ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 12/15 ojú ìwé 22-25
  • Rahabu—A Polongo Rẹ̀ ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Ìgbàgbọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Rahabu—A Polongo Rẹ̀ ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Ìgbàgbọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọmọ Israeli Ń Bọ̀!
  • Rahabu Mú Ìdúró Rẹ̀
  • Odi Náà Wólulẹ̀!
  • Wíwo Àwọn Ànímọ́-Ìwà Rahabu
  • Èrè-Ẹ̀san Rahabu
  • A “Polongo Rẹ̀ Ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ráhábù Fi Ohun Tó Gbọ́ Sọ́kàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ráhábù Gba Jèhófà Gbọ́
    Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 12/15 ojú ìwé 22-25

Rahabu—A Polongo Rẹ̀ ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Ìgbàgbọ́

WULẸ̀ fojú-inú wò ó ná! Aṣẹ́wó kan tí a polongo ní olódodo ní ojú-ìwòye Ọlọrun. “Àgbẹdọ̀!” ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ yoo kígbe. Síbẹ̀, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Rahabu aṣẹ́wó kan ní Jeriko, ìlú-ńlá Kenaani àtijọ́ nìyẹn.

Òǹkọ̀wé Bibeli naa Jakọbu ṣàkọsílẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ríi pé a polongo ènìyàn kan ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́, kìí sìí ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan. Ní irú-ọ̀nà kan náà a kò ha polongo Rahabu aṣẹ́wó ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́, lẹ́yìn tí ó ti gba àwọn ońṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn? Nítòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ láìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jakọbu 2:24-26, NW) Èéṣe tí a fi polongo Rahabu ní olódodo? Kí ni ó ṣe tí a fi fún un ní irú àǹfààní ipò ìdúró bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọrun?

Àwọn Ọmọ Israeli Ń Bọ̀!

Ẹ jẹ́ kí a ronú padà sí ọdún 1473 B.C.E. Fojú-inú wo ìgbékalẹ̀ náà. A fi odi yí Jeriko ká lọ́nà bíbùáyà. Lórí òkè ògiri ìlú-ńlá náà ni ilé Rahabu aṣẹ́wó naa wà. Láti òkè tente tí ó ti rọrùn láti ríran yìí, ó ṣeéṣe kí ó lè wo apá ìhà ìlà-oòrùn síhà odò Jordani tí ó kún bo bèbè rẹ̀. (Joṣua 3:15) Ní bèbè ìhà ìlà-oòrùn rẹ̀, òun lè ṣàkíyèsí ibùdó àwọn ọmọ Israeli, pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun tí ó lé ní 600,000. Wọ́n kò jìnnà ju kìkì ẹsẹ̀ bàtà bíi mélòókan síi!

Rahabu ti mọ̀ nípa ìwà-akin àwọn ọmọ Israeli lójú ogun. Ó tún ti gbọ́ nípa àwọn ìfihàn agbára Jehofa, ní pàtàkì ní ṣíṣí ọ̀nà àsálà kan fún àwọn ọmọ Israeli la Òkun Pupa já. Dájúdájú, nígbà náà, odò Jordani tí ó kún bo bèbè naa kì yóò jẹ́ ìdínà kan. Àkókò yánpọnyánrin ni èyí jẹ́! Báwo ni Rahabu yóò ṣe hùwàpadà?

Rahabu Mú Ìdúró Rẹ̀

Láìpẹ́, Rahabu gba àwọn àlejò àìròtẹ́lẹ̀ méjì—àwọn amí láti ibùdó àwọn ọmọ Israeli. Wọ́n béèrè fún ibi tí wọ́n lè wọ̀ sí, ó sì gbà wọ́n sí ilé rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ nípa wíwà níbẹ̀ wọn dé etígbọ̀ọ́ ọba Jeriko. Lójú-ẹsẹ̀ ni ó rán àwọn ẹmẹ̀wà amófinṣẹ rẹ̀ jáde láti fi wọ́n sí ìhámọ́.—Joṣua 2:1, 2.

Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ ọba fi máa dé, Rahabu ti mú ìdúró rẹ̀ fún Jehofa Ọlọrun. “Mú àwọn ọkùnrin nì tí ó tọ̀ ọ́ wá . . . jáde wá,” ní àwọn ikọ̀ ọba wí. Rahabu ti fi àwọn amí náà pamọ́ sáàárín àwọn pòròpórò ewéko-ọ̀gbọ̀ tí ó sá sórí òrùlé rẹ̀. Ó wí pé: “Àwọn ọkùnrin kan wá sọ́dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ibi tí wọ́n ti wá. Ó sì ṣe ní àkókò àti ti ilẹ̀kùn ẹnubodè [ilú-ńlá], nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ọkùnrin náà sì jáde lọ: ibi tí àwọn ọkùnrin náà gbé lọ, èmi kò mọ̀: ẹ lépa wọn kánkán; nítorí ẹ̀yin óò bá wọn.” (Joṣua 2:3-5) Àwọn oníṣẹ́ ọba náà ṣe bẹ́ẹ̀—lórí asán.

Rahabu ti ṣi àwọn ọ̀tá náà lọ́nà. Kíákíá ni ó gbé àwọn ìgbésẹ̀ mìíràn tí ó fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jehofa hàn nípasẹ̀ iṣẹ́. Ó lọ sí òkè òrùlé ó sì wí fún àwọn amí náà pé: ‘Èmi mọ̀ pé dájúdájú Jehofa yóò fún yín ní ilẹ̀ náà.’ Rahabu gbà pé gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà kún fún ìbẹ̀rù nítorí wọ́n ti gbọ́ pé Ọlọrun “mú omi Òkun Pupa gbẹ” níwájú àwọn ọmọ Israeli ní 40 ọdún ṣáájú ìgbà náà. Àwọn ènìyàn náà tún mọ̀ pé àwọn ọmọ Israeli pa àwọn ọba Amori méji run. “Bí àwa ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí,” ni Rahabu sọ, “àyà wa já, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí agbára kan nínu ọkùnrin kan mọ́ nítorí yín; nítorí pé Oluwa Ọlọrun yín, òun ni Ọlọrun lókè ọ̀run, àti nísàlẹ̀ ayé.”—Joṣua 2:8-11.

Rahabu bẹ̀bẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ yín, ẹ fi Oluwa búra fún mi, bí mo ti ṣe yín ní oore, ẹ̀yin óò ṣe oore pẹ̀lu fún ilé bàbá mi, ẹ̀yin óò sì fún mi ní àmì òtítọ́: àti pé ẹ̀yin óò pa bàbá mi mọ́ láàyè, àti ìyá mi, àti àwọn arákùnrin mi, àti àwọn arábìnrin mi, àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, kí ẹ̀yin sì gba ẹ̀mí wa lọ́wọ́ ikú.”—Joṣua 2:12, 13.

Àwọn ọkùnrin náà gbà wọ́n sì sọ ohun tí Rahabu yóò ṣe. Láti ojú fèrèsé rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ so okùn rírẹ̀dòdò tí ó fi sọ àwọn amí náà kalẹ̀ lẹ́yìn odi Jeriko rọ̀. Ó gbọ́dọ̀ kó ìdílé rẹ̀ jọ sínú ilé rẹ̀, níbi tí wọ́n gbọ́dọ̀ wà fún ààbò. Rahabu fún àwọn amí tí wọ́n ń lọ náà ní àwọn ìsọfúnni ṣíṣèrànwọ́ nípa ìṣètò-gbékalẹ̀ ilẹ̀ náà ó sì sọ fún wọn bí wọ́n ṣe lè dọ́gbọ́n yẹra fún àwọn olùlépa wọn. Àwọn amí náà ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn síso okùn rírẹ̀dòdò náà kọ́ tí ó sì kó àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ̀ jọ, Rahabu dúró de àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e.—Joṣua 2:14-24.

Kí ni ohun tí Rahabu ṣe yìí? Họ́wù, ó ti fihàn pé ìgbàgbọ́ òun sinmi lé Jehofa, Ọlọrun Olódùmarè! Òun yóò gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni, a óò sì polongo rẹ̀ ní olódodo fún irú àwọn iṣẹ́ ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀.

Odi Náà Wólulẹ̀!

Ọ̀sẹ̀ bíi mélòókan rékọjá. Bí àwọn àlùfáà—tí àwọn kan ní ìwo àgbò ti àwọn mìíràn sì gbé àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú mímọ́ náà—tí ń jùmọ̀ lọ̀ pẹ̀lú wọn àwọn ọkùnrin ogun Israeli ń yí odi Jeriko po. Wọ́n ti ń ṣe èyí ní ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà nísinsìnyí. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọjọ́ keje yìí wọ́n ti yí ìlú náà po ní ìgbà mẹ́fà. Wọ́n tún ń lọ lẹ́ẹ̀kan síi!

Ìyípo keje parí, ìró ńlá láti inú àwọn ìwo náà gbòdekan. Ní báyìí, àwọn ọmọ Israeli hó kíkankíkan. Nígbà náà, Jehofa mú kí àwọn odi ààbò Jeriko wólulẹ̀ pẹ̀lú ìkùnrìrì adún-bí-àrá kan. Kìkì ẹ̀ka-ìpín tí ó gbé ilé Rahabu ró ní ó ṣẹ́kù ní ìdúró. Gbogbo ìyókù ìlú-ńlá náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ ni a parun. Aṣẹ́wó onírònúpìwàdà náà tí ó fi ẹ̀rí ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn nípa iṣẹ́ ni a pamọ́ pẹ̀lú agbo-ilé rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ síí gbé láàárín àwọn ènìyàn Jehofa.—Joṣua 6:1-25.

Wíwo Àwọn Ànímọ́-Ìwà Rahabu

Rahabu kìí ṣe ọ̀lẹ obìnrin, tí a kẹ́ bàjẹ́, ìdí ni pé àwọn pòròpórò ewéko-ọ̀gbọ̀ ni a sá sínú oòrùn lórí òrùlé rẹ̀. Àwọn okùn ewéko-ọ̀gbọ̀ ni a ó lò láti ṣe aṣọ-ọ̀gbọ̀. Àwọn ìdì okùn pípọ́nròrò tún wà ní ilé Rahabu. (Joṣua 2:6, 18) Nítorí náà, ó lè ti máa ṣe aṣọ-ọ̀gbọ̀ ó sì ṣeeṣe kí ó mọ iṣẹ́-ọnà àdìrẹ. Bẹ́ẹ̀ni, Rahabu jẹ́ aláápọn obìnrin. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ti wá ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Jehofa.—Fiwé Owe 31:13, 19, 21, 22, 30.

Iṣẹ́ Rahabu kejì ńkọ́? Òun kìí wulẹ̀ ṣe olùgbàlejo obìnrin ní ilé-èrò kan. Rara, Ìwé Mímọ́ dá a mọ̀yàtọ̀ nípa lílo àwọn ọ̀rọ̀ Heberu àti Griki náà tí ń túmọ̀sí aṣẹ́wó. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Heberu náà zoh·nahʹ sábà máa ń níí ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ aláìtọ́sófin. Lọ́nà àkọsẹ̀bá, láàárín àwọn ará Kenaani, iṣẹ́ aṣẹ́wó kìí ṣe òwò tí a fi ojú burúkú wò.

Lílò tí Jehofa lo aṣẹ́wó kan fi àánú rẹ̀ títóbi hàn. Ìrísí ojú lè tàn wá jẹ, ṣùgbọ́n Ọlọrun ‘rí ohun tí ọkàn jẹ́.’ (1 Samueli 16:7) Nípa báyìí, àwọn aṣẹ́wó ọlọ́kàn-títọ́ tí wọ́n ronúpìwàdà kúrò nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó wọn le rí ìdáríjì Jehofa Ọlọrun gbà. (Fiwé Matteu 21:23, 31, 32.) Rahabu fúnraarẹ̀ yípadà kúrò nínú ṣíṣẹ̀ sí ọ̀nà òdodo tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà àtọ̀runwá.

Àwọn amí ọmọ Israeli náà ń fi Òfin Ọlọrun sílò, nítorí náà wọn kò wọ̀ sí ilé Rahabu fún àwọn ète oníwàpálapàla. Ète wọn ti lè jẹ́ pé kò lè rọrùn láti gbé ìfura dìde nípa wíwà wọn ní ilé aṣẹ́wó. Ipò rẹ̀ lórí ògiri ìlú -ńlá náà yóò tún mú àsálà rọ́rùn. Dájúdájú, Jehofa ṣamọ̀nà wọn sí ọ̀dọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí àwọn ìròyìn nípa àwọn ìbálò àtọ̀runwá pẹ̀lú àwọn ọmọ Israeli ti ní ipa dídára lórí ọkàn-àyà rẹ̀ débi pé ó ronúpìwàdà ó sì yí àwọn ọ̀nà rẹ̀ padà. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pé Israeli yóò pa àwọn ará Kenaani run nítorí àwọn ìwàpálapàla wọn, àti ìbùkún rẹ̀ lórí Rahabu àti lórí ìṣẹ́gun Jeriko, mú kí ó dánilójú pé àwọn amí náà kò hùwà pálapàla.—Lefitiku 18:24-30.

Àwọn ọ̀rọ̀ aṣinilọ́nà Rahabu sí àwọn olùlépa àwọn amí náà ńkọ́? Ọlọrun fọwọ́sí ipa-ọ̀nà rẹ̀. (Fiwé Romu 14:4.) Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu kí ó baà lè dáàbòbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ní fífi ẹ̀rí ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn. Bí ó ti jẹ́ pé irọ́ pípa aláràn-án-kan kò tọ́ ni ojú Jehofa, kò di dandangbọ̀n fún ẹnìkan láti túdìí àṣírí ìsọfúnni òtítọ́ fún àwọn ènìyàn tí wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Jesu Kristi pàápàá kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tàbí ìdáhùn tààràtà nígbà tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ti fa ìpalára tí kò yẹ. (Matteu 7:6; 15:1-6; 21:23-27; Johannu 7:3-10) Dájúdájú, ipa-ọ̀nà Rahabu ti ṣíṣi àwọn ọ̀tá oníṣẹ́ náà lọ́nà ni a gbọ́dọ̀ fi ojú yẹn wò.

Èrè-Ẹ̀san Rahabu

Báwo ni a ṣe san èrè-ẹ̀san fún Rahabu fún fífi ìgbàgbọ́ hàn? Dájúdájú, pípa a mọ́ nígbà ìparun Jeriko jẹ́ ìbùkún kan láti ọ̀dọ̀ Jehofa. Lẹ́yìn náà, ó fẹ́ Salmoni (Salma), ọmọkùnrin olórí aginjù náà Naṣoni ti ẹ̀yà Juda. Gẹ́gẹ́ bí òbí Boasi oníwà-bí-Ọlọ́run naa, Salmoni àti Rahabu ní ìsopọ̀ kan nínú ìlà ìdílé tí ó ṣamọ̀nà sí Ọba Dafidi ti Israeli. (1 Kronika 2:3-15; Rutu 4:20-22) Ní pàtàkì jùlọ, aṣẹ́wó tẹ́lẹ̀rí náà Rahabu jẹ́ ọ̀kan péré lára àwọn obìnrin mẹ́rin tí a dárúkọ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Matteu nípa ìlà-ìdílé Jesu Kristi. (Matteu 1:5, 6) Ẹ wo irú ìbùkún tí èyí jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jehofa!

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe ọmọ Israeli tí ó sì jẹ́ aṣẹ́wó kan tẹ́lẹ̀rí, Rahabu jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ ti obìnrin kan tí ó fihàn nípa iṣẹ́ rẹ̀ pé òun ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jehofa. (Heberu 11:30, 31) Bíi ti àwọn mìíràn, díẹ̀ lára àwọn tí wọn ti kọ ìgbésí-ayé ti ṣíṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó sílẹ̀, òun yóò gba èrè-ẹ̀san mìíràn síbẹ̀—àjínde kúrò nínú ikú sí ìwàláàyè lórí paradise ilẹ̀-ayé. (Luku 23:43) Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti ó fi iṣẹ́ tì lẹ́yìn, Rahabu jèrè ìtẹ́wọ́gbà Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, olùdáríjini. (Orin Dafidi 130:3, 4) Dájúdájú, àpẹẹrẹ rere rẹ̀ pèsè ìṣírí rere fún gbogbo àwọn olùfẹ́ òdodo láti gbójúlé Jehofa Ọlọrun fún ìyè àìnípẹ̀kun.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

A polongo Rahabu ni olódodo nítorí pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ fihàn pé ó ní ìgbàgbọ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwọn awalẹ̀pìtàn ti hú àwọn òkúta Jeriko ìgbàanì jáde, tí ó ní àlàpà àtijọ́ kékeré kan nínú

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́