọgbà, àmọ́ ẹ̀rù bà mí torí pé mo wà ní ìhòòhò, mo wá lọ fara pa mọ́.” 11 Ó sọ fún un pé: “Ta ló sọ fún ọ pé o wà ní ìhòòhò?+ Ṣé o jẹ èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé kí o má jẹ ni?”+ 12 Ọkùnrin náà sọ pé: “Obìnrin tí o fún mi pé kó wà pẹ̀lú mi ni, òun ló fún mi ní èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.” 13 Ni Jèhófà Ọlọ́run bá sọ fún obìnrin náà pé: “Kí lo ṣe yìí?” Obìnrin náà fèsì pé: “Ejò ló tàn mí, tí mo fi jẹ ẹ́.”+

14 Jèhófà Ọlọ́run wá sọ fún ejò+ náà pé: “Torí ohun tí o ṣe yìí, ègún ni fún ọ nínú gbogbo ẹran ọ̀sìn àti gbogbo ẹranko. Ikùn rẹ ni wàá máa fi wọ́, erùpẹ̀ ni wàá sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. 15 Màá mú kí ìwọ+ àti obìnrin+ náà di ọ̀tá+ ara yín,* ọmọ* rẹ+ àti ọmọ* rẹ̀+ yóò sì di ọ̀tá. Òun yóò fọ́ orí rẹ,*+ ìwọ yóò sì ṣe é léṣe* ní gìgísẹ̀.”+

16 Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Èmi yóò mú kí ìrora rẹ pọ̀ gan-an tí o bá lóyún; inú ìrora ni wàá ti máa bímọ, ọkàn rẹ á máa fà sí ọkọ rẹ, á sì máa jọba lé ọ lórí.”

17 Ó sọ fún Ádámù* pé: “Torí o fetí sí ìyàwó rẹ, tí o sì jẹ èso igi tí mo pàṣẹ+ fún ọ pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ jẹ,’ ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ.+ Inú ìrora ni wàá ti máa jẹ èso rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.+ 18 Ẹ̀gún àti òṣùṣú ni yóò máa hù jáde fún ọ, ewéko ni wàá sì máa jẹ. 19 Inú òógùn ojú rẹ ni wàá ti máa jẹun títí wàá fi pa dà sí ilẹ̀, torí inú rẹ̀ lo ti wá.+ Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.”+

20 Lẹ́yìn èyí, Ádámù sọ ìyàwó rẹ̀ ní Éfà,* torí òun ló máa di ìyá gbogbo èèyàn.*+ 21 Jèhófà Ọlọ́run sì fi awọ ṣe aṣọ gígùn fún Ádámù àti ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n á máa wọ̀.+ 22 Jèhófà Ọlọ́run wá sọ pé: “Ọkùnrin náà ti dà bí ọ̀kan lára wa, ó ti mọ rere àti búburú.+ Ní báyìí, kó má bàa na ọwọ́ rẹ̀, kó sì tún mú èso igi ìyè,+ kó jẹ ẹ́, kó sì wà láàyè títí láé,*—” 23 Ni Jèhófà Ọlọ́run bá lé e kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì  + kó lè máa ro ilẹ̀ tí a ti mú un jáde.+ 24 Torí náà, ó lé ọkùnrin náà jáde, ó sì fi àwọn kérúbù+ àti idà oníná tó ń yí láìdáwọ́ dúró sí ìlà oòrùn ọgbà Édẹ́nì, kí wọ́n lè máa ṣọ́ ọ̀nà tó lọ síbi igi ìyè náà.

4 Ádámù bá Éfà ìyàwó rẹ̀ ní àṣepọ̀, ó sì lóyún.+ Nígbà tó bí Kéènì,+ ó sọ pé: “Jèhófà ti mú kí n ní* ọmọkùnrin kan.” 2 Lẹ́yìn náà, ó tún bí Ébẹ́lì,+ àbúrò rẹ̀.

Ébẹ́lì di olùṣọ́ àgùntàn, àmọ́ Kéènì di àgbẹ̀. 3 Nígbà tó yá, Kéènì mú àwọn èso kan wá, ó fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà. 4 Àmọ́ Ébẹ́lì mú lára àwọn àkọ́bí ẹran+ rẹ̀ wá, pẹ̀lú ọ̀rá wọn. Jèhófà ṣojúure sí Ébẹ́lì, ó sì gba ọrẹ+ rẹ̀, 5 àmọ́ kò ṣojúure sí Kéènì rárá, kò sì gba ọrẹ rẹ̀. Torí náà, Kéènì bínú gan-an, inú rẹ̀ ò sì dùn.* 6 Jèhófà wá sọ fún Kéènì pé: “Kí ló dé tí inú ń bí ọ tó báyìí, tí inú rẹ ò sì dùn? 7 Tí o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe rere, ṣé o ò ní pa dà rí ojúure ni?* Àmọ́ tí o ò bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ó sì fẹ́ jọba lé ọ lórí; àmọ́ ṣé o máa kápá rẹ̀?”

8 Lẹ́yìn náà, Kéènì sọ fún Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀ pé: “Jẹ́ ká lọ sí oko.” Nígbà tí wọ́n sì wà nínú oko, Kéènì lu Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀, ó sì pa á.+ 9 Lẹ́yìn náà, Jèhófà bi Kéènì pé: “Ibo ni Ébẹ́lì arákùnrin rẹ wà?” Ó fèsì pé: “Mi ò mọ̀. Ṣé èmi ni olùṣọ́ arákùnrin mi ni?” 10 Ọlọ́run wá sọ pé: “Kí lo ṣe yìí? Tẹ́tí kó o gbọ́ mi! Ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ń ké jáde sí mi láti inú ilẹ̀.+ 11 Ní báyìí, ègún wà lórí rẹ, màá sì lé ọ kúrò lórí ilẹ̀ tó la ẹnu láti mu ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ tí o ta sílẹ̀.+ 12 Tí o bá dá oko, ilẹ̀ ò ní mú èso* rẹ̀ jáde fún ọ. O sì máa di alárìnká àti ìsáǹsá ní ayé.” 13 Kéènì wá sọ fún Jèhófà pé: “Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ jù fún mi. 14 Lónìí, ò ń lé mi kúrò ní ilẹ̀,* èmi yóò sì kúrò níwájú rẹ; èmi yóò di alárìnká àti ìsáǹsá ní ayé, ó sì dájú pé ẹnikẹ́ni tó bá rí mi yóò pa mí.” 15 Jèhófà wá sọ fún un pé: “Kí ìyẹn má bàa ṣẹlẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá pa Kéènì yóò jìyà ìlọ́po méje.”

Jèhófà wá ṣe àmì kan* fún Kéènì kí ẹnikẹ́ni tó bá rí i má bàa pa á. 16 Lẹ́yìn náà, Kéènì kúrò níwájú Jèhófà, ó sì lọ ń gbé ní ilẹ̀ Ìgbèkùn,* ní apá ìlà oòrùn Édẹ́nì.+

17 Kéènì wá bá ìyàwó+ rẹ̀ ní àṣepọ̀, ó lóyún, ó sì bí Énọ́kù. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìlú kan, ó sì fi orúkọ ọmọ rẹ̀ Énọ́kù pe ìlú náà. 18 Énọ́kù wá bí Írádì. Írádì bí Mèhújáélì, Mèhújáélì bí Mètúṣáélì, Mètúṣáélì sì bí Lámékì.

19 Lámékì fẹ́ ìyàwó méjì. Orúkọ àkọ́kọ́ ni Ádà, orúkọ ìkejì sì ni Síláhì. 20 Ádà bí Jábálì. Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tó gbé inú àgọ́ tó sì ní ẹran ọ̀sìn. 21 Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Júbálì. Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tó lo háàpù àti fèrè ape. 22 Bákan náà, Síláhì bí Tubali-kéénì, ẹni tó ń rọ onírúurú irinṣẹ́ tí wọ́n fi bàbà àti irin ṣe. Náámà sì ni arábìnrin Tubali-kéénì. 23 Lámékì ń sọ fún àwọn ìyàwó rẹ̀, Ádà àti Síláhì, pé:

“Ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin ìyàwó Lámékì;

Ẹ fetí sí mi:

Mo pa ọkùnrin kan torí ó ṣe mí léṣe,

Àní ọ̀dọ́kùnrin kan, torí ó lù mí.

24 Tí ẹni tó bá pa Kéènì bá máa jìyà ní ìlọ́po méje,+

Ẹni tó bá pa Lámékì máa jìyà ní ìgbà àádọ́rin ó lé méje (77).”

25 Ádámù tún bá ìyàwó rẹ̀ ní àṣepọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́ẹ̀tì*+ torí ó sọ pé: “Ọlọ́run ti fi ọmọ* míì rọ́pò Ébẹ́lì fún mi, torí Kéènì pa á.”+ 26 Sẹ́ẹ̀tì náà bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Énọ́ṣì.+ Ìgbà yẹn ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà.

5 Ìwé ìtàn Ádámù nìyí. Ní ọjọ́ tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run.+ 2 Ó dá wọn ní akọ àti abo.+ Ní ọjọ́ tó dá wọn,+ ó súre fún wọn, ó sì pè wọ́n ní Èèyàn.*

3 Ádámù pé ẹni àádóje (130) ọdún, ó wá bí ọmọkùnrin kan tó jọ ọ́, tó jẹ́ àwòrán rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́ẹ̀tì.+ 4 Lẹ́yìn tó bí Sẹ́ẹ̀tì, Ádámù tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 5 Gbogbo ọjọ́ ayé Ádámù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé ọgbọ̀n (930) ọdún, ó sì kú.+

6 Sẹ́ẹ̀tì pé ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rùn-ún (105), ó wá bí Énọ́ṣì.+ 7 Lẹ́yìn tó bí Énọ́ṣì, Sẹ́ẹ̀tì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ọdún ó lé méje (807). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 8 Gbogbo ọjọ́ ayé Sẹ́ẹ̀tì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé méjìlá (912), ó sì kú.

9 Énọ́ṣì pé ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, ó wá bí Kénánù. 10 Lẹ́yìn tó bí Kénánù, Énọ́ṣì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 11 Gbogbo ọjọ́ ayé Énọ́ṣì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú.

12 Kénánù pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, ó wá bí Máhálálélì.+ 13 Lẹ́yìn tó bí Máhálálélì, Kénánù tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé ogójì (840) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 14 Gbogbo ọjọ́ ayé Kénánù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé mẹ́wàá (910), ó sì kú.

15 Máhálálélì pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin (65), ó wá bí Járédì.+ 16 Lẹ́yìn tó bí Járédì, Máhálálélì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé ọgbọ̀n (830) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 17 Gbogbo ọjọ́ ayé Máhálálélì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú.

18 Járédì pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́jọ (162), ó wá bí Énọ́kù.+ 19 Lẹ́yìn tó bí Énọ́kù, Járédì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 20 Gbogbo ọjọ́ ayé Járédì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti méjìlélọ́gọ́ta (962) ọdún, ó sì kú.

21 Énọ́kù pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin (65), ó wá bí Mètúsélà.+ 22 Lẹ́yìn tó bí Mètúsélà, Énọ́kù ń bá Ọlọ́run tòótọ́* rìn fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 23 Gbogbo ọjọ́ ayé Énọ́kù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùndínláàádọ́rin (365) ọdún. 24 Énọ́kù ń bá Ọlọ́run tòótọ́+ rìn. Nígbà tó yá, Énọ́kù ò sí mọ́, torí Ọlọ́run mú un lọ.+

25 Mètúsélà pé ẹni ọgọ́sàn-án ọdún ó lé méje (187), ó wá bí Lámékì.+ 26 Lẹ́yìn tó bí Lámékì, Mètúsélà tún lo ọgọ́rùn-ún méje àti méjìlélọ́gọ́rin (782) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 27 Gbogbo ọjọ́ ayé Mètúsélà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mọ́kàndínláàádọ́rin (969) ọdún, ó sì kú.

28 Lámékì pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́sàn-án (182), ó wá bí ọmọkùnrin kan. 29 Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Nóà,*+ ó sọ pé: “Ọmọ yìí á tù wá nínú* nídìí iṣẹ́ wa àti làálàá tí a ṣe torí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.”+ 30 Lẹ́yìn tó bí Nóà, Lámékì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ọdún ó dín márùn-ún (595). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 31 Gbogbo ọjọ́ ayé Lámékì jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (777) ọdún, ó sì kú.

32 Lẹ́yìn tí Nóà pé ẹni ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún, ó bí Ṣémù,+ Hámù+ àti Jáfẹ́tì.+

6 Nígbà tí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ lórí ilẹ̀, tí wọ́n sì ń bí àwọn ọmọbìnrin, 2 àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́*+ wá bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé àwọn ọmọbìnrin èèyàn rẹwà. Wọ́n sì ń fi gbogbo ẹni tó wù wọ́n ṣe aya. 3 Jèhófà wá sọ pé: “Ẹ̀mí mi ò ní gba èèyàn láyè títí láé,+ torí ẹlẹ́ran ara ni.* Torí náà, ọgọ́fà (120) ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”+

4 Àwọn Néfílímù* wà ní ayé nígbà yẹn àti lẹ́yìn ìgbà yẹn. Ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ ń bá àwọn ọmọbìnrin èèyàn lò pọ̀, wọ́n sì bí àwọn ọmọ fún wọn. Àwọn ni alágbára ayé ìgbà yẹn, àwọn ọkùnrin olókìkí.

5 Jèhófà wá rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, ó sì rí i pé kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.+ 6 Ó dun Jèhófà* pé òun dá èèyàn sáyé, ọkàn rẹ̀ sì bà jẹ́.*+ 7 Torí náà, Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò run àwọn èèyàn tí mo ti dá kúrò lórí ilẹ̀, èèyàn àti ẹran ọ̀sìn, ẹran tó ń rákò àti àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, torí ó dùn mí pé mo dá wọn.” 8 Àmọ́ Nóà rí ojúure Jèhófà.

9 Ìtàn Nóà nìyí.

Olódodo ni Nóà.+ Ó fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́bi* láàárín àwọn tí wọ́n jọ gbé láyé.* Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́+ rìn. 10 Nígbà tó yá, Nóà bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì.+ 11 Àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ rí i pé ayé ti bà jẹ́, ìwà ipá sì kún ayé. 12 Ọlọ́run wo ayé, àní ó ti bà jẹ́;+ ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo ẹlẹ́ran ara* ń hù ní ayé.+

13 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run wá sọ fún Nóà pé: “Mo ti pinnu pé màá run gbogbo ẹlẹ́ran ara, torí wọ́n ti fi ìwà ipá kún ayé, torí náà, màá pa wọ́n run pẹ̀lú ayé.+ 14 Ìwọ fi igi olóje*+ ṣe áàkì* fún ara rẹ. Kí o ṣe àwọn yàrá sínú áàkì náà, kí o sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì+ bo inú àti ìta rẹ̀. 15 Bí o ṣe máa ṣe é nìyí: Kí áàkì náà gùn tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ìgbọ̀nwọ́,* kó fẹ̀ tó àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, kó sì ga tó ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. 16 Kí o ṣe fèrèsé* tí ìmọ́lẹ̀ á máa gbà wọ* inú áàkì náà, kó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan láti òkè. Kí o ṣe ẹnu ọ̀nà áàkì náà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,+ kí o sì jẹ́ kó ní àjà kìíní, àjà kejì àti àjà kẹta.

17 “Ní tèmi, màá mú kí ìkún omi  + bo ayé kí n lè run gbogbo ẹran ara tó ní ẹ̀mí* lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ohun tó wà ní ayé ló máa pa run.+ 18 Mo sì ń bá ọ dá májẹ̀mú, kí o wọ inú áàkì náà, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti ìyàwó rẹ pẹ̀lú ìyàwó àwọn ọmọ rẹ.+ 19 Kí o mú méjì-méjì lára gbogbo oríṣiríṣi ohun alààyè+ wọnú áàkì náà, kí ẹ lè jọ wà láàyè. Kí o mú wọn ní akọ àti abo;+ 20 àwọn ẹ̀dá tó ń fò ní irú tiwọn, àwọn ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn àti gbogbo ẹran tó ń rákò lórí ilẹ̀ ní irú tiwọn, méjì-méjì ni kí o mú wọn wọlé sọ́dọ̀ rẹ kí wọ́n lè wà láàyè.+ 21 Ní tìrẹ, kí o kó oríṣiríṣi oúnjẹ+ jọ, kí o sì gbé wọn dání, òun ni ìwọ àti àwọn ẹran náà á máa jẹ.”

22 Nóà sì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.+

7 Jèhófà wá sọ fún Nóà pé: “Wọ inú áàkì, ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, torí ìwọ ni mo rí pé ó jẹ́ olódodo níwájú mi nínú ìran yìí.+ 2 Kí o mú gbogbo onírúurú ẹran tó mọ́ ní méje-méje,*+ ní akọ àti abo; mú méjì-méjì péré nínú gbogbo ẹran tí kò mọ́, ní akọ àti abo; 3 kí o sì mú àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run ní méje-méje,* ní akọ àti abo, kí ọmọ wọn má bàa pa run ní gbogbo ayé.+ 4 Torí ní ọjọ́ méje òní, èmi yóò rọ òjò+ sórí ayé fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru,+ màá sì run gbogbo ohun alààyè tí mo dá kúrò lórí ilẹ̀.”+ 5 Nóà sì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kó ṣe.

6 Ẹni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọdún ni Nóà nígbà tí ìkún omi bo ayé.+ 7 Nóà, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ sì wọnú áàkì kí ìkún omi+ náà tó bẹ̀rẹ̀. 8 Àwọn kan lára gbogbo ẹran tó mọ́ àti gbogbo ẹran tí kò mọ́, lára àwọn ẹ̀dá tó ń fò àti gbogbo ohun tó ń rìn lórí ilẹ̀,+ 9 wọ́n wọnú áàkì lọ bá Nóà ní méjì-méjì, ní akọ àti abo, bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún Nóà. 10 Lẹ́yìn ọjọ́ méje, ìkún omi bo ayé.

11 Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì, ní ọdún tí Nóà pé ẹni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọdún, ọjọ́ yẹn ni gbogbo orísun omi ya, àwọn ibodè omi ọ̀run sì ṣí.+ 12 Òjò rọ̀ sórí ayé fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. 13 Ní ọjọ́ yẹn gan-an, Nóà wọ inú áàkì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì,+ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.+ 14 Wọ́n wọlé, pẹ̀lú gbogbo ẹran inú igbó ní irú tiwọn, gbogbo ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn, gbogbo ẹran tó ń rákò ní ayé ní irú tiwọn, gbogbo ẹ̀dá tó ń fò ní irú tiwọn, títí kan gbogbo ẹyẹ àti gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́. 15 Wọ́n ń wọlé lọ bá Nóà nínú áàkì, ní méjì-méjì, lára onírúurú ẹran tó ní ẹ̀mí.* 16 Wọ́n wá wọlé, akọ àti abo nínú onírúurú ẹran, bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún un. Lẹ́yìn náà, Jèhófà ti ilẹ̀kùn pa.

17 Ìkún omi náà ò dáwọ́ dúró* lórí ayé fún ogójì (40) ọjọ́, omi náà sì ń pọ̀ sí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé áàkì náà, ó sì léfòó lórí omi tó bo ayé. 18 Omi náà bolẹ̀, ó sì ń pọ̀ gan-an ní ayé, àmọ́ áàkì náà léfòó lórí omi. 19 Omi náà bo ayé débi pé gbogbo òkè tó ga tó wà lábẹ́ ọ̀run ni omi bò mọ́lẹ̀.+ 20 Omi náà fi ìgbọ̀nwọ́* mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ga ju àwọn òkè lọ.

21 Torí náà, gbogbo ohun alààyè* tó wà ní ayé pa run,+ ìyẹn, àwọn ẹ̀dá tó ń fò, àwọn ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹran inú igbó, àwọn ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn àti gbogbo aráyé.+ 22 Gbogbo ohun tó wà lórí ilẹ̀ tó ní èémí ìyè* ní ihò imú rẹ̀ ló kú.+ 23 Ó run gbogbo ohun alààyè tó wà ní ayé, títí kan èèyàn àti ẹran, ẹran tó ń rákò àti àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run. Gbogbo wọn pátá ló pa run ní ayé;+ Nóà àti àwọn tí wọ́n jọ wà nínú áàkì nìkan ló yè é.+ 24 Omi náà sì bo ayé fún àádọ́jọ (150) ọjọ́.+

8 Àmọ́ Ọlọ́run yí àfiyèsí rẹ̀ sí* Nóà àti gbogbo ẹran inú igbó àti ẹran ọ̀sìn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú áàkì,+ Ọlọ́run sì mú kí atẹ́gùn fẹ́ sórí ayé, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fà. 2 Àwọn orísun omi àti àwọn ibodè omi ọ̀run tì pa, òjò ò sì rọ̀ mọ́* láti ọ̀run.+ 3 Omi náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í fà lórí ilẹ̀. Lẹ́yìn àádọ́jọ (150) ọjọ́, omi náà ti lọ sílẹ̀. 4 Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje, áàkì náà gúnlẹ̀ sórí àwọn òkè Árárátì. 5 Omi náà ń lọ sílẹ̀ ṣáá títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá, téńté àwọn òkè fara hàn.+

6 Lẹ́yìn ogójì (40) ọjọ́, Nóà ṣí fèrèsé*+ tó ṣe sí áàkì náà, 7 ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde; ẹyẹ náà ń fò jáde, ó sì ń pa dà wá títí omi náà fi gbẹ lórí ilẹ̀.

8 Lẹ́yìn náà, ó rán àdàbà kan jáde kó lè mọ̀ bóyá omi náà ti fà lórí ilẹ̀. 9 Àdàbà náà ò rí ibi ìsinmi kankan tó lè bà lé,* torí náà, ó pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú áàkì torí omi ṣì bo gbogbo ayé.+ Ó wá na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú un wọlé sínú áàkì. 10 Ó dúró fún ọjọ́ méje, ó sì rán àdàbà náà jáde lẹ́ẹ̀kan sí i látinú áàkì. 11 Nígbà tí àdàbà náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ó rí i pé ewé ólífì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ já wà ní ẹnu rẹ̀! Nóà wá mọ̀ pé omi náà ti lọ sílẹ̀.+ 12 Ó tún dúró fún ọjọ́ méje míì. Ó wá rán àdàbà náà jáde, àmọ́ kò pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.

13 Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní, ọdún kọkànlélẹ́gbẹ̀ta (601),+ omi náà ti fà lórí ilẹ̀; Nóà ṣí ìbòrí áàkì náà, ó sì rí i pé ilẹ̀ ti ń gbẹ. 14 Ilẹ̀ náà wá gbẹ tán ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kejì.

15 Ọlọ́run wá sọ fún Nóà pé: 16 “Jáde nínú áàkì, ìwọ, ìyàwó rẹ, àwọn ọmọ rẹ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ.+ 17 Kó onírúurú ẹran ara+ tó jẹ́ ohun alààyè jáde pẹ̀lú rẹ, àwọn ẹ̀dá tó ń fò, àwọn ẹran àti gbogbo ẹran tó ń rákò lórí ilẹ̀, kí wọ́n lè máa pọ̀ sí i* ní ayé, kí wọ́n máa bímọ, kí wọ́n sì pọ̀ ní ayé.”+

18 Torí náà, Nóà jáde, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ ìyàwó rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀. 19 Gbogbo ohun alààyè, gbogbo ẹran tó ń rákò, gbogbo ẹ̀dá tó ń fò àti gbogbo ohun tó ń rìn lórí ilẹ̀ jáde nínú áàkì náà lọ́wọ̀ọ̀wọ́.+ 20 Nóà sì mọ pẹpẹ+ kan fún Jèhófà, ó mú lára gbogbo ẹran tó mọ́ àti lára gbogbo ẹ̀dá tó ń fò+ tó sì mọ́, ó sì rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà.+ 21 Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ òórùn dídùn.* Jèhófà wá sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Mi ò tún ní fi ilẹ̀+ gégùn-ún* mọ́ torí èèyàn, torí pé kìkì ibi ni èèyàn ń rò lọ́kàn láti ìgbà èwe rẹ̀ wá;+ mi ò sì tún ní pa gbogbo ohun alààyè run mọ́, bí mo ti ṣe.+ 22 Láti ìsinsìnyí lọ, ìgbà ìfúnrúgbìn àti ìgbà ìkórè kò ní tán ní ayé, bẹ́ẹ̀ ni òtútù àti ooru, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù, ọ̀sán àti òru.”+

9 Ọlọ́run súre fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ pọ̀, kí ẹ sì kún ayé.+ 2 Gbogbo ohun alààyè tó wà láyé, gbogbo ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, gbogbo ohun tó ń rìn lórí ilẹ̀ àti gbogbo ẹja inú òkun yóò máa bẹ̀rù yín, wọ́n á sì máa wárìrì torí yín. Wọ́n ti wà ní ìkáwọ́ yín báyìí.*+ 3 Gbogbo ẹran tó ń rìn tó sì wà láàyè lè jẹ́ oúnjẹ fún yín.+ Mo fún yín ní gbogbo wọn bí mo ṣe fún yín ní ewéko tútù.+ 4 Kìkì ẹran pẹ̀lú ẹ̀mí* rẹ̀, ìyẹn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ ni ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ.+ 5 Yàtọ̀ sí ìyẹn, èmi yóò béèrè ẹ̀jẹ̀ yín tó jẹ́ ẹ̀mí yín* pa dà. Èmi yóò béèrè lọ́wọ́ gbogbo ohun alààyè; ọwọ́ kálukú ni màá sì ti béèrè ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀.+ 6 Ẹnikẹ́ni tó bá ta ẹ̀jẹ̀ èèyàn sílẹ̀, èèyàn ni yóò ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀,+ torí àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá èèyàn.+ 7 Ní tiyín, ẹ máa bímọ, kí ẹ pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ.”+

8 Ọlọ́run wá sọ fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: 9 “Mò ń bá ẹ̀yin  + àti àwọn ọmọ yín dá májẹ̀mú, 10 àti gbogbo ohun alààyè* tó wà pẹ̀lú yín, àwọn ẹyẹ, àwọn ẹran àti gbogbo ohun alààyè tó wà ní ayé pẹ̀lú yín, gbogbo àwọn tó tinú áàkì jáde, ìyẹn gbogbo ohun alààyè tó wà ní ayé.+ 11 Àní, mo fìdí májẹ̀mú tí mo bá yín dá múlẹ̀: Ìkún omi ò tún ní pa gbogbo ẹran ara* run mọ́, ìkún omi ò sì ní pa ayé run mọ́.”+

12 Ọlọ́run sì fi kún un pé: “Àmì májẹ̀mú tí mò ń bá ẹ̀yin àti gbogbo ohun alààyè* tó wà pẹ̀lú yín dá nìyí, jálẹ̀ gbogbo ìran tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. 13 Mo fi òṣùmàrè mi sí ojú ọ̀run, ó sì máa jẹ́ àmì májẹ̀mú tó wà láàárín èmi àti ayé. 14 Nígbàkigbà tí mo bá mú kí ojú ọ̀run ṣú, ó dájú pé òṣùmàrè máa hàn lójú ọ̀run. 15 Ó sì dájú pé màá rántí májẹ̀mú tí mo bá ẹ̀yin àti onírúurú ohun alààyè* dá; omi ò sì tún ní pọ̀ mọ́ débi tó fi máa kún, tó sì máa pa gbogbo ẹran ara run.+ 16 Òṣùmàrè á yọ lójú ọ̀run, ó sì dájú pé màá rí i, màá sì rántí májẹ̀mú ayérayé tó wà láàárín Ọlọ́run àti onírúurú ohun alààyè* tó wà ní ayé.”

17 Ọlọ́run tún sọ fún Nóà pé: “Àmì májẹ̀mú tí mo bá gbogbo ẹran ara tó wà ní ayé dá nìyí.”+

18 Àwọn ọmọ Nóà tó jáde nínú áàkì ni Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì.+ Nígbà tó yá, Hámù bí Kénáánì.+ 19 Àwọn mẹ́ta yìí ni ọmọ Nóà, àwọn ló sì bí gbogbo èèyàn tó wà ní ayé, tí wọ́n sì tàn káàkiri.+

20 Nóà wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà kan. 21 Nígbà tó mu lára wáìnì rẹ̀, ọtí bẹ̀rẹ̀ sí í pa á, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò nínú àgọ́ rẹ̀. 22 Hámù, bàbá Kénáánì, rí ìhòòhò bàbá rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ méjèèjì níta. 23 Ṣémù àti Jáfẹ́tì wá mú aṣọ kan, wọ́n fi lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn wọlé. Wọ́n bo ìhòòhò bàbá wọn, àmọ́ wọn ò wo ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn ò sì rí ìhòòhò bàbá wọn.

24 Nígbà tí wáìnì dá lójú Nóà, ó gbọ́ ohun tí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí i, 25 ó sì sọ pé:

“Ègún ni fún Kénáánì.+

Kó di ẹrú àwọn arákùnrin rẹ̀.”*+

26 Ó sì fi kún un pé:

“Ẹ yin Jèhófà, Ọlọ́run Ṣémù,

Kí Kénáánì sì di ẹrú rẹ̀.+

27 Kí Ọlọ́run fún Jáfẹ́tì ní àyè tó fẹ̀ dáadáa,

Kó sì máa gbé inú àwọn àgọ́ Ṣémù.

Kí Kénáánì di ẹrú tiẹ̀ náà.”

28 Nóà lo ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́ta (350) ọdún lẹ́yìn Ìkún Omi.+ 29 Torí náà, gbogbo ọjọ́ ayé Nóà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé àádọ́ta (950) ọdún, ó sì kú.

10 Ìtàn àwọn ọmọ Nóà nìyí, Ṣémù,+ Hámù àti Jáfẹ́tì.

Wọ́n bí àwọn ọmọ lẹ́yìn Ìkún Omi.+ 2 Àwọn ọmọ Jáfẹ́tì ni Gómérì,+ Mágọ́gù,+ Mádáì, Jáfánì, Túbálì,+ Méṣékì+ àti Tírásì.+

3 Àwọn ọmọ Gómérì ni Áṣíkénásì,+ Rífátì àti Tógámà.+

4 Àwọn ọmọ Jáfánì ni Élíṣáhì,+ Táṣíṣì,+ Kítímù+ àti Dódánímù.

5 Ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn tó ń gbé àwọn erékùṣù ti tàn ká àwọn ilẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí èdè wọn, ìdílé wọn àti orílẹ̀-èdè wọn.

6 Àwọn ọmọ Hámù ni Kúṣì, Mísíráímù,+ Pútì+ àti Kénáánì.+

7 Àwọn ọmọ Kúṣì ni Sébà,+ Háfílà, Sábítà, Ráámà+ àti Sábítékà.

Àwọn ọmọ Ráámà sì ni Ṣébà àti Dédánì.

8 Kúṣì bí Nímírọ́dù. Òun ló kọ́kọ́ di alágbára ní ayé. 9 Ó di ọdẹ alágbára tó ń ta ko Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń sọ pé: “Bíi Nímírọ́dù ọdẹ alágbára tó ta ko Jèhófà.” 10 Ibi tí ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ni* Bábélì,+ Érékì,+ Ákádì àti Kálínè, ní ilẹ̀ Ṣínárì.+ 11 Láti ibẹ̀, ó lọ sí Ásíríà,+ ó sì kọ́ Nínéfè,+ Rehoboti-Írì, Kálà 12 àti Résénì, láàárín Nínéfè àti Kálà: Èyí ni ìlú ńlá náà.*

13 Mísíráímù bí Lúdímù,+ Ánámímù, Léhábímù, Náfítúhímù,+ 14 Pátírúsímù,+ Kásílúhímù (ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn Filísínì+ ti wá) àti Káfítórímù.+

15 Kénáánì bí Sídónì+ àkọ́bí rẹ̀ àti Hétì+ 16 àti àwọn ará Jébúsì,+ àwọn Ámórì,+ àwọn Gẹ́gáṣì, 17 àwọn Hífì,+ àwọn Ákì, àwọn Sáínì, 18 àwọn Áfádì,+ àwọn Sémárì àti àwọn Hámátì.+ Lẹ́yìn náà, àwọn ìdílé àwọn ọmọ Kénáánì tàn káàkiri. 19 Ààlà àwọn ọmọ Kénáánì bẹ̀rẹ̀ láti Sídónì títí lọ dé Gérárì,+ nítòsí Gásà,+ títí lọ dé Sódómù, Gòmórà,+ Ádímà àti Sébóíímù,+ nítòsí Láṣà. 20 Àwọn ọmọ Hámù nìyí, bí wọ́n ṣe wà nínú ìdílé wọn, èdè wọn, ilẹ̀ wọn àti orílẹ̀-èdè wọn.

21 Ṣémù náà bímọ, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn ọmọ Ébérì,+ òun sì ni arákùnrin Jáfẹ́tì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n pátápátá.* 22 Àwọn ọmọ Ṣémù ni Élámù,+ Áṣúrì,+ Ápákíṣádì,+ Lúdì àti Árámù.+

23 Àwọn ọmọ Árámù ni Úsì, Húlì, Gétérì àti Máṣì.

24 Ápákíṣádì bí Ṣélà,+ Ṣélà sì bí Ébérì.

25 Ọmọ méjì ni Ébérì bí. Ọ̀kan ń jẹ́ Pélégì,*+ torí pé ìgbà ayé rẹ̀ ni ayé* pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jókítánì.+

26 Jókítánì bí Álímódádì, Ṣéléfì, Hásámáfétì, Jérà,+ 27 Hádórámù, Úsálì, Díkílà, 28 Óbálì, Ábímáélì, Ṣébà, 29 Ófírì,+ Háfílà àti Jóbábù; gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Jókítánì.

30 Ibi tí wọ́n ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Méṣà títí lọ dé Séfárì, agbègbè olókè Ìlà Oòrùn.

31 Àwọn ọmọ Ṣémù nìyí bí wọ́n ṣe wà nínú ìdílé wọn, èdè wọn, ilẹ̀ wọn àti orílẹ̀-èdè wọn.+

32 Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Nóà, bí wọ́n ṣe wà nínú ìdílé kálukú wọn àti orílẹ̀-èdè wọn. Ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn orílẹ̀-èdè ti tàn káàkiri ayé lẹ́yìn Ìkún Omi.+

11 Èdè kan ni gbogbo ayé ń sọ, wọ́n sì ń lo àwọn ọ̀rọ̀ kan náà.* 2 Bí wọ́n ṣe ń rìnrìn àjò lọ sí apá ìlà oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣínárì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀. 3 Wọ́n wá sọ fún ara wọn pé: “Ó yá! Ẹ jẹ́ ká mọ bíríkì, ká fi sínú iná.” Torí náà, wọ́n lo bíríkì dípò òkúta, wọ́n sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì ṣe àpòrọ́. 4 Wọ́n wá sọ pé: “Ó yá! Ẹ jẹ́ ká kọ́ ìlú kan fún ara wa, ká kọ́ ilé gogoro tó ga dé ọ̀run, ká mú kí orúkọ wa lókìkí, ká má bàa tú ká sí gbogbo ayé.”+

5 Ni Jèhófà bá lọ wo ìlú náà àti ilé gogoro tí àwọn ọmọ èèyàn kọ́. 6 Jèhófà sì sọ pé: “Wò ó! Èèyàn kan ni wọ́n, èdè kan+ ni wọ́n ń sọ, ohun tí wọ́n sì dáwọ́ lé nìyí. Kò ní sí ohun tí wọ́n ní lọ́kàn tí kò ní ṣeé ṣe fún wọn. 7 Wá! Jẹ́ ká+ lọ síbẹ̀ ká sì da èdè wọn rú, kí wọ́n má bàa gbọ́ èdè ara wọn mọ́.” 8 Torí náà, Jèhófà tú wọn ká láti ibẹ̀ lọ sí gbogbo ayé,+ kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ìlú tí wọ́n ń kọ́ sílẹ̀. 9 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Bábélì,*+ torí ibẹ̀ ni Jèhófà ti da èdè gbogbo ayé rú, ibẹ̀ sì ni Jèhófà ti tú wọn ká sí gbogbo ayé.

10 Ìtàn Ṣémù+ nìyí.

Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ṣémù nígbà tó bí Ápákíṣádì+ ní ọdún kejì lẹ́yìn Ìkún Omi. 11 Lẹ́yìn tó bí Ápákíṣádì, Ṣémù tún lo ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.+

12 Ápákíṣádì pé ẹni ọdún márùndínlógójì (35), ó wá bí Ṣélà.+ 13 Lẹ́yìn tó bí Ṣélà, Ápákíṣádì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ọdún ó lé mẹ́ta (403). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

14 Ṣélà pé ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún, ó wá bí Ébérì.+ 15 Lẹ́yìn tó bí Ébérì, Ṣélà tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ọdún ó lé mẹ́ta (403). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

16 Ébérì pé ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34), ó wá bí Pélégì.+ 17 Lẹ́yìn tó bí Pélégì, Ébérì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

18 Pélégì pé ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún, ó wá bí Réù.+ 19 Lẹ́yìn tó bí Réù, Pélégì tún lo igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

20 Réù pé ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32), ó wá bí Sérúgù. 21 Lẹ́yìn tó bí Sérúgù, Réù tún lo igba ọdún ó lé méje (207). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

22 Sérúgù pé ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún, ó wá bí Náhórì. 23 Lẹ́yìn tó bí Náhórì, Sérúgù tún lo igba (200) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

24 Náhórì pé ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), ó wá bí Térà.+ 25 Lẹ́yìn tó bí Térà, Náhórì tún lo ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́fà (119). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

26 Térà pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, ó sì bí Ábúrámù,+ Náhórì+ àti Háránì.

27 Ìtàn Térà nìyí.

Térà bí Ábúrámù, Náhórì àti Háránì; Háránì sì bí Lọ́ọ̀tì.+ 28 Háránì kú nígbà tí Térà bàbá rẹ̀ ṣì wà láàyè, ní ilẹ̀ tí wọ́n ti bí i, ní Úrì+ ti àwọn ará Kálídíà.+ 29 Ábúrámù àti Náhórì fẹ́ ìyàwó. Orúkọ ìyàwó Ábúrámù ni Sáráì,+ orúkọ ìyàwó Náhórì sì ni Mílíkà,+ ọmọbìnrin Háránì, bàbá Mílíkà àti Ísíkà. 30 Àmọ́ àgàn+ ni Sáráì; kò ní ọmọ kankan.

31 Térà wá mú Ábúrámù ọmọ rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ̀,+ ọmọ Háránì, ó sì mú Sáráì, ìyàwó Ábúrámù ọmọ rẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé e nígbà tó kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà láti lọ sí ilẹ̀ Kénáánì.+ Nígbà tó yá, wọ́n dé Háránì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀. 32 Gbogbo ọjọ́ ayé Térà jẹ́ igba ọdún ó lé márùn-ún (205). Térà wá kú ní Háránì.

12 Jèhófà sì sọ fún Ábúrámù pé: “Kúrò ní ilẹ̀ rẹ, kí o kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ àti ilé bàbá rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí màá fi hàn ọ́.+ 2 Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá, màá sì bù kún ọ. Màá mú kí orúkọ rẹ di ńlá, ó sì máa jẹ́ ìbùkún.+ 3 Màá súre fún àwọn tó ń súre fún ọ, màá sì gégùn-ún fún ẹni tó bá gégùn-ún fún ọ,+ ó dájú pé gbogbo ìdílé tó wà lórí ilẹ̀ yóò rí ìbùkún gbà* nípasẹ̀ rẹ.”+

4 Torí náà, Ábúrámù gbéra, bí Jèhófà ṣe sọ fún un, Lọ́ọ̀tì sì bá a lọ. Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) ni Ábúrámù nígbà tó kúrò ní Háránì.+ 5 Ábúrámù mú Sáráì+ ìyàwó rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì ọmọ arákùnrin rẹ̀,+ ó kó gbogbo ẹrù tí wọ́n ti ní+ àti àwọn èèyàn* tó jẹ́ tiwọn ní Háránì, wọ́n sì forí lé ilẹ̀ Kénáánì.+ Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Kénáánì, 6 Ábúrámù rin ilẹ̀ náà já títí dé ibi tí Ṣékémù+ wà, nítòsí àwọn igi ńlá tó wà ní Mórè.+ Àwọn ọmọ Kénáánì wà ní ilẹ̀ náà nígbà yẹn. 7 Jèhófà wá fara han Ábúrámù, ó sì sọ pé: “Ọmọ* rẹ+ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí.”+ Ó sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ẹni tó fara hàn án. 8 Lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè olókè tó wà ní ìlà oòrùn Bẹ́tẹ́lì,+ ó pa àgọ́ rẹ̀ síbẹ̀, Bẹ́tẹ́lì wà ní ìwọ̀ oòrùn àgọ́ náà, Áì+ sì wà ní ìlà oòrùn. Ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà.+ 9 Lẹ́yìn náà, Ábúrámù kó kúrò níbẹ̀, ó sì gba ọ̀nà Négébù+ lọ, ó ń pa àgọ́ láti ibì kan dé ibòmíì.

10 Ìyàn wá mú ní ilẹ̀ náà, Ábúrámù sì gbéra lọ sí Íjíbítì kó lè gbé ibẹ̀ fúngbà díẹ̀,*+ torí ìyàn mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.+ 11 Bó ṣe fẹ́ wọ Íjíbítì, ó sọ fún Sáráì ìyàwó rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́, gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! Mo mọ̀ pé o rẹwà gan-an lóbìnrin.+ 12 Tí àwọn ará Íjíbítì bá sì rí ọ, ó dájú pé wọ́n á sọ pé, ‘Ìyàwó rẹ̀ nìyí.’ Wọ́n á pa mí, àmọ́ wọ́n á dá ọ sí. 13 Jọ̀ọ́, sọ fún wọn pé àbúrò mi ni ọ́, kí nǹkan kan má bàa ṣe mí torí rẹ, kí wọ́n lè dá ẹ̀mí mi sí.”*+

14 Gbàrà tí Ábúrámù wọ Íjíbítì, àwọn ará Íjíbítì rí i pé obìnrin náà rẹwà gan-an. 15 Àwọn ìjòyè Fáráò pẹ̀lú rí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn rẹ̀ dáadáa fún Fáráò, débi pé wọ́n mú obìnrin náà lọ sí ilé Fáráò. 16 Fáráò tọ́jú Ábúrámù dáadáa nítorí obìnrin náà, Ábúrámù sì wá ní àwọn àgùntàn, màlúù, akọ àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin àti àwọn ràkúnmí.+ 17 Jèhófà fi àjàkálẹ̀ àrùn* kọ lu Fáráò àti agbo ilé rẹ̀ nítorí Sáráì, ìyàwó Ábúrámù.+ 18 Ni Fáráò bá pe Ábúrámù, ó sì sọ fún un pé: “Kí lo ṣe sí mi yìí? Kí ló dé tí o ò sọ fún mi pé ìyàwó rẹ ni? 19 Kí ló dé tí o sọ pé, ‘Àbúrò+ mi ni,’ tó fi jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kí n fi ṣe aya? Ìyàwó rẹ nìyí. Mú un, kí o sì máa lọ!” 20 Ni Fáráò bá pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ nípa Ábúrámù, wọ́n sì ní kí Ábúrámù àti ìyàwó rẹ̀ kúrò ní ìlú náà pẹ̀lú gbogbo ohun tó ní.+

13 Ábúrámù kúrò ní Íjíbítì lọ sí Négébù,+ òun àti ìyàwó rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní, pẹ̀lú Lọ́ọ̀tì. 2 Ábúrámù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn, fàdákà àti wúrà.+ 3 Ó ń pàgọ́ láti ibì kan dé ibòmíì lẹ́nu ìrìn àjò rẹ̀ láti Négébù lọ dé Bẹ́tẹ́lì, títí ó fi dé ibi tó pàgọ́ sí tẹ́lẹ̀ láàárín Bẹ́tẹ́lì àti Áì,+ 4 níbi tó mọ pẹpẹ sí tẹ́lẹ̀. Ibẹ̀ ni Ábúrámù ti ké pe orúkọ Jèhófà.

5 Lọ́ọ̀tì, tó ń bá Ábúrámù rìnrìn àjò, pẹ̀lú ní àwọn àgùntàn, màlúù àti àwọn àgọ́. 6 Wọn ò sì lè jọ wà níbì kan náà torí ilẹ̀ náà ò gba gbogbo wọn; ohun ìní wọn ti pọ̀ gan-an débi pé wọn ò lè jọ máa gbé pọ̀ mọ́. 7 Torí náà, ìjà ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tó ń da ẹran ọ̀sìn Ábúrámù àti àwọn tó ń da ẹran ọ̀sìn Lọ́ọ̀tì. (Nígbà yẹn, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì ń gbé ní ilẹ̀ náà.)+ 8 Ábúrámù wá sọ fún Lọ́ọ̀tì+ pé: “Jọ̀ọ́, kò yẹ kí ìjà wáyé láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn tó ń da ẹran mi àti àwọn tó ń da ẹran rẹ, torí arákùnrin ni wá. 9 Ṣebí gbogbo ilẹ̀ ló wà níwájú rẹ yìí? Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Tí o bá lọ sí apá òsì, èmi á lọ sí apá ọ̀tún; àmọ́ tí o bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi á lọ sí apá òsì.” 10 Lọ́ọ̀tì wá gbójú sókè, ó sì rí i pé gbogbo agbègbè Jọ́dánì+ lómi dáadáa, (kí Jèhófà tó pa Sódómù àti Gòmórà run), bí ọgbà Jèhófà,+ bí ilẹ̀ Íjíbítì, títí lọ dé Sóárì.+ 11 Lọ́ọ̀tì wá yan gbogbo agbègbè Jọ́dánì fún ara rẹ̀, ó sì ṣí ibùdó rẹ̀ lọ sí ìlà oòrùn. Bí wọ́n ṣe lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nìyẹn. 12 Ábúrámù ń gbé ilẹ̀ Kénáánì, àmọ́ Lọ́ọ̀tì ń gbé láàárín àwọn ìlú tó wà ní agbègbè náà.+ Nígbà tó yá, ó pàgọ́ rẹ̀ sí tòsí Sódómù. 13 Èèyàn burúkú ni àwọn ará Sódómù, ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku ni wọ́n jẹ́ lójú Jèhófà.+

14 Jèhófà sọ fún Ábúrámù lẹ́yìn tí Lọ́ọ̀tì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́ gbójú sókè níbi tí o wà, kí o sì wo àríwá àti gúúsù, ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, 15 torí gbogbo ilẹ̀ tí o rí yìí ni màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ, yóò sì di ohun ìní yín títí láé.+ 16 Màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó fi jẹ́ pé tí ẹnikẹ́ni bá lè ka erùpẹ̀ ilẹ̀ ni wọ́n á tó lè ka+ ọmọ* rẹ. 17 Dìde, kí o sì rin ilẹ̀ náà já, kí o rin gígùn àti fífẹ̀ rẹ̀, torí ìwọ ni màá fún.” 18 Ábúrámù sì ń gbé inú àgọ́. Nígbà tó yá, ó lọ ń gbé láàárín àwọn igi ńlá Mámúrè,+ tó wà ní Hébúrónì;+ ó sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà.+

14 Nígbà ayé Ámúráfélì ọba Ṣínárì,+ Áríókù ọba Élásárì, Kedoláómà+ ọba Élámù+ àti Tídálì ọba Góíímù, 2 àwọn ọba yìí bá Bérà ọba Sódómù+ jagun àti Bíṣà ọba Gòmórà,+ Ṣínábù ọba Ádímà, Ṣémébà ọba Sébóíímù+ àti ọba Bélà, ìyẹn Sóárì. 3 Gbogbo ọmọ ogun wọn para pọ̀ ní Àfonífojì* Sídímù,+ ìyẹn Òkun Iyọ̀.*+

4 Wọ́n ti fi ọdún méjìlá (12) sin Kedoláómà, àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ ní ọdún kẹtàlá. 5 Torí náà, ní ọdún kẹrìnlá, Kedoláómà àti àwọn ọba tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá, wọ́n sì ṣẹ́gun Réfáímù ní Aṣiteroti-kánáímù, wọ́n ṣẹ́gun Súsímù ní Hámù, Émímù+ ní Ṣafe-kíríátáímù, 6 àwọn Hórì+ ní òkè Séírì+ tó jẹ́ tiwọn, títí dé Eli-páránì, tó wà ní aginjù. 7 Wọ́n wá pa dà, wọ́n sì wá sí Ẹn-míṣípátì, ìyẹn Kádéṣì,+ wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo agbègbè àwọn ọmọ Ámálékì+ àti àwọn Ámórì+ tí wọ́n ń gbé ní Hasasoni-támárì.+

8 Ìgbà náà ni ọba Sódómù gbéra, ọba Gòmórà náà gbéra àti ọba Ádímà, ọba Sébóíímù àti ọba Bélà, ìyẹn Sóárì, wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun jà wọ́n ní Àfonífojì* Sídímù, 9 wọ́n gbógun ja Kedoláómà ọba Élámù, Tídálì ọba Góíímù, Ámúráfélì ọba Ṣínárì àti Áríókù ọba Élásárì,+ ọba mẹ́rin dojú kọ ọba márùn-ún. 10 Kòtò tó ní ọ̀dà bítúmẹ́nì ló kún Àfonífojì* Sídímù. Nígbà tí àwọn ọba Sódómù àti Gòmórà fẹ́ sá lọ, wọ́n kó sínú àwọn kòtò náà, àwọn tó ṣẹ́ kù sì sá lọ sí agbègbè olókè. 11 Àwọn tó ṣẹ́gun kó gbogbo ẹrù Sódómù àti Gòmórà àti gbogbo oúnjẹ wọn, wọ́n sì lọ.+ 12 Wọ́n tún mú Lọ́ọ̀tì, ọmọ arákùnrin Ábúrámù, tó ń gbé ní Sódómù,+ wọ́n kó ẹrù rẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.

13 Lẹ́yìn náà, ọkùnrin kan tó sá àsálà wá sọ fún Ábúrámù tó jẹ́ Hébérù. Nígbà yẹn, ó ń gbé* láàárín àwọn igi ńlá Mámúrè ọmọ Ámórì,+ arákùnrin Éṣíkólì àti Ánérì.+ Àwọn ọkùnrin yìí máa ń ran Ábúrámù lọ́wọ́. 14 Bí Ábúrámù ṣe gbọ́ pé wọ́n ti mú mọ̀lẹ́bí*+ òun lẹ́rú, ó kó àwọn ọkùnrin tó ti kọ́ ní ogun jíjà, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìdínlógún (318) ìránṣẹ́ tí wọ́n bí sínú agbo ilé rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lé wọn títí dé Dánì.+ 15 Ní òru, ó pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀, òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ gbógun jà wọ́n, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Ó lé wọn dé Hóbà, tó wà ní àríwá Damásíkù. 16 Ó gba gbogbo ẹrù náà pa dà, ó sì tún gba Lọ́ọ̀tì mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àti àwọn ẹrù rẹ̀ pa dà pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn èèyàn míì.

17 Nígbà tí Ábúrámù ń pa dà bọ̀ lẹ́yìn tó ṣẹ́gun Kedoláómà àti àwọn ọba tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ọba Sódómù jáde lọ pàdé Ábúrámù ní Àfonífojì* Ṣáfè, ìyẹn Àfonífojì Ọba.+ 18 Melikisédékì+ ọba Sálẹ́mù+ sì gbé búrẹ́dì àti wáìnì jáde wá; òun ni àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ.+

19 Lẹ́yìn náà, ó súre fún un, ó sì sọ pé:

“Kí Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé

Bù kún Ábúrámù;

20 Ìyìn yẹ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,

Ẹni tó mú kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn tó ń ni ọ́ lára!”

Ábúrámù sì fún un ní ìdá mẹ́wàá gbogbo nǹkan.+

21 Lẹ́yìn náà, ọba Sódómù sọ fún Ábúrámù pé: “Fún mi ní àwọn èèyàn* náà, àmọ́ kí ìwọ kó àwọn ẹrù náà.” 22 Àmọ́ Ábúrámù sọ fún ọba Sódómù pé: “Mo gbé ọwọ́ mi sókè, mo sì búra sí Jèhófà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé, 23 pé mi ò ní mú ohunkóhun tó jẹ́ tìrẹ, látorí fọ́nrán òwú dórí okùn bàtà, kí o má bàa sọ pé, ‘Èmi ni mo sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀.’ 24 Mi ò ní mú ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin ti jẹ. Àmọ́ ní ti àwọn ọkùnrin tó bá mi lọ, Ánérì, Éṣíkólì àti Mámúrè,+ jẹ́ kí wọ́n mú ìpín tiwọn.”

15 Lẹ́yìn èyí, Jèhófà sọ fún Ábúrámù nínú ìran pé: “Ábúrámù, má bẹ̀rù.+ Apata ni mo jẹ́ fún ọ.+ Èrè rẹ yóò pọ̀ gan-an.”+ 2 Ábúrámù fèsì pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, kí lo máa fún mi, bí o ṣe rí i pé mi ò tíì bímọ, tó sì jẹ́ pé Élíésérì,+ ọkùnrin ará Damásíkù ni yóò jogún ilé mi?” 3 Ábúrámù fi kún un pé: “O ò fún mi ní ọmọ,*+ ará* ilé mi ló sì máa jogún ohun tí mo ní.” 4 Àmọ́, èsì tí Jèhófà fún un ni pé: “Ọkùnrin yìí ò ní jogún rẹ, ọmọ rẹ* ni yóò jogún rẹ.”+

5 Ó wá mú un wá sí ìta, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, gbójú sókè wo ọ̀run, kí o sì ka àwọn ìràwọ̀, tí o bá lè kà á.” Ó sì sọ fún un pé: “Bí ọmọ* rẹ á ṣe pọ̀ nìyẹn.”+ 6 Ábúrámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,+ Ó sì kà á sí òdodo fún un.+ 7 Ó wá fi kún un pé: “Èmi ni Jèhófà, ẹni tó mú ọ kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí kó lè di ohun ìní+ rẹ.” 8 Ó bi í pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, báwo ni màá ṣe mọ̀ pé ilẹ̀ yìí máa di ohun ìní mi?” 9 Ó fèsì pé: “Mú abo ọmọ màlúù ọlọ́dún mẹ́ta kan wá fún mi àti abo ewúrẹ́ ọlọ́dún mẹ́ta kan, àgbò ọlọ́dún mẹ́ta kan, ẹyẹ oriri kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.” 10 Ó wá kó gbogbo rẹ̀, ó gé wọn sí méjì-méjì, ó sì kọjú wọn síra,* àmọ́ kò gé àwọn ẹyẹ náà. 11 Àwọn ẹyẹ aṣọdẹ wá ń bà lé àwọn òkú ẹran náà, àmọ́ Ábúrámù ń lé wọn.

12 Nígbà tó kù díẹ̀ kí oòrùn wọ̀, Ábúrámù sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tó ń dẹ́rù bani sì ṣú bò ó. 13 Ó wá sọ fún Ábúrámù pé: “Mọ̀ dájú pé àwọn ọmọ* rẹ máa di àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, àwọn èèyàn ibẹ̀ á fi wọ́n ṣe ẹrú, wọ́n á sì fìyà jẹ wọ́n fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún.+ 14 Àmọ́ màá dá orílẹ̀-èdè tí wọn yóò sìn+ lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà, wọ́n á kó ọ̀pọ̀ ẹrù+ jáde. 15 Ní tìrẹ, wàá lọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ ní àlàáfíà; wàá dàgbà, wàá darúgbó kí o tó kú.+ 16 Àmọ́ ìran wọn kẹrin á pa dà síbí,+ torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Ámórì kò tíì kún rẹ́rẹ́.”+

17 Nígbà tí oòrùn wọ̀, tí ilẹ̀ sì ti ṣú, iná ìléru tó ń rú èéfín fara hàn, iná ògùṣọ̀ sì kọjá láàárín àwọn ẹran tó gé. 18 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà bá Ábúrámù dá májẹ̀mú+ kan pé: “Ọmọ* rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí,+ láti odò Íjíbítì dé odò ńlá náà, ìyẹn odò Yúfírétì:+ 19 ilẹ̀ àwọn Kénì,+ àwọn ọmọ Kénásì, àwọn Kádímónì, 20 àwọn ọmọ Hétì,+ àwọn Pérísì,+ àwọn Réfáímù,+ 21 àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Gẹ́gáṣì àti àwọn ará Jébúsì.”+

16 Sáráì ìyàwó Ábúrámù kò bí ọmọ kankan+ fún un, àmọ́ ó ní ìránṣẹ́ kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì, Hágárì+ ni orúkọ rẹ̀. 2 Sáráì wá sọ fún Ábúrámù pé: “Jọ̀ọ́, gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! Jèhófà ò jẹ́ kí n bímọ. Jọ̀ọ́, bá ìránṣẹ́ mi ní àṣepọ̀. Bóyá mo lè ní ọmọ nípasẹ̀ rẹ̀.”+ Ábúrámù sì fetí sí ohun tí Sáráì sọ. 3 Lẹ́yìn tí Ábúrámù ti lo ọdún mẹ́wàá ní ilẹ̀ Kénáánì, Sáráì ìyàwó Ábúrámù mú Hágárì, ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì fún Ábúrámù ọkọ rẹ̀ kó fi ṣe aya. 4 Ábúrámù wá bá Hágárì ní àṣepọ̀, ó sì lóyún. Nígbà tó rí i pé òun ti lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fojú àbùkù wo Sáráì ọ̀gá rẹ̀.

5 Torí náà, Sáráì sọ fún Ábúrámù pé: “Ìwọ lo fa ìyà tó ń jẹ mí. Èmi ni mo fa ìránṣẹ́ mi lé ọ lọ́wọ́,* àmọ́ nígbà tó rí i pé òun ti lóyún, ó wá ń fojú àbùkù wò mí. Kí Jèhófà ṣèdájọ́ èmi àti ìwọ.” 6 Ábúrámù wá sọ fún Sáráì pé: “Wò ó! O ní àṣẹ lórí ìránṣẹ́ rẹ. Ohun tí o bá rí i pé ó dáa jù ni kí o ṣe fún un.” Sáráì wá ni ín lára, ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

7 Nígbà tó yá, áńgẹ́lì Jèhófà rí i níbi ìsun omi kan nínú aginjù, ìsun omi tó wà lójú ọ̀nà Ṣúrì.+ 8 Ó sì sọ pé: “Hágárì, ìránṣẹ́ Sáráì, ibo lo ti ń bọ̀, ibo lo sì ń lọ?” Ó fèsì pé: “Mo sá kúrò lọ́dọ̀ Sáráì ọ̀gá mi ni.” 9 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún un pé: “Pa dà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ, kí o sì tẹrí ba fún un.”* 10 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ pé: “Èmi yóò mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ gan-an débi pé wọn ò ní lè kà wọ́n.”+ 11 Áńgẹ́lì Jèhófà fi kún un pé: “O ti lóyún, wàá sì bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Íṣímáẹ́lì,* torí Jèhófà ti gbọ́ nípa ìyà tó ń jẹ ọ́. 12 Ó máa dà bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó.* Ó máa bá gbogbo èèyàn jà, gbogbo èèyàn á sì bá a jà, òdìkejì gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ ni á máa gbé.”*

13 Ó wá ké pe orúkọ Jèhófà, ẹni tó ń bá a sọ̀rọ̀, ó sì sọ pé: “Ọlọ́run tó ń ríran+ ni ọ́,” torí ó sọ pé: “Ṣé kì í ṣe pé mo ti rí ẹni tó ń rí mi lóòótọ́!” 14 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe kànga náà ní Bia-laháí-róì.* (Ó wà láàárín Kádéṣì àti Bérédì.) 15 Hágárì wá bí ọmọkùnrin kan fún Ábúrámù, Ábúrámù sì pe orúkọ ọmọ tí Hágárì bí fún un ní Íṣímáẹ́lì.+ 16 Ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún (86) ni Ábúrámù nígbà tí Hágárì bí Íṣímáẹ́lì fún un.

17 Nígbà tí Ábúrámù pé ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99), Jèhófà fara han Ábúrámù, ó sì sọ fún un pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè. Máa bá mi rìn,* kí o sì fi hàn pé o jẹ́ aláìlẹ́bi.* 2 Màá fìdí májẹ̀mú mi tí mo bá ọ dá+ múlẹ̀, màá sì mú kí o di púpọ̀ gan-an.”+

3 Ni Ábúrámù bá dojú bolẹ̀, Ọlọ́run tún sọ fún un pé: 4 “Wò ó! Ní tèmi, mo ti bá ọ dá májẹ̀mú,+ ó sì dájú pé wàá di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.+ 5 O ò ní jẹ́ Ábúrámù* mọ́; orúkọ rẹ yóò di Ábúráhámù,* torí màá mú kí o di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. 6 Màá mú kí o bímọ tó pọ̀ gan-an, màá mú kí o di àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba yóò sì tinú rẹ jáde.+

7 “Màá mú májẹ̀mú mi ṣẹ, tí mo bá ìwọ+ àti ọmọ* rẹ dá jálẹ̀ gbogbo ìran wọn, pé màá jẹ́ Ọlọ́run fún ọ àti fún ọmọ* rẹ. 8 Màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ ní ilẹ̀ tí o gbé nígbà tí o jẹ́ àjèjì,+ ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Kénáánì, yóò jẹ́ ohun ìní wọn títí láé, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run+ wọn.”

9 Ọlọ́run tún sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní tìrẹ, kí o pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ jálẹ̀ àwọn ìran wọn. 10 Májẹ̀mú tí mo bá ọ dá nìyí, òun sì ni ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò máa pa mọ́: Gbogbo ọkùnrin tó wà láàárín yín gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́.*+ 11 Kí ẹ dá adọ̀dọ́ yín,* yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú tó wà láàárín èmi àti ẹ̀yin.+ 12 Jálẹ̀ àwọn ìran yín, gbogbo ọmọkùnrin tó wà láàárín yín tó jẹ́ ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́,*+ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá bí nínú ilé àti ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ* yín àmọ́ tí ẹ fi owó yín rà lọ́wọ́ àjèjì. 13 Gbogbo ọkùnrin tí wọ́n bí ní ilé rẹ àti gbogbo ọkùnrin tí o fi owó rẹ rà gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́,*+ májẹ̀mú mi tó wà nínú ẹran ara yín gbọ́dọ̀ jẹ́ májẹ̀mú ayérayé. 14 Tí ọkùnrin èyíkéyìí ò bá dá adọ̀dọ́ rẹ̀, kí wọ́n pa ẹni* náà, kí wọ́n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Ó ti da májẹ̀mú mi.”

15 Ọlọ́run wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní ti Sáráì*+ ìyàwó rẹ, má pè é ní Sáráì mọ́, torí Sérà* ni yóò máa jẹ́. 16 Èmi yóò bù kún un, màá sì mú kí ó+ bí ọmọkùnrin kan fún ọ; èmi yóò bù kún un, ó máa di àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ọba àwọn èèyàn yóò sì tinú rẹ̀ jáde.” 17 Ni Ábúráhámù bá dojú bolẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, ó sì ń sọ lọ́kàn rẹ̀+ pé: “Ṣé ọkùnrin ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún lè di bàbá ọmọ? Ṣé Sérà, obìnrin ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún sì lè bímọ?”+

18 Ábúráhámù wá sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí Íṣímáẹ́lì wà láàyè níwájú rẹ!”+ 19 Ọlọ́run fèsì pé: “Ó dájú pé Sérà ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan fún ọ, kí o sì sọ ọ́ ní Ísákì.*+ Màá sì fìdí májẹ̀mú mi tí mo bá a dá múlẹ̀, ó máa jẹ́ májẹ̀mú ayérayé fún àtọmọdọ́mọ* rẹ̀.+ 20 Ní ti ohun tó o sọ nípa Íṣímáẹ́lì, mo ti gbọ́. Wò ó! Èmi yóò bù kún un, màá mú kó bímọ, màá sì mú kí ó di púpọ̀ gan-an. Ó máa bí ìjòyè méjìlá (12), màá sì mú kí ó di orílẹ̀-èdè ńlá.+ 21 Àmọ́, èmi yóò fìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Ísákì,+ ọmọ tí Sérà máa bí fún ọ ní àkókò yìí lọ́dún tó ń bọ̀.”+

22 Nígbà tí Ọlọ́run bá a sọ̀rọ̀ tán, ó kúrò lọ́dọ̀ Ábúráhámù. 23 Ábúráhámù wá mú Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin tí wọ́n bí nínú ilé rẹ̀ àti gbogbo ẹni tó fi owó rà, gbogbo ọkùnrin inú agbo ilé Ábúráhámù, ó sì dá adọ̀dọ́ wọn* ní ọjọ́ yẹn gan-an, bí Ọlọ́run ṣe sọ fún un.+ 24 Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) ni Ábúráhámù nígbà tó dádọ̀dọ́.+ 25 Ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13) sì ni Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ nígbà tó dádọ̀dọ́.  + 26 Ní ọjọ́ yẹn gan-an, Ábúráhámù àti Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ dádọ̀dọ́. 27 Gbogbo ọkùnrin agbo ilé rẹ̀, gbogbo ẹni tí wọ́n bí nínú ilé náà àti ẹni tí wọ́n fi owó rà láti ọwọ́ àjèjì ló dádọ̀dọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

18 Lẹ́yìn náà, Jèhófà+ fara hàn án láàárín àwọn igi ńlá tó wà ní Mámúrè+ nígbà tó jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ní àkókò tí ojú ọjọ́ gbóná gan-an. 2 Ó wòkè, ó sì rí ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n dúró ní ọ̀ọ́kán.+ Nígbà tó rí wọn, ó sáré láti ẹnu ọ̀nà àgọ́ lọ pàdé wọn, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀. 3 Ó wá sọ pé: “Jèhófà, tó bá jẹ́ pé mo ti rí ojúure rẹ, jọ̀ọ́, má kọjá ìránṣẹ́ rẹ. 4 Jọ̀ọ́, jẹ́ ká bu omi díẹ̀ wá, ká lè fọ+ ẹsẹ̀ yín; kí ẹ wá jókòó lábẹ́ igi. 5 Ní báyìí tí ẹ ti wá sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ yín, ẹ jẹ́ kí n fún yín ní búrẹ́dì, kí ara lè tù yín.* Lẹ́yìn ìyẹn, ẹ lè máa lọ.” Torí náà, wọ́n sọ pé: “Ó dáa. O lè ṣe ohun tí o sọ.”

6 Ábúráhámù wá sáré lọ bá Sérà nínú àgọ́, ó sì sọ pé: “Yára! Mú òṣùwọ̀n* ìyẹ̀fun tó kúnná mẹ́ta. Pò ó, kí o sì fi ṣe búrẹ́dì.” 7 Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù sáré lọ síbi tí agbo ẹran wà, ó sì mú akọ ọmọ màlúù kan tó dára, tí ara rẹ̀ sì rọ̀. Ó fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ìránṣẹ́ náà sì yára lọ sè é. 8 Ó mú bọ́tà àti wàrà àti akọ ọmọ màlúù tó ti sè, ó sì gbé oúnjẹ náà fún wọn. Ó wá dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn lábẹ́ igi bí wọ́n ṣe ń jẹun.+

9 Wọ́n bi í pé: “Ibo ni Sérà+ ìyàwó rẹ wà?” Ó fèsì pé: “Ó wà nínú àgọ́ níbí.” 10 Torí náà, ọ̀kan nínú wọn sọ pé: “Màá pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní àkókò yìí lọ́dún tó ń bọ̀. Wò ó! Sérà ìyàwó rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin+ kan.” Àmọ́ Sérà wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ tó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà, ó ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. 11 Ábúráhámù àti Sérà ti darúgbó, wọ́n ti lọ́jọ́ lórí.+ Sérà ti dàgbà kọjá ẹni tó lè bímọ.*+ 12 Sérà wá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín sínú, ó ń sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti gbó tán, tí olúwa mi sì ti darúgbó, ṣé mo ṣì lè nírú ayọ̀ yẹn?”+ 13 Jèhófà wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Kí ló dé tí Sérà ń rẹ́rìn-ín, tó sì sọ pé, ‘Èmi tí mo ti darúgbó yìí, ṣé mo ṣì lè bímọ?’ 14 Ǹjẹ́ a rí ohun tó pọ̀ jù fún Jèhófà+ láti ṣe? Màá pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní àkókò yìí lọ́dún tó ń bọ̀, Sérà yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” 15 Àmọ́ Sérà sẹ́ nítorí ẹ̀rù bà á, ó sọ pé, “Mi ò rẹ́rìn-ín o!” Ó wá fèsì pé: “Àní o rẹ́rìn-ín!”

16 Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà dìde láti kúrò níbẹ̀, tí wọ́n sì wo apá ibi tí Sódómù+ wà, Ábúráhámù ń bá wọn lọ kó lè sìn wọ́n sọ́nà. 17 Jèhófà sọ pé: “Ṣé màá fi ohun tí mo fẹ́ ṣe+ pa mọ́ fún Ábúráhámù ni? 18 Ó dájú pé Ábúráhámù máa di orílẹ̀-èdè ńlá tó máa lágbára, gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóò rí ìbùkún gbà* nípasẹ̀ rẹ̀.+ 19 Torí mo ti wá mọ̀ ọ́n, kó lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ àti agbo ilé rẹ̀ pé kí wọ́n máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà nípa ṣíṣe ohun tó dáa, tó sì tọ́,+ kí Jèhófà bàa lè mú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ.”

20 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ pé: “Igbe àwọn tó ń ráhùn nípa Sódómù àti Gòmórà ti pọ̀ gidigidi,+ ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì wúwo gan-an.+ 21 Èmi yóò lọ wò ó bóyá ohun tí mò ń gbọ́ nípa wọn náà ni wọ́n ń ṣe. Tí kò bá sì rí bẹ́ẹ̀, màá lè mọ̀.”+

22 Àwọn ọkùnrin náà kúrò níbẹ̀, wọ́n sì forí lé ọ̀nà Sódómù, àmọ́ Jèhófà+ wà pẹ̀lú Ábúráhámù. 23 Ábúráhámù wá sún mọ́ ọn, ó sì sọ pé: “Ṣé o máa pa olódodo run pẹ̀lú ẹni burúkú+ ni? 24 Ká sọ pé àádọ́ta (50) olódodo wà nínú ìlú náà. Ṣé o ṣì máa pa wọ́n run? Ṣé o ò ní dárí ji ìlú náà nítorí àádọ́ta (50) olódodo tó wà níbẹ̀? 25 Ó dájú pé o ò ní hùwà báyìí, pé kí o pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú, tó fi jẹ́ pé ohun kan náà+ ló máa ṣẹlẹ̀ sí olódodo àti ẹni burúkú! Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.+ Ṣé Onídàájọ́ gbogbo ayé kò ní ṣe ohun tó tọ́ ni?”+ 26 Jèhófà wá sọ pé: “Tí mo bá rí àádọ́ta (50) olódodo ní ìlú Sódómù, màá dárí ji gbogbo ìlú náà nítorí wọn.” 27 Àmọ́ Ábúráhámù tún sọ pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, èmi tí mo jẹ́ erùpẹ̀ àti eérú kò lẹ́tọ̀ọ́ láti bá ọ sọ̀rọ̀. 28 Ká sọ pé àádọ́ta (50) olódodo náà dín márùn-ún, ṣé wàá pa gbogbo ìlú náà run nítorí àwọn márùn-ún náà?” Ó fèsì pé: “Mi ò ní pa á run tí mo bá rí márùndínláàádọ́ta (45)+ níbẹ̀.”

29 Àmọ́, ó tún sọ fún un pé: “Ká sọ pé ogójì (40) lo rí níbẹ̀.” Ó dáhùn pé: “Mi ò ní pa á run nítorí ogójì (40).” 30 Àmọ́ ó tún sọ pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, má bínú+ sí mi, jẹ́ kí n máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ: Ká sọ pé ọgbọ̀n (30) péré lo rí níbẹ̀.” Ó fèsì pé: “Mi ò ní pa á run tí mo bá rí ọgbọ̀n (30) níbẹ̀.” 31 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, má bínú pé mo gbójúgbóyà láti bá ọ sọ̀rọ̀: Ká sọ pé ogún (20) péré lo rí níbẹ̀.” Ó fèsì pé: “Mi ò ní pa á run nítorí ogún (20).” 32 Níkẹyìn, ó sọ pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, má bínú sí mi, jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i: Ká sọ pé olódodo mẹ́wàá péré lo rí níbẹ̀.” Ó fèsì pé: “Mi ò ní pa á run nítorí mẹ́wàá.” 33 Nígbà tí Jèhófà bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ tán, ó kúrò níbẹ̀,+ Ábúráhámù sì pa dà sí ibi tó ń gbé.

19 Àwọn áńgẹ́lì méjì náà dé Sódómù ní alẹ́, Lọ́ọ̀tì sì jókòó sí ẹnubodè Sódómù. Nígbà tí Lọ́ọ̀tì rí wọn, ó dìde lọ pàdé wọn, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀.+ 2 Ó sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ̀yin olúwa mi, ẹ jọ̀ọ́ ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín, kí ẹ sùn mọ́jú, ká sì fọ ẹsẹ̀ yín. Ẹ lè dìde ní ìdájí, kí ẹ sì máa lọ.” Wọ́n fèsì pé: “Rárá, ojúde ìlú la máa sùn mọ́jú.” 3 Àmọ́ kò fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀, títí wọ́n fi tẹ̀ lé e lọ sílé rẹ̀. Ó se àsè fún wọn, ó yan búrẹ́dì aláìwú, wọ́n sì jẹun.

4 Kí wọ́n tó dùbúlẹ̀ láti sùn, àwọn ọkùnrin ìlú náà, ìyẹn àwọn ọkùnrin Sódómù kóra jọ bíi jàǹdùkú yí ilé náà ká, gbogbo wọn látorí ọmọdé dórí àgbàlagbà. 5 Wọ́n ń pe Lọ́ọ̀tì, wọ́n sì ń sọ fún un pé: “Àwọn ọkùnrin tó wá sọ́dọ̀ rẹ ní alẹ́ yìí dà? Mú wọn jáde ká lè bá wọn lò pọ̀.”+

6 Lọ́ọ̀tì jáde lọ bá wọn ní ẹnu ọ̀nà, ó sì ti ilẹ̀kùn lẹ́yìn tó jáde. 7 Ó sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ má hùwà ìkà. 8 Ẹ jọ̀ọ́, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò tíì bá ọkùnrin lò pọ̀ rí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n mú wọn wá fún yín kí ẹ lè ṣe ohun tó wù yín sí wọn. Àmọ́ ẹ má fọwọ́ kan àwọn ọkùnrin yìí, torí abẹ́ òrùlé*+ mi ni wọ́n wá.” 9 Ni wọ́n bá sọ pé: “Kúrò lọ́nà!” Wọ́n tún sọ pé: “Ẹ wo ọkùnrin àjèjì yìí, tó wá gbé nílẹ̀ wa, ó tún láyà láti dá wa lẹ́jọ́. Wò ó, ohun tí a máa ṣe sí ọ yóò burú ju èyí tí a máa ṣe sí wọn.” Bí wọ́n ṣe ya bo* Lọ́ọ̀tì nìyẹn, wọ́n sì sún mọ́ ilẹ̀kùn kí wọ́n lè fọ́ ọ wọlé. 10 Àmọ́ àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú Lọ́ọ̀tì wọlé sọ́dọ̀ wọn, wọ́n sì ti ilẹ̀kùn. 11 Ṣùgbọ́n wọ́n bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tó wà ní ẹnu ọ̀nà ilé náà, látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù, tó fi jẹ́ pé ó rẹ̀ wọ́n bí wọ́n ṣe ń wá ibi tí ẹnu ọ̀nà wà.

12 Ni àwọn ọkùnrin náà bá sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: “Ṣé èèyàn rẹ kankan ṣì kù níbí? Mú ọkọ àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ àti gbogbo èèyàn rẹ tó bá wà nínú ìlú yìí kúrò! 13 A máa pa ìlú yìí run, torí igbe àwọn tó ń ráhùn nípa wọn ti pọ̀ gan-an* níwájú Jèhófà, ìdí nìyẹn tí Jèhófà+ fi rán wa láti pa ìlú yìí run.” 14 Lọ́ọ̀tì bá jáde lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọkùnrin tí wọ́n fẹ́ fi àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣaya sọ̀rọ̀, ó ń sọ pé: “Ẹ dìde! Ẹ jáde kúrò níbí, torí Jèhófà máa pa ìlú yìí run!” Àmọ́ àwọn ọkùnrin náà rò pé ó kàn ń ṣàwàdà+ ni.

15 Bí ilẹ̀ ṣe ń mọ́, àwọn áńgẹ́lì náà bẹ̀rẹ̀ sí í kán Lọ́ọ̀tì lójú, wọ́n ń sọ pé: “Dìde! Mú ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tó wà níbí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ má bàa pa run nígbà tí ìlú+ náà bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀!” 16 Àmọ́ nígbà tó ń lọ́ra ṣáá, àwọn ọkùnrin náà gbá ọwọ́ rẹ̀ mú àti ọwọ́ ìyàwó rẹ̀ àti ọwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, torí Jèhófà yọ́nú sí i,+ wọ́n mú un jáde, wọ́n sì mú un wá sí ìta ìlú náà.+ 17 Bí wọ́n ṣe mú wọn dé ẹ̀yìn odi, ó sọ pé: “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí* yín! Ẹ má wo ẹ̀yìn,+ ẹ má sì dúró níbikíbi ní agbègbè yìí!+ Ẹ sá lọ sí agbègbè olókè kí ẹ má bàa pa run!”

18 Torí náà, Lọ́ọ̀tì sọ fún wọn pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kí n lọ síbẹ̀ yẹn! 19 Jọ̀ọ́, ní báyìí, ìránṣẹ́ rẹ ti rí ojúure rẹ, o sì ti ṣe inúure tó pọ̀* sí mi torí o dá ẹ̀mí* mi sí,+ àmọ́ mi ò lè sá lọ sí agbègbè olókè torí ẹ̀rù ń bà mí pé àjálù lè dé bá mi, kí n sì kú.+ 20 Jọ̀ọ́, ìlú kékeré yìí wà nítòsí, mo sì lè sá lọ síbẹ̀. Jọ̀ọ́, ṣé kí n sá lọ síbẹ̀? Ìlú kékeré ni. Mi* ò sì ní kú.” 21 Ló bá sọ fún un pé: “Ó dáa, màá tún ro tìẹ,+ mi ò sì ní run ìlú tí o sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí.+ 22 Tètè sá lọ síbẹ̀! Torí mi ò lè ṣe nǹkan kan títí wàá fi dé ibẹ̀!”+ Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ ìlú náà ní Sóárì.*+

23 Oòrùn ti yọ ní ilẹ̀ náà nígbà tí Lọ́ọ̀tì dé Sóárì. 24 Jèhófà wá rọ òjò imí ọjọ́ àti iná lé Sódómù àti Gòmórà lórí, ó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, láti ọ̀run.+ 25 Ó run àwọn ìlú yìí, àní, gbogbo agbègbè náà, títí kan àwọn tó ń gbé àwọn ìlú náà àti àwọn ewéko ilẹ̀.+ 26 Àmọ́ ìyàwó Lọ́ọ̀tì tó wà lẹ́yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wo ẹ̀yìn, ó sì di ọwọ̀n* iyọ̀.+

27 Ábúráhámù jí ní àárọ̀ kùtù, ó sì lọ síbi tó ti dúró níwájú Jèhófà.+ 28 Nígbà tó wo apá ibi tí Sódómù àti Gòmórà wà àti gbogbo ilẹ̀ agbègbè náà, ó rí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó rí èéfín tó ṣú dùdù tó ń lọ sókè ní ilẹ̀ náà, ó sì dà bí èéfín tó máa ń jáde látinú iná ìléru!+ 29 Nígbà tí Ọlọ́run pa àwọn ìlú agbègbè náà run, Ọlọ́run fi Ábúráhámù sọ́kàn nítorí ó mú Lọ́ọ̀tì kúrò nínú àwọn ìlú tó pa run, àwọn ìlú tí Lọ́ọ̀tì ń gbé.+

30 Nígbà tó yá, Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì kúrò ní Sóárì, wọ́n sì lọ ń gbé ní agbègbè olókè,+ torí ẹ̀rù ń bà á láti máa gbé ní Sóárì.+ Ó wá lọ ń gbé inú ihò, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì. 31 Èyí àkọ́bí sọ fún àbúrò rẹ̀ pé: “Bàbá wa ti darúgbó, kò sì sí ọkùnrin kankan ní ilẹ̀ yìí tó máa bá wa lò pọ̀ bí ìṣe gbogbo ayé. 32 Wá, jẹ́ ká fún bàbá wa ní wáìnì mu, ká sì sùn tì í, ká lè ní ọmọ nípasẹ̀ bàbá wa.”

33 Torí náà, ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, wọ́n ń fún bàbá wọn ní wáìnì mu; èyí àkọ́bí wọlé, ó sì sùn ti bàbá rẹ̀, àmọ́ bàbá rẹ̀ kò mọ ìgbà tó sùn ti òun àti ìgbà tó dìde. 34 Ní ọjọ́ kejì, èyí àkọ́bí sọ fún àbúrò rẹ̀ pé: “Mo sùn ti bàbá mi lálẹ́ àná. Jẹ́ ká tún fún un ní wáìnì mu lálẹ́ òní. Kí o wọlé, kí o sì sùn tì í, ká lè ní ọmọ nípasẹ̀ bàbá wa.” 35 Torí náà, ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, wọ́n tún fún bàbá wọn ní wáìnì mu léraléra; èyí àbúrò wá lọ sùn tì í, àmọ́ bàbá rẹ̀ kò mọ ìgbà tó sùn ti òun àti ìgbà tó dìde. 36 Àwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì méjèèjì lóyún nípasẹ̀ bàbá wọn. 37 Èyí àkọ́bí bí ọmọkùnrin kan, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Móábù.+ Òun ló wá di bàbá àwọn ọmọ Móábù.+ 38 Èyí àbúrò náà bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-ámì. Òun ló wá di bàbá àwọn ọmọ Ámónì.+

20 Ábúráhámù wá ṣí ibùdó rẹ̀ kúrò níbẹ̀+ lọ sí ilẹ̀ Négébù, ó sì ń gbé láàárín Kádéṣì+ àti Ṣúrì.+ Nígbà tó ń gbé* ní Gérárì,+ 2 Ábúráhámù tún sọ nípa Sérà ìyàwó rẹ̀ pé: “Àbúrò mi ni.”+ Ni Ábímélékì ọba Gérárì bá ránṣẹ́ pe Sérà, ó sì mú un sọ́dọ̀.+ 3 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ábímélékì sọ̀rọ̀ lójú àlá ní òru, ó sọ fún un pé: “Wò ó, o ti kú tán torí obìnrin tí o mú yìí,+ ó ti lọ́kọ, ìyàwó oníyàwó+ sì ni.” 4 Àmọ́ Ábímélékì kò tíì sún mọ́ ọn.* Torí náà, ó sọ pé: “Jèhófà, ṣé o máa pa orílẹ̀-èdè tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀* run ni? 5 Ṣebí ọkùnrin náà sọ fún mi pé, ‘Àbúrò mi ni,’ obìnrin náà sì sọ pé, ‘Ẹ̀gbọ́n mi ni’? Òótọ́ inú ni mo fi ṣe ohun tí mo ṣe yìí, ọwọ́ mi mọ́.” 6 Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un lójú àlá pé: “Mo mọ̀ pé òótọ́ inú lo fi ṣe ohun tí o ṣe, torí ẹ̀ ni mi ò fi jẹ́ kí o dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyẹn tí mi ò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án. 7 Dá ìyàwó ọkùnrin náà pa dà, torí wòlíì+ ni, ó máa bá ọ bẹ̀bẹ̀,+ o ò sì ní kú. Àmọ́ tí o kò bá dá a pa dà, ó dájú pé wàá kú, ìwọ àti gbogbo àwọn tó jẹ́ tìrẹ.”

8 Ábímélékì jí ní àárọ̀ kùtù, ó pe gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sọ gbogbo nǹkan yìí fún wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n gan-an. 9 Ábímélékì wá pe Ábúráhámù, ó sì sọ fún un pé: “Kí lo ṣe sí wa yìí? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́, tí o fi fẹ́ fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó pọ̀ tó báyìí jẹ èmi àti àwọn èèyàn mi? Ohun tí o ṣe sí mi yìí ò dáa.” 10 Ábímélékì bi Ábúráhámù pé: “Kí lo ní lọ́kàn tó o fi ṣe báyìí?”+ 11 Ábúráhámù fèsì pé: “Èrò mi ni pé, ‘Ó dájú pé àwọn èèyàn tó wà níbí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n á sì pa mí torí ìyàwó+ mi.’ 12 Àbúrò mi ni lóòótọ́ o, bàbá kan náà ló bí wa, àmọ́ a kì í ṣọmọ ìyá kan náà, mo sì mú un ṣaya.+ 13 Torí náà, nígbà tí Ọlọ́run mú kí n kúrò ní ilé bàbá mi,+ mo sọ fún un pé: ‘Bí o ṣe máa fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ lo ní sí mi nìyí: Gbogbo ibi tí a bá lọ, máa sọ nípa mi pé, “Ẹ̀gbọ́n mi ni.”’”+

14 Ìgbà náà ni Ábímélékì mú àwọn àgùntàn àti màlúù pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó kó wọn fún Ábúráhámù, ó sì dá Sérà ìyàwó rẹ̀ pa dà fún un. 15 Ábímélékì tún sọ pé: “Ilẹ̀ mi nìyí. Ibi tó bá wù ọ́ ni kó o máa gbé níbẹ̀.” 16 Ó sì sọ fún Sérà pé: “Mo fún ẹ̀gbọ́n+ rẹ ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà. Ó jẹ́ àmì pé o ò mọwọ́ mẹsẹ̀* lójú gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ àti lójú gbogbo èèyàn, wọn ò sì ní pẹ̀gàn rẹ mọ́.” 17 Ábúráhámù bẹ̀rẹ̀ sí í rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run sì mú Ábímélékì àti ìyàwó rẹ̀ lára dá, pẹ̀lú àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀, wọ́n sì wá ń bímọ; 18 nítorí Jèhófà ti mú kí gbogbo obìnrin ilé Ábímélékì di àgàn* torí Sérà, ìyàwó+ Ábúráhámù.

21 Jèhófà rántí Sérà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, Jèhófà sì ṣe ohun tó ṣèlérí+ fún Sérà. 2 Sérà lóyún,+ ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ní àkókò tí Ọlọ́run ṣèlérí fún un.+ 3 Ábúráhámù pe orúkọ ọmọ tuntun tí Sérà bí fún un ní Ísákì.+ 4 Ábúráhámù sì dádọ̀dọ́* Ísákì ọmọ rẹ̀ nígbà tó pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ fún un.+ 5 Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ábúráhámù nígbà tó bí Ísákì ọmọ rẹ̀. 6 Sérà wá sọ pé: “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín; gbogbo ẹni tó bá gbọ́ nípa rẹ̀ á bá mi rẹ́rìn-ín.”* 7 Ó fi kún un pé: “Ta ni ì bá sọ fún Ábúráhámù pé, ‘Ó dájú pé Sérà yóò di ìyá ọlọ́mọ’? Síbẹ̀ mo bímọ fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀.”

8 Ọmọ náà wá dàgbà, wọ́n sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, Ábúráhámù sì se àsè ńlá ní ọjọ́ tí wọ́n gba ọmú lẹ́nu Ísákì. 9 Àmọ́ Sérà ń kíyè sí i pé ọmọ tí Hágárì+ ará Íjíbítì bí fún Ábúráhámù ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́.+ 10 Ó wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọkùnrin rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin yìí kò ní bá Ísákì ọmọ mi pín ogún!”+ 11 Àmọ́ ohun tó sọ nípa ọmọ yìí kò dùn mọ́ Ábúráhámù+ nínú rárá. 12 Ọlọ́run wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Má ṣe jẹ́ kí ohun tí Sérà ń sọ fún ọ nípa ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ bà ọ́ nínú jẹ́. Fetí sí ohun tó sọ,* torí látọ̀dọ̀ Ísákì+ ni ọmọ* rẹ yóò ti wá. 13 Ní ti ọmọ ẹrúbìnrin+ náà, màá mú kí òun náà di orílẹ̀-èdè kan,+ torí ọmọ* rẹ ni.”

14 Ábúráhámù wá jí ní àárọ̀ kùtù, ó mú búrẹ́dì àti ìgò omi tí wọ́n fi awọ ṣe, ó sì fún Hágárì. Ó gbé e lé èjìká rẹ̀, ó sì ní kí òun àti ọmọ+ náà máa lọ. Hágárì kúrò níbẹ̀, ó sì ń rìn kiri nínú aginjù Bíá-ṣébà.+ 15 Nígbà tó yá, omi inú ìgò awọ náà tán, ó sì gbé ọmọ náà sábẹ́ igi kan nínú igbó. 16 Lẹ́yìn náà, ó lọ dá jókòó sí ìwọ̀n ibi tí ọfà lè dé téèyàn bá ta á, torí ó sọ pé: “Mi ò fẹ́ kí ọmọ náà kú níṣojú mi.” Torí náà, ó jókòó sí ọ̀ọ́kán, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ké, ó sì ń sunkún.

17 Ọlọ́run gbọ́ igbe ọmọ+ náà, áńgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Hágárì láti ọ̀run, ó sì sọ fún un+ pé: “Ṣé kò sí o, Hágárì? Má bẹ̀rù, torí Ọlọ́run ti gbọ́ igbe ọmọ náà níbi tó wà yẹn. 18 Dìde, gbé ọmọ náà, kí o sì fi ọwọ́ rẹ dì í mú, torí màá mú kí ó di orílẹ̀-èdè ńlá.”+ 19 Ọlọ́run wá ṣí i lójú, ló bá rí kànga omi kan, ó wá lọ rọ omi kún ìgò awọ náà, ó sì fún ọmọ náà ní omi mu. 20 Ọlọ́run wà pẹ̀lú ọmọ+ náà bó ṣe ń dàgbà. Ó ń gbé inú aginjù, ó sì wá di tafàtafà. 21 Ó ń gbé inú aginjù Páránì,+ ìyá rẹ̀ sì fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Íjíbítì.

22 Nígbà yẹn, Ábímélékì àti Fíkólì olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sọ fún Ábúráhámù pé: “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo ohun tí ò ń ṣe.+ 23 Torí náà, fi Ọlọ́run búra fún mi báyìí, pé o ò ní hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí èmi àti àwọn ọmọ mi àti àtọmọdọ́mọ mi àti pé o máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí èmi àti ilẹ̀ tí ò ń gbé bí mo ṣe fi hàn sí ọ.”+ 24 Torí náà, Ábúráhámù sọ pé: “Mo búra.”

25 Àmọ́ Ábúráhámù fẹjọ́ sun Ábímélékì nípa kànga omi tí àwọn ìránṣẹ́ Ábímélékì fipá gbà.+ 26 Ábímélékì fèsì pé: “Mi ò mọ ẹni tó ṣe èyí; o ò sọ ọ́ létí mi rí, òní yìí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́.” 27 Ni Ábúráhámù bá mú àgùntàn àti màlúù, ó kó o fún Ábímélékì, àwọn méjèèjì sì jọ dá májẹ̀mú. 28 Nígbà tí Ábúráhámù ya abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje sọ́tọ̀ kúrò lára agbo ẹran, 29 Ábímélékì bi Ábúráhámù pé: “Kí nìdí tí o fi ya abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje yìí sọ́tọ̀?” 30 Ó fèsì pé: “Gba abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà lọ́wọ́ mi, kó jẹ́ ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.” 31 Ìdí nìyẹn tó fi pe ibẹ̀ ní Bíá-ṣébà,*+ torí pé àwọn méjèèjì búra níbẹ̀. 32 Torí náà, wọ́n dá májẹ̀mú+ ní Bíá-ṣébà, lẹ́yìn náà, Ábímélékì àti Fíkólì olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbéra, wọ́n sì pa dà sí ilẹ̀ àwọn Filísínì.+ 33 Lẹ́yìn náà, ó gbin igi támáríkì kan sí Bíá-ṣébà, ó sì ké pe orúkọ Jèhófà,+ Ọlọ́run ayérayé+ níbẹ̀. 34 Ábúráhámù sì ń gbé ní ilẹ̀ àwọn Filísínì,* ó pẹ́ gan-an*+ níbẹ̀.

22 Lẹ́yìn èyí, Ọlọ́run tòótọ́ dán Ábúráhámù wò,+ ó ní: “Ábúráhámù!” Ó fèsì pé: “Èmi nìyí!” 2 Ó wá sọ pé: “Jọ̀ọ́, mú ọmọ rẹ, ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi,+ ìyẹn Ísákì,+ kí o sì lọ sí ilẹ̀ Moráyà,+ kí o fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí màá fi hàn ọ́.”

3 Torí náà, Ábúráhámù jí ní àárọ̀ kùtù, ó de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀,* ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dání pẹ̀lú Ísákì ọmọ rẹ̀. Ó la igi tó fẹ́ fi dáná ẹbọ sísun náà, ó gbéra, ó sì lọ síbi tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un. 4 Ní ọjọ́ kẹta, Ábúráhámù gbójú sókè, ó sì rí ibẹ̀ ní ọ̀ọ́kán. 5 Ábúráhámù wá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ẹ dúró ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ níbí, àmọ́ èmi àti ọmọ náà máa lọ síbẹ̀ yẹn láti jọ́sìn, a ó sì pa dà wá bá yín.”

6 Ábúráhámù wá gbé igi tó fẹ́ fi dáná ẹbọ sísun náà, ó sì gbé e ru Ísákì ọmọ rẹ̀. Ó mú iná àti ọ̀bẹ* dání, àwọn méjèèjì sì jọ ń rìn lọ. 7 Ísákì wá sọ fún Ábúráhámù bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi!” Ó fèsì pé: “Èmi nìyí, ọmọ mi!” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Iná àti igi rèé, àmọ́ ibo ni àgùntàn tí a máa fi rú ẹbọ sísun wà?” 8 Ábúráhámù fèsì pé: “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa pèsè àgùntàn tí a máa fi rú ẹbọ sísun.”+ Àwọn méjèèjì sì jọ ń rìn lọ.

9 Níkẹyìn, wọ́n dé ibi tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un, Ábúráhámù wá mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì to igi sórí rẹ̀. Ó de Ísákì ọmọ rẹ̀ tọwọ́ tẹsẹ̀, ó sì gbé e sórí igi tó wà lórí pẹpẹ náà.+ 10 Ábúráhámù sì nawọ́ mú ọ̀bẹ* kó lè pa ọmọ+ rẹ̀. 11 Àmọ́ áńgẹ́lì Jèhófà pè é láti ọ̀run, ó sì sọ pé: “Ábúráhámù, Ábúráhámù!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí!” 12 Ó sì sọ pé: “Má pa ọmọ náà, má sì ṣe ohunkóhun sí i, torí mo ti wá mọ̀ báyìí pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, torí o ò kọ̀ láti fún mi+ ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní.” 13 Ni Ábúráhámù bá wòkè, ó sì rí àgbò kan ní ọ̀ọ́kán tí ìwo rẹ̀ há sínú igbó. Ábúráhámù lọ mú àgbò náà, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. 14 Ábúráhámù sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Jèhófà-jirè.* Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ ọ́ títí dòní pé: “Orí òkè Jèhófà ni a ó ti pèsè.”+

15 Áńgẹ́lì Jèhófà tún pe Ábúráhámù lẹ́ẹ̀kejì láti ọ̀run, 16 ó sọ pé: “‘Mo fi ara mi búra pé torí ohun tí o ṣe yìí,’ ni Jèhófà+ wí, ‘tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo+ tí o ní, 17 ó dájú pé màá bù kún ọ, ó sì dájú pé màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti iyanrìn etí òkun,+ ọmọ* rẹ yóò sì gba ẹnubodè* àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ lọ́wọ́ wọn. 18 Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ*+ rẹ torí pé o fetí sí ohùn+ mi.’”

19 Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù pa dà sọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n gbéra, wọ́n sì jọ pa dà sí Bíá-ṣébà;+ Ábúráhámù sì ń gbé ní Bíá-ṣébà.

20 Lẹ́yìn èyí, wọ́n ròyìn fún Ábúráhámù pé: “Mílíkà náà ti bí àwọn ọmọ fún Náhórì arákùnrin+ rẹ: 21 Úsì ni àkọ́bí rẹ̀, Búsì ni àbúrò àti Kémúélì bàbá Árámù, 22 Késédì, Hásò, Pílídáṣì, Jídíláfù àti Bẹ́túẹ́lì.”+ 23 Bẹ́túẹ́lì bí Rèbékà.+ Àwọn mẹ́jọ yìí ni Mílíkà bí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù. 24 Wáhàrì* rẹ̀ tó ń jẹ́ Réúmà náà bímọ: Tébà, Gáhámù, Táháṣì àti Máákà.

23 Ọdún mẹ́tàdínláàádóje (127) ni Sérà lò kó tó kú; gbogbo ọjọ́ ayé Sérà nìyẹn.+ 2 Sérà kú sí Kiriati-ábà,+ ìyẹn Hébúrónì,+ ní ilẹ̀ Kénáánì.+ Ábúráhámù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀, ó sì ń sunkún nítorí Sérà. 3 Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù kúrò níbi tí òkú ìyàwó rẹ̀ wà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ Hétì+ pé: 4 “Àjèjì ni mo jẹ́ nílẹ̀ yìí,+ àárín yín ni mo sì ń gbé. Ẹ fún mi níbì kan tí mo lè sìnkú sí nílẹ̀ yín, kí n lè sin òkú ìyàwó mi síbẹ̀.” 5 Àwọn ọmọ Hétì dá Ábúráhámù lóhùn pé: 6 “Gbọ́ wa, olúwa mi. Ìjòyè Ọlọ́run* lo jẹ́ láàárín wa.+ O lè sin òkú ìyàwó rẹ sí ibi tó dáa jù nínú àwọn ibi ìsìnkú wa. Ẹnikẹ́ni nínú wa ò ní sọ pé kí o má sin òkú ìyàwó rẹ síbi ìsìnkú òun.”

7 Ábúráhámù wá dìde, ó sì tẹrí ba fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, fún àwọn ọmọ Hétì,+ 8 ó sọ fún wọn pé: “Bí ẹ* bá gbà pé kí n sin òkú ìyàwó mi, ẹ fetí sí mi, kí ẹ sì rọ Éfúrónì ọmọ Sóhárì, 9 pé kó ta ihò Mákípẹ́là tó jẹ́ tiẹ̀ fún mi; ó wà ní ìkángun ilẹ̀ rẹ̀. Ẹ jẹ́ kó tà á fún mi níṣojú yín ní iye fàdákà+ tó bá jẹ́, kí n lè ní ilẹ̀ tí màá fi ṣe ibi ìsìnkú.”+

10 Éfúrónì wà láàárín àwọn ọmọ Hétì níbi tí wọ́n jókòó sí. Torí náà, Éfúrónì ọmọ Hétì dá Ábúráhámù lóhùn lójú àwọn ọmọ Hétì àti gbogbo àwọn tó gba ẹnubodè ìlú rẹ̀+ wọlé, ó ní: 11 “Rárá olúwa mi! Fetí sí mi. Mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò tó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níṣojú àwọn ọmọ àwọn èèyàn mi. Lọ sin òkú ìyàwó rẹ.” 12 Ni Ábúráhámù bá tẹrí ba níwájú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, 13 ó sì sọ fún Éfúrónì níṣojú àwọn èèyàn náà, ó ní: “Jọ̀ọ́, fetí sí mi! Màá fún ọ ní iye fàdákà tí ilẹ̀ náà bá jẹ́. Gbà á ní ọwọ́ mi, kí n lè sin òkú ìyàwó mi síbẹ̀.”

14 Éfúrónì dá Ábúráhámù lóhùn pé: 15 “Olúwa mi, fetí sí mi. Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ṣékélì* fàdákà ni ilẹ̀ yìí jẹ́, àmọ́ kí ni ìyẹn já mọ́ láàárín èmi àti ìwọ? Torí náà, lọ sin òkú ìyàwó rẹ.” 16 Ábúráhámù gbọ́ ohun tí Éfúrónì sọ, Ábúráhámù sì wọn iye fàdákà tí Éfúrónì sọ níṣojú àwọn ọmọ Hétì fún un, ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ṣékélì* fàdákà, ó lo ìwọ̀n tí àwọn oníṣòwò+ ń lò nígbà yẹn. 17 Nípa báyìí, ilẹ̀ Éfúrónì tó wà ní Mákípẹ́là níwájú Mámúrè, ilẹ̀ náà àti ihò tó wà níbẹ̀ àti gbogbo igi tó wà lórí ilẹ̀ náà wá di 18 ohun ìní Ábúráhámù, èyí tó rà níṣojú àwọn ọmọ Hétì àti gbogbo àwọn tó ń gba ẹnubodè ìlú rẹ̀ wọlé. 19 Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù sin Sérà ìyàwó rẹ̀ sínú ihò tó wà ní Mákípẹ́là níwájú Mámúrè, ìyẹn ní Hébúrónì, ní ilẹ̀ Kénáánì. 20 Nípa báyìí, àwọn ọmọ Hétì fún Ábúráhámù ní ilẹ̀ náà àti ihò tó wà níbẹ̀, ó sì di ohun ìní rẹ̀ tó fi ṣe ibi ìsìnkú.+

24 Ábúráhámù ti wá darúgbó, ó ti lọ́jọ́ lórí, Jèhófà sì ti bù kún Ábúráhámù ní gbogbo ọ̀nà.+ 2 Ábúráhámù sọ fún ìránṣẹ́ tó dàgbà jù nínú agbo ilé rẹ̀, tó sì ń bójú tó gbogbo ohun ìní+ rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́, fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, 3 mo fẹ́ kí o fi Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀run àti Ọlọ́run ayé búra, pé o ò ní fẹ́ ìyàwó fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì tí mò ń gbé+ láàárín wọn. 4 Àmọ́ kí o lọ sí ilẹ̀ tí mo ti wá, lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí+ mi, kí o sì mú ìyàwó wá fún Ísákì ọmọ mi.”

5 Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà bi í pé: “Tí obìnrin náà ò bá fẹ́ bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ńkọ́? Ṣé kí n mú ọmọ rẹ pa dà sí ilẹ̀ tí o ti wá+ ni?” 6 Ni Ábúráhámù bá fèsì pé: “O ò gbọ́dọ̀ mú ọmọ mi lọ síbẹ̀+ o. 7 Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run, ẹni tó mú mi kúrò ní ilé bàbá mi àti ilẹ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí+ mi, ẹni tó bá mi sọ̀rọ̀, tó sì búra fún mi+ pé: ‘Ọmọ*+ rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí,’+ yóò rán áńgẹ́lì rẹ̀ lọ ṣáájú rẹ,+ ó sì dájú pé wàá mú ìyàwó wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.+ 8 Àmọ́ tí obìnrin náà ò bá fẹ́ bá ọ wá, ìwọ yóò bọ́ nínú ìbúra yìí. O ò gbọ́dọ̀ mú ọmọ mi lọ síbẹ̀ o.” 9 Ìránṣẹ́ náà wá fi ọwọ́ rẹ̀ sí abẹ́ itan Ábúráhámù ọ̀gá rẹ̀, ó sì búra fún un nípa ọ̀rọ̀ yìí.+

10 Torí náà, ìránṣẹ́ náà mú mẹ́wàá lára ràkúnmí ọ̀gá rẹ̀, ó sì lọ. Ó mú oríṣiríṣi nǹkan tó dára dání látọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Ó wá forí lé Mesopotámíà, ó lọ sí ìlú Náhórì. 11 Ó mú kí àwọn ràkúnmí náà kúnlẹ̀ síbi kànga omi kan lẹ́yìn ìlú náà. Ó jẹ́ nǹkan bí ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ní àsìkò tí àwọn obìnrin máa ń lọ fa omi. 12 Ó wá sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ṣàṣeyọrí lónìí, kí o sì fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí Ábúráhámù ọ̀gá mi. 13 Ibi ìsun omi ni mo wà báyìí, àwọn ọmọbìnrin ìlú yìí sì ti ń jáde wá fa omi. 14 Jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́bìnrin tí mo bá sọ fún pé, ‘Jọ̀ọ́, sọ ìṣà omi rẹ kalẹ̀, kí n lè mu omi,’ tó sì fèsì pé, ‘Gba omi, màá sì tún fún àwọn ràkúnmí rẹ lómi,’ kí ó jẹ́ ẹni tí wàá yàn fún Ísákì ìránṣẹ́ rẹ; kí èyí sì jẹ́ kí n mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí ọ̀gá mi.”

15 Kó tó sọ̀rọ̀ tán, Rèbékà ti ń jáde bọ̀, ó sì gbé ìṣà omi rẹ̀ lé èjìká. Òun ni ọmọ Bẹ́túẹ́lì,+ ọmọ Mílíkà+ ìyàwó Náhórì,+ arákùnrin Ábúráhámù. 16 Ọmọbìnrin náà rẹwà gan-an, wúńdíá ni; ọkùnrin kankan ò bá a lò pọ̀ rí. Ó sọ̀ kalẹ̀ wá síbi ìsun omi náà, ó pọn omi kún ìṣà rẹ̀, ó sì gòkè pa dà. 17 Ni ìránṣẹ́ náà bá sáré lọ bá a, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní omi díẹ̀ mu látinú ìṣà omi rẹ.” 18 Ó fèsì pé: “Gba omi, olúwa mi.” Ló bá yára sọ ìṣà omi rẹ̀ sọ́wọ́, ó sì fún un ní omi mu. 19 Nígbà tó fún un ní omi tán, ó sọ pé: “Màá tún fa omi fún àwọn ràkúnmí rẹ títí wọ́n á fi mumi tẹ́rùn.” 20 Ló bá yára da omi tó wà nínú ìṣà rẹ̀ sínú ọpọ́n ìmumi, ó ń sáré lọ sáré bọ̀ síbi kànga náà kó lè fa omi, ó sì ń fa omi kó lè fún gbogbo àwọn ràkúnmí náà lómi. 21 Ní gbogbo àkókò yìí, ọkùnrin náà dákẹ́, ó sì ń wò ó tìyanutìyanu, ó ń wò ó bóyá Jèhófà ti mú kí ohun tí òun bá wá yọrí sí rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

22 Nígbà tí àwọn ràkúnmí náà mumi tán, ọkùnrin náà mú òrùka wúrà tí wọ́n ń fi sí imú, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìlàjì ṣékélì* àti ẹ̀gbà ọwọ́ méjì tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì* mẹ́wàá, ó sì fún obìnrin náà, 23 ó wá bi í pé: “Jọ̀ọ́ sọ fún mi, ọmọ ta ni ọ́? Ṣé yàrá kankan wà ní ilé bàbá rẹ tí a lè sùn mọ́jú?” 24 Ló bá fèsì pé: “Èmi ni ọmọbìnrin Bẹ́túẹ́lì,+ ọmọkùnrin tí Mílíkà bí fún Náhórì.”+ 25 Ó tún sọ pé: “A ní pòròpórò àti oúnjẹ ẹran tó pọ̀, a sì ní ibi tí ẹ lè sùn mọ́jú.” 26 Ọkùnrin náà wá tẹrí ba, ó wólẹ̀ síwájú Jèhófà, 27 ó nì: “Ìyìn yẹ Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, torí ó ṣì nífẹ̀ẹ́ tí kì í yẹ̀ sí ọ̀gá mi, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. Jèhófà ti darí mi wá sí ilé àwọn mọ̀lẹ́bí ọ̀gá mi.”

28 Ọmọbìnrin náà sì sáré lọ sí agbo ilé ìyá rẹ̀ láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn. 29 Rèbékà ní arákùnrin kan tó ń jẹ́ Lábánì.+ Lábánì wá sáré lọ bá ọkùnrin náà níta níbi ìsun omi. 30 Nígbà tó rí òrùka imú àti ẹ̀gbà ọwọ́ ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀, tó sì gbọ́ ohun tí Rèbékà arábìnrin rẹ̀ sọ pé, “Ohun tí ọkùnrin náà sọ fún mi nìyí,” ó wá bá ọkùnrin náà níbi tó ṣì dúró sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ràkúnmí níbi ìsun omi. 31 Ló bá sọ pé: “Máa bọ̀, ìwọ ẹni tí Jèhófà bù kún. Kí ló dé tí o fi dúró síta níbí? Mo ti ṣètò ibi tí wàá dé sí nínú ilé àti ibi tí àwọn ràkúnmí rẹ máa wà.” 32 Ọkùnrin náà bá wá sínú ilé, ó* tú ìjánu àwọn ràkúnmí, ó sì fún àwọn ràkúnmí náà ní pòròpórò àti oúnjẹ ẹran, ó tún fún ọkùnrin náà ní omi láti fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ àti ẹsẹ̀ àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ wá. 33 Àmọ́, nígbà tí wọ́n gbé oúnjẹ fún un, ó ní: “Mi ò ní jẹun títí màá fi sọ ohun tí mo fẹ́ sọ fún ọ.” Lábánì fèsì pé: “Ó yá, mò ń gbọ́!”

34 Ó wá sọ pé: “Ìránṣẹ́+ Ábúráhámù ni mí. 35 Jèhófà sì ti bù kún ọ̀gá mi gan-an, ó ti mú kó lọ́rọ̀ gidigidi torí ó fún un ní àwọn àgùntàn àti màlúù, fàdákà àti wúrà, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, àwọn ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ 36 Lẹ́yìn tí Sérà ìyàwó ọ̀gá mi darúgbó,+ ó bí ọmọkùnrin kan fún ọ̀gá mi, ọmọ yìí ni yóò sì jogún gbogbo ohun tí ọ̀gá mi ní.+ 37 Torí náà, ọ̀gá mi mú kí n búra, ó sọ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ìyàwó fún ọmọ mi láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tí mò ń gbé+ ní ilẹ̀ wọn. 38 Àmọ́ kí o lọ sí ilé bàbá mi, sí ọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí+ mi, kí o sì mú ìyàwó fún ọmọ+ mi níbẹ̀.’ 39 Àmọ́ mo bi ọ̀gá mi pé: ‘Tí obìnrin náà ò bá fẹ́ bá mi wá+ ńkọ́?’ 40 Ó sọ fún mi pé: ‘Jèhófà, ẹni tí mò ń bá rìn+ máa rán áńgẹ́lì+ rẹ̀ pé kó wà pẹ̀lú rẹ, á mú kí ìrìn àjò rẹ yọrí sí rere, kí o sì mú ìyàwó fún ọmọ mi látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí mi, ní ilé bàbá+ mi. 41 Ìwọ yóò bọ́ nínú ìbúra tí o ṣe fún mi, tí o bá lọ sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí mi àmọ́ tí wọn ò fún ọ ní obìnrin náà. Ìyẹn ló máa mú kí o bọ́ nínú ìbúra+ tí o ṣe.’

42 “Nígbà tí mo dé ibi ìsun omi lónìí, mo sọ pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, tí o bá mú kí ohun tí mo bá wá yọrí sí rere, 43 níbi ìsun omi tí mo dúró sí yìí, jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ pé tí ọmọbìnrin+ kan bá wá fa omi, màá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní omi díẹ̀ mu látinú ìṣà omi rẹ,” 44 kí ó fèsì pé: “Gba omi, màá sì tún fa omi fún àwọn ràkúnmí rẹ.” Kí obìnrin yẹn jẹ́ ẹni tí Jèhófà yàn fún ọmọ ọ̀gá+ mi.’

45 “Kí n tó gbàdúrà tán nínú ọkàn mi, Rèbékà ti ń jáde bọ̀, ó gbé ìṣà omi rẹ̀ lé èjìká, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ síbi ìsun omi náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fa omi. Mo wá sọ fún un pé: ‘Jọ̀ọ́,+ fún mi lómi mu.’ 46 Ló bá yára sọ ìṣà omi rẹ̀ kúrò ní èjìká, ó sì sọ pé: ‘Gba omi,+ màá sì tún fún àwọn ràkúnmí rẹ lómi.’ Ni mo bá mu omi, ó sì fún àwọn ràkúnmí náà lómi. 47 Lẹ́yìn náà, mo bi í pé, ‘Ọmọ ta ni ọ́?’ Ó fèsì pé, ‘Èmi ni ọmọbìnrin Bẹ́túẹ́lì, ọmọkùnrin tí Mílíkà bí fún Náhórì.’ Mo bá fi òrùka náà sí imú rẹ̀, mo sì fi àwọn ẹ̀gbà ọwọ́ náà sí ọwọ́ rẹ̀.+ 48 Mo wá tẹrí ba, mo wólẹ̀ síwájú Jèhófà, mo sì yin Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù,+ ẹni tó darí mi sí ọ̀nà tó tọ́, kí n lè mú ọmọ mọ̀lẹ́bí ọ̀gá mi lọ fún Ísákì ọmọ rẹ̀. 49 Tí ẹ bá máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ọ̀gá mi, tí ẹ sì fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí i, ẹ sọ fún mi; àmọ́ tí ẹ ò bá ní ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sọ fún mi, kí n lè mọ ibi tí màá yà sí.”*+

50 Lábánì àti Bẹ́túẹ́lì fèsì pé: “Jèhófà ló mú kí èyí ṣẹlẹ̀. A ò lè sọ fún ọ pé bẹ́ẹ̀ ni àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.* 51 Rèbékà ló wà níwájú rẹ yìí. Mú un, kí o máa lọ, kó sì di ìyàwó ọmọ ọ̀gá rẹ, bí Jèhófà ṣe sọ.” 52 Nígbà tí ìránṣẹ́ Ábúráhámù gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ojú ẹsẹ̀ ló tẹrí ba mọ́lẹ̀ níwájú Jèhófà. 53 Ìránṣẹ́ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn nǹkan tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe àti aṣọ, ó kó wọn fún Rèbékà, ó sì fún arákùnrin rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ ní àwọn nǹkan iyebíye. 54 Lẹ́yìn náà, òun àti àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹun, wọ́n mu, wọ́n sì sun ibẹ̀ mọ́jú.

Nígbà tó jí ní àárọ̀, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí n máa lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá mi.” 55 Arákùnrin obìnrin náà àti ìyá rẹ̀ sọ pé: “Jẹ́ kí ọmọbìnrin náà ṣì wà lọ́dọ̀ wa fún ọjọ́ mẹ́wàá, ó kéré tán. Lẹ́yìn náà, ó lè máa lọ.” 56 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe dá mi dúró, torí ó hàn pé Jèhófà ti mú kí ohun tí mo bá wá yọrí sí rere. Ẹ jẹ́ kí n máa lọ, kí n lè lọ bá ọ̀gá mi.” 57 Wọ́n wá sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká pe ọmọbìnrin náà, ká sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” 58 Wọ́n pe Rèbékà, wọ́n sì bi í pé: “Ṣé wàá bá ọkùnrin yìí lọ?” Ó fèsì pé: “Màá bá a lọ.”

59 Torí náà, wọ́n jẹ́ kí Rèbékà+ arábìnrin wọn àti olùtọ́jú*+ rẹ̀ tẹ̀ lé ìránṣẹ́ Ábúráhámù àti àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ wá. 60 Wọ́n súre fún Rèbékà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Arábìnrin wa, wàá di ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún,* àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò sì gba ẹnubodè* àwọn tó kórìíra wọn lọ́wọ́ wọn.”+ 61 Rèbékà àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ wá dìde, wọ́n gun ràkúnmí, wọ́n sì tẹ̀ lé ọkùnrin náà. Bí ìránṣẹ́ náà ṣe mú Rèbékà nìyẹn, ó sì mú un lọ.

62 Ísákì ti dé láti agbègbè Bia-laháí-róì,+ torí ilẹ̀ Négébù+ ló ń gbé. 63 Ísákì sì ń rìn nínú pápá lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ kó lè ṣe àṣàrò.+ Nígbà tó gbójú sókè, ó rí àwọn ràkúnmí tó ń bọ̀! 64 Nígbà tí Rèbékà gbójú sókè, ó rí Ísákì, ó sì yára sọ̀ kalẹ̀ látorí ràkúnmí. 65 Ó wá bi ìránṣẹ́ náà pé: “Ta ni ọkùnrin yẹn tó ń rìn bọ̀ wá pàdé wa látinú pápá?” Ìránṣẹ́ náà fèsì pé: “Ọ̀gá mi ni.” Rèbékà wá mú ìborùn rẹ̀, ó sì fi bo ara rẹ̀. 66 Ìránṣẹ́ náà sì sọ gbogbo ohun tí òun ṣe fún Ísákì. 67 Lẹ́yìn náà, Ísákì mú Rèbékà wá sínú àgọ́ Sérà ìyá rẹ̀.+ Ó fi Rèbékà ṣe aya; ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀+ gan-an, Ísákì sì rí ìtùnú lẹ́yìn tí ìyá+ rẹ̀ kú.

25 Ábúráhámù fẹ́ ìyàwó míì, Kétúrà ni orúkọ rẹ̀. 2 Nígbà tó yá, ó bí Símíránì, Jókíṣánì, Médánì, Mídíánì,+ Íṣíbákì àti Ṣúáhì.+

3 Jókíṣánì bí Ṣébà àti Dédánì.

Àwọn ọmọ Dédánì ni Áṣúrímù, Létúṣímù àti Léúmímù.

4 Àwọn ọmọ Mídíánì ni Eéfà, Éférì, Hánókù, Ábíídà àti Élídáà.

Ọmọ Kétúrà ni gbogbo wọn.

5 Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù fún Ísákì  + ní gbogbo ohun tó ní, 6 àmọ́ Ábúráhámù fún àwọn ọmọ tí àwọn wáhàrì* rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn. Nígbà tó ṣì wà láàyè, ó ní kí wọ́n máa lọ sí apá ìlà oòrùn kúrò lọ́dọ̀ Ísákì ọmọ+ rẹ̀, sí ilẹ̀ Ìlà Oòrùn. 7 Ọjọ́ ayé Ábúráhámù jẹ́ ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án (175). 8 Ábúráhámù mí èémí ìkẹyìn, ó sì kú, ó darúgbó, ayé rẹ̀ sì dára, wọ́n wá kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.* 9 Ísákì àti Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ sin ín sí ihò Mákípẹ́là lórí ilẹ̀ Éfúrónì ọmọ Sóhárì, ọmọ Hétì, tó wà níwájú Mámúrè,+ 10 ilẹ̀ tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hétì. Ibẹ̀ ni wọ́n sin Ábúráhámù sí, pẹ̀lú Sérà+ ìyàwó rẹ̀. 11 Lẹ́yìn tí Ábúráhámù kú, Ọlọ́run ṣì ń bù kún Ísákì+ ọmọ rẹ̀, Ísákì sì ń gbé nítòsí Bia-laháí-róì.+

12 Ìtàn Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Ábúráhámù nìyí, ẹni tí Hágárì+ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Sérà bí fún Ábúráhámù.

13 Orúkọ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì nìyí, orúkọ wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé tí wọ́n ti wá: Àkọ́bí Íṣímáẹ́lì ni Nébáótì,+ lẹ́yìn náà ó bí Kídárì,+ Ádíbéélì, Míbúsámù,+ 14 Míṣímà, Dúmà, Máásà, 15 Hádádì, Témà, Jétúrì, Náfíṣì àti Kédémà. 16 Àwọn yìí ni ọmọ Íṣímáẹ́lì, orúkọ wọn sì nìyí, gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ń gbé àti ibùdó* wọn, wọ́n jẹ́ ìjòyè méjìlá (12) ní àwọn agbo ilé+ wọn. 17 Ọjọ́ ayé Íṣímáẹ́lì jẹ́ ọdún mẹ́tàdínlógóje (137). Ó mí èémí ìkẹyìn, ó sì kú, wọ́n kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.* 18 Wọ́n tẹ̀ dó sí Háfílà+ nítòsí Ṣúrì,+ tó sún mọ́ Íjíbítì, títí lọ dé Ásíríà. Wọ́n sì ń gbé nítòsí gbogbo àwọn arákùnrin+ wọn.*

19 Ìtàn Ísákì ọmọ Ábúráhámù+ nìyí.

Ábúráhámù bí Ísákì. 20 Ẹni ogójì (40) ọdún ni Ísákì nígbà tó fẹ́ Rèbékà, ọmọ Bẹ́túẹ́lì+ ará Arémíà ní ilẹ̀ Padani-árámù, òun ni arábìnrin Lábánì ará Arémíà. 21 Ísákì sì ń bẹ Jèhófà nítorí ìyàwó rẹ̀, torí pé ó yàgàn; Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, Rèbékà ìyàwó rẹ̀ sì lóyún. 22 Àwọn ọmọ inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn+ jà, débi tó fi sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé bó ṣe máa ń rí nìyí, ǹjẹ́ kò ní sàn kí n kú?” Torí náà, ó wádìí lọ́wọ́ Jèhófà. 23 Jèhófà sì sọ fún un pé: “Orílẹ̀-èdè méjì ló wà nínú ikùn+ rẹ, èèyàn méjì tó yàtọ̀ síra máa tinú rẹ+ jáde; orílẹ̀-èdè kan máa lágbára ju ìkejì+ lọ, ẹ̀gbọ́n sì máa sin àbúrò.”+

24 Nígbà tí àsìkò tó máa bímọ tó, wò ó! ìbejì ló wà ní inú rẹ̀. 25 Èyí àkọ́kọ́ sì jáde, ó pupa látòkè délẹ̀, ó dà bí aṣọ onírun,+ torí náà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísọ̀.*+ 26 Lẹ́yìn náà, àbúrò rẹ̀ jáde, ó sì di gìgísẹ̀ Ísọ̀+ mú, torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jékọ́bù.*+ Ẹni ọgọ́ta (60) ọdún ni Ísákì nígbà tí Rèbékà bí àwọn ọmọ náà.

27 Bí àwọn ọmọ náà ṣe ń dàgbà, Ísọ̀ di ọdẹ+ tó já fáfá, inú igbó ló sábà máa ń lọ, àmọ́ Jékọ́bù jẹ́ aláìlẹ́bi, inú àgọ́+ ló máa ń wà. 28 Ísákì nífẹ̀ẹ́ Ísọ̀ torí ó máa ń fún un ní ẹran ìgbẹ́ jẹ, àmọ́ Rèbékà nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù.+ 29 Lọ́jọ́ kan, Jékọ́bù ń se ọbẹ̀ nígbà tí Ísọ̀ dé láti oko ọdẹ, ó sì ti rẹ̀ ẹ́ gan-an. 30 Torí náà Ísọ̀ sọ fún Jékọ́bù pé: “Jọ̀ọ́, sáré fún mi lára* ọbẹ̀ pupa tí ò ń sè yẹn,* torí ó ti rẹ̀ mí!”* Ìdí nìyẹn tí orúkọ rẹ̀ fi ń jẹ́ Édómù.*+ 31 Jékọ́bù wá fèsì pé: “Kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí+ fún mi!” 32 Ísọ̀ dá a lóhùn pé: “Èmi tí mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú! Kí ni ogún ìbí fẹ́ dà fún mi?” 33 Jékọ́bù sọ pé: “Kọ́kọ́ búra fún mi!” Ló bá búra fún un, ó sì ta ogún ìbí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún Jékọ́bù.+ 34 Jékọ́bù wá fún Ísọ̀ ní búrẹ́dì àti ọbẹ̀ ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, ó jẹ, ó sì mu. Ó dìde, ó sì ń lọ. Bí Ísọ̀ ṣe fi hàn pé òun ò mọyì ogún ìbí rẹ̀ nìyẹn.

26 Ìyàn mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ sí ìyàn tó kọ́kọ́ mú nígbà ayé Ábúráhámù.+ Ísákì lọ sọ́dọ̀ Ábímélékì ọba àwọn Filísínì, ní Gérárì. 2 Jèhófà sì fara hàn án, ó sọ pé: “Má lọ sí Íjíbítì. Máa gbé ní ilẹ̀ tí mo fún ọ. 3 Máa gbé ilẹ̀+ yìí bí àjèjì, màá wà pẹ̀lú rẹ, màá sì bù kún ọ torí pé ìwọ àti ọmọ* rẹ ni màá fún ní gbogbo ilẹ̀+ yìí, màá sì ṣe ohun tí mo búra fún Ábúráhámù+ bàbá rẹ pé: 4 ‘Màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,+ màá sì fún ọmọ* rẹ ní gbogbo ilẹ̀+ yìí; gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóò sì gba ìbùkún fún ara wọn+ nípasẹ̀ ọmọ* rẹ,’ 5 torí pé Ábúráhámù fetí sí ohùn mi, ó ń ṣe ohun tí mo fẹ́, ó ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà mi àti àwọn òfin mi.”+ 6 Ísákì sì ń gbé ní Gérárì.+

7 Tí àwọn ọkùnrin ibẹ̀ bá ń béèrè nípa ìyàwó rẹ̀, ó máa ń sọ pé: “Àbúrò+ mi ni.” Ẹ̀rù ń bà á láti sọ pé “Ìyàwó mi ni,” nítorí ó sọ pé, “Àwọn ọkùnrin ibẹ̀ lè pa mí torí Rèbékà,” torí ó rẹwà gan-an.+ 8 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, Ábímélékì ọba àwọn Filísínì ń wo ìta látojú fèrèsé,* ó sì rí Ísákì tó ń bá Rèbékà ìyàwó rẹ̀ tage.*+ 9 Ni Ábímélékì bá pe Ísákì, ó sì sọ pé: “Ìyàwó rẹ ni obìnrin yìí! Kí nìdí tó o fi sọ pé, ‘Àbúrò mi ni’?” Ísákì wá fèsì pé: “Ẹ̀rù ló bà mí, kí n má bàa kú torí rẹ̀+ ni mo ṣe sọ bẹ́ẹ̀.” 10 Àmọ́ Ábímélékì sọ pé: “Kí lo ṣe sí wa yìí?+ Ọ̀kan nínú àwọn èèyàn yìí ì bá ti bá ìyàwó rẹ sùn, o ò bá sì ti mú ká jẹ̀bi!”+ 11 Ábímélékì wá sọ fún gbogbo èèyàn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí àti ìyàwó rẹ̀, ó dájú pé ó máa kú!”

12 Ísákì bẹ̀rẹ̀ sí í dá oko ní ilẹ̀ náà. Lọ́dún yẹn, ó kórè ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) ohun tó gbìn, torí Jèhófà ń bù kún un.+ 13 Ọkùnrin náà wá ní ọrọ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì ń ròkè sí i títí ọrọ̀ rẹ̀ fi pọ̀ gan-an. 14 Ó ní àwọn agbo àgùntàn, ọ̀wọ́ màlúù àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìránṣẹ́,+ àmọ́ àwọn Filísínì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara rẹ̀.

15 Torí náà, àwọn Filísínì rọ iyẹ̀pẹ̀ dí gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù+ bàbá rẹ̀ gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀. 16 Ábímélékì wá sọ fún Ísákì pé: “Kúrò ní ìlú wa, torí o ti lágbára gan-an jù wá lọ.” 17 Ísákì ṣí kúrò níbẹ̀, ó lọ pàgọ́ sí àfonífojì Gérárì,+ ó sì ń gbé ibẹ̀. 18 Ísákì tún àwọn kànga náà gbẹ́, ìyẹn àwọn kànga tí wọ́n gbẹ́ nígbà ayé Ábúráhámù bàbá rẹ̀ àmọ́ tí àwọn Filísínì dí pa lẹ́yìn ikú+ Ábúráhámù, ó sì pè wọ́n ní orúkọ tí bàbá rẹ̀ sọ wọ́n.+

19 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Ísákì ń gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n rí omi tó mọ́ níbẹ̀. 20 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn Gérárì wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ísákì jà, wọ́n ń sọ pé: “Omi wa ni!” Torí náà, ó pe orúkọ kànga náà ní Ésékì,* torí wọ́n bá a jà. 21 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ kànga míì, wọ́n sì tún bá wọn jà nítorí rẹ̀. Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sítínà.* 22 Nígbà tó yá, ó kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga míì, àmọ́ wọn ò bá a jà torí rẹ̀. Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Réhóbótì,* ó sì sọ pé: “Ó jẹ́ torí pé Jèhófà ti fún wa ní àyè tó fẹ̀, ó sì ti mú ká bímọ tó pọ̀ ní ilẹ̀ yìí.”+

23 Lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Bíá-ṣébà.+ 24 Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Jèhófà fara hàn án ní òru, ó sì sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù+ bàbá rẹ. Má bẹ̀rù,+ torí mo wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò bù kún ọ, màá sì mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ torí Ábúráhámù ìránṣẹ́+ mi.” 25 Torí náà, ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì ké pe orúkọ Jèhófà.+ Ísákì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀,+ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan síbẹ̀.

26 Lẹ́yìn náà, Ábímélékì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Gérárì pẹ̀lú Áhúsátì agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ àti Fíkólì olórí àwọn ọmọ ogun+ rẹ̀. 27 Ni Ísákì bá sọ fún wọn pé: “Kí nìdí tí ẹ fi wá sọ́dọ̀ mi, ṣebí ẹ kórìíra mi, ẹ sì lé mi kúrò ní ìlú yín?” 28 Wọ́n fèsì pé: “Ó ti hàn kedere sí wa pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.+ Torí rẹ̀ la ṣe sọ pé, ‘Jọ̀ọ́, jẹ́ ká jọ búra, ká sì bá ọ+ dá májẹ̀mú 29 pé o ò ní ṣe ohun búburú kankan sí wa bí a ò ṣe ṣèkà sí ọ, bí o ṣe rí i pé kìkì ohun tó dáa la ṣe sí ọ torí a ní kí o máa lọ ní àlàáfíà. Jèhófà ti bù kún ọ.’” 30 Lẹ́yìn náà, ó se àsè fún wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu. 31 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n tètè jí, wọ́n sì jọ+ búra. Lẹ́yìn ìyẹn, Ísákì ní kí wọ́n máa lọ, wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní àlàáfíà.

32 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ìránṣẹ́ Ísákì wá ròyìn fún un nípa kànga tí wọ́n gbẹ́,+ wọ́n sì sọ fún un pé: “A ti kan omi!” 33 Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣíbà. Ìdí nìyẹn tí orúkọ ìlú náà fi ń jẹ́ Bíá-ṣébà+ títí dòní.

34 Nígbà tí Ísọ̀ pé ẹni ogójì (40) ọdún, ó fi Júdítì ọmọ Béérì, ọmọ Hétì ṣe aya àti Básémátì ọmọ Ẹ́lónì, ọmọ Hétì.+ 35 Wọ́n ba Ísákì àti Rèbékà+ nínú jẹ́* gidigidi.

27 Nígbà tí Ísákì darúgbó, tí ojú rẹ̀ ò sì ríran dáadáa mọ́, ó pe Ísọ̀+ ọmọ rẹ̀ àgbà, ó sì sọ fún un pé: “Ọmọ mi!” Ísọ̀ fèsì pé: “Èmi nìyí!” 2 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mo ti darúgbó báyìí. Mi ò mọ ọjọ́ tí màá kú. 3 Torí náà, ní báyìí, jọ̀ọ́ lọ mú àwọn nǹkan tí o fi ń ṣọdẹ, mú apó rẹ àti ọfà* rẹ, kí o lọ sínú igbó, kí o sì pa ẹran ìgbẹ́ wá fún mi.+ 4 Kí o wá se oúnjẹ tó dùn, irú èyí tí mo fẹ́ràn, kí o gbé e wá fún mi, kí n sì jẹ ẹ́, kí n* lè súre fún ọ kí n tó kú.”

5 Àmọ́ Rèbékà ń gbọ́ ohun tí Ísákì ń bá Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ sọ. Ísọ̀ sì lọ sínú igbó kó lè pa ẹran ìgbẹ́ wálé.+ 6 Rèbékà sọ fún Jékọ́bù ọmọ+ rẹ̀ pé: “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tí bàbá rẹ ń sọ fún Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ pé, 7 ‘Lọ pa ẹran ìgbẹ́ wá fún mi, kí o se oúnjẹ tó dùn, kí n sì jẹ ẹ́, kí n lè súre fún ọ níwájú Jèhófà kí n tó kú.’+ 8 Ọmọ mi, fetí sílẹ̀ dáadáa, kí o sì ṣe ohun tí mo fẹ́ sọ fún ọ.+ 9 Jọ̀ọ́, lọ síbi tí agbo ẹran wà, kí o sì mú méjì nínú àwọn ọmọ ewúrẹ́ tó dáa jù wá fún mi, kí n lè fi wọ́n se oúnjẹ tó dùn fún bàbá rẹ, bó ṣe máa ń fẹ́ kó rí. 10 Kí o wá gbé e lọ fún bàbá rẹ kó jẹ ẹ́, kó lè súre fún ọ kó tó kú.”

11 Jékọ́bù sọ fún Rèbékà ìyá rẹ̀ pé: “Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi nírun lára,+ àmọ́ èmi ò nírun lára. 12 Tí bàbá mi bá fọwọ́ kàn mí lára+ ńkọ́? Ó dájú pé yóò mọ̀ pé ṣe ni mo tan òun, màá wá mú ègún wá sórí ara mi dípò ìbùkún.” 13 Ni ìyá rẹ̀ bá sọ fún un pé: “Ọmọ mi, kí ègún tó yẹ kó wá sórí rẹ kọjá sórí mi. Ṣáà lọ ṣe ohun tí mo sọ fún ọ, lọ bá mi mú wọn wá.”+ 14 Torí náà, ó lọ mú wọn wá fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì se oúnjẹ tó dùn bí bàbá rẹ̀ ṣe máa ń fẹ́ kó rí. 15 Lẹ́yìn náà, Rèbékà mú aṣọ tó dáa jù tó jẹ́ ti Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà, èyí tó ní nínú ilé, ó sì wọ̀ ọ́ fún Jékọ́bù+ ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ àbúrò. 16 Ó tún fi awọ àwọn ọmọ ewúrẹ́ náà bo ọwọ́ rẹ̀ àti ibi tí kò nírun ní ọrùn+ rẹ̀. 17 Ó wá gbé oúnjẹ aládùn náà àti búrẹ́dì tó ṣe lé Jékọ́bù+ ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.

18 Ló bá wọlé lọ bá bàbá rẹ̀, ó sì sọ pé: “Bàbá mi!” Ó fèsì pé: “Èmi nìyí! Ọmọ mi, ìwọ ta ni?” 19 Jékọ́bù sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Èmi ni Ísọ̀ àkọ́bí+ rẹ. Mo ti ṣe ohun tí o ní kí n ṣe. Jọ̀ọ́, dìde jókòó, kí o sì jẹ lára ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí o* lè súre fún mi.”+ 20 Ni Ísákì bá bi ọmọ rẹ̀ pé: “Báwo lo ṣe tètè rí i pa, ọmọ mi?” Ó fèsì pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló jẹ́ kí n tètè rí i pa.” 21 Ísákì sọ fún Jékọ́bù pé: “Ọmọ mi, jọ̀ọ́ sún mọ́ mi kí n lè fọwọ́ kan ara rẹ, kí n lè mọ̀ bóyá ìwọ ni Ísọ̀ ọmọ mi lóòótọ́ tàbí ìwọ kọ́.”+ 22 Torí náà, Jékọ́bù sún mọ́ Ísákì bàbá rẹ̀, ó fọwọ́ kàn án lára, ó sì sọ pé: “Ohùn Jékọ́bù ni ohùn yìí, àmọ́ ọwọ́ yìí, ti Ísọ̀+ ni.” 23 Kò dá a mọ̀, torí ọwọ́ rẹ̀ nírun bí ọwọ́ Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Torí náà, ó súre fún un.+

24 Lẹ́yìn náà, ó bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ísọ̀ ọmọ mi lóòótọ́?” Ó fèsì pé: “Èmi ni.” 25 Ó wá sọ pé: “Ọmọ mi, mú lára ẹran ìgbẹ́ tí o pa wá, kí n lè jẹ ẹ́, kí n* sì súre fún ọ.” Torí náà, ó gbé e wá fún un, ó sì jẹ ẹ́, ó tún gbé wáìnì wá fún un, ó sì mu ún. 26 Lẹ́yìn náà, Ísákì bàbá rẹ̀ sọ fún un pé: “Ọmọ mi, jọ̀ọ́ sún mọ́ mi, kó o sì fi ẹnu kò mí lẹ́nu.”+ 27 Ó sún mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó ń gbọ́ òórùn aṣọ+ tó wọ̀. Ó sì súre fún un, ó ní:

“Wò ó, òórùn ọmọ mi dà bí òórùn pápá tí Jèhófà bù kún. 28 Kí Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ìrì sẹ̀ fún ọ láti ọ̀run,+ kó fún ọ ní àwọn ilẹ̀ tó lọ́ràá ní ayé,+ kó sì fún ọ ní ọkà tó pọ̀ àti wáìnì tuntun.+ 29 Kí àwọn èèyàn máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹrí ba fún ọ. Kí o di ọ̀gá lórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn ọmọ ìyá rẹ sì máa tẹrí ba fún ọ.+ Kí ègún wà lórí ẹnikẹ́ni tó bá gégùn-ún fún ọ, kí ìbùkún sì wà lórí ẹnikẹ́ni tó bá ń súre fún ọ.”+

30 Bí Ísákì ṣe súre fún Jékọ́bù tán, tí Jékọ́bù sì kúrò lọ́dọ̀ Ísákì bàbá rẹ̀ ni Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ dé láti oko ọdẹ.+ 31 Òun náà se oúnjẹ tó dùn, ó gbé e wá fún bàbá rẹ̀, ó sì sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, dìde, kí o sì jẹ lára ẹran ìgbẹ́ tí ọmọ rẹ pa, kí o* lè súre fún mi.” 32 Ni Ísákì bàbá rẹ̀ bá bi í pé: “Ìwọ ta ni?” Ó fèsì pé: “Èmi ọmọ rẹ ni, Ísọ̀+ àkọ́bí rẹ.” 33 Ísákì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ó sì bi í pé: “Ta ló wá pa ẹran ìgbẹ́, tó sì gbé e wá fún mi? Mo ti jẹ ẹ́ kí o tó dé, mo sì ti súre fún ẹni náà. Ó sì dájú pé yóò rí ìbùkún gbà!”

34 Nígbà tí Ísọ̀ gbọ́ ohun tí bàbá rẹ̀ sọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe tantan torí ohun tó ṣẹlẹ̀ dùn ún wọra, ó sì sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá+ mi, súre fún mi, àní kí o súre fún èmi náà!” 35 Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Àbúrò rẹ ti wá fi ẹ̀tàn gba ìbùkún tó yẹ kí o gbà.” 36 Ló bá fèsì pé: “Abájọ tí orúkọ rẹ̀ fi ń jẹ́ Jékọ́bù,* ẹ̀ẹ̀mejì+ ló ti gba ipò mi báyìí! Ó ti kọ́kọ́ gba ogún ìbí mi,+ ó tún gba ìbùkún+ tó jẹ́ tèmi!” Ó wá sọ pé: “Ṣé o ò ṣẹ́ ìbùkún kankan kù fún mi ni?” 37 Àmọ́ Ísákì dá Ísọ̀ lóhùn pé: “Mo ti fi ṣe olórí rẹ,+ mo ti fi gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, mo sì ti fi ọkà àti wáìnì tuntun bù kún un.+ Kí ló wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?”

38 Ísọ̀ sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, ṣé ìbùkún kan ṣoṣo lo ní ni? Súre fún mi, bàbá mi, àní kí o súre fún èmi náà!” Ni Ísọ̀ bá ké, ó sì bú sẹ́kún.+ 39 Ísákì bàbá rẹ̀ wá sọ fún un pé:

“Wò ó, ibi tó jìnnà sí àwọn ilẹ̀ tó lọ́ràá ní ayé àti ibi tó jìnnà sí ìrì tó ń sẹ̀ láti ọ̀run ni wàá máa gbé.+ 40 Idà rẹ ni yóò máa mú ọ wà láàyè,+ àbúrò+ rẹ sì ni ìwọ yóò máa sìn. Àmọ́ tí o kò bá lè fara dà á mọ́, ó dájú pé wàá ṣẹ́ àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.”+

41 Ṣùgbọ́n Ísọ̀ di Jékọ́bù sínú torí pé bàbá rẹ̀ ti súre fún un,+ Ísọ̀ sì ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Ọjọ́ tí a máa ṣọ̀fọ̀ bàbá mi ti ń sún mọ́lé.+ Lẹ́yìn náà, ṣe ni màá pa Jékọ́bù àbúrò mi.” 42 Nígbà tí wọ́n sọ fún Rèbékà ohun tí Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà sọ, ojú ẹsẹ̀ ló ránṣẹ́ pe Jékọ́bù ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ àbúrò, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó! Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ ń wá bó ṣe máa pa ọ́ kó lè gbẹ̀san.* 43 Torí náà, ọmọ mi, ṣe ohun tí mo bá sọ fún ọ. Gbéra, kí o sì sá lọ sọ́dọ̀ Lábánì arákùnrin mi ní Háránì.+ 44 Kí o lọ gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ fúngbà díẹ̀ títí inú ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀, 45 títí inú tó ń bí ẹ̀gbọ́n rẹ sí ọ á fi rọlẹ̀, tí á sì gbàgbé ohun tí o ṣe sí i. Màá wá ránṣẹ́ sí ọ pé kí o pa dà wá láti ibẹ̀. Kò yẹ kí ẹ̀yin méjèèjì kú mọ́ mi lọ́wọ́ lọ́jọ́ kan náà!”

46 Lẹ́yìn ìyẹn, Rèbékà ń tẹnu mọ́ ọn fún Ísákì pé: “Àwọn ọmọbìnrin Hétì+ ti fayé sú mi. Bí Jékọ́bù bá lọ fẹ́ ìyàwó nínú àwọn ọmọ Hétì, irú àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ yìí, kí làǹfààní pé mo wà láàyè?”+

28 Torí náà, Ísákì pe Jékọ́bù, ó súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé: “O ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì!+ 2 Lọ sí Padani-árámù, ní ilé Bẹ́túẹ́lì bàbá ìyá rẹ, kí o sì fẹ́ ìyàwó níbẹ̀ láàárín àwọn ọmọbìnrin Lábánì,+ arákùnrin ìyá rẹ. 3 Ọlọ́run Olódùmarè yóò bù kún ọ, yóò mú kí o bímọ tó pọ̀, yóò mú kí o pọ̀ gan-an, ó sì dájú pé ìwọ yóò di àwùjọ àwọn èèyàn.+ 4 Yóò bù kún ọ bó ṣe ṣèlérí fún Ábúráhámù,+ ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ, kí ilẹ̀ tí ò ń gbé bí àjèjì, tí Ọlọ́run ti fún Ábúráhámù+ lè di ohun ìní rẹ.”

5 Ísákì wá ní kí Jékọ́bù máa lọ, ó sì forí lé Padani-árámù, ó lọ sọ́dọ̀ Lábánì ọmọ Bẹ́túẹ́lì ará Arémíà,+ arákùnrin Rèbékà  + tó jẹ́ ìyá Jékọ́bù àti Ísọ̀.

6 Ísọ̀ mọ̀ pé Ísákì ti súre fún Jékọ́bù, ó sì ti ní kó lọ sí Padani-árámù, kó lọ fẹ́ ìyàwó níbẹ̀, ó mọ̀ pé nígbà tó súre fún un, ó pàṣẹ fún un pé: “Má lọ fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì,”+ 7 ó sì mọ̀ pé Jékọ́bù ṣe ohun tí bàbá àti ìyá rẹ̀ sọ, ó forí lé Padani-árámù.+ 8 Ìgbà yẹn ni Ísọ̀ wá rí i pé inú Ísákì+ bàbá òun ò dùn sí àwọn ọmọ Kénáánì, 9 torí náà, Ísọ̀ lọ sọ́dọ̀ Íṣímáẹ́lì ọmọ Ábúráhámù, ó sì fẹ́ Máhálátì ọmọ Íṣímáẹ́lì tó jẹ́ arábìnrin Nébáótì. Ó fẹ́ ẹ kún àwọn ìyàwó tó ti ní.+

10 Jékọ́bù kúrò ní Bíá-ṣébà, ó sì ń lọ sí agbègbè Háránì.+ 11 Nígbà tó yá, ó dé ibì kan, ó sì fẹ́ sun ibẹ̀ mọ́jú torí oòrùn ti wọ̀. Torí náà, ó gbé ọ̀kan lára àwọn òkúta tó wà níbẹ̀, ó gbé e sílẹ̀ kó lè gbórí lé e, ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.+ 12 Ó wá lá àlá, sì wò ó! àtẹ̀gùn* kan wà ní ayé, òkè rẹ̀ sì kan ọ̀run; àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ lórí rẹ̀.+ 13 Wò ó! Jèhófà wà lókè rẹ̀, ó sì sọ pé:

“Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run Ábúráhámù bàbá rẹ àti Ọlọ́run Ísákì.+ Ìwọ àti àtọmọdọ́mọ*+ rẹ ni màá fún ní ilẹ̀ tí o dùbúlẹ̀ sí yìí. 14 Ó dájú pé àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,+ ìwọ yóò sì tàn káàkiri dé ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn, dé àríwá àti gúúsù, ó sì dájú pé gbogbo ìdílé ayé yóò rí ìbùkún gbà*+ nípasẹ̀ ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ. 15 Mo wà pẹ̀lú rẹ, màá dáàbò bò ọ́ ní gbogbo ibi tí o bá lọ, màá sì mú ọ pa dà sí ilẹ̀ yìí.+ Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí màá fi ṣe ohun tí mo ṣèlérí fún ọ.”+

16 Jékọ́bù jí lójú oorun, ó sì sọ pé: “Jèhófà wà níbí lóòótọ́, mi ò sì mọ̀.” 17 Ẹ̀rù wá ń bà á, ó sì sọ pé: “Ibí yìí mà ń bani lẹ́rù o! Ó ní láti jẹ́ pé ilé Ọlọ́run+ ni ibí, ẹnubodè ọ̀run+ sì nìyí.” 18 Jékọ́bù wá jí ní àárọ̀ kùtù, ó sì gbé òkúta tó gbórí lé, ó gbé e dúró bí òpó, ó sì da òróró sórí rẹ̀.+ 19 Ó wá pe orúkọ ibẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì,* àmọ́ Lúsì+ ni ìlú náà ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.

20 Jékọ́bù sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan pé: “Tí Ọlọ́run ò bá fi mí sílẹ̀, tó dáàbò bò mí lẹ́nu ìrìn àjò mi, tó sì fún mi ní oúnjẹ tí màá jẹ àti aṣọ tí màá wọ̀, 21 tí mo sì pa dà sí ilé bàbá mi ní àlàáfíà, á jẹ́ pé Jèhófà ti fi hàn dájú pé òun ni Ọlọ́run mi. 22 Òkúta tí mo gbé kalẹ̀ bí òpó yìí yóò di ilé Ọlọ́run,+ ó sì dájú pé màá fún ọ ní ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí o fún mi.”

29 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó sì forí lé ilẹ̀ àwọn ará Ìlà Oòrùn. 2 Ó wá rí kànga kan nínú pápá, ó sì rí agbo àgùntàn mẹ́ta tí wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, torí wọ́n máa ń fún àwọn agbo ẹran lómi látinú kànga yẹn. Òkúta ńlá kan wà ní ẹnu kànga náà. 3 Nígbà tí gbogbo agbo ẹran náà ti kóra jọ síbẹ̀, wọ́n yí òkúta náà kúrò ní ẹnu kànga náà, wọ́n fún àwọn agbo ẹran náà lómi, wọ́n sì dá òkúta pa dà síbi tó wà, ní ẹnu kànga náà.

4 Jékọ́bù bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin èèyàn mi, ibo lẹ ti wá?” Wọ́n fèsì pé: “Háránì+ la ti wá.” 5 Ó bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ mọ Lábánì+ ọmọ ọmọ Náhórì?”+ Wọ́n fèsì pé: “A mọ̀ ọ́n.” 6 Ló bá bi wọ́n pé: “Ṣé àlàáfíà ló wà?” Wọ́n fèsì pé: “Àlàáfíà ni. Réṣẹ́lì+ ọmọ rẹ̀ náà ló ń da àgùntàn bọ̀ yìí!” 7 Ló bá sọ pé: “Ọ̀sán ṣẹ̀ṣẹ̀ pọ́n ni. Kò tíì tó àkókò láti kó agbo ẹran jọ. Ẹ fún àwọn àgùntàn lómi, kí ẹ sì lọ fún wọn ní oúnjẹ.” 8 Wọ́n fèsì pé: “Wọn ò gbà wá láyè ká ṣe bẹ́ẹ̀, ó dìgbà tí a bá kó gbogbo agbo ẹran jọ, tí wọ́n sì yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga náà. Lẹ́yìn ìyẹn, a lè fún àwọn àgùntàn lómi.”

9 Bó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Réṣẹ́lì kó àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀ dé, torí darandaran ni Réṣẹ́lì. 10 Nígbà tí Jékọ́bù rí Réṣẹ́lì ọmọ Lábánì, arákùnrin ìyá rẹ̀ àti àwọn àgùntàn Lábánì, Jékọ́bù sún mọ́ ibi kànga náà lójú ẹsẹ̀, ó yí òkúta kúrò ní ẹnu rẹ̀, ó sì fún àwọn àgùntàn Lábánì arákùnrin ìyá rẹ̀ lómi. 11 Jékọ́bù wá fi ẹnu ko Réṣẹ́lì lẹ́nu, ó ké, ó sì bú sẹ́kún. 12 Jékọ́bù sì sọ fún Réṣẹ́lì pé mọ̀lẹ́bí* bàbá rẹ̀ ni òun àti pé òun ni ọmọ Rèbékà. Réṣẹ́lì bá sáré lọ sọ fún bàbá rẹ̀.

13 Gbàrà tí Lábánì+ gbọ́ ìròyìn nípa Jékọ́bù ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó sáré lọ pàdé rẹ̀. Ó gbá a mọ́ra, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì mú un wá sínú ilé rẹ̀. Jékọ́bù wá ń ròyìn gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ fún Lábánì. 14 Lábánì sọ fún un pé: “Ó dájú pé egungun mi àti ẹran ara mi ni ọ́.”* Torí náà, ó dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ fún oṣù kan gbáko.

15 Lábánì wá sọ fún Jékọ́bù pé: “Ṣé wàá máa bá mi ṣiṣẹ́ láìgba nǹkan kan torí o jẹ́ mọ̀lẹ́bí*+ mi ni? Sọ fún mi, kí lo fẹ́ kí n fún ọ?”+ 16 Lábánì ní ọmọbìnrin méjì. Ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Líà, àbúrò sì ń jẹ́ Réṣẹ́lì.+ 17 Ojú Líà kò fani mọ́ra, àmọ́ Réṣẹ́lì wuni, ó sì rẹwà gan-an. 18 Jékọ́bù wá nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì gidigidi, ó sì sọ pé: “Mo ṣe tán láti sìn ọ́ fún ọdún méje torí Réṣẹ́lì+ ọmọ rẹ tó jẹ́ àbúrò Líà.” 19 Lábánì fèsì pé: “Ó tẹ́ mi lọ́rùn kí n fún ọ ju kí n fún ọkùnrin míì. Máa gbé lọ́dọ̀ mi.” 20 Jékọ́bù wá fi ọdún méje ṣiṣẹ́ fún Lábánì nítorí Réṣẹ́lì,+ àmọ́ bí ọjọ́ díẹ̀ ló rí lójú rẹ̀ torí ìfẹ́ tó ní fún Réṣẹ́lì.

21 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù sọ fún Lábánì pé: “Fún mi ní ìyàwó mi torí ọjọ́ mi ti pé, kí o sì jẹ́ kí n bá a ní àṣepọ̀.” 22 Ni Lábánì bá kó gbogbo èèyàn ibẹ̀ jọ, ó sì se àsè. 23 Àmọ́ ní alẹ́, Líà ló mú lọ fún un, kó lè bá a ní àṣepọ̀. 24 Lábánì tún fún Líà ọmọ rẹ̀ ní Sílípà ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, kó lè jẹ́ ìránṣẹ́+ Líà. 25 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jékọ́bù rí i pé Líà ni! Torí náà, ó sọ fún Lábánì pé: “Kí lo ṣe fún mi yìí? Ṣebí torí Réṣẹ́lì ni mo ṣe sìn ọ́? Kí ló dé tí o fi tàn mí jẹ?”+ 26 Lábánì fèsì pé: “Kì í ṣe àṣà wa níbí pé kí àbúrò lọ ilé ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n. 27 Ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú obìnrin yìí fún ọ̀sẹ̀ kan. Lẹ́yìn náà, màá fún ọ ní obìnrin kejì yìí tí o bá sìn mí fún ọdún méje sí i.”+ 28 Jékọ́bù ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà fún ọ̀sẹ̀ kan. Lẹ́yìn náà, Lábánì fún un ní Réṣẹ́lì ọmọ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya. 29 Lábánì tún fún Réṣẹ́lì ọmọ rẹ̀ ní Bílíhà,+ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ kó lè di ìránṣẹ́+ Réṣẹ́lì.

30 Jékọ́bù wá bá Réṣẹ́lì pẹ̀lú ní àṣepọ̀, ó nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì ju Líà lọ, ó sì fi ọdún méje+ míì ṣiṣẹ́ fún Lábánì. 31 Nígbà tí Jèhófà rí i pé Jékọ́bù kò fẹ́ràn* Líà, ó jẹ́ kí Líà lóyún,*+ àmọ́ Réṣẹ́lì yàgàn.+ 32 Líà wá lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Rúbẹ́nì.*+ Ó sọ pé: “Ìdí ni pé Jèhófà ti rí ìyà+ tó ń jẹ mí, ọkọ mi á wá nífẹ̀ẹ́ mi báyìí.” 33 Ó tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Ìdí ni pé Jèhófà ti fetí sílẹ̀, ó rí i pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ mi, torí náà, ó tún fún mi ní èyí.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Síméónì.*+ 34 Ó tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, ọkọ mi yóò fà mọ́ mi, torí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Léfì.*+ 35 Ó tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, màá yin Jèhófà.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Júdà.*+ Lẹ́yìn ìyẹn, kò bímọ mọ́.

30 Nígbà tí Réṣẹ́lì rí i pé òun ò bí ọmọ kankan fún Jékọ́bù, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó sì ń sọ fún Jékọ́bù pé: “Fún mi ní ọmọ, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, màá kú.” 2 Ni inú bá bí Jékọ́bù sí Réṣẹ́lì, ó sì sọ pé: “Ṣé èmi ni Ọlọ́run tí kò fún ẹ lọ́mọ ni?”* 3 Torí náà, Réṣẹ́lì sọ pé: “Bílíhà+ ẹrúbìnrin mi nìyí. Bá a ní àṣepọ̀ kó lè bímọ fún mi,* kí èmi náà lè ní ọmọ nípasẹ̀ rẹ̀.” 4 Ló bá fún Jékọ́bù ní Bílíhà ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya, Jékọ́bù sì bá a ní àṣepọ̀.+ 5 Bílíhà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jékọ́bù. 6 Réṣẹ́lì wá sọ pé: “Ọlọ́run ti ṣe onídàájọ́ mi, ó sì ti gbọ́ ohùn mi, ó wá fún mi ní ọmọkùnrin kan.” Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì.*+ 7 Bílíhà, ìránṣẹ́ Réṣẹ́lì tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, nígbà tó yá, ó bí ọmọkùnrin kejì fún Jékọ́bù. 8 Réṣẹ́lì wá sọ pé: “Ìjàkadì gidi ni mo bá ẹ̀gbọ́n mi jà. Mo sì ti borí!” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Náfútálì.*+

9 Nígbà tí Líà rí i pé òun ò bímọ mọ́, ó mú Sílípà ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fún Jékọ́bù pé kó fi ṣe aya.+ 10 Sílípà ìránṣẹ́ Líà sì bí ọmọkùnrin kan fún Jékọ́bù. 11 Líà wá sọ pé: “Ire wọlé dé!” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gádì.*+ 12 Lẹ́yìn náà, Sílípà ìránṣẹ́ Líà bí ọmọkùnrin kejì fún Jékọ́bù. 13 Líà sì sọ pé: “Ayọ̀ mi kún! Ó dájú pé àwọn ọmọbìnrin máa pè mí ní aláyọ̀.”+ Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Áṣérì.*+

14 Nígbà ìkórè àlìkámà,* Rúbẹ́nì+ ń rìn nínú oko, ó sì rí máńdírékì. Ó mú un wá fún Líà ìyá rẹ̀. Réṣẹ́lì wá sọ fún Líà pé: “Jọ̀ọ́, fún mi lára àwọn máńdírékì tí ọmọ rẹ mú wá.” 15 Ló bá sọ fún un pé: “Ṣé ohun kékeré lo rò pé o ṣe nígbà tó o gba ọkọ mi?+ Ṣé o tún fẹ́ gba máńdírékì ọmọ mi ni?” Ni Réṣẹ́lì bá sọ pé: “Kò burú. Màá jẹ́ kó sùn tì ọ́ lálẹ́ òní tí o bá fún mi ní máńdírékì ọmọ rẹ.”

16 Nígbà tí Jékọ́bù ń bọ̀ láti oko ní ìrọ̀lẹ́, Líà lọ pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Èmi lo máa bá ní àṣepọ̀, torí mo ti fi àwọn máńdírékì ọmọ mi gbà ọ́ pátápátá.” Ó wá sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ yẹn. 17 Ọlọ́run fetí sí Líà, ó sì dá a lóhùn, ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin karùn-ún fún Jékọ́bù. 18 Líà sì sọ pé: “Ọlọ́run ti pín mi lérè,* torí mo ti fún ọkọ mi ní ìránṣẹ́ mi.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákà.*+ 19 Líà tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jékọ́bù.+ 20 Líà wá sọ pé: “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn, àní ó fún mi ní ẹ̀bùn tó dára. Ní báyìí, ọkọ mi yóò fàyè gbà mí,+ torí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́fà+ fún un.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sébúlúnì.*+ 21 Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọbìnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dínà.+

22 Níkẹyìn, Ọlọ́run rántí Réṣẹ́lì, Ọlọ́run fetí sí i, ó sì dá a lóhùn torí ó jẹ́ kó lóyún.*+ 23 Ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó wá sọ pé: “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn+ mi kúrò!” 24 Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jósẹ́fù,*+ ó sì sọ pé: “Jèhófà ti fún mi ní ọmọkùnrin míì.”

25 Lẹ́yìn tí Réṣẹ́lì bí Jósẹ́fù, Jékọ́bù sọ fún Lábánì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Jẹ́ kí n máa lọ, kí n lè pa dà síbi tí mo ti wá àti sí ilẹ̀+ mi. 26 Fún mi ní àwọn ìyàwó mi àti àwọn ọmọ mi, àwọn tí mo torí wọn sìn ọ́, kí n lè máa lọ, torí o mọ bí mo ṣe sìn ọ́ tó.”+ 27 Lábánì wá sọ fún un pé: “Tí mo bá ti rí ojúure rẹ, mo ti rí àmì tó fi hàn pé* torí rẹ ni Jèhófà ṣe ń bù kún mi.” 28 Ó tún sọ pé: “Sọ iye tí o fẹ́ gbà fún mi, màá sì fún ọ.”+ 29 Jékọ́bù fèsì pé: “O mọ bí mo ṣe sìn ọ́, o sì mọ bí mo ṣe tọ́jú agbo ẹran rẹ;+ 30 díẹ̀ lo ní kí n tó dé, àmọ́ agbo ẹran rẹ ti wá pọ̀ sí i, ó ti di púpọ̀ rẹpẹtẹ, Jèhófà sì ti bù kún ọ látìgbà tí mo ti dé. Ìgbà wo ni mo wá fẹ́ ṣe ohun tó máa jẹ́ ti agbo ilé mi?”+

31 Ó wá bi í pé: “Kí ni kí n fún ọ?” Jékọ́bù fèsì pé: “Má ṣe fún mi ní nǹkan kan rárá! Àmọ́ tí o bá máa ṣe ohun kan ṣoṣo yìí fún mi, màá pa dà máa bójú tó agbo àgùntàn rẹ, màá sì máa ṣọ́ wọn.+ 32 Màá gba àárín gbogbo agbo ẹran rẹ kọjá lónìí. Kí o ya gbogbo àgùntàn aláwọ̀ tó-tò-tó àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ sọ́tọ̀ àti gbogbo àgùntàn tí àwọ̀ rẹ̀ pọ́n rẹ́súrẹ́sú* láàárín àwọn ọmọ àgbò. Kí o sì ya èyíkéyìí tó bá ní oríṣiríṣi àwọ̀ àti àwọ̀ tó-tò-tó sọ́tọ̀ láàárín àwọn abo ewúrẹ́. Láti ìsinsìnyí lọ, àwọn yẹn ló máa jẹ́ èrè mi.+ 33 Kí òdodo* tí mò ń ṣe jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní ọjọ́ tí o bá wá wo àwọn tó jẹ́ èrè mi; tí o bá rí èyí tí kì í ṣe aláwọ̀ tó-tò-tó tí kò sì ní oríṣiríṣi àwọ̀ láàárín àwọn abo ewúrẹ́ àti èyí tí àwọ̀ rẹ̀ kò pọ́n rẹ́súrẹ́sú láàárín àwọn ọmọ àgbò lọ́dọ̀ mi, á jẹ́ pé mo jí i ni.”

34 Ni Lábánì bá fèsì pé: “Mo fara mọ́ ọn! Jẹ́ kó rí bí o ṣe sọ.”+ 35 Ní ọjọ́ yẹn, ó ya àwọn òbúkọ abilà àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ sọ́tọ̀ àti gbogbo abo ewúrẹ́ aláwọ̀ tó-tò-tó àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀. Ó ya gbogbo èyí tó ní funfun lára àtàwọn tí àwọ̀ wọn pọ́n rẹ́súrẹ́sú sọ́tọ̀ láàárín àwọn ọmọ àgbò, ó sì ní kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa bójú tó wọn. 36 Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi àyè tó fẹ̀ tó ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta sí àárín òun àti Jékọ́bù, Jékọ́bù sì ń bójú tó èyí tó ṣẹ́ kù nínú agbo ẹran Lábánì.

37 Jékọ́bù wá fi igi tórásì, álímọ́ńdì àti igi adánra* tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gé ṣe ọ̀pá, ó bó àwọn ibì kan lára àwọn ọ̀pá náà sí funfun. 38 Ó wá kó àwọn ọ̀pá tó ti bó náà síwájú agbo ẹran, sínú àwọn kòtò omi, sínú àwọn ọpọ́n ìmumi, níbi tí àwọn agbo ẹran ti wá ń mumi, kí wọ́n lè gùn níwájú àwọn ọ̀pá náà tí wọ́n bá wá mumi.

39 Torí náà, àwọn ẹran náà máa ń gùn níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì ń bí àwọn ọmọ tó nílà lára, aláwọ̀ tó-tò-tó àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀. 40 Jékọ́bù wá ya àwọn ọmọ àgbò sọ́tọ̀, ó sì mú kí àwọn agbo ẹran náà kọjú sí àwọn tó jẹ́ abilà àti gbogbo àwọn tí àwọ̀ wọn pọ́n rẹ́súrẹ́sú lára àwọn ẹran Lábánì. Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn ẹran tirẹ̀ sọ́tọ̀, kò sì kó wọn mọ́ ti Lábánì. 41 Nígbàkigbà tí àwọn ẹran tó sanra bá fẹ́ gùn, Jékọ́bù máa ń kó àwọn ọ̀pá náà sínú kòtò omi níwájú àwọn agbo ẹran náà, kí wọ́n lè gùn níwájú àwọn ọ̀pá náà. 42 Àmọ́ tí àwọn ẹran náà ò bá lókun, kò ní kó àwọn ọ̀pá náà síbẹ̀. Torí náà, àwọn tí kò lókun yẹn ló máa ń di ti Lábánì, àmọ́ àwọn tó sanra á di ti Jékọ́bù.+

43 Ohun ìní rẹ̀ wá ń pọ̀ sí i, ó ní agbo ẹran tó pọ̀ rẹpẹtẹ, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, ó sì tún ní àwọn ràkúnmí àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+

31 Nígbà tó yá, ó gbọ́ ohun tí àwọn ọmọ Lábánì ń sọ pé: “Jékọ́bù ti gba gbogbo ohun tí bàbá wa ní, ó sì ti kó gbogbo ọrọ̀+ yìí jọ látinú àwọn ohun tí bàbá wa ní.” 2 Tí Jékọ́bù bá wo ojú Lábánì, ó ń rí i pé ìwà rẹ̀ sí òun ti yí pa dà.+ 3 Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún Jékọ́bù pé: “Pa dà sí ilẹ̀ àwọn bàbá rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí+ rẹ, mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.” 4 Jékọ́bù wá ránṣẹ́ pe Réṣẹ́lì àti Líà pé kí wọ́n wá sínú pápá níbi tí agbo ẹran rẹ̀ wà, 5 ó sì sọ fún wọn pé:

“Mo rí i pé bàbá yín ti yíwà pa dà sí mi,+ àmọ́ Ọlọ́run bàbá mi ò fi mí sílẹ̀.+ 6 Ó dájú pé ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé gbogbo okun+ mi ni mo fi sin bàbá yín. 7 Bàbá yín sì ti fẹ́ rẹ́ mi jẹ, ìgbà mẹ́wàá ló ti yí ohun tó yẹ kó jẹ́ èrè mi pa dà; àmọ́ Ọlọ́run ò jẹ́ kó pa mí lára. 8 Tó bá sọ pé, ‘Àwọn aláwọ̀ tó-tò-tó ló máa jẹ́ èrè rẹ,’ ìgbà yẹn ni gbogbo ẹran á bí aláwọ̀ tó-tò-tó; àmọ́ tó bá sọ pé, ‘Àwọn abilà ló máa jẹ́ èrè rẹ,’ ìgbà yẹn ni gbogbo ẹran á bí abilà.+ 9 Ọlọ́run wá ń gba ẹran ọ̀sìn bàbá yín kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ń mú kó di tèmi. 10 Nígbà kan tí àwọn ẹran fẹ́ gùn, mo lá àlá, mo wòkè, mo sì rí i pé àwọn òbúkọ abilà, aláwọ̀ tó-tò-tó àti àwọn tó lámì lára+ ń gun àwọn ẹran náà. 11 Áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ pè mí lójú àlá, ó ní, ‘Jékọ́bù!’ mo sì fèsì pé, ‘Èmi nìyí.’ 12 Ó wá sọ pé, ‘Jọ̀ọ́ wòkè, wàá sì rí i pé gbogbo àwọn òbúkọ abilà, aláwọ̀ tó-tò-tó àti àwọn tó lámì lára ló ń gun àwọn ẹran náà, torí mo ti rí gbogbo ohun tí Lábánì ń ṣe sí ọ.+ 13 Èmi ni Ọlọ́run tòótọ́ tó bá ọ sọ̀rọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì,+ níbi tí o ti da òróró sórí òpó tí o gbé sílẹ̀, tí o sì ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún mi.+ Wá gbéra báyìí, kí o kúrò ní ilẹ̀ yìí, kí o sì pa dà sí ilẹ̀ tí wọ́n ti bí ọ.’”+

14 Ni Réṣẹ́lì àti Líà bá fèsì pé: “Ṣé ìpín kankan ṣì ṣẹ́ kù ní ilé bàbá wa tí a lè jogún ni? 15 Ṣebí àjèjì ló kà wá sí? Ó kúkú ti tà wá, ó sì ń ná gbogbo owó tó gbà lórí wa.+ 16 Àwa àtàwọn ọmọ+ wa la ni gbogbo ọrọ̀ tí Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ bàbá wa. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run ní kí o ṣe.”+

17 Jékọ́bù wá dìde, ó sì gbé àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ sórí àwọn ràkúnmí,+ 18 ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da agbo ẹran rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ti ní,+ àwọn ẹran ọ̀sìn tó wá di tirẹ̀ ní Padani-árámù, ó dà wọ́n lọ sọ́dọ̀ Ísákì bàbá rẹ̀ ní ilẹ̀ Kénáánì.+

19 Nígbà tí Lábánì lọ rẹ́ irun àwọn àgùntàn rẹ̀, Réṣẹ́lì jí àwọn ère tẹ́ráfímù*+ tó jẹ́ ti bàbá+ rẹ̀. 20 Àmọ́, Jékọ́bù lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ fún Lábánì ará Arémíà, torí kò sọ fún un pé òun fẹ́ sá lọ. 21 Ó sá lọ, ó sì sọdá Odò,*+ òun àti gbogbo ohun tó ní. Ó wá forí lé agbègbè olókè Gílíádì.+ 22 Ní ọjọ́ kẹta, Lábánì gbọ́ pé Jékọ́bù ti sá lọ. 23 Ló bá mú àwọn arákùnrin* rẹ̀ dání, wọ́n sì ń lé e, lẹ́yìn tí wọ́n rin ìrìn àjò ọjọ́ méje, wọ́n lé e bá ní agbègbè olókè Gílíádì. 24 Ọlọ́run bá Lábánì ará Arémíà+ sọ̀rọ̀ lójú àlá ní òru,+ ó sọ fún un pé: “Ṣọ́ ohun tí o máa sọ fún Jékọ́bù, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú.”*+

25 Lábánì lọ bá Jékọ́bù lẹ́yìn tí Jékọ́bù ti pa àgọ́ rẹ̀ sórí òkè, tí Lábánì àtàwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú sì ti pàgọ́ sí agbègbè olókè Gílíádì. 26 Lábánì bi Jékọ́bù pé: “Kí lo ṣe yìí? Kí nìdí tí o fi lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ fún mi, tí o wá kó àwọn ọmọ mi lọ bí ẹrú tí wọ́n fi idà mú? 27 Kí ló dé tí o fi sá lọ láìjẹ́ kí n mọ̀, tí o lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ fún mi, tó ò sì sọ fún mi? Ká ní o sọ fún mi ni, ṣebí tayọ̀tayọ̀ ni ǹ bá fi sìn ọ́ sọ́nà, pẹ̀lú orin, ìlù tanboríìnì àti háàpù? 28 Àmọ́ o ò jẹ́ kí n fi ẹnu ko àwọn ọmọ mi àtàwọn ọmọ ọmọ* mi lẹ́nu. Ìwà òmùgọ̀ lo hù yìí. 29 Mo lágbára láti fìyà jẹ ọ́, àmọ́ Ọlọ́run bàbá rẹ bá mi sọ̀rọ̀ lóru àná pé, ‘Ṣọ́ ohun tí o máa sọ fún Jékọ́bù, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú.’+ 30 O ti kúrò báyìí torí ó ń wù ọ́ pé kí o pa dà sí ilé bàbá rẹ, àmọ́ kí ló dé tí o jí àwọn ọlọ́run+ mi kó?”

31 Jékọ́bù dá Lábánì lóhùn pé: “Ẹ̀rù ló bà mí, torí mò ń sọ lọ́kàn ara mi pé, ‘O lè fipá gba àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ mi.’ 32 Ẹnikẹ́ni tí o bá rí àwọn ọlọ́run rẹ lọ́wọ́ rẹ̀ yóò kú. Wo inú àwọn ẹrù mi níṣojú àwọn arákùnrin wa, kí o sì mú ohun tó bá jẹ́ tìrẹ.” Àmọ́ Jékọ́bù ò mọ̀ pé Réṣẹ́lì ló jí i. 33 Torí náà, Lábánì wọnú àgọ́ Jékọ́bù, ó sì wọnú àgọ́ Líà àti àgọ́ àwọn ẹrúbìnrin+ méjèèjì, àmọ́ kò rí i. Ó wá jáde nínú àgọ́ Líà, ó sì wọnú àgọ́ Réṣẹ́lì. 34 Àmọ́ Réṣẹ́lì ti kó àwọn ère tẹ́ráfímù náà sínú apẹ̀rẹ̀ tí àwọn obìnrin máa ń gbé sórí ràkúnmí, ó sì jókòó lé wọn. Lábánì wá gbogbo inú àgọ́ náà, àmọ́ kò rí àwọn ère náà. 35 Réṣẹ́lì sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Má ṣe bínú olúwa mi, mi ò lè dìde níwájú rẹ, torí mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.”*+ Ó sì fara balẹ̀ wá a, àmọ́ kò rí àwọn ère tẹ́ráfímù náà.+

36 Inú wá bí Jékọ́bù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ sí Lábánì. Ó sọ fún Lábánì pé: “Kí ni mo ṣe fún ọ, kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ mi, tí o fi ń lé mi kiri lójú méjèèjì? 37 Ní báyìí tí o ti wo inú gbogbo ẹrù mi, kí lo rí tó jẹ́ ti ilé rẹ? Kó o síbí, níwájú àwọn arákùnrin mi àtàwọn arákùnrin rẹ, kí wọ́n sì ṣèdájọ́ láàárín àwa méjèèjì. 38 Ní gbogbo ogún (20) ọdún tí mo fi wà pẹ̀lú rẹ, oyún ò bà jẹ́+ lára àwọn àgùntàn rẹ àtàwọn ewúrẹ́ rẹ, mi ò sì jẹ nínú àwọn àgbò rẹ rí. 39 Mi ò mú ẹran èyíkéyìí tí ẹranko+ ti fà ya wá fún ọ. Èmi ni mò ń forí fá àdánù rẹ̀. Ì báà jẹ́ ọ̀sán tàbí òru ni wọ́n jí ẹran, o máa ń sọ pé kí n dí i pa dà fún ọ. 40 Oòrùn máa ń pa mí lọ́sàn-án, òtútù máa ń mú mi lóru, oorun sì máa ń dá lójú mi.+ 41 Ó ti pé ogún (20) ọdún báyìí tí mo ti wà nílé rẹ. Mo fi ọdún mẹ́rìnlá (14) sìn ọ́ torí àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì, mo sì fi ọdún mẹ́fà sìn ọ́ torí agbo ẹran rẹ, ìgbà mẹ́wàá+ lo yí ohun tó yẹ kó jẹ́ èrè mi pa dà. 42 Ká ní Ọlọ́run bàbá mi,+ Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ẹni tí Ísákì ń bẹ̀rù*+ kò tì mí lẹ́yìn ni, ọwọ́ òfo lò bá ní kí n kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ọlọ́run ti rí ìyà tó ń jẹ mí àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ́ mi ṣe, ìdí nìyẹn tó fi bá ọ wí lóru àná.”+

43 Lábánì wá dá Jékọ́bù lóhùn pé: “Ọmọ mi làwọn obìnrin yìí, ọmọ mi sì làwọn ọmọ yìí, èmi ni mo ni àwọn agbo ẹran yìí, èmi àtàwọn ọmọbìnrin mi ló ni gbogbo ohun tí ò ń wò yìí. Kò sóhun búburú kankan tí mo lè ṣe sí wọn lónìí tàbí sí àwọn ọmọ tí wọ́n bí. 44 Ó yá, jẹ́ ká jọ dá májẹ̀mú, èmi àti ìwọ, ìyẹn ló máa jẹ́ ẹ̀rí láàárín wa.” 45 Jékọ́bù gbé òkúta kan, ó sì gbé e dúró bí òpó.+ 46 Jékọ́bù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ ṣa òkúta!” Wọ́n sì ṣa òkúta, wọ́n wá kó o jọ láti fi ṣe òkìtì. Lẹ́yìn náà, wọ́n jẹun níbẹ̀ lórí òkìtì òkúta náà. 47 Lábánì sì pè é ní Jegari-sáhádútà,* ṣùgbọ́n Jékọ́bù pè é ní Gáléédì.*

48 Lẹ́yìn náà, Lábánì sọ pé: “Òkìtì yìí jẹ́ ẹ̀rí láàárín èmi àti ìwọ lónìí.” Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ rẹ̀ ní Gáléédì+ 49 àti Ilé Ìṣọ́, torí ó sọ pé: “Kí Jèhófà máa ṣọ́ èmi àti ìwọ tí a ò bá sí nítòsí ara wa. 50 Tó o bá fìyà jẹ àwọn ọmọ mi, tí o sì ń fẹ́ ìyàwó lé wọn, bí èèyàn kankan ò tiẹ̀ sí pẹ̀lú wa, má gbàgbé pé Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí láàárín èmi àti ìwọ.” 51 Lábánì tún sọ fún Jékọ́bù pé: “Wo òkìtì òkúta yìí àti òpó tí mo gbé dúró láàárín èmi àti ìwọ. 52 Òkìtì òkúta yìí jẹ́ ẹ̀rí, òpó yìí náà sì jẹ́ ẹ̀rí,+ pé mi ò ní kọjá òkìtì yìí láti ṣe ọ́ níkà àti pé ìwọ náà ò ní kọjá òkìtì yìí láti ṣe mí níkà. 53 Kí Ọlọ́run Ábúráhámù+ àti Ọlọ́run Náhórì, Ọlọ́run bàbá wọn ṣèdájọ́ láàárín wa.” Jékọ́bù sì fi Ẹni tí Ísákì bàbá rẹ̀ ń bẹ̀rù búra.*+

54 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù rúbọ lórí òkè náà, ó sì pe àwọn arákùnrin rẹ̀ pé kí wọ́n wá jẹun. Torí náà, wọ́n jẹun, wọ́n sì sun òkè náà mọ́jú. 55 Àmọ́ Lábánì jí ní àárọ̀ kùtù, ó fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ*+ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì súre fún wọn.+ Lẹ́yìn náà, Lábánì kúrò níbẹ̀, ó sì pa dà sílé.+

32 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù ń bá tirẹ̀ lọ, àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀. 2 Gbàrà tí Jékọ́bù rí wọn, ó sọ pé: “Àgọ́ Ọlọ́run nìyí!” Torí náà, ó pe orúkọ ibẹ̀ ní Máhánáímù.*

3 Nígbà náà, Jékọ́bù ní kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní ilẹ̀ Séírì,+ ní agbègbè* Édómù,+ 4 ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún Ísọ̀ olúwa mi nìyí, ‘Ohun tí Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ sọ nìyí: “Ó ti pẹ́ tí mo ti ń gbé* lọ́dọ̀ Lábánì títí di báyìí.+ 5 Mo ti ní àwọn akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin,+ mo sì ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi láti fi èyí tó o létí, kí n lè rí ojúure rẹ.”’”

6 Nígbà tó yá, àwọn ìránṣẹ́ náà pa dà sọ́dọ̀ Jékọ́bù, wọ́n sì sọ fún un pé: “A rí Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ, ó sì ti ń bọ̀ wá pàdé rẹ+ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin.” 7 Ẹ̀rù wá ba Jékọ́bù gan-an, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀.+ Torí náà, ó pín àwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ àtàwọn agbo ẹran, àwọn màlúù àtàwọn ràkúnmí, ó pín wọn sí ọ̀nà méjì. 8 Ó ní: “Bí Ísọ̀ bá gbéjà ko apá kan, apá kejì á lè sá lọ.”

9 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù sọ pé: “Ọlọ́run Ábúráhámù bàbá mi àti Ọlọ́run Ísákì bàbá mi, Jèhófà, ìwọ tí ò ń sọ fún mi pé, ‘Pa dà sí ilẹ̀ rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, màá sì ṣe dáadáa sí ọ,’+ 10 ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o fi hàn àti bí o ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí ìránṣẹ́+ rẹ kò tọ́ sí mi, mi ò ní ju ọ̀pá kan ṣoṣo nígbà tí mo sọdá odò Jọ́dánì, àmọ́ mo ti wá di àgọ́ méjì+ báyìí. 11 Mo bẹ̀ ọ́,+ gbà mí lọ́wọ́ Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi, torí ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí, ó lè wá gbógun ja èmi+ àti àwọn ọmọ mi pẹ̀lú àwọn ìyá wọn. 12 O sì ti sọ pé: ‘Ó dájú pé màá ṣe dáadáa sí ọ, màá sì mú kí àtọmọdọ́mọ* rẹ pọ̀ bí iyanrìn òkun, débi pé wọn ò ní lè kà wọ́n.’”+

13 Ó wá sun ibẹ̀ mọ́jú. Ó sì mú ẹ̀bùn fún Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀ látinú àwọn ohun ìní rẹ̀: 14 igba (200) abo ewúrẹ́, ogún (20) òbúkọ, igba (200) abo àgùntàn, ogún (20) àgbò, 15 ọgbọ̀n (30) ràkúnmí tó ń tọ́mọ, ogójì (40) màlúù, akọ màlúù mẹ́wàá, ogún (20) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ mẹ́wàá tó ti dàgbà dáadáa.

16 Ó fà wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, agbo ẹran kan tẹ̀ lé òmíràn, ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ sọdá, kí ẹ máa lọ níwájú mi, kí ẹ sì fi àyè sílẹ̀ láàárín agbo ẹran kan àti èyí tó tẹ̀ lé e.” 17 Ó tún pàṣẹ fún èyí tó ṣáájú pé: “Tí Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi bá pàdé rẹ, tó sì bi ọ́ pé, ‘Ta ni ọ̀gá rẹ, ibo lò ń lọ, ta ló sì ni àwọn ohun tó wà níwájú rẹ yìí?’ 18 kí o sọ pé, ‘Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ ni. Ẹ̀bùn yìí ló fi ránṣẹ́ sí Ísọ̀+ olúwa mi. Wò ó! Òun náà ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’” 19 Ó sì pàṣẹ fún ẹnì kejì, ẹnì kẹta àti gbogbo àwọn tó ń tẹ̀ lé agbo ẹran pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún Ísọ̀ nìyẹn tí ẹ bá pàdé rẹ̀. 20 Kí ẹ tún sọ pé, ‘Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’” Torí ó sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: ‘Tí mo bá kọ́kọ́ fi ẹ̀bùn ránṣẹ́,+ tí mo fi wá ojúure rẹ̀, tí mo bá wá rí òun fúnra rẹ̀, bóyá ó lè tẹ́wọ́ gbà mí.’ 21 Wọ́n sì kó àwọn ẹ̀bùn náà sọdá ṣáájú rẹ̀, àmọ́ inú àgọ́ ni òun sùn.

22 Lóru ọjọ́ yẹn, ó dìde, ó mú àwọn ìyàwó rẹ̀ méjèèjì,+ àwọn ìránṣẹ́bìnrin+ rẹ̀ méjèèjì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kànlá (11) tí wọ́n ṣì kéré, wọ́n sì gba ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò Jábókù+ sọdá. 23 Ó kó gbogbo wọn, ó mú wọn sọdá odò,* ó sì kó gbogbo ohun míì tó ní kọjá.

24 Níkẹyìn, ó ṣẹ́ ku Jékọ́bù nìkan. Ọkùnrin kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a jìjàkadì títí ilẹ̀ fi mọ́.+ 25 Nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun ò borí, ó fọwọ́ kan egungun ìbàdí rẹ̀; egungun ìbàdí Jékọ́bù sì yẹ̀ nígbà tó ń bá a jìjàkadì.+ 26 Lẹ́yìn ìyẹn, ó sọ pé: “Jẹ́ kí n máa lọ, torí ilẹ̀ ti ń mọ́.” Àmọ́ ó fèsì pé: “Mi ò ní jẹ́ kí o lọ, àfi tí o bá súre fún mi.”+ 27 Ó wá bi í pé: “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó fèsì pé: “Jékọ́bù.” 28 Ó wá sọ fún un pé: “O ò ní máa jẹ́ Jékọ́bù mọ́, Ísírẹ́lì*+ ni wàá máa jẹ́, torí o ti bá Ọlọ́run + àti èèyàn wọ̀jà, o sì ti wá borí.” 29 Ni Jékọ́bù bá sọ pé: “Jọ̀ọ́, sọ orúkọ rẹ fún mi.” Àmọ́ ó fèsì pé: “Kí nìdí tí o fi ń béèrè orúkọ mi?”+ Ó sì súre fún un níbẹ̀. 30 Torí náà, Jékọ́bù pe orúkọ ibẹ̀ ní Péníélì,*+ torí ó sọ pé, “Mo ti rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ ó dá ẹ̀mí* mi sí.”+

31 Oòrùn wá yọ ní gbàrà tó kọjá Pénúélì,* àmọ́ ó ń tiro torí ohun tó ṣe ìbàdí+ rẹ̀. 32 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé títí dòní, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í jẹ iṣan tó wà níbi itan* ní oríkèé egungun ìbàdí, torí ó fọwọ́ kan iṣan tó wà níbi itan ní oríkèé egungun ìbàdí Jékọ́bù.

33 Jékọ́bù bá wòkè, ó sì rí Ísọ̀ tó ń bọ̀ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin.+ Torí náà, ó pín àwọn ọmọ sọ́dọ̀ Líà, Réṣẹ́lì àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin+ méjèèjì. 2 Ó fi àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà àti àwọn ọmọ wọn síwájú,+ Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ̀ lé wọn,+ Réṣẹ́lì+ àti Jósẹ́fù sì wà lẹ́yìn wọn. 3 Òun fúnra rẹ̀ wá ṣíwájú wọn, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀meje bó ṣe ń sún mọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

4 Àmọ́ Ísọ̀ sáré pàdé rẹ̀, ó gbá a mọ́ra, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n sì bú sẹ́kún. 5 Nígbà tó gbójú sókè, tó sì rí àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ náà, ó bi í pé: “Àwọn wo ló wà pẹ̀lú rẹ yìí?” Ó fèsì pé: “Àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi bù kún ìránṣẹ́+ rẹ ni.” 6 Àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà wá bọ́ síwájú pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì tẹrí ba, 7 Líà náà bọ́ síwájú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba. Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù bọ́ síwájú pẹ̀lú Réṣẹ́lì, wọ́n sì tẹrí ba.+

8 Ísọ̀ bi Jékọ́bù pé: “Kí ni gbogbo àwùjọ àwọn arìnrìn-àjò tí mo pàdé+ yìí wà fún?” Ó fèsì pé: “Kí n lè rí ojúure olúwa+ mi ni.” 9 Ísọ̀ wá sọ pé: “Àbúrò mi,+ mo ní àwọn ohun tó pọ̀ gan-an. Máa mú àwọn nǹkan rẹ lọ.” 10 Àmọ́ Jékọ́bù sọ pé: “Jọ̀ọ́, má ṣe bẹ́ẹ̀. Tí mo bá rí ojúure rẹ, wàá gba ẹ̀bùn tí mo fún ọ lọ́wọ́ mi, torí kí n lè rí ojú rẹ ni mo ṣe mú un wá. Mo sì ti rí ojú rẹ, ó dà bí ìgbà tí mo rí ojú Ọlọ́run, torí o gbà mí tayọ̀tayọ̀.+ 11 Jọ̀ọ́, gba ẹ̀bùn tí mo mú wá fún ọ+ láti bù kún ọ, torí Ọlọ́run ti ṣojúure sí mi, mo sì ní gbogbo ohun tí mo nílò.”+ Ó sì ń rọ̀ ọ́ títí ó fi gbà á.

12 Nígbà tó yá, Ísọ̀ sọ pé: “Jẹ́ ká ṣí kúrò, ká sì máa lọ. Jẹ́ kí n máa lọ níwájú rẹ.” 13 Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Olúwa mi mọ̀ pé àwọn ọmọ ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára,+ mo sì ní àwọn àgùntàn àti màlúù tó ń tọ́mọ lọ́wọ́. Tí mo bá yára dà wọ́n jù láàárín ọjọ́ kan, gbogbo ẹran ló máa kú. 14 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí olúwa mi máa lọ níwájú ìránṣẹ́ rẹ̀, èmi á rọra máa bọ̀ bí agbára àwọn ẹran ọ̀sìn mi àti àwọn ọmọ mi bá ṣe gbé e, títí màá fi dé ọ̀dọ̀ olúwa mi ní Séírì.”+ 15 Ísọ̀ wá sọ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n fi díẹ̀ lára àwọn èèyàn mi sílẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ.” Ó fèsì pé: “Má ṣèyọnu, jẹ́ kí n ṣáà rí ojúure olúwa mi.” 16 Ísọ̀ sì pa dà sí Séírì ní ọjọ́ yẹn.

17 Jékọ́bù wá lọ sí Súkótù,+ ó kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe àtíbàbà fún agbo ẹran rẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ ibẹ̀ ní Súkótù.*

18 Jékọ́bù rìnrìn àjò wá láti Padani-árámù,+ ó sì dé sí ìlú Ṣékémù+ ní ilẹ̀ Kénáánì+ ní àlàáfíà, ó wá pàgọ́ sí tòsí ìlú náà. 19 Ó ra apá kan lára ilẹ̀ tó pa àgọ́ rẹ̀ sí lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì, bàbá Ṣékémù, ó rà á ní ọgọ́rùn-ún (100) ẹyọ owó.+ 20 Ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pè é ní Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+

34 Dínà ọmọbìnrin tí Líà+ bí fún Jékọ́bù sábà máa ń lọ sọ́dọ̀* àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà.+ 2 Nígbà tí Ṣékémù, ọmọ Hámórì, ọmọ Hífì,+ tó jẹ́ ìjòyè ilẹ̀ náà rí i, ó mú un, ó sì bá a sùn, ó fipá bá a lò pọ̀. 3 Ọkàn rẹ̀ wá fà mọ́ Dínà ọmọ Jékọ́bù gan-an, ó nífẹ̀ẹ́ ọmọbìnrin náà, ó sì ń fìfẹ́ rọ̀ ọ́ bó ṣe ń bá a sọ̀rọ̀.* 4 Níkẹyìn, Ṣékémù sọ fún Hámórì+ bàbá rẹ̀ pé: “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi kí n fi ṣe aya.”

5 Àwọn ọmọ Jékọ́bù ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀ nínú pápá nígbà tó gbọ́ pé ọkùnrin náà ti bá Dínà ọmọ rẹ̀ sùn. Jékọ́bù ò sì sọ nǹkan kan títí wọ́n fi dé. 6 Nígbà tó yá, Hámórì bàbá Ṣékémù jáde lọ bá Jékọ́bù sọ̀rọ̀. 7 Àmọ́ nígbà tí àwọn ọmọ Jékọ́bù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n pa dà wálé láti inú pápá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Inú wọn ò dùn rárá, inú sì bí wọn gidigidi, torí ó ti dójú ti Ísírẹ́lì bó ṣe bá ọmọ Jékọ́bù+ sùn, ohun tí kò yẹ kó ṣẹlẹ̀.+

8 Hámórì sọ fún wọn pé: “Ọkàn Ṣékémù ọmọ mi ń fà sí* ọmọ yín. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fún un kó fi ṣe aya, 9 kí ẹ sì bá wa dána.* Ẹ fún wa ní àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ̀yin náà sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wa.+ 10 Ẹ lè máa gbé lọ́dọ̀ wa, ilẹ̀ yìí yóò sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó yín. Ẹ máa gbé ibẹ̀, ẹ máa ṣòwò, kí ẹ sì wà níbẹ̀.” 11 Ṣékémù sọ fún bàbá ọmọbìnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí n rí ojúure yín, màá sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ bá bi mí. 12 Ẹ lè béèrè owó orí ìyàwó tó pọ̀ gan-an àti ẹ̀bùn+ lọ́wọ́ mi. Mo ṣe tán láti fún yín ní ohunkóhun tí ẹ bá bi mí. Ẹ ṣáà fún mi ní ọmọbìnrin náà kí n fi ṣe aya.”

13 Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù wá fi ẹ̀tàn dá Ṣékémù àti Hámórì bàbá rẹ̀ lóhùn torí Ṣékémù ti bá Dínà arábìnrin wọn sùn. 14 Wọ́n sọ fún wọn pé: “A ò lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, pé ká fún ọkùnrin tí kò dádọ̀dọ́*+ ní arábìnrin wa torí ohun ìtìjú ló jẹ́ fún wa. 15 Ohun kan ṣoṣo tó lè mú ká gbà ni pé: kí ẹ dà bíi wa, kí gbogbo ọkùnrin+ yín sì dádọ̀dọ́.* 16 Àá wá fún yín ní àwọn ọmọbìnrin wa, àwa náà á sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin yín, àá máa bá yín gbé, àá sì di ọ̀kan. 17 Àmọ́ tí ẹ ò bá fetí sí wa, kí ẹ sì dádọ̀dọ́, àá mú ọmọ wa lọ.”

18 Ọ̀rọ̀ wọn múnú Hámórì+ àti Ṣékémù ọmọ+ rẹ̀ dùn. 19 Torí ọmọkùnrin náà fẹ́ràn ọmọ Jékọ́bù gan-an, kíá ló ṣe ohun tí wọ́n sọ,+ òun sì ni wọ́n kà sí èèyàn pàtàkì jù lọ ní gbogbo ilé bàbá rẹ̀.

20 Hámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀ wá lọ sí ẹnubodè ìlú náà,+ wọ́n sì sọ fún àwọn ọkùnrin ìlú wọn pé: 21 “Àwọn ọkùnrin yìí fẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín wa. Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ yìí, kí wọ́n sì máa ṣòwò níbí, torí ilẹ̀ yìí fẹ̀ dáadáa, ó lè gbà wọ́n. A lè fi àwọn ọmọbìnrin wọn ṣe aya, a sì lè fún wọn ní àwọn ọmọbìnrin wa.+ 22 Ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí wọ́n gbà láti bá wa gbé, ká lè di ọ̀kan ni pé: kí gbogbo ọkùnrin àárín wa dádọ̀dọ́*+ bíi tiwọn. 23 Nígbà náà, gbogbo ohun ìní wọn, ọrọ̀ wọn àti gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn á di tiwa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n lè máa bá wa gbé.” 24 Gbogbo àwọn tó ń gba ẹnubodè ìlú rẹ̀ jáde fetí sí Hámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀, gbogbo ọkùnrin sì dádọ̀dọ́, gbogbo àwọn tó ń gba ẹnubodè ìlú jáde.

25 Àmọ́ ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí wọ́n ṣì ń jẹ̀rora, àwọn ọmọ Jékọ́bù méjì, Síméónì àti Léfì tí wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n+ Dínà mú idà wọn, wọ́n yọ́ lọ sí ìlú náà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin.+ 26 Wọ́n fi idà pa Hámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀, wọ́n wá mú Dínà kúrò ní ilé Ṣékémù, wọ́n sì lọ. 27 Àwọn ọmọ Jékọ́bù yòókù lọ síbi tí wọ́n ti pa àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì kó ohun ìní àwọn ará ìlú náà, torí wọ́n ti kẹ́gàn bá arábìnrin+ wọn. 28 Wọ́n kó àwọn agbo ẹran wọn, ọ̀wọ́ ẹran wọn, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn àti gbogbo ohun tó wà nínú ìlú náà àti nínú oko. 29 Wọ́n tún kó gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n mú gbogbo àwọn ọmọ wọn kéékèèké àti àwọn ìyàwó wọn, wọ́n sì kó gbogbo ohun tó wà nínú ilé wọn.

30 Ni Jékọ́bù bá sọ fún Síméónì àti Léfì+ pé: “Wàhálà ńlá lẹ kó mi sí yìí,* torí ẹ máa mú kí àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì tó ń gbé ilẹ̀ yìí kórìíra mi. Mo kéré níye, ó sì dájú pé wọ́n á kóra jọ láti bá mi jà, wọ́n á sì pa mí run, èmi àti ilé mi.” 31 Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Ṣé ó yẹ kí ẹnikẹ́ni ṣe irú nǹkan yìí sí arábìnrin wa nígbà tí kì í ṣe aṣẹ́wó?”

35 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ fún Jékọ́bù pé: “Gbéra, gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì,+ ibẹ̀ ni kí o máa gbé, kí o sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó fara hàn ọ́ nígbà tí ò ń sá fún Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n+ rẹ.”

2 Jékọ́bù wá sọ fún agbo ilé rẹ̀ àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ mú àwọn ọlọ́run àjèjì tó wà láàárín yín+ kúrò, kí ẹ wẹ ara yín mọ́, kí ẹ pààrọ̀ aṣọ yín, 3 kí ẹ jẹ́ ká gbéra, ká sì gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Ibẹ̀ ni èmi yóò mọ pẹpẹ kan sí fún Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó dá mi lóhùn ní ọjọ́ tí mo wà nínú ìṣòro, tó sì wà pẹ̀lú mi ní gbogbo ibi* tí mo lọ.”+ 4 Torí náà, wọ́n kó gbogbo ọlọ́run àjèjì tí wọ́n ní àti àwọn yẹtí tó wà ní etí wọn fún Jékọ́bù, Jékọ́bù sì rì wọ́n mọ́lẹ̀* sábẹ́ igi ńlá tó wà nítòsí Ṣékémù.

5 Bí wọ́n ṣe ń lọ, ìbẹ̀rù Ọlọ́run mú àwọn ìlú tó yí wọn ká, torí náà, wọn ò lépa àwọn ọmọ Jékọ́bù. 6 Jékọ́bù wá dé Lúsì,+ ìyẹn Bẹ́tẹ́lì, ní ilẹ̀ Kénáánì, òun àti gbogbo èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. 7 Ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe ibẹ̀ ní Eli-bẹ́tẹ́lì,* torí ibẹ̀ ni Ọlọ́run tòótọ́ ti fara hàn án nígbà tó ń sá fún ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀. 8 Nígbà tó yá, Dèbórà+ tó jẹ́ olùtọ́jú Rèbékà kú, wọ́n sì sin ín sí ìsàlẹ̀ Bẹ́tẹ́lì lábẹ́ igi ràgàjì* kan. Torí náà, ó pè é ní Aloni-bákútì.*

9 Ọlọ́run fara han Jékọ́bù lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà tó ń bọ̀ láti Padani-árámù, ó sì súre fún un. 10 Ọlọ́run sọ fún un pé: “Jékọ́bù+ ni orúkọ rẹ. Àmọ́, o ò ní máa jẹ́ Jékọ́bù mọ́, Ísírẹ́lì ni wàá máa jẹ́.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Ísírẹ́lì.+ 11 Ọlọ́run tún sọ fún un pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè.+ Máa bímọ, kí o sì di púpọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè àti àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè yóò tinú rẹ jáde,+ àwọn ọba yóò sì ti ara rẹ jáde.*+ 12 Màá fún ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ ní ilẹ̀+ tí mo fún Ábúráhámù àti Ísákì.” 13 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ níbi tó ti bá a sọ̀rọ̀.

14 Jékọ́bù sì gbé òpó kan dúró níbi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀, òpó òkúta ni, ó sì da ọrẹ ohun mímu àti òróró sórí rẹ̀.+ 15 Jékọ́bù sì ń pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.+

16 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tí ọ̀nà wọn ṣì jìn díẹ̀ sí Éfúrátì, Réṣẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, ó sì nira fún un gan-an. 17 Àmọ́ bó ṣe ń tiraka kí ọmọ náà lè jáde, agbẹ̀bí náà sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, torí wàá bí ọmọ yìí pẹ̀lú.”+ 18 Bí ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ń bọ́ lọ* (torí ó ń kú lọ), ó sọ ọmọ náà ní Bẹni-ónì,* àmọ́ bàbá rẹ̀ sọ ọ́ ní Bẹ́ńjámínì.*+ 19 Réṣẹ́lì wá kú, wọ́n sì sin ín ní ojú ọ̀nà Éfúrátì, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ 20 Jékọ́bù gbé òpó kan dúró sórí sàréè rẹ̀; òun ni òpó sàréè Réṣẹ́lì títí dòní.

21 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì ṣí kúrò, ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí ìkọjá ilé gogoro Édérì. 22 Nígbà kan tí Ísírẹ́lì ń gbé ilẹ̀ yẹn, Rúbẹ́nì lọ bá Bílíhà tó jẹ́ wáhàrì* bàbá rẹ̀ sùn, Ísírẹ́lì sì gbọ́ nípa rẹ̀.+

Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù jẹ́ méjìlá (12). 23 Àwọn ọmọkùnrin tí Líà bí ni Rúbẹ́nì+ tó jẹ́ àkọ́bí Jékọ́bù, lẹ́yìn náà, ó bí Síméónì, Léfì, Júdà, Ísákà àti Sébúlúnì. 24 Àwọn ọmọkùnrin tí Réṣẹ́lì bí ni Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. 25 Àwọn ọmọkùnrin tí Bílíhà ìránṣẹ́ Réṣẹ́lì bí ni Dánì àti Náfútálì. 26 Àwọn ọmọkùnrin tí Sílípà ìránṣẹ́ Líà bí ni Gádì àti Áṣérì. Àwọn ni ọmọkùnrin Jékọ́bù, tí wọ́n bí fún un ní Padani-árámù.

27 Nígbà tó yá, Jékọ́bù dé ibi tí Ísákì bàbá rẹ̀ wà ní Mámúrè,+ ní Kiriati-ábà, ìyẹn Hébúrónì, níbi tí Ábúráhámù àti Ísákì pẹ̀lú ti gbé rí bí àjèjì.+ 28 Ọjọ́ ayé Ísákì sì jẹ́ ọgọ́sàn-án (180) ọdún.+ 29 Ísákì wá mí èémí ìkẹyìn, ó sì kú, wọ́n kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀,* lẹ́yìn tó ti pẹ́ láyé, tí ayé rẹ̀ sì dáa;* Ísọ̀ àti Jékọ́bù ọmọ rẹ̀ sì sin ín.+

36 Èyí ni ìtàn Ísọ̀, ìyẹn Édómù.+

2 Ísọ̀ fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì: Ádà+ ọmọ Élónì ọmọ Hétì;+ Oholibámà+ ọmọ Ánáhì, ọmọ ọmọ Síbéónì ọmọ Hífì; 3 àti Básémátì+ ọmọ Íṣímáẹ́lì, arábìnrin Nébáótì.+

4 Ádà bí Élífásì fún Ísọ̀, Básémátì bí Réúẹ́lì,

5 Oholibámà sì bí Jéúṣì, Jálámù àti Kórà.+

Àwọn ni ọmọ Ísọ̀ tí wọ́n bí fún un ní ilẹ̀ Kénáánì. 6 Lẹ́yìn náà, Ísọ̀ kó àwọn ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, gbogbo àwọn* tó wà ní agbo ilé rẹ̀, agbo ẹran rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹran rẹ̀ yòókù, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tó ti ní+ nílẹ̀ Kénáánì, ó sì lọ sí ilẹ̀ míì, níbi tó jìnnà sí Jékọ́bù àbúrò+ rẹ̀. 7 Torí ohun ìní wọn ti pọ̀ débi pé wọn ò lè máa gbé pa pọ̀, ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé* ò sì lè tó wọn mọ́ torí agbo ẹran wọn. 8 Ísọ̀ wá ń gbé ní agbègbè olókè Séírì.+ Ísọ̀ ni Édómù.+

9 Èyí ni ìtàn Ísọ̀, bàbá Édómù ní agbègbè olókè Séírì.+

10 Orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísọ̀ nìyí: Élífásì ọmọ Ádà ìyàwó Ísọ̀; Réúẹ́lì ọmọ Básémátì ìyàwó Ísọ̀.+

11 Àwọn ọmọ Élífásì ni Témánì,+ Ómárì, Séfò, Gátámù àti Kénásì.+ 12 Tímínà di wáhàrì* Élífásì ọmọ Ísọ̀. Nígbà tó yá, ó bí Ámálékì+ fún Élífásì. Àwọn ni ọmọ Ádà ìyàwó Ísọ̀.

13 Àwọn ọmọ Réúẹ́lì nìyí: Náhátì, Síírà, Ṣámà àti Mísà. Àwọn ni ọmọ Básémátì+ ìyàwó Ísọ̀.

14 Àwọn ọmọ tí Oholibámà ọmọ Ánáhì, ọmọ ọmọ Síbéónì, ìyàwó Ísọ̀ bí fún Ísọ̀ nìyí: Jéúṣì, Jálámù àti Kórà.

15 Àwọn tó jẹ́ séríkí* nínú àwọn ọmọ Ísọ̀+ nìyí: Àwọn ọmọkùnrin Élífásì, àkọ́bí Ísọ̀ ni: Séríkí Témánì, Séríkí Ómárì, Séríkí Séfò, Séríkí Kénásì,+ 16 Séríkí Kórà, Séríkí Gátámù àti Séríkí Ámálékì. Àwọn ni séríkí nínú àwọn ọmọ Élífásì+ ní ilẹ̀ Édómù. Àwọn ọmọ Ádà nìyẹn.

17 Àwọn ọmọkùnrin Réúẹ́lì ọmọ Ísọ̀ nìyí: Séríkí Náhátì, Séríkí Síírà, Séríkí Ṣámà àti Séríkí Mísà. Àwọn ni séríkí nínú àwọn ọmọ Réúẹ́lì ní ilẹ̀ Édómù.+ Àwọn ni ọmọ Básémátì ìyàwó Ísọ̀.

18 Àwọn ọmọ Oholibámà ìyàwó Ísọ̀ sì nìyí: Séríkí Jéúṣì, Séríkí Jálámù àti Séríkí Kórà. Àwọn ni séríkí nínú àwọn ọmọ Oholibámà ọmọ Ánáhì, ìyàwó Ísọ̀.

19 Àwọn ọmọ Ísọ̀ nìyẹn, àwọn séríkí wọn sì nìyẹn. Òun ni Édómù.+

20 Àwọn ọmọ Séírì ọmọ Hórì tí wọ́n ń gbé ilẹ̀+ náà nìyí: Lótánì, Ṣóbálì, Síbéónì, Ánáhì,+ 21 Díṣónì, Ésérì àti Díṣánì.+ Àwọn ni séríkí àwọn Hórì, àwọn ọmọ Séírì, ní ilẹ̀ Édómù.

22 Àwọn ọmọ Lótánì ni Hórì àti Hémámù, arábìnrin Lótánì sì ni Tímínà.+

23 Àwọn ọmọ Ṣóbálì nìyí: Álífánì, Manáhátì, Ébálì, Ṣéfò àti Ónámù.

24 Àwọn ọmọ Síbéónì+ nìyí: Áyà àti Ánáhì. Òun ni Ánáhì tó rí àwọn ìsun omi gbígbóná nínú aginjù nígbà tó ń tọ́jú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Síbéónì bàbá rẹ̀.

25 Àwọn ọmọ Ánáhì nìyí: Díṣónì àti Oholibámà ọmọbìnrin Ánáhì.

26 Àwọn ọmọ Díṣónì nìyí: Hémúdánì, Éṣíbánì, Ítíránì àti Kéránì.+

27 Àwọn ọmọ Ésérì nìyí: Bílíhánì, Sááfánì àti Ékánì.

28 Àwọn ọmọ Díṣánì nìyí: Úsì àti Áránì.+

29 Àwọn séríkí àwọn Hórì nìyí: Séríkí Lótánì, Séríkí Ṣóbálì, Séríkí Síbéónì, Séríkí Ánáhì, 30 Séríkí Díṣónì, Séríkí Ésérì àti Séríkí Díṣánì.+ Àwọn ni séríkí àwọn Hórì, wọ́n jẹ́ séríkí káàkiri ilẹ̀ Séírì.

31 Àwọn ọba tó jẹ ní ilẹ̀ Édómù+ nìyí kí ọba kankan tó jẹ lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.*+ 32 Bélà ọmọ Béórì jọba ní Édómù, orúkọ ìlú rẹ̀ sì ni Dínhábà. 33 Nígbà tí Bélà kú, Jóbábù ọmọ Síírà láti Bósírà bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 34 Nígbà tí Jóbábù kú, Húṣámù láti ilẹ̀ àwọn ará Témánì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 35 Nígbà tí Húṣámù kú, Hádádì ọmọ Bédádì, ẹni tó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Mídíánì+ ní agbègbè* Móábù bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀, orúkọ ìlú rẹ̀ sì ni Áfítì. 36 Nígbà tí Hádádì kú, Sámúlà láti Másírékà bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 37 Nígbà tí Sámúlà kú, Ṣéọ́lù láti Réhóbótì tó wà lẹ́gbẹ́ẹ̀ Odò bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 38 Nígbà tí Ṣéọ́lù kú, Baali-hánánì ọmọ Ákíbórì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 39 Nígbà tí Baali-hánánì ọmọ Ákíbórì kú, Hádárì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Páù, orúkọ ìyàwó rẹ̀ sì ni Méhétábélì ọmọ Mátírédì ọmọbìnrin Mésáhábù.

40 Orúkọ àwọn séríkí tó jẹ́ ọmọ Ísọ̀ nìyí, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ibi tí wọ́n ń gbé àti orúkọ wọn: Séríkí Tímínà, Séríkí Álíífà, Séríkí Jététì,+ 41 Séríkí Oholibámà, Séríkí Élà, Séríkí Pínónì, 42 Séríkí Kénásì, Séríkí Témánì, Séríkí Míbúsárì, 43 Séríkí Mágídíélì àti Séríkí Írámù. Àwọn ni séríkí Édómù gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ tó jẹ́ ohun ìní+ wọn. Èyí ni Ísọ̀, bàbá Édómù.+

37 Jékọ́bù ń gbé ilẹ̀ Kénáánì nìṣó, ibi tí bàbá rẹ̀ gbé bí àjèjì.+

2 Ìtàn Jékọ́bù nìyí.

Nígbà tí Jósẹ́fù+ wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17), ọ̀dọ́kùnrin náà pẹ̀lú àwọn ọmọ Bílíhà+ àti àwọn ọmọ Sílípà+ tí wọ́n jẹ́ ìyàwó bàbá rẹ̀ jọ ń bójú tó agbo ẹran.+ Jósẹ́fù wá ròyìn ohun búburú tí wọ́n ṣe fún bàbá wọn. 3 Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jósẹ́fù ju gbogbo àwọn ọmọ+ rẹ̀ yòókù lọ torí pé ìgbà tó darúgbó ló bí i, ó sì ṣe aṣọ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀* fún un. 4 Nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rí i pé bàbá àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ju gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra rẹ̀, wọn kì í sì í fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀.

5 Nígbà tó yá, Jósẹ́fù lá àlá kan, ó sì rọ́ ọ fún àwọn arákùnrin+ rẹ̀, èyí mú kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀. 6 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fetí sí àlá tí mo lá. 7 Ó ṣẹlẹ̀ pé à ń di ìtí ọkà ní àárín oko, ni ìtí tèmi bá dìde, ó nàró, àwọn ìtí tiyín sì tò yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì tẹrí ba fún un.”+ 8 Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣé o wá fẹ́ jọba lé wa lórí ni, kí o wá máa pàṣẹ fún wa?”+ Ìyẹn wá mú kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀, torí àwọn àlá tó lá àti ohun tó sọ.

9 Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún lá àlá míì, ó sì rọ́ ọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, ó ní: “Mo tún lá àlá míì. Lọ́tẹ̀ yìí, oòrùn àti òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá (11) ń tẹrí ba fún mi.”+ 10 Ó rọ́ ọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, bàbá rẹ̀ sì bá a wí, ó ní: “Kí ni ìtúmọ̀ àlá tí o lá yìí? Ṣé èmi àti ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ yóò wá máa tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún ọ ni?” 11 Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í jowú rẹ̀,+ àmọ́ bàbá rẹ̀ fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn.

12 Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kó agbo ẹran bàbá wọn lọ jẹko lẹ́bàá Ṣékémù.+ 13 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì sọ fún Jósẹ́fù pé: “Ṣebí tòsí Ṣékémù làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ti ń bójú tó agbo ẹran, àbí? Wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.” Ó fèsì pé: “Ó ti yá!” 14 Ó wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, lọ wò ó bóyá àlàáfíà ni àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ wà. Wo bí agbo ẹran náà ṣe ń ṣe sí, kí o sì pa dà wá jíṣẹ́ fún mi.” Ló bá rán an lọ láti àfonífojì* Hébúrónì,+ ó sì forí lé Ṣékémù. 15 Nígbà tó yá, ọkùnrin kan rí i bó ṣe ń rìn kiri nínú oko. Ọkùnrin náà bi í pé: “Kí lò ń wá?” 16 Ó fèsì pé: “Mò ń wá àwọn ẹ̀gbọ́n mi ni. Ẹ jọ̀ọ́, ǹjẹ́ ẹ mọ ibi tí wọ́n ti ń da agbo ẹran?” 17 Ọkùnrin náà fèsì pé: “Wọ́n ti ṣí kúrò níbí, torí mo gbọ́ tí wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ ká lọ sí Dótánì.’” Torí náà, Jósẹ́fù wá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní Dótánì.

18 Wọ́n rí Jósẹ́fù tó ń bọ̀ ní ọ̀ọ́kán, àmọ́ kó tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbìmọ̀ pọ̀ kí wọ́n lè pa á. 19 Wọ́n wá ń sọ fún ara wọn pé: “Wò ó! Alálàá+ yẹn ló ń bọ̀ yìí. 20 Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká pa á, ká sì jù ú sínú ọ̀kan nínú àwọn kòtò omi, ká sì sọ pé ẹranko burúkú kan ló pa á jẹ. Ká wá wo bí àwọn àlá rẹ̀ ṣe máa ṣẹ.” 21 Nígbà tí Rúbẹ́nì+ gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ó sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ ká pa á.”*+ 22 Rúbẹ́nì sọ fún wọn pé: “Ẹ má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Ẹ jù ú sínú kòtò omi yìí nínú aginjù, àmọ́ ẹ má ṣe é léṣe.”*+ Ó ní in lọ́kàn láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn kó lè dá a pa dà sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀.

23 Gbàrà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, wọ́n bọ́ aṣọ rẹ̀, ìyẹn aṣọ àrà ọ̀tọ̀ tó wọ̀,+ 24 wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò omi. Kòtò náà ṣófo nígbà yẹn; kò sí omi nínú rẹ̀.

25 Wọ́n wá jókòó láti jẹun. Nígbà tí wọ́n wòkè, wọ́n rí àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì+ tó ń rìnrìn àjò tí wọ́n ń bọ̀ láti Gílíádì. Àwọn ràkúnmí wọn ru gọ́ọ̀mù lábídánọ́mù, básámù àti èèpo+ igi olóje, wọ́n ń lọ sí Íjíbítì. 26 Ni Júdà bá sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá pa àbúrò wa, tí a sì bo ẹ̀jẹ̀+ rẹ̀ mọ́lẹ̀? 27 Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká tà á  + fún àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, ẹ má sì jẹ́ ká fọwọ́ kàn án. Ó ṣe tán, àbúrò wa ni, ara kan náà ni wá.” Wọ́n sì gbọ́ ohun tí arákùnrin wọn sọ. 28 Nígbà tí àwọn oníṣòwò tí wọ́n jẹ́ ọmọ Mídíánì+ ń kọjá lọ, wọ́n fa Jósẹ́fù jáde látinú kòtò omi náà, wọ́n sì tà á fún àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì ní ogún (20) ẹyọ fàdákà.+ Ni àwọn ọkùnrin yìí bá mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì.

29 Nígbà tí Rúbẹ́nì wá pa dà dé ibi kòtò omi náà, tó sì rí i pé Jósẹ́fù ò sí nínú rẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ ara rẹ̀ ya. 30 Nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ àwọn àbúrò rẹ̀, ó pariwo pé: “Ọmọ náà ti lọ! Kí ni màá ṣe báyìí?”

31 Wọ́n wá mú aṣọ Jósẹ́fù, wọ́n pa òbúkọ kan, wọ́n sì ti aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 32 Lẹ́yìn náà, wọ́n fi aṣọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ náà ránṣẹ́ sí bàbá wọn, wọ́n sì sọ pé: “Ohun tí a rí nìyí. Jọ̀ọ́, yẹ̀ ẹ́ wò bóyá aṣọ ọmọ rẹ ni tàbí òun kọ́.”+ 33 Ó sì yẹ̀ ẹ́ wò, ló bá kígbe pé: “Aṣọ ọmọ mi ni! Ẹranko burúkú ti pa á jẹ! Ó dájú pé ẹranko náà ti fa Jósẹ́fù ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ!” 34 Ni Jékọ́bù bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sán aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́ ìbàdí, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. 35 Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń gbìyànjú láti tù ú nínú, àmọ́ kò gbà, ó ń sọ pé: “Màá ṣọ̀fọ̀ ọmọ mi wọnú Isà Òkú!”*+ Bàbá rẹ̀ sì ń sunkún torí rẹ̀.

36 Àwọn ọmọ Mídíánì ta Jósẹ́fù fún Pọ́tífárì, òṣìṣẹ́ láàfin Fáráò+ àti olórí ẹ̀ṣọ́,+ ní Íjíbítì.

38 Ní àkókò yẹn, Júdà kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí tòsí ọkùnrin ará Ádúlámù kan tó ń jẹ́ Hírà. 2 Ibẹ̀ ni Júdà ti rí ọmọbìnrin ara Kénáánì+ kan tó ń jẹ́ Ṣúà. Ó mú un, ó bá a lò pọ̀, 3 ó sì lóyún. Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Éérì.+ 4 Ó tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ónánì. 5 Ó tún bí ọmọkùnrin míì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣélà. Ìlú Ákísíbù+ ni ó* wà nígbà tí obìnrin náà bí i.

6 Nígbà tó yá, Júdà fẹ́ ìyàwó fún Éérì àkọ́bí rẹ̀, Támárì+ ni orúkọ rẹ̀. 7 Àmọ́ inú Jèhófà ò dùn sí Éérì, àkọ́bí Júdà; torí náà, Jèhófà pa á. 8 Torí ìyẹn, Júdà sọ fún Ónánì pé: “Bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ lò pọ̀, kí o ṣú u lópó, kí o sì mú kí ẹ̀gbọ́n+ rẹ ní ọmọ.” 9 Àmọ́ Ónánì mọ̀ pé ọmọ náà ò ní jẹ́ tòun.+ Torí náà, nígbà tó bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lò pọ̀, ó fi àtọ̀ rẹ̀ ṣòfò sórí ilẹ̀, kí ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀ má bàa ní ọmọ. 10 Ohun tó ṣe yìí burú lójú Jèhófà; torí náà, ó pa+ òun náà. 11 Júdà sọ fún Támárì ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé: “Lọ máa ṣe opó ní ilé bàbá rẹ títí Ṣélà ọmọ mi yóò fi dàgbà,” torí ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Òun náà lè kú bíi ti àwọn ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀.” Támárì wá lọ ń gbé ní ilé bàbá rẹ̀.

12 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ìyàwó Júdà tó jẹ́ ọmọ Ṣúà+ kú. Júdà ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, lẹ́yìn náà, òun àti Hírà ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Ádúlámù+ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀ ní Tímúnà.+ 13 Àwọn kan sọ fún Támárì pé: “Bàbá ọkọ rẹ ń lọ sí Tímúnà láti rẹ́ irun àwọn àgùntàn rẹ̀.” 14 Ló bá bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó fi aṣọ bojú, ó sì fi ìborùn borí rẹ̀. Ó wá jókòó sí ẹnu ọ̀nà Énáímù, tó wà ní ọ̀nà Tímúnà, torí ó rí i pé Ṣélà ti dàgbà, bàbá rẹ̀ kò sì tíì sọ pé kí òun di ìyàwó+ Ṣélà.

15 Nígbà tí Júdà rí i, ó rò pé aṣẹ́wó ni, torí ó fi nǹkan bojú. 16 Torí náà, ó yà sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n bá ọ lò pọ̀,” ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé ìyàwó ọmọ+ òun ni. Obìnrin náà bi í pé: “Kí lo máa fún mi tí o bá bá mi lò pọ̀?” 17 Ó fèsì pé: “Màá fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ́ látinú agbo ẹran mi.” Àmọ́ obìnrin náà sọ pé: “Ṣé o máa fi nǹkan ṣe ìdúró títí dìgbà tí wàá fi ewúrẹ́ náà ránṣẹ́?” 18 Ó bi í pé: “Kí ni kí n fi ṣe ìdúró fún ọ?” Obìnrin náà fèsì pé: “Òrùka èdìdì+ rẹ, okùn rẹ àti ọ̀pá ọwọ́ rẹ.” Ló bá kó o fún un, ó sì bá a lò pọ̀, obìnrin náà sì lóyún fún un. 19 Lẹ́yìn náà, ó gbéra, ó sì kúrò níbẹ̀, ó mú ìborùn kúrò, ó sì wọ aṣọ opó rẹ̀.

20 Júdà fi ọmọ ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀ ará Ádúlámù,+ kó bàa lè gba ohun tó fi ṣe ìdúró pa dà lọ́wọ́ obìnrin náà, àmọ́ kò rí i. 21 Ó bi àwọn tó ń gbé ibi tí obìnrin náà wà pé: “Ibo ni aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì tó wà ní Énáímù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà yẹn wà?” Àmọ́ wọ́n fèsì pé: “Aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì kankan ò sí níbí yìí rí.” 22 Níkẹyìn, ó pa dà sọ́dọ̀ Júdà, ó sì sọ pé: “Mi ò rí i, àwọn èèyàn ibẹ̀ náà sọ pé, ‘Aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì kankan ò sí níbí yìí rí.’” 23 Júdà wá sọ pé: “Jẹ́ kó máa mú un lọ, ká má bàa di ẹni àbùkù. Mo kúkú ti fi ọmọ ewúrẹ́ yìí ránṣẹ́, ṣùgbọ́n o ò rí obìnrin náà.”

24 Àmọ́, ní nǹkan bí oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n sọ fún Júdà pé: “Támárì ìyàwó ọmọ rẹ ṣe aṣẹ́wó, ó sì ti lóyún nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ṣe.” Ni Júdà bá sọ pé: “Ẹ mú un jáde ká sì sun ún.”+ 25 Nígbà tí wọ́n mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí bàbá ọkọ rẹ̀ pé: “Ọkùnrin tó ni àwọn nǹkan yìí ló fún mi lóyún.” Ó tún sọ pé: “Jọ̀ọ́, wo òrùka èdìdì yìí, okùn àti ọ̀pá+ yìí kí o lè mọ ẹni tó ni ín.” 26 Ni Júdà bá yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì sọ pé: “Òdodo rẹ̀ ju tèmi lọ, torí mi ò fún un ní Ṣélà ọmọ mi.”+ Kò sì bá a lò pọ̀ mọ́ lẹ́yìn ìyẹn.

27 Nígbà tó tó àkókò tó máa bímọ, ìbejì ló wà nínú rẹ̀. 28 Bó ṣe ń bímọ, ọ̀kan na ọwọ́ jáde, ni agbẹ̀bí bá mú òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, ó sì so ó mọ́ ọwọ́ rẹ̀, ó ní: “Èyí ló kọ́kọ́ jáde.” 29 Àmọ́ bó ṣe fa ọwọ́ rẹ̀ pa dà, arákùnrin rẹ̀ jáde, obìnrin náà sì sọ pé: “Wo bí o ṣe dọ́gbẹ́ sí ìyá rẹ lára kí o tó lè jáde!” Torí náà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Pérésì.*+ 30 Lẹ́yìn náà, arákùnrin rẹ̀ jáde, òun ni wọ́n so òwú pupa mọ́ lọ́wọ́, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Síírà.+

39 Wọ́n wá mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì,+ Pọ́tífárì+ ará Íjíbítì tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin Fáráò àti olórí ẹ̀ṣọ́ sì rà á lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì+ tó mú un lọ síbẹ̀. 2 Àmọ́ Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù.+ Ìyẹn mú kó ṣàṣeyọrí, ọ̀gá rẹ̀ tó jẹ́ ará Íjíbítì sì fi ṣe alábòójútó ilé rẹ̀. 3 Ọ̀gá rẹ̀ sì rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀ àti pé Jèhófà ń mú kí gbogbo ohun tó ń ṣe yọrí sí rere.

4 Jósẹ́fù máa ń rí ojúure rẹ̀, ó sì di ìránṣẹ́ Pọ́tífárì fúnra rẹ̀. Ó wá fi ṣe olórí ilé rẹ̀, ó sì ní kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní òun. 5 Látìgbà tí ọ̀gá rẹ̀ ti fi ṣe olórí ilé rẹ̀, tó sì ń bójú tó gbogbo ohun tó ní, Jèhófà ń bù kún ilé ará Íjíbítì náà torí Jósẹ́fù. Jèhófà sì bù kún gbogbo ohun ìní Pọ́tífárì nílé lóko.+ 6 Nígbà tó yá, ó fi gbogbo ohun tó ní sí ìkáwọ́ Jósẹ́fù, kò sì da ara rẹ̀ láàmú nípa ohunkóhun àfi oúnjẹ tó ń jẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Jósẹ́fù taagun, ó sì rẹwà.

7 Lẹ́yìn náà, ojú ìyàwó ọ̀gá Jósẹ́fù kò kúrò lára rẹ̀, ó sì ń sọ fún un pé: “Wá bá mi sùn.” 8 Àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà, ó sì sọ fún ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ọ̀gá mi kì í yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò nínú ilé, ó sì ti fa gbogbo ohun tó ní lé mi lọ́wọ́. 9 Kò sẹ́ni tó tóbi jù mí lọ nínú ilé yìí, kò sì fawọ́ ohunkóhun sẹ́yìn fún mi àyàfi ìwọ, torí pé ìwọ ni ìyàwó rẹ̀. Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?”+

10 Ojoojúmọ́ ló ń bá Jósẹ́fù sọ ọ́, àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà rárá láti bá a sùn tàbí kó wà pẹ̀lú rẹ̀. 11 Lọ́jọ́ kan tí Jósẹ́fù wọnú ilé lọ ṣiṣẹ́ rẹ̀, kò sí ìránṣẹ́ ilé kankan nínú ilé. 12 Obìnrin náà di aṣọ rẹ̀ mú, ó sì sọ pé: “Wá bá mi sùn!” Àmọ́ Jósẹ́fù fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì sá jáde. 13 Bí obìnrin náà ṣe rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, tó sì ti sá jáde, 14 ó bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe àwọn èèyàn tó wà nílé, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Ó mú ọkùnrin Hébérù yìí wá sọ́dọ̀ wa kó lè fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wá bá mi, ó fẹ́ bá mi sùn, àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí í ké tantan. 15 Bó ṣe wá rí i pé mò ń pariwo, tí mo sì ń kígbe, ó fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sá jáde.” 16 Lẹ́yìn náà, obìnrin náà fi aṣọ Jósẹ́fù sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ títí ọ̀gá rẹ̀ fi dé sí ilé.

17 Ó sọ ohun kan náà fún un, ó ní: “Ìránṣẹ́ Hébérù tí o mú wá sọ́dọ̀ wa wá bá mi kó lè fi mí ṣe ẹlẹ́yà. 18 Àmọ́ gbàrà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, tí mo sì kígbe, ó fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sá jáde.” 19 Gbàrà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ohun tí ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Ohun tí ìránṣẹ́ rẹ ṣe sí mi nìyí,” inú bí i gan-an. 20 Ni ọ̀gá Jósẹ́fù bá ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí wọ́n ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí, ó sì wà níbẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n.+

21 Àmọ́ Jèhófà ò fi Jósẹ́fù sílẹ̀, ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí i, ó sì ń mú kó rí ojúure ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n+ náà. 22 Ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wá fi Jósẹ́fù ṣe olórí gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú ẹ̀wọ̀n, òun ló sì máa ń rí sí i pé wọ́n ṣe gbogbo iṣẹ́ tó wà níbẹ̀.+ 23 Ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ò yẹ Jósẹ́fù lọ́wọ́ wò rárá, torí Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, Jèhófà sì ń mú kí gbogbo ohun tó bá ṣe yọrí sí rere.+

40 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, olórí agbọ́tí+ ọba Íjíbítì àti olórí alásè* ṣẹ ọba Íjíbítì tó jẹ́ olúwa wọn. 2 Fáráò wá bínú sí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ méjèèjì, ìyẹn olórí agbọ́tí àti olórí alásè,+ 3 ó sì jù wọ́n sí ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́,+ níbi tí Jósẹ́fù ti ń ṣẹ̀wọ̀n.+ 4 Olórí ẹ̀ṣọ́ wá yan Jósẹ́fù pé kó wà pẹ̀lú wọn, kó sì máa bójú tó wọn.+ Wọ́n sì wà lẹ́wọ̀n fúngbà díẹ̀.*

5 Agbọ́tí àti alásè ọba Íjíbítì tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n lá àlá ní alẹ́ ọjọ́ kan náà, àlá tí kálukú wọn lá sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. 6 Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, nígbà tí Jósẹ́fù wọlé, ó rí i pé inú wọn ò dùn. 7 Ó wá bi àwọn òṣìṣẹ́ Fáráò tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n ní ilé ọ̀gá rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ fajú ro lónìí?” 8 Wọ́n fèsì pé: “Kálukú wa lá àlá, àmọ́ kò sẹ́ni tó máa túmọ̀ rẹ̀ fún wa.” Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Ṣebí Ọlọ́run+ ló ni ìtúmọ̀? Ẹ jọ̀ọ́, ẹ rọ́ àlá yín fún mi.”

9 Olórí agbọ́tí sì rọ́ àlá tó lá fún Jósẹ́fù, ó ní: “Mo rí igi àjàrà kan lójú àlá. 10 Ẹ̀ka mẹ́ta wà lórí igi àjàrà náà. Bí ọ̀mùnú rẹ̀ ṣe ń yọ, ó yọ òdòdó, òṣùṣù èso àjàrà rẹ̀ sì pọ́n. 11 Ife Fáráò wà lọ́wọ́ mi, mo mú àwọn èso àjàrà náà, mo fún un sínú ife Fáráò, mo sì gbé ife náà fún Fáráò.” 12 Jósẹ́fù wá sọ fún un pé: “Ìtúmọ̀ rẹ̀ nìyí: Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta. 13 Lọ́jọ́ mẹ́ta òní, Fáráò máa mú ọ jáde,* ó máa dá ọ pa dà sẹ́nu iṣẹ́+ rẹ, wàá sì máa gbé ife fún Fáráò bí o ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ nígbà tí o jẹ́ agbọ́tí+ rẹ̀. 14 Àmọ́ kí o rántí mi tí nǹkan bá ti ṣẹnuure fún ọ. Jọ̀ọ́, fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi, kí o sì sọ̀rọ̀ mi fún Fáráò, kí n lè kúrò níbí. 15 Ṣe ni wọ́n jí mi gbé kúrò ní ilẹ̀ àwọn Hébérù,+ mi ò sì ṣe ohunkóhun níbí tó fi yẹ kí wọ́n jù mí sí ẹ̀wọ̀n.”*+

16 Nígbà tí olórí alásè rí i pé ìtúmọ̀ tí Jósẹ́fù ṣe dára, ó sọ fún un pé: “Èmi náà lá àlá. Apẹ̀rẹ̀ mẹ́ta tó ní búrẹ́dì funfun wà lórí mi nínú àlá náà. 17 Oríṣiríṣi oúnjẹ tí wọ́n yan tó jẹ́ ti Fáráò wà nínú apẹ̀rẹ̀ tó wà lókè pátápátá, àwọn ẹyẹ sì ń jẹ ẹ́ nínú apẹ̀rẹ̀ tó wà lórí mi.” 18 Jósẹ́fù wá sọ pé: “Ìtúmọ̀ rẹ̀ nìyí: Apẹ̀rẹ̀ mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta. 19 Lọ́jọ́ mẹ́ta òní, Fáráò yóò bẹ́ orí rẹ,* yóò gbé ọ kọ́ sórí òpó igi, àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ẹran ara rẹ.”+

20 Ọjọ́ kẹta wá jẹ́ ọjọ́ ìbí+ Fáráò, ó sì se àsè fún gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀, ó wá mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde* níṣojú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 21 Ó dá olórí agbọ́tí pa dà sí ipò tó wà tẹ́lẹ̀, ó sì ń gbé ife fún Fáráò. 22 Àmọ́, ó gbé olórí alásè kọ́, bí Jósẹ́fù ṣe túmọ̀ àlá wọn fún wọn.+ 23 Ṣùgbọ́n olórí agbọ́tí náà ò rántí Jósẹ́fù; ó ti gbàgbé rẹ̀.+

41 Lẹ́yìn ọdún méjì gbáko, Fáráò lá àlá+ pé òun dúró létí odò Náílì. 2 Màlúù méje tó rẹwà tó sì sanra ń jáde bọ̀ látinú odò náà, wọ́n sì ń jẹ koríko+ tó wà ní odò Náílì. 3 Lẹ́yìn náà, màlúù méje míì tí kò lẹ́wà, tó sì rù ń jáde bọ̀ látinú odò Náílì, wọ́n dúró létí odò Náílì lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn màlúù tó sanra. 4 Àwọn màlúù tí kò lẹ́wà, tó sì rù wá jẹ àwọn màlúù méje tó rẹwà, tó sì sanra ní àjẹrun. Ni Fáráò bá jí.

5 Ó pa dà lọ sùn, ó sì lá àlá míì. Ṣírí ọkà méje tó yọmọ dáadáa, tó sì dára+ jáde láti ara pòròpórò kan. 6 Lẹ́yìn náà, ṣírí ọkà méje tó tín-ín-rín, tí atẹ́gùn ìlà oòrùn sì ti jó gbẹ hù jáde. 7 Àwọn ṣírí ọkà tó tín-ín-rín náà wá ń gbé ṣírí ọkà méje tó yọmọ dáadáa, tó sì dára mì. Ni Fáráò bá jí, ó sì rí i pé àlá ni òun lá.

8 Àmọ́ nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀. Ó wá ránṣẹ́ pe gbogbo àlùfáà onídán nílẹ̀ Íjíbítì àti gbogbo àwọn amòye ilẹ̀ náà. Fáráò rọ́ àwọn àlá rẹ̀ fún wọn, àmọ́ kò sẹ́nì kankan tó lè túmọ̀ wọn fún Fáráò.

9 Ni olórí agbọ́tí bá sọ fún Fáráò pé: “Màá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi lónìí. 10 Fáráò bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó fi èmi àti olórí alásè+ sínú ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́. 11 Lẹ́yìn náà, àwa méjèèjì lá àlá ní alẹ́ ọjọ́ kan náà. Àlá tí kálukú wa lá ní ìtúmọ̀+ tirẹ̀. 12 Ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ Hébérù wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa, ìránṣẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́+ ni. Nígbà tí a rọ́ àlá wa fún un,+ ó túmọ̀ àlá kálukú fún un. 13 Bó ṣe túmọ̀ rẹ̀ fún wa gẹ́lẹ́ ló rí. Èmi pa dà sẹ́nu iṣẹ́ mi, àmọ́ wọ́n gbé ẹnì kejì kọ́.”+

14 Fáráò bá ránṣẹ́ pe Jósẹ́fù,+ wọ́n sì sáré mú un wá látinú ẹ̀wọ̀n.*+ Ó fá irun rẹ̀, ó pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọlé lọ bá Fáráò. 15 Fáráò sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mo lá àlá kan, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ pé tí wọ́n bá rọ́ àlá fún ọ, o lè túmọ̀ rẹ̀.”+ 16 Jósẹ́fù dá Fáráò lóhùn pé: “Mi ò já mọ́ nǹkan kan! Ọlọ́run yóò sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Fáráò.”+

17 Fáráò wá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Lójú àlá mi, mo dúró létí odò Náílì. 18 Màlúù méje tó rẹwà tó sì sanra ń jáde bọ̀ látinú odò náà, wọ́n sì ń jẹ koríko+ tó wà ní odò Náílì. 19 Lẹ́yìn náà, màlúù méje míì tí ìrísí wọn ò dáa, tí wọn ò lẹ́wà rárá, tí wọ́n sì rù ń jáde bọ̀. Mi ò rí irú màlúù tí ìrísí wọn burú tó bẹ́ẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 20 Àwọn màlúù tí kò dáa tí wọ́n sì rù kan egungun yẹn wá ń jẹ màlúù méje àkọ́kọ́ tó sanra ní àjẹrun. 21 Àmọ́ nígbà tí wọ́n jẹ wọ́n tán, kò sẹ́ni tó lè mọ̀ pé wọ́n jẹ nǹkan kan, torí kò hàn lára wọn. Ni mo bá jí.

22 “Lẹ́yìn ìyẹn, mo lá àlá pé ṣírí ọkà méje tó yọmọ dáadáa, tó sì dára+ jáde láti ara pòròpórò kan. 23 Lẹ́yìn náà, ṣírí ọkà méje tó ti rọ, tó tín-ín-rín, tí atẹ́gùn ìlà oòrùn sì ti jó gbẹ hù jáde. 24 Àwọn ṣírí ọkà tín-ín-rín náà wá ń gbé ṣírí ọkà méje tó dára mì. Mo ti rọ́ àlá yìí fún àwọn àlùfáà onídán,+ àmọ́ kò sẹ́ni tó lè sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi.”+

25 Jósẹ́fù sọ fún Fáráò pé: “Ọ̀kan náà ni àwọn àlá Fáráò, ohun kan náà ni wọ́n sì túmọ̀ sí. Ọlọ́run tòótọ́ ti jẹ́ kí Fáráò mọ ohun tí òun fẹ́ ṣe.+ 26 Màlúù méje tó dára náà dúró fún ọdún méje. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ṣírí ọkà méje tó dára dúró fún ọdún méje. Ọ̀kan náà ni àwọn àlá náà, ohun kan náà ni wọ́n sì túmọ̀ sí. 27 Màlúù méje tó rù kan egungun, tí wọn ò sì dáa tí wọ́n jáde wá lẹ́yìn wọn dúró fún ọdún méje. Àwọn òfìfo ṣírí ọkà méje tí atẹ́gùn ìlà oòrùn ti jó gbẹ yóò jẹ́ ọdún méje ìyàn. 28 Bó ṣe rí ni mo sọ fún Fáráò: Ọlọ́run tòótọ́ ti fi ohun tó fẹ́ ṣe han Fáráò.

29 “Ọdún méje ni nǹkan yóò fi pọ̀ rẹpẹtẹ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 30 Àmọ́ lẹ́yìn ìyẹn, ó dájú pé ìyàn máa mú fún ọdún méje. Ó dájú pé gbogbo ohun tó pọ̀ rẹpẹtẹ nílẹ̀ Íjíbítì yóò di ohun ìgbàgbé, ìyàn yóò sì run ilẹ̀+ náà. 31 Wọn ò sì ní rántí ìgbà tí nǹkan pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ náà torí ìyàn tó máa mú, torí pé ìyàn náà á mú gidigidi. 32 Ẹ̀ẹ̀mejì ni Fáráò lá àlá yìí torí pé Ọlọ́run tòótọ́ ti fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ gbọn-in, Ọlọ́run tòótọ́ yóò sì mú kó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.

33 “Ní báyìí, kí Fáráò wá ọkùnrin kan tó jẹ́ olóye, tó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kó fi ṣe olórí ilẹ̀ Íjíbítì. 34 Kí Fáráò ṣe nǹkan kan lórí ọ̀rọ̀ yìí, kó yan àwọn alábòójútó ní ilẹ̀ náà, kó sì gba ìdá márùn-ún irè oko ilẹ̀ Íjíbítì ní ọdún méje tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ+ bá fi wà. 35 Kí wọ́n kó gbogbo oúnjẹ jọ ní àwọn ọdún tó ń bọ̀ yìí tí nǹkan máa ṣẹnuure, kí Fáráò sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà tí wọ́n á jẹ pa mọ́ sí àwọn ìlú, kí wọ́n sì tọ́jú rẹ̀.+ 36 Oúnjẹ yẹn ni kí wọ́n máa jẹ nígbà tí ìyàn bá mú fún ọdún méje ní ilẹ̀ Íjíbítì, kí ìyàn+ má bàa run ilẹ̀ náà.”

37 Ohun tó sọ yìí dára lójú Fáráò àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 38 Torí náà, Fáráò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ ọkùnrin míì wà tó ní ẹ̀mí Ọlọ́run bí ẹni yìí?” 39 Ni Fáráò bá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló jẹ́ kí o mọ gbogbo èyí, kò sí ẹni tó lóye, tó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n bíi tìẹ. 40 Ìwọ ni màá fi ṣe olórí ilé mi, gbogbo àwọn èèyàn mi yóò sì máa ṣègbọràn sí ọ délẹ̀délẹ̀.+ Ipò ọba* mi nìkan ni màá fi jù ọ́ lọ.” 41 Fáráò tún sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 42 Fáráò wá bọ́ òrùka àṣẹ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi sí ọwọ́ Jósẹ́fù. Ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa fún un, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. 43 Ó tún mú kí ó gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ kejì tó lọ́lá, ó sì ní kí wọ́n máa kígbe níwájú rẹ̀ pé, “Áfírékì!”* Bó ṣe fi Jósẹ́fù ṣe olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì nìyẹn.

44 Fáráò tún sọ fún Jósẹ́fù pé: “Èmi ni Fáráò, àmọ́ ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun* ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì,+ láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i.” 45 Lẹ́yìn náà, Fáráò sọ Jósẹ́fù ní Safenati-pánéà, ó sì fún un ní Ásénátì+ ọmọ Pọ́tíférà àlùfáà Ónì* pé kó fi ṣe aya. Jósẹ́fù wá bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó* ilẹ̀ Íjíbítì.+ 46 Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún+ ni Jósẹ́fù nígbà tó dúró níwájú* Fáráò ọba Íjíbítì.

Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù kúrò níwájú Fáráò, ó sì lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 47 Ní ọdún méje tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ fi wà, ilẹ̀ náà méso jáde wọ̀ǹtìwọnti.* 48 Ó sì ń kó gbogbo oúnjẹ jọ ní ilẹ̀ Íjíbítì fún ọdún méje náà, ó ń kó oúnjẹ pa mọ́ sí àwọn ìlú. Ó máa ń kó àwọn irè oko agbègbè ìlú kọ̀ọ̀kan pa mọ́ sí ìlú náà. 49 Jósẹ́fù sì ń kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà pa mọ́, ó pọ̀ bí iyanrìn etíkun, débi pé wọn ò lè wọ̀n ọ́n torí kò ṣeé wọ̀n mọ́.

50 Jósẹ́fù+ ti bí ọmọkùnrin méjì kí ìyàn tó bẹ̀rẹ̀ sí í mú. Ásénátì ọmọ Pọ́tíférà àlùfáà Ónì* ló bí àwọn ọmọ náà fún un. 51 Jósẹ́fù sọ àkọ́bí rẹ̀ ní Mánásè,*+ torí ó sọ pé, “Ọlọ́run ti mú kí n gbàgbé gbogbo ìdààmú tó bá mi àti gbogbo ilé bàbá mi.” 52 Ó sì sọ èkejì ní Éfúrémù,*+ torí ó sọ pé, “Ọlọ́run ti mú kí n di púpọ̀ ní ilẹ̀ tí mo ti jìyà.”+

53 Ọdún méje tí nǹkan fi pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Íjíbítì wá dópin,+ 54 ìyàn ọdún méje sì bẹ̀rẹ̀, bí Jósẹ́fù ṣe sọ.+ Ìyàn mú ní gbogbo àwọn ilẹ̀, àmọ́ oúnjẹ*+ wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 55 Àmọ́ nígbà tó yá, ìyàn náà dé gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Fáráò pé kó fún àwọn ní oúnjẹ.+ Fáráò wá sọ fún gbogbo ará Íjíbítì pé: “Ẹ lọ bá Jósẹ́fù, kí ẹ sì ṣe ohunkóhun tó bá sọ.”+ 56 Ìyàn náà kò dáwọ́ dúró ní gbogbo ilẹ̀.+ Jósẹ́fù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí gbogbo ibi tó kó ọkà pa mọ́ sí láwọn ìlú náà, ó sì ń tà á fún àwọn ará Íjíbítì+ torí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ Íjíbítì. 57 Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo sì ń lọ sí Íjíbítì kí wọ́n lè ra oúnjẹ lọ́dọ̀ Jósẹ́fù torí ìyàn náà mú gidigidi ní gbogbo ilẹ̀.+

42 Nígbà tí Jékọ́bù gbọ́ pé ọkà wà ní Íjíbítì,+ ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ kàn ń wo ara yín lójú?” 2 Ó ní: “Mo ti gbọ́ pé ọkà wà ní Íjíbítì. Ẹ lọ rà á wá níbẹ̀ fún wa, ká lè wà láàyè, ká má bàa kú.”+ 3 Mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin+ Jósẹ́fù wá lọ ra ọkà ní Íjíbítì. 4 Àmọ́ Jékọ́bù ò jẹ́ kí Bẹ́ńjámínì+ àbúrò Jósẹ́fù tẹ̀ lé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yòókù, torí ó sọ pé: “Jàǹbá lè lọ ṣe é.”+

5 Àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì lọ pẹ̀lú àwọn míì tí wọ́n fẹ́ ra oúnjẹ, torí pé ìyàn náà ti dé ilẹ̀ Kénáánì.+ 6 Jósẹ́fù ló ní àṣẹ lórí ilẹ̀+ Íjíbítì, òun ló sì ń ta ọkà fún gbogbo èèyàn tó wà láyé.+ Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù dé, wọ́n tẹrí ba fún un, wọ́n sì wólẹ̀.+ 7 Ojú ẹsẹ̀ tí Jósẹ́fù rí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ló dá wọn mọ̀, àmọ́ kò jẹ́ kí wọ́n+ mọ̀ pé òun ni. Ó wá fi ohùn líle bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní: “Ibo lẹ ti wá?” Wọ́n fèsì pé: “Ilẹ̀ Kénáánì la ti wá, ká lè ra oúnjẹ.”+

8 Jósẹ́fù dá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ̀, àmọ́ wọn ò dá a mọ̀. 9 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jósẹ́fù rántí àwọn àlá tó lá nípa wọn, ó sì sọ fún wọn+ pé: “Amí ni yín! Ṣe lẹ wá wo ibi tí ẹ ti lè gbógun ja ilẹ̀ wa!”* 10 Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “Rárá olúwa mi, oúnjẹ ni àwa ìránṣẹ́ rẹ wá rà. 11 Ọmọ bàbá kan náà ni gbogbo wa. Olódodo ni wá. Àwa ìránṣẹ́ rẹ kì í ṣe amí.” 12 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Irọ́ lẹ̀ ń pa! Ṣe lẹ wá wo ibi tí ẹ ti lè gbógun ja ilẹ̀ wa!” 13 Ni wọ́n bá sọ pé: “Ọkùnrin méjìlá (12) ni àwa ìránṣẹ́ rẹ.+ Ọmọ bàbá kan+ náà ni wá, ilẹ̀ Kénáánì sì ni bàbá+ wa wà. Àbúrò wa tó kéré jù wà lọ́dọ̀ bàbá wa, àmọ́ àbúrò wa kejì ò sí mọ́.”+

14 Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Bí mo ṣe sọ ló rí, mo ní, ‘Amí ni yín!’ 15 Ohun tí màá fi dán yín wò nìyí: Bí Fáráò ti wà láàyè, ẹ ò ní kúrò níbí àfi tí àbúrò yín tó kéré jù bá wá síbí.+ 16 Ẹ rán ọ̀kan nínú yín kó lọ mú àbúrò yín wá, àmọ́ ẹ̀yin máa wà nínú ẹ̀wọ̀n níbí. Ohun tí màá fi mọ̀ nìyẹn bóyá òótọ́ lẹ̀ ń sọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, bí Fáráò ti wà láàyè, amí ni yín.” 17 Ló bá tì wọ́n mọ́lé fún ọjọ́ mẹ́ta.

18 Ní ọjọ́ kẹta, Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Mo bẹ̀rù Ọlọ́run, torí náà, ohun tí mo bá sọ ni kí ẹ ṣe, kí ẹ lè wà láàyè. 19 Tí ẹ bá jẹ́ olódodo, ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín wà ní àtìmọ́lé níbí, àmọ́ kí ẹ̀yin tó kù máa lọ, kí ẹ sì gbé ọkà dání kí agbo ilé+ yín lè rí nǹkan jẹ. 20 Kí ẹ wá mú àbúrò yín tó kéré jù wá sọ́dọ̀ mi, kí n lè rí i pé òótọ́ lẹ̀ ń sọ, ẹ ò sì ní kú.” Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.

21 Wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ó dájú pé torí Jósẹ́fù+ ni ìyà yìí ṣe ń jẹ wá, torí a rí ìdààmú tó bá a* nígbà tó bẹ̀ wá pé ká yọ́nú sí òun, àmọ́ a ò dá a lóhùn. Ìdí nìyẹn tí wàhálà yìí fi dé bá wa.” 22 Ni Rúbẹ́nì bá sọ fún wọn pé: “Ṣebí mo sọ fún yín pé, ‘Ẹ má ṣẹ ọmọ náà,’ àmọ́ ṣé ẹ dá mi lóhùn?+ Ẹ̀san+ ti wá dé báyìí torí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.” 23 Àmọ́ wọn ò mọ̀ pé Jósẹ́fù gbọ́ èdè wọn torí ògbufọ̀ ló ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 24 Ló bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.+ Nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ wọn, tó sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, ó mú Síméónì+ láàárín wọn, ó sì dè é níṣojú+ wọn. 25 Jósẹ́fù wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi ọkà kún àwọn àpò wọn, kí wọ́n dá owó kálukú pa dà sínú àpò rẹ̀, kí wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọ́n á jẹ lójú ọ̀nà. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn.

26 Torí náà, wọ́n kó ọkà wọn sórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì kúrò níbẹ̀. 27 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn ṣí àpò rẹ̀ kó lè fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ níbi tí wọ́n dé sí, ó rí owó rẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀. 28 Ló bá sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Wọ́n dá owó mi pa dà, òun ló wà nínú àpò mi yìí!” Ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n kọjú síra wọn, wọ́n sì sọ pé: “Kí ni Ọlọ́run ṣe sí wa yìí?”

29 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jékọ́bù bàbá wọn ní ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn fún un, wọ́n ní: 30 “Ọkùnrin tó jẹ́ olórí ilẹ̀ náà fi ohùn líle bá wa sọ̀rọ̀,+ ó sì fẹ̀sùn kàn wá pé amí la wá ṣe ní ilẹ̀ wọn. 31 Àmọ́ a sọ fún un pé, ‘Olódodo ni wá. A kì í ṣe amí.+ 32 Ọkùnrin méjìlá (12)+ ni wá, ọmọ bàbá kan náà ni wá. Ọ̀kan ò sí mọ́,+ àbúrò wa tó kéré jù sì wà lọ́dọ̀ bàbá wa báyìí ní ilẹ̀ Kénáánì.’+ 33 Àmọ́ ọkùnrin tó jẹ́ olórí ilẹ̀ náà sọ fún wa pé, ‘Ohun tí màá fi mọ̀ pé olódodo ni yín ni pé: Ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín dúró sọ́dọ̀ mi.+ Kí ẹ sì máa lọ,+ kí ẹ mú nǹkan dání kí agbo ilé yín lè rí nǹkan jẹ. 34 Kí ẹ sì mú àbúrò yín tó kéré jù wá sọ́dọ̀ mi, kí n lè mọ̀ pé olódodo ni yín, pé ẹ kì í ṣe amí. Màá wá dá arákùnrin yín pa dà fún yín, ẹ sì lè máa ṣòwò ní ilẹ̀ yìí.’”

35 Bí wọ́n ṣe ń kó ẹrù inú àpò wọn jáde, àpò owó kálukú wà nínú rẹ̀. Nígbà tí àwọn àti bàbá wọn rí àpò owó wọn, ẹ̀rù bà wọ́n. 36 Jékọ́bù bàbá wọn wá sọ fún wọn pé: “Èmi ni ẹ mú kí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀!+ Jósẹ́fù ò sí mọ́,+ Síméónì náà ò sí mọ́,+ ẹ tún fẹ́ mú Bẹ́ńjámínì lọ! Èmi ni gbogbo nǹkan yìí wá ṣẹlẹ̀ sí!” 37 Àmọ́ Rúbẹ́nì sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “O lè pa àwọn ọmọkùnrin mi méjèèjì tí mi ò bá mú un pa dà wá bá ọ.+ Fà á lé mi lọ́wọ́, màá sì mú un pa dà wá bá ọ.”+ 38 Àmọ́ ó sọ pé: “Ọmọ mi ò ní bá yín lọ, torí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ló sì ṣẹ́ kù.+ Bí jàǹbá bá lọ ṣe é ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, ó dájú pé ẹ ó mú kí n ṣọ̀fọ̀+ wọnú Isà Òkú*+ pẹ̀lú ewú orí mi.”

43 Ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀+ náà. 2 Torí náà, nígbà tí wọ́n jẹ ọkà tí wọ́n gbé wá láti Íjíbítì+ tán, bàbá wọn sọ fún wọn pé: “Ẹ pa dà lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá fún wa.” 3 Júdà wá sọ fún un pé: “Ọkùnrin náà ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ tún fojú kàn mí mọ́ àfi tí ẹ bá mú àbúrò yín dání.’+ 4 Tí o bá jẹ́ kí àbúrò wa bá wa lọ, a máa lọ síbẹ̀, a sì máa ra oúnjẹ wá fún ọ. 5 Àmọ́ tí o ò bá jẹ́ kó bá wa lọ, a ò ní lọ, torí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ tún fojú kàn mí mọ́ àfi tí ẹ bá mú àbúrò yín dání.’”+ 6 Ísírẹ́lì+ wá bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ sọ fún ọkùnrin náà pé ẹ ní àbúrò míì, tí ẹ sì fi ìyẹn fa wàhálà yìí bá mi?” 7 Wọ́n fèsì pé: “Ọkùnrin náà bi wá nípa ara wa àti àwọn mọ̀lẹ́bí wa pé, ‘Ṣé bàbá yín ṣì wà láàyè? Ṣé ẹ ní arákùnrin míì?’ A sì sọ òótọ́ fún un.+ Báwo la ṣe fẹ́ mọ̀ pé yóò sọ pé, ‘Ẹ mú àbúrò yín wá’?”+

8 Júdà wá rọ Ísírẹ́lì bàbá rẹ̀ pé: “Jẹ́ kí ọmọ náà bá mi lọ,+ sì jẹ́ ká máa lọ ká lè wà láàyè, ká má bàa kú,+ àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ+ wa. 9 Mo fi dá ọ lójú pé kò sóhun tó máa ṣe ọmọ náà.*+ Ọwọ́ mi ni kí o ti béèrè rẹ̀. Tí mi ò bá mú un pa dà wá bá ọ, kí n sì fà á lé ọ lọ́wọ́, a jẹ́ pé mo ti ṣẹ̀ ọ́ títí láé nìyẹn. 10 Tí kì í bá ṣe pé a fi falẹ̀ ni, à bá ti lọ ibẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì ká sì ti dé báyìí.”

11 Ísírẹ́lì bàbá wọn wá sọ fún wọn pé: “Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ẹ kó àwọn ohun tó dáa jù ní ilẹ̀ yìí sínú àwọn àpò yín, kí ẹ gbé e lọ fún ọkùnrin náà bí ẹ̀bùn:+ básámù+ díẹ̀, oyin díẹ̀, gọ́ọ̀mù lábídánọ́mù, èèpo+ igi olóje, ẹ̀pà pítáṣíò àti álímọ́ńdì. 12 Ẹ mú owó ìlọ́po méjì dání; kí ẹ sì mú owó tí wọ́n dá pa dà sí ẹnu àpò+ yín dání. Bóyá àṣìṣe ni. 13 Ẹ mú àbúrò yín, kí ẹ sì máa lọ, ẹ pa dà sọ́dọ̀ ọkùnrin náà. 14 Kí Ọlọ́run Olódùmarè mú kí ọkùnrin náà ṣàánú yín, kó lè fi arákùnrin yín kan tó kù àti Bẹ́ńjámínì sílẹ̀. Àmọ́ ní tèmi, tó bá jẹ́ pé ọ̀fọ̀ yóò ṣẹ̀ mí+ lóòótọ́, kó ṣẹ̀ mí!”

15 Àwọn ọkùnrin náà wá mú ẹ̀bùn yìí, wọ́n mú owó ìlọ́po méjì, wọ́n sì mú Bẹ́ńjámínì dání. Wọ́n gbéra, wọ́n forí lé Íjíbítì, wọ́n sì tún lọ síwájú Jósẹ́fù.+ 16 Nígbà tí Jósẹ́fù rí Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú wọn, ojú ẹsẹ̀ ló sọ fún ọkùnrin tó ń bójú tó ilé rẹ̀ pé: “Mú àwọn ọkùnrin náà lọ sínú ilé, kí o pa ẹran, kí o sì se oúnjẹ, torí àwọn ọkùnrin náà yóò bá mi jẹun ní ọ̀sán.” 17 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkùnrin náà ṣe ohun tí Jósẹ́fù sọ,+ ó sì mú wọn lọ sí ilé Jósẹ́fù. 18 Àmọ́ ẹ̀rù ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Jósẹ́fù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Torí owó tí wọ́n dá pa dà sínú àpò wa nígbà yẹn ni wọ́n ṣe mú wa wá síbí. Wọ́n máa wá gbéjà kò wá, wọ́n á sọ wá di ẹrú, wọ́n á sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ wa!”

19 Torí náà, wọ́n lọ bá ọkùnrin tó ń bójú tó ilé Jósẹ́fù, wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ ní ẹnu ọ̀nà ilé náà. 20 Wọ́n ní: “Jọ̀ọ́, olúwa mi! A ti kọ́kọ́ wá ra oúnjẹ+ níbí. 21 Àmọ́ nígbà tí a dé ibi tí a fẹ́ wọ̀ sí, tí a sì ṣí àwọn àpò wa, a rí owó kálukú ní ẹnu àpò rẹ̀, gbogbo owó+ wa la bá níbẹ̀. Torí náà, a fẹ́ fi ọwọ́ ara wa dá a pa dà. 22 A sì tún mú owó wá sí i ká lè ra oúnjẹ. A ò mọ ẹni tó fi owó wa sínú àwọn àpò+ wa.” 23 Ọkùnrin náà sọ fún wọn pé: “Ó dáa. Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run yín àti Ọlọ́run bàbá yín ló fi ìṣúra sínú àpò yín. Èmi ni mo kọ́kọ́ gba owó yín.” Lẹ́yìn náà, ó mú Síméónì jáde wá bá wọn.+

24 Ọkùnrin náà wá mú wọn wá sínú ilé Jósẹ́fù, ó fún wọn ní omi kí wọ́n fi fọ ẹsẹ̀ wọn, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní oúnjẹ. 25 Wọ́n ṣètò ẹ̀bùn+ náà de Jósẹ́fù kó tó dé ní ọ̀sán, torí wọ́n ti gbọ́ pé àwọn máa jẹun níbẹ̀.+ 26 Nígbà tí Jósẹ́fù wọnú ilé, wọ́n gbé ẹ̀bùn wọn wá fún un nínú ilé, wọ́n sì wólẹ̀ fún un.+ 27 Lẹ́yìn náà, ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì bi wọ́n pé: “Bàbá yín tó ti dàgbà tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ ńkọ́? Ṣé ó ṣì wà láàyè?”+ 28 Wọ́n fèsì pé: “Àlàáfíà ni bàbá wa tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ wà. Ó ṣì wà láàyè.” Wọ́n wá tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀.+

29 Nígbà tó wòkè, tó sì rí Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀, ọmọ ìyá+ rẹ̀, ó bi wọ́n pé: “Ṣé àbúrò yín tó kéré jù tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi nìyí?”+ Ó sọ pé: “Kí Ọlọ́run ṣojúure sí ọ, ọmọ mi.” 30 Jósẹ́fù sáré jáde, torí ọkàn rẹ̀ fà sí àbúrò rẹ̀ débi pé kò lè mú un mọ́ra mọ́, ó sì wá ibì kan láti sunkún. Ó wọnú yàrá àdáni kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún níbẹ̀.+ 31 Lẹ́yìn náà, ó fọ ojú rẹ̀, ó sì jáde. Ó mọ́kàn le, ó sì sọ pé: “Ẹ gbé oúnjẹ wá.” 32 Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fún un lọ́tọ̀, tiwọn náà wà lọ́tọ̀, àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì jẹun lọ́tọ̀, torí àwọn ará Íjíbítì kò lè bá àwọn Hébérù jẹun, torí pé ohun ìríra ló jẹ́ lójú àwọn ará Íjíbítì.+

33 Àwọn arákùnrin rẹ̀* jókòó síwájú rẹ̀, látorí àkọ́bí tó ní ẹ̀tọ́ àkọ́bí+ dórí èyí tó kéré jù, wọ́n sì ń wo ara wọn tìyanutìyanu. 34 Ó sì ń bù lára oúnjẹ tó wà lórí tábìlì rẹ̀ fún wọn, àmọ́ ìlọ́po márùn-ún èyí tó bù fún àwọn yòókù+ ló ń bù fún Bẹ́ńjámínì. Wọ́n wá ń jẹun pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ń mu títí wọ́n fi jẹun yó.

44 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún ọkùnrin tó ń bójú tó ilé rẹ̀ pé: “Kó oúnjẹ sínú àpò àwọn ọkùnrin náà, kó sì kún dé ìwọ̀n tí wọ́n á lè gbé, kí o sì fi owó kálukú sí ẹnu àpò+ rẹ̀. 2 Àmọ́ kí o fi ife mi, ife fàdákà, sí ẹnu àpò ẹni tó kéré jù, pẹ̀lú owó ọkà rẹ̀.” Ó sì ṣe ohun tí Jósẹ́fù sọ.

3 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ dáadáa, wọ́n ní kí àwọn ọkùnrin náà máa lọ pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. 4 Wọn ò tíì rìn jìnnà sí ìlú náà nígbà tí Jósẹ́fù sọ fún ọkùnrin tó ń bójú tó ilé rẹ̀ pé: “Dìde! Lé àwọn ọkùnrin yẹn bá! Tí o bá dé ọ̀dọ̀ wọn, sọ fún wọn pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ibi san ire? 5 Ṣebí ohun tí ọ̀gá mi fi ń mu nǹkan nìyí, tó sì máa ń lò dáadáa láti fi woṣẹ́? Ìwà burúkú lẹ hù yìí.’”

6 Ó lé wọn bá, ó sì sọ bẹ́ẹ̀ fún wọn. 7 Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “Kí ló dé tí olúwa mi fi ń sọ̀rọ̀ báyìí? Ó dájú pé àwa ìránṣẹ́ rẹ ò lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. 8 Ṣebí a mú owó tí a rí lẹ́nu àpò wa pa dà wá fún ọ láti ilẹ̀ Kénáánì?+ Báwo la ṣe máa wá jí fàdákà tàbí wúrà ní ilé ọ̀gá rẹ? 9 Tí o bá rí i lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwa ẹrú rẹ, ṣe ni kí o pa onítọ̀hún, àwa yòókù náà yóò sì di ẹrú ọ̀gá mi.” 10 Ó wá sọ pé: “Kó rí bí ẹ ṣe sọ: Ẹni tí mo bá rí i nínú ẹrù rẹ̀ yóò di ẹrú mi, àmọ́ kò sóhun tó máa ṣe ẹ̀yin yòókù.” 11 Ni kálukú wọn bá yára sọ àpò rẹ̀ kalẹ̀, wọ́n sì ṣí i. 12 Ó fara balẹ̀ wá a, látorí ẹ̀gbọ́n pátápátá dórí ẹni tó kéré jù. Ó wá rí ife náà nínú àpò+ Bẹ́ńjámínì.

13 Ni wọ́n bá fa aṣọ wọn ya, kálukú wọn gbé ẹrù rẹ̀ pa dà sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, wọ́n sì pa dà sí ìlú náà. 14 Nígbà tí Júdà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ sínú ilé Jósẹ́fù, ó ṣì wà níbẹ̀; wọ́n sì wólẹ̀ síwájú rẹ̀.+ 15 Jósẹ́fù bi wọ́n pé: “Kí lẹ ṣe yìí? Ṣé ẹ ò mọ̀ pé èèyàn bíi tèmi mọ bí wọ́n ṣe ń woṣẹ́+ dáadáa ni?” 16 Ni Júdà bá fèsì pé: “Kí la lè sọ fún ọ̀gá mi? Ọ̀rọ̀ ò dùn lẹ́nu wa. Báwo la ṣe máa fi hàn pé a ò mọwọ́mẹsẹ̀? Ọlọ́run tòótọ́ ti fi àṣìṣe àwa ẹrú+ rẹ hàn. A ti wá di ẹrú ọ̀gá mi, àwa àti ẹni tí wọ́n rí ife náà lọ́wọ́ rẹ̀!” 17 Àmọ́ ó sọ pé: “Mi ò lè ṣe irú ẹ̀ láé! Ẹni tí wọ́n rí ife náà lọ́wọ́ rẹ̀ ni yóò di ẹrú mi.+ Kí ẹ̀yin yòókù máa pa dà lọ sọ́dọ̀ bàbá yín ní àlàáfíà.”

18 Júdà wá sún mọ́ ọn, ó sì sọ pé: “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀gá mi, jọ̀ọ́ jẹ́ kí ẹrú rẹ sọ̀rọ̀ kan létí ọ̀gá mi, má sì bínú sí ẹrú rẹ, torí bíi Fáráò lo jẹ́.+ 19 Ọ̀gá mi bi àwa ẹrú rẹ̀ pé, ‘Ṣé ẹ ní bàbá tàbí àbúrò?’ 20 A sì sọ fún ọ̀gá mi pé, ‘A ní bàbá tó ti darúgbó, ó sì bí ọmọ kan ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, òun ló kéré jù.+ Àmọ́ ẹ̀gbọ́n ọmọ náà ti kú,+ torí náà, òun ló ṣẹ́ kù nínú àwọn ọmọ ìyá+ rẹ̀, bàbá rẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.’ 21 Lẹ́yìn náà, o sọ fún àwa ẹrú rẹ pé, ‘Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi kí n lè rí i.’+ 22 Àmọ́ a sọ fún ọ̀gá mi pé, ‘Ọmọ náà ò lè fi bàbá rẹ̀ sílẹ̀. Tó bá fi í sílẹ̀, ó dájú pé bàbá rẹ̀ máa kú.’+ 23 O sọ fún àwa ẹrú rẹ pé, ‘Ẹ ò ní fojú kàn mí mọ́ àfi tí ẹ bá mú àbúrò yín tó kéré jù dání.’+

24 “A pa dà sọ́dọ̀ ẹrú rẹ tó jẹ́ bàbá mi, a sì sọ ohun tí ọ̀gá mi sọ fún un. 25 Lẹ́yìn náà, bàbá wa sọ pé, ‘Ẹ pa dà lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá fún wa.’+ 26 Àmọ́ a sọ pé, ‘A ò lè lọ. Tí àbúrò wa bá tẹ̀ lé wa, a máa lọ, torí a ò lè fojú kan ọkùnrin náà àfi tí àbúrò wa bá tẹ̀ lé wa lọ.’+ 27 Bàbá mi tó jẹ́ ẹrú rẹ wá sọ fún wa pé, ‘Ẹ mọ̀ dáadáa pé ọmọ méjì péré ni ìyàwó mi bí fún mi.+ 28 Àmọ́ ọ̀kan nínu wọn ti fi mí sílẹ̀, mo sì sọ pé: “Ó dájú pé ẹranko kan ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ!”+ mi ò sì tíì rí i títí di báyìí. 29 Tí ẹ bá tún mú eléyìí kúrò lọ́dọ̀ mi, tí jàǹbá sì lọ ṣe é, ó dájú pé ẹ máa mú ewú orí mi lọ sínú Isà Òkú*+ tòun ti àjálù.’+

30 “Tí mo bá wá pa dà sọ́dọ̀ bàbá mi tó jẹ́ ẹrú rẹ, láìmú ọmọ náà dání, tí ọkàn rẹ̀ sì ti fà mọ́ ọkàn ọmọ yìí, 31 tí kò bá wá rí ọmọ náà, ṣe ló máa kú, àwa ẹrú rẹ yóò sì mú kí bàbá wa tó jẹ́ ẹrú rẹ ṣọ̀fọ̀ wọnú Isà Òkú* pẹ̀lú orí ewú. 32 Ẹrú rẹ fi dá bàbá mi lójú nípa ọmọ náà pé, ‘Tí mi ò bá mú un pa dà wá bá ọ, á jẹ́ pé mo ti ṣẹ bàbá mi títí láé.’+ 33 Torí náà, jọ̀ọ́, jẹ́ kí ẹrú rẹ dúró kí n sì di ẹrú ọ̀gá mi dípò ọmọ náà, kí ọmọ náà lè bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pa dà. 34 Ṣé mo wá lè pa dà sọ́dọ̀ bàbá mi láìmú ọmọ náà dání? Mi ò ní lè wò ó tí àjálù yìí bá dé bá bàbá mi!”

45 Jósẹ́fù ò lè mú un mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀. Ló bá pariwo pé: “Kí gbogbo èèyàn kúrò lọ́dọ̀ mi!” Kò sẹ́nì kankan lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí Jósẹ́fù sọ bí òun ṣe jẹ́ fún àwọn arákùnrin+ rẹ̀.

2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, ohùn rẹ̀ sì lọ sókè débi pé àwọn ará Íjíbítì gbọ́, ilé Fáráò sì gbọ́. 3 Níkẹyìn, Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Èmi ni Jósẹ́fù. Ṣé bàbá mi ṣì wà láàyè?” Àmọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ ò lè dá a lóhùn rárá, torí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu. 4 Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sún mọ́ mi.” Ni wọ́n bá sún mọ́ ọn.

Ó sọ pé: “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín, tí ẹ tà sí Íjíbítì.+ 5 Àmọ́ ẹ má banú jẹ́, ẹ má sì bínú sí ara yín torí pé ẹ tà mí síbí; torí Ọlọ́run ti rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là.+ 6 Ọdún kejì tí ìyàn náà ti mú káàkiri nìyí,+ ó ṣì ku ọdún márùn-ún tí wọn ò ní túlẹ̀, tí wọn ò sì ní kórè. 7 Àmọ́ Ọlọ́run ti rán mi ṣáájú yín, kó lè mú kí ẹ ní àṣẹ́kù+ ní ayé,* kó sì gba ẹ̀mí yín là lọ́nà ìyanu. 8 Torí náà, ẹ̀yin kọ́ lẹ rán mi wá síbí, Ọlọ́run tòótọ́ ni, torí kó lè fi mí ṣe olórí agbani-nímọ̀ràn* fún Fáráò, kó sì fi mí ṣe olúwa lórí gbogbo ilé rẹ̀ àti olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+

9 “Ẹ tètè pa dà sọ́dọ̀ bàbá mi, kí ẹ sì sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jósẹ́fù ọmọ rẹ sọ nìyí: “Ọlọ́run ti fi mí ṣe olúwa lórí gbogbo Íjíbítì.+ Máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi. Tètè máa bọ̀.+ 10 Kí o máa gbé ilẹ̀ Góṣénì,+ kí o lè wà nítòsí mi, ìwọ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ, àwọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti gbogbo ohun tí o ní. 11 Èmi yóò máa fún ọ ní oúnjẹ níbẹ̀, torí ó ṣì ku ọdún márùn-ún tí ìyàn+ á fi mú. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ àti ilé rẹ máa di aláìní àti gbogbo ohun tí o ní.”’ 12 Ẹ̀yin àti Bẹ́ńjámínì àbúrò mi ti wá fojú ara yín rí i pé èmi gan-an ni mò ń bá yín sọ̀rọ̀.+ 13 Torí náà, kí ẹ sọ fún bàbá mi nípa gbogbo ògo tí mo ní nílẹ̀ Íjíbítì àti gbogbo ohun tí ẹ rí. Ó yá, ẹ tètè lọ mú bàbá mi wá síbí.”

14 Ó wá dì mọ́* Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀, ó sì bú sẹ́kún, Bẹ́ńjámínì náà dì mọ́ ọn lọ́rùn,+ ó sì sunkún. 15 Ó wá fi ẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ń sunkún bó ṣe ń dì mọ́ wọn, lẹ́yìn náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ bá a sọ̀rọ̀.

16 Ìròyìn dé ilé Fáráò pé: “Àwọn arákùnrin Jósẹ́fù ti dé!” Èyí dùn mọ́ Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú. 17 Fáráò wá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ẹ di ẹrù lé àwọn ẹran tí ẹ fi ń kẹ́rù, kí ẹ lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, 18 kí ẹ sì mú bàbá yín àti agbo ilé yín wá sọ́dọ̀ mi níbí. Màá fún yín ní àwọn ohun rere ilẹ̀ Íjíbítì, ẹ ó sì jẹ ohun tó dára jù* ní ilẹ̀ yìí.’+ 19 Mo sì pàṣẹ pé kí o sọ fún wọn pé:+ ‘Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ẹ kó àwọn kẹ̀kẹ́+ láti ilẹ̀ Íjíbítì torí àwọn ọmọ yín àti ìyàwó yín, kí ẹ sì fi ọ̀kan lára rẹ̀ gbé bàbá yín wá síbí.+ 20 Ẹ má da ara yín láàmú torí àwọn ohun ìní+ yín, torí ẹ̀yin lẹ ni gbogbo ohun tó dáa jù ní ilẹ̀ Íjíbítì.’”

21 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀, Jósẹ́fù fún wọn ní àwọn kẹ̀kẹ́ bí Fáráò ṣe pàṣẹ, ó tún fún wọn ní ohun tí wọ́n á jẹ lójú ọ̀nà. 22 Ó fún kálukú wọn ní aṣọ tuntun, àmọ́ ó fún Bẹ́ńjámínì ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ẹyọ fàdákà àti aṣọ+ tuntun márùn-ún. 23 Àwọn ohun tó fi ránṣẹ́ sí bàbá rẹ̀ nìyí: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tó gbé àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ Íjíbítì àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tó gbé ọkà àti búrẹ́dì àti ohun tí bàbá rẹ̀ máa jẹ lẹ́nu ìrìn àjò. 24 Ó wá ní kí àwọn arákùnrin rẹ̀ máa lọ, nígbà tí wọ́n sì ń lọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe bá ara yín jà lójú ọ̀nà.”+

25 Wọ́n kúrò ní Íjíbítì, wọ́n sì dé ilẹ̀ Kénáánì lọ́dọ̀ Jékọ́bù bàbá wọn. 26 Wọ́n ròyìn fún un pé: “Jósẹ́fù ò tíì kú, ó ti di olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì!”+ Àmọ́ ohun tí wọ́n sọ kò wọ Jékọ́bù lọ́kàn, torí kò gbà wọ́n gbọ́.+ 27 Nígbà tí wọ́n wá ń sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jósẹ́fù sọ fún wọn, tí Jékọ́bù sì wá rí àwọn kẹ̀kẹ́ tí Jósẹ́fù fi ránṣẹ́ pé kí wọ́n fi gbé e, ara Jékọ́bù bàbá wọn bẹ̀rẹ̀ sí í yá gágá. 28 Ísírẹ́lì sọ pé: “Ó tó! Jósẹ́fù ọmọ mi ò tíì kú! Mo gbọ́dọ̀ lọ rí i kí n tó kú!”+

46 Ísírẹ́lì bá kó gbogbo ohun tó ní,* ó sì gbéra. Nígbà tó dé Bíá-ṣébà,+ ó rúbọ sí Ọlọ́run Ísákì+ bàbá rẹ̀. 2 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ lójú ìran ní òru, ó ní: “Jékọ́bù, Jékọ́bù!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí!” 3 Ó sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run bàbá+ rẹ. Má bẹ̀rù láti lọ sí Íjíbítì, torí ibẹ̀ ni màá ti sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.+ 4 Èmi fúnra mi yóò bá ọ lọ sí Íjíbítì, èmi fúnra mi yóò sì mú ọ pa dà wá láti ibẹ̀,+ Jósẹ́fù yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú rẹ.”*+

5 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù kúrò ní Bíá-ṣébà, àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sì fi kẹ̀kẹ́ tí Fáráò fi ránṣẹ́ gbé Jékọ́bù bàbá wọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ìyàwó wọn. 6 Wọ́n kó agbo ẹran wọn àti ẹrù wọn dání, èyí tí wọ́n ti ní nílẹ̀ Kénáánì. Jékọ́bù àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ wá dé sí ilẹ̀ Íjíbítì. 7 Ó kó àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin dání wá sí Íjíbítì, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lóbìnrin. Gbogbo ọmọ rẹ̀ ló kó wá.

8 Orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tó wá sí Íjíbítì  + nìyí, Jékọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀: Rúbẹ́nì+ ni àkọ́bí Jékọ́bù.

9 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni Hánókù, Pálù, Hésírónì àti Kámì.+

10 Àwọn ọmọ Síméónì+ ni Jémúélì, Jámínì, Óhádì, Jákínì, Sóhárì àti Ṣéọ́lù+ ọmọ obìnrin ará Kénáánì.

11 Àwọn ọmọ Léfì+ ni Gẹ́ṣónì, Kóhátì àti Mérárì.+

12 Àwọn ọmọ Júdà+ ni Éérì, Ónánì, Ṣélà,+ Pérésì+ àti Síírà.+ Àmọ́ Éérì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénáánì.+

Àwọn ọmọ Pérésì ni Hésírónì àti Hámúlù.+

13 Àwọn ọmọ Ísákà ni Tólà, Púfà, Íóbù àti Ṣímúrónì.+

14 Àwọn ọmọ Sébúlúnì+ ni Sérédì, Élónì àti Jálíẹ́lì.+

15 Àwọn ni ọmọkùnrin tí Líà bí fún Jékọ́bù ní Padani-árámù, pẹ̀lú Dínà+ ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀* jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33).

16 Àwọn ọmọ Gádì+ ni Sífíónì, Hágì, Ṣúnì, Ésíbónì, Érì, Áródì àti Árélì.+

17 Àwọn ọmọkùnrin Áṣérì+ ni Ímúnà, Íṣífà, Íṣífì àti Bẹráyà, pẹ̀lú Sírà arábìnrin wọn.

Àwọn ọmọ Bẹráyà ni Hébà àti Málíkíélì.+

18 Àwọn ni ọmọ Sílípà,+ tí Lábánì fún Líà ọmọ rẹ̀. Ó bí wọn fún Jékọ́bù: gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún (16).*

19 Àwọn ọmọ Réṣẹ́lì ìyàwó Jékọ́bù ni Jósẹ́fù+ àti Bẹ́ńjámínì.+

20 Ásénátì+ ọmọ Pọ́tíférà àlùfáà Ónì* bí Mánásè+ àti Éfúrémù+ fún Jósẹ́fù ní ilẹ̀ Íjíbítì.

21 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì+ ni Bélà, Békérì, Áṣíbélì, Gérà,+ Náámánì, Éhì, Róṣì, Múpímù, Húpímù+ àti Áádì.+

22 Àwọn ni ọmọ tí Réṣẹ́lì bí fún Jékọ́bù: gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìnlá (14).*

23 Ọmọ* Dánì+ ni Húṣímù.+

24 Àwọn ọmọ Náfútálì+ ni Jáséélì, Gúnì, Jésérì àti Ṣílẹ́mù.+

25 Àwọn ni ọmọ Bílíhà, tí Lábánì fún Réṣẹ́lì ọmọ rẹ̀. Ó bí wọn fún Jékọ́bù: gbogbo wọn jẹ́ méje.*

26 Gbogbo ọmọ Jékọ́bù* tó bá a lọ sí Íjíbítì, yàtọ̀ sí ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin (66).+ 27 Ọmọ méjì* ni Jósẹ́fù bí ní Íjíbítì. Gbogbo ará* ilé Jékọ́bù tó wá sí Íjíbítì jẹ́ àádọ́rin (70).+

28 Jékọ́bù rán Júdà+ ṣáájú pé kó lọ sọ fún Jósẹ́fù pé òun ti wà lọ́nà Góṣénì. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Góṣénì,+ 29 Jósẹ́fù múra kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sílẹ̀, ó sì lọ pàdé Ísírẹ́lì bàbá rẹ̀ ní Góṣénì. Nígbà tó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó dì mọ́ ọn* lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì sunkún fúngbà díẹ̀.* 30 Ísírẹ́lì wá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mo lè wá kú báyìí; mo ti rí ojú rẹ, mo sì wá mọ̀ pé o ṣì wà láàyè.”

31 Jósẹ́fù wá sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti agbo ilé bàbá rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí n lọ bá Fáráò,+ kí n sì sọ fún un pé, ‘Àwọn arákùnrin mi àti agbo ilé bàbá mi láti ilẹ̀ Kénáánì ti wá bá mi níbí.+ 32 Olùṣọ́ àgùntàn+ ni wọ́n, wọ́n sì ní àwọn ẹran ọ̀sìn.+ Wọ́n ti kó agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn àti gbogbo ohun ìní wọn wá.’+ 33 Tí Fáráò bá pè yín, tó sì bi yín pé, ‘Iṣẹ́ wo lẹ̀ ń ṣe?’ 34 Kí ẹ sọ pé, ‘Àti kékeré ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ti ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn, àwa àti àwọn baba ńlá+ wa,’ kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ Góṣénì,+ torí àwọn ará Íjíbítì+ kórìíra gbogbo àwọn tó ń da àgùntàn.”

47 Jósẹ́fù wá lọ sọ fún Fáráò+ pé: “Bàbá mi àti àwọn arákùnrin mi, agbo ẹran wọn, ọ̀wọ́ ẹran wọn àti gbogbo ohun ìní wọn ti dé láti ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì ti wà ní ilẹ̀ Góṣénì.”+ 2 Ó mú márùn-ún lára àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ bá Fáráò.+

3 Fáráò bi àwọn arákùnrin Jósẹ́fù pé: “Iṣẹ́ wo lẹ̀ ń ṣe?” Wọ́n fèsì pé: “Olùṣọ́ àgùntàn ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, àwa àti àwọn baba ńlá+ wa.” 4 Wọ́n sọ fún Fáráò pé: “A wá gbé ilẹ̀+ yìí bí àjèjì torí kò sí ibi tí agbo ẹran àwa ìránṣẹ́ rẹ yóò ti máa jẹko, torí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ Kénáánì.+ Torí náà, jọ̀ọ́, jẹ́ kí àwa ìránṣẹ́ rẹ máa gbé ilẹ̀ Góṣénì.”+ 5 Ni Fáráò bá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Bàbá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ti wá bá ọ níbí. 6 Ilẹ̀ Íjíbítì wà ní ìkáwọ́ rẹ. Jẹ́ kí bàbá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ máa gbé ibi tó dáa jù ní ilẹ̀+ yìí. Kí wọ́n máa gbé nílẹ̀ Góṣénì. Tí o bá sì mọ àwọn tó dáńgájíá nínú wọn, jẹ́ kí wọ́n máa bójú tó ẹran ọ̀sìn mi.”

7 Jósẹ́fù wá mú Jékọ́bù bàbá rẹ̀ wọlé lọ bá Fáráò, Jékọ́bù sì súre fún Fáráò. 8 Fáráò bi Jékọ́bù pé: “Ẹni ọdún mélòó ni ọ́?” 9 Jékọ́bù sọ fún Fáráò pé: “Àádóje (130) ọdún ni mo fi ń lọ káàkiri.* Ọdún tí mo ti lò láyé kéré, ó sì kún fún wàhálà,+ kò gùn tó ọdún tí àwọn baba ńlá mi lò láyé nígbà tí wọ́n ń lọ káàkiri.”*+ 10 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù súre fún Fáráò, ó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

11 Jósẹ́fù wá mú kí bàbá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ máa gbé ilẹ̀ náà, ó sì fún wọn ní ohun ìní nílẹ̀ Íjíbítì, níbi tó dáa jù ní ilẹ̀ náà, ní ilẹ̀ Rámésésì,+ bí Fáráò ṣe pàṣẹ. 12 Jósẹ́fù sì ń pèsè oúnjẹ* fún bàbá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo agbo ilé bàbá rẹ̀, bí àwọn ọmọ wọn ṣe pọ̀ tó.

13 Kò sí oúnjẹ* ní gbogbo ilẹ̀ náà torí ìyàn náà mú gidigidi, ìyàn+ náà mú kí oúnjẹ tán pátápátá ní ilẹ̀ Íjíbítì àti Kénáánì. 14 Jósẹ́fù sì ń gba gbogbo owó tó wà nílẹ̀ Íjíbítì àti Kénáánì tí àwọn èèyàn fi ra+ ọkà, Jósẹ́fù sì ń kó owó náà wá sínú ilé Fáráò. 15 Nígbà tó yá, wọ́n náwó tán ní ilẹ̀ Íjíbítì àti Kénáánì, gbogbo àwọn ará Íjíbítì sì ń wá sọ́dọ̀ Jósẹ́fù, wọ́n ń sọ pé: “Fún wa ní oúnjẹ! Ṣé ó yẹ ká kú níṣojú rẹ torí pé owó ti tán lọ́wọ́ wa?” 16 Jósẹ́fù wá sọ pé: “Tí owó yín bá ti tán, ẹ mú ẹran ọ̀sìn yín wá, màá gbà á lọ́wọ́ yín, màá sì fi fún yín ní oúnjẹ.” 17 Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú ẹran ọ̀sìn wọn wá fún Jósẹ́fù. Jósẹ́fù ń gba ẹṣin, agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, ó sì ń fún àwọn èèyàn náà ní oúnjẹ. Ó ń fún wọn ní oúnjẹ dípò gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn tó gbà lọ́dún yẹn.

18 Nígbà tí ọdún yẹn parí, wọ́n wá bá a ní ọdún tó tẹ̀ lé e, wọ́n ń sọ fún un pé: “Ká má parọ́ fún olúwa mi, a ti kó owó wa àti ẹran ọ̀sìn wa fún olúwa mi. A ò ní nǹkan kan mọ́ tí a lè fún olúwa mi àyàfi ara wa àti ilẹ̀ wa. 19 Ṣé ó yẹ kí àwa àti ilẹ̀ wa kú níṣojú rẹ ni? Ra àwa àti ilẹ̀ wa, kí o fi fún wa lóúnjẹ, àwa yóò di ẹrú Fáráò, ilẹ̀ wa yóò sì di tirẹ̀. Fún wa ní irúgbìn ká lè wà láàyè, ká má bàa kú, kí ilẹ̀ wa má sì di ahoro.” 20 Jósẹ́fù wá bá Fáráò ra gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Íjíbítì, torí gbogbo ará Íjíbítì ló ta ilẹ̀ wọn, torí pé ìyàn náà mú gidigidi; ilẹ̀ náà sì wá di ti Fáráò.

21 Ó wá kó àwọn èèyàn náà lọ sínú àwọn ìlú, láti ìkángun ilẹ̀ Íjíbítì kan sí ìkejì.+ 22 Ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò rà,+ torí Fáráò ló ń fún àwọn àlùfáà ní oúnjẹ. Oúnjẹ tí Fáráò ń fún wọn ni wọ́n gbára lé. Ìdí nìyẹn tí wọn ò fi ta ilẹ̀ wọn. 23 Jósẹ́fù sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ wò ó, mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín fún Fáráò lónìí. Ẹ gba irúgbìn, kí ẹ sì gbìn ín sí ilẹ̀ náà. 24 Nígbà tí ẹ bá kórè, kí ẹ fún Fáráò+ ní ìdá kan nínú márùn-ún, kí ẹ fi ìdá mẹ́rin yòókù ṣe irúgbìn tí ẹ máa gbìn sínú oko àti oúnjẹ tí ẹ̀yin àti ilé yín àti àwọn ọmọ yín máa jẹ.” 25 Torí náà, wọ́n sọ pé: “O ti dá ẹ̀mí wa sí.+ Jẹ́ ká rí ojú rere olúwa mi, àwa yóò sì di ẹrú Fáráò.”+ 26 Jósẹ́fù wá sọ ọ́ di òfin pé ìdá kan nínú márùn-ún gbọ́dọ̀ jẹ́ ti Fáráò, òfin yìí ni wọ́n ń tẹ̀ lé títí di òní nílẹ̀ Íjíbítì. Ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Fáráò.+

27 Ísírẹ́lì wá ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní Góṣénì,+ wọ́n tẹ̀ dó síbẹ̀, wọ́n bímọ, wọ́n sì ń pọ̀ gan-an.+ 28 Jékọ́bù gbé ilẹ̀ Íjíbítì fún ọdún mẹ́tàdínlógún (17), ọjọ́ ayé Jékọ́bù sì wá jẹ́ ọdún mẹ́tàdínláàádọ́jọ (147).+

29 Nígbà tí àkókò tí Ísírẹ́lì máa kú+ sún mọ́ tòsí, ó pe Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Tí mo bá rí ojúure rẹ, jọ̀ọ́ fi ọwọ́ rẹ sábẹ́ itan mi, kí o fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi, kí o sì jẹ́ olóòótọ́ sí mi. Jọ̀ọ́, má sin mí sí Íjíbítì.+ 30 Tí mo bá kú,* kí o gbé mi kúrò ní Íjíbítì, kí o sì lọ sin mí sí sàréè àwọn baba ńlá+ mi.” Jósẹ́fù fèsì pé: “Màá ṣe ohun tí o sọ.” 31 Ísírẹ́lì wá sọ pé: “Búra fún mi.” Ó sì búra fún un.+ Ísírẹ́lì sì tẹrí ba níbi ìgbèrí ibùsùn+ rẹ̀.

48 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, ara bàbá rẹ ò yá.” Ló bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì dání lọ síbẹ̀, ìyẹn Mánásè àti Éfúrémù.+ 2 Wọ́n sì sọ fún Jékọ́bù pé: “Jósẹ́fù ọmọ rẹ ti dé.” Torí náà, Ísírẹ́lì tiraka, ó sì dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀. 3 Jékọ́bù wá sọ fún Jósẹ́fù pé:

“Ọlọ́run Olódùmarè fara hàn mí ní Lúsì nílẹ̀ Kénáánì, ó sì súre fún mi.+ 4 Ó sọ fún mi pé, ‘Màá mú kí o bímọ, màá sì mú kí o di púpọ̀, màá sọ ọ́ di àwùjọ àwọn èèyàn,+ màá sì fún àtọmọdọ́mọ* rẹ ní ilẹ̀ yìí kó lè di ohun ìní wọn títí láé.’+ 5 Tèmi+ ni àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí o bí ní ilẹ̀ Íjíbítì kí n tó wá sọ́dọ̀ rẹ ní Íjíbítì. Éfúrémù àti Mánásè yóò di tèmi bí Rúbẹ́nì àti Síméónì ṣe jẹ́ tèmi.+ 6 Àmọ́ àwọn ọmọ tí o bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ tìrẹ. Orúkọ àwọn ẹ̀gbọ́n wọn ni wọ́n á máa fi pe ogún wọn.+ 7 Ní tèmi, nígbà tí mò ń bọ̀ láti Pádánì, Réṣẹ́lì kú+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nílẹ̀ Kénáánì, nígbà tí ọ̀nà ṣì jìn sí Éfúrátì.+ Mo sì sin ín níbẹ̀ lójú ọ̀nà Éfúrátì, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”+

8 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì rí àwọn ọmọ Jósẹ́fù, ó sì bi í pé: “Àwọn wo nìyí?” 9 Jósẹ́fù dá a lóhùn pé: “Àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fún mi níbí+ ni.” Ni Ísírẹ́lì bá sọ pé: “Jọ̀ọ́ mú wọn wá sọ́dọ̀ mi, kí n lè súre fún wọn.”+ 10 Ojú Ísírẹ́lì ti di bàìbàì torí ó ti darúgbó, kò sì ríran dáadáa. Jósẹ́fù mú wọn sún mọ́ ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì. Ísírẹ́lì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó sì gbá wọn mọ́ra. 11 Ísírẹ́lì sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mi ò rò pé mo lè rí ọ mọ́,+ àmọ́ Ọlọ́run ti jẹ́ kí n tún rí ọmọ* rẹ.” 12 Jósẹ́fù wá gbé wọn kúrò ní orúnkún Ísírẹ́lì, ó tẹrí ba, ó sì wólẹ̀.

13 Jósẹ́fù wá mú àwọn méjèèjì, ó mú Éfúrémù+ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ tó jẹ́ apá òsì Ísírẹ́lì, ó sì mú Mánásè+ sí ọwọ́ òsì rẹ̀ tó jẹ́ apá ọ̀tún Ísírẹ́lì, ó mú wọn sún mọ́ ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì. 14 Àmọ́ Ísírẹ́lì gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé orí Éfúrémù bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì gbé ọwọ́ òsì rẹ̀ lé orí Mánásè. Ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ni, torí Mánásè ni àkọ́bí.+ 15 Ó wá súre fún Jósẹ́fù, ó sì sọ pé:+

“Ọlọ́run tòótọ́, tí àwọn bàbá mi Ábúráhámù àti Ísákì bá rìn,+

Ọlọ́run tòótọ́ tó ń bójú tó mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí dòní,+

16 Áńgẹ́lì tó ń gbà mí lọ́wọ́ gbogbo àjálù,+ jọ̀ọ́ bù kún àwọn ọmọ+ yìí.

Jẹ́ kí wọ́n máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn bàbá mi, Ábúráhámù àti Ísákì,

Jẹ́ kí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ ní ayé.”+

17 Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé bàbá òun ò gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kò dùn mọ́ ọn nínú, ó sì gbìyànjú láti mú ọwọ́ bàbá rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kó sì gbé e sórí Mánásè. 18 Jósẹ́fù sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́ bàbá mi, àkọ́bí+ nìyí. Gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.” 19 Àmọ́ bàbá rẹ̀ ò gbà, ó sì sọ pé: “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà á di èèyàn púpọ̀, yóò sì di ẹni ńlá. Àmọ́, àbúrò rẹ̀ máa jù ú lọ,+ àwọn ọmọ* rẹ̀ yóò sì pọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè.”+ 20 Ó sì súre fún wọn ní ọjọ́+ yẹn, ó ní:

“Kí Ísírẹ́lì máa fi orúkọ rẹ súre pé,

‘Kí Ọlọ́run mú kí o dà bí Éfúrémù àti Mánásè.’”

Ó wá ń fi Éfúrémù ṣáájú Mánásè.

21 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, mi ò ní pẹ́ kú,+ àmọ́ ó dájú pé Ọlọ́run ò ní fi yín sílẹ̀, yóò sì mú yín pa dà sí ilẹ̀ àwọn baba ńlá+ yín. 22 Ní tèmi, ilẹ̀* tí mo fún ọ fi ọ̀kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ, èyí tí mo fi idà àti ọrun mi gbà lọ́wọ́ àwọn Ámórì.”

49 Jékọ́bù sì pe àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ kó ara yín jọ, kí n lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́jọ́ iwájú. 2 Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ sì fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin Jékọ́bù, àní, ẹ fetí sí Ísírẹ́lì bàbá yín.

3 “Rúbẹ́nì,+ ìwọ ni àkọ́bí+ mi, okun mi, ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ mi, iyì àti okun rẹ ta yọ. 4 Torí ara rẹ kò balẹ̀ bí omi tó ń ru gùdù, o ò ní ta yọ, torí pé o gun ibùsùn+ bàbá rẹ. O sọ ibùsùn mi di ẹlẹ́gbin* nígbà yẹn. Ó gun orí rẹ̀!

5 “Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò+ ni Síméónì àti Léfì. Ohun èlò ìwà ipá ni ohun ìjà wọn.+ 6 Má ṣe wá sáàárín wọn, ìwọ ọkàn* mi. Má ṣe bá wọn pé jọ, ìwọ ọlá* mi. Torí wọ́n fi ìbínú pa àwọn ọkùnrin,+ wọ́n sì tún já iṣan ẹsẹ̀* àwọn akọ màlúù láti tẹ́ ara wọn lọ́rùn. 7 Ègún sì ni fún ìbínú wọn, torí ìkà ni wọ́n fi ṣe àti ìrunú wọn, torí ó le jù.+ Jẹ́ kí n tú wọn ká sí ilẹ̀ Jékọ́bù, kí n sì tú wọn ká sáàárín Ísírẹ́lì.+

8 “Ní ti ìwọ Júdà,+ àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ́.+ Ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ.+ Àwọn ọmọ bàbá rẹ yóò tẹrí ba fún ọ.+ 9 Ọmọ kìnnìún+ ni Júdà. Ọmọ mi, ìwọ yóò jẹ ẹran tí o pa, wàá sì dìde kúrò níbẹ̀. Ó ti dùbúlẹ̀, ó sì nà tàntàn bíi kìnnìún. Ó rí bíi kìnnìún, ta ló láyà láti jí i? 10 Ọ̀pá àṣẹ kò ní kúrò lọ́dọ̀ Júdà,+ ọ̀pá aláṣẹ kò sì ní kúrò láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ títí Ṣílò* yóò fi dé,+ òun ni àwọn èèyàn yóò máa ṣègbọràn sí.+ 11 Yóò so kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ àjàrà, yóò sì so ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ àjàrà tó dára, yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì, yóò sì fọ ẹ̀wù rẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà. 12 Wáìnì mú kí ojú rẹ̀ pọ́n gan-an, wàrà sì mú kí eyín rẹ̀ funfun.

13 “Sébúlúnì+ yóò máa gbé ní etíkun, ní èbúté tí àwọn ọkọ̀ òkun gúnlẹ̀ sí,+ ààlà rẹ̀ tó jìnnà jù yóò sì wà ní ọ̀nà Sídónì.+

14 “Ísákà+ jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí egungun rẹ̀ le, tó dùbúlẹ̀ sáàárín àpò ẹrù méjì tí wọ́n so mọ́ ẹ̀yìn rẹ̀. 15 Yóò rí i pé ibi ìsinmi náà dáa àti pé ilẹ̀ náà wuni. Yóò tẹ èjìká rẹ̀ wálẹ̀ kó lè gbé ẹrù, yóò sì gbà láti ṣiṣẹ́ àṣekára.

16 “Dánì+ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì+ máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn rẹ̀. 17 Kí Dánì jẹ́ ejò tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ejò tó ní ìwo lẹ́bàá ọ̀nà, tó ń bu ẹṣin jẹ ní gìgísẹ̀, kí ẹni tó ń gùn ún lè ṣubú sẹ́yìn.+ 18 Jèhófà, èmi yóò dúró de ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ.

19 “Ní ti Gádì,+ àwọn jàǹdùkú* yóò jà á lólè, àmọ́ òun yóò kọ lù wọ́n ní gìgísẹ̀.+

20 “Oúnjẹ* Áṣérì+ yóò pọ̀ gan-an,* yóò sì pèsè oúnjẹ tó tọ́ sí ọba.+

21 “Náfútálì+ jẹ́ abo àgbọ̀nrín tó rí pẹ́lẹ́ńgẹ́. Ó ń sọ ọ̀rọ̀ tó dùn.+

22 “Jósẹ́fù+ jẹ́ èéhù igi eléso, igi tó ń so lẹ́bàá ìsun omi, tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà sórí ògiri. 23 Àmọ́ àwọn tafàtafà ń fòòró rẹ̀, wọ́n ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dì í sínú.+ 24 Síbẹ̀, ọfà* rẹ̀ dúró sí àyè rẹ̀,+ ọwọ́ rẹ̀ lágbára, ó sì já fáfá.+ Èyí wá láti ọwọ́ alágbára Jékọ́bù, láti ọwọ́ olùṣọ́ àgùntàn, òkúta Ísírẹ́lì. 25 Ó* wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bàbá rẹ, yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́, ó wà pẹ̀lú Olódùmarè, yóò sì fi àwọn ìbùkún ọ̀run lókè bù kún ọ, pẹ̀lú àwọn ìbùkún ibú nísàlẹ̀,+ pẹ̀lú àwọn ìbùkún ọmú àti ilé ọmọ. 26 Àwọn ìbùkún bàbá rẹ yóò ga ju àwọn ìbùkún òkè ayérayé lọ, yóò ga ju àwọn ohun tó wuni lórí àwọn òkè tó ti wà tipẹ́.+ Wọn yóò máa wà ní orí Jósẹ́fù, ní àtàrí ẹni tí Ọlọ́run yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀.+

27 “Bẹ́ńjámínì+ yóò máa fani ya bí ìkookò.+ Ní àárọ̀, yóò jẹ ẹran tó pa. Ní ìrọ̀lẹ́, yóò pín ẹrù ogun.”+

28 Ìwọ̀nyí ni ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì. Ohun tí bàbá wọn sì sọ fún wọn nìyẹn nígbà tó ń súre fún wọn. Ó súre+ fún kálukú bó ṣe tọ́ sí i.

29 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún wọn pé: “Wọn ò ní pẹ́ kó mi jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn mi.*+ Torí náà, kí ẹ sin mí pẹ̀lú àwọn bàbá mi sínú ihò tó wà lórí ilẹ̀ Éfúrónì ọmọ Hétì,+ 30 ihò tó wà lórí ilẹ̀ Mákípẹ́là níwájú Mámúrè ní ilẹ̀ Kénáánì, ilẹ̀ tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì tó fi ṣe ibi ìsìnkú. 31 Ibẹ̀ ni wọ́n sin Ábúráhámù àti Sérà+ ìyàwó rẹ̀ sí. Ibẹ̀ náà ni wọ́n sin Ísákì+ àti Rèbékà ìyàwó rẹ̀ sí, ibẹ̀ sì ni mo sin Líà sí. 32 Ọwọ́ àwọn ọmọ Hétì+ ni Ábúráhámù ti ra ilẹ̀ náà àti ihò tó wà nínú rẹ̀.”

33 Nígbà tí Jékọ́bù fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ìtọ́ni wọ̀nyí tán, ó ká ẹsẹ̀ rẹ̀ sórí ibùsùn, ó mí èémí ìkẹyìn, wọ́n sì kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.*+

50 Jósẹ́fù sì ṣubú lé bàbá+ rẹ̀, ó sunkún lórí rẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 2 Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn oníṣègùn, pé kí wọ́n tọ́jú òkú bàbá òun kó má bàa jẹrà.+ Àwọn oníṣègùn náà wá tọ́jú òkú Ísírẹ́lì, 3 wọ́n sì fi ogójì (40) ọjọ́ gbáko tọ́jú rẹ̀, torí iye ọjọ́ tí wọ́n fi ń tọ́jú òkú nìyẹn, kó má bàa jẹrà. Àwọn ará Íjíbítì sì ń sunkún torí Jékọ́bù fún àádọ́rin (70) ọjọ́.

4 Nígbà tí wọ́n ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ tán, Jósẹ́fù sọ fún àwọn òṣìṣẹ́* Fáráò pé: “Tí mo bá rí ojúure yín, ẹ bá mi sọ fún Fáráò pé: 5 ‘Bàbá mi mú kí n búra,+ ó ní: “Wò ó! Mi ò ní pẹ́ kú.+ Kí o sin mí sí ibi ìsìnkú+ mi tí mo gbẹ́ ní ilẹ̀ Kénáánì.”+ Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n lọ sin bàbá mi, màá sì pa dà lẹ́yìn náà.’” 6 Fáráò fèsì pé: “Lọ sin bàbá rẹ, bó ṣe mú kí o búra.”+

7 Jósẹ́fù wá lọ sin bàbá rẹ̀, gbogbo ìránṣẹ́ Fáráò sì bá a lọ, pẹ̀lú àwọn àgbààgbà+ ilé rẹ̀ àti gbogbo àgbààgbà ilẹ̀ Íjíbítì, 8 gbogbo agbo ilé Jósẹ́fù, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti agbo ilé bàbá+ rẹ̀. Àwọn ọmọ wọn kéékèèké, agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn nìkan ni wọ́n fi sílẹ̀ ní ilẹ̀ Góṣénì. 9 Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti àwọn tó ń gẹṣin tún bá a lọ, àwọn èèyàn náà pọ̀ gan-an. 10 Wọ́n wá dé ibi ìpakà Átádì, tó wà ní agbègbè Jọ́dánì, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ gidigidi níbẹ̀. Ọjọ́ méje ni Jósẹ́fù fi ṣọ̀fọ̀ bàbá rẹ̀. 11 Àwọn ọmọ Kénáánì, tó ń gbé ilẹ̀ náà rí wọn tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà Átádì, wọ́n sì sọ pé: “Ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ àwọn ará Íjíbítì yìí o!” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sọ ibẹ̀ ní Ebẹli-mísíráímù,* tó wà ní agbègbè Jọ́dánì.

12 Àwọn ọmọ Jékọ́bù ṣe ohun tó sọ fún wọn+ gẹ́lẹ́. 13 Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì sin ín sínú ihò tó wà ní ilẹ̀ Mákípẹ́là, ilẹ̀ tó wà níwájú Mámúrè tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì tó fi ṣe ibi ìsìnkú.+ 14 Lẹ́yìn tó sin bàbá rẹ̀, Jósẹ́fù pa dà sí Íjíbítì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn tó tẹ̀ lé e lọ sìnkú bàbá rẹ̀.

15 Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù rí i pé bàbá àwọn ti kú, wọ́n sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé Jósẹ́fù ń dì wá sínú, tí yóò sì san wá lẹ́san gbogbo ibi tí a ṣe sí i.”+ 16 Wọ́n wá ránṣẹ́ sí Jósẹ́fù pé: “Kí bàbá rẹ tó kú, ó pàṣẹ pé: 17 ‘Ẹ sọ fún Jósẹ́fù pé: “Jọ̀ọ́, mo bẹ̀ ọ́, dárí àṣìṣe àwọn arákùnrin rẹ jì wọ́n, kí o sì gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá nígbà tí wọ́n ṣe ọ́ ní ibi.”’ Jọ̀ọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bàbá rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Jósẹ́fù gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún. 18 Àwọn arákùnrin rẹ̀ náà wá, wọ́n wólẹ̀ síwájú rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Wò ó, a ti di ẹrú rẹ!”+ 19 Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni Ọlọ́run ni? 20 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èrò ibi lẹ ní sí mi,+ Ọlọ́run mú kó yọrí sí rere, kó lè dá ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn sí, bó ti ń ṣe lónìí.+ 21 Torí náà, ẹ má bẹ̀rù. Màá ṣì máa pèsè oúnjẹ+ fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín kéékèèké.” Bó ṣe tù wọ́n nínú nìyẹn, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.

22 Jósẹ́fù ń gbé ní Íjíbítì, òun àti agbo ilé bàbá rẹ̀. Ọjọ́ ayé Jósẹ́fù sì jẹ́ àádọ́fà (110) ọdún. 23 Jósẹ́fù rí ìran kẹta àwọn ọmọ+ Éfúrémù, pẹ̀lú àwọn ọmọ Mákírù,+ ọmọ Mánásè. Orúnkún Jósẹ́fù ni wọ́n bí wọn sí.* 24 Níkẹyìn, Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Mi ò ní pẹ́ kú, àmọ́ ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé yín,+ ó sì dájú pé yóò mú yín kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tó búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.”+ 25 Jósẹ́fù wá mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì búra, ó ní: “Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé yín. Kí ẹ kó egungun mi kúrò níbí.”+ 26 Ẹni àádọ́fà (110) ọdún ni Jósẹ́fù nígbà tó kú, wọ́n sì tọ́jú òkú rẹ̀ kó má bàa jẹrà,+ wọ́n wá gbé e sínú pósí ní ilẹ̀ Íjíbítì.

Tàbí “omi tó ń ru gùdù.”

Tàbí “agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run.”

Tàbí “àwọn ìmọ́lẹ̀.”

Tàbí “àwọn alààyè ọkàn.”

Tàbí “òfúrufú.”

Tàbí “àwọn alààyè ọkàn.”

Tàbí “àwọn alààyè ọkàn.”

Tàbí “àwọn ẹran tó ń rìn káàkiri,” ó jọ pé àwọn ẹran afàyàfà àti oríṣiríṣi ẹran míì wà lára wọn.

Tàbí “ohun tó ní ẹ̀mí; ohun tó jẹ́ alààyè ọkàn.”

Ní Héb., “àti gbogbo ọmọ ogun wọn.”

Tàbí “àwọn ohun tó ti ń dá.”

Tàbí “gbogbo ohun tó ti ń dá.”

Orúkọ yìí, יהוה (YHWH), ni a fi ń dá Ọlọ́run tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tó fara hàn. Wo Àfikún A4.

Tàbí “alààyè ọkàn.” Lédè Hébérù, neʹphesh, èyí tó túmọ̀ sí “ẹ̀dá tó ń mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “ó sì di orí mẹ́rin.”

Tàbí “Tígírísì.”

Tàbí “alààyè ọkàn.”

Tàbí “wà pẹ̀lú.”

Tàbí “ló gbọ́n jù.”

Ní Héb., “àkókò tí atẹ́gùn máa ń fẹ́ lóòjọ́.”

Tàbí “kórìíra ara yín.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “dọ́gbẹ́ sí ọ lórí; ṣe ọ́ lẹ́ṣe ní orí.”

Tàbí “dọ́gbẹ́ sí i; fọ́ ọ.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí A Fi Erùpẹ̀ Mọ; Èèyàn; Aráyé.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Wà Láàyè.”

Ní Héb., “gbogbo èèyàn tó wà láàyè.”

Tàbí “títí ayérayé.”

Tàbí “bí.”

Ní Héb., “ó sì sorí kodò.”

Tàbí “ṣé mi ò ní tẹ́wọ́ gbà ọ́ ni?”

Ní Héb., “agbára.”

Ní Héb., “ní orí ilẹ̀.”

Tàbí “gbé àmì kan kalẹ̀.”

Tàbí “Nódì.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí Wọ́n Yàn; Ẹni Tí Wọ́n Gbé Kalẹ̀.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “Ádámù; Aráyé.”

Ní Héb., “Ọlọ́run náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ìsinmi; Ìtùnú.”

Tàbí “tù wá lára.”

Àkànlò èdè Hébérù tó ń tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.

Tàbí “torí ohun tí ẹran ara ń fẹ́ ló ń ṣe.”

Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Àwọn Abiniṣubú,” ìyẹn, àwọn tó ń gbé èèyàn ṣubú. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Jèhófà kẹ́dùn.”

Tàbí “ó sì dùn ún dọ́kàn.”

Tàbí “aláìlábùkù.”

Ní Héb., “àwọn ìran rẹ̀.”

Tàbí “gbogbo èèyàn.”

Ní Héb., “àwọn igi góférì,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ igi sípírẹ́sì.

Ní Héb., “àpótí ńlá.”

Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Tàbí “wíńdò.”

Lédè Hébérù, tsoʹhar. Yàtọ̀ sí fèrèsé tí ìmọ́lẹ̀ á máa gbà wọlé, tsoʹhar tún lè tọ́ka sí àjà tó ga ní ìgbọ̀nwọ́ kan, tó sì dagun.

Tàbí “èémí ìyè.”

Tàbí kó jẹ́, “méjì-méjì lọ́nà méje lára gbogbo ẹran tó mọ́.”

Tàbí kó jẹ́, “méjì-méjì lọ́nà méje lára gbogbo ẹran tó mọ́.”

Tàbí “èémí ìyè.”

Tàbí “ń bá a lọ.”

Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”

Tàbí “ẹ̀mí.”

Ní Héb., “rántí.”

Tàbí “òjò sì dáwọ́ dúró.”

Tàbí “wíńdò.”

Tàbí “fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.”

Tàbí “gbá yìn-ìn.”

Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Tàbí “pe ibi wá sórí ilẹ̀.”

Tàbí “Ẹ ti ní àṣẹ lórí wọn báyìí.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ẹ̀jẹ̀ ọkàn yín.”

Tàbí “alààyè ọkàn.”

Tàbí “ohun alààyè.”

Tàbí “alààyè ọkàn.”

Tàbí “gbogbo alààyè ọkàn tó jẹ́ ẹlẹ́ran ara.”

Tàbí “gbogbo alààyè ọkàn tó jẹ́ ẹlẹ́ran ara.”

Ní Héb., “ẹrú àwọn ẹrú.”

Tàbí “Àwọn ìlú tó kọ́kọ́ wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀ ni.”

Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n para pọ̀ di ìlú ńlá náà.”

Tàbí kó jẹ́, “òun sì ni ẹ̀gbọ́n Jáfẹ́tì.”

Ó túmọ̀ sí “Pín Sọ́tọ̀.”

Tàbí “aráyé.”

Tàbí “irú àwọn ọ̀rọ̀ kan náà.”

Ó túmọ̀ sí “Ìdàrú.”

Tàbí “yóò gba ìbùkún fún ara wọn.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “Èso.”

Tàbí “kó lè máa gbé ibẹ̀ bí àjèjì.”

Tàbí “kí ọkàn mi lè wà láàyè.”

Tàbí “ìyọnu àjàkálẹ̀.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Ìyẹn, Òkun Òkú.

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “gbé inú àgọ́.”

Ní Héb., “arákùnrin.”

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “àwọn ọkàn.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “ọmọ.”

Ní Héb., “ẹni tó wá látinú ara rẹ.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “ó sì kọjú wọn síra kí wọ́n lè bára mu.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “Èso.”

Ní Héb., “lé àyà rẹ.”

Ní Héb., “rẹ ara rẹ sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”

Ní Héb., “èso.”

Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Ń Gbọ́.”

Tàbí oríṣi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó kan tí wọ́n ń pè ní onager lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́, àwọn kan gbà pé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà ni. Ó lè jẹ́ torí pé kì í gbára lé ẹnikẹ́ni.

Tàbí kó jẹ́, “kò ní sí àlàáfíà láàárín òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀.”

Ó túmọ̀ sí “Kànga Ẹni Tó Wà Láàyè Tó Ń Rí Mi.”

Ní Héb., “Máa rìn níwájú mi.”

Tàbí “aláìlábùkù.”

Ó túmọ̀ sí “Bàbá Ga (Di Ẹni Àgbéga).”

Ó túmọ̀ sí “Bàbá Èèyàn Rẹpẹtẹ (Ogunlọ́gọ̀); Bàbá Ọ̀pọ̀ Èèyàn.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “kọ ara yín nílà.”

Tàbí “kọlà.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “ọkàn.”

Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Alárìíyànjiyàn.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí Yóò Di Ìyá Àwọn Ọba.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹ̀rín.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “ó sì kọ wọ́n nílà.”

Ní Héb., “kí ọkàn yín lè lókun.”

Ní Héb., “òṣùwọ̀n síà.” Síà kan jẹ́ Lítà 7.33. Wo Àfikún B14.

Ní Héb., “Sérà ò ṣe ohun tí obìnrin ń ṣe mọ́.”

Tàbí “gba ìbùkún fún ara wọn.”

Tàbí “ààbò.” Ní Héb., “òjìji.”

Tàbí “rọ́ lu.”

Tàbí “lọ sókè.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “o sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Ó túmọ̀ sí “Kékeré.”

Tàbí “òpó.”

Tàbí “tó jẹ́ àjèjì.”

Ìyẹn ni pé, kò tíì bá a ní àṣepọ̀.

Tàbí “tó jẹ́ olódodo.”

Ní Héb., “Ìbòjú ló jẹ́ fún ọ.”

Tàbí “ti sé gbogbo ilé ọlẹ̀ pa ní ilé Ábímélékì.”

Tàbí “kọlà.”

Tàbí kó jẹ́, “á fi mí rẹ́rìn-ín.”

Ní Héb., “ohùn rẹ̀.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Kànga Ìbúra tàbí Kànga Ohun Méje.”

Tàbí “gbé ní ilẹ̀ àwọn Filísínì bí àjèjì.”

Ní Héb., “ó lo ọjọ́ tó pọ̀.”

Tàbí “ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì.”

Tàbí “ọ̀bẹ ìpẹran.”

Tàbí “ọ̀bẹ ìpẹran.”

Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Yóò Pèsè; Jèhófà Yóò Rí sí I.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “àwọn ìlú.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “Ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Tàbí kó jẹ́, “Ìjòyè pàtàkì.”

Tàbí “ọkàn yín.”

Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

Ní Héb., “Èso.”

Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

Ó lè jẹ́ Lábánì.

Ní Héb., “kí n lè mọ̀ bóyá ọ̀tún ni màá yà sí tàbí òsì.”

Tàbí “A ò lè sọ ohun tó dáa tàbí ohun tí kò dáa fún ọ.”

Ìyẹn, olùtọ́jú rẹ̀ tó wá di ìránṣẹ́.

Tàbí “wàá di ìyá ọ̀kẹ́ àìmọye.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “àwọn ìlú.”

Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.

Tàbí “àgọ́ olódi.”

Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.

Tàbí kó jẹ́, “Kò sí àlàáfíà láàárín àwọn àtàwọn arákùnrin wọn.”

Ó túmọ̀ sí “Onírun Lára.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Ń Di Gìgísẹ̀ Mú; Ẹni Tó Gba Ipò Onípò.”

Tàbí “fún mi ní díẹ̀ nínú.”

Ní Héb., “pupa yìí, pupa yìí gangan.”

Tàbí “ebi ń pa mí gan-an.”

Ó túmọ̀ sí “Pupa.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “wíńdò.”

Tàbí “dì mọ́ Rèbékà ìyàwó rẹ̀.”

Ó túmọ̀ sí “Àríyànjiyàn.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹ̀sùn.”

Ó túmọ̀ sí “Ibi Tó Fẹ̀.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “Wọ́n mú kí ẹ̀mí Ísákì àti Rèbékà korò.”

Ní Héb., “ọrun.”

Tàbí “kí ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn rẹ.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn rẹ.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Ń Di Gìgísẹ̀ Mú; Ẹni Tó Gba Ipò Onípò.”

Tàbí “ń fi bó ṣe fẹ́ pa ọ́ tu ara rẹ̀ nínú.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “àkàbà.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “gba ìbùkún fún ara wọn.”

Ní Héb., “èso.”

Ó túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run.”

Ní Héb., “arákùnrin.”

Tàbí “ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wá.”

Ní Héb., “arákùnrin.”

Ní Héb., “kórìíra.”

Ní Héb., “ó ṣí ilé ọlẹ̀ rẹ̀.”

Ó túmọ̀ sí “Ọmọkùnrin Kan Rèé!”

Ó túmọ̀ sí “Ó Ń Gbọ́.”

Ó túmọ̀ sí “Rọ̀ Mọ́; Fà Mọ́.”

Ó túmọ̀ sí “Ìyìn; Ẹni Tí Ìyìn Yẹ.”

Tàbí “tí kò jẹ́ kí o ní èso ikùn ni?”

Ní Héb., “kó lè bímọ lórí orúnkún mi.”

Ó túmọ̀ sí “Onídàájọ́.”

Ó túmọ̀ sí “Ìjàkadì Mi.”

Ó túmọ̀ sí “Ire.”

Ó túmọ̀ sí “Ayọ̀; Ìdùnnú.”

Tàbí “wíìtì.”

Tàbí “pín mi lérè iṣẹ́.”

Ó túmọ̀ sí “Òun Ni Èrè.”

Ó túmọ̀ sí “Ó Fàyè Gbà Mí.”

Ní Héb., “Ọlọ́run fetí sí i, ó sì ṣí ilé ọlẹ̀ rẹ̀.”

Ìkékúrú Josifáyà, tó túmọ̀ sí “Kí Jáà Fi Kún Un (Bù sí I).”

Tàbí “ẹ̀rí ti fi hàn pé.”

Ìyẹn, oríṣi àwọ̀ búráùn kan.

Tàbí “òótọ́.”

Igi tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ fẹ̀, tí èèpo rẹ̀ sì máa ń bó.

Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; àwọn òrìṣà.”

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Tàbí “mọ̀lẹ́bí.”

Ní Héb., “Ṣọ́ ara rẹ, kí o má bàa sọ ohun rere àti búburú fún Jékọ́bù.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

Ní Héb., “ohun tí obìnrin ń ṣe.”

Ní Héb., “ìbẹ̀rù Ísákì.”

Ó túmọ̀ sí “Òkìtì Ẹ̀rí” lédè Árámáíkì.

Ó túmọ̀ sí “Òkìtì Ẹ̀rí” lédè Hébérù.

Ní Héb., “fi ìbẹ̀rù Ísákì búra.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

Ó túmọ̀ sí “Àgọ́ Méjì.”

Ní Héb., “pápá.”

Tàbí “gbé bí àjèjì.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “àfonífojì.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Bá Ọlọ́run Wọ̀jà” (“Ẹni Tó Rọ̀ Mọ́ Ọlọ́run”) tàbí “Ọlọ́run Wọ̀jà.”

Ó túmọ̀ sí “Ojú Ọlọ́run.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Péníélì.”

Ní Héb., “fọ́nrán iṣan tó wà níbi itan.”

Ó túmọ̀ sí “Àwọn Àtíbàbà; Ibi Ààbò.”

Tàbí “lọ rí.”

Ní Héb., “sọ̀rọ̀ tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn.”

Tàbí “Ọkàn Ṣékémù ọmọ mi rọ̀ mọ́.”

Tàbí “kí àwọn èèyàn wa sì máa fẹ́ra wọn.”

Tàbí “tí kò kọlà.”

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “Ohun tó máa mú kí wọ́n ta mí nù lẹ ṣe yìí.”

Tàbí “ní ọ̀nà.”

Tàbí “fi wọ́n pa mọ́.”

Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì.”

Tàbí “igi óákù.”

Ó túmọ̀ sí “Igi Óákù Tí Wọ́n Ń Sunkún Lábẹ́ Rẹ̀.”

Ní Héb., “ti abẹ́nú rẹ jáde.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “Bí ọkàn rẹ̀ ṣe ń jáde lọ.”

Ó túmọ̀ sí “Ọmọ Tí Mo Bí Nígbà Ọ̀fọ̀.”

Ó túmọ̀ sí “Ọmọ Ọwọ́ Ọ̀tún.”

Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.

Ní Héb., “ó darúgbó, ó sì lọ́jọ́ lórí.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “tí wọ́n ń gbé bí àjèjì.”

Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Séríkí jẹ́ olóyè láàárín ẹ̀yà kan.

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”

Ní Héb., “pápá.”

Tàbí “aṣọ gígùn kan tó rẹwà.”

Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “pa ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “ẹ má fọwọ́ kàn án.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ìyẹn, Júdà.

Ó túmọ̀ sí “Ya,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abẹ́ tó ya.

Ìyẹn, olórí àwọn tó ń ṣe búrẹ́dì, kéèkì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní Héb., “fún ọjọ́ díẹ̀.”

Ní Héb., “máa gbé orí rẹ sókè.”

Ní Héb., “kòtò omi; ihò.”

Ní Héb., “yóò gbé orí rẹ sókè kúrò lára rẹ.”

Ní Héb., “ó wá gbé orí olórí agbọ́tí àti olórí alásè sókè.”

Ní Héb., “kòtò omi; ihò.”

Tàbí “Ìtẹ́.”

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Ó jọ pé ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí pé kí wọ́n bọlá fún un kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un.

Ní Héb., “gbé ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè.”

Ìyẹn, Heliopólísì.

Tàbí “lọ káàkiri.”

Tàbí “nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́dọ̀.”

Ní Héb., “ní ẹ̀kúnwọ́-ẹ̀kúnwọ́.”

Ìyẹn, Heliopólísì.

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Ń Múni Gbàgbé; Amúnigbàgbé.”

Ó túmọ̀ sí “Èso Ìlọ́po Méjì.”

Tàbí “búrẹ́dì.”

Tàbí “ibi tí a kù sí ní ilẹ̀ wa.”

Tàbí “ìdààmú ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Màá ṣe onídùúró fún ọmọ náà.”

Ní Héb., “Wọ́n.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ní ilẹ̀ náà.”

Ní Héb., “baba.”

Ní Héb., “rọ̀ mọ́ ọrùn.”

Tàbí “gbára lé ibi tó lọ́ràá jù.”

Tàbí “gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.”

Ìyẹn ni pé yóò fi ọwọ́ rẹ̀ pa ojú Jékọ́bù dé tó bá kú.

Tàbí “Ọkàn gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀.”

Tàbí “ọkàn mẹ́rìndínlógún.”

Ìyẹn, Heliopólísì.

Tàbí “ọkàn mẹ́rìnlá.”

Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”

Tàbí “ọkàn méje.”

Tàbí “Gbogbo ọkàn tó wá láti ara Jékọ́bù.”

Tàbí “Ọkàn méjì.”

Tàbí “Gbogbo àwọn ọkàn.”

Ní Héb., “rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀.”

Tàbí “sunkún ní ọrùn rẹ̀ léraléra.”

Tàbí “kó káàkiri; gbé bí àjèjì.”

Tàbí “kó káàkiri; gbé bí àjèjì.”

Ní Héb., “búrẹ́dì.”

Ní Héb., “búrẹ́dì.”

Ní Héb., “dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba mi.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ilẹ̀.” Ní Héb., “èjìká ilẹ̀.”

Tàbí “O kẹ́gàn ibùsùn mi.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “èrò ọkàn.”

Tàbí “já pátì.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Ni Nǹkan; Ẹni Tí Nǹkan Tọ́ Sí.”

Tàbí “akónilẹ́rù.”

Tàbí “Búrẹ́dì.”

Ní Héb., “yóò lọ́ràá.”

Ní Héb., “ọrun.”

Ìyẹn, Jósẹ́fù.

Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.

Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.

Tàbí “agbo ilé.”

Ó túmọ̀ sí “Àwọn Ará Íjíbítì Ṣọ̀fọ̀.”

Ìyẹn ni pé, ó ṣe wọ́n bí ọmọ, ó sì ṣojúure sí wọn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́