ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 12:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Fáráò tọ́jú Ábúrámù dáadáa nítorí obìnrin náà, Ábúrámù sì wá ní àwọn àgùntàn, màlúù, akọ àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin àti àwọn ràkúnmí.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 26:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ísákì bẹ̀rẹ̀ sí í dá oko ní ilẹ̀ náà. Lọ́dún yẹn, ó kórè ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) ohun tó gbìn, torí Jèhófà ń bù kún un.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 26:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ó ní àwọn agbo àgùntàn, ọ̀wọ́ màlúù àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìránṣẹ́,+ àmọ́ àwọn Filísínì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara rẹ̀.

  • Jẹ́nẹ́sísì 31:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Jékọ́bù wá dìde, ó sì gbé àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ sórí àwọn ràkúnmí,+ 18 ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da agbo ẹran rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ti ní,+ àwọn ẹran ọ̀sìn tó wá di tirẹ̀ ní Padani-árámù, ó dà wọ́n lọ sọ́dọ̀ Ísákì bàbá rẹ̀ ní ilẹ̀ Kénáánì.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 46:33, 34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 Tí Fáráò bá pè yín, tó sì bi yín pé, ‘Iṣẹ́ wo lẹ̀ ń ṣe?’ 34 Kí ẹ sọ pé, ‘Àti kékeré ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ti ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn, àwa àti àwọn baba ńlá+ wa,’ kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ Góṣénì,+ torí àwọn ará Íjíbítì+ kórìíra gbogbo àwọn tó ń da àgùntàn.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́