ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 28 ojú ìwé 70-ojú ìwé 71 ìpínrọ̀ 1
  • Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù Sọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù Sọ̀rọ̀
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Kan Sọ̀rọ̀
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Númérì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Olùkọ́ Èké!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 28 ojú ìwé 70-ojú ìwé 71 ìpínrọ̀ 1
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà nígbà tó rí áńgẹ́lì Ọlọ́run

Ẹ̀KỌ́ 28

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù Sọ̀rọ̀

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì (40) ọdún nínú aginjù. Wọ́n ti ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ ìlú tó lágbára. Ní báyìí, wọ́n pàgọ́ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lápá ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì. Ó ti tó àkókò fún wọn láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ẹ̀rù ń ba Bálákì ọba Móábù pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tó gba ilẹ̀ òun. Torí náà, ó ní kí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Báláámù wá sí Móábù láti wá ṣépè fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Báláámù pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ ṣépè fún wọn.’ Torí náà, Báláámù ò lọ. Ọba Bálákì tún pe Báláámù nígbà kejì, ó sì ṣèlérí pé òun máa fún un ní ohunkóhun tó bá béèrè. Síbẹ̀, Báláámù kọ̀ jálẹ̀. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Ọlọ́run sọ fún Báláámù pé: ‘Lọ, àmọ́ ohun tí mo bá sọ fún ẹ ni kó o sọ.’

Báláámù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó kọrí sí apá gúúsù. Ó ń lọ sí ilẹ̀ Móábù, ó fẹ́ lọ ṣépè fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti sọ fún un pé kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Bó ṣe ń lọ, áńgẹ́lì Jèhófà yọ sí i lẹ́ẹ̀mẹta. Báláámù ò rí áńgẹ́lì náà, àmọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ rí i. Nígbà àkọ́kọ́, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn sá kúrò lójú ọ̀nà, ó sáré gba orí koríko tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Nígbà kejì, ẹ̀gbẹ́ ògiri ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lọ gbà, ó sì sún mọ́ ògiri náà débi pé ògiri náà ṣe Báláámù léṣe lẹ́sẹ̀. Nígbà kẹta, ńṣe ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà kọ̀ tí ò lọ mọ́, tó sì wá dùbúlẹ̀ sáàárín ọ̀nà. Ìgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni Báláámù ń fi igi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yìí.

Nígbà kẹta, Jèhófà jẹ́ kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yìí sọ̀rọ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà bi Báláámù pé: ‘Kí ló dé tó o fi ń lù mí?’ Báláámù dáhùn pé: ‘O ti múnú bí mi gan-an. Ká ní idà wà lọ́wọ́ mi ni, ǹ bá ti pa ẹ́ dà nù.’ Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá sọ pé: ‘Ọ̀pọ̀ ọdún lo ti ń gùn mí. Ṣé mo ti ṣe báyìí sí ẹ rí ni?’

Ní báyìí, Jèhófà jẹ́ kí Báláámù rí áńgẹ́lì náà. Áńgẹ́lì yìí wá sọ fún un pé: ‘Ṣebí Jèhófà kìlọ̀ fún ẹ pé kó o má lọ ṣépè fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?’ Báláámù sọ pé: ‘Mo ti ṣe ohun tí kò dáa. Màá pa dà sílé.’ Àmọ́ áńgẹ́lì náà sọ pé: ‘Máa lọ síbi tó ò ń lọ ní Móábù, àmọ́ ohun ti Jèhófà bá ní kó o sọ nìkan ni kó o sọ.’

Ṣé Báláámù kọ́gbọ́n látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Rárá o. Torí pé lẹ́yìn tó rí áńgẹ́lì yẹn, Báláámù ṣì gbìyànjú láti lọ ṣépè fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbà mẹ́ta, àmọ́ kàkà kó ṣépè, Jèhófà jẹ́ kó gbàdúrà fún wọn nígbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Níkẹyìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn ará Móábù jà, wọ́n sì pa Báláámù. Ká ní Báláámù ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un ni, ṣé ó máa kú sógun?

‘Ẹ máa ṣọ́ra fún onírúurú ojúkòkòrò, torí pé tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ní nǹkan rẹpẹtẹ, àwọn ohun tó ní kò lè fún un ní ìwàláàyè.’​—Lúùkù 12:15

Ìbéèrè: Kí nìdí tí Báláámù fi lọ sí Móábù? Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Báláámù lójú ọ̀nà?

Nọ́ńbà 22:1–24:25; 31:8; Nehemáyà 13:2; 2 Pétérù 2:15, 16; Júùdù 11

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́