Ẹ̀KỌ́ 30
Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ amí dé ìlú Jẹ́ríkò, ilé obìnrin kan tó ń jẹ́ Ráhábù ni wọ́n dé sí. Nígbà tí ọba ìlú Jẹ́ríkò gbọ́, ó rán àwọn ẹ̀ṣọ́ ẹ̀ pé kí wọ́n lọ mú wọn wá nílé Ráhábù. Àmọ́, Ráhábù fi àwọn amí náà pa mọ́ sí òrùlé ilé ẹ̀. Nígbà táwọn ẹ̀ṣọ́ ọba dé, ńṣe ló júwe ibòmíì fún wọn. Ó wá sọ fáwọn amí náà pé: ‘Màá ràn yín lọ́wọ́ tórí mo mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú yín àti pé ẹ máa ṣẹ́gun ìlú yìí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ ṣèlérí fún mi pé ẹ ò ní pa èmi àtàwọn mọ̀lẹ́bí mi.’
Àwọn amí náà sọ fún Ráhábù pé: ‘A ṣèlérí pé kò sẹ́nì kankan nínú ilé rẹ tó máa fara pa.’ Wọ́n wá sọ pé: ‘So okùn pupa mọ́ ojú wíńdò ẹ kí ìdílé rẹ má bàa pa run.’
Ráhábù jẹ́ káwọn amí yìí fi okùn kan sọ̀ kalẹ̀ láti ojú wíńdò ẹ̀. Wọ́n sì sá lọ sórí àwọn òkè láti fara pa mọ́ fún ọjọ́ mẹ́ta kí wọ́n tó pa dà sọ́dọ̀ Jóṣúà. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá Odò Jọ́dánì láti lọ gba ilẹ̀ náà. Ìlú Jẹ́ríkò ni wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́gun. Jèhófà ní kí wọ́n máa yan yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà. Nígbà tó wá di ọjọ́ keje, wọ́n yan yí i ká lẹ́ẹ̀méje. Lẹ́yìn náà, àwọn àlùfáà fọn kàkàkí wọn, àwọn ológun sì fi gbogbo agbára wọn pariwo. Bí ògiri ìlú Jẹ́ríkò ṣe wó lulẹ̀ nìyẹn! Àmọ́ ilé Ráhábù tí wọ́n kọ́ mọ́ ògiri ìlú náà kò wó. Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ kò kú torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
“Bákan náà, ṣebí àwọn iṣẹ́ ló mú kí á ka Ráhábù . . . pẹ̀lú sí olódodo, lẹ́yìn tó gba àwọn òjíṣẹ́ lálejò, tó sì ní kí wọ́n gba ọ̀nà míì jáde?”—Jémíìsì 2:25