ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 102:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Tipẹ́tipẹ́ lo ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,

      Ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.+

  • Àìsáyà 42:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, sọ nìyí,

      Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti Atóbilọ́lá tó nà án jáde,+

      Ẹni tó tẹ́ ayé àti èso rẹ̀,+

      Ẹni tó fún àwọn èèyàn inú rẹ̀ ní èémí,+

      Tó sì fún àwọn tó ń rìn lórí rẹ̀ ní ẹ̀mí:+

  • Àìsáyà 45:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Torí ohun tí Jèhófà sọ nìyí,

      Ẹlẹ́dàá ọ̀run,+ Ọlọ́run tòótọ́,

      Ẹni tó dá ayé, Aṣẹ̀dá rẹ̀ tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,+

      Ẹni tí kò kàn dá a lásán,* àmọ́ tó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀:+

      “Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì.

  • Róòmù 1:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Nítorí àwọn ànímọ́* rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá,+ títí kan agbára ayérayé tó ní+ àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run,+ tó fi jẹ́ pé wọn ò ní àwíjàre.

  • Hébérù 1:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Àti pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Olúwa, o fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

  • Ìfihàn 4:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 “Jèhófà,* Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo+ àti ọlá+ àti agbára,+ torí ìwọ lo dá ohun gbogbo,+ torí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”

  • Ìfihàn 10:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 ó sì fi Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé+ búra, ẹni tó dá ọ̀run àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, ayé àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú òkun àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀,+ ó sọ pé: “A ò ní fi falẹ̀ mọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́