13 Mo gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tó wà ní ọ̀run àti ayé àti lábẹ́ ilẹ̀+ àti lórí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn, ń sọ pé: “Kí ìbùkún àti ọlá+ àti ògo àti agbára jẹ́ ti Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà+ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+ títí láé àti láéláé.”+
“Ní báyìí, ìgbàlà+ àti agbára dé àti Ìjọba Ọlọ́run wa+ pẹ̀lú àṣẹ Kristi rẹ̀, torí pé a ti ju ẹni tó ń fẹ̀sùn kan àwọn ará wa sísàlẹ̀, ẹni tó ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sántòru níwájú Ọlọ́run wa!+