ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yc ẹ̀kọ́ 3 ojú ìwé 8-9
  • Ráhábù Gba Jèhófà Gbọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ráhábù Gba Jèhófà Gbọ́
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ráhábù Fi Ohun Tó Gbọ́ Sọ́kàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • A “Polongo Rẹ̀ Ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Rahabu—A Polongo Rẹ̀ ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Ìgbàgbọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Kọ́ Ọmọ Rẹ
yc ẹ̀kọ́ 3 ojú ìwé 8-9
Ráhábù wá sí òrùlé níbi tí àwọn amí náà fara pa mọ́ sí

Ẹ̀kọ́ 3

Ráhábù Gba Jèhófà Gbọ́

Jẹ́ ká sọ pé ìlú Jẹ́ríkò la wà. Ilẹ̀ Kénáánì ni ìlú yìí wà, àwọn èèyàn ibẹ̀ kò gba Jèhófà gbọ́. Ìlú yẹn ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Ráhábù ń gbé.

Nígbà tí Ráhábù wà ní ọmọ kékeré, ó máa ń gbọ́ ìtàn nípa bí Mósè ṣe la Òkun Pupa tí ó sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní Íjíbítì. Ó tún gbọ́ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tó wá bá wọn jà. Ní báyìí, ó ti gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ti dé sí ìtòsí ìlú Jẹ́ríkò!

Ráhábù fi àwọn amí náà pa mọ́ torí pé ó gba Jèhófà gbọ́

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wọ ìlú Jẹ́ríkò kí wọ́n lè lọ wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, amí ni wọ́n ń pè wọ́n. Ilé Ráhábù ni wọ́n sì lọ. Ráhábù ní kí wọ́n wọlé, kí wọ́n sì dúró sọ́dọ̀ òun. Nígbà tó di alẹ́, ọba ìlú Jẹ́ríkò gbọ́ pé àwọn méjì kan ti yọ́ wọnú ìlú láti wá mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ àti pé ilé Ráhábù ni wọ́n wà. Ni ọba bá sọ pé kí àwọn ìránṣẹ́ òun lọ mú àwọn amí yẹn wá. Àmọ́, Ráhábù fi àwọn amí méjèèjì pa mọ́ sí òrùlé ilé rẹ̀, ó wá sọ fún àwọn tí ọba rán wá pé: ‘Àwọn amí yẹn wá sọ́dọ̀ mi, àmọ́ wọ́n ti kúrò nínú ìlú. Tí ẹ bá sáré tẹ̀ lé wọn, ẹ ṣì lè rí wọn mú!’ Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Ráhábù ṣe fi àwọn amí yẹn pa mọ́?— Ìdí ni pé ó gba Jèhófà gbọ́, ó sì mọ̀ pé Jèhófà máa jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ Kénáánì.

Kí àwọn amí yẹn tó kúrò ní ilé Ráhábù, wọ́n ṣèlérí fún un pé àwọn ò ní pa òun àti ìdílé rẹ̀ nígbà tí àwọn bá wá pa Jẹ́ríkò run. Ṣé o mọ ohun tí wọ́n sọ pé kó ṣe?— Wọ́n sọ fún un pé: ‘Gba aṣọ pupa yìí, kí o sì so ó mọ́ ojú fèrèsé rẹ. Tí o bá ṣe ohun tí a sọ yìí, kò ní séwu fún ìwọ àti ìdílé rẹ.’ Ohun tí wọ́n sọ pé kí Ráhábù ṣe gan-an ló ṣe. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?—

Okùn pupa náà wà ní ojú fèrèsé Ráhábù lára ògiri Jẹ́ríkò

Jèhófà gba Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ là

Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn yíká ìlú yẹn láì pariwo. Fún odindi ọjọ́ mẹ́fà, wọ́n rìn yípo ìlú náà ní ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́. Àmọ́ lọ́jọ́ keje, wọ́n rìn yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀méje. Ni gbogbo wọn bá pariwo sókè lẹ́ẹ̀kan náà! Jèhófà sì mú kí gbogbo ògiri ìlú náà wó lulẹ̀. Ilé tí wọ́n so okùn pupa mọ́ ojú wíńdò rẹ̀ nìkan ni kò wó lulẹ̀! Ṣé o rí ilé náà nínú àwòrán yìí?— Jèhófà gba Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ là!

Kí lo kọ́ lára Ráhábù?— Ráhábù gba Jèhófà gbọ́ nítorí gbogbo nǹkan rere tó ti gbọ́ nípa rẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan rere ni ìwọ náà ń kọ́ nípa Jèhófà. Ṣé ìwọ náà gba Jèhófà gbọ́ bíi ti Ráhábù?— A gbà pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀!

KÀ Á NÍNÚ BÍBÉLÌ RẸ

  • Jóṣúà 2:1-24; 6:1-5, 14, 15, 20-25

  • Hébérù 11:31

ÌBÉÈRÈ:

  • Àwọn ìtàn wo ni Ráhábù gbọ́ nígbà tó wà ní kékeré?

  • Báwo ni Ráhábù ṣe ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wá ṣe amí lọ́wọ́? Kí sì nìdí tó fi ràn wọ́n lọ́wọ́?

  • Ìlérí wo ni àwọn amí yẹn ṣe fún Ráhábù?

  • Kí lo kọ́ lára Ráhábù?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́